Ẹ Máa Gba Ti Ara Yín Rò Kẹ́ ẹ Sì Máa Fún Ara Yín Ní Ìṣírí
‘Ẹ jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.’—HÉB. 10:24.
1, 2. Kí ló mú kí ọgbọ̀nlérúgba [230] àwọn ará wa lè la ìrìn àjò ikú kan tó wáyé lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì já?
NÍGBÀ tí ìjọba Násì lórílẹ̀-èdè Jámánì forí ṣánpọ́n ní ìparí Ogun Àgbáyé Kejì, wọ́n pàṣẹ pé kí wọ́n pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó ṣẹ́ kù nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Wọ́n pinnu pé wọ́n máa kó ẹlẹ́wọ̀n tó wà nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Sachsenhausen jáde kí wọ́n sì fẹsẹ̀ rìn títí wọ́n á fi dé etíkun, wọ́n á sì kó wọn sínú ọkọ̀ ojú omi. Wọ́n á wá mú kí ọkọ̀ náà rì nígbà tó bá dójú agbami. Ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí wọ́n dá yìí la wá mọ̀ sí ìrìn àjò ikú.
2 Bí wọ́n ṣe mú ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33,000] àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Sachsenhausen láti fẹsẹ̀ rìn nìyẹn o. Wọ́n mú kí wọ́n rin ìrìn àádọ́talérúgba [250] kìlómítà lọ́ sí etíkun Lübeck, lórílẹ̀-èdè náà. Ọgbọ̀nlérúgba [230] àwọn ará wa láti orílẹ̀-èdè mẹ́fà wà lára àwọn tí wọ́n fipá mú láti fẹsẹ̀ rin ìrìn náà. Ebi àti àìsàn ti mú kí àárẹ̀ mú wọn. Kí ló mú kí àwọn ará wa náà lè rin ìrìn àjò yẹn já? Ọ̀kan lára wọn sọ pé, “Ńṣe là ń fún ara wa níṣìírí pé ká ṣáà máa forí tì í.” Ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ara wọn lẹnì kìíní-kejì mú kí wọ́n lè la ìrìn àjò ikú yẹn já. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà fún wọn ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.”—2 Kọ́r. 4:7.
3. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fún ara wa níṣìírí?
3 Lónìí, kò sẹ́ni tó ń fipá mú wa rin ìrìn àjò ikú bíi tàwọn ará wa yẹn, àmọ́ àwa náà ní ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń pọ́n wa lójú. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ lọ́dún 1914, a lé Sátánì kúrò ní ọ̀run wá sí sàkání ayé yìí, tòun ti “ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣí. 12:7-9, 12) Bí Amágẹ́dọ́nì ṣe ń sún mọ́lé, ṣe ni Sátánì túbọ̀ ń lo onírúurú àdánwò àti pákáǹleke láti mú ká dẹwọ́ nínú ìjọsìn wa. Ká má ṣẹ̀sẹ̀ wá sọ ti kòókòó-jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé. (Jóòbù 14:1; Oníw. 2:23) Nígbà míì, téèyàn bá ro bí àwọn ìṣòro tó ń báni fínra ṣe ń rọ́ lura, ńṣe ló máa ń dà bíi pé gbogbo ìsapá téèyàn ń ṣe láti dúró sán-ún nípa tẹ̀mí já sí pàbó, ó sì máa ń tojú súni débi pé ṣe lèèyàn máa rẹ̀wẹ̀sì, téèyàn ò sì ní lè forí tì í. Àpẹẹrẹ kan ni ti arákùnrin kan tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ló ti fi ń ràn àwọn èèyàn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Àmọ́, nígbà tọ́jọ́ ogbó dé, arákùnrin yìí àti ìyàwó rẹ̀ ṣàìsàn, èyí sì mú kó rẹ̀wẹ̀sì gan-an. Bá a ṣe rí i nínú àpẹẹrẹ arákùnrin yìí, ó hàn pé gbogbo wa pátá la nílò “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” látọ̀dọ̀ Jèhófà, a sì nílò káwọn ẹlòmíì fún wa níṣìírí.
4. Tá a bá fẹ́ fún àwọn èèyàn níṣìírí, ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wo ló yẹ ká máa fi sọ́kàn?
4 Tá a bá fẹ́ fún àwọn ẹlòmíì níṣìírí, a gbọ́dọ̀ máa fi ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù sọ́kàn. Ó gbà wọ́n níyànjú pé: ‘Ẹ jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.’ (Héb. 10:24, 25) Ọ̀rọ̀ àtàtà lèyí jẹ́. Àmọ́, báwo la ṣe lè fi ìmọ̀ràn yìí sílò?
Ẹ MÁA GBA TI ARA YÍN RÒ
5. Kí ló túmọ̀ sí pé ká máa gba ti ara wa rò, kí nìyẹn sì ń béèrè pé ká ṣe?
5 Gbólóhùn náà, ‘ẹ máa gba ti ara yín rò’ túmọ̀ sí pé ká máa ro tàwọn ẹlòmíì mọ́ tiwa. Tó bá jẹ́ pé gbogbo ọ̀rọ̀ tá à ń bá wọn sọ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kò ju pé ká kàn kí wọn tàbí ká kàn bá wọn sọ̀rọ̀ lóréfèé, ǹjẹ́ a lè sọ pé à ń ro tàwọn ẹlòmíì mọ́ tiwa? Kò dájú. Lóòótọ́, a ò fẹ́ máa “yọjú sí ọ̀ràn ọlọ́ràn,” a ò sì fẹ́ jẹ́ “alátojúbọ àlámọ̀rí àwọn ẹlòmíràn.” (1 Tẹs. 4:11; 1 Tím. 5:13) Síbẹ̀, tá a bá fẹ́ máa fún àwọn èèyàn níṣìírí, a ní láti sún mọ́ wọn, ká mọ́ bí nǹkan ṣe ń lọ pẹ̀lú wọn, àwọn ànímọ́ rere wọn, ipò tẹ̀mí wọn, ohun tí agbára wọ́n gbé àti kùdìẹ̀-kudiẹ wọn. Ká jẹ́ kí wọ́n rí wa bí ọ̀rẹ́ wọn, ká sì jẹ́ kó dá wọn lójú pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Kì í ṣe ìgbà tí wọ́n bá ní ìṣòro tàbí tí nǹkan tójú sú wọn nìkan la fẹ́ máa yọjú sí wọn, àmọ́ ká jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa lo àkókò pẹ̀lú wọn láwọn ìgbà míì.—Róòmù 12:13.
6. Kí ló lè mú kí alàgbà kan máa gba tàwọn tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀ rò?
6 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ àwọn alàgbà pé kí wọ́n máa “ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó” wọn, kí wọ́n sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ tinútinú àti pẹ̀lú ìháragàgà. (1 Pét. 5:1-3) Ṣé wọ́n á lè bójú tó àwọn àgùntàn tó ń bẹ lábẹ́ àbójútó wọn bó ṣe yẹ tí wọn ò bá mọ àwọn àgùntàn náà dáadáa? (Ka Òwe 27:23.) Táwọn alàgbà bá ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó, tí wọ́n sì ń nífẹ̀ẹ́ àtimáa wà pẹ̀lú àwọn ará, ó máa rọrùn fáwọn ará nínú ìjọ láti sún mọ́ wọn nígbà tí wọ́n bá nílò ìrànwọ́ wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, á máa wu àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin láti bá wọn sọ ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn àti bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Èyí á sì mú káwọn alàgbà lè máa gba tiwọn rò, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.
7. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tí ẹni tó rẹ̀wẹ̀sì bá sọ ọ̀rọ̀ tó dà bí ọ̀rọ̀ ẹhànnà?
7 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ lẹ́tà sáwọn ará nílùú Tẹsalóníkà, ó sọ pé: “Ẹ máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera.” (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:14.) A lè ka “àwọn ọkàn tí ó soríkọ́” sí aláìlera, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá. Ìwé Òwe 24:10 sọ pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” Nígbà míì, ẹni tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá lè sọ ọ̀rọ̀ tó dà bí “ọ̀rọ̀ ẹhànnà.” (Jóòbù 6:2, 3) Tá a bá máa gba tàwọn ẹni bẹ́ẹ̀ rò, a gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn pé kì í ṣe ohun tí wọ́n ní lọ́kàn gan-an ni wọ́n sábà máa ń sọ jáde lẹ́nu. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Rachelle jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ yìí nígbà kan tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá màmá rẹ̀. Rachelle sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mọ́mì máa ń kanra tí wọ́n sì máa ń sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí wa. Nírù àwọn ipò yìí, mo sábà máa ń ran ara mi létí irú ẹni tí mọ́mì mi jẹ́ gan-an. Mo mọ̀ pé ẹniire ni mọ́mì, wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa, wọ́n sì lawọ́ gan-an. Mó wá rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá máa ń sọ tó jẹ́ pé kì í ṣe ohun tí wọ́n ní lọ́kàn gan-an nìyẹn. Tá a bá wá ń foró yaró, ṣe ló máa mú kọ́rọ̀ náà burú sí i.” Òwe 19:11 sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú, ẹwà ni ó sì jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.”
8. Àwọn wo ló ṣe pàtàkì pé ká fìfẹ́ hàn sí? Kí sì nìdí?
8 Ká sọ pé ẹnì kan ti dẹ́ṣẹ̀ nígbà kan rí, àmọ́ ó ti ṣàtúnṣe tó yẹ. Síbẹ̀ ojú ṣì ń tì í, ìbànújẹ́ sì bá a. Kí la lè ṣe láti fi hàn pé a gba tiẹ̀ rò? Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé nípa ẹnì kan tó hùwà àìtọ́ ní ìjọ Kọ́ríńtì, àmọ́ tó ti ronú pìwà dà, ó sọ pé: “Kí ẹ fi inú rere dárí jì í, kí ẹ sì tù ú nínú, pé lọ́nà kan ṣáá, kí ìbànújẹ́ rẹ̀ tí ó pàpọ̀jù má bàa gbé irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ mì. Nítorí náà, mo gbà yín níyànjú pé kí ẹ fìdí òtítọ́ ìfẹ́ yín fún un múlẹ̀.” (2 Kọ́r. 2:7, 8) Ohun tó túmọ̀ sí láti fìdí ìfẹ́ ẹni múlẹ̀ ni pé ká jẹ́ kó dá onítọ̀hún lójú pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kó rí i pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán. Kò ní dáa ká máa ronú pé ó yẹ kóun náà mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ òun àti pé ọ̀rọ̀ òun jẹ wá lógún. Ó gbọ́dọ̀ rí i nínú ìwà àti ìṣe wa pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Ẹ MÁA ‘RU ARA YÍN SÓKÈ SÍ ÌFẸ́ ÀTI SÍ ÀWỌN IṢẸ́ ÀTÀTÀ’
9. Kí ló túmọ̀ sí láti “ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà”?
9 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.’ Ó yẹ ká ṣe ohun táá mú káwọn ará wa máa fìfẹ́ hàn kí wọ́n sì máa ṣe iṣẹ́ àtàtà. Tí èèyàn kan bá ń da iná tí iná náà sì ń kú lọ, ńṣe ló máa koná mọ́ ọn, táá sì fẹ́ atẹ́gùn sí i. (2 Tím. 1:6) Lọ́nà kan náà, a lè ṣe ohun táá mú káwọn ará wa máa fìfẹ́ hàn sí Ọlọ́run àti sí àwọn aládùúgbò wọn. Tá a bá fẹ́ káwọn ará wa máa ṣe iṣẹ́ àtàtà, ó yẹ ká máa gbóríyìn fún wọn látọkànwá.
10, 11. (a) Àwọn wo ló yẹ ká máa gbóríyìn fún? (b) Sọ àpẹẹrẹ kan to fi hàn pé tá a bá gbóríyìn fún ẹni tó “ṣi ẹsẹ gbé,” ó lè ṣàtúnṣe.
10 Bóyá a rẹ̀wẹ̀sì tàbí a ò rẹ̀wẹ̀sì, gbogbo wa pátá la máa ń fẹ́ kí wọ́n yìn wá. Alàgbà kan sọ pé, “Kò sígbà kan tí bàbá mi sọ pé mo mọ nǹkan ṣe rí. Èyí jẹ́ kí èmi náà rí ara mi bí ẹni tí kò wúlò. . . . Òótọ́ ni pé mo ti pé àádọ́ta [50] ọdún báyìí, síbẹ̀ inú mi máa ń dùn táwọn ọ̀rẹ́ mi bá yìn mí pé alàgbà tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ ni mí. . . . Ìrírí mi ti jẹ́ kí n mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa gbóríyìn fáwọn èèyàn, mo sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà gbogbo.” Kó sẹ́ni tí orí rẹ̀ kì í wú tí wọ́n bá yìn ín, ì báà jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, àgbàlagbà àtàwọn tó rẹ̀wẹ̀sì.—Róòmù 12:10.
11 Nígbà táwọn tó tóótun nípa tẹ̀mí bá ń gbìyànjú láti tọ́ ẹnì kan tó ṣi ẹsẹ̀ gbé sọ́nà, wọ́n lè gbóríyìn fún un níbi tó ti yẹ, kí wọ́n sì fìfẹ́ bá a wí. Nípa bẹ́ẹ̀, onítọ̀hún lè ṣàtúnṣe, kí ó sì wá máa ṣe iṣẹ́ àtàtà. (Gál. 6:1) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Miriam gan-an nìyẹn. Ó sọ pé: “Ayé sú mi pátápátá nígbà táwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ kan kúrò nínú òtítọ́. Ó tún wá lọ jẹ́ pé láàárín àkókò yẹn náà ni bàbá mi ṣàìsàn tí ẹ̀jẹ̀ ń dà ní ọpọlọ wọn. Ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi gan-an. Kí n lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ ọkùnrin aláìgbàgbọ́ kan.” Ohun tó ṣe yìí mú kó gbà pé Jèhófà kò lè nífẹ̀ẹ́ òun mọ́. Torí bẹ́ẹ̀, ó ronú pé òun máa fi ètò Jèhófà sílẹ̀. Àmọ́ alàgbà kan bá a sọ̀rọ̀, ó sì rán an létí àwọn ìgbà tó ti ń fi ìṣòtítọ́ sìn, èyí wá mú kó tún inú rò. Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara balẹ̀ nígbà táwọn alàgbà ń jẹ́ kó mọ̀ pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Látàrí èyí, àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà tún wá pa dà gún régé. Bó ṣe já aláìgbàgbọ́ tó ń fẹ́ sílẹ̀ nìyẹn, ó sì ń sin Jèhófà nìṣó.
12. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé torí ká lè mú káwọn èèyàn ṣe ohun tó yẹ, a wá ń dójú tì wọ́n, à ń bẹnu àtẹ́ lù wọ́n tàbí à ń mú kí wọ́n máa dá ara wọn lẹ́bi?
12 Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé ńṣe là ń fi ohun tí ẹnì kan ń ṣe wé tàwọn ẹlòmíì torí pé a fẹ́ kí ojú tì í kó bàa lè ṣe ohun tó tọ́, tàbí à ń bẹnu àtẹ́ lù ú torí pé kò dójú ìlà ohun táwa ń retí, àbí ńṣe là ń sọ̀rọ̀ tó mú kó máa dá ara rẹ̀ lẹ́bi nítorí pé kò ṣe dáadáa tó? Ó ṣeé ṣe kí èyí mú kí onítọ̀hún túbọ̀ wá tẹra mọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ lóòótọ́, àmọ́ irú ìtara bẹ́ẹ̀ kì í tọ́jọ́. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ará wa á túbọ̀ máa ṣe dáadáa tá a bá ń gbóríyìn fún wọn, tá a sì ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run ló ń mú kí wọ́n máa ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe.—Ka Fílípì 2:1-4.
‘Ẹ MÁA FÚN ARA YÍN NÍṢÌÍRÍ LẸ́NÌ KÌÍNÍ-KEJÌ’
13. Kí la ní láti ṣe tá a bá máa fún ẹnì kan níṣìírí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
13 Ó ṣe pàtàkì pé ká máa ‘fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí a ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.’ Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà fún àwọn èèyàn níṣìírí ni pé ká máa rọ̀ wọ́n láti tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. A lè fi bá a ṣe ń mú káwọn ará wa máa fìfẹ́ hàn kí wọ́n sì máa ṣe iṣẹ́ àtàtà wé kéèyàn máa koná, kó sì máa fẹ́ atẹ́gùn sí iná tó fẹ́ kú, nígbà tí ìṣírí tá à ń fún un dà bí ìgbà tá à ń da epo sí iná náà kó bàa lè jò dáadáa. A tún lè fún àwọn èèyàn ní ìṣírí tá a bá ń tù wọ́n nínú tá a sì ń fún wọn lókun nígbà tí wọ́n bá rẹ̀wẹ̀sì. Tá a bá láǹfààní láti fún ẹni tó rẹ̀wẹ̀sì níṣìírí, ó yẹ ká sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́ tó máa tu ẹni náà lára. (Òwe 12:18) Ó tún yẹ ká “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́” ká sì tún “lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.” (Ják. 1:19) Tá a bá ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, tá a sì ń fi ọ̀rọ̀ wọn ro ara wa wò, àá lè mọ ohun náà gan-an tó fà á tí arákùnrin tàbí arábìnrin náà fi rẹ̀wẹ̀sì, àá sì mọ ohun tá a lè sọ táá mú kó lè máa fara dà á.
14. Báwo ni alàgbà kan ṣe ran arákùnrin kan tó rẹ̀wẹ̀sì lọ́wọ́?
14 Jẹ́ ká wo bí alàgbà onínúure kan ṣe ṣèrànwọ́ fún arákùnrin kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Bí alàgbà yìí ṣe ń tẹ́tí sí arákùnrin náà, ó rí i pé arákùnrin yìí ṣì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Ó máa ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ gbogbo Ilé Ìṣọ́ tó bá jáde, ó sì máa ń sapá láti wá sí gbogbo ìpàdé. Àmọ́, ìwà àwọn kan nínú ìjọ ń dà á lọ́kàn rú, inú sì ń bí i. Alàgbà náà fi ara balẹ̀ tẹ́tí sí i dáadáa, ó fi ọ̀rọ̀ náà ro ara rẹ̀ wò, kò sì dá a lẹ́bi. Ó jẹ́ kó mọ pé ọ̀rọ̀ arákùnrin náà àti ìdílé rẹ̀ jẹ òun lógún. Nígbà tó yá, arákùnrin yìí wá rí i pé òun ti jẹ́ kí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn mú kí òun jìnnà sí Ọlọ́run tí òun nífẹ̀ẹ́. Alàgbà náà wá ṣètò pé kí àwọn jọ lọ sóde ẹ̀rí. Bí Jèhófà ṣe lo alàgbà yìí láti mú kí arákùnrin náà tún máa lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìwàásù nìyẹn o. Ní báyìí, arákùnrin náà ti pa dà di alàgbà.
15. Kí la rí kọ́ látinú bí Jèhófà ṣe máa ń fún àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì níṣìírí?
15 Nígbà míì, ẹni tó rẹ̀wẹ̀sì lè má tètè túra ka, ó sì lè má tètè fi ìmọ̀ràn wa sílò. Ó lè gba pé ká túbọ̀ máa sapá láti ràn án lọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa ran àwọn aláilera lọ́wọ́; ẹ máa mú suuru pẹlu gbogbo eniyan.” (1 Tẹs. 5:14, Ìròyìn Ayọ̀) Dípò tá a fi máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn aláìlera sú wa, ẹ jẹ́ ká dúró tì wọ́n ká sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń mú sùúrù fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láyé àtijọ́ láwọn ìgbà tí wọ́n bá rẹ̀wẹ̀sì. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run gba ti wòlíì Èlíjà rò, kò bínú sí i rárá. Jèhófà fún un lóhun tó nílò láti máa bá iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ nìṣó. (1 Ọba 19:1-18) Jèhófà dárí ji Dáfídì torí pé ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn. (Sm. 51:7, 17) Ọlọ́run tún ran ẹni tó kọ Sáàmù kẹtàléláàádọ́rin [73] lọ́wọ́, ẹni tó jẹ́ pé díẹ̀ báyìí ló kù kí ó yẹsẹ̀. (Sm. 73:13, 16, 17) Jèhófà máa ń ṣàánú wa, ó sì máa ń ṣe wá lóore gan-an, pàápàá nígbà tá a bá rẹ̀wẹ̀sì. (Ẹ́kís. 34:6) Ojoojúmọ́ ló máa ń fàánú hàn sí wa, ó sì dájú pé “àánú rẹ̀ kì yóò wá sí òpin.” (Ìdárò 3:22, 23) Bí Jèhófà ṣe ń fọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì náà ló fẹ́ ká máa ṣe sí wọn.
Ẹ MÁA FÚN ARA YÍN NÍṢÌÍRÍ LÁTI TẸ̀ SÍWÁJÚ LÓJÚ Ọ̀NÀ TÓ LỌ SÍ ÌYÈ
16, 17. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe bí òpin àwọn nǹkan yìí ṣe ń sún mọ́lé? Kí sì nìdí?
16 Nínú ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33,000] àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó fi àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Sachsenhausen sílẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló kú. Àmọ́ o, kò sí èyíkéyìí lára ọgbọ̀nlérúgba [230] àwọn ará wa tó kú sẹ́nu ìrìn gbẹ̀mígbẹ̀mí yẹn. Ìṣírí àti ìtìlẹ́yìn tí wọ́n ń fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì ni ohun pàtàkì tí kò jẹ́ kí ìrìn àjò gbẹ̀mígbẹ̀mí yẹn já sí ikú fún wọn.
17 Lónìí, a wà ní “ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè.” (Mát. 7:14) Láìpẹ́, gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà máa rìn pa pọ̀ wọnú ayé tuntun tí òdodo ń gbé. (2 Pét. 3:13) Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa ran ara wa lọ́wọ́ bá a ṣe ń rìn lọ́ lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.