Ǹjẹ́ O Ní “Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ”?
ÀWỌN èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà ní igba ilẹ̀ ó lè márùndínlógójì [235] ní ohun tí Bíbélì pè ní “òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ.” Nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ìgbà mẹ́rìndínlógún ni gbólóhùn yìí fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. (Fílípì 1:20; 1 Tímótì 3:13; Hébérù 3:6; 1 Jòhánù 3:21) Kí ni “òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ” yìí túmọ̀ sí? Kí ló máa jẹ́ ká lè ní in? Àwọn ìgbà wo sì ni òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ yìí máa jẹ́ ká lè sọ̀rọ̀ fàlàlà?
Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words, fi hàn pé ọ̀rọ̀ táwọn Gíríìkì ń lò fún “òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ” túmọ̀ sí “kéèyàn lómìnira láti sọ̀rọ̀, kéèyàn lè sọ̀rọ̀ fàlàlà, . . . láìsí pé ìbẹ̀rù ń múni pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ; nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí jẹ mọ́ níní ìdánilójú, ìgboyà, àìṣojo, bẹ́ẹ̀ ni kì í bá ọ̀rọ̀ sísọ lọ lọ́pọ̀ ìgbà.” Àmọ́ ọ̀rọ̀ sísọ fàlàlà tá à ń wí yìí yàtọ̀ sí kéèyàn sọ̀kò ọ̀rọ̀ luni tàbí kéèyàn sọ̀rọ̀ ọ̀yájú. Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́.” (Kólósè 4:6) Ńṣe lẹni tó ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ máa ń fòye báni sọ̀rọ̀, kì í sì í jẹ́ kí ìṣòro tàbí ìbẹ̀rù èèyàn mú òun pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ.
Ǹjẹ́ ohun àbímọ́ni tó jẹ́ ẹ̀tọ́ gbogbo wa ni òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ? Wo ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù ná. Ó ní: “Èmi, ẹni tí ó kéré ju kékeré jù lọ nínú gbogbo ẹni mímọ́, ni a fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí fún, pé kí n polongo ìhìn rere nípa àwọn ọrọ̀ tí kò ṣeé díwọ̀n ti Kristi fún àwọn orílẹ̀-èdè.” Pọ́ọ̀lù tún sọ pé ipasẹ̀ Jésù Kristi ni “àwa ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ yìí àti ọ̀nà ìwọlé pẹ̀lú ìgbọ́kànlé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀.” (Éfésù 3:8-12) Nítorí náà, òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ kì í ṣe ohun àbímọ́ni tó jẹ́ ẹ̀tọ́ gbogbo wa o. Àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run nítorí ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi la fi lè ní in. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó máa jẹ́ ká ní òmìnira yìí, àti bí a ṣe lè máa lò ó tá a bá ń wàásù, tá a bá ń kọ́ni àti tá a bá ń gbàdúrà.
Kí Ló Máa Ń Jẹ́ Ká Lè Fi Ìgboyà Wàásù?
Jésù Kristi ni àpẹẹrẹ tó ta yọ nínú gbogbo àwọn tó ti ń lo òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ. Ìtara tó ní mú kó máa lo gbogbo àǹfààní tó bá ní láti fi wàásù. Yálà ó ń sinmi níbì kan ni o, ó ń jẹun nílé èèyàn ni o, ó ń rìn lọ lójú ọ̀nà ni o, kì í jẹ́ kí àǹfààní kankan lọ láìsọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ìfiniṣẹ̀sín tàbí àtakò líle koko ò pa Jésù lẹ́nu mọ́ kó má wàásù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń fi ìgboyà táṣìírí àwọn aṣáájú ìsìn ìgbà ayé rẹ̀. (Mátíù 23:13-36) Kódà nígbà tí wọ́n mú Jésù tí wọ́n ń bá a ṣẹjọ́, ó ṣì sọ̀rọ̀ láìṣojo.—Jòhánù 18:6, 19, 20, 37.
Àwọn àpọ́sítélì Jésù náà dẹni tó ń sọ̀rọ̀ láìṣojo. Nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Pétérù sọ̀rọ̀ fàlàlà níwájú àwọn èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000]. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, láìpẹ́ ṣáájú ìgbà yẹn, ńṣe ni jìnnìjìnnì bo Pétérù nígbà tí ìránṣẹ́bìnrin kan sọ pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù. (Máàkù 14:66-71; Ìṣe 2:14, 29, 41) Nígbà tí wọ́n mú Pétérù àti Jòhánù wá síwájú àwọn aṣáájú ìsìn, wọn ò bẹ̀rù rárá. Ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láìṣojo nípa Jésù Kristi tó ti jíǹde. Bí Pétérù àti Jòhánù ṣe sọ̀rọ̀ láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ ló jẹ́ káwọn aṣáájú ìsìn mọ̀ pé àwọn méjèèjì ti máa ń wà pẹ̀lú Jésù. (Ìṣe 4:5-13) Kí ló jẹ́ kí wọ́n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀?
