Mọrírì Ìwà Ọ̀làwọ́ Jèhófà
Ọ̀LÀWỌ́ ni Jèhófà Ọlọ́run. (Ják. 1:17) Àwọn ìràwọ̀ tó máa ń kún ojú ọ̀run lálẹ́ àtàwọn ewéko títutù yọ̀yọ̀ tó ń mú kí ilẹ̀ ayé dùn-ún wò ń fi hàn pé ọ̀làwọ́ ni Jèhófà lóòótọ́.—Sm. 65:12, 13; 147:7, 8; 148:3, 4.
Onísáàmù náà mọrírì àwọn ohun tí Jèhófà dá gan-an débi pé ó kọ orin kan láti yin Jèhófà lógo. Tó o bá ka ìwé Sáàmù 104, ìwọ náà á rí ìdí tó fi yẹ kó o yin Jèhófà. Onísáàmù náà sọ pé: “Ṣe ni èmi yóò máa kọrin sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé mi; èmi yóò máa kọ orin atunilára sí Ọlọ́run mi níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà.” (Sm. 104:33) Ṣó wu ìwọ náà láti yin Jèhófà?
ÌWÀ Ọ̀LÀWỌ́ TÓ TA YỌ JÙ LỌ
Jèhófà fẹ́ kí àwa náà jẹ́ ọ̀làwọ́ bíi tiẹ̀. Nínú ọ̀rọ̀ tó mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ, Jèhófà jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká jẹ́ ọ̀làwọ́, ó ní: “Fún àwọn ọlọ́rọ̀ nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ní àṣẹ ìtọ́ni láti má ṣe jẹ́ ọlọ́kàn-gíga, kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa; láti máa ṣe rere, láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, láti jẹ́ aláìṣahun, kí wọ́n múra tán láti ṣe àjọpín, kí wọ́n máa fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la, kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.”—1 Tím. 6:17-19.
Nígbà tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì sí ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì, ó sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ ọ̀làwọ́. Ó sọ pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́r. 9:7) Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù sọ àwọn tó máa ń jàǹfààní látinú ìwà ọ̀làwọ́: ẹni tí wọ́n hùwà ọ̀làwọ́ sí á rí ohun tó nílò gbà; ẹni tó hùwà ọ̀làwọ́ síni á sì rí ìbùkún yanturu gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.—2 Kọ́r. 9:11-14.
Níparí lẹ́tà rẹ̀ yìí, Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà títayọ jù lọ tí Ọlọ́run gbà jẹ́ ọ̀làwọ́. Ó sọ pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run fún ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ aláìṣeé-ṣàpèjúwe.” (2 Kọ́r. 9:15) Ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa yìí ni gbogbo oore tó ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi. Oore náà pọ̀ débi pé ó kọjá àfẹnusọ.
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì gbogbo ohun tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ti ṣe fún wa àtàwọn ohun tí wọ́n ṣì máa ṣe? Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa lo àkókò wa, okun wa àtàwọn ohun ìní wa, yálà ó kéré tàbí ó pọ̀, láti ti ìjọsìn mímọ́ Jèhófà lẹ́yìn.—1 Kíró. 22:14; 29:3-5; Lúùkù 21:1-4.