Ǹjẹ́—“Bẹ́ẹ̀ Ni” Rẹ Kì Í Di “Bẹ́ẹ̀ Kọ́”?
Finú yàwòrán alàgbà kan tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn tó ṣètò láti bá ọ̀dọ́kùnrin kan ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí láàárọ̀ Sunday. Láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, alàgbà yìí gba ìpè kánjúkánjú látọ̀dọ̀ arákùnrin kan tí wọ́n gbé ìyàwó rẹ̀ lọ sí ilé ìwòsàn torí jàǹbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí i. Ó ní kí alàgbà náà bá òun wá dókítà kan tí kò ní lo ẹ̀jẹ̀ tó bá ń tọ́jú ìyàwó òun. Ni alàgbà náà bá sọ fún ọ̀dọ́kùnrin yẹn pé àwọn ò ní lè jọ jáde mọ́ kí òun lè rí àyè ran ìdílé tí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ṣẹlẹ̀ sí náà lọ́wọ́, torí pé wọ́n nílò òun gan-an.
Tún ronú lórí àpẹẹrẹ kejì yìí: Ká sọ pé tọkọtaya kan pe ìyá kan tó ń dá tọ́ ọmọbìnrin méjì nínú ìjọ wọn pé kí wọ́n wá báwọn ṣeré nílé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan. Nígbà tí ìyá yìí sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀, inú wọn dùn gan-an, wọ́n sì ń fayọ̀ retí ọjọ́ náà. Àmọ́ nígbà tó ku ọ̀la kí wọ́n lọ, tọkọtaya náà sọ fún wọn pé ohun kan tí àwọn ò rò tẹ́lẹ̀ wáyé torí náà àwọn ò ní lè gbà wọ́n lálejò mọ́. Lẹ́yìn yẹn ni ìyá àwọn ọmọ náà wá mọ ohun tó fà á tí tọkọtaya náà fi ní kí wọ́n má wulẹ̀ wá mọ́. Ó gbọ́ pé lẹ́yìn tí wọ́n ti ké sí òun àtàwọn ọmọ òun ni àwọn ọ̀rẹ́ wọn kan ní kí wọ́n wá kí àwọn ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan náà yẹn. Wọ́n sì gbà láti lọ.
Torí pé a jẹ́ Kristẹni, ó yẹ ká máa mú àdéhùn wa ṣẹ. Kò yẹ kí “Bẹ́ẹ̀ ni” wa máa di “Bẹ́ẹ̀ kọ́.” (2 Kọ́r. 1:18) Àwọn àpẹẹrẹ méjì tá a gbé yẹ̀ wò yìí fi hàn pé nǹkan kì í rí bákàn náà lọ́pọ̀ ìgbà. Àwọn ìgbà míì wà tó lè dà bíi pé kò sí ohun tá a lè ṣe ju pé ká yẹ àdéhùn tá a ti ṣe. Irú ẹ náà ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.
WỌ́N SỌ PÉ PỌ́Ọ̀LÙ Ò NÍ ÀDÉHÙN
Pọ́ọ̀lù wà ní ìlú Éfésù ní ọdún 55 Sànmánì Kristẹni, nígbà ìrìn àjò rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì. Ó ní in lọ́kàn láti sọdá Òkun Aegean lọ sí ìlú Kọ́ríńtì kó sì máa gba ibẹ̀ lọ sí ìlú Makedóníà. Ó ti pinnu pé tí òun bá ń pa dà lọ sí Jerúsálẹ́mù, òun tún máa fi ẹsẹ̀ kan yà wo àwọn ará tó wà ní ìlú Kọ́ríńtì kí òun lè gba ẹ̀bùn inú rere wọn dání fún àwọn ará tó wà ní Jerúsálẹ́mù. (1 Kọ́r. 16:3) Ó ṣe kedere látinú ohun tó wà nínú 2 Kọ́ríńtì 1:15, 16 pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn. Ó sọ pé: “Pẹ̀lú ìgbọ́kànlé yìí, mo ń pète-pèrò láti wá sọ́dọ̀ yín láìpẹ́, kí ẹ bàa lè ní àyè ẹ̀ẹ̀kejì fún ìdùnnú, àti lẹ́yìn títẹsẹ̀dúró díẹ̀ lọ́dọ̀ yín láti lọ sí Makedóníà, àti láti padà láti Makedóníà sọ́dọ̀ yín, kí ẹ sì sìn mí díẹ̀ lọ́nà Jùdíà.”