Jésù ti ṣèlérí fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ níṣàájú pé: “Nígbà tí wọ́n bá fà yín léni lọ́wọ́, ẹ má ṣàníyàn nípa báwo tàbí kí ni ẹ ó sọ; nítorí a ó fi ohun tí ẹ ó sọ fún yín ní wákàtí yẹn; nítorí kì í wulẹ̀ ṣe ẹ̀yin ni ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀mí Baba yín ni ó ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ yín.” (Mátíù 10:19, 20) Ẹ̀mí mímọ́ ló jẹ́ kí Pétérù àtàwọn yòókù lè borí ìtìjú tàbí ìbẹ̀rù tí ì bá ṣèdíwọ́ fún wọn láti sọ̀rọ̀ fàlàlà. Ẹ̀mí alágbára yẹn lè ran àwa náà lọ́wọ́ lọ́nà kan náà.
Ohun mìíràn tún ni pé, Jésù ló gbé iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́. Jésù lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé òun lẹni tí Ọlọ́run fún ní “gbogbo ọlá àṣẹ . . . ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” Ó sì tún ‘wà pẹ̀lú wọn.’ (Mátíù 28:18-20) Mímọ̀ tí àwọn àpọ́sítélì ìjímìjí yìí mọ̀ pé Jésù wà pẹ̀lú àwọn jẹ́ kí wọ́n nígboyà bí wọ́n ṣe dúró níwájú àwọn aláṣẹ tó ti pinnu pé wọ́n á dá iṣẹ́ ìwàásù wọn dúró bí wọ́n fẹ́ bí wọ́n kọ̀. (Ìṣe 4:18-20; 5:28, 29) Táwa náà bá mọ̀ bẹ́ẹ̀ pé Jésù wà pẹ̀lú wa, a óò nígboyà bíi tiwọn.
Pọ́ọ̀lù tún jẹ́ ká mọ nǹkan míì tó máa ń jẹ́ kéèyàn lè sọ̀rọ̀ láìṣojo nígbà tó sọ pé ìrètí tá a ní máa ń jẹ́ ká ní “òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ńláǹlà.” (2 Kọ́ríńtì 3:12; Fílípì 1:20) Ìhìn rere tó ń fúnni nírètí jẹ́ ìròyìn ayọ̀ ńlá tí kò ṣeé pa mọ́ra, torí náà, ó di dandan káwa Kristẹni máa sọ ọ́ fáwọn èèyàn. Dájúdájú, ìrètí yìí jẹ́ ìdí míì tó fi yẹ ká máa lo òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ.—Hébérù 3:6.
Bí A Ṣe Lè Wàásù Láìṣojo
Báwo la ṣe lè máa wàásù láìṣojo láwọn ìgbà tí ẹ̀rù lè máa bà wá láti sọ̀rọ̀? Wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Nígbà tó wà lẹ́wọ̀n ní ìlú Róòmù, ó ní kí àwọn onígbàgbọ́ bíi ti òun máa bá òun gbàdúrà pé ‘kí a lè fún òun ní agbára láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú líla ẹnu òun, kí òun lè sọ̀rọ̀ láìṣojo bí ó ti yẹ kí òun sọ̀rọ̀.’ (Éfésù 6:19, 20) Ǹjẹ́ Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wọn? Bẹ́ẹ̀ ni o! Bí Pọ́ọ̀lù ṣe wà lẹ́wọ̀n, ó ń bá a lọ “ní wíwàásù ìjọba Ọlọ́run . . . pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ńláǹlà, láìsí ìdílọ́wọ́.”—Ìṣe 28:30, 31.
Tá a bá ń wàásù nígbà tí àyè bá ṣí sílẹ̀ níbi iṣẹ́, nílé ìwé àti nígbà tá a bá ń rìnrìn àjò, èyí yóò fi bá a ṣe ní ìgboyà tàbí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tó hàn. A lè má fẹ́ sọ̀rọ̀ nítorí ìtìjú, ìbẹ̀rù ohun táwọn èèyàn lè sọ tàbí tí wọ́n lè ṣe, tàbí nítorí àìdára-ẹni-lójú. Ṣùgbọ́n àpẹẹrẹ rere ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún lè ràn wá lọ́wọ́ nírú àwọn àsìkò bẹ́ẹ̀. Ó kọ̀wé pé: ‘Àwa máyàle nípasẹ̀ Ọlọ́run wa láti sọ ìhìn rere Ọlọ́run fún yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìjàkadì.’ (1 Tẹsalóníkà 2:2) Ìgbẹ́kẹ̀lé tí Pọ́ọ̀lù ní nínú Jèhófà ló jẹ́ kó lè ṣe ohun tí kì bá má lè ṣe.
