Jehófà Ni “Olùsẹ̀san Fún Àwọn Tí Ń Fi Taratara Wá A”
“Ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—HÉBÉRÙ 11:6.
1, 2. Kí ló lè mú káwọn kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa ní èrò òdì nípa ara wọn?
ARÁBÌNRIN kan tó ń jẹ́ Barbaraa sọ pé: “Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgbọ̀n ọdún báyìí tí mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ kò tíì fìgbà kan rí ṣe mí bíi pé mo yẹ lẹ́ni tí wọ́n ń pè bẹ́ẹ̀.” Ó tún sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ṣe aṣáájú ọ̀nà mo sì ti láǹfààní láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìsìn pàtàkì mìíràn, síbẹ̀ kò sí ọ̀kankan nínú wọn tó jọ pé ó tó láti mú mi gbà nínú ọkàn mi pé mo yẹ lẹ́ni tí wọ́n ń pè ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Gbólóhùn tí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Keith sọ náà fara jọ èyí, ó ní: “Àwọn ìgbà míì máa ń wà tó máa dà bíi pé mi ò já mọ́ nǹkan kan nítorí pé ọ̀pọ̀ ìdí ló fi yẹ káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà jẹ́ aláyọ̀, àmọ́ èmi ò láyọ̀. Èyí máa ń jẹ́ kí n máa dá ara mi lẹ́bi, ńṣe ló sì wá mú kí ọ̀rọ̀ náà túbọ̀ burú sí i.”
2 Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ láyé àtijọ́ àti láyé òde òní ti ní irú àròdùn ọkàn kan náà. Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ìwọ náà bẹ́ẹ̀ nígbà míì? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe lo máa ń tinú ìṣòro kan bọ́ sínú òmíràn, tó sì jọ pé àwọn Kristẹni mìíràn ń gbádùn ìgbésí ayé, bíi pé wọn ò níṣòro kankan, wọ́n sì láyọ̀. Èyí lè mú kó o máa rò pé Jèhófà ò tẹ́wọ́ gbà ọ́ tàbí pé o kò yẹ lẹ́ni tí Jèhófà ń fiyè sí. Má ṣe rò bẹ́ẹ̀. Bíbélì mú un dá wa lójú pé: “[Jèhófà] kò tẹ́ńbẹ́lú bẹ́ẹ̀ ni kò kórìíra ìṣẹ́ ẹni tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́; kò sì fi ojú pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí ó sì kígbe pè é fún ìrànlọ́wọ́, ó gbọ́.” (Sáàmù 22:24) Gbólóhùn yìí tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà fi hàn pé kì í ṣe pé Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nìkan ni, ó tún ń san èrè fún wọn.
3. Kí nìdí táwa náà ò fi bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro ètò àwọn nǹkan yìí?
3 Kò sẹ́nì kankan tó bọ́ lọ́wọ́ àwọn wàhálà ètò àwọn nǹkan yìí, kódà, àwọn èèyàn Jèhófà pàápàá ò bọ́. Inú ayé tí Sátánì Èṣù tó jẹ́ olórí ọ̀tá Jèhófà ń ṣàkóso là ń gbé. (2 Kọ́ríńtì 4:4; 1 Jòhánù 5:19) Dípò táwọn èèyàn Jèhófà ì bá fi máa rí ààbò lọ́nà ìyanu, àwọn gan-an ni Sátánì dájú sọ. (Jóòbù 1:7-12; Ìṣípayá 2:10) Nítorí náà títí dìgbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́rùn, ó di dandan ká máa ní “ìfaradà lábẹ́ ìpọ́njú,” ká “máa ní ìforítì nínú àdúrà,” ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà bìkítà nípa wa. (Róòmù 12:12) A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn ìṣòro inú ayé yìí mú wa ronú pé Jèhófà Ọlọ́run wa kò nífẹ̀ẹ́ wa!
Àpẹẹrẹ Àwọn Tó Ní Ìfaradà Láyé Ọjọ́un
4. Sọ díẹ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n fara da àwọn ìṣòro tí ń kó ìbànújẹ́ báni.
4 Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nígbà àtijọ́ ló ní àwọn ìṣòro tó ń kó ìbànújẹ́ bá wọn tí wọ́n sì ní láti fara dà á. Bí àpẹẹrẹ, Hánà ní “ìkorò ọkàn” nítorí pé kò bímọ, ojú tó sì fi wo ìṣòro rẹ̀ yìí ni pé Ọlọ́run ti gbàgbé òun. (1 Sámúẹ́lì 1:9-11) Nígbà tí Jésíbẹ́lì ayaba ń lépa Èlíjà lójú méjèèjì láti gbẹ̀mí rẹ̀, ẹ̀rù ba Èlíjà ó sì sọ nínú àdúrà rẹ̀ sí Jèhófà pé: “Ó tó gẹ́ẹ́! Wàyí o, Jèhófà, gba ọkàn mi kúrò, nítorí èmi kò sàn ju àwọn baba ńlá mi.” (1 Àwọn Ọba 19:4) Ó sì dájú pé àìpé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ní láti bà á lọ́kàn jẹ́ gan-an débi tó fi sọ pé: “Nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi.” Ó tún sọ pé: “Èmi abòṣì ènìyàn!” (Róòmù 7:21-24)
5. (a) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà san èrè fún Hánà, Èlíjà, àti Pọ́ọ̀lù? (b) Ìtùnú wo la lè rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nígbà tá a bá ń ní àròdùn ọkàn?
5 Lóòótọ́ la mọ̀ pé Hánà, Èlíjà, àti Pọ́ọ̀lù ní ìfaradà bí wọ́n ti ń sin Jèhófà, ó sì san èrè fún wọn lọ́pọ̀lọpọ̀. (1 Sámúẹ́lì 1:20; 2:21; 1 Àwọn Ọba 19:5-18; 2 Tímótì 4:8) Síbẹ̀, oríṣiríṣi nǹkan tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀dá làwọn náà kojú rẹ̀, lára wọn ni ìbànújẹ́, àìnírètí àti ìbẹ̀rù. Nítorí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu táwa náà bá ń ní àròdùn ọkàn nígbà míì. Àmọ́ kí lo lè ṣe nígbà táwọn ìṣòro ìgbésí ayé bá mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó lọ́kàn rẹ pé bóyá ni Jèhófà tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ? O lè rí ìtùnú látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a jíròrò lórí gbólóhùn tí Jésù sọ pé Jèhófà mọ iye ‘gbogbo irun orí rẹ.’ (Mátíù 10:30) Gbólóhùn tó ń fúnni níṣìírí yìí fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gidigidi. Tún rántí àkàwé tí Jésù ṣe nípa àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́. Bó bá jẹ́ pé kò sí ọ̀kankan lára àwọn ẹyẹ kéékèèké yìí tó lè já bọ́ lulẹ̀ kí Jèhófà má mọ̀, kí nìdí tí kò fi wá ní rí ìṣòro rẹ?
6. Báwo ni Bíbélì ṣe lè jẹ́ orísun ìrànwọ́ fáwọn tó ní ìbànújẹ́ ọkàn?
6 Ṣé lóòótọ́ ni àwa ẹ̀dá èèyàn aláìpé lè ṣeyebíye lójú Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá alágbára gíga jù lọ? Bẹ́ẹ̀ ni! Kódà, ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì mú èyí dá wa lójú. Bá a bá ń ronú lórí irú àwọn ẹsẹ Bíbélì bẹ́ẹ̀ nígbà gbogbo, yóò ṣeé ṣe fún wa láti sọ gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà ṣe sọ pé: “Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú tìrẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.” (Sáàmù 94:19) Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ lára àwọn gbólóhùn tó ń tuni nínú tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹ̀ wò, èyí tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ rí i pé a ṣeyebíye lójú Ọlọ́run, àti pé yóò bù kún wa bá a ti ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nìṣó.
“Àkànṣe Dúkìá” fún Jèhófà
7. Àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ́ ìṣírí wo ni Jèhófà tipasẹ̀ Málákì sọ fún orílẹ̀-èdè kan tó bà jẹ́ bàlùmọ̀?
7 Ní ọ̀rúndún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù wà nínú ipò kan tó bani nínú jẹ́. Àwọn àlùfáà ń gba ẹran tí kò bójú mu rárá wọ́n sì ń fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ Jèhófà. Àwọn onídàájọ́ ń ṣojúsàájú. Ìbẹ́mìílò, irọ́ pípa, èrú ṣíṣe àti panṣágà gbalẹ̀ kan. (Málákì 1:8; 2:9; 3:5) Málákì wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ jíjọnilójú kan nípa orílẹ̀-èdè tó ti bà jẹ́ bàlùmọ̀ tí kò sì nítìjú yìí. Ohun tó sọ ni pé, nígbà tó bá yá, Jèhófà yóò dá àwọn èèyàn rẹ̀ padà, wọ́n á sì tún rí ojú rere rẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “‘Dájúdájú, wọn yóò sì di tèmi,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘ní ọjọ́ náà nígbà tí èmi yóò mú àkànṣe dúkìá wá. Èmi yóò sì fi ìyọ́nú hàn sí wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń fi ìyọ́nú hàn sí ọmọ rẹ̀ tí ń sìn ín.’”—Málákì 3:17.
8. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìlànà tó wà ní Málákì 3:17 kan ogunlọ́gọ̀ ńlá?
8 Àsọtẹ́lẹ̀ Málákì tún ń nímùúṣẹ lọ́jọ́ tòní, ìmúṣẹ náà sì ní í ṣe pẹ̀lú àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn tí wọ́n para pọ̀ di orílẹ̀-èdè tẹ̀mí tí gbogbo wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì. “Àkànṣe dúkìá” tàbí “àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní” ni orílẹ̀-èdè yẹn jẹ́ fún Jèhófà ní tòótọ́. (1 Pétérù 2:9) Àsọtẹ́lẹ̀ Málákì tún lè jẹ́ ìṣírí fáwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí wọ́n “dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, [tí] wọ́n wọ aṣọ funfun.” (Ìṣípayá 7:4, 9) Wọ́n di agbo kan pẹ̀lú àwọn ẹni àmì òróró, wọ́n sì wà lábẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn kan ṣoṣo, Jésù Kristi.—Jòhánù 10:16.
9. Kí nìdí táwọn èèyàn Jèhófà fi jẹ́ “àkànṣe dúkìá” fún un?
9 Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó pinnu láti sìn ín? Gẹ́gẹ́ bí Málákì 3:17 ṣe sọ, ojú tí bàbá tó nífẹ̀ẹ́ fi máa ń wo ọmọ rẹ̀ ló fi ń wò wọ́n. Sì wá wo àwọn ọ̀rọ̀ ìwúrí tó fi ṣàpèjúwe àwọn èèyàn rẹ̀. Ó pè wọ́n ní “àkànṣe dúkìá.” Ohun táwọn Bíbélì mìíràn pe gbólóhùn yìí ni, “tèmi gan-an,” “ohun ìní mi tó ṣeyebíye jù lọ,” àti “ohun tí mo ṣìkẹ́.” Kí ló lè mú kí Jèhófà ka àwọn tó ń sìn ín sẹ́ni pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Ìdí kan ni pé, ó jẹ́ Ọlọ́run tó máa ń fi ìmọrírì hàn. (Hébérù 6:10) Ó máa ń sún mọ́ àwọn tó bá ń sìn ín látọkànwá, wọ́n sì ṣe pàtàkì lójú rẹ̀.
10. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀?
10 Ǹjẹ́ o ní ohun ìní kan tó ṣeyebíye lójú rẹ tó o kà sí àkànṣe dúkìá? Ǹjẹ́ o kì í sa gbogbo ipá rẹ láti dáàbò bo nǹkan náà? Bí Jèhófà ṣe ń ṣe sí “àkànṣe dúkìá” rẹ̀ nìyẹn. Òótọ́ ni pé kì í gba àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ gbogbo ìṣòro ìgbésí ayé àtàwọn nǹkan ìbànújẹ́ tó ń ṣẹlẹ̀. (Oníwàásù 9:11) Àmọ́ Jèhófà lè dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́, ó sì dájú pé yóò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó máa ń fún wọn ní okun tí wọ́n nílò láti lè fara da àdánwò èyíkéyìí. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Ìdí nìyẹn tí Mósè fi sọ fáwọn èèyàn Ọlọ́run láyé ọjọ́un, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pé: “Ẹ jẹ́ onígboyà àti alágbára. . . . Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ẹni tí ń bá ọ lọ. Òun kì yóò kọ̀ ọ́ tì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ pátápátá.” (Diutarónómì 31:6) Ohun tí yóò ṣe àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láǹfààní ló máa ń ṣe fún wọn nígbà gbogbo. “Àkànṣe dúkìá” ni wọ́n jẹ́ fún un.
“Olùsẹ̀san” Ni Jèhófà
11, 12. Báwo ni mímọ̀ tá a mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ Olùsẹ̀san ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe fàyè gba iyèméjì?
11 Ẹ̀rí mìíràn tó tún fi hàn pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣeyebíye lójú rẹ̀ ni pé, ó máa ń san èrè fún wọn. Ó sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “‘Ẹ sì jọ̀wọ́, dán mi wò nínú ọ̀ràn yìí,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘bóyá èmi kì yóò ṣí ibodè ibú omi ọ̀run fún yín, kí èmi sì tú ìbùkún dà sórí yín ní ti tòótọ́ títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’” (Málákì 3:10) Ó dájú pé, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Jèhófà yóò san èrè fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nípa fífún wọn ní ìyè ayérayé. (Jòhánù 5:24; Ìṣípayá 21:4) Èrè tí kò ṣeé díye lé yìí fi bí ìfẹ́ àti ẹ̀mí ọ̀làwọ́ Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó hàn. Ó tún fi hàn pé lóòótọ́ làwọn tó pinnu láti sìn ín ṣeyebíye lójú rẹ̀. Tá a bá kọ́ láti máa wo Jèhófà pé Olùsẹ̀san tó lawọ́ ni, èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe ní iyèméjì èyíkéyìí nípa àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run. Àní sẹ́, Jèhófà rọ̀ wá pé ká máa wo òun gẹ́gẹ́ bí Olùsẹ̀san! Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—Hébérù 11:6.
12 Kò sí àní-àní pé nítorí ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà la ṣe ń sìn ín kì í kàn ṣe torí pé ó ṣèlérí láti san èrè fún wa. Síbẹ̀, kì í ṣe ohun tó burú bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ohun tí kò tọ́ tá a bá ní in lọ́kàn láti gba èrè. (Kólósè 3:23, 24) Nítorí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń fi taratara wá a tí wọ́n sì ṣeyebíye gan-an lójú rẹ̀ ló mú kó sọ pé òun yóò san èrè fún wọn.
13. Kí nìdí tí ìràpadà tí Jèhófà pèsè fi jẹ́ ẹ̀rí tó lágbára jù lọ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa?
13 Ẹ̀bùn ìràpadà ni ẹ̀rí tó lágbára jù lọ tó fi hàn pé ìran èèyàn ṣeyebíye lójú Jèhófà. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Bí Jèhófà ṣe pèsè ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi fi hàn pé èrò òdì pátápátá ni pé a ò já mọ́ nǹkan kan lójú Jèhófà tàbí pé kò nífẹ̀ẹ́ wa. Àní, bí Jèhófà bá lè fi ohun tó tó bẹ́ẹ̀ yẹn rúbọ nítorí wa, ìyẹn Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, kò sí àní-àní pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.
14. Kí ló fi ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà wo ìràpadà náà hàn?
14 Nítorí náà, bí èrò pé o ò já mọ́ nǹkan kan bá bẹ̀rẹ̀ sí wá sí ọ lọ́kàn, ńṣe ni kó o fara balẹ̀ ronú lórí ìràpadà náà. Àní sẹ́, máa wo ẹ̀bùn yìí bíi pé tìtorí tìẹ gan-an ni Jèhófà ṣe pèsè rẹ̀. Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe gan-an nìyẹn. Rántí ohun tó sọ nípa ara rẹ̀, ó ní: “Èmi abòṣì ènìyàn!” Àmọ́ ó wá sọ síwájú sí i pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa,” ẹni tó “nífẹ̀ẹ́ mi, tí ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.” (Róòmù 7:24, 25; Gálátíà 2:20) Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí kò túmọ̀ sí pé ó ń gbéra ga. Ńṣe ló wulẹ̀ fi hàn pé ó dá a lójú pé Jèhófà ka òun sí gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ó yẹ kí ìwọ náà máa wo ìràpadà yẹn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn tí Ọlọ́run dìídì pèsè fún ọ. Kì í ṣe pé Jèhófà jẹ́ Olùgbàlà tó lágbára nìkan ni, ó tún jẹ́ Olùsẹ̀san tó nífẹ̀ẹ́.
Ṣọ́ra fún “Àwọn Ètekéte” Sátánì
15-17. (a) Báwo ni Èṣù ṣe máa ń lo àwọn èrò òdì tó máa ń wá sí wa lọ́kàn láti bì wá ṣubú? (b) Ìṣírí wo la lè rí látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù?
15 Síbẹ̀, ó ṣì lè ṣòro fún ọ láti gbà pé àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tí Ọlọ́run mí sí tó wà nínú Bíbélì kan ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan. O lè máa rò ó pé ọwọ́ àwọn mìíràn lè tẹ èrè ìyè ayérayé nínú ayé tuntun Ọlọ́run, àmọ́ pé kì í ṣe irú ẹ ló wà fún. Bó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ nìyẹn, kí lo lè ṣe?
16 Ó dájú pé o mọ ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará Éfésù pé: “Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.” (Éfésù 6:11) Nígbà tá a bá ń ronú nípa àwọn ọ̀nà tí Sátánì ń gbà mú àwọn èèyàn, àwọn nǹkan bí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì àti ìwà pálapàla lè yára wá sọ́kàn wa, bó sì ṣe rí nìyẹn. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ti dẹkùn mú ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run láyé ọjọ́un àti lóde òní. Àmọ́, kò yẹ ká gbójú fo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ mìíràn tí Sátánì tún máa ń lò, ìyẹn ni bó ṣe ń sapá láti mú káwọn èèyàn gbà pé Jèhófà Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ àwọn.
17 Èṣù jáfáfá gan-an nínú lílo irú èrò bẹ́ẹ̀ bó ṣe ń gbìyànjú láti yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Rántí ọ̀rọ̀ tí Bílídádì sọ fún Jóòbù. Ó ní: “Báwo ni ẹni kíkú ṣe lè jàre níwájú Ọlọ́run, tàbí báwo ni ẹni tí obìnrin bí ṣe lè mọ́? Wò ó! Òṣùpá pàápàá wà, kò sì mọ́lẹ̀; àwọn ìràwọ̀ pàápàá kò sì mọ́ lójú rẹ̀. Áńbọ̀sìbọ́sí ẹni kíkú, tí ó jẹ́ ìdin, àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ kòkòrò mùkúlú!” (Jóòbù 25:4-6; Jòhánù 8:44) Ǹjẹ́ o mọ bí ọ̀rọ̀ yẹn ti ní láti ba Jóòbù lọ́kàn jẹ́ tó? Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí Sátánì bà ọ́ lọ́kàn jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, máa ṣọ́ra fáwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Sátánì kó o lè ní ìgboyà àti okun láti sa gbogbo ipá rẹ láti lè máa ṣe ohun tó dára. (2 Kọ́ríńtì 2:11) Ní ti Jóòbù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà bá a wí, ó san èrè fún un nítorí ìfaradà rẹ̀ nípa dídá gbogbo ohun tó ti pàdánù padà fún un ní ìlọ́po méjì.—Jóòbù 42:10.
Jèhófà “Tóbi Ju Ọkàn-Àyà Wa Lọ”
18, 19. Báwo ni Ọlọ́run ṣe “tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ,” ọ̀nà wo ló sì gbà “mọ ohun gbogbo”?
18 Òótọ́ ni pé ó lè ṣòro láti borí àwọn èrò tí ń múni rẹ̀wẹ̀sì bí irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ bá ti gbà ọ́ lọ́kàn pátápátá. Síbẹ̀, ẹ̀mí Jèhófà lè máa ràn ọ́ lọ́wọ́ nìṣó láti dojú “àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in dé . . . tí a gbé dìde lòdì sí ìmọ̀ nípa Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 10:4, 5) Nígbà tó bá dà bíi pé àròdùn ọkàn fẹ́ bò ọ́ mọ́lẹ̀ pátápátá, ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Nípa èyí ni àwa yóò mọ̀ pé a pilẹ̀ṣẹ̀ láti inú òtítọ́, a óò sì fún ọkàn-àyà wa ní ìdánilójú níwájú rẹ̀ ní ti ohun yòówù nínú èyí tí ọkàn-àyà wa ti lè dá wa lẹ́bi, nítorí Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.”—1 Jòhánù 3:19, 20.
19 Kí ni gbólóhùn náà, “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ” túmọ̀ sí? Nígbà míì, ọkàn wa lè máa dá wa lẹ́bi, àgàgà nígbà tá a bá ronú nípa àìpé wa àtàwọn àṣìṣe wa, tí èyí sì kó ìbànújẹ́ bá wa gan-an. Ó sì lè jẹ́ pé èrò òdì la máa ń ní nípa ara wa ṣáá nítorí àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa sẹ́yìn, bí ẹni pé kò sóhun tá a lè ṣe tí Jèhófà yóò fi tẹ́wọ́ gbà wá. Àmọ́ ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Jòhánù mú un dá wa lójú pé ohun tí Jèhófà ń rò nípa wa ju ìyẹn lọ! Ohun tó mọ̀ nípa wa ré kọjá àwọn àṣìṣe wa, ó sì mọ̀ pé a ṣì lè ṣe dáadáa gan-an. Ó tún mọ ìdí tá a fi ń sin òun àtàwọn ohun tó wà nínú ọkàn wa. Dáfídì kọ̀wé pé: “Òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:14) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà mọ̀ wá dáadáa ju bá a ṣe mọ ara wa lọ!
“Adé Ẹwà” àti “Láwàní Ọba”
20. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò tí Aísáyà sọ fi hàn nípa irú ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?
20 Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà fún àwọn èèyàn rẹ̀ ayé ọjọ́un nírètí pé òun yóò mú wọn padà bọ̀ sí ilẹ̀ wọn. Nígbà táwọn èèyàn tí ìbànújẹ́ dorí wọn kodò yìí wà nígbèkùn nílẹ̀ Bábílónì, ọ̀rọ̀ ìtùnú tó tún ń fini lọ́kàn balẹ̀ yìí gan-an ni wọ́n nílò! Nígbà tí Jèhófà ń sọ nípa àkókò tí wọn yóò padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, ó ní: “Ìwọ yóò sì di adé ẹwà ní ọwọ́ Jèhófà, àti láwàní ọba ní àtẹ́lẹwọ́ Ọlọ́run rẹ.” (Aísáyà 62:3) Gbólóhùn yìí fi hàn pé Jèhófà buyì kún àwọn èèyàn rẹ̀ ó sì fi ọlá fún wọn. Ó tún ti ṣe irú ohun kan náà fún Ísírẹ́lì tẹ̀mí tó jẹ́ orílẹ̀-èdè rẹ̀ lónìí. Ńṣe ló dà bíi pé ó gbé wọn ga sókè fíofío kí gbogbo èèyàn lè rí wọn.
21. Báwo lo ṣe lè ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò bù kún ọ bó o ti ń ní ìfaradà nìṣó?
21 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni àmì òróró ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń bá wí, síbẹ̀ ó jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń buyì kún gbogbo àwọn tó ń sìn ín. Nítorí náà, nígbà tó o bá ń ṣiyèméjì, máa rántí pé bó o tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, o ṣeyebíye lójú Jèhófà gẹ́gẹ́ bí “adé ẹwà” àti “láwàní ọba” ti ṣeyebíye. Nítorí náà, máa bá a nìṣó láti mú ọkàn Jèhófà yọ̀ nípa sísa gbogbo ipá rẹ láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Òwe 27:11) Èyí á jẹ́ kó dá ọ lójú pé Jèhófà yóò bù kún ọ bó o ti ń ní ìfaradà nìṣó!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Lọ́nà wo la fi jẹ́ “àkànṣe dúkìá” fún Jèhófà?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa ní in lọ́kàn pé Olùsẹ̀san ni Jèhófà?
• “Àwọn ètekéte” Sátánì wo ló yẹ ká ṣọ́ra fún?
• Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà “tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Pọ́ọ̀lù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èlíjà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Hánà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú pọ̀ jaburata nínú Bíbélì