Sọ́ọ̀lù Lọ Sọ́dọ̀ Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ̀ Tẹ́lẹ̀ Àtàwọn Ọ̀tá Rẹ̀ Ìgbà Kan
BÓYÁ ni àníyàn ọkàn ò ní bá Sọ́ọ̀lù nígbà tó kọ́kọ́ padà sí Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn tó di Kristẹni. Sọ́ọ̀lù yìí ló dẹni tá a wá mọ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nígbà tó yá.a Ọdún mẹ́ta ṣáájú ìgbà yẹn ló kúrò ní Jerúsálẹ́mù láti lọ halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù àti láti máa pa wọ́n. Ó gbàṣẹ láti lọ mú Kristẹni èyíkéyìí tọ́wọ́ ẹ̀ bá tẹ̀ ní Damásíkù.—Ìṣe 9:1, 2; Gálátíà 1:18.
Gbàrà tí Sọ́ọ̀lù di Kristẹni ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fáwọn èèyàn láìṣojo pé òun nígbàgbọ́ nínú Mèsáyà tí Ọlọ́run jíǹde. Ìyẹn mú káwọn Júù tó wà ní Damásíkù fẹ́ pa á. (Ìṣe 9:19-25) Ṣé ó lè máa wá retí pé káwọn Júù tó jẹ́ ọ̀rẹ́ òun tẹ́lẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù gba òun tọwọ́ tẹsẹ̀? Ohun tó jẹ Sọ́ọ̀lù lógún ni bó ṣe máa wá àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tó wà ní Jerúsálẹ́mù kàn. Ìyẹn ò sì ní rọrùn rárá.
“Nígbà tí ó dé Jerúsálẹ́mù, ó sapá láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn; ṣùgbọ́n gbogbo wọ́n ń fòyà rẹ̀, nítorí wọn kò gbà gbọ́ pé ọmọ ẹ̀yìn ni.” (Ìṣe 9:26) Kò yani lẹ́nu pé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Onínúnibíni paraku ni wọ́n ṣáà mọ̀ ọ́n sí tẹ́lẹ̀. Ńṣe ni wọ́n á gbà pé ọgbọ́n táá fi wọlé sí ìjọ lára ló ń ta tó fi sọ pé òun ti di Kristẹni. Nítorí náà, àwọn Kristẹni ní Jerúsálẹ́mù ò fẹ́ fi gbogbo ara gbà á mọ́ra.
Ṣùgbọ́n ọ̀kan lára wọn ran Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé Bánábà mú Sọ́ọ̀lù onínúnibíni tẹ́lẹ̀ rí yìí “lọ bá àwọn àpọ́sítélì.” Ẹ̀rí fi hàn pé Pétérù (ìyẹn Kéfà) àti Jákọ́bù arákùnrin Olúwa làwọn àpọ́sítélì yìí. Bánábà jẹ́ kí wọ́n mọ bí Sọ́ọ̀lù ṣe yí padà di Kristẹni àti bó ṣe wàásù ní Damásíkù. (Ìṣe 9:27; Gálátíà 1:18, 19) Bíbélì ò ṣàlàyé bó ṣe di pé Bánábà gba ọ̀rọ̀ Sọ́ọ̀lù gbọ́. Ṣé ojúlùmọ̀ làwọn méjèèjì ni, tíyẹn sì mú kí Bánábà fẹ̀sọ̀ wádìí lẹ́nu rẹ̀ tó fi wá gba ẹ̀rí rẹ̀ jẹ́? Àbí Bánábà mọ àwọn kan lára àwọn Kristẹni ní Damásíkù ni, tó sì wá tipa bẹ́ẹ̀ gbọ́ nípa bí Sọ́ọ̀lù ṣe dẹni tó yí padà? A ò mọ̀. Ohun tó ṣáà ṣẹlẹ̀ ni pé Bánábà fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ nípa Sọ́ọ̀lù. Sọ́ọ̀lù wá lo ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ́dọ̀ àpọ́sítélì Pétérù.