Àdúrà tí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sherry gbà jẹ́ kó lè sọ̀rọ̀ láìṣojo nígbà tí àyè ṣí sílẹ̀ fún un láti wàásù lọ́nà àìjẹ́bí-àṣà. Lọ́jọ́ kan tó ń dúró de ọkọ rẹ̀ tó lọ rí ẹnì kan, ó rí obìnrin kan tóun náà dúró. Sherry ní: “Ẹ̀rù ń bà mí àmọ́ mo gbàdúrà pé kí Jèhófà fún mi nígboyà láti sọ̀rọ̀.” Bí Sherry ṣe lọ sọ́dọ̀ obìnrin náà ni ọ̀kan lára àlùfáà ìjọ Onítẹ̀bọmi dé ọ̀dọ̀ wọn. Sherry ò retí pé òun máa bá àlùfáà pàdé. Ló bá tún gbàdúrà lẹ́ẹ̀kan sí i, ìyẹn sì jẹ́ kó lè wàásù. Obìnrin náà gbàwé lọ́wọ́ Sherry, ó sì tún gbà kí Sherry wá ṣe ìpadàbẹ̀wò òun. Kí ó dá wa lójú pé tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a ó lè sọ̀rọ̀ fàlàlà nígbà tá a bá fẹ́ lo àǹfààní àyè tó ṣí sílẹ̀ láti fi wàásù.
Nígbà Tá A Bá Ń Kọ́ni
Òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ṣe pàtàkì gan-an nígbà tá a bá ń kọ́ni. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀,” ó ní: “[Wọ́n] ń jèrè ìdúró tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ara wọn àti òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ńláǹlà nínú ìgbàgbọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.” (1 Tímótì 3:13) Ohun tó ń jẹ́ kí wọ́n ní òmìnira sísọ yìí ni pé, àwọn fúnra wọn máa ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ni sílò. Ṣíṣe tí wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ààbò fún ìjọ, ó sì máa ń gbé ìjọ ró.
Tá a bá ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lọ́nà yìí, ìmọ̀ràn wa a lè máa wọ àwọn ará lọ́kàn, á sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ fẹ́ láti lo ìmọ̀ràn náà. Àwọn olùgbọ́ wa á lè rí àpẹẹrẹ tiwa pé à ń fi ohun tí à ń kọ́ wọn sílò, ìyẹn á sì máa fún wọn níṣìírí. Kò ní jẹ́ pé àpẹẹrẹ tí ò dáa ni wọ́n ń rí lára wa, èyí tí yóò máa bà wọ́n nínú jẹ́. Òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ yìí máa ń jẹ́ kí àwọn tó tóótun nípa tẹ̀mí lè ‘tọ́ àwọn arákùnrin wọn sọ́nà padà’ kí ìṣòro wọn tó di ńlá. (Gálátíà 6:1) Ṣùgbọ́n tọ́wọ́ ẹnì kan ò bá mọ́, yóò máa lọ́ra láti bá ẹni tó ṣàṣìṣe wí, nítórí yóò wò ó pé ọ̀rọ̀ ò dùn lẹ́nu òun. Tẹ́ni tó ń ṣàṣìṣe ò bá sì tètè rí ìbáwí, ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè bọ́ sórí.
Sísọ̀rọ̀ láìṣojo kò túmọ̀ sí pé ká di ẹni tó ń ṣàríwísí àwọn èèyàn, ẹni tó jẹ́ pé èrò tirẹ̀ nìkan ló ń yé e, tàbí aṣetinú-ẹni. Ńṣe ni Pọ́ọ̀lù fi “ìfẹ́” gba Fílémónì níyànjú. (Fílémónì 8, 9) Ẹ̀rí sì fi hàn pé Fílémónì ṣe bí Pọ́ọ̀lù ṣe wí. Ká sòotọ́, ìfẹ́ ló yẹ kí alàgbà máa fi fúnni nímọ̀ràn!
Ìgbà tá a bá fẹ́ báni wí nìkan kọ́ ló ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ ẹni tó lómìnira ọ̀rọ̀ sísọ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì pé: “Mo ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ńláǹlà sí yín. Mo ní ìṣògo ńláǹlà nípa yín.” (2 Kọ́ríńtì 7:4) Pọ́ọ̀lù máa ń yin àwọn arákùrin àti arábìnrin rẹ̀ nígbà tó bá yẹ kó yìn wọ́n. Ìfẹ́ ló mú kó máa wo àwọn ànímọ́ rere táwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ ní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ kùdìẹ̀-kudiẹ wọn. Lónìí bákan náà, táwọn alàgbà bá ń yin àwọn ará dáadáa, tí wọ́n sì ń fún wọn níṣìírí, ìyẹn máa ń gbé ìjọ ró.
