Máa Tẹ̀ Síwájú Sí Ìdàgbàdénú Torí Pé “Ọjọ́ Ńlá Jèhófà Sún Mọ́lé”
“Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú.”—HÉB. 6:1.
1, 2. Báwo làyè ṣe ṣí sílẹ̀ fáwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà ní ọ̀rúndún kìíní láti sá lọ “sí àwọn òkè ńlá”?
NÍGBÀ tí Jésù wà láyé, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè pé: “Kí ni yóò . . . jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” Àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù fi dáhùn ìbéèrè wọn ní ìmúṣẹ àkọ́kọ́ ní ọ̀rúndún kìíní. Jésù sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ táráyé ò rírú ẹ̀ rí tó máa fi hàn pé òpin ti sún mọ́lé. Jésù sọ fún wọn pé tí wọ́n bá ti bẹ̀rẹ̀ sí rí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ “kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.” (Mát. 24:1-3, 15-22) Ṣé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa dá àmì náà mọ̀, tí wọ́n á sì tẹ̀ lé ìtọ́ni Jésù?
2 Ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 61 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó fakíki tó sì gbàrònú sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù tó wà nílùú Jerúsálẹ́mù àti àgbègbè rẹ̀. Pọ́ọ̀lù àtàwọn onígbàgbọ́ tó kù ò mọ̀ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ “ìpọ́njú ńlá” máa wáyé ní ọdún márùn-ún sígbà yẹn. (Mát. 24:21) Lọ́dún 66 Sànmánì Kristẹni, Cestius Gallus kó àwọn ọmọ ogun Róòmù wá, wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣẹ́gun ìlú Jerúsálẹ́mù nígbà yẹn. Lójijì ni Cestius Gallus kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò, èyí sì fún àwọn Kristẹni láyè láti sá lọ síbi tí kò sí wàhálà.
3. Ọ̀rọ̀ ìyànjú wo ni Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù, kí sì nìdí?
3 Ó yẹ káwọn Kristẹni yẹn fòye mọ̀ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jésù, kí wọ́n sì sá lọ. Àmọ́, àwọn kan ti di ẹni tó “yigbì ní gbígbọ́.” Ńṣe ni wọ́n dà bí ìkókó nípa tẹ̀mí tó nílò “wàrà.” (Ka Hébérù 5:11-13.) Kódà, ó jọ pé àwọn tó ti ń rìn ní ọ̀nà òtítọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún náà ti ń fà sẹ́yìn “kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.” (Héb. 3: 12) Ó tún jẹ́ “àṣà” àwọn kan pé kí wọ́n máa pa ìpàdé Kristẹni jẹ, lákòókò tí ‘ọjọ́ àjálù náà ń sún mọ́lé.’ (Héb. 10:24, 25) Pọ́ọ̀lù wá sọ ọ̀rọ̀ ìyànjú kan tó bọ́ sákòókò fún wọn, ó ní: “Nísinsìnyí tí a ti fi àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ nípa Kristi sílẹ̀, ẹ jẹ́ kí a tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú.”—Héb. 6:1.
4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká wà lójúfò nípa tẹ̀mí, kí ló sì máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?
4 Àkókò tí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù máa ní ìmúṣẹ tó kẹ́yìn la wà yìí. “Ọjọ́ ńlá Jèhófà,” ìyẹn ọjọ́ tí gbogbo ètò Sátánì máa pa run ti “sún mọ́lé.” (Sef. 1: 14) Torí náà, àkókò yìí gan-an ló yẹ ká wà lójúfò nípa tẹ̀mí ju ti ìgbàkígbà rí lọ. (1 Pét. 5:8) Ṣé à ń ṣe bẹ́ẹ̀? Bí òtítọ́ bá ṣe jinlẹ̀ nínú wa tó ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí bí àkókò tá a wà yìí ti ṣe pàtàkì tó.
Ohun Tí Ìdàgbàdénú Túmọ̀ Sí
5, 6. (a) Kí ni ìdàgbàdénú nípa tẹ̀mí wé mọ́? (b) Àwọn nǹkan méjì wo la gbọ́dọ̀ sapá láti ṣe kí òtítọ́ lè jinlẹ̀ nínú wa?