Ọjọ́ Mẹ́ẹ̀ẹ́dógún Lọ́dọ̀ Pétérù
Jésù fúnra rẹ̀ ló gbé iṣẹ́ lé Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́, torí náà kò ṣẹ̀ṣẹ̀ sí pé èèyàn kankan ń fọwọ́ sí i, bóun alára ṣe sọ fáwọn ará Gálátíà. (Gálátíà 1:11, 12) Ṣùgbọ́n ó dájú pé Sọ́ọ̀lù mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kóun ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù. Ìgbà tó lò lọ́dọ̀ Pétérù á sì jẹ́ kó lè mọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù dáadáa. (Lúùkù 24:12; 1 Kọ́ríńtì 15:3-8) Ọ̀pọ̀ ìbéèrè ni Sọ́ọ̀lù máa bi Pétérù àti Jákọ́bù, àwọn pàápàá á sì bi Sọ́ọ̀lù láwọn ìbéèrè nípa ìran tó lóun rí àti bó ṣe di pé Jésù gbéṣẹ́ lé e lọ́wọ́.
Wọ́n Gba Ẹ̀mí Sọ́ọ̀lù Là Lọ́wọ́ Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ̀ Tẹ́lẹ̀
Sítéfánù làwọn èèyàn sọ pé ó jẹ́ Kristẹni tó kọ́kọ́ di ajẹ́rìíkú. Àwọn tí Sítéfánù bá fa ọ̀rọ̀ nígbà ayé ẹ̀ ni àwọn tó wá láti ibi tí “àwọn ènìyàn ń pè ní Sínágọ́gù Àwọn Olómìnira, àti lára àwọn ará Kírénè àti àwọn ará Alẹkisáńdíríà àti lára àwọn tí wọ́n wá láti Sìlíṣíà àti Éṣíà.” Ní báyìí, àwọn tí Sọ́ọ̀lù ń bá fa ọ̀rọ̀ ni “àwọn Júù tí ń sọ èdè Gíríìkì,” ìyẹn àwọn Hélénì, tó sì ń wàásù fún wọn láìṣojo. Kí ni wọ́n wá ṣe? Ńṣe ni wọ́n fẹ́ pa á.—Ìṣe 6:9; 9:28, 29.
Ó dájú pé Sọ́ọ̀lù máa fẹ́ ṣàlàyé ohun tó fa àyípadà pátápátá tó dé bá òun yìí fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, á sì tún gbìyànjù láti jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọ̀ nípa Mèsáyà. Àmọ́ ńṣe làwọn Júù tó jẹ́ Hélénì náà yí pupa ojú sí i, torí ọ̀dàlẹ̀ gbáà ni wọ́n kà á sí.
Ǹjẹ́ Sọ́ọ̀lù tiẹ̀ mọ̀ pé inú ewu ńlá lòun wà? A kà á nínú Bíbélì pé bó ṣe ń gbàdúrà, ó rí Jésù nínú ìran, Jésù sì sọ fún un pé: “Ṣe wéré, kí o sì jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù ní kíákíá, nítorí pé wọn kì yóò gba ẹ̀rí rẹ nípa mi.” Sọ́ọ̀lù wá dáhùn pé: “Olúwa, àwọn fúnra wọn mọ̀ dunjú pé tẹ́lẹ̀ rí mo máa ń sọ àwọn tí wọ́n gbà ọ́ gbọ́ sẹ́wọ̀n, mo sì máa ń nà wọ́n lẹ́gba ní sínágọ́gù kan tẹ̀ lé òmíràn; nígbà tí a sì ń ta ẹ̀jẹ̀ Sítéfánù ẹlẹ́rìí rẹ sílẹ̀, èmi alára dúró nítòsí, mo fọwọ́ sí [i].”—Ìṣe 22:17-20.
Àwọn kan gbà pé èsì Sọ́ọ̀lù yìí fi hàn pé ó mọ̀ pé inú ewu lòun wà. Àwọn míì ronú pé ohun tó ń sọ ni pé: ‘A ṣáà jọ ń ṣenúnibíni tẹ́lẹ̀ ni, wọ́n sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Torí náà, wọ́n á ronú dáadáa lórí yíyí tí mo yí padà. Bóyá máa tiẹ̀ lè là wọ́n lójú sí òtítọ́.’ Síbẹ̀ Jésù mọ̀ pé àwọn Júù yẹn ò ní gba ẹ̀rí ẹni tí wọ́n kà sí apẹ̀yìndà gbọ́ rárá. Ó sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Mú ọ̀nà rẹ pọ̀n, nítorí pé èmi yóò rán ọ jáde lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè jíjìnnàréré.”—Ìṣe 22:21, 22.
Nígbà táwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ mọ inú ewu tó wà, wọ́n mú un sọ̀ kalẹ̀ kíákíá lọ sí Kesaréà tó wa létíkun. Wọ́n ní kó lọ sí Tásù ìlú rẹ̀ tó wà ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] kìlómítà sí Kesaréà. (Ìṣe 9:30) Ó tó ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà kí Sọ́ọ̀lù tó tún yọjú sí Jerúsálẹ́mù.
Ó ṣeé ṣe kí mímú tí wọ́n mú un lọ síbòmíì kíákíá yẹn jẹ́ ààbò fún ìjọ Kristẹni ìgbà náà. Tí Sọ́ọ̀lù onínunibíni tẹ́lẹ̀ rí yìí bá wà pẹ̀lú wọn níbẹ̀, wàhálà lè bẹ́ sílẹ̀. Lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù kúrò níbẹ̀, “ìjọ jákèjádò Jùdíà àti Gálílì àti Samáríà wọnú sáà àlàáfíà, a ń gbé e ró; bí ó sì ti ń rìn ní ìbẹ̀rù Jèhófà àti ní ìtùnú ẹ̀mí mímọ́, ó ń di púpọ̀ sí i ṣáá.”—Ìṣe 9:31.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa Nípa Ṣíṣọ́ra
Lóde òní, àwọn ipò kan tó gbàṣọ́ra gan-an lè yọjú, bó ṣe rí lọ́gọ́rùn-ún ọdún kìíní. Kò yẹ ká kàn dédé máa fura sáwọn tó bá jẹ́ àjèjì o. Ṣùgbọ́n nígbà míì, àwọn afàwọ̀rajà máa ń gbìyànjú láti wọlé sáwọn èèyàn Jèhófà lára, bóyá láti lù wọ́n ní jìbìtì tàbí láti da ìjọ rú. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká máa lo òye káwọn afàwọ̀rajà má bàa ráyè tú wa jẹ.—Òwe 3:27; 2 Tímótì 3:13.
Ohun tí Sọ́ọ̀lù ṣe nípa iṣẹ́ ìwàásù ní Jerúsálẹ́mù jẹ́ àpẹẹrẹ ọ̀nà míì táwa Kristẹni ti lè ṣọ́ra gan-an. Wíwàásù láwọn àdúgbò kan tàbí fáwọn ẹnì kan, títí kan àwọn ọ̀rẹ́ wa kan tẹ́lẹ̀ rí, lè kó wa sínú ewu, ó lè ṣàkóbá fún ìjọsìn wa tàbí kó tiẹ̀ kó ìwàkiwà ràn wá. Ó dára ká máa ṣọ́ra, bóyá nípa fífọgbọ́n yan ibi tá a ó ti wàásù àti àkókò tá a máa lọ síbẹ̀.—Òwe 22:3; Mátíù 10:16.
Kí ó dá wa lójú pé a ó ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láṣeparí kí òpin ètò nǹkan búburú yìí tó dé. Àpẹẹrẹ àtàtà ni Sọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ fún wa nínú iṣẹ́ ìwàásù yìí o, ní ti pé “ó ń sọ̀rọ̀ láìṣojo ní orúkọ Olúwa,” àní fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ìgbà kan àtàwọn ọ̀tá rẹ̀ tẹ́lẹ̀ pàápàá!—Ìṣe 9:28.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù làwọn èèyàn mọ Sọ́ọ̀lù sí jù lóde òní. Àmọ́ Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ orúkọ rẹ̀ lédè àwọn Júù ló wà nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí nínú àpilẹ̀kọ yìí.—Ìṣe 13:9.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Nígbà tí Sọ́ọ̀lù dé Jerúsálẹ́mù, ó ń wàásù fáwọn Júù tó ń sọ èdè Gíríìkì láìṣojo