Gbogbo Kristẹni ló yẹ kó ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ kí ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni lè máa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. Nígbà kan, Sherry tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan fẹ́ gba àwọn ọmọ rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n máa wàásù nílé ìwé. Ṣùgbọ́n Sherry sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú òtítọ́ ni mo dàgbà sí, mi ò kì í sábà wàásù nígbà tí mo wà nílé ìwé. Agbára káká sì ni mo fi ń wàásù lọ́nà àìjẹ́bí-àṣà. Mo wá bi ara mi pé, ‘Irú àpẹẹrẹ wo ni mo fi ń lélẹ̀ fáwọn ọmọ mi ná?’” Èyí mú kí Sherry sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rí i pé òun ń wàásù lọ́nà àìjẹ́bí-àṣà.
Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn èèyàn máa ń wo ìṣe wa, wọ́n sì ń rí wa tá ò bá tẹ̀ lé ohun tá à ń kọ́ni. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa sapá láti jẹ́ kí ìṣe wa bá ọ̀rọ̀ wa mu ká lè jẹ́ ẹni tó ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ.
Nígbà Tá A Bá Ń Gbàdúrà
Ó ṣe pàtàkì gidigidi pé ká ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà. Gbogbo ohun tí ń bẹ lọ́kàn wa la lè sọ fún Jèhófà, pẹ̀lú ìdánilójú pé yóò gbọ́ àdúrà wa àti pé yóò dáhùn rẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Baba wa ọ̀run. Ẹ má ṣe jẹ́ ká lọ́ tìkọ̀ rárá o láti bá Jèhófà sọ̀rọ̀, ká má sì ṣe rò pé a ò já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ̀. Àmọ́ kí ni ká wá ṣe tí ẹ̀rí ọkàn bá ń yọ wá lẹ́nu nítorí àṣìṣe tàbí ẹ̀ṣẹ̀ wa, débi pé a ò lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀ látọkànwá? Ǹjẹ́ a ṣì lè bá Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run sọ̀rọ̀ fàlàlà nírú ipò bẹ́ẹ̀?
Ipò Àlùfáà Àgbà tó jẹ́ ipò gíga tí Jésù wà máa ń jẹ́ kí ọkàn wa túbọ̀ balẹ̀ pé a lè gbàdúrà láìbẹ̀rù. Hébérù 4:15, 16 sọ pé: “Àwa ní gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà, kì í ṣe ẹni tí kò lè báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa, bí kò ṣe ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa, ṣùgbọ́n tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́.” Èyí fi hàn pé ikú tí Jésù kú àti ipa tó ń kó gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà ṣàǹfààní fún wa gan-an ni.
Bí a bá ń sa gbogbo ipá wa láti ṣègbọràn sí Jèhófà, kí ó dá wa lójú pé yóò gbọ́ àdúrà wa. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, bí ọkàn-àyà wa kò bá dá wa lẹ́bi, a ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ lọ́dọ̀ Ọlọ́run; ohun yòówù tí a bá sì béèrè ni a ń rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, nítorí a ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, a sì ń ṣe àwọn ohun tí ó dára lójú rẹ̀.”—1 Jòhánù 3:21, 22.
Nígbà tá a ti lè gbàdúrà sí Jèhófà fàlàlà, ó fi hàn pé kò sí ohun tá ò lè sọ fún un. Bí ohunkóhun bá ń bà wá lẹ́rù, tàbí ó ń dà wá láàmù, tàbí à ń ṣàníyàn nípa rẹ̀ tàbí ó ń já wa láyà, a lè sọ ọ́ fún Jèhófà, pẹ̀lú ìdánilójú pé yóò gbọ́ àdúrà àtọkànwá wa. Bá a bá tiẹ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá pàápàá, tá a bá ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn, kò yẹ kí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ dí wa lọ́wọ́ ká má lè bá Jèhófà sọ ohun tó wà lọ́kàn wa.
Òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tó jẹ́ ẹ̀bùn tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí ṣeyebíye gan-an ni. A lè lò ó láti fi yin Ọlọ́run lógo tá a bá ń wàásù tàbí à ń kọ́ni. A sì lè lò ó tá a bá ń gbàdúrà ká lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Nítorí náà, ‘ẹ má ṣe jẹ́ ká gbé òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ wa sọ nù, èyí tí ó ní ẹ̀san ńláǹlà tí a ó san fún un,’ ìyẹn èrè ìyè àìnípẹ̀kun.—Hébérù 10:35.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ láìṣojo
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Kí ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ àwọn èèyàn tó lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn, a gbọ́dọ̀ ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ó ṣe pàtàkì ká ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tá a bá ń gbàdúrà