5 Kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù kàn fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù níṣìírí pé kí wọ́n tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú nìkan ni, ó tún sọ ohun tí ìdàgbàdénú, ìyẹn kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹni, wé mọ́. (Ka Hébérù 5:14.) Kì í ṣe “wàrà” nìkan làwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn máa ń mu. Wọ́n máa ń jẹ “oúnjẹ líle.” Torí náà wọ́n mọ àwọn “ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀” àti “àwọn ohun ìjìnlẹ̀” tó jẹ́ ti òtítọ́. (1 Kọ́r. 2:10) Síwájú sí i, wọ́n ti tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn, ìyẹn bí wọ́n ṣe ń fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò, èyí sì ń jẹ́ kí wọ́n lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. Tó bá dọ̀rọ̀ kí wọ́n ṣèpinnu, ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti kọ́ máa ń jẹ́ kí wọ́n fòye mọ ìlànà Ìwé Mímọ́ tó wé mọ́ ìpinnu tí wọ́n fẹ́ ṣe àti bí wọ́n á ṣe fi ìlànà ọ̀hún sílò.
6 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ó . . . pọndandan fún wa láti fún àwọn ohun tí a gbọ́ ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, kí a má bàa sú lọ láé.” (Héb. 2:1) A lè ti sú lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́ láìfura. Àmọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ní ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá ń fún àwọn ohun tí a ń gbọ́ nígbà tá a bá pàdé fún ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run “ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.” Torí náà, ó yẹ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan bi ara rẹ̀ pé ‘Ṣé àwọn ohun àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ni mo ṣì mọ̀? Ṣé kì í ṣe pé mo kàn ń ṣe àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run lásán tí kò sì ti ọkàn mi wá? Báwo ni mo ṣe lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí ní ti gidi?’ Jíjẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wa gba pé ká sapá láti ṣe àwọn nǹkan méjì kan. Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ di ojúlùmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èkejì, a gbọ́dọ̀ kọ́ láti jẹ́ onígbọràn.
Di Ojúlùmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
7. Báwo la ṣe lè jàǹfààní tá a bá di ojúlùmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
7 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń mu wàrà jẹ́ aláìdojúlùmọ̀ ọ̀rọ̀ òdodo, nítorí tí ó jẹ́ ìkókó.” (Héb. 5:13) Ká tó lè dẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ di ojúlùmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Torí pé Bíbélì ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó yẹ ka máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìwé tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tẹ̀ jáde dáadáa. (Mát. 24:45-47) Bá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà yìí, á jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ àtohun tí kò fẹ́, a ó sì tipa báyìí kọ́ agbára ìwòye wa. Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ arábìnrin kan tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Orchid yẹ̀ wò.a Ohun tó sọ rèé: “Ìránnilétí náà pé ká máa ka Bíbélì déédéé lohun tó ti nípa pàtàkì jù lórí ìgbésí ayé mi. Ó gba ọdún méjì gbáko kí n tó lè ka Bíbélì tán, àmọ́ ṣe ló dà bíi pé mò ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọ Ẹlẹ́dàá mi fúngbà àkọ́kọ́. Mo kọ́ nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, ohun tó fẹ́ àtohun tí kò fẹ́, bí agbára rẹ̀ ṣe pọ̀ tó àti bí ọgbọ́n rẹ̀ kò ṣe láfiwé. Kíka Bíbélì lójoojúmọ́ ló gbé mi ró nígbà tí nǹkan ṣòro fún mi gan-an.”
8. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè sa agbára lórí wa?
8 Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé máa jẹ́ kí àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ “sa agbára” lórí wa. (Ka Hébérù 4:12.) Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun déédéé, á jẹ́ kí ìwà wa túbọ̀ dáa, inú Jèhófà á sì máa dùn sí wa. Ṣéwọ náà rí i pé ó yẹ kó o ṣètò àkókò tí wàá fi máa ka Bíbélì, kó o sì ṣàṣàrò lórí ohun tó o kà?
9, 10. Kí ni dídi ojúlùmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní nínú? Sọ àpẹẹrẹ kan.
9 Dídi ojúlùmọ̀ Bíbélì kọjá pé kéèyàn kàn mọ ohun tó wà níbẹ̀. Kì í kúkú ṣe pé àwọn tí Pọ́ọ̀lù pè ní ìkókó nígbà yẹn kò mọ ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ rárá. Àmọ́, wọn ò fi ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ṣèwà hù, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ méso rere jáde. Wọn ò di ojúlùmọ̀ ọ̀rọ̀ náà nípa jíjẹ́ kó máa darí wọn láti ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dáni nígbèésí ayé wọn.
10 Dídi ojúlùmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gba pé kéèyàn mọ ohun tó sọ, kó sì máa fi ṣèwà hù. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Kyle jẹ́ ka mọ bá a ṣe lè ṣe é. Àríyànjiyàn kan wáyé láàárín arábìnrin yìí àti ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Báwo ló ṣe wá yanjú àríyànjiyàn náà? Ó sọ pé: “Ẹsẹ Bíbélì tó wá sí mi lọ́kàn ni Róòmù 12:18, tó sọ pé: ‘Níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.’ Mo wá sọ fún ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ náà pé kó jẹ́ ká ríra tíṣẹ́ bá parí.” Wọ́n yanjú àríyànjiyàn náà, inú ẹni tọ̀hún sì dùn pé Arábìnrin Kyle gbé ìgbésẹ̀ láti yanjú ìṣòro náà. Arábìnrin Kyle wá sọ pé: “Mo mọ̀ pé a ò ní ṣì ṣe tá a bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì.”
Kọ́ Ìgbọràn
11. Kí ló fi hàn pé ó máa ń ṣòro láti ṣègbọràn nígbà tí ipò nǹkan bá le?
11 Ó lè ṣòro láti fi ohun tá a kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ sílò, ní pàtàkì jù lọ tí ipò nǹkan bá le. Bí àpẹẹrẹ, kò pẹ́ tí Jèhófà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lóko òǹdè àwọn ará Íjíbítì, tí wọ́n fi “bẹ̀rẹ̀ sí bá Mósè ṣe aáwọ̀” wọ́n sì ń bá a nìṣó “ní dídán Jèhófà wò.” Kí nìdí? Ìdí ni pé wọn kò rí omi mu. (Ẹ́kís. 17:1-4) Kò tíì pé oṣù méjì lẹ́yìn tí wọ́n wọnú májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, tí wọ́n sọ pé àwọn á ṣe “gbogbo [ohun] tí Jèhófà sọ” tí wọ́n fi rú òfin Ọlọ́run lórí ìbọ̀rìṣà. (Ẹ́kís. 24:3, 12-18; 32:1, 2, 7-9) Ṣé ó lè jẹ́ pípẹ́ tí Mósè pẹ́ nígbà tí Ọlọ́run ń fún un ní ìtọ́ni lórí Òkè Hórébù ló bà wọ́n lẹ́rù? Àbí ṣe ni wọ́n ronú pé àwọn ará Ámálékì lè gbógun dé, táwọn ọmọ Ísírẹ́lì á sì wà láìní olùgbèjà torí pé Mósè tí wọ́n gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè nígbà tí wọ́n ṣẹ́gun Ámálékì nígbà kan rí kò sí nílé? (Ẹ́kís. 17:8-16) Ó lè jẹ́ bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, àmọ́ láìkà ohun yòówù kó jẹ́ sí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “kọ̀ láti jẹ́ onígbọràn.” (Ìṣe 7:39-41) Pọ́ọ̀lù rọ àwa Kristẹni pé “kí a sa gbogbo ipá wa” ká má bàa “ṣubú sínú àpẹẹrẹ ọ̀nà àìgbọràn” táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi hàn nígbà tí wọ́n ń bẹ̀rù láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí.—Héb. 4: 3, 11.
12. Báwo ni Jésù ṣe kọ́ ìgbọràn, kí ló sì jẹ́ àbájáde rẹ̀?
12 Tá a bá fẹ́ tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú a gbọ́dọ̀ máa sa gbogbo ipá wa láti máa gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu. Bí àpẹẹrẹ Jésù ṣe fi hàn, a máa ń kọ́ ìgbọràn látinú ohun tá a jìyà rẹ̀. (Ka Hébérù 5:8, 9.) Jésù máa ń gbọ́ràn sí Bàbá rẹ̀ lẹ́nu ṣáájú kó tó wá sáyé. Àmọ́, jíjẹ́ onígbọràn sí Bàbá rẹ̀ nígbà tó wà láyé gba pé kó jìyà gidigidi, ó sì ní ẹ̀dùn ọkàn. Jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ onígbọràn nígbà tí nǹkan le gan-an sọ ọ́ “di pípé” fún iṣẹ́ tí Ọlọ́run fẹ́ gbé lé e lọ́wọ́, ìyẹn jíjẹ́ Ọba àti Àlùfáà Àgbà.
