Àwọn Wo Ni Òjíṣẹ́ Ọlọ́run Lóde Òní?
“Títóótun wa tẹ́rùntẹ́rùn ń jáde wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ti mú wa tóótun tẹ́rùntẹ́rùn ní tòótọ́ láti jẹ́ òjíṣẹ́ májẹ̀mú tuntun kan.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 3:5, 6.
1, 2. Inú iṣẹ́ wo ni gbogbo Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ti kópa, àmọ́ báwo ni nǹkan ṣe wá yí padà?
NÍ Ọ̀RÚNDÚN kìíní Sànmánì Tiwa, gbogbo Kristẹni ló ń kópa nínú iṣẹ́ pàtàkì kan—ìyẹn ni iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà. Gbogbo wọn pátá la fòróró yàn, tí wọ́n sì jẹ́ òjíṣẹ́ májẹ̀mú tuntun náà. Àwọn kan tún ní àfikún ẹrù iṣẹ́, irú bíi kíkọ́ni nínú ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 12:27-29; Éfésù 4:11) Ẹrù iṣẹ́ wíwúwo wà fún àwọn òbí láti gbé nínú ìdílé. (Kólósè 3:18-21) Síbẹ̀, gbogbo wọn ló ń kópa nínú iṣẹ́ pàtàkì ti wíwàásù náà. Nínú èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ táa fi kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni, di·a·ko·niʹa ni ẹrù iṣẹ́ yìí jẹ́ —ìyẹn iṣẹ́ ìsìn, tàbí iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan.—Kólósè 4:17.
2 Bí àkókò ti ń lọ, nǹkan yí padà. Ẹgbẹ́ kan wá dìde, táa mọ̀ sí ẹgbẹ́ àlùfáà, àwọn tí wọ́n gbà pé àwọn nìkan ló láǹfààní láti wàásù. (Ìṣe 20:30) Ìwọ̀nba kéréje làwọn àlùfáà náà jẹ́ láàárín àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni. Àwọn tó pọ̀ jù lọ la wá mọ̀ sí ọmọ ìjọ. Nítorí pé wọ́n ti kọ́ àwọn ọmọ ìjọ pé àwọn iṣẹ́ kan ló wà tó pọndandan fún wọn láti ṣe, títí kan owó dídá láti gbọ́ bùkátà àwọn àlùfáà, ọ̀pọ̀ jù lọ ọmọ ìjọ ni kò wá mọ̀ ju kí wọ́n kàn máa fi etí lásán gbọ́ ìwàásù.
3, 4. (a) Báwo làwọn èèyàn ṣe ń di òjíṣẹ́ ní Kirisẹ́ńdọ̀mù? (b) Ta ni wọ́n kà sí òjíṣẹ́ ní Kirisẹ́ńdọ̀mù, èé sì ti ṣe tí nǹkan fi yàtọ̀ láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
3 Àwọn àlùfáà náà sọ pé òjíṣẹ́ làwọn (a túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà òjíṣẹ́ látinú ọ̀rọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì náà, minister, tó jẹ́ ìtumọ̀ èdè Látìn fún di·aʹko·nos, “ìránṣẹ́”).a Nítorí ìdí èyí, wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ gboyè láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tàbí àwọn ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ àlùfáà, tí wọ́n sì ń fi wọ́n joyè. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The International Standard Bible Encyclopedia sọ pé: “‘Oyè jíjẹ’ àti ‘ìfinijoyè’ wulẹ̀ tọ́ka sí àkànṣe ipò kan tí wọ́n fi àwọn òjíṣẹ́ tàbí àwọn àlùfáà sí nípasẹ̀ ààtò kan tí wọ́n fọwọ́ sí lábẹ́ òfin, pẹ̀lú ìtẹnumọ́ lórí àṣẹ tí wọ́n ní láti kéde Ọ̀rọ̀ náà tàbí láti darí àwọn àkànṣe ààtò ìsìn, tàbí láti ṣe méjèèjì.” Ta ló ń fi àwọn òjíṣẹ́ náà joyè? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Láwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó máa ń ní àwọn bíṣọ́ọ̀bù, òjíṣẹ́ tó ń fini joyè sábà máa ń jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù kan. Láwọn ṣọ́ọ̀ṣì Presbyterian, àwọn òjíṣẹ́ ìjọ Presbyterian ló máa ń fini joyè.”