Ó jọ pé nínú lẹ́tà kan tí Pọ́ọ̀lù ti kọ sí àwọn ará ní Kọ́ríńtì tẹ́lẹ̀, ó ti mẹ́nu kan bó ṣe fẹ́ rin ìrìn àjò rẹ̀ fún wọn. (1 Kọ́r. 5:9) Ṣùgbọ́n kò pẹ́ lẹ́yìn tó kọ lẹ́tà yẹn ni agboolé Kílóè sọ fún un pé ìyapa ńláǹlà wà nínú ìjọ náà. (1 Kọ́r. 1:10, 11) Èyí ló mú kí Pọ́ọ̀lù tún èrò pa tó sì kọ lẹ́tà tá a wá mọ̀ sí Kọ́ríńtì Kìíní. Nínú lẹ́tà yẹn Pọ́ọ̀lù fi ìfẹ́ bá wọn wí, ó sì fún wọn ní ìmọ̀ràn tó yẹ. Ó tún sọ pé òun ti yí bí òun ṣe fẹ́ rin ìrìn àjò òun pa dà. Ó ní òun máa kọ́kọ́ lọ sí ìlú Makedóníà kí òun tó wá lọ sí ìlú Kọ́ríńtì.—1 Kọ́r. 16:5, 6.a
Ó jọ pé nígbà tí àwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì gba lẹ́tà Pọ́ọ̀lù, àwọn kan lára “àwọn àpọ́sítélì adárarégèé” tó wà nínú ìjọ náà fi ẹ̀sùn kàn án pé kò ní àdéhùn, torí pé kì í mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé ara rẹ̀, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Tóò, nígbà tí mo ní irúfẹ́ ìpètepèrò bẹ́ẹ̀, èmi kò fi ìwà àìfi-nǹkan-pè èyíkéyìí kẹ́ra, àbí mo ṣe bẹ́ẹ̀? Tàbí àwọn ohun tí mo pète, mo ha pète wọn lọ́nà ti ẹran ara, pé lọ́dọ̀ mi ni kí ó jẹ́ ‘Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ ni’ àti ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, Bẹ́ẹ̀ kọ́’?”—2 Kọ́r. 1:17; 11:5.
A wá lè béèrè pé, Pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ṣé òótọ́ ni pé “ìwà àìfi-nǹkan-pè” ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kẹ́ra lóòótọ́? Rárá o! Ọ̀rọ̀ tí a tú sí “àìfi-nǹkan-pè” tún lè túmọ̀ sí kéèyàn máà ní àdéhùn, bíi ká sọ pé èèyàn kan ò ṣeé gbára lé, pé kì í mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ìbéèrè mọ̀ọ́nú tí Pọ́ọ̀lù bi àwọn ará tó wà ní ìlú Kọ́ríńtì pé “àwọn ohun tí mo pète, mo ha pète wọn lọ́nà ti ẹran ara?” ti ní láti mú kó ṣe kedere sí wọn pé kì í ṣe torí pé Pọ́ọ̀lù ò ṣeé gbára lé ló ṣe yí ìpinnu rẹ̀ pa dà.
Pọ́ọ̀lù wá já àwọn tó fi ẹ̀sùn kàn án nírọ́ lọ́nà tó ṣe ṣàkó, ó ní: “Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣeé gbójú lé pé ọ̀rọ̀ wa tí a sọ fún yín kì í ṣe Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀ kí ó sì jẹ́ Bẹ́ẹ̀ kọ́.” (2 Kọ́r. 1:18) Ó dájú pé ire àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó wà ní ìjọ Kọ́ríńtì ló jẹ Pọ́ọ̀lù lógún tó fi yí ètò tó ti ṣe nípa bó ṣe fẹ́ rin ìrìn àjò rẹ̀ pa dà. A rí i kà nínú 2 Kọ́ríńtì 1:23 pé torí kó lè “dá” àwọn ará Kọ́ríńtì “sí” ni kò jẹ́ kó lọ síbẹ̀ mọ́ bó ṣe kọ́kọ́ pinnu láti ṣe. Kódà, ó mú kí wọ́n ní àǹfààní láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ kó tó di pé ó máa yọjú sí wọn. Bí ọ̀rọ̀ sì ṣe rí náà nìyẹn, torí nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní Makedóníà, Títù sọ fún un pé lẹ́tà rẹ̀ mú kí wọ́n ní ẹ̀dùn ọkàn, ó sì mú kí wọ́n ronú pìwà dà, ìyẹn sì mú kí inú Pọ́ọ̀lù dùn gan-an.—2 Kọ́r. 6:11; 7:5-7.
À Ń ṢE “ÀMÍN” SÍ ỌLỌ́RUN
Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Pọ́ọ̀lù pé kò ní àdéhùn tún lè túmọ̀ sí pé tí kò bá ṣeé gbára lé nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan, a jẹ́ pé ohun tó ń wàásù rẹ̀ kò ṣeé gbára lé nìyẹn. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù rán àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì létí pé òun ti wàásù nípa Jésù Kristi fún wọn. Ó sọ pé: “Ọmọ Ọlọ́run, Kristi Jésù, tí a wàásù rẹ̀ láàárín yín nípasẹ̀ wa, èyíinì ni, nípasẹ̀ èmi àti Sílífánù àti Tímótì, kò di Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀ kí ó sì jẹ́ Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n Bẹ́ẹ̀ ni ti di Bẹ́ẹ̀ ni nínú ọ̀ràn tirẹ̀.” (2 Kọ́r. 1:19) Ṣé Jésù Kristi, tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ fún Pọ́ọ̀lù ò wá ṣeé gbára lé ni? Rárá o! Ní gbogbo ìgbà tí Jésù fi wà láyé àti lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ òtítọ́ ló máa ń sọ. (Jòh. 14:6; 18:37) Tó bá jẹ́ pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ohun tí Jésù wàásù rẹ̀ tó sì ṣeé gbára lé, tó sì jẹ́ pé ohun tí Pọ́ọ̀lù wàásù rẹ̀ náà nìyẹn, a jẹ́ pé ohun tí àpọ́sítélì náà wàásù rẹ̀ ṣeé gbára lé.
Ó dájú pé Jèhófà ni “Ọlọ́run òtítọ́.” (Sm. 31:5) Èyí ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù tún sọ, ó ní: “Bí ó ti wù kí àwọn ìlérí Ọlọ́run pọ̀ tó, wọ́n ti di Bẹ́ẹ̀ ni nípasẹ̀ rẹ̀,” ìyẹn nípasẹ̀ Kristi. Bí Jésù ṣe jẹ́ olùṣòtítọ́ jálẹ̀ gbogbo àkókò tó lò lórí ilẹ̀ ayé mú kó ṣe kedere pé kò sí èyíkéyìí lára àwọn ìlérí Jèhófà tí kò ní ṣẹ. Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Nítorí náà nípasẹ̀ rẹ̀ [Jésù] pẹ̀lú ni a ń ṣe ‘Àmín’ sí Ọlọ́run fún ògo nípasẹ̀ wa.” (2 Kọ́r. 1:20) Jésù ni “Àmín” tàbí ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro tí Jèhófà Ọlọ́run fi mú kó dá wa lójú pé gbogbo ìlérí tí òun ṣe ló máa ṣẹ!
Bí Jèhófà àti Jésù ṣe máa ń sọ òtítọ́ nígbà gbogbo, òótọ́ ni Pọ́ọ̀lù náà máa ń sọ. (2 Kọ́r. 1:19) Pọ́ọ̀lù kì í ṣe ẹni tí kò ní àdéhùn, táá wulẹ̀ máa ṣe ìlérí “lọ́nà ti ẹran ara.” (2 Kọ́r. 1:17) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ‘rìn nípa ẹ̀mí.’ (Gál. 5:16) Ó máa ń jẹ́ kí ire àwọn ẹlòmíì jẹ òun lógún nínú ohun gbogbo tó bá ń ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni rẹ̀ sì máa ń jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni!
ǸJẸ́ BẸ́Ẹ̀ NI RẸ MÁA Ń JẸ́ BẸ́Ẹ̀ NI?
Àwọn kan wà lónìí tí wọn kì í tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ kì í sábàá mú ìlérí wọn ṣẹ bí ìṣòro kékeré kan bá yọjú tàbí tí wọ́n bá rí ohun míì tó wù wọ́n. Àwọn tó ń bára wọn ṣòwò pẹ̀lú kì í sábàá jẹ́ kí “bẹ́ẹ̀ ni” wọ́n jẹ́ “bẹ́ẹ̀ ni,” kódà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti jọ tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ò wo ìgbéyàwó, tó jẹ́ àdéhùn láàárín ẹni méjì, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ́ láti jọ wà títí ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí iye ìkọ̀sílẹ̀ ṣe ń pọ̀ sí i fi hàn pé, ńṣe ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń wo ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí àjọṣe kan lásán tí wọ́n kàn lè pa tì tó bá ti sú wọn.—2 Tím. 3:1, 2.
Ìwọ ńkọ́? Ṣé Bẹ́ẹ̀ ni rẹ máa ń jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni? Bá a ṣe rí i ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ó lè ṣẹlẹ̀ pé kó o wọ́gi lé àdéhùn kan torí pé àwọn ohun àìròtẹ́lẹ̀ kan wáyé, kó má sì jẹ́ nítorí pé o kì í pa àdéhùn mọ́. Ṣùgbọ́n, torí pé o jẹ́ Kristẹni, tó o bá ṣe ìlérí tàbí àdéhùn kan, rí i pé o ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kó o lè pa àdéhùn náà mọ́. (Sm. 15:4; Mát. 5:37) Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn á mọ̀ ẹ́ sí ẹni tó ṣeé fọkàn tán, ẹni tó ń pa àdéhùn mọ́, tó sì máa ń sọ òótọ́ ní gbogbo ìgbà. (Éfé. 4:15, 25; Ják. 5:12) Bí àwọn èèyàn bá mọ̀ pé àwọn lè fi ọkàn tán ẹ nínú ohunkóhun, wọ́n máa túbọ̀ fẹ́ láti fetí sí ẹ tó o bá ń wàásù òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún wọn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa rí i dájú pé Bẹ́ẹ̀ ni wa ń jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni!
a Kò pẹ́ púpọ̀ tí Pọ́ọ̀lù kọ ìwé Kọ́ríńtì Kìíní tó fi gba Tíróásì lọ sí Makedóníà, ibẹ̀ ló sì ti kọ ìwé Kọ́ríńtì Kejì. (2 Kọ́r. 2:12; 7:5) Lẹ́yìn ìgbà yẹn ló wá lọ sí ìlú Kọ́ríńtì.