13. Kí ló máa fi hàn bóyá a ti kọ́ ìgbọràn?
13 Àwa ń kọ́? Ṣé a ti pinnu láti máa gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu kódà nígbà tá a bá dojú kọ ìṣòro tó ń pinni lẹ́mìí? (Ka 1 Pétérù 1:6, 7.) Ìmọ̀ràn tó ṣe kedere ni Ọlọ́run fún wa pé ká máa hùwà tó tọ́, ká jẹ́ aláìlábòsí, ká máa lo ahọ́n wa lọ́nà tó tọ́, ká máa ka Ìwé Mímọ́, ká máa dá kẹ́kọ̀ọ́, ká máa lọ sípàdé, ká sì máa wàásù. (Jóṣ. 1:8; Mát. 28:19, 20; Éfé. 4:25, 28, 29; 5:3-5; Héb. 10:24, 25) Ṣé a máa ń ṣègbọràn sí Jèhófà lórí àwọn nǹkan yìí kódà tá a bá wà nínú ìpọ́njú? Tá a bá jẹ́ onígbọràn, ńṣe là ń fi hàn pé òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wa.
Àǹfààní Wo Ló Wà Nínú Kéèyàn Dàgbà Nípa Tẹ̀mí?
14. Sọ àpèjúwe tó fi hàn pé ààbò ló jẹ́ tá a bá jẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wa.
14 Ààbò gidi ló jẹ́ fún Kristẹni kan láti kọ́ agbára ìwòye rẹ̀ kó lè máa fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ nínú ayé yìí táwọn èèyàn ti “ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere.” (Éfé. 4:19) Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin James, máa ń ka àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Ìwé Mímọ́, ó sì máa ń mọrírì ohun tó kà, ó wá ríṣẹ́ síbì kan tó jẹ́ pé obìnrin ni gbogbo àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Arákùnrin James sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára wọn ló jẹ́ oníṣekúṣe, àmọ́ obìnrin kan wà tó dá yàtọ̀ láàárín wọn, ó sì nífẹ̀ẹ́ sí kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà témi àti ẹ̀ nìkan dá wà nínú yàrà kan tá a ti ń ṣiṣẹ́, obìnrin yìí wá fẹ́ kí n bá òun lò pọ̀. Eré ni mo kọ́kọ́ pè é, mo gbìyànjú láti dá a dúró àmọ́ kò gbọ́. Mo wá rántí ìrírí kan tí mo kà nínú Ilé Ìṣọ́ nípa arákùnrin kan tó nírú ìṣòro yìí níbi iṣẹ́. Àpilẹ̀kọ náà lo àpẹẹrẹ Jósẹ́fù àti ìyàwó Pọ́tífárì.b Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, mo tì í dà nù, ló bá sá jáde.” (Jẹ́n. 39:7-12) Arákùnrin James dúpẹ́ pé òun ò hùwà pálapàla pẹ̀lú obìnrin náà, ọkàn òun sì mọ́.—1 Tím. 1:5.
15. Báwo ni dídàgbà nípa tẹ̀mí ṣe lè dáàbò bo ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa?
15 Tá a bá dàgbà nípa tẹ̀mí, ó tún máa ṣàǹfààní torí pé ó máa ń dáàbò bo ọkàn àyà wa ìṣàpẹẹrẹ, tí kò sì ní jẹ́ kí ‘onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́ gbé wa lọ.’ (Ka Hébérù 13:9.) Tá a bá ń sapá láti dàgbà nípa tẹ̀mí, ìyẹn á jẹ́ ká máa ronú lórí àwọn “ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílí. 1:9, 10) A ó sì tipa bẹ́ẹ̀ máa fi ìmoore hàn fún Ọlọ́run àtàwọn ohun tó ti pèsè fún àǹfààní wa. (Róòmù 3:24) Kristẹni kan tó ti “dàgbà di géńdé nínú agbára òye” máa ń fi irú ìmoore bẹ́ẹ̀ hàn ó sì máa ń tipa bẹ́ẹ̀ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.—1 Kọ́r. 14:20.
16. Kí ló ran arábìnrin kan lọ́wọ́ láti dẹni tó ‘fìdí ọkàn-àyà ẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in’?
