KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí O Máa Gbàdúrà?
Ó ṣeé ṣe kí o ti bi ara rẹ pé: ‘Tó bá jẹ́ pé ohun gbogbo ni Ọlọ́run mọ̀, títí kan ohun tí mò ń rò àti ohun tí mo nílò, ṣé ó yẹ kí n tún máa gbàdúrà?’ Ìbéèrè yẹn mọ́gbọ́n dání lóòótọ́. Ó ṣe tán, Jésù sọ pé Ọlọ́run “mọ àwọn ohun tí ẹ ṣe aláìní kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ rárá.” (Mátíù 6:8) Dáfídì Ọba sì ti ọ̀rọ̀ yẹn lẹ́yìn nígbà tó sọ pé: “Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi, Ṣùgbọ́n, wò ó! Jèhófà, ìwọ ti mọ gbogbo rẹ̀ tẹ́lẹ̀!” (Sáàmù 139:4) Tí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, Kí nìdí tí a fi gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí Ọlọ́run? Ìdáhùn yẹn wà nínú ohun tí Bíbélì sọ nípa àdúrà tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbà.a
“Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8
ÀDÚRÀ Ń MÚ KÁ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN
Lóòótọ́ Bíbélì sọ pé ohun gbogbo ni Jèhófàb mọ̀, ó tún fi hàn pé kì í ṣe pé Ọlọ́run kàn fẹ́ gbọ́ ohun tí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ fẹ́ sọ lásán. (Sáàmù 139:6; Róòmù 11:33) Agbára ìrántí Ọlọ́run yàtọ̀ pátápátá sí ti kọ̀ǹpútà tó kàn máa ń kó ìsọfúnni jọ lásán. Èrò inú wa lọ́hùn-ún ni Ọlọ́run máa ń fẹ́ mọ̀, nítorí pé ó fẹ́ ká sún mọ́ òun. (Sáàmù 139:23, 24; Jákọ́bù 4:8) Èyí ló mú kí Jésù rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà bó tiẹ̀ jẹ́ pé baba wọn ọ̀run ti mọ àwọn ohun tí wọ́n nílò. (Mátíù 6:6-8) Bí a bá ṣe ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún Ẹlẹ́dàá wa tó, bẹ́ẹ̀ náà la ò ṣe sún mọ́ ọn tó.
Nígbà míì, ó lè ṣòro fún wa láti mọ ohun tí a máa sọ nínú àdúrà. Ní irú àkókò bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run mọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa tí a ò le ṣàlàyé, á sì lo agbára tó ní láti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ipò wa, kó lè dáhùn àdúrà wa. (Róòmù 8:26, 27; Éfésù 3:20) Tí àwa náà bá rí ọwọ́ Ọlọ́run láyé wa, kódà lọ́nà tí a kò tiẹ̀ retí tẹ́lẹ̀, ó máa wù wá pé ká túbọ̀ sún mọ́ ọn.
ǸJẸ́ GBOGBO ÀDÚRÀ NI ỌLỌ́RUN Ń GBỌ́?
Bíbélì fi dá wa lójú pé Ọlọ́run Olódùmarè máa ń dáhùn àdúrà àwọn olóòótọ́, ṣùgbọ́n ó nídìí tí kì í fí dáhùn àwọn àdúrà kan. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìwà ipá gbòde kan nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, Ọlọ́run ní kí wòlíì Aísáyà sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Bí ẹ tilẹ̀ gba àdúrà púpọ̀, èmi kò ní fetí sílẹ̀; àní ọwọ́ yín kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.” (Aísáyà 1:15) Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run kì í gbọ́ àdúrà àwọn tó bá ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí òfin rẹ̀ tàbí tó ń gbàdúrà fún nǹkan tí kò tọ́.—Òwe 28:9; Jákọ́bù 4:3.
Tí a bá tún wò ó lọ́nà míì, Bíbélì sọ pé: “Ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.” (1 Jòhánù 5:14) Ṣé ohun tí à ń sọ ni pé gbogbo ohun tí a bá ṣáà ti béèrè ni Ọlọ́run máa ṣe? Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ o. Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò. Ìgbà mẹ́ta ló bẹ Ọlọ́run pé kí ó mú ‘ẹ̀gún kan nínú ẹran ara rẹ̀’ kúrò. (2 Kọ́ríńtì 12:7, 8) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àìsàn ojú ló ń da Pọ́ọ̀lù láàmú, kó sì jẹ́ èyí tí kì í lọ bọ̀rọ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Pọ́ọ̀lù ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, ó tún jí òkú dìde. Síbẹ̀, Ọlọ́run ò fún Pọ́ọ̀lù lágbára tó lè fi mú àìsàn ti ara rẹ̀ kúrò. Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ yẹn á ṣe ká a lára tó! (Ìṣe 19:11, 12; 20:9, 10) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe bí Pọ́ọ̀lù ṣe fẹ́ kí Ọlọ́run dáhùn àdúrà rẹ̀ ni ó gbà dáhùn rẹ̀, síbẹ̀ ó fara mọ́ ìrànlọ́wọ́ tí Ọlọ́run ṣe fún un.—2 Kọ́ríńtì 12:9, 10.
“Èyí sì ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí i, pé, ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.”—1 Jòhánù 5:14
Òótọ́ ni pé Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn tí Ọlọ́run dáhùn àdúrà wọn lọ́nà ìyanu. (2 Àwọn Ọba 20:1-7) Àmọ́ irú ẹ̀ kò wọ́pọ̀ láyé ìgbà yẹn. Kódà, ó tiẹ̀ sú púpọ̀ nínú wọn nígbà tí ó dà bíi pé Ọlọ́run kò tètè dáhùn àdúrà wọn. Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì Ọba bi Ọlọ́run pé: “Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí ìwọ yóò fi gbàgbé mi? Ṣé títí láé ni?” (Sáàmù 13:1) Ṣùgbọ́n nígbà tí Dáfídì ronú lórí bí Jèhófà ṣe máa ń gba òun sílẹ̀ ní onírúurú ọ̀nà, ìgbọ́kànlé tó ní nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i. Ní àkókò yẹn kan náà, Dáfídì sọ pé: “Ní tèmi, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.” (Sáàmù 13:5) Ọ̀rọ̀ lè rí bákan náà fún àwọn olùjọ́sìn Ọlọ́run lónìí. Nígbà míì, ó lè gba pé kí wọ́n túbọ̀ tẹra mọ́ àdúrà títí tí Ọlọ́run á fi dá wọn lóhùn.—Róòmù 12:12.
BÍ ỌLỌ́RUN ṢE Ń DÁHÙN ÀDÚRÀ WA
Ọlọ́run máa ń pèsè àwọn nǹkan tá a nílò.
Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ máa ń fún àwọn ọmọ wọn ní ohun tí wọ́n bá béèrè lásìkò tí wọ́n béèrè rẹ̀. Bákan náà, ó lè máà jẹ́ bí a ṣe rò ni Ọlọ́run á ṣe dáhùn àdúrà wa, ó tiẹ̀ lè máà jẹ́ ìgbà tá a retí ló máa dáhùn àdúrà náà. Àmọ́, ó dájú pé bàbá wa ọ̀run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa nífẹ̀ẹ́ wa, kì í já wa kulẹ̀, ó sì máa ń pèsè àwọn ohun tá a nílò nígbà tó yẹ àti lọ́nà tó tọ́.—Lúùkù 11:11-13.
Ọlọ́run lè dáhùn àdúrà wa lọ́nà tí a kò fọkàn sí.
Ká sọ pé ó ti pẹ́ tí a ti ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run yanjú ìṣòro kan tó ń bá wa fínra, àmọ́ tí a kò tíì rí ojútùú sí i, kí la máa ṣe? Ṣé nítorí a ò tíì rí ìdáhùn ní kíákíá, àá kàn gbà pé Jèhófà kò tíì dáhùn àdúrà wa? Dípò ká ronú bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká ronú pé ó ṣeé ṣe kí Ọlọ́run ti ràn wá lọ́wọ́ ní àwọn ọ̀nà míì tí a lè máà fọkàn sí. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rẹ́ wa kan lè ràn wá lọ́wọ́ lákòókò tí a nílò rẹ̀ gan-an. (Òwe 17:17) Tí a bá sì wò ó dáádáá, ó lè jẹ́ pé Jèhófà ni ó lo ẹni yẹn láti ràn wá lọ́wọ́. Ìgbà míì sì rèé, ó lè jẹ́ ohun tá a kà nínú Bíbélì ni Ọlọ́run máa lò láti ràn wá lọ́wọ́. Ọgbọ́n tá a bá rí kọ́ nínú Bíbélì lè gbé wa ró ká bàa lè fara da ìṣòro náà.—2 Tímótì 3:16, 17.
Lọ́pọ̀ ìgbà, Ọlọ́run lè máà mú ìṣòro kan kúrò, àmọ́ ńṣe ló máa ń fún wa lágbára láti fara da ìṣòro náà. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù ní ìṣòro kan, tó sì rò pé ìṣòro náà lè mú kí òun bọ́hùn, ó bẹ Baba rẹ̀ pé kó mú un kúrò, ńṣe ni Jèhófà rán áńgẹ́lì kan sí Ọmọ rẹ̀, kó lè fún un lókun. (Lúùkù 22:42, 43) Bákan náà, Ọlọ́run lè lo ọ̀rẹ́ wa kan láti fún wa níṣìírí lákòókò tá a nílò rẹ̀ gan-an. (Òwe 12:25) Nítorí pé irú àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dáhùn yìí kì í ṣe ibi tá a fọkàn sí tẹ́lẹ̀, ó yẹ ká túbọ̀ ronú jinlẹ̀ ká lè mọ ìgbà tí Ọlọ́run bá dáhùn àdúrà wa.
Tí kò bá tíì tó àkókò lójú Ọlọ́run, kì í dáhùn àwọn àdúrà kan.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run Olódùmarè máa ṣojúure sí àwọn onírẹ̀lẹ̀ “ní àkókò yíyẹ.” (1 Pétérù 5:6) Torí náà, tó bá ń ṣe wá bíi pé Ọlọ́run ń pẹ́ kó tó dáhùn àdúrà wa, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ó ti ta wá nù tàbí pé kò rí tiwa rò. Kàkà bẹ́ẹ̀, torí pé ọgbọ́n rẹ̀ ga ju tiwa lọ, Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ máa ń yẹ̀ wá wò dáadáa, ó sì mọ ohun tó dáa jù fún wa àti àkókò tó dáa jù láti ṣe ohun tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
“Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, kí ó lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ.”—1 Pétérù 5:6
Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ọmọkùnrin rẹ ní kí o ra kẹ̀kẹ́ fún òun, ṣé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wàá ra kẹ̀kẹ́ náà fún un? Ó lè máà tíì dàgbà tó ẹni tó lè gun kẹ̀kẹ́ náà dáadáa. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wàá dúró títí tó máa fi dàgbà tó láti gun kẹ̀kẹ́ kí ó tó rà á fún un. Bákan náà, tí a kò bá dákẹ́ àdúrà, lákòókò tó yẹ, Ọlọ́run yóò dáhùn àwọn ohun ‘tí ó ti inú ọkàn wa wá.’—Sáàmù 37:4.
JẸ́ KÓ DÁ Ẹ LÓJÚ PÉ JÈHÓFÀ Ń GBỌ́ ÀDÚRÀ RẸ
Bíbélì rọ gbogbo Kristẹni tòótọ́ pé ká má ṣe dákẹ́ àdúrà. Ṣùgbọ́n àwọn míì lè sọ pé: ‘Ọ̀rọ̀ yẹn dùn-ún sọ, àmọ́ kò rọrùn láti ṣe.’ Ká sòótọ́, tí ẹnì kan bá rẹ́ wa jẹ, tó sì mú un jẹ tàbí tí a ń fara da ìṣòro kan tí kì í lọ bọ̀rọ̀, ó lè ṣòro láti mú sùúrù títí dìgbà tí Ọlọ́run á fi bá wa yanjú rẹ̀. Tí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, rántí ohun tí Jésù sọ nípa ìdí tí kò fi yẹ ká dáwọ́ àdúrà dúró.
Jésù ṣe àkàwé nípa obìnrin opó tó máa ń lọ bá onídàájọ́ kan tí kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, kó lè rí i pé ó rí ìdájọ́ òdodo gbà. (Lúùkù 18:1-3) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé onídàájọ́ yẹn kọ́kọ́ yarí fún obìnrin náà, ó sọ nígbẹ̀yìn pé: ‘Èmi yóò ríi pé obìnrin yìí rí ìdájọ́ òdodo gbà, kí ó má bàa pin mí lẹ́mìí dé òpin.’ (Lúùkù 18:4, 5) Ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n lò fún ohun tí adájọ́ yìí sọ jẹ́ kí àlàyé yìí túbọ̀ ṣe kedere. Adájọ́ yìí ṣe ohun tí opó náà ń fẹ́ fún un, kí opó náà má bàa “gbá a ní ìsàlẹ̀ ojú [rẹ̀],” tàbí lédè míì kí ó má bàa “bà á lórúkọ jẹ́.”c Tí adájọ́ tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí kò sì bẹ̀rù èèyàn bá lè yí ìpinnu rẹ̀ pa dà nítorí kí orúkọ rẹ̀ má bàa bà jẹ́, ó dájú pé Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ yóò mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ “tí ń ké jáde sí i tọ̀sán-tòru”! Jésù sọ pé Ọlọ́run “yóò mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún wọn pẹ̀lú ìyára kánkán.”—Lúùkù 18:6-8.
“Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín.”—Lúùkù 11:9
Nígbà míì, ó lè sú wa láti máa béèrè fún ojúure tàbí ìrànlọ́wọ́, síbẹ̀ a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa. Tá a bá tẹra mọ́ àdúrà, ńṣe là ń fi hàn pé tọkàntọkàn la ń fẹ́ kí Ọlọ́run lọ́wọ́ sí ìgbésí ayé wa. Ó yẹ ká máa ronú lórí àwọn ọ̀nà tó ṣeé ṣe kí Ọlọ́run gbà dáhùn àdúrà wa, ká lè túbọ̀ sún mọ́ ọn. Paríparí rẹ̀, jẹ́ kí ọkàn rẹ balẹ̀ pé tí o bá ń béèrè ohun tí o tọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí o sì ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run á gbọ́ tìẹ, ó dájú pé Ọlọ́run á dáhùn àdúrà tó o fi tọkàntọkàn gbà sí i.—Lúùkù 11:9.
a Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ sapá láti máa fi òótọ́ inú ṣe àwọn ohun tó fẹ́. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan la tó lè rí agbára àdúrà ní ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bí a ṣe máa jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka orí 17 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. Ó tún lè lọ wo ìkànnì wa, ìyẹn www.jw.org/yo.
b Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.
c Ní ayé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, Ọlọ́run retí pé kí àwọn onídàájọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì fojúure àrà ọ̀tọ̀ hàn sí àwọn opó àti àwọn ọmọ aláìní baba.—Diutarónómì 1:16, 17; 24:17; Sáàmù 68:5.