Ominira Ti Ọlọrun Fi Funni Ń mú Ayọ Wá
“Ayọ Jehofa ni odi-agbara yin.”—NEHEMAYA 8:10, NW.
1. Ki ni ayọ, eesitiṣe ti awọn wọnni ti wọn ṣe iyasimimọ si Ọlọrun fi lè niriiri rẹ̀?
JEHOFA fi ayọ kún ọkan-aya awọn eniyan rẹ̀. Ipo ayọ tabi idunnu ńlá yii jẹ jade lati inu gbígbà tabi rireti ohun rere. Awọn eniyan ti a yà sí mímọ́ fun Ọlọrun lè niriiri iru ero imọlara kan bẹẹ nitori pe ayọ jẹ́ eso ẹmi mímọ́, tabi ipá agbékánkánṣiṣẹ́ kan. (Galatia 5:22, 23) Nitori naa ani bi awọn idanwo ti ń pọnniloju bá tilẹ dojukọ wá, a lè kún fun ayọ gẹgẹ bi iranṣẹ Jehofa, awọn tí a ń ṣamọna nipasẹ ẹmi mímọ́ rẹ̀.
2. Eeṣe ti awọn Juu fi yọ̀ ni akoko akanṣe kan ni ọjọ Ẹsira?
2 Ni akoko akanṣe kan ni ọrundun karun-un B.C.E., awọn Juu lo ominira ti Ọlọrun fifun wọn lati ṣe Ajọdun alayọ ti awọn Àgọ́ ni Jerusalẹmu. Lẹhin ti Ẹsira ati awọn ọmọ Lefi miiran ti kà ti wọn sì ṣalaye Ofin Ọlọrun fun wọn, “awọn eniyan naa lọ kuro lati jẹ ati lati mu ati lati fi awọn ìpín ranṣẹ sode ati lati maa bá yíyọ̀ ńlá lọ, nitori wọn ti loye awọn ọrọ ti a ti sọ di mímọ̀ fun wọn.”—Nehemaya 8:5-12, NW.
Ayọ Jehofa Ni Odi-Agbara Wa
3. Labẹ awọn ipo wo ni “ayọ Jehofa” lè gbà jẹ́ odi-agbara wa?
3 Ni akoko ajọdun yẹn, awọn Juu mọ ìjótìítọ́ awọn ọrọ naa: “Ayọ Jehofa ni odi-agbara yin.” (Nehemaya 8:10, NW) Ayọ yii ni odi-agbara wa pẹlu bi awa bá ń duro ṣinṣin fun ominira ti Ọlọrun fifun wa gẹgẹ bi Ẹlẹ́rìí oluṣeyasimimọ, ti a ti bamtisi fun Jehofa. Diẹ ninu wa ti niriiri ìfàmì ororo yàn nipasẹ ẹmi mímọ́ ati ìgbàṣọmọ sinu idile Ọlọrun gẹgẹ bi ajumọjogun pẹlu Kristi. (Roomu 8:15-23) Ọpọ yanturu ninu wa lonii ni ireti ìyè ninu paradise ilẹ̀-ayé kan. (Luuku 23:43) Bawo ni o ti yẹ ki a layọ tó!
4. Eeṣe ti awọn Kristẹni fi lè farada awọn ijiya ati inunibini?
4 Bi o tilẹ jẹ pe a ni awọn ifojusọna agbayanu, kò rọrun lati farada awọn ijiya ati inunibini. Bi o ti wu ki o ri, a lè ṣe bẹẹ, nitori pe Ọlọrun fun wa ni ẹmi mímọ́ rẹ̀. Pẹlu rẹ̀ a lè ni ayọ ati idaniloju pe kò si ohunkohun ti o lè fi ireti wa tabi ifẹ Ọlọrun dù wá. Ju bẹẹ lọ, a lè ni idaniloju pe Jehofa yoo jẹ́ odi-agbara wa niwọn bi a bá ti nifẹẹ rẹ̀ pẹlu gbogbo ọkan-aya, ọkàn, okun, ati ero-inu wa.—Luuku 10:27.
5. Nibo ni a ti lè rí awọn idi lati yọ̀?
5 Awọn eniyan Jehofa gbadun awọn ibukun jìngbìnnì wọn sì ni ọpọlọpọ idi lati yọ̀. Awọn idi diẹ fun ayọ ni a mẹnukan ninu lẹta Pọọlu si awọn ará Galatia. Awọn miiran ni a fihan nibomiran ninu Iwe Mímọ́. Yoo ru ẹmi wa soke lati gbe iru awọn ibukun alayọ bẹẹ yẹwo.
Mọriri Ominira Ti Ọlọrun Fi Funni
6. Eeṣe ti Pọọlu fi rọ awọn Kristẹni ara Galatia lati duro ṣinṣin?
6 Gẹgẹ bii Kristẹni, a ni ibukun alayọ ti iduro ti o ṣetẹwọgba pẹlu Ọlọrun. Niwọn bi Kristi ti dá awọn ọmọlẹhin rẹ̀ silẹ lominira kuro labẹ Ofin Mose, awọn ará Galatia ni a rọ̀ lati duro ṣinṣin ki a má sì ṣe sé wọn mọ́ inú “àjàgà ẹrú” yẹn. Awa ń kọ? Bi a bá gbiyanju lati di ẹni ti a polongo ní olododo nipa pipa Ofin mọ́, a ó yà wá nipa kuro lọdọ Kristi. Bi o ti wu ki o ri, pẹlu iranlọwọ ẹmi Ọlọrun, a duro de ododo ti a reti fun naa tí ń jẹ jade lati inu igbagbọ ti ń ṣiṣẹ nipasẹ ifẹ, kii ṣe lati inu ìkọlà ti ara tabi awọn iṣẹ ti Ofin miiran.—Galatia 5:1-6.
7. Oju wo ni a gbọdọ fi wo iṣẹ-isin mímọ́ si Jehofa?
7 Ó jẹ́ ibukun lati lo ominira ti Ọlọrun fifun wa lati “ṣiṣẹsin Jehofa pẹlu ayọ̀.” (Saamu 100:2) Nitootọ, anfaani alaiṣeediyele ni o jẹ́ lati ṣe iṣẹ-isin mímọ́ si “Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun, Olodumare,” “Ọba ayeraye” naa gan-an! (Iṣipaya 15:3) Bí ìgbì imọlara fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ti iyì ara-ẹni rirẹlẹ bá fẹ́ lù ọ́, ó lè ṣeranwọ lati mọ pe Ọlọrun ti fà ọ́ sunmọ ọdọ araarẹ̀ nipasẹ Jesu Kristi ó sì ti yọọda rẹ lati nípìn-ín ninu “iṣẹ mímọ́ ti ihinrere Ọlọrun.” (Roomu 15:16; Johanu 6:44; 14:6) Iru idi fun ayọ ati imoore si Ọlọrun wo ni eyi jẹ́!
8. Niti Babiloni Ńlá, idi wo fun ayọ ni awọn eniyan Ọlọrun ni?
8 Idi miiran fun ayọ ni ominira ti Ọlọrun fifun wa kuro ninu Babiloni Ńlá, ilẹ-ọba isin èké agbaye. (Iṣipaya 18:2, 4, 5) Bi o tilẹ jẹ pe lọna iṣapẹẹrẹ kárùwà isin yii “jokoo lori omi pupọ,” ti o tumọsi “awọn eniyan ati ẹ̀yà ati orilẹ ati oniruuru èdè,” oun kò jokoo lori, tabi nipa lori ki ó sì dari awọn iranṣẹ Jehofa lọna ti isin. (Iṣipaya 17:1, 15) A yọ̀ ninu imọlẹ agbayanu ti Ọlọrun, nigba ti awọn alatilẹhin Babiloni Ńlá wà ninu okunkun tẹmi. (1 Peteru 2:9) Bẹẹni, ó lè ṣoro lati loye awọn “ohun ijinlẹ ti Ọlọrun” melookan. (1 Kọrinti 2:10) Ṣugbọn adura fun ọgbọn ati iranlọwọ nipasẹ ẹmi mímọ́ ran wa lọwọ lati loye otitọ ti o bá Iwe Mímọ́ mu eyi ti o dá awọn ẹni ti ó ní i silẹ lominira nipa tẹmi.—Johanu 8:31, 32; Jakobu 1:5-8.
9. Bi awa yoo bá nilati gbadun ibukun ominira ti ń baa lọ kuro ninu aṣiṣe isin, ki ni a gbọdọ ṣe?
9 A gbadun ibukun ominira ti ń baa lọ kuro ninu aṣiṣe isin, ṣugbọn lati pa ìdásílẹ̀ yẹn mọ́, a gbọdọ ṣá ipẹhinda tì. Awọn ará Galatia ti ń sá eré-ìje Kristẹni daradara, ṣugbọn awọn kan ń fà wọn sẹhin kuro ninu ṣiṣegbọran si otitọ. Iru ìyínilérò pada buruku bẹẹ kii ṣe lati ọdọ Ọlọrun a sì gbọdọ dènà rẹ̀. Gẹgẹ bi ìwúkàrà kekere ti ń mú gbogbo ìyẹ̀fun wú, awọn olukọ èké tabi títẹ̀ siha ipẹhinda lè sọ gbogbo ijọ kan dibajẹ. Pọọlu daniyan pe ki awọn agbẹnusọ fun ìkọlà ti wọn ń wá ọna lati ṣoju igbagbọ awọn ará Galatia dé má wulẹ di ẹni ti a kọlà fun nikan ṣugbọn ki wọn gé ẹ̀yà araawọn ti ibalopọ danu. Èdè ti o lagbara nitootọ! Ṣugbọn awa gbọdọ wulẹ jẹ́ aduroṣinṣin bakan naa ninu ṣíṣá ipẹhinda tì bi awa yoo bá maa ba a lọ ninu ominira ti Ọlọrun fifun wa kuro ninu aṣiṣe isin.—Galatia 5:7-12.
Ẹ Fi Ifẹ Sìnrú Fun Araayin
10. Ki ni ẹrù-iṣẹ́ wa gẹgẹ bi apakan ẹgbẹ́ ará Kristẹni?
10 Ominira ti Ọlọrun fi funni ti mú wa wá sinu ibakẹgbẹ pẹlu ẹgbẹ́ ará onifẹẹ kan, ṣugbọn a gbọdọ ṣe ipa tiwa lati fi ifẹ han. Awọn ará Galatia ni wọn kò nilati lo ominira wọn gẹgẹ bi “ìmúniṣiṣẹ́ fun ẹran-ara” tabi gẹgẹ bii gáfárà kan fun imọtara-ẹni-nikan aláìnífẹ̀ẹ́. Wọn nilati sìnrú fun araawọn pẹlu ifẹ gẹgẹ bi agbara isunniṣe. (Lefitiku 19:18; Johanu 13:35) Awa pẹlu gbọdọ yẹra fun sisọrọ ẹni lẹhin ati ikoriira ti ó lè yọri si pipa araawa run. Dajudaju, eyi ki yoo ṣẹlẹ bi a bá fi ifẹ ará han.—Galatia 5:13-15, NW.
11. Bawo ni a ṣe lè jẹ́ ibukun fun awọn ẹlomiran, bawo sì ni wọn ṣe lè bukun wa?
11 Nipa lilo ominira ti Ọlọrun fi funni ni ibamu pẹlu ìdarí ẹmi Ọlọrun, awa yoo fi ifẹ han a o sì jẹ́ ibukun fun awọn ẹlomiran. Ó gbọdọ jẹ́ ìwà wa lati yọnda araawa ki a di ẹni ti ẹmi mímọ́ ń ṣakoso tí ó sì ń dari. Nigba naa awa kì yoo tẹ̀ si títẹ́ ẹran araawa abẹ̀ṣẹ̀ eyi ti o “lodi si ẹmi” lọrun lọna àìnífẹ̀ẹ́. Bi a bá ṣamọna wa nipasẹ ẹmi Ọlọrun, awa yoo ṣe ohun ti o jẹ́ onifẹẹ ṣugbọn kii ṣe nitori pe ofin beere fun ṣiṣe igbọran ti ó sì ń di ẹ̀bi ijiya ru awọn ahùwà àìtọ́. Fun apẹẹrẹ, ifẹ—kii wulẹ ṣe ofin kan—ni yoo pa wá mọ́ kuro ninu fifi ọrọ ẹhin ba awọn ẹlomiran jẹ́. (Lefitiku 19:16) Ifẹ yoo sún wa lati sọrọ ki a sì hùwà ni awọn ọna oninuure. Nitori pe a fi eso ifẹ ti ẹmi han, awọn miiran yoo bukun wa, tabi sọrọ wa ni rere. (Owe 10:6) Ju bẹẹ lọ, ikẹgbẹpọ pẹlu wa yoo jẹ́ ibukun fun wọn.—Galatia 5:16-18.
Awọn Eso Ti Ó Yatọ Ni Ifiwera
12. Ki ni diẹ lara awọn ibukun ti o sopọ mọ́ yiyẹra fun “awọn iṣẹ ti ara” ti o kun fun ẹṣẹ?
12 Ọpọlọpọ ibukun ti o sopọ mọ ominira tí Ọlọrun fifun wa jẹ jade lati inu yiyẹra fun “awọn iṣẹ ti ara” ti o kun fun ẹṣẹ. Gẹgẹ bi eniyan Ọlọrun, awa, ni gbogbogboo, yẹra fun ọpọ julọ idaamu nitori pe a kii ṣe agbere, ìwà-àìmọ́, ati ìwà-àìníjàánu bi àṣà. Nipa yiyẹra fun ibọriṣa, a ni ayọ ti ń jẹ jade lati inu wiwu Jehofa ni ọna yẹn. (1 Johanu 5:21) Niwọn bi a kò ti ṣe ibẹmiilo ni àṣà, a wà lominira kuro lọwọ ìjẹgàba leni lori nipasẹ awọn ẹmi eṣu. Ẹgbẹ́ ará Kristẹni wa ni a kò bajẹ nipasẹ ìṣọ̀tá, rogbodiyan, owú, ibinu fùfù, gbólóhùn-asọ̀, ìyapa, awọn ẹ̀yà isin, ati ilara. Ayọ wa kò sì sọnu ninu idije ọtí mímu ati ariya alariwo. Pọọlu kilọ pe awọn wọnni ti ń ṣe iṣẹ ti ara ní àṣà ki yoo jogun Ijọba Ọlọrun. Bi o ti wu ki o ri, nitori pe a kọbiara si awọn ọrọ rẹ̀, a lè rọ̀ mọ́ ireti alayọ ti Ijọba naa.—Galatia 5:19-21, NW.
13. Ẹmi mimọ Jehofa ń mú awọn eso wo jade?
13 Ominira ti Ọlọrun fi funni mú ayọ wá fun wa nitori pe awọn Kristẹni fi awọn eso ẹmi Jehofa hàn. Lati inu awọn ọrọ Pọọlu si awọn ará Galatia, ó rọrùn lati rí i pe awọn iṣẹ ti ara ti o kun fun ẹṣẹ dabi ẹ̀gún ni ifiwera pẹlu awọn eso titayọ tẹmi ti ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, inurere, iwarere-iṣeun, igbagbọ, iwatutu, ati ikora-ẹni-nijaanu ti a gbìn sinu awọn ọkan-aya oniwa-bi-Ọlọrun. Bi a ti pinnu lati gbé ni idakeji si ifẹ ẹran-ara ti o kun fun ẹṣẹ, a daniyan lati di ẹni ti a ṣamọna nipasẹ ẹmi Ọlọrun ati lati gbé nipasẹ rẹ̀. Ẹmi naa ń mú wa jẹ́ onirẹlẹ ati ẹni alaafia, ki “a má ṣogo asan, ki a má mu ọmọnikeji wa binu, ki a má ṣe ilara ọmọnikeji wa.” Abajọ ti o fi jẹ́ ayọ lati kẹgbẹ pẹlu awọn wọnni ti ń fi awọn eso ẹmi han!—Galatia 5:22-26, NW.
Awọn Idi Miiran fun Ayọ
14. Ìhámọ́ra wo ni a nilo ninu ijakadi wa lodisi awọn ipá ẹmi buburu?
14 Eyi ti o sopọ mọ ominira tẹmi ti Ọlọrun fifun wa ni ibukun aabo kuro lọwọ Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀. Lati ṣaṣeyọri ninu ijakadi wa lodisi awọn ipá ẹmi buburu, a gbọdọ wọ “gbogbo ihamọra Ọlọrun.” A nilo àmùrè otitọ ati ìgbàyà ododo. Ẹsẹ̀ wa ni a gbọdọ fi ohun èèlò ihinrere alaafia wọ̀. Ohun ti a nilo, pẹlu, ni apata igbagbọ titobi, eyi ti a o maa fi paná awọn àfọ̀njá ajóbíiná ẹni buburu nì. A gbọdọ wọ aṣibori igbala ki a sì lo “idà ẹmi,” Ọrọ Ọlọrun. Ẹ jẹ ki a tun “maa gbadura nigba gbogbo ninu ẹmi.” (Efesu 6:11-18) Bi a bá wọ ihamọra tẹmi naa ti a sì ṣá ìbẹ́mìílò tì, a lè jẹ́ alaibẹru ati alayọ.—Fiwe Iṣe 19:18-20.
15. Ibukun alayọ wo ni o jẹ́ tiwa nitori pe a ń hùwà dari araawa ni ibamu pẹlu Ọrọ Ọlọrun?
15 Ayọ jẹ́ tiwa nitori pe ìwà wa baramu pẹlu Ọrọ Ọlọrun, a sì wà lominira kuro ninu ẹ̀bi ẹṣẹ ti ń daamu ọpọlọpọ awọn oluṣaitọ. A ‘ń lo araawa laidawọ duro lati nimọlara aidẹṣẹ kankan lodisi Ọlọrun ati awọn eniyan.’ (Iṣe 24:16) Fun idi yii, a kò nilati bẹru ẹ̀san-ibi atọrunwa ti yoo ṣubu lu awọn ẹlẹṣẹ àmọ̀ọ́mọ̀dá, alaironupiwada. (Matiu 12:22-32; Heberu 10:26-31) Nipa fifi imọran Owe 3:21-26 silo, a wá mọ imuṣẹ awọn ọrọ wọnni: “Pa ọgbọn ti o yè, ati imoye mọ́: Bẹẹni wọn ó maa jẹ́ ìyè si ọkàn rẹ, ati oore-ọfẹ si ọrùn rẹ. Nigba naa ni iwọ yoo maa rin ọna rẹ lailewu, ẹsẹ rẹ ki yoo sì kọ. Nigba ti iwọ dubulẹ, iwọ ki yoo bẹru: Nitootọ, iwọ yoo dubulẹ, oorun rẹ yoo sì dùn. Maṣe foya ẹ̀rù òjijì, tabi idahoro awọn eniyan buburu, nigba ti o dé, nitori Oluwa [“Jehofa,” NW] ni yoo ṣe igbẹkẹle rẹ, yoo sì pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kuro ninu àtimú.”
16. Ọna wo ni adura gbà jẹ́ idi fun ayọ, ipa wo sì ni ẹmi Jehofa ń kó ninu ọran yii?
16 Idi miiran fun ayọ ni ominira ti Ọlọrun fifun wa lati tọ Jehofa lọ ninu adura pẹlu idaniloju pe a o gbọ́ wa. Bẹẹni, awọn adura wa ni a ń dahun nitori pe a ní “ibẹru” ti ń fi ọ̀wọ̀ han fun “Jehofa.” (Owe 1:7, NW) Ju bẹẹ lọ, a ràn wa lọwọ lati pa araawa mọ́ ninu ifẹ Ọlọrun nipa ‘gbigbadura ninu ẹmi mímọ́.’ (Juuda 20, 21) Eyi ni a ń ṣe nipa fifi ipo ọkan-aya ti o ṣetẹwọgba si Jehofa han ati nipa gbigbadura labẹ agbara idari ẹmi fun awọn ohun ti o wà ni ibamu pẹlu ifẹ-inu rẹ̀ ati Ọrọ rẹ̀, eyi ti o fi bi a o ti gbadura ati ohun ti a o beere fún ninu adura hàn wá. (1 Johanu 5:13-15) Bi a bá dán wa wò gidigidi ti a kò sì mọ ohun ti a o gbadura fun, ‘ẹmi ń darapọ ninu iranlọwọ fun ailera wa, ni bibẹbẹ fun wa pẹlu awọn ìkérora ti a kò sọ jade.’ Ọlọrun ń gbọ iru awọn adura bẹẹ. (Roomu 8:26, 27) Ẹ jẹ́ ki a gbadura fun ẹmi mímọ́ ki a sì yọnda rẹ̀ lati mú awọn eso rẹ̀ wọnni ti a nilo ni pataki lati dojukọ adanwo kan pato jade ninu wa. (Luuku 11:13) Awa yoo tun mú ayọ wa pọ̀ sii bi a bá fi taduratadura ati taapọntaapọn kẹkọọ Ọrọ Ọlọrun ti a fi ẹmi mísí ati awọn itẹjade Kristẹni ti a ṣe labẹ idari ẹmi naa.
A Bukun Wa Pẹlu Iranlọwọ Ti Ó Wà Lọjọkọjọ
17. Bawo ni awọn iriri Mose ati awọn ọrọ Dafidi ṣe fihan pe Jehofa wà pẹlu awọn eniyan Rẹ̀?
17 Nipa lilo ominira ti Ọlọrun fifun wa lọna titọ, a ni ayọ mímọ̀ pe Jehofa wà pẹlu wa. Nigba ti awọn ipo ti o nira mú ki Mose fi Ijibiti silẹ, nipa igbagbọ “ó duro ṣinṣin bi ẹni ti o ń rí ẹni airi.” (Heberu 11:27) Mose kò danikan rìn; ó mọ pe Jehofa wà pẹlu oun. Bakan naa, awọn ọmọkunrin Kora kọrin pe: “Ọlọrun ni ààbò wa ati agbara, lọwọlọwọ iranlọwọ ni ìgbà ipọnju. Nitori naa ni awa ki yoo bẹru, bi a tilẹ ṣí ayé ni idi, ti a sì ṣí awọn oke ńlá nipo lọ si inu okun: Bi omi rẹ̀ tilẹ ń hó ti o sì ń ru, bi awọn oke ńlá tilẹ ń mì nipa ọwọ́ bíbì rẹ̀.” (Saamu 46:1-3) Bi iwọ bá ni iru igbagbọ bẹẹ ninu Ọlọrun, oun ki yoo pa ọ́ tì lae. Dafidi wi pe: “Nigba ti baba ati ìyá mi kọ̀ mi silẹ, nigba naa ni Oluwa [“Jehofa,” NW] yoo tẹwọgba mi.” (Saamu 27:10) Iru ayọ wo ni ó wà nibẹ ninu mímọ̀ pe Ọlọrun bikita fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pupọpupọ tobẹẹ!—1 Peteru 5:6, 7.
18. Eeṣe ti awọn wọnni ti wọn ni ayọ Jehofa fi ni ominira ti Ọlọrun fi funni kuro lọwọ aniyan ti ń bonimọlẹ?
18 Bi a ti ní ayọ Jehofa, a ni ominira tí Ọlọrun fi funni kuro lọwọ aniyan ti ń bonimọlẹ. “Ẹ maṣe aniyan ohunkohun,” ni Pọọlu wí, “ṣugbọn ninu ohun gbogbo, nipa adura ati ẹ̀bẹ̀ pẹlu idupẹ, ẹ maa fi ibeere yin han fun Ọlọrun. Ati alaafia Ọlọrun, ti o ju imọran gbogbo lọ, yoo ṣọ́ ọkàn ati ero yin ninu Kristi Jesu.” (Filipi 4:6, 7) Alaafia Ọlọrun jẹ́ ìparọ́rọ́ ti kò lafiwe ani ninu awọn ipo ti ń danniwo julọ paapaa. Pẹlu rẹ̀ ọkan-aya wa wà ni ìparọ́rọ́—ohun kan ti o dara fun wa nipa ti ẹmi, ero imọlara, ati ti ara ìyára. (Owe 14:30) Ó tun ran wa lọwọ lati pa iwadeedee ti ero ori mọ́, nitori pe a mọ̀ pe kò si ohun kankan ti Ọlọrun yọnda ti ó lè ṣe wa ni ipalara wíwà pẹtiti. (Matiu 10:28) Alaafia yii ti ń jẹ jade lati inu ipo ibatan wa timọtimọ pẹlu Ọlọrun nipasẹ Kristi jẹ́ tiwa nitori pe a ṣeyasimimọ si Jehofa a sì juwọsilẹ fun idari ẹmi rẹ̀, eyi ti ń mú iru awọn eso bii ayọ ati alaafia jade.
19. Pipa ọkan-aya wa mọ́ sori ki ni ni yoo ran wa lọwọ lati jẹ́ alayọ?
19 Pípa ọkan-aya wa mọ́ sori ominira ti Ọlọrun fifun wa ati ireti Ijọba naa yoo ran wa lọwọ lati jẹ́ alayọ. Fun apẹẹrẹ, nigba miiran iwọnba ni ohun ti a lè ṣe nipa ilera ti kò sunwọn, ṣugbọn a lè gbadura fun ọgbọn ati igboya lati koju rẹ̀ a sì lè ri itunu ninu rironu nipa ilera tẹmi ti a ń gbadun nisinsinyi ati iwosan ti ara ìyára ti yoo ṣẹlẹ labẹ iṣakoso Ijọba. (Saamu 41:1-3; Aisaya 33:24) Bi o tilẹ jẹ pe ó beere pe ki a farada awọn aini lonii, kò ni sí àìtó awọn kòṣeémánìí igbesi-aye kankan ninu Paradise ilẹ̀-ayé ti o ti sunmọle pẹkipẹki. (Saamu 72:14, 16; Aisaya 65:21-23) Bẹẹni, Baba wa ọrun yoo fun wa lokun nisinsinyi yoo sì mú ayọ wa kún nigbẹhin-gbẹhin.—Saamu 145:14-21.
Ṣìkẹ́ Ominira Ti Ọlọrun Fifun Ọ
20. Ni ibamu pẹlu Saamu 100:1-5 (NW), bawo ni a ṣe nilati fi araawa han niwaju Jehofa?
20 Gẹgẹ bi awọn eniyan Jehofa, ó daju pé awa gbọdọ ṣìkẹ́ ominira ti Ọlọrun fifun wa eyi ti o ti mú ayọ ati ọpọlọpọ awọn ibukun tobẹẹ wá fun wa. Abajọ ti Saamu 100:1-5 (NW) fi rọ̀ wa lati wá si iwaju Ọlọrun “pẹlu igbe ayọ.” Jehofa ni ó ni wá ti ó sì bikita fun wa gẹgẹ bi Oluṣọ agutan onifẹẹ. Bẹẹni, “awa ni eniyan rẹ̀ ati agutan ilẹ papa-koriko rẹ̀.” Ipo jíjẹ́ Ẹlẹdaa ati awọn animọ titobilọla rẹ̀ pese iṣiri fun wa lati wọnu àgbàlá ibujọsin rẹ̀ pẹlu iyin ati ọpẹ. A sun wa lati “fi ibukun fun orukọ rẹ̀,” lati sọrọ Jehofa Ọlọrun ni rere. Siwaju sii, a lè gbarale iṣeun-ifẹ, tabi ìkàsí oníyọ̀ọ́nú rẹ̀, fun wa nigba gbogbo. “Lati iran dé iran,” Jehofa jẹ́ oloootọ, alaiyẹsẹ ninu fifi ifẹ han fun awọn wọnni ti ń ṣe ifẹ-inu rẹ̀.
21. Iṣiri wo ni a fi funni ninu itẹjade akọkọ iwe irohin yii, ki sì ni a gbọdọ ṣe nipa ominira ti Ọlọrun fifun wa?
21 Gẹgẹ bi awọn eniyan alaipe, a kò lè yèbọ́ lọwọ gbogbo awọn adanwo nisinsinyi. Bi o ti wu ki o ri, pẹlu iranlọwọ atọrunwa, a lè jẹ́ Ẹlẹ́rìí onigboya ati alayọ ti Jehofa. Eyi ti o yẹ fun akiyesi ninu ọran yii ni awọn ọrọ wọnyi ti a ri ninu itẹjade akọkọ iwe irohin yii (July 1879): “Igboya . . . ẹyin Kristẹni arakunrin tabi arabinrin mi, tí ń wá ọna lati tọ ọna tóóró naa pẹlu ìṣísẹ ti àárẹ̀ ti mú. Ẹ maṣe kọbiara si ipa-ọna págunpàgun naa; gbogbo rẹ̀ ni a yà sí mímọ́ ti a sì sọ di mímọ́ nipa ẹsẹ̀ Ọga ti a bukun fun naa. Ẹ ka gbogbo ẹ̀gún si òdòdó; gbogbo apata mímú si okuta ìsàmì-ọ̀nà, ti ń mú yin yára siwaju sí gongo naa. . . . Ẹ pa oju yin pọ̀ sara èrè naa.” Araadọta ti ń ṣiṣẹsin Jehofa nisinsinyi tẹ oju wọn mọ́ èrè naa wọn sì ní ọpọlọpọ idi fun igboya ati ayọ. Pẹlu wọn, ẹ duro ṣinṣin fun ominira ti Ọlọrun fi funni. Ẹ maṣe tase ète rẹ̀, ǹjẹ́ ki ayọ Jehofa sì maa jẹ́ odi-agbara yin nigba gbogbo.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Bawo ni “ayọ Jehofa” ṣe lè jẹ́ odi-agbara wa?
◻ Ni sisọrọ niti isin, awọn ibukun wo ni ominira ti Ọlọrun fi funni ti mú wá fun awọn eniyan Jehofa?
◻ Eeṣe ti a fi nilati sinru fun araawa ninu ifẹ?
◻ Awọn ibukun diẹ wo ni wọn sopọ mọ ominira ti Ọlọrun fi funni?
◻ Bawo ni awọn eniyan Ọlọrun ṣe lè maa baa lọ ni kikun fun ayọ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
“Ẹ ka gbogbo ẹ̀gún si òdòdó; gbogbo apata mímú si okuta ìsàmì-ọ̀nà, ti ń mú yin yára siwaju sí gongo naa”