16 Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Louise sọ pé, ìdí tóun fi ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni lákòókò kan lẹ́yìn tóun ṣèrìbọmi ni pé kóun lè tẹ́ àwọn èèyàn lọ́rùn. Ó ní: “Mi ò ṣohun àìtọ́ kankan o, àmọ́ tọkàntọkàn kọ́ ni mo fi ń sin Jèhófà. Mo wá rí i pé ó yẹ kí n ṣàwọn àyípadà kan kí n lè máa fún Jèhófà ní gbogbo ohun tí mo bá lè fún un. Àyípadà tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé kí n máa fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run.” Nígbà tí Arábìnrin Louise sapá láti ṣe ohun tó sọ yìí, ó wá dẹni tó ‘fìdí ọkàn-àyà ẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in,’ ìyẹn ló sì ràn án lọ́wọ́ nígbà tó ṣàìsàn tó le gan-an. (Ják. 5:8) Arábìnrin Louise sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn, àmọ́ mo ti wá sún mọ́ Jèhófà gan-an.”
“Ẹ Di Onígbọràn Láti Inú Ọkàn-Àyà”
17. Kí nìdí tí ṣíṣègbọràn fi ṣe pàtàkì ní ọ̀rúndún kìíní?
17 Ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà pé kí wọ́n “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú” gbà wọ́n là. Àwọn tó fetí sí ìmọ̀ràn yìí jẹ́ àwọn tó ní ìfòyemọ̀ tẹ̀mí tí wọ́n á fi dá àmì tí Jésù fún wọn mọ̀ pé tí wọ́n bá ti rí i, kí wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.” Nígbà tí wọ́n rí “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́,” ìyẹn àwọn ọmọ ogun Róòmù tó wọnú ìlú Jerúsálẹ́mù tí wọ́n sì yí i ká, wọ́n mọ̀ pé àkókò nìyẹn fún wọn láti sá lọ. (Mát. 24:15, 16) Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gbẹ́ni Eusebius tó jẹ́ òpìtàn nípa ṣọ́ọ̀ṣì ṣe sọ, àwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù tẹ̀ lé ìkìlọ̀ Jésù, wọ́n fi ìlú yẹn sílẹ̀, wọ́n sì sá lọ sí ìlú Pella tó jẹ́ ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá lágbègbè Gílíádì. Wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ àjálù tó burú jù lọ nínú ìtàn ìlú Jerúsálẹ́mù.
18, 19. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ onígbọràn lásìkò yìí? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
18 Bákan náà ni ìgbọ́ràn téèyàn máa ń ṣe torí pé òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹni ṣe máa dáàbò bò ó nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ, pé “ìpọ́njú ńlá” tí kò sírú ẹ̀ rí, bá máa ní ìmúṣẹ. (Mát. 24:21) Ṣé a máa ṣègbọràn tá a bá gbọ́ ìtọ́ni kánjúkánjú èyíkéyìí látọ̀dọ̀ “olóòótọ́ ìríjú náà”? (Lúùkù 12:42) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká kọ́ láti jẹ́ “onígbọràn láti inú ọkàn-àyà wá”!—Róòmù 6:17.
19 Ká tó lè dàgbà nípa tẹ̀mí, ó gba pé ká kọ́ agbára ìwòye wa. Ọ̀nà tá a gbà ń ṣe èyí ni nípa dídi ojúlùmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nípa kíkọ́ láti jẹ́ onígbọràn. Kì í rọrùn rárá fáwọn ọ̀dọ́ láti di ẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí bí wọ́n ṣe lè borí ìṣòro náà.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
b Wo àpilẹ̀kọ tí àkòrí ẹ̀ sọ pé “A Fún Wọn Lókun Láti Sọ Pé A Ò Jẹ́ Hùwà Àìtọ́ Láé” nínú Ilé Ìṣọ́, October 1, 1999.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?
• Kí ni ìdàgbàdénú, báwo la sì ṣe lè dẹni tó dàgbà dénú?
• Báwo ni dídi ojúlùmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè mú ká dẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí?
• Báwo la ṣe ń kọ́ ìgbọràn?
• Àwọn ọ̀nà wo la máa gbà jàǹfààní tá a bá jẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Fífi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò máa ń jẹ́ ká borí ìṣòro lọ́nà tó fi hàn pé a dàgbà nípa tẹ̀mí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]
Títẹ̀lé ìmọ̀ràn Jésù ló gba àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní là