À Ń Láyọ̀ Bá A Ṣe Ń Lo Ara Wa Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà!
1 Tayọ̀tayọ̀ ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi “ná” ara rẹ̀ “tán pátápátá” kó bàa lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láṣepé. (2 Kọ́r. 12:15) Bákan náà, ọ̀pọ̀ Kristẹni lónìí ló ń ṣiṣẹ́ taápọntaápọn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà. Ọwọ́ àwọn míì di gan-an nítorí pé bùkátà ìdílé wọn ti fẹjú, síbẹ̀ wọ́n ń wáyè láti máa jáde òde ẹ̀rí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àwọn tí àìlera ń pọ́n lójú pàápàá máa ń lo ìwọ̀nba okun tí wọ́n ní láti tan ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kálẹ̀. Ẹ ò rí i pé ohun ìṣírí gbáà ló jẹ́ láti rí báwọn èèyàn Jèhófà ṣe ń lo ara wọn nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ láìfi tọjọ́ orí àti ipò tó yí wọn ká pè!
2 Ìfẹ́ Aládùúgbò: Ẹ̀rí ọkàn ò ní máa nà wá lẹ́gba bá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti sin Jèhófà, tá a sì ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò. Nítorí pé tọkàntara ni Pọ́ọ̀lù fi wàásù ìhìn rere, ó ṣeé ṣe fún un láti sọ tayọ̀tayọ̀ pé: “Mo pè yín ṣe ẹlẹ́rìí ní òní yìí gan-an pé ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo.” (Ìṣe 20:24, 26; 1 Tẹs. 2:8) Bó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tí agbára wa gbé là ń ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, a ò ní jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.—Ìsík. 3:18-21.
3 A ó máa láyọ̀ bá a bá ń ṣiṣẹ́ kára láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. (Ìṣe 20:35) Arákùnrin kan sọ pé: “Lọ́jọ́ èyíkéyìí tí mo bá jáde òde ẹ̀rí, ó ti máa ń rẹ̀ mí nígbà tí mo bá fi máa darí délé nírọ̀lẹ́. Àmọ́, mo máa ń láyọ̀ mo sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń fún mi láyọ̀ tí ẹnikẹ́ni ò lè gbà lọ́wọ́ mi.”
4 Ìfẹ́ Ọlọ́run: Ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a fi ń lo ara wa nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni pé ó máa ń múnú Baba wa ọ̀run dùn. Bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ló máa ń jẹ́ ká lè pa òfin rẹ̀ mọ́, lára òfin náà sì ni pé ká máa wàásù ká sì máa sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn. (1 Jòh. 5:3) Kódà nígbà táwọn èèyàn ò bá fẹ́ gbọ́ wa tàbí tí wọ́n ń ta kò wá, ńṣe ni kẹ́ ẹ jẹ́ ká máa fayọ̀ bá a lọ láti máa ṣiṣẹ́ kára fún Jèhófà.
5 Kò ní bójú mu pé ká dẹwọ́ níbi tá a báṣẹ́ náà dé yìí. Àkókò ìkórè la wà. (Mát. 9:37) Ṣe ni àgbẹ̀ sábà máa ń pẹ́ lóko lákòókò ìkórè nítorí pé ìwọ̀nba àkókò ló ní láti fi kórè káwọn ọ̀gbìn tó bẹ̀rẹ̀ sí í bà jẹ́. Bákan náà, àkókò tá a ní láti fi ṣiṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí yìí ò tó nǹkan mọ́. Bá a ṣe ń fi àkókò tá à ń gbé yìí sọ́kàn, ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa bá a lọ láti máa lo ara wa tọkàntara nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.—Lúùkù 13:24; 1 Kọ́r. 7:29-31.