4 Nípa bẹ́ẹ̀, àǹfààní jíjẹ́ òjíṣẹ́ ti di èyí tí wọ́n pààlà sí gan-an nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kí ló fà á? Ìdí ni pé kò rí bẹ́ẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní.
Àwọn Wo Gan-an Ni Òjíṣẹ́ Ọlọ́run?
5. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, àwọn wo ló wà lára àwọn tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́?
5 Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, gbogbo àwọn olùjọ́sìn Jèhófà—lọ́run àti lórí ilẹ̀ ayé—ni òjíṣẹ́. Àwọn áńgẹ́lì ṣe ìránṣẹ́ fún Jésù. (Mátíù 4:11; 26:53; Lúùkù 22:43) Àwọn áńgẹ́lì tún “ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà.” (Hébérù 1:14; Mátíù 18:10) Jésù jẹ́ òjíṣẹ́. Ó sọ pé: “Ọmọ ènìyàn . . . wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́.” (Mátíù 20:28; Róòmù 15:8) Nítorí náà, níwọ̀n bí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti ní láti “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí,” kò yáni lẹ́nu pé àwọn náà gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́.—1 Pétérù 2:21.
6. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́?
6 Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù gòkè re ọ̀run, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn tí ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn—ìyẹn àwọn òjíṣẹ́. Àwọn tí wọ́n bá sọ di ọmọ ẹ̀yìn tuntun gbọ́dọ̀ kọ́ bí a ṣe ń pa gbogbo ohun tí Jésù pa láṣẹ mọ́, títí kan àṣẹ tó pa pé kí wọ́n lọ máa sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, àgbà tàbí ọmọdé, ẹni tó bá jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi ní ti tòótọ́ yóò jẹ́ òjíṣẹ́.—Jóẹ́lì 2:28, 29.
7, 8. (a) Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló fi hàn pé gbogbo Kristẹni tòótọ́ ni òjíṣẹ́? (b) Àwọn ìbéèrè wo la gbé dìde nípa fífi ọlá àṣẹ yanni?
7 Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó wà níbẹ̀, tọkùnrin, tobìnrin, ló kópa nínú sísọ “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run.” (Ìṣe 2:1-11) Láfikún sí i, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọkàn-àyà ni a fi ń lo ìgbàgbọ́ fún òdodo, ṣùgbọ́n ẹnu ni a fi ń ṣe ìpolongo ní gbangba fún ìgbàlà.” (Róòmù 10:10) Pọ́ọ̀lù ò darí ọ̀rọ̀ yẹn sí kìkì ẹgbẹ́ àlùfáà nìkan, àmọ́, ó darí rẹ̀ “sí gbogbo àwọn tí ó wà ní Róòmù gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún Ọlọ́run.” (Róòmù 1:1, 7) Bákan náà, gbogbo ‘àwọn ẹni mímọ́ ní Éfésù àti àwọn olùṣòtítọ́ ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù’ ni “ẹsẹ̀” wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí “tí a fi ohun ìṣiṣẹ́ ìhìn rere àlàáfíà wọ̀ ní bàtà.” (Éfésù 1:1; 6:15) Gbogbo àwọn tó sì gbọ́ lẹ́tà táa kọ sí àwọn ará Hébérù ló ní láti ‘di ìpolongo ìrètí wọn ní gbangba mú ṣinṣin láìmikàn.’—Hébérù 10:23.
8 Àmọ́ o, ìgbà wo ni ẹnì kan máa ń di òjíṣẹ́? Lọ́rọ̀ mìíràn, ìgbà wo la fi ọlá àṣẹ yàn án? Ta ló sì yàn án?
Ìgbà Wo Là Ń Fi Ọlá Àṣẹ Yanni Gẹ́gẹ́ Bí Òjíṣẹ́?
9. Ìgbà wo la fàṣẹ yan Jésù, ta ló sì yàn án?
9 Gbé àpẹẹrẹ Jésù Kristi yẹ̀ wò, tí o bá fẹ́ mọ ìgbà tí a ń yan ẹnì kan gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ àti ẹni tó yàn án. Kò ní ìwé ẹ̀rí ìfinijoyè, bẹ́ẹ̀ ni kò gboyè jáde láwọn ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ àlùfáà láti fẹ̀rí hàn pé ó jẹ́ òjíṣẹ́, kì í sì í ṣe ọmọ aráyé ló yàn án. Èé ṣe táa fi wá ń sọ pé òjíṣẹ́ ni? Nítorí pé àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí tí Aísáyà sọ ní ìmúṣẹ sí i lára: “Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi, nítorí tí ó fòróró yàn mí láti polongo ìhìn rere.” (Lúùkù 4:17-19; Aísáyà 61:1) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn mú iyèméjì kúrò pé ṣe la yan Jésù láti sọ ìhìn rere náà. Ta ló yàn án? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹ̀mí Jèhófà ló fòróró yàn Jésù láti ṣe iṣẹ́ náà, ó ṣe kedere pé Jèhófà Ọlọ́run ló fi ọlá àṣẹ yàn án. Ìgbà wo lèyí ṣẹlẹ̀? Ńṣe ni ẹ̀mí Jèhófà dìídì bà lé Jésù nígbà tó ṣe batisí. (Lúùkù 3:21, 22) Nítorí náà, ìgbà ìbatisí rẹ̀ la fàṣẹ yàn án.
10. Ta ló ń mú kí Kristẹni òjíṣẹ́ kan di ẹni tí ó “tóótun tẹ́rùntẹ́rùn”?
10 Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní ńkọ́? Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ipò táa yan àwọn náà sí gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ ti wá. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Títóótun wa tẹ́rùntẹ́rùn ń jáde wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ti mú wa tóótun tẹ́rùntẹ́rùn ní tòótọ́ láti jẹ́ òjíṣẹ́ májẹ̀mú tuntun kan.” (2 Kọ́ríńtì 3:5, 6) Báwo ni Jèhófà ṣe ń mú kí àwọn olùjọsìn rẹ̀ tóótun láti jẹ́ òjíṣẹ́? Gbé àpẹẹrẹ ti Tímótì yẹ̀ wò, ẹni tí Pọ́ọ̀lù pè ní “òjíṣẹ́ Ọlọ́run nínú ìhìn rere nípa Kristi.”—1 Tẹsalóníkà 3:2.
11, 12. Báwo ni Tímótì ṣe tẹ̀ síwájú dórí dídi òjíṣẹ́?
11 Àwọn ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí tí a kọ sí Tímótì ràn wá lọ́wọ́ láti lóye bó ṣe di òjíṣẹ́: “Àmọ́ ṣá o, ìwọ, máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́, ní mímọ ọ̀dọ̀ àwọn tí o ti kọ́ wọn àti pé láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.” (2 Tímótì 3:14, 15) Ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ Tímótì, tí yóò sún un láti polongo ní gbangba ni ìmọ̀ Ìwé Mímọ́. Ṣé kìkì dídánìkan kà á ló nílò láti ṣe èyí? Rárá o. Tímótì nílò ìrànlọ́wọ́ láti jèrè ìmọ̀ pípéye àti òye tẹ̀mí nípa ohun tó ń kà. (Kólósè 1:9) Nípa bẹ́ẹ̀, ṣe la “yí” Tímótì “lérò padà láti gbà gbọ́.” Níwọ̀n ìgbà tó ti mọ Ìwé Mímọ́ “láti ìgbà ọmọdé jòjòló,” ó ní láti jẹ́ ìyá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ àgbà ló ti kọ́kọ́ fún un nítọ̀ọ́ni, níwọ̀n bí bàbá rẹ̀ kì í ti í ṣe onígbàgbọ́.—2 Tímótì 1:5.
12 Àmọ́ ṣá o, àwọn nǹkan mìíràn tún wà lára ohun tó mú kí Tímótì di òjíṣẹ́. Ohun kan ni pé, bíbá àwọn Kristẹni tó ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ìjọ tó wà nítòsí kẹ́gbẹ́ ti ní láti fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun. Báwo la ṣe mọ̀? Nítorí pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ pàdé Tímótì pàá, “àwọn ará ní Lísírà àti Íkóníónì . . . ròyìn” ọ̀dọ́kùnrin náà “dáadáa.” (Ìṣe 16:2) Ìyẹn nìkan kọ́ o, láyé ọjọ́un, àwọn arákùnrin kan máa ń kọ lẹ́tà sáwọn ìjọ kí wọ́n lè fún wọn lókun. Àwọn alábòójútó sì máa ń bẹ̀ wọ́n wò láti gbé wọn ró. Irú àwọn ìpèsè wọ̀nyẹn ran àwọn Kristẹni bíi Tímótì lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.—Ìṣe 15:22-32; 1 Pétérù 1:1.
13. Ìgbà wo la yan Tímótì gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́, kí sì nìdí tí o fi lè sọ pé ìtẹ̀síwájú rẹ̀ nípa tẹ̀mí kò dópin síbẹ̀?
13 Lójú àṣẹ tí Jésù pa tó wà nínú Mátíù 28:19, 20, ó lè dá wa lójú pé láwọn àkókò kan, ìgbàgbọ́ Tímótì sún un láti fara wé Jésù, kó sì ṣe batisí. (Mátíù 3:15-17; Hébérù 10:5-9) Èyí jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn bí Tímótì ṣe fi tọkàntọkàn ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Ìgbà tí Tímótì ṣe batisí tán ló di òjíṣẹ́. Láti ìgbà yẹn lọ, ìgbésí ayé rẹ̀, okun rẹ̀, àti gbogbo ohun tó ní di ti Ọlọ́run. Èyí jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn rẹ̀, “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀.” Àmọ́ ṣá o, Tímótì kò wá tìtorí ìyẹn jókòó gẹlẹtẹ. Ó ń tẹ̀ síwájú láti dàgbà nípa tẹ̀mí, títí ó fi di Kristẹni òjíṣẹ́ kan tó dàgbà dénú. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tímọ́tímọ́ tí Tímótì ní pẹ̀lú àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú bíi Pọ́ọ̀lù, ìdákẹ́kọ̀ọ́ tiẹ̀ fúnra rẹ̀, àti bó ṣe fi ìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà.—1 Tímótì 4:14; 2 Tímótì 2:2; Hébérù 6:1.
14. Lóde òní, báwo ni ẹnì kan tó “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” ṣe ń tẹ̀ síwájú dórí dídi òjíṣẹ́?
14 Bákan náà ni fífi ọlá àṣẹ yanni fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ṣe rí lóde òní. A máa ń lo ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti ran ẹnì kan tó “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àtàwọn ète rẹ̀. (Ìṣe 13:48) Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀, ó sì ń gbàdúrà àtọkànwá sí Ọlọ́run. (Sáàmù 1:1-3; Òwe 2:1-9; 1 Tẹsalóníkà 5:17, 18) Yóò bá àwọn onígbàgbọ́ mìíràn kẹ́gbẹ́, yóò sì tún máa jàǹfààní àwọn ìpèsè àti ètò tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń ṣe. (Mátíù 24:45-47; Òwe 13:20; Hébérù 10:23-25) Nípa bẹ́ẹ̀, yóò máa tẹ̀ síwájú nípa títẹ̀lé ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ táa là lẹ́sẹẹsẹ.
15. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹnì kan bá ṣe batisí? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
15 Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ti ní ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run, tó sì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú ẹbọ ìràpadà náà, yóò fẹ́ ya ara rẹ̀ sí mímọ́ pátápátá fún Baba rẹ̀ ọ̀run. (Jòhánù 14:1) Nínú àdúrà rẹ̀ ni yóò ti ṣe ìyàsímímọ́ yẹn, ẹ̀yìn ìyẹn ni yóò wá ṣe batisí tó jẹ́ àmì tí gbogbo ènìyàn fi máa mọ̀ pé ó ti ń gbé ìgbésẹ̀ yẹn ní ìkọ̀kọ̀. Batisí tó ṣe ló jẹ́ àmì yíyàn tí a fi ọlá àṣẹ yàn án, nítorí pé ìgbà yẹn la mọ̀ ọ́n sí ìránṣẹ́, di·aʹko·nos, tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ pátápátá fún Ọlọ́run. Ó gbọ́dọ̀ ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé. (Jòhánù 17:16; Jákọ́bù 4:4) Ó ti fi gbogbo ara rẹ̀ “fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà” láìkù síbì kankan. (Róòmù 12:1)b Òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni, tó ń fara wé Kristi.
Kí Ni Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni?
16. Kí ni àwọn kan lára ojúṣe Tímótì gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́?
16 Kí ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ Tímótì ní nínú? Tímótì ní àwọn ojúṣe àrà ọ̀tọ̀ tó ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń bá Pọ́ọ̀lù rin ìrìn àjò. Nígbà tí Tímótì di alàgbà, ó ṣe iṣẹ́ àṣekára nínú kíkọ́ni àti fífún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lókun. Àmọ́ apá tó ṣe kókó jù lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, bíi ti Jésù àti Pọ́ọ̀lù, ni wíwàásù ìhìn rere àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 4:23; 1 Kọ́ríńtì 3:5) Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Àmọ́ ṣá o, ìwọ, máa pa agbára ìmòye rẹ mọ́ nínú ohun gbogbo, jìyà ibi, ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere, ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún.”—2 Tímótì 4:5.
17, 18. (a) Inú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wo ni àwọn Kristẹni ti ń kópa? (b) Báwo ni iṣẹ́ wíwàásù ti ṣe pàtàkì tó fún Kristẹni òjíṣẹ́ kan?
17 Bákan náà ló ṣe rí pẹ̀lú àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ lóde òní. Wọ́n ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba, iṣẹ́ kan tó jẹ́ ti ajíhìnrere, wọ́n ń tọ́ka àwọn ẹlòmíràn sí ìgbàlà lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ Jésù, wọ́n sì ń kọ́ àwọn ọlọ́kàn tútù láti máa ké pe orúkọ Jèhófà. (Ìṣe 2:21; 4:10-12; Róòmù 10:13) Wọ́n ń fẹ̀rí hàn látinú Bíbélì pé Ìjọba náà ni ìrètí kan ṣoṣo fún aráyé tí ìyà ń jẹ, wọ́n sì ń fi hàn pé lákòókò táa wà yìí pàápàá, àwọn nǹkan lè sunwọ̀n sí i táa bá ń gbé ìgbésí ayé tó bá àwọn ìlànà Ọlọ́run mu. (Sáàmù 15:1-5; Máàkù 13:10) Àmọ́ ṣá o, ohun tí Kristẹni òjíṣẹ́ ń wàásù kì í ṣe báa ṣe lè fi àwọn ìlànà ẹ̀sìn Kristẹni tún ìlú ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń kọ́ni pé ‘fífọkànsin Ọlọ́run ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀.’—1 Tímótì 4:8.
18 Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn òjíṣẹ́ ló tún ń sìn láwọn ọ̀nà mìíràn, ti Kristẹni kan sì lè yàtọ̀ sí ti òmíràn. Ọ̀pọ̀ ló ní àwọn ẹrù iṣẹ́ ìdílé. (Éfésù 5:21-6:4) Àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní àwọn ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ. (1 Tímótì 3:1, 12, 13; Títù 1:5; Hébérù 13:7) Ọ̀pọ̀ Kristẹni ló ń ṣèrànwọ́ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn kan ní àǹfààní àgbàyanu ti ṣíṣe iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùyọ̀ǹda ara ẹni ní ọ̀kan lára àwọn Bẹ́tẹ́lì ti Watch Tower Society. Bó ti wù kó rí, gbogbo Kristẹni òjíṣẹ́ ló ń kópa nínú wíwàásù ìhìn rere náà. Kò sẹ́ni tí kò kàn. Kíkópa nínú iṣẹ́ yìí ló ń fi ẹnì kan hàn gbangba pé ó jẹ́ ojúlówó Kristẹni òjíṣẹ́.
Irú Ẹ̀mí Tí Kristẹni Òjíṣẹ́ Kan Ní
19, 20. Irú ẹ̀mí wo ló yẹ kí àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ ní?
19 Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn òjíṣẹ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù ló máa ń retí pé káwọn èèyàn máa bọlá àrà ọ̀tọ̀ fáwọn, wọ́n sì máa ń fún ara wọn ní àwọn orúkọ oyè bí “ẹni ọ̀wọ̀” àti “fadá.” Àmọ́, àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ mọ̀ pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ni ọ̀wọ̀ ńlá tọ́ sí. (1 Tímótì 2:9, 10) Kò sí Kristẹni òjíṣẹ́ kan tó fẹ́ irú ọ̀wọ̀ gíga bẹ́ẹ̀ tàbí tó ń nàgà láti gba àwọn orúkọ oyè àrà ọ̀tọ̀ bẹ́ẹ̀. (Mátíù 23:8-12) Ó mọ̀ pé “iṣẹ́ ìsìn” ni ìtumọ̀ di·a·ko·niʹa gan-an. Ọ̀rọ̀ ìṣe tó so pọ̀ mọ́ ọn ni wọ́n sábà máa ń lò nínú Bíbélì nígbà tọ́rọ̀ bá kan àwọn iṣẹ́ tara ẹni, bíi gbígbé oúnjẹ sórí tábìlì. (Lúùkù 4:39; 17:8; Jòhánù 2:5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lílò tí a lò ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí ju ìyẹn lọ, síbẹ̀ ìránṣẹ́ ṣì ni di·aʹko·nos kan jẹ́.
20 Nítorí náà, kò sí ìdí fún Kristẹni òjíṣẹ́ kankan láti jọ ara rẹ̀ lójú. Ojúlówó Kristẹni òjíṣẹ́—kódà àwọn tó ní ẹrù iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nínú ìjọ pàápàá—jẹ́ ẹrú onírẹ̀lẹ̀. Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín, ẹnì yòówù tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú yín.” (Mátíù 20:26, 27) Nígbà tí Jésù ń fi irú ẹ̀mí tó yẹ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní hàn wọ́n, ó wẹ ẹsẹ̀ wọn, ó ṣe iṣẹ́ tí ẹrú tí ó rẹlẹ̀ jù lọ máa ń ṣe. (Jòhánù 13:1-15) Iṣẹ́ ìsìn onírẹ̀lẹ̀ gbáà mà lèyí o! Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ ń fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ sin Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi. (2 Kọ́ríńtì 6:4; 11:23) Wọ́n ń fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú hàn ní sísin ẹnì kìíní kejì wọn. Nígbà tí wọ́n bá sì ń wàásù ìhìn rere náà, wọ́n ń fi àìmọtara ẹni nìkan sin àwọn aládùúgbò wọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́.—Róòmù 1:14, 15; Éfésù 3:1-7.
Fara Dà Á Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́
21. Báwo la ṣe san èrè fún Pọ́ọ̀lù nítorí pé ó fara dà á nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́?
21 Fún Pọ́ọ̀lù, jíjẹ́ òjíṣẹ́ gba ìfaradà. Ó sọ fún àwọn ará Kólósè pé òun jìyà púpọ̀ kí òun lè wàásù ìhìn rere náà fún wọn. (Kólósè 1:24, 25) Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ ló tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà tí wọ́n sì di òjíṣẹ́ nítorí pé ó fara dà á. Wọ́n di ẹni tí a bí gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ọlọ́run àti àwọn arákùnrin Jésù Kristi, pẹ̀lú ìrètí dídi àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run. Ẹ ò rí èrè ńlá tí ìfaradà mú wá!
22, 23. (a) Èé ṣe tí àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ fi nílò ìfaradà lóde òní? (b) Kí ni èso àgbàyanu tí ìfaradà Kristẹni ń mú jáde?
22 Ìfaradà pọndandan lónìí fún àwọn tó jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run ní ti gidi. Ọ̀pọ̀ ló ń bá àìsàn tàbí àwọn ìrora ọjọ́ ogbó wọ̀yá ìjà lójoojúmọ́. Àwọn òbí ń ṣe iṣẹ́ àṣekára—ọ̀pọ̀ lára wọn ni kò ní ẹnì kejì—tí wọn ó jọ tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà. Tìgboyàtìgboyà sì làwọn ọmọ tó wà nílé ìwé fi ń dènà àwọn ìwà búburú tó yí wọn ká. Ọ̀pọ̀ Kristẹni ni ipò ìṣúnná owó ò rọrùn fún rárá. Ọ̀pọ̀ la sì ń ṣe inúnibíni sí tàbí tí wọ́n ń dojú kọ ìṣòro nítorí “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” lóde òní! (2 Tímótì 3:1) Òótọ́ ọ̀rọ̀ ni o, àwọn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́fà òjíṣẹ́ Jèhófà lóde òní lè sọ bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Lọ́nà gbogbo, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run, nípa ìfaradà púpọ̀.” (2 Kọ́ríńtì 6:4) Àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ kò juwọ́ sílẹ̀. Ní ti tòótọ́, ó yẹ ká yìn wọ́n fún ìfaradà wọn.
23 Láfikún sí i, bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti Pọ́ọ̀lù, ìfaradà máa ń mú àgbàyanu èso jáde. Nípa fífaradà á, àjọṣe tímọ́tímọ́ táa ní pẹ̀lú Jèhófà kò ní yingin, a ó sì máa mú inú rẹ̀ dùn. (Òwe 27:11) A ń fún ìgbàgbọ́ tiwa fúnra wa lókun, a sì ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn, èyí tó ń fi kún ẹgbẹ́ àwọn ará Kristẹni. (1 Tímótì 4:16) Jèhófà ti mẹ́sẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ dúró, ó sì ti bù kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn láwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. Látàrí èyí, a ti kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà jọ, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn sì ní ìrètí tí ń fini lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn ó gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 23:43; Ìṣípayá 14:1) Ní ti tòótọ́, iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ń fi àánú Jèhófà hàn. (2 Kọ́ríńtì 4:1) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa fojú ribiribi wò ó, ká sì dúpẹ́ pé èso rẹ̀ yóò dúró títí láé.—1 Jòhánù 2:17.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ náà “díákónì” wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà di·aʹko·nos, òṣìṣẹ́ kan nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Láwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí àwọn obìnrin ti lè jẹ díákónì, wọ́n lè pè wọ́n ní díákónì obìnrin.
b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni Róòmù 12:1 tọ́ka sí ní pàtó, ìlànà tó wà níbẹ̀ kan “àwọn àgùntàn mìíràn” pẹ̀lú. (Jòhánù 10:16) Àwọn wọ̀nyí “ti dara pọ̀ mọ́ Jèhófà láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un àti láti nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà, láti lè di ìránṣẹ́ fún un.”—Aísáyà 56:6.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Nínú iṣẹ́ wo ni gbogbo Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ti kópa?
• Ìgbà wo la yan Kristẹni kan gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́, ta ló sì yàn án?
• Irú ẹ̀mí wo ló yẹ kí Kristẹni òjíṣẹ́ kan ní?
• Èé ṣe tó fi yẹ kí Kristẹni òjíṣẹ́ kan ní ìfaradà nígbà tó bá dojú kọ àwọn ìṣòro?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Àtìgbà ọmọdé jòjòló la ti kọ́ Tímótì ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó di òjíṣẹ́ tí a fi ọlá àṣẹ yàn nígbà tó ṣe batisí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Batisí fi ìyàsímímọ́ fún Ọlọ́run hàn, ó sì sàmì sí yíyàn tí a fi ọlá àṣẹ yan ẹnì kan gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ múra tán láti sìn