Ẹ Kọ Ojú Ìjà Sí Sátánì, Yóò Sì Sá!
“Ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.”—Jákọ́bù 4:7.
1, 2. (a) Ìwà Èṣù wo ni ohun tó wà nínú Aísáyà orí kẹrìnlá jẹ́ ká mọ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni a óò dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
ÈṢÙ ni olórí agbéraga. Ohun tí Aísáyà wòlíì Ọlọ́run kọ jẹ́ ká rí bí ìgbéraga rẹ̀ ṣe tó. Ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú kí Bábílónì tó di ìjọba tó ń ṣàkóso ayé ni Aísáyà ti sọ pé àwọn èèyàn Jèhófà yóò sọ fún “ọba Bábílónì” pé: “Ìwọ ti sọ nínú ọkàn-àyà rẹ pé, ‘Ọ̀run ni èmi yóò gòkè lọ. Òkè àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run [ìyẹn, àwọn ọba tó ń jẹ láti ìran Dáfídì] ni èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sí . . . èmi yóò mú ara mi jọ Ẹni Gíga Jù Lọ.’” (Aísáyà 14:3, 4, 12-15; Númérì 24:17) Ìgbéraga “ọba Bábílónì” yìí ò yàtọ̀ sí ìgbéraga Sátánì “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Kọ́ríńtì 4:4) Bí ìjọba Bábílónì ṣe tẹ́ tó sì pa run náà ni Sátánì ṣe máa kàgbákò nígbẹ̀yìn nítorí ìgbéraga rẹ̀.
2 Àmọ́, níwọ̀n ìgbà tí Èṣù bá ṣì wà, àwọn ìbéèrè tó lè máa wá sí wa lọ́kàn ni: Ǹjẹ́ ó yẹ ká bẹ̀rù Sátánì? Kí nìdí tó fi ń mú káwọn èèyàn ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni? Kí la lè ṣe kí Èṣù má lè fi ọgbọ́n àyínìke borí wa?
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Bẹ̀rù Èṣù?
3, 4. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn kò fi bẹ̀rù Èṣù?
3 Ọ̀rọ̀ kan tí Jésù Kristi sọ ń fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lókun gan-an ni, ó sọ pé: “Má fòyà àwọn ohun tí ìwọ máa tó jìyà rẹ̀. Wò ó! Èṣù yóò máa bá a nìṣó ní sísọ àwọn kan nínú yín sí ẹ̀wọ̀n kí a lè dán yín wò ní kíkún, kí ẹ sì lè ní ìpọ́njú fún ọjọ́ mẹ́wàá. Jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú, dájúdájú, èmi yóò sì fún ọ ní adé ìyè.” (Ìṣípayá 2:10) Àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó ń retí láti wà lórí ilẹ̀ ayé kò bẹ̀rù Èṣù rárá. Kì í ṣe pé ẹ̀dá tí kì í bẹ̀rù rárá ni wọ́n o. Ohun tó fún wọn nígboyà ni bíbẹ̀rù tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, tí wọ́n sì ‘sá di abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ̀.’—Sáàmù 34:9; 36:7.
4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn han àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi ìjímìjí tí kì í bẹ̀rù léèmọ̀, síbẹ̀ wọ́n jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú. Wọn kò bẹ̀rù ohun tí Sátánì Èṣù lè ṣe, nítorí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ò ní kọ àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ sí i sílẹ̀. Lónìí bákan náà, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ò ní jẹ́ ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ wọn, bó ti wù kí inúnibíni tí wọ́n ń fojú winá rẹ̀ gbóná tó. Ṣùgbọ́n o, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Èṣù lè ṣekú pani. Ǹjẹ́ ìyẹn kò tó nǹkan tí yóò máa dẹ́rù bà wá?
5. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú Hébérù 2:14, 15?
5 Pọ́ọ̀lù sọ pé Jésù ‘ṣalábàápín ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara’ nítorí kí ó lè ‘tipasẹ̀ ikú rẹ̀ sọ ẹni tí ó ní ọ̀nà àtimú ikú wá di asán, èyíinì ni, Èṣù; àti pé kí ó lè dá gbogbo àwọn tí a ti fi sábẹ́ ìsìnrú ní gbogbo ìgbésí ayé wọn nítorí ìbẹ̀rù ikú nídè kúrò lóko ẹrú.’ (Hébérù 2:14, 15) Sátánì “tí ó ní ọ̀nà àtimú ikú wá” lo Júdásì Ísíkáríótù, ó sì tún lo àwọn aṣáájú àwọn Júù àtàwọn ará Róòmù láti pa Jésù. (Lúùkù 22:3; Jòhánù 13:26, 27) Ṣùgbọ́n Jésù fi ikú tó kú láti fi ṣe ìrúbọ yìí dá ìran èèyàn nídè kúrò lábẹ́ agbára Sátánì, ó sì mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 3:16.
6, 7. Báwo lagbára tí Èṣù ní láti fa ikú ṣe pọ̀ tó?
6 Báwo lagbára tí Èṣù ní láti fa ikú ṣe pọ̀ tó? Ṣé ẹ rí i, gbàrà tí Sátánì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ibi rẹ̀ ni irọ́ rẹ̀ àti ọ̀nà tó ń darí ènìyàn sí ti ń fa ikú bá ìran ènìyàn. Ohun tó mú kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé Ádámù dẹ́ṣẹ̀ ó sì tipa báyìí mú kí ìran ènìyàn jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 5:12) Síwájú sí i, àwọn ìránṣẹ́ Sátánì lórí ilẹ̀ ayé ń ṣenúnibíni sáwọn olùjọsìn Jèhófà, débi pé wọ́n ń pa òmíràn lára wọn, àní gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe pa Jésù Kristi.
7 Àmọ́ ṣá, ká má ṣe rò pé Èṣù lágbára láti kàn gbẹ̀mí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ o. Ọlọ́run máa ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀, kò sì ní gbà kí Sátánì run gbogbo àwọn olùjọsìn rẹ̀ tòótọ́ kúrò láyé. (Róòmù 14:8) Lóòótọ́, Jèhófà máa ń gbà kí inúnibíni dé bá èyíkéyìí nínú àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì máa ń gbà kí ikú pa àwọn kan lára wa tí Èṣù bá dojú ìjà kọ wá. Ṣùgbọ́n, Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé àjíǹde tó jẹ́ ìrètí àgbàyanu ń bẹ fáwọn tó bá wà nínú “ìwé ìrántí” Ọlọ́run, kò sì sí ohunkóhun tí Èṣù lè ṣe láti dá àjíǹde wọn dúró!—Málákì 3:16; Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15.
Kí Nìdí Tí Sátánì Fi Ń Ṣenúnibíni sí Wa?
8. Kí nìdí tí Sátánì fi ń dojú inúnibíni kọ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run?
8 Ìdí kan pàtàkì wà tí Èṣù fi ń dojú inúnibíni kọ àwa tá a bá ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run. Ńṣe ló ń fẹ́ mú wa ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ wa. Àjọṣe pàtàkì wà láàárín àwa àti Bàbá wa ọ̀run, àjọṣe yẹn ni Sátánì sì fẹ́ bà jẹ́. Àmọ́ kò yẹ kí ìyẹn yà wá lẹ́nu. Jèhófà ti sọ ọ́ ní ọgbà Édẹ́nì pé ìṣọ̀tá yóò wà láàárín “obìnrin” ìṣàpẹẹrẹ òun àti “ejò náà,” àti pé ìṣọ̀tá yẹn yóò tún wà láàárín “irú-ọmọ” àwọn méjèèjì. (Jẹ́nẹ́sísì 3:14, 15) Ìwé Mímọ́ fi hàn pé Èṣù ni “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà,” ó sì fi hàn pé àkókò kúkúrú ló kù fún un àti pé ìbínú rẹ̀ pọ̀ jọjọ. (Ìṣípayá 12:9, 12) Nítorí náà, níwọ̀n bí ìṣọ̀tá àárín “irú-ọmọ” àwọn méjèèjì ti ń bá a nìṣó, kí gbogbo àwọn tó bá ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà mọ̀ dájú pé inúnibíni máa bá àwọn. (2 Tímótì 3:12) Ǹjẹ́ o mọ ohun tó fà á gan-an tí Sátánì fi ń ṣe inúnibíni?
9, 10. Ọ̀ràn wo ni Èṣù dá sílẹ̀, báwo ló sì ṣe kan ìwà ẹ̀dá ènìyàn?
9 Èṣù dá ọ̀ràn kan sílẹ̀ nípa ẹni tó yẹ kó jẹ́ ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Ẹ̀wẹ̀, ó tún sọ pé ìwà títọ́ àwọn èèyàn sí Ẹlẹ́dàá wọn ò wá látinú ọkàn wọn. Sátánì ṣenúnibíni sí Jóòbù olódodo. Kí nìdí rẹ̀? Ó fẹ́ kí Jóòbù ṣe ohun tó máa ba ìwà títọ́ rẹ̀ sí Jèhófà jẹ́ ni. Aya Jóòbù àtàwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta tó jẹ́ “olùtùnú tí ń dani láàmú” wà lára ohun tí Èṣù lò sí Jóòbù nígbà náà. Ìwé Jóòbù fi hàn pé Èṣù pe Ọlọ́run níjà pé kò sí ọmọ èèyàn tó máa jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run tó bá gbà kóun dán onítọ̀hún wò. Ṣùgbọ́n Jóòbù kò yẹsẹ̀ nínú ìwà títọ́ rẹ̀ rárá, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. (Jóòbù 1:8–2:9; 16:2; 27:5; 31:6) Bákan náà, Èṣù ń dojú inúnibíni kọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní nítorí pé ó fẹ́ ká ba ìwà títọ́ wa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè já sí òótọ́.
10 Nígbà tá a ti wá mọ̀ pé ìdí tí Èṣù fi ń dojú inúnibíni kọ wá ni pé ó ń wọ́nà lójú méjèèjì láti ba ìwà títọ́ wa sí Ọlọ́run jẹ́, ó yẹ kí ìyẹn mú ká túbọ̀ jẹ́ onígboyà àti alágbára. (Diutarónómì 31:6) Ọlọ́run wa ni Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ ká lè dúró gbọn-in láìba ìwà títọ́ wa jẹ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa bá ìwà títọ́ wa nìṣó ká lè múnú Jèhófà dùn, kó sì lè rí èsì fún Sátánì Èṣù, olórí àwọn tó ń ṣáátá rẹ̀.—Òwe 27:11.
“Dá Wa Nídè Kúrò Lọ́wọ́ Ẹni Burúkú Náà”
11. Kí ni àdúrà náà, “Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò” túmọ̀ sí?
11 Kò rọrùn láti jẹ́ ẹni tó pa ìwà títọ́ mọ́; ó gba pé kéèyàn gbàdúrà gidigidi. Àdúrà tí Jésù kọ́ wa sì wúlò gan-an fún èyí. Apá kan àdúrà yẹn lọ báyìí: “Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.” (Mátíù 6:13) Jèhófà kì í fi ẹ̀ṣẹ̀ dẹ wá wò o. (Jákọ́bù 1:13) Ṣùgbọ́n nígbà míì, Ìwé Mímọ́ máa ń sọ pé Jèhófà ṣe nǹkan kan tàbí ó fa nǹkan kan nígbà tó jẹ́ pé ńṣe ló kàn gbà á láyè. (Rúùtù 1:20, 21) Tá a bá wá ń gbàdúrà bí Jésù ṣe sọ yìí, ńṣe là ń sọ pé kí Jèhófà gbà wá lọ́wọ́ ìdẹwò. Ó sì dájú pé yóò gbà wá, torí Ìwé Mímọ́ fi dá wa lójú pé: “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.”—1 Kọ́ríńtì 10:13.
12. Kí nìdí tá a fi ń gbàdúrà pé, “Dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà”?
12 Lẹ́yìn tí Jésù mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ ìdẹwò tán nínú àdúrà tó kọ́ wa, ó tún sọ ọ̀rọ̀ pàtàkì yìí pé: “Dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.” Àwọn Bíbélì kan sọ pé: “Gbà wá lọ́wọ́ ibi” (King James Version; Revised Standard Version) tàbí “Dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ibi.” (Contemporary English Version) Àmọ́, gbólóhùn náà “dá wa nídè kúrò lọ́wọ́” tí wọ́n lò nínú Bíbélì, èèyàn ni wọ́n sábà máa ń lò ó fún. Ìwé Ìhìn Rere Mátíù sì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹnì kan ní pàtó, ìyẹn Èṣù ni “Adẹniwò náà.” (Mátíù 4:3, 11) Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì ká máa gbàdúrà pé kí Jèhófà dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ “ẹni burúkú náà,” Sátánì Èṣù, torí pé ńṣe ló máa ń fẹ́ tì wá dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. (1 Tẹsalóníkà 3:5) Nígbà tá a bá gbàdúrà sí Ọlọ́run pé, “Dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà,” ohun tá à ń sọ fún Baba wa ọ̀run ni pé kó ṣamọ̀nà wa, kó sì ràn wá lọ́wọ́ kí Èṣù má bàa fi ọgbọ́n àyínìke borí wa.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Èṣù Fi Ọgbọ́n Àyínìke Borí Rẹ
13, 14. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ará Kọ́ríńtì yí ọwọ́ tí wọ́n fi mú ọ̀rọ̀ ọkùnrin oníṣekúṣe tó wà nínú ìjọ wọn padà?
13 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń rọ àwọn Kristẹni ìlú Kọ́ríńtì pé kí wọ́n máa dárí jini, ó kọ̀wé pé: “Ohunkóhun tí ẹ bá fi inú rere dárí ji ẹnikẹ́ni, èmi náà ṣe bẹ́ẹ̀. Ní ti tòótọ́, ní tèmi, ohun yòówù tí mo bá ti fi inú rere dárí rẹ̀ jini, bí mo bá tí fi inú rere dárí ohunkóhun jini, ó jẹ́ nítorí yín níwájú Kristi; kí Sátánì má bàa fi ọgbọ́n àyínìke borí wa, nítorí àwa kò ṣe aláìmọ àwọn ète-ọkàn rẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 2:10, 11) Onírúurú ọ̀nà ni Èṣù lè gbà fi ọgbọ́n àyínìke borí wa lóòótọ́, àmọ́ kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì tá a fàyọ yìí?
14 Ó ṣẹlẹ̀ pé Pọ́ọ̀lù ti kọ́kọ́ bá ìjọ Kọ́ríńtì wí torí pé ó yẹ kí wọ́n yọ ọkùnrin oníṣekúṣe kan nínú ìjọ, àmọ́ wọn ò yọ ọ́. Ó dájú pé èyí múnú Sátánì dùn gan-an torí pé ẹ̀gàn wá sórí ìjọ náà fún àyè tí wọ́n fi gba “irúfẹ́ àgbèrè tí kò tilẹ̀ sí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè” nínú ìjọ. Bí ìjọ yẹn ṣe wá yọ oníṣekúṣe náà lẹ́gbẹ́ nìyẹn. (1 Kọ́ríńtì 5:1-5, 11-13) Ọkùnrin yìí sì ronú pìwà dà nígbà tó yá. Bí àwọn ará Kọ́ríńtì bá wá kọ̀ tí wọn ò dárí jì í kí wọ́n sì gbà á padà, Èṣù yóò fọgbọ́n àyínìke borí wọn lọ́nà míì. Bíi ti báwo? Ní ti pé wọ́n á di aláìláàánú àtẹni tó le koko jù bíi ti Sátánì. Bí ‘ìbànújẹ́ ẹni tó ronú pìwà dà náà bá pàpọ̀jù’ tó sì ṣíwọ́ sísin Ọlọ́run, Jèhófà Ọlọ́run aláàánú yóò kà á sí àwọn alàgbà ìjọ yẹn lọ́rùn pé wọ́n dá kún ìṣòro rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 2:7; Jákọ́bù 2:13; 3:1) Ó dájú pé kò sí Kristẹni tòótọ́ tó máa fẹ́ jẹ́ ìkà, òǹrorò àti aláìláàánú bíi ti Sátánì.
Ìhámọ́ra Tí Ọlọ́run Fún Wa Ń Dáàbò Bò Wá
15. Ogun wo là ń jà, kí la sì máa ṣe ká tó lè ṣẹ́gun?
15 Bí Ọlọ́run yóò bá gbà wá lọ́wọ́ Èṣù, a ní láti kọjú ìjà sí agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú. Ká sì tó lè ṣẹ́gun irú ìjà tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ a ní láti “gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun tẹ̀mí wọ̀.” (Éfésù 6:11-18) Lára ìhámọ́ra yìí ni “àwo ìgbàyà ti òdodo.” (Éfésù 6:14) Nígbà tí Sọ́ọ̀lù ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ẹ̀mí mímọ́ kúrò lára rẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 15:22, 23) Ṣùgbọ́n tá a bá ń ṣòdodo tá a sì gbé gbogbo ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run kò ní fi wá sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò wá lọ́wọ́ Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ burúkú tí í ṣe ẹ̀mí èṣù.—Òwe 18:10.
16. Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run máa dáàbò bò wá nìṣó kúrò lọ́wọ́ agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú, kí la ní láti máa ṣe?
16 Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run máa dáàbò bò wá nìṣó kúrò lọ́wọ́ agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú, lára ohun tá a ní láti máa ṣe ni pé ká máa ka Bíbélì ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ déédéé, ká máa fi àwọn ìwé tí “olóòótọ́ ìríjú náà” ń tẹ̀ jáde kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. (Lúùkù 12:42) Ìyẹn á jẹ́ kí àwọn nǹkan tẹ̀mí tó ń gbéni ró máa wà lọ́kàn wa níbàámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Ẹ̀yin ará, ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.”—Fílípì 4:8.
17. Kí ni yóò jẹ́ ká lè máa kéde ìhín rere lọ́nà tó múná dóko?
17 Jèhófà ń jẹ́ ká lè ‘fi ohun ìṣiṣẹ́ ìhìn rere àlàáfíà wọ ẹsẹ̀ wa ní bàtà.’ (Éfésù 6:15) Tá a bá ń kópa nínú ìpàdé ìjọ déédéé, a ó mọ bá a ṣe lè máa kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ó sì máa ń dùn mọ́ wa gan-an ni tá a bá kọ́ àwọn mìíràn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run tí wọ́n sì bọ́ kúrò nínú ìgbèkùn èké! (Jòhánù 8:32) “Idà ẹ̀mí, èyíinì ni, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ṣe pàtàkì gan-an, nítorí pé òun la lè fi já irọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké, tá a sì lè fi dojú “àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” dé. (Éfésù 6:17; 2 Kọ́ríńtì 10:4, 5) Bí a bá mọ Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lò dáadáa, a ó lè máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kò sì ní jẹ́ kí Èṣù lè fi ètekéte mú wa.
18. Kí la ó ṣe ká “bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù”?
18 Ohun tí Pọ́ọ̀lù fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tó sọ nípa ìhámọ́ra tẹ̀mí tó yẹ ká gbé wọ̀ ni: “Ẹ máa bá a lọ ní gbígba agbára nínú Olúwa àti nínú agbára ńlá okun rẹ̀. Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.” (Éfésù 6:10, 11) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “dúró gbọn-in gbọn-in” jẹ mọ́ bí ọmọ ogun ṣe máa ń dúró pa sí ipò rẹ̀ láìsá. Onírúurú ètekéte ni Sátánì ń lò bó ṣe ń gbìyànjú láti da àárín wa rú, láti lú ayédèrú ẹ̀kọ́ mọ́ ẹ̀kọ́ wa àti láti mú ká hùwà àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run, síbẹ̀ a ò jẹ́ kí mìmì kankan mì wá kúrò ní ipò wa nínú ogun tẹ̀mí tá à ń jà. Pàbó ni gbogbo ogun Èṣù ń já sí látẹ̀yìnwá, pàbó ni yóò sì máa já sí!a
Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù, Yóò sì Sá
19. Kí ni ọ̀nà kan tá a lè gbà gbógun ti Èṣù?
19 Ó dájú pé a lè borí nínú ogun tẹ̀mí tá à ń bá Èṣù àti agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú tó wà lábẹ́ rẹ̀ jà. Kò sídìí tó fi yẹ kí jìnnìjìnnì bò wá tìtorí Sátánì, nítorí ohun tí ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù sọ nínú ìwé rẹ̀ ni pé: “Ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Jákọ́bù 4:7) Ọ̀nà kan tá a lè gbà gbógun ti Sátánì àtàwọn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú tó bá a lẹ̀dí àpò pọ̀ ni pé ká má ṣe lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òkùnkùn kankan, ká má ṣe ṣoògùn rárá bó ti wù kó kéré mọ, ká má sì ní àjọṣe kankan pẹ̀lú àwọn tó bá ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ìwé Mímọ́ fi hàn gbangba gbàǹgbà pé ìránṣẹ́ Jèhófà kò gbọ́dọ̀ wá àmì ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí kí wọ́n wòràwọ̀ tàbí kí wọ́n woṣẹ́ tàbí kí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò. Bí ọwọ́ wa bá dí lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run tí ìgbàgbọ́ wa sì lágbára, a ò ní máa bẹ̀rù pé ẹnì kan lè sa oògùn sí wa.—Númérì 23:23; Diutarónómì 18:10-12; Aísáyà 47:12-15; Ìṣe 19:18-20.
20. Báwo la ṣe lè kọjú ìjà sí Èṣù?
20 Ọ̀nà mìíràn tá a tún lè gbà “kọ ojú ìjà sí Èṣù” ni pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà àti ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a ti kọ́ nígbà gbogbo, ká má sì gba Èṣù láyè rárá. Ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ayé àti ti Sátánì wọ̀ gan-an nítorí pé òun ni ọlọ́run ayé. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Ìdí nìyẹn tá a fi ní láti kọ ìwà àti ìṣe ayé, irú bí ìgbéraga, ìmọtara-ẹni-nìkan, ìṣekúṣe, ìwà ipá àti ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì. A mọ̀ pé ńṣe ni Èṣù sá nígbà tí Jésù fi ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ kọjú ìjà sí i nígbà tó wá dán Jésù wò ní aginjù. (Mátíù 4:4, 7, 10, 11) Bákan náà ni Sátánì yóò ṣe gbà pé a ti ṣẹ́gun òun tí yóò sì ‘sá kúrò lọ́dọ̀ wa’ bí a bá fi ara wa sábẹ́ Jèhófà pátápátá tá a sì ń gbàdúrà sí i láti fi hàn pé a gbára lé e. (Éfésù 6:18) Pẹ̀lú ìtìlẹyìn Jèhófà Ọlọ́run àti ti Ọmọ rẹ̀ olùfẹ́, kò sẹ́ni tó lè ṣe ìpalára ayérayé fún wa rárá àti rárá, àní títí kan Èṣù pàápàá!—Sáàmù 91:9-11.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìhámọ́ra ogun tẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, wo Ilé-Ìṣọ́nà May 15, 1992, ojú ìwé 21 sí 23.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Ǹjẹ́ ó yẹ ká bẹ̀rù Sátánì Èṣù?
• Kí nìdí tí Sátánì fi ń dojú inúnibíni kọ àwọn Kristẹni?
• Kí nìdí tá a fi ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ “ẹni burúkú náà”?
• Ọ̀nà wo la lè gbà borí nínú ogun tẹ̀mí tá à ń jà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ayé àtijọ́ tí kì í bẹ̀rù ṣe olóòótọ́ dójú ikú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Èṣù ò lè dènà àjíǹde àwọn tó wà ní ìrántí Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ǹjẹ́ o máa ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run dá ọ nídè kúrò lọ́wọ́ “ẹni burúkú náà”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ǹjẹ́ ò ń gbé “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀”?