“Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Yóò Sì Sún Mọ́ Yín”
Nígbà kan Rí àti Nísinsìnyí—Àwọn Ìlànà Bíbélì Ràn Án Lọ́wọ́ Láti Yí Padà
NÍGBÀ tí Adrian wà lọ́dọ̀ọ́, ó máa ń bínú fùfù, ó sì ní ẹ̀mí ìkórìíra. Nítorí pé inú rẹ̀ tètè máa ń ru ló ṣe máa ń bínú sódì. Ó máa ń mu ọtí, ó máa ń mu sìgá, oníṣekúṣe ẹ̀dá sì ni. Ẹhànnà làwọn èèyàn mọ Adrian sí, ó sì tún fín nǹkan sára tó fi hàn pé ó fẹ́ràn dídá rúgúdù sílẹ̀. Nígbà tó ń ṣàpèjúwe ara rẹ̀ láwọn àkókò yẹn, ó ní: “Mo máa ń ṣe irun mi bíi tàwọn ọmọ ìta, màá wá fi oje sí i kó lè dúró ṣánṣán, nígbà míì sì rèé, màá pa á láró pupa tàbí àwọ̀ mìíràn.” Adrian tún lu ihò sí imú rẹ̀.
Adrian àtàwọn ọmọ ìta tó jẹ́ ọ̀dọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kó lọ sínú ilé àwókù kan. Ibẹ̀ ni wọ́n ti máa ń mutí tí wọ́n sì máa ń lo oògùn olóró. Adrian sọ pé: “Mo máa ń lo oògùn líle tó máa ń mórí ẹni yá gágá, mo sì tún máa ń fi oògùn yẹn àti Valium gún ara mi lábẹ́rẹ́, bákan náà, gbogbo oògùn tí mo bá ti rí ni mo máa ń lò. Bí kò bá ti sí oògùn olóró lárọ̀ọ́wọ́tó, mà á wá lọ jí epo fà nínú ọkọ̀ àwọn ẹlòmíràn, kí n lè máa fa òórùn rẹ̀ sórí títí dì ìgbà tí yóò fi máa pa mí bí ọtí.” Ìgbésí ayé ọ̀daràn tí Adrian ń gbé wá sọ́ ọ di oníwà ipá paraku, ó sì máa ń halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn. Ó wá dẹni táwọn èèyàn ò fẹ́ bá da nǹkan pọ̀ mọ́. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ìṣesí rẹ̀ jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ẹ̀gbẹ́ búburú ṣọ̀rẹ́.
Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Adrian wá rí i pé kì í ṣe torí nǹkan mìíràn làwọn “ọ̀rẹ́” òun fi wá ń bá òun bí kò ṣe nítorí ire tara wọn. Kò tán síbẹ̀ o, ó sọ pé “gbogbo ìbínú mi àti ìwà ìpá tí mo hù kò ṣàṣeyọrí kankan.” Nígbà tí ìgbésí ayé rẹ̀ dìdàkudà tí gbogbo nǹkan sì tojú sú u, ó fi ẹgbẹ́ búburú yẹn sílẹ̀. Ó rí ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ kan ní ibi kan tí wọ́n tí ń kọ́lé, ìsọfúnni tá a mú jáde látinú Bíbélì tó wà nínú ìwé yẹn wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kíákíá ni Adrian dáhùn sí ìpè náà tó sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Àbájáde rẹ̀ ni pé kò pẹ́ tí Adrian fi bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ìlànà tó rí nínú Ìwé Mímọ́ sílò.
Bí Adrian ṣe túbọ̀ ń ní ìmọ̀ Bíbélì sí i ní ìmọ̀ yẹn ń ní ipa tó dára lórí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀, ó sì mú kó yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà. A ràn án lọ́wọ́ láti borí ìbínú fùfù, ó sì dẹni tó ń kó ara rẹ̀ níjàánu. Nítorí agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní, àkópọ̀ ìwà Adrian wá yàtọ̀ pátápátá sí ti tẹ́lẹ̀.—Hébérù 4:12.
Báwo wá ni Bíbélì ṣe lè lágbára lórí ẹnì kan tó báyẹn? Ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ ń ṣèrànwọ́ láti “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ.” (Éfésù 4:24) Bẹ́ẹ̀ ni o, àkópọ̀ ìwà wa máa ń yí padà tá a bá fi ìmọ̀ pípéye tó wà nínú Bíbélì ṣèwà hù. Ṣùgbọ́n báwo ni irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe ń yí àwọn èèyàn padà?
Lákọ̀ọ́kọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn àkópọ̀ ìwà tí kò bójú mu tá a ní láti pa tì. (Òwe 6:16-19) Lọ́nà kejì, Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá láti ní àwọn ànímọ́ tó dára tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń mú jáde. Ará àwọn ànímọ́ náà ni “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù àti ìkóra-ẹni-níjàánu.”—Gálátíà 5:22, 23.
Òye jíjinlẹ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run béèrè ló ràn Adrian lọ́wọ́ tó fi lè ṣàyẹ̀wò ara rẹ̀, tó sì rí àwọn àkópọ̀ ìwà tó yẹ kó ní àtèyí tó yẹ kó pa tì. (Jákọ́bù 1:22-25) Ṣùgbọ́n ìbẹ̀rẹ̀ lásán ṣì nìyẹn o. Ní àfikún si ìmọ̀, ó nílò ohun tí yóò sún ọkàn rẹ̀ ṣiṣẹ́, ìyẹn ohun tí yóò sún Adrian tí yóò fi fẹ́ láti yí padà.
Adrian kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn àkópọ̀ ìwà tó dára là ń kọ́ “ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán Ẹni tí ó dá a.” (Kólósè 3:10) Ó wá mọ̀ pé àkópọ̀ ìwà Kristẹni gbọ́dọ̀ jọ àkópọ̀ ìwà Ọlọ́run. (Éfésù 5:1) Nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Adrian kọ́ nípa bí Jèhófà ṣe máa ń hùwà sí àwọn èèyàn, ó sì ṣàkíyèsí àwọn ànímọ́ rere tí Ọlọ́run ní, irú bí ìfẹ́, inú rere, ìwà rere, àánú àti òdodo. Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ ló sún Adrian láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó sì làkàkà láti dẹni tí inú Jèhófà dùn sí.—Mátíù 22:37.
Bí àkókò ti ń lọ, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, Adrian borí ìbínú fùfù rẹ̀. Ní báyìí, ọwọ́ òun àti ìyàwó rẹ̀ dí ní fífi ìmọ̀ Bíbélì ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti yí ọnà wọn padà. Adrian sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọ̀rẹ́ mi tẹ́lẹ̀ ló ti kú báyìí, àmọ́ èmi wà láàyè tí mo ń gbádùn ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀.” Adrian wá di ẹ̀rí tó fara hàn kedere pé Bíbélì ní agbára láti yí àwọn èèyàn padà sí rere.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 25]
“Gbogbo ìbínú mi àti ìwà ìpá tí mo hù kò ṣàṣeyọrí kankan”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Ṣe É Mú lò
Díẹ̀ lára àwọn ìlànà Bíbélì tó ti mú káwọn tó máa ń bínú tí wọ́n sì jẹ́ oníwà ipá tẹ́lẹ̀ di ẹni àlàáfíà rèé:
“Ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú.” (Róòmù 12:18, 19) Ẹ jẹ́ kí Ọlọ́run pinnu ìgbà tó fẹ́ gbẹ̀san àti ara ẹni tí yóò ti gbẹ̀san. Òun lè ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé òun ló mọ ohun gbogbo, àti pé ẹ̀san èyíