Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ṣẹ́gun
“Ojú rẹ yóò rí [Atóbilọ́lá Olùkọ́ni, NW] rẹ: etí rẹ ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, Èyí yìí ni ọ̀nà, ẹ máa rìn nínú rẹ̀.”—ISAIAH 30:20, 21.
1. Èéṣe ti a fi lè fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ pe ìtọ́ni Jehofa ní ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá?
JEHOFA ỌLỌRUN ni Orísun ẹ̀kọ́ dídára julọ tí ẹnikẹ́ni lè kọ́. Bí a bá fetísílẹ̀ nígbà tí ó bá ń sọ̀rọ̀, ní pàtàkì nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Mímọ́-Ọlọ́wọ̀ rẹ̀, òun yóò jẹ́ Atóbilọ́lá Olùkọ́ni wa. (Isaiah 30:20) Ọ̀rọ̀-ẹsẹ̀-ìwé Bibeli Lédè Heberu pẹ̀lú pè é ní “Olú Ọ̀run.” (Orin Dafidi 50:1, NW) Nípa báyìí, ìtọ́ni Jehofa jẹ́ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá.
2. Ní èrò-ìtúmọ̀ wo ni ó fi jẹ́ òtítọ́ pé Ọlọrun nìkanṣoṣo ni ó gbọ́n?
2 Ayé ń fi ètò ilé-ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí ó pọ̀ rẹpẹtẹ yangàn, ṣùgbọ́n kò sí ọ̀kankan nínú wọn tí ń fúnni ní ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá. Họ́wù, gbogbo ọgbọ́n tí aráyé ti kójọ jálẹ̀ ọ̀rọ̀-ìtàn rẹ̀ jẹ́ ìwọ̀n bíńtín nígbà tí a bá fiwéra pẹ̀lú ìtọ́ni àtọ̀runwá tí a gbékarí ọgbọ́n aláìlópin ti Jehofa. Romu 16:27 sọ pé Ọlọrun nìkanṣoṣo ni ọlọ́gbọ́n, èyí sì jẹ́ òtítọ́ ní èrò-ìtumọ̀ náà pé Jehofa nìkanṣoṣo ni ó gbọ́n tán.
3. Èéṣe tí Jesu Kristi fi jẹ́ olùkọ́ títóbilọ́lá jùlọ náà tí ó tíì rìn lórí ilẹ̀-ayé rí?
3 Ọmọkùnrin Ọlọrun, Jesu Kristi, jẹ́ àpẹẹrẹ títayọlọ́lá nínú ọgbọ́n, òun sì ni olùkọ́ títóbilọ́lá jùlọ náà tí ó tíì rìn lórí ilẹ̀-ayé rí. Kò yanilẹ́nu! Fún ọ̀pọ̀ sànmánì Jehofa ti jẹ́ Olùkọ́ rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run. Níti gidi, ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ọlọrun bẹ̀rẹ̀ síí fún ìṣẹ̀dá rẹ̀ àkọ́kọ́, Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kanṣoṣo ní ìtọ́ni. Jesu lè tipa báyìí sọ pé: “Bí Baba ti kọ́ mi, èmi ń sọ nǹkan wọ̀nyí.” (Johannu 8:28; Owe 8:22, 30) Àwọn ọ̀rọ̀ Kristi fúnraarẹ̀ tí a kọsílẹ̀ nínú Bibeli fi púpọ̀ kún ìmọ̀ wa nípa ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá. Nípa kíkọ́ni ní àwọn ẹ̀kọ́ ti Jesu fi kọ́ni, àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ṣègbọràn sí Atóbilọ́lá Olùkọ́ni wọn, ẹni tí ó jẹ́ ìfẹ́-inú rẹ̀ pé kí a baà lè fi “ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírúurú ọgbọ́n Ọlọrun” hàn nípasẹ̀ ìjọ.—Efesu 3:10, 11; 5:1; Luku 6:40.
Wíwá Ọgbọ́n Kiri
4. Ki ni a ti sọ nípa agbára ọpọlọ?
4 Jíjèrè ọgbọ́n tí ń wá láti inú ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ń béèrè fún fífi aápọn lo agbára ìrònú tí Ọlọrun fifún wa. Èyí ṣeéṣe nítorí pé ọpọlọ ènìyàn ní agbára kíkàmàmà fún ìdàgbàsókè. Ìwé náà The Incredible Machine sọ pé: “Kódà àwọn ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà dídíjú jùlọ tí àwa lè fojú inú yàwòràn rẹ̀ jẹ́ páńda-àgbélẹ̀rọ ní ìfiwéra pẹ̀lú ìdíjú tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ aláìlópin àti ṣíṣeétẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún ọpọlọ ẹ̀dá ènìyàn—àwọn ànímọ́ tí ètò-ìgbékalẹ̀ àmì-atàtaré ìsọfúnni rẹ̀ dídíjú tí a fètò sí, tí ètò oníná mànàmáná àti kẹ́míkà mú kí ó ṣeéṣe. . . . Àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn àmì-atàtaré ìsọfúnni tí wọ́n ń bùyẹ̀rì gba inú ọpọlọ rẹ kọjá ní ìṣẹ́jú èyíkéyìí ń gbé ẹrù ìsọfúnni tí ó jẹ́ àrà-ọ̀tọ̀. Wọ́n ń mú ìsọfúnni wá nípa àyíká ara rẹ ti inú lọ́hùn-ún àti ti òde: nípa pajápajá ní ọmọ ìkasẹ̀ rẹ, tàbí òórùn dídùn kọfí, tàbí ọ̀rọ̀ apanilẹ́rìn-ín tí ọ̀rẹ́ kan sọ. Bí àwọn àmì-atàtaré ìsọfúnni mìíràn ti ń ṣiṣẹ́ lórí ìsọfúnni tí wọ́n sì ń ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ rẹ̀, wọ́n ń mú àwọn èrò-ìmọ̀lára, ìrántí, ìrònú, tàbí àwọn ìwéwèé kan pàtó jáde èyí tí ń ṣamọ̀nà sí ìpinnu kan. Ní èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ lójú ẹsẹ̀, àwọn àmì-atàtaré ìsọfúnni láti inú ọpọlọ rẹ ń sọ ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún àwọn apá ibòmíràn nínú ara rẹ: mi ọmọ ìkasẹ̀ rẹ, mu kọfí, rẹ́rìn-ín, tàbí bóyá kí o fèsì tí ń dẹ́rìn-ín-pani. Láàárín àkókò kan-náà ọpọlọ rẹ ń bójútó mímí rẹ, àpòpọ̀ kẹ́míkà tí ń bẹ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ, ìdíwọ̀n ooru ara, àti àwọn ètò ìṣiṣẹ́ mìíràn tí ó ṣekókó èyí tí ìwọ kò mọ̀. Ó ń pa àṣẹ tí ń mú kí ara rẹ ṣiṣẹ́ lọ́nà jíjágeere láìka àwọn ìyípadà ìgbà gbogbo ní àyíká rẹ sí. Ó ń múrasílẹ̀ fún àwọn àìní ọjọ́ iwájú pẹ̀lú.”—Ojú-ìwé 326.
5. Ní èrò-ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́, kí ni ọgbọ́n jẹ́?
5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dájú rékọjá ìyèméjì pé ọpọlọ ènìyàn ní agbára àgbàyanu, báwo ni a ṣe lè lo èrò-inú lọ́nà dídára jùlọ? Kìí ṣe nípa ríri araawa sínú ìkẹ́kọ̀ọ́ àfitokuntokun ṣe láti kẹ́kọ̀ọ́ èdè, ọ̀rọ̀-ìtàn, ìmọ̀-ìjìnlẹ̀, tàbí fífi àwọn ìsìn wéra. A gbọ́dọ̀ lo agbára ìrònú wa ní pàtàkì láti gba ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá. Ẹ̀kọ́ yìí nìkanṣoṣo ni ó ń yọrísí ojúlówó ọgbọ́n. Ṣùgbọ́n kí ni ọgbọ́n tòótọ́ jẹ́? Ní ọ̀nà tí Ìwé Mímọ́ gbà túmọ̀ rẹ̀, ọgbọ́n fi ìtẹnumọ́ sórí ìdájọ́ yíyèkooro tí a gbékarí ìmọ̀ pípéye àti òye gidi. Ọgbọ́n ń mú kí ó ṣeéṣe fún wa láti lo ìmọ̀ àti òye lọ́nà yíyọrísírere láti yanjú àwọn ìṣòro, láti yẹra fún àwọn ewu tàbí dènà rẹ̀, láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, àti láti lé àwọn góńgó bá. Lọ́nà tí ó ru ọkàn-ìfẹ́ sókè, Bibeli fi ọgbọ́n wéra pẹ̀lú ìwà-òmùgọ̀ àti ìyadìndìnrìn—àwọn ànímọ́ tí ó dájú pé àwa yóò fẹ́ láti yẹra fún.—Deuteronomi 32:6; Owe 11:29; Oniwasu 6:8.
Ìwé-Ẹ̀kọ́ Ńlá ti Jehofa
6. Bí a bá níláti fi ọgbọ́n tòótọ́ hàn, kí ni a gbọ́dọ̀ lò lọ́nà rere?
6 Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọgbọ́n ayé ni ó wà yí wa ká. (1 Korinti 3:18, 19) Họ́wù, ayé yìí kún fún àwọn ilé-ẹ̀kọ́ àti ibi-àkójọ-ìwé-kíkà tí ó ní àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn ìwé nínú! Ọ̀pọ̀ nínú ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ìwé-ẹ̀kọ́ tí ń fúnni ní ìtọ́ni nínú èdè, ìmọ̀ ìṣirò, ìmọ̀-ìjìnlẹ̀, àti àwọn pápá ìmọ̀ mìíràn. Ṣùgbọ́n Atóbilọ́lá Olùkọ́ni náà ti pèsè ìwé-ẹ̀kọ́ náà tí ó tayọ gbogbo àwọn yòókù—Bibeli, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó ní ìmísí. (2 Timoteu 3:16, 17) Ó péye kìí ṣe kìkì nígbà tí ó bá mẹnukan irú àwọn kókó-ẹ̀kọ́ bíi ọ̀rọ̀-ìtàn, ìmọ̀ nípa ìrísí ojú-ilẹ̀, àti ìmọ̀ nípa ohun-ọ̀gbìn nìkan ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́-ọ̀la pẹ̀lú. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí-ayé aláyọ̀ tí ó sì ń mérè wá jùlọ nísinsìnyí gan-an. Àmọ́ ṣáá o, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ ayé ti gbọ́dọ̀ lo àwọn ìwé wọn, àwa gbọ́dọ̀ mọ Ìwé-Ẹ̀kọ́ ńlá ti Ọlọrun dunjú bí àwa yóò bá fi ọgbọ́n tòótọ́ hàn gẹ́gẹ́ bí àwọn wọnnì tí a “kọ́ . . . láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.”—Johannu 6:45.
7. Èéṣe tí ìwọ yóò fi sọ pé mímọ àwọn ohun tí ń bẹ nínú Bibeli dunjú lọ́nà ìrònúmòye kò tó?
7 Síbẹ̀, mímọ Bibeli dunjú lọ́nà ìrònúmòye kìí ṣe ohun kan-náà pẹ̀lú ọgbọ́n tòótọ́ àti fífaramọ́ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá. Láti ṣàkàwé: Ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún C.E., ọkùnrin onísìn Katoliki kan tí ń jẹ́ Cornelius van der Steen fẹ́ láti di onísìn Jesuit ṣùgbọ́n a kọ̀ ọ́ nítorí pé ó ti kúrú jù. Manfred Barthel sọ nínú ìwé rẹ̀ The Jesuits—History & Legend of the Society of Jesus pé: “Ìgbìmọ̀ náà fi tó van der Steen létí pé àwọn ṣetán láti gbé ohun-àbéèrè-fún wọn nípa gíga tì sí ẹ̀gbẹ́ kan, ṣùgbọ́n wọ́n fi òté lé e pé òun níláti kọ́ láti ka gbogbo Bibeli ní àkọ́sórí. Agbára káká ni ìtàn náà ìbá fi yẹ ní sísọ bí ó bá jẹ́ pé van der Steen kò ti faramọ́ ohun-àbéèrè-fún ọlọ́yàájú yìí.” Ẹ wo ìsapá tí ó gbà láti kọ́ odidi Bibeli sórí! Bí ó ti wù kí ó rí, ó dájú pé ó ṣe pàtàkì púpọ̀púpọ̀ láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ju híhá a sórí lọ.
8. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jàǹfààní láti inú ẹ̀kọ̀ àtọ̀runwá kí a sì fi ọgbọ́n tòótọ́ hàn?
8 Bí àwa yóò bá jàǹfààní lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ láti inú ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá kí a si fi ọgbọ́n tòótọ́ hàn, a nílò ìmọ̀ pípéye nínú Ìwé Mímọ́. Ẹ̀mí mímọ́ tàbí agbára ìṣiṣẹ́ Jehofa gbọ́dọ̀ tọ́ wa sọ́nà pẹ̀lú. Èyí yóò mú kí ó ṣeéṣe fún wa láti kọ́ àwọn òtítọ́ jíjinlẹ̀, àwọn “ohun ìjìnlẹ̀ ti Ọlọrun.” (1 Korinti 2:10) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a fi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé-Ẹ̀kọ́ ńlá ti Jehofa kí a sì gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà rẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. Ní ìbámu pẹ̀lú Owe 2:1-6, ẹ jẹ́ kí a fetísílẹ̀ sí ọgbọ́n, kí a sì mú kí ọkàn-àyà wa fà sí ìfòyemọ̀, kí a sì ké pe òye. A gbọ́dọ̀ ṣe èyí bí ẹni pé a ń wá àwọn ìṣúra fífarasin, nítorí kìkì nígbà náà ni àwa yóò ‘lóye ìbẹ̀rù Jehofa tí a ó sì rí ìmọ̀ Ọlọrun gan–an.’ Ìgbéyẹ̀wò àwọn ìṣẹ́gun àti àǹfààní ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá yóò mú ìmọrírì wa fún ọgbọ́n tí Ọlọrun fifúnni pọ̀ síi.
Òye Ní Ṣísẹ̀-N-Tẹ̀lé
9, 10. Kí ni Ọlọrun sọ bí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní Genesisi 3:15, kí sì ni òye títọ̀nà nípa àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì?
9 Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ṣẹ́gun nípa fífún àwọn ènìyàn Jehofa ní òye Ìwé Mímọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Fún àpẹẹrẹ, a ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Satani Eṣu ni ẹni tí ó tipasẹ̀ ejò kan sọ̀rọ̀ ní Edeni tí ó sì fi ẹ̀sùn kàn lọ́nà èké pé Ọlọrun purọ́ nígbà tí Ó sọ pé ikú ni yóò jẹ́ ìjìyà fún jíjẹ èso tí a kàléèwọ̀ náà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a ríi pé àìgbọ́ràn sí Jehofa Ọlọrun mú ikú wá sórí ìran ènìyàn nítòótọ́. (Genesisi 3:1-6; Romu 5:12) Síbẹ̀, Ọlọrun fún aráyé ní ìrètí nígbà tí ó sọ fún ejò náà, àti nípa bẹ́ẹ̀ Satani pé: “Èmi ó sì fi ọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀: òun óò fọ́ ọ ní orí, ìwọ ó sì pa á ní gìgísẹ̀.”—Genesisi 3:15.
10 Àṣírí kan tí a ti ń ṣípayá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ń bẹ nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì. Jehofa ti kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pé ẹṣin-ọ̀rọ̀ Bibeli tí ó gba iwájú jùlọ ni ìdáláre ipò ọba-aláṣẹ rẹ̀ nípasẹ̀ Irú-Ọmọ náà, ọmọ-ìran Abrahamu àti Dafidi tí ó ní ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin sí ìṣàkóso Ìjọba. (Genesisi 22:15-18; 2 Samueli 7:12, 13; Esekieli 21:25-27) Atóbilọ́lá Olùkọ́ni wa ti kọ́ wa pé Jesu Kristi ni Irú-Ọmọ onípò àkọ́kọ́ ti “obìnrin” náà, ètò-àjọ àgbáyé Ọlọrun. (Galatia 3:16) Láìka gbogbo ìdánwò tí Satani mú wá sórí rẹ̀ sí, Jesu di ìwàtítọ́ rẹ̀ mú—àní títí dójú ikú, pípa Irú-Ọmọ náà ní gìgísẹ̀. A ti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú pé 144,000 àwọn ajùmọ̀jogún Ìjọba láti inú aráyé yóò ṣàjọpín pẹ̀lú Kristi nínú fífọ́ orí Satani, “ejò àtijọ nì.” (Ìfihàn 14:1-4; 20:2; Romu 16:20; Galatia 3:29; Efesu 3:4-6) Ẹ wo bí a ṣe mọrírì irú ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun bẹ́ẹ̀ tó!
Sínú Ìmọ́lẹ̀ Àgbàyanu Ọlọrun
11. Èéṣe tí a fi lè sọ pé ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ṣẹ́gun nípa mímú àwọn ènìyàn wá sínú ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí?
11 Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ṣẹ́gun nípa mímú àwọn ènìyàn wá sínú ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí. Àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ti ní ìrírí yẹn ní ìmúṣẹ 1 Peteru 2:9: “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ìran tí a yàn, olú-àlùfáà, orílẹ̀-èdè mímọ́, ènìyàn ọ̀tọ̀; kí ẹ̀yin kí ó lè fi ọlá ńlá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ [àgbàyanu, NW] rẹ̀ hàn.” Lónìí, ìmọ́lẹ̀ tí Ọlọrun fi fúnni ni àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí wọn yóò wàláàyè títíláé nínú paradise lórí ilẹ̀-ayé ń gbádùn pẹ̀lú. (Ìfihàn 7:9, NW; Luku 23:43) Bí Ọlọrun ti ń kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀, Owe 4:18 jásí òtítọ́ pé: “Ipa-ọ̀nà àwọn olóòótọ́ dàbí títàn ìmọ́lẹ̀, tí ó ń tàn síwájú àti síwájú títí di ọ̀sán gangan.” Ọ̀nà ìgbàkẹ́kọ̀ọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé yìí ń sọ òye wa nípa ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá dọ̀tun síi, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ ti ń tẹ̀síwájú nítorí ìrànwọ́ rere láti ọ̀dọ̀ olùkọ́ nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ gírámà, ọ̀rọ̀-ìtàn, tàbí àwọn kókó-ẹ̀kọ́ mìíràn kan.
12, 13. Lòdìsí àwọn ewu wo níti ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ ni ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ti dáàbòbo àwọn ènìyàn Jehofa?
12 Ìṣẹ́gun ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá mìíràn ni pé ó ń dábòòbo àwọn tí ń fìrẹ̀lẹ̀-ọkàn tẹ́wọ́gbà á kúrò lọ́wọ́ “ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí-èṣù.” (1 Timoteu 4:1) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹ wo Kristẹndọm! Nígbà náà lọ́hùn-ún ní 1878, bíṣọ́ọ̀bù àgbà ṣọ́ọ̀ṣì Roman Katoliki John Henry Newman kọ̀wé pé: “Ní gbígbọ́kànlé agbára ìsìn Kristian nígbà náà láti dènà àkóràn ibi, àti láti yí àwọn irin-iṣẹ́ àti ìjàǹjá ìjọsìn eṣu padà pátápátá sí ìlò ìjíhìnrere, . . . àwọn alákòóso Ṣọ́ọ̀ṣì láti àkókò ìjímìjí ti múratán, bí ipò-ọ̀ràn náà bá dìde, láti gbà, tàbí farawé, tàbí fọwọ́sí àwọn ààtò-ìsìn àti àṣà tí àwọn ará ìlú ti ní, àti ọgbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn ẹgbẹ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n pẹ̀lú.” Newman fikún un pé irú àwọn nǹkan bí omi mímọ́, aṣọ aláyẹyẹ ìsìn ti àwọn àlùfáà, àti àwọn ère “ni gbogbo wọn ní ìpilẹ̀sẹ̀ olórìṣà, tí a sì sọ wọ́n dí mímọ́ nípa mímú wọn wọnú Ṣọ́ọ̀ṣì.” Àwọn ènìyàn Ọlọrun kún fún ọpẹ́ nítòótọ́ pé ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá dáàbòbò wọ́n kúrò nínú irú ìpẹ̀yìndà bẹ́ẹ̀. Ó borí gbogbo onírúurú ìjọsìn ẹ̀mí-èṣù.—Iṣe 19:20.
13 Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ṣẹ́gun ìṣìnà ìsìn ní gbogbo ọ̀nà. Fún àpẹẹrẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn wọnnì tí Ọlọrun kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, àwa kò gbàgbọ́ nínú Mẹ́talọ́kan ṣùgbọ́n a gbà pé Jehofa ni Ẹni Gíga Jùlọ, Jesu jẹ́ Ọmọkùnrin rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ sì jẹ́ ipá agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọrun. A kò bẹ̀rù iná hẹ́ẹ̀lì, nítorí tí a mọ̀ pé hẹ́ẹ̀lì ti Bibeli jẹ́ isà-òkú gbogbo aráyé lápapọ̀. Nígbà tí àwọn onísìn èké sì sọ pé ọkàn ènìyàn jẹ́ aláìlèkú, a mọ̀ pé àwọn òkú kò mọ ohunkóhun rárá. Bí àkọsílẹ̀ náà ti lọ jáǹtìrẹrẹ nìyẹn nípa àwọn òtítọ́ tí a ti jèrè nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá. Ẹ wo irú ìbùkún tí ó jẹ́ láti di òmìnira kúrò nínú ìgbèkùn tẹ̀mí lábẹ́ Babiloni Ńlá, ilẹ̀-ọba ìsìn èké àgbáyé!—Johannu 8:31, 32; Ìfihàn 18:2, 4, 5.
14. Èéṣe tí àwọn ìránṣẹ́ Jehofa fi lè máa rìn nìṣó nínú ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí?
14 Nítorí pé ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ṣẹ́gun ìṣìnà ìsìn, ó mú kí ó ṣeéṣe fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun láti rìn nínú ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí. Nítòótọ́, wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn wọn tí ń sọ pé: “Èyí yìí ni ọ̀nà, ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” (Isaiah 30:21) Ẹ̀kọ́ Ọlọrun tún ń dáàbòbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ìrònú èké. Nígbà tí “àwọn èké Aposteli” ń fa wàhálà nínú ìjọ tí ó wà ní Korinti, aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ohun ìjà wa kìí ṣe ti ara, ṣùgbọ́n ó ní agbára nínú Ọlọrun láti wó ibi gíga palẹ̀; àwa ń sọ gbogbo èrò kalẹ̀, àti gbogbo ohun gíga tí ń gbé ara rẹ̀ ga sí ìmọ̀ Ọlọrun, àwa sì ń di gbogbo èrò ní ìgbèkùn wá sí ìtẹríba fún Kristi.” (2 Korinti 10:4, 5; 11:13-15) A ń sọ gbogbo èrò tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá kalẹ̀ nípasẹ̀ ìtọ́ni tí a ń fifúnni pẹ̀lú ìwàtútù nínú ìjọ àti nípa wíwàásù ìhìnrere fún àwọn wọnnì tí ń bẹ lóde.—2 Timoteu 2:24-26.
Ìjọsìn Ní Ẹ̀mí àti Ní Òtítọ́
15, 16. Kí ni ó túmọ̀sí láti sin Jehofa ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́?
15 Bí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ti ń tẹ̀síwájú, ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ń ṣẹ́gun ní fífihan àwọn onínútútù bí wọ́n ṣe lè jọ́sìn Ọlọrun “ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́.” Níbi kànga Jakọbu nítòsí ìlú-ńlá Sikari, Jesu sọ fún obìnrin ará Samaria kan pé òun lè pèsè omi tí ń fúnni ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ní títọ́ka sí àwọn ará Samaria, ó fikún un pé: “Ẹ̀yin ń sin ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀ . . . Wákàtí ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsìnyí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́: nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun.” (Johannu 4:7-15, 21-23) Lẹ́yìn náà Jesu fi araarẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bíi Messia náà.
16 Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe lè sin Ọlọrun ní ẹ̀mí? Nípa ṣíṣe ìjọsìn mímọ́gaara láti inú ọkàn-àyà ìmoore tí ó kún fún ìfẹ́ fún Ọlọrun tí a gbékarí ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ rẹ̀. A lè sìn ín ní òtítọ́ nípa kíkọ àwọn èké ìsìn sílẹ̀ àti ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun, bí a ṣe ṣí i payá nínú Ìwé-Ẹ̀kọ́ ńlá ti Jehofa.
Ó Ṣẹ́gun Àwọn Àdánwò àti Ayé
17. Báwo ni o ṣe lè fi ẹ̀rí hàn pé ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ti ran àwọn ìránṣẹ́ Jehofa lọ́wọ́ láti dojúkọ àwọn àdánwò?
17 Nígbà tí àwọn ènìyàn Ọlọrun bá dojúkọ àwọn àdánwò, ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ń ṣẹ́gun léraléra. Gbé èyí yẹ̀wò: Ní ìbẹ̀rẹ̀ Ogun Àgbáyé Kejì, ní September 1939, àwọn ìránṣẹ́ Jehofa nílò àkànṣe ìjìnlẹ̀-òye nínú Ìwé-Ẹ̀kọ́ ńlá rẹ̀. Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti November 1, 1939 (Gẹ̀ẹ́sì) tí ó gbé ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá kalẹ̀ kedere lórí ọ̀ràn àìdásítọ̀túntòsì Kristian jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà. (Johannu 17:16) Lọ́nà tí ó jọra, ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1960, àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà lórí ìtẹríba tí ó ní ààlà fún “àwọn aláṣẹ” ìjọba “tí ó wà ní ipò gíga” ran àwọn ènìyàn Ọlọrun lọ́wọ́ láti ṣègbọràn sí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá lójú rògbòdìyàn ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà.—Romu 13:1-7; Iṣe 5:29.
18. Ojú wo ni àwọn tí wọ́n jẹ́wọ́ jíjẹ́ Kristian ní àwọn ọ̀rúndún kejì àti ìkẹta C.E. fi wo eré-ìnàjú tí ń sọni dìbàjẹ́, ìrànlọ́wọ́ wo sì ni ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá pèsè nínú ọ̀ràn yẹn lónìí?
18 Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ìdẹwò, irú bí ìrélọ láti wá eré-ìnàjú tí ń sọni dìbàjẹ́. Ṣàkíyèsí ohun tí àwọn tí wọ́n jẹ́wọ́ jíjẹ́ Kristian ní ọ̀rúndún kejì àti ìkẹta nínú Sànmánì Tiwa sọ. Tertullian kọ̀wé pé: “Àwa kò ní ohunkóhun láti ṣe pẹ̀lú ìṣiwèrè ibi eré àṣedánilárayá, ìwà àìnítìjú gbọ̀ngàn-ìṣeré, ìwà-ẹhànnà ibi-ìṣeré, níti ọ̀rọ̀, ìran tàbí gbígbọ́.” Òǹkọ̀wé mìíràn ní àkókò yẹn béèrè pé: “Kí ni Kristian olùṣòtítọ́ kan ń ṣe láàárín àwọn nǹkan wọ̀nyí, níwọ̀n bí òun kò tilẹ̀ ti ní ronú nípa ìwà burúkú? Èéṣe tí ó fí ń wá adùn nínú ohun tí ó dúró fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́?” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òǹkọ̀wé wọ̀nyí gbé ayé ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-ín-ní, wọ́n yẹra fún àwọn ohun ìṣiré tí ń sọni dìbàjẹ́. Lónìí, ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ń fún wa ní ọgbọ́n láti kọ eré-ìnàjú tí kọ̀ tọ́, oníwà pálapàla, àti oníwà-ipá sílẹ̀.
19. Báwo ni ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun ayé?
19 Ṣíṣègbọràn sí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ń mú kí ó ṣeéṣe fún wa láti ṣẹ́gun ayé fúnraarẹ̀. Bẹ́ẹ̀ni, fífi ẹ̀kọ́ Atóbilọ́lá Olùkọ́ni wa sílò ń mú kí a ṣẹ́gun àwọn agbára ìdarí búburú ayé yìí tí ó wà lábẹ́ agbára Satani. (2 Korinti 4:4; 1 Johannu 5:19) Efesu 2:1-3 sọ pé Ọlọrun ti sọ wá di alààyè bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ òkú nínú ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ wa nígbà tí a rìn ní ìbámu pẹ̀lú alákòóso ọlá-àṣẹ afẹ́fẹ́. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa pé ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ìfẹ́-ọkàn ayé àti ẹ̀mí tí ń jáde wá láti ọ̀dọ̀ ọ̀tá rẹ̀ àti tiwa—olórí atannijẹ náà, Satani Eṣu!
20. Àwọn ìbéèrè wo ni wọ́n yẹ fún ìgbéyẹ̀wò síwájú síi?
20 Nígbà náà, ó ṣe kedere pé ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ń ṣẹ́gun ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Níti tòótọ́, yóò dàbí ohun tí kò ṣeéṣe láti mẹ́nukan gbogbo ìṣẹ́gun rẹ̀. Ó nípalórí gbogbo àwọn ènìyàn káàkiri ayé. Ṣùgbọ́n kí ni ó ń ṣe fún ọ? Báwo ni ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ṣe ń nípalórí ìgbésí-ayé rẹ?
Kí Ni O Ti Rí Kọ́?
◻ Báwo ni a ṣe lè túmọ̀ ọgbọ́n tòótọ́?
◻ Kí ni Ọlọrun ti ṣípayá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nípa Genesisi 3:15?
◻ Báwo ni ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ti ṣẹ́gun nínú àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí?
◻ Kí ni ó túmọ̀sí láti sin Ọlọrun ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́?
◻ Báwo ni ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ti ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ Jehofa lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn àdánwò àti ayé?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jesu di ìwàtítọ́ rẹ̀ mú títí dójú ikú—pípa Irú-Ọmọ náà ní gìgísẹ̀