Jèhófà Ń fi “Ẹ̀mí Mímọ́ Fún Àwọn Tí Ń béèrè Lọ́wọ́ Rẹ̀”
“Bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”—LÚÙKÙ 11:13.
1. Ìgbà wo la nílò ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ jù?
Ọ̀PỌ̀ Kristẹni ló ti sọ ẹ̀dùn ọkàn wọn jáde báyìí pé, ‘Ìṣòro yìí kọjá agbára mi. Àfi ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run nìkan ló lè ràn mí lọ́wọ́ tí màá fi lè fàyà rán an!’ Ǹjẹ́ ìwọ náà ti sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ rí? Ó ṣeé ṣe kéèyàn sọ irú ọ̀rọ̀ yẹn tí wọ́n bá sọ fún un pé ó ti kó àrùn burúkú kan tàbí nígbà tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ tí wọ́n ti jọ wà tipẹ́ ṣaláìsí. Tàbí kẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o sọ bẹ́ẹ̀ nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan sọ ọ́ dẹni tí ìbànújẹ́ sórí ẹ̀ kodò. Láwọn àkókò tí nǹkan le fún ọ gan-an, ó ṣeé ṣe kó o gbà pé ohun kan ṣoṣo tó mú kó o lè fàyà rán an ni ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà tó fún ọ ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.”—2 Kọ́ríńtì 4:7-9; Sáàmù 40:1, 2.
2. (a) Àwọn ìṣòro wo ló ń bá àwọn Kristẹni tòótọ́ fínra? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Nínú ayé èṣù tá a wà yìí, àwọn Kristẹni tòótọ́ ò yéé kojú pákáǹleke àti àtakò tó ń pọ̀ sí i. (1 Jòhánù 5:19) Yàtọ̀ síyẹn, Sátánì Èṣù alára ò fi wọ́n lọ́rùn sílẹ̀, ńṣe ló ń gbógun ti àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi wọ̀nyí, ìyẹn “àwọn ẹni tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣípayá 12:12, 17) Ẹ lè wá rí ìdí tá a fi nílò ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Kí la lè ṣe láti rí i dájú pé à ń rí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà lọ́pọ̀ yanturu nígbà gbogbo? Kí ló sì lè mú kó dá wá lójú pé Jèhófà ṣe tán lọ́jọ́kọ́jọ́ láti fún wa lókun lákòókò ìṣòro? Àpèjúwe méjì kan tí Jésù sọ yóò jẹ́ ká rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
Tẹpẹlẹ Mọ́ Àdúrà Gbígbà
3, 4. Àpèjúwe wo ni Jésù sọ, ẹ̀kọ́ wo ló sì sọ pé a lè rí kọ́ látinú àpèjúwe náà tó bá kan ọ̀rọ̀ àdúrà gbígbà?
3 Lọ́jọ́ kan, ọmọ ẹ̀yìn Jésù kan sọ fún un pé: “Olúwa, kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà.” (Lúùkù 11:1) Nígbà tí Jésù máa dáhùn, ó sọ àpèjúwe méjì kan tó jọra wọn fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Àkọ́kọ́ dá lórí ọkùnrin kan tó ní àlejò, èkejì sì dá lórí bàbá kan tó fún ọmọ rẹ̀ lóhun tó béèrè. Ẹ jẹ́ ká gbé àpèjúwe méjì yìí yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.
4 Jésù sọ pé: “Ta ni nínú yín tí yóò ní ọ̀rẹ́ kan, tí yóò sì lọ bá a ní ọ̀gànjọ́ òru, tí yóò sì wí fún un pé, ‘Ọ̀rẹ́, yá mi ní ìṣù búrẹ́dì mẹ́ta, nítorí pé ọ̀rẹ́ mi kan ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sọ́dọ̀ mi láti ìrìn àjò, èmi kò sì ní nǹkan kan láti gbé ka iwájú rẹ̀’? Tí ẹni yẹn láti inú ilé sì sọ ní ìfèsìpadà pé, ‘Yé dà mí láàmú. Ilẹ̀kùn ti wà ní títì pa, àwọn ọmọ mi kéékèèké sì wà pẹ̀lú mi lórí ibùsùn; èmi kò lè dìde kí n sì fún ọ ní ohunkóhun.’ Mo sọ fún yín, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì yóò dìde, kí ó sì fún un ní ohunkóhun nítorí pé ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, dájúdájú, nítorí ìtẹpẹlẹ rẹ̀ aláìṣojo, yóò dìde, yóò sì fún un ní àwọn ohun tí ó nílò.” Lẹ́yìn tí Jésù sọ àpèjúwe yìí, ó wá sọ ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ látinú rẹ̀ tó bá kan ọ̀rọ̀ àdúrà gbígbà, ó ní: “Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, mo wí fún yín, Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín. Nítorí pé olúkúlùkù ẹni tí ń béèrè ń rí gbà, àti olúkúlùkù ẹni tí ń wá kiri ń rí, olúkúlùkù ẹni tí ó sì ń kànkùn ni a óò ṣí i fún.”—Lúùkù 11:5-10.
5. Kí ni àpèjúwe tó dá lórí ọkùnrin tó tẹpẹlẹ mọ́ bíbéèrè ohun tó ń fẹ́ kọ́ wa nípa irú ẹ̀mí tó yẹ ká ní tá a bá ń gbàdúrà?
5 Àpèjúwe tó ṣe kedere tí Jésù sọ nípa ọkùnrin tó tẹpẹlẹ mọ́ bíbéèrè ohun tó ń fẹ́ yìí jẹ́ ká mọ irú ẹ̀mí tó yẹ káwa náà ní tá a bá ń gbàdúrà. Kíyè sí i pé Jésù sọ pé ọkùnrin náà rí ohun tó ń béèrè gbà “nítorí ìtẹpẹlẹ rẹ̀ aláìṣojo.” (Lúùkù 11:8) Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré ni Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà ‘ìtẹpẹlẹ aláìṣojo.’ Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí jẹ yọ látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tí ìtumọ̀ olówuuru rẹ̀ jẹ́ “àìnítìjú.” Ìwà tí kò dára ni ọ̀rọ̀ náà àìnítìjú sábà máa ń tọ́ka sí. Àmọ́, tó bá jẹ́ lórí ohun tó dára lẹ́nì kan ò ṣe tijú tàbí tó fi ń tẹpẹlẹ mọ́ nǹkan, ohun tó dára nìyẹn. Bí ọ̀rọ̀ ọkùnrin tó lálejò nínú àpèjúwe Jésù sì ṣe rí nìyẹn. Kò tijú rárá láti tẹpẹlẹ mọ́ bíbéèrè ohun tó ń fẹ́. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ńṣe ni Jésù sọ àpèjúwe yìí ká lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú rẹ̀, ńṣe ló yẹ káwa náà máa tẹpẹlẹ mọ́ àdúrà gbígbà. Àní, Jèhófà fẹ́ ‘ká máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, ká máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ká máa bá a nìṣó ní kíkànkùn.’ Jèhófà ò sì ní ṣàì dáhùn, yóò “fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”
6. Nígbà ayé Jésù, irú ọwọ́ wo làwọn èèyàn fi mú ọ̀rọ̀ àlejò ṣíṣe?
6 Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ńṣe ló yẹ ká máa fi àìṣojo tẹpẹlẹ mọ́ àdúrà gbígbà. Àmọ́ yàtọ̀ síyẹn, ó tún jẹ́ ká mọ ìdí tó fi yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. Kí kókó yìí lè yé wa dáadáa, ẹ jẹ́ ká wo irú ọwọ́ táwọn tó gbọ́ àpèjúwe Jésù nípa ọkùnrin tó tẹpẹlẹ mọ́ bíbéèrè ohun tó ń fẹ́ yìí fi mú ọ̀rọ̀ àlejò ṣíṣe. Ọ̀pọ̀ ìtàn tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ló fi hàn pé láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ́ Bíbélì, àwọn èèyàn fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ àlejò ṣíṣe, pàápàá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 18:2-5; Hébérù 13:2) Nǹkan ìtìjú gbáà ló jẹ́ tí àlejò bá dé sọ́dọ̀ ẹnì kan tí onítọ̀hún ò sì ṣe é lálejò. (Lúùkù 7:36-38, 44-46) Ẹ jẹ́ ká fi kókó yẹn sọ́kàn bá a ṣe fẹ́ padà sórí àpèjúwe Jésù.
7. Kí nìdí tójú ò fi ti ẹni tó gbàlejò nínú àpèjúwe tí Jésù sọ yìí láti jí ọ̀rẹ́ ẹ̀ lójú oorun?
7 Ọ̀gànjọ́ òru ni àlejò dé sílé ọkùnrin tí Jésù mẹ́nu kàn nínú àpèjúwe yìí. Ọkùnrin náà rí i pé òun gbọ́dọ̀ pèsè oúnjẹ fún àlejò òun, àmọ́ kò ní “nǹkan kan láti gbé ka iwájú rẹ̀.” Ó wò ó pé àlejò pàjáwìrì mà rèé! Ó wá di pé kó ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti rí i pé òun fún àlejò òun ní oúnjẹ jẹ. Bó ṣe gbọ̀nà ilé ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ nìyẹn, kò sì tijú rárá láti jí i lójú oorun. Ó ní: “Ọ̀rẹ́, yá mi ní ìṣù búrẹ́dì mẹ́ta.” Ó bẹ ọ̀rẹ́ ẹ̀ títí tíyẹn fi fún un lóhun tó ń béèrè. Ìgbà tó rí búrẹ́dì mú lọ sílé ló tó lè ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó gbàlejò.
Bí NǹKan Bá Ṣe Ṣe Pàtàkì Sí La Ṣe Ń Béèrè fún Un
8. Kí ni yóò jẹ́ ká lè tẹpẹlẹ mọ́ gbígbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́?
8 Kí ni àpèjúwe yìí fi hàn nípa ìdí tó fi yẹ ká tẹpẹlẹ mọ́ àdúrà gbígbà? Ọkùnrin náà ò yéé bẹ ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé kó fóun ní búrẹ́dì nítorí ó mọ̀ pé kóun tó lè ṣe ojúṣe òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tó gbàlejò, òun gbọ́dọ̀ ní búrẹ́dì. (Aísáyà 58:5-7) Láìsí búrẹ́dì, kò ní lè ṣe ojúṣe rẹ̀ dáadáa. Àwa Kristẹni tòótọ́ náà mọ̀ pé láti lè máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe pàtàkì ó ṣe kókó, ìdí nìyẹn tá ò yéé gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Sekaráyà 4:6) Láìsí ẹ̀mí mímọ́, a ò ní lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (Mátíù 26:41) Ǹjẹ́ o rí ẹ̀kọ́ pàtàkì tá a lè rí kọ́ látinú àpèjúwe yìí? Tá a bá wo ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ohun kòṣeémáàní, a óò máa tẹpẹlẹ mọ́ bíbéèrè fún un.
9, 10. (a) Sọ àpèjúwe kan láti jẹ́ ká mọ ìdí tó fi yẹ ká tẹpẹlẹ mọ́ gbígbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. (b) Ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa, kí sì nìdí?
9 Ẹ jẹ́ ká lo àpèjúwe ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní láti fi gbé ẹ̀kọ́ yẹn yọ. Ká sọ pé àìsàn dédé kọ lu ẹnì kan nínú ìdílé rẹ láàjìn òru. Ǹjẹ́ o ò ní wá dókítà lọ kó lè ràn ọ́ lọ́wọ́? Tí àìsàn ọ̀hún kò bá le jù, o lè má ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ńṣe lonítọ̀hún dá kú, ó dájú pé o ò ní tijú láti jí dókítà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀ràn pàjáwìrì tó la ẹ̀mí lọ ni. O rí i pé o gbọ́dọ̀ jí dókítà lóru yẹn kó lè bá ẹ tọ́jú rẹ̀. Tí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹni náà lè kú. Lọ́nà kan náà, àwa Kristẹni tòótọ́ wà nínú ipò pàjáwìrì kan. Sátánì ń lọ káàkiri bíi “kìnnìún tí ń ké ramúramù,” ó ń wá ọ̀nà láti pa wá jẹ. (1 Pétérù 5:8) Tá ò bá sì fẹ́ kú nípa tẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Tá ò bá béèrè fún un, ohun tó léwu gan-an là ń ṣe yẹn. Nítorí náà, ó yẹ ká máa fi àìṣojo tẹpẹlẹ mọ́ gbígbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Éfésù 3:14-16) Tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ yìí nìkan la ó fi lè ní okun tá a fi máa “fara dà á dé òpin.”—Mátíù 10:22; 24:13.
10 Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká jókòó nígbà míì ká bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ mo máa ń tẹpẹlẹ mọ́ àdúrà gbígbà?’ Rántí pé, tá a bá mọ̀ dájú pé kò sóhun tá a lè ṣe láìsí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, a ò ní yéé gbàdúrà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.
Kí Ló Ń Mú Ká Fi Ìdánilójú Gbàdúrà?
11. Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù sọ pé a lè rí kọ́ látinú àpèjúwe bàbá kan àti ọmọ rẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ àdúrà gbígbà?
11 Àpèjúwe tí Jésù sọ nípa ọkùnrin tó tẹpẹlẹ mọ́ bíbéèrè nǹkan lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ jẹ́ ká mọ irú ẹ̀mí tí ẹni tó ń gbàdúrà, ìyẹn ẹni tó ní ìgbàgbọ́, ní. Àpèjúwe kejì sì jẹ́ ká mọ ìṣarasíhùwà olùgbọ́ àdúrà, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. Jésù béèrè pé: “Ní tòótọ́, baba wo ní ń bẹ láàárín yín tí ó jẹ́ pé, bí ọmọ rẹ̀ bá béèrè ẹja, bóyá tí yóò fi ejò lé e lọ́wọ́ dípò ẹja? Tàbí bí ó bá tún béèrè ẹyin, tí yóò fi àkekèé lé e lọ́wọ́?” Jésù wá sọ ẹ̀kọ́ tó wà nínú àpèjúwe yẹn, ó ní: “Nígbà náà, bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”—Lúùkù 11:11-13.
12. Báwo ni àpèjúwe bàbá tó fún ọmọ rẹ̀ lóhun tó béèrè ṣe fi hàn pé Jèhófà múra tán láti dáhùn àdúrà wa?
12 Jésù lo àpèjúwe bàbá tó fún ọmọ rẹ̀ lóhun tó béèrè láti jẹ́ ká mọ ìṣarasíhùwà Jèhófà sí àwọn tó ń gbàdúrà sí i. (Lúùkù 10:22) Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wo ìyàtọ̀ tó wà láàárín àpèjúwe méjèèjì. Ọkùnrin tí Jésù mẹ́nu kàn nínú àpèjúwe àkọ́kọ́ ò ṣe tán láti dá ọ̀rẹ́ rẹ̀ lóhun, àmọ́ Jèhófà kì í ṣe irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ńṣe ni Jèhófà dà bí bàbá tó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀, tó sì ṣe tán láti fún ọmọ rẹ̀ lóhun tó bá béèrè. (Sáàmù 50:15) Jésù tún sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín bàbá orí ilẹ̀ ayé àti Bàbá wa ọ̀run láti jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe múra tán láti ṣe ohun tá a bá béèrè fún wa. Jésù sọ pé bí bàbá kan, bó tilẹ̀ jẹ́ “ẹni burúkú” nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá, bá lè fi ẹ̀bùn rere fún ọmọ rẹ̀, mélòómélòó ni Bàbá wa ọ̀run tó jẹ́ ọ̀làwọ́. Ó yẹ kó dá wá lójú pé yóò fún àwọn tó ń sìn ín ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀!—Jákọ́bù 1:17.
13. Nígbà tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà, kí ló yẹ kó dá wa lójú?
13 Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa? Kí ó dá wa lójú pé tá a bá gbàdúrà sí Bàbá wa ọ̀run pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́, yóò dáhùn àdúrà wa. (1 Jòhánù 5:14) Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà láìdábọ̀, kò ní sọ fún wa pé: “Yé dà mí láàmú. Ilẹ̀kùn ti wà ní títì pa.” (Lúùkù 11:7) Dípò ìyẹn, Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín.” (Lúùkù 11:9, 10) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà “yóò dá wa lóhùn ní ọjọ́ tí a bá pè é.”—Sáàmù 20:9; 145:18.
14. (a) Èrò tí kò tọ̀nà wo làwọn kan máa ń rò tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro? (b) Nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro, kí nìdí tá a fi lè fi ìdánilójú gbàdúrà sí Jèhófà?
14 Àpèjúwe nípa bàbá tó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ tún fi hàn pé ohun rere tí Jèhófà ń fún wa ju èyí tí bàbá èyíkéyìí lè fun ọmọ rẹ̀ lọ fíìfíì. Nítorí náà, nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro, ká má ṣe rò pé torí pé Ọlọ́run ń bínú sí wa la ṣe wà nínú ìṣòro. Sátánì tí í ṣe olórí ọ̀tá wa ló fẹ́ ká ní irú èrò bẹ́ẹ̀. (Jóòbù 4:1, 7, 8; Jòhánù 8:44) Kò sí ohunkóhun nínú Bíbélì tó lè mú ká ní irú èrò òdì yẹn. Jèhófà kì í fi “àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi” dán wa wò. (Jákọ́bù 1:13) Jèhófà ò ní gbé ìṣòro tàbí àdánwò lé wa lọ́wọ́ bí ìgbà téèyàn gbé ejò tàbí àkekèé léni lọ́wọ́. Ńṣe ni Bàbá wa ọ̀run máa ń fi “àwọn ohun rere fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Mátíù 7:11; Lúùkù 11:13) Tá a bá lóye bí Jèhófà ṣe jẹ́ onínúure tó tá a sì mọ̀ pé ó ṣe tán lọ́jọ́kọ́jọ́ láti ràn wá lọ́wọ́, a óò túbọ̀ máa fi ìdánilójú gbàdúrà sí i. Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ó lè sọ irú ọ̀rọ̀ tí onísáàmù kan sọ pé: “Lóòótọ́, Ọlọ́run ti gbọ́; ó ti fetí sí ohùn àdúrà mi.”—Sáàmù 10:17; 66:19.
Bí Ẹ̀mí Mímọ́ Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́
15. (a) Ìlérí wo ni Jésù ṣe nípa ẹ̀mí mímọ́? (b) Kí ni ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí ẹ̀mí mímọ́ gbà ń ràn wá lọ́wọ́?
15 Kété ṣáájú kí Jésù tó kú, ó tún ọ̀rọ̀ ìdánilójú tó mẹ́nu kàn nínú àpèjúwe rẹ̀ sọ. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀mí mímọ́, ó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Èmi yóò sì béèrè lọ́wọ́ Baba, yóò sì fún yín ní olùrànlọ́wọ́ mìíràn láti wà pẹ̀lú yín títí láé.” (Jòhánù 14:16) Ohun tí Jésù ń fi yé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé olùrànlọ́wọ́ yìí, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́, yóò wà pẹ̀lú wọn lọ́jọ́ iwájú, àní títí dé àkókò tiwa yìí. Kí ni ọ̀nà pàtàkì kan tí ẹ̀mí mímọ́ gbà ń ràn wá lọ́wọ́ lóde òní? Ẹ̀mí mímọ́ ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da onírúurú ìṣòro. Báwo ló ṣe ń ràn wá lọ́wọ́? Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tóun náà kojú ìṣòro kọ sáwọn Kristẹni tó wà nílùú Kọ́ríńtì, ó sọ bí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe ran òun lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tó sọ yẹ̀ wò ní ṣókí.
16. Ọ̀nà wo ni ipò tá a wà lè gbà dà bíi ti Pọ́ọ̀lù?
16 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Pọ́ọ̀lù là á mọ́lẹ̀ fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé ‘ẹ̀gún kan wà nínú ẹran ara’ òun, ìyẹn ni pé òun ní ìṣòro kan tó ń yọ òun lẹ́nu. Lẹ́yìn ìyẹn, ó sọ pé: “Ìgbà mẹ́ta ni mo pàrọwà sí Olúwa [Jèhófà] pé kí ó lè kúrò lára mi.” (2 Kọ́ríńtì 12:7, 8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù bẹ Ọlọ́run pé kó bá òun mú ohun tó ń pọ́n òun lójú yìí kúrò, síbẹ̀ ìpọ́njú ọ̀hún ń bá a nìṣó. Bóyá bí nǹkan ṣe rí fún ìwọ náà nìyẹn. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ó ṣeé ṣe kó o ti gbàdúrà títí pé kí Jèhófà bá ọ mú ìṣòro náà kúrò. Àmọ́ láìka iye ìgbà tó o ti ń gbàdúrà sí, ìṣòro náà ò yanjú. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé Jèhófà ò dáhùn àdúrà rẹ ni tàbí pé ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ò ràn ọ́ lọ́wọ́? Ó tì o! (Sáàmù 10:1, 17) Wo ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ tẹ̀ lé e.
17. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà dáhùn àdúrà Pọ́ọ̀lù?
17 Nígbà tí Ọlọ́run máa dá Pọ́ọ̀lù lóhùn, ó sọ fún un pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ; nítorí agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.” Pọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Nítorí náà, ṣe ni èmi yóò kúkú máa fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an ṣògo nípa àwọn àìlera mi, kí agbára Kristi lè wà lórí mi bí àgọ́.” (2 Kọ́ríńtì 12:9; Sáàmù 147:5) Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé Pọ́ọ̀lù rí i pé Ọlọ́run tipa Kristi da ààbò rẹ̀ tó nípọn bo òun bí àgọ́. Bákan náà lónìí, bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà wa jọ ìyẹn. Ó máa ń da ààbò rẹ̀ tó nípọn bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bí àgọ́.
18. Kí ló mú ká lè máa fara dá ìṣòro?
18 Lóòótọ́, àgọ́ tàbí ilé tó ní òrùlé kò lè dá òjò dúró kó má rọ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò lè da ìjì dúró kó má jà, àmọ́ kò ní jẹ́ kí òjò pa ẹni tó bá sá sábẹ́ rẹ̀ yóò sì tún dáàbò bò ó lọ́wọ́ ìjì. Bákan náà, “agbára Jésù” tó dà bí àgọ́ tàbí ilé kò ní káwa ìránṣẹ́ Jèhófà má ní ìṣòro bẹ́ẹ̀ ni kò dá àwọn èèyàn dúró kí wọ́n má kó ìṣòro bá wa. Àmọ́, ó ń dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí, ìyẹn ni pé kì í jẹ́ kí ohunkóhun bá àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ nínú ayé yìí, ó sì ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ Sátánì tí ń ṣàkóso ayé. (Ìṣípayá 7:9, 15, 16) Torí náà, bí ìṣòro kan bá tilẹ̀ ń bá ọ fínra, tí ìṣòro ọ̀hún ò ‘kúrò lára rẹ,’ kí ó dá ọ lójú pé Jèhófà rí gbogbo bó o ṣe ń tiraka àti pé ó ń ṣe nǹkan kan nípa “igbe ẹkún rẹ.” (Aísáyà 30:19; 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.”—1 Kọ́ríńtì 10:13; Fílípì 4:6, 7.
19. Kí lo pinnu nísinsìnyí láti ṣe, kí sì nìdí tó o fi ṣe ìpinnu yẹn?
19 Lóòótọ́, “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” nínú ayé èṣù tá à ń gbé yìí jẹ́ “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tímótì 3:1) Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ò ní lè fara da àwọn àkókò lílekoko yìí o. Kí nìdí? Ìdí ni pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń ràn wọ́n lọ́wọ́ ó sì ń dáàbò bò wọ́n. Ẹ̀mí yìí ni Jèhófà ń fi tinútinú fún gbogbo àwọn tó ń bá a nìṣó láti fi ìdánilójú béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ńṣe ló sì ń fún wọn lọ́pọ̀ yanturu. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a óò máa bá a nìṣó láti máa gbàdúrà sí Ọlọ́run lójoojúmọ́ pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.—Sáàmù 34:6; 1 Jòhánù 5:14, 15.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Ká tó lè rí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà, kí ló yẹ ká ṣe?
• Kí ló mú kó dá wa lójú pé tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, yóò dáhùn àdúrà wa?
• Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí mímọ́ gbà ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da ìṣòro?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Kí la lè rí kọ́ látinú àpèjúwe tí Jésù sọ nípa ẹni tí àlejò dé bá tó tẹpẹlẹ mọ́ bíbéèrè nǹkan lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ṣé o máa ń tẹpẹlẹ mọ́ gbígbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fún ọ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ nípa Jèhófà látinú àpèjúwe bàbá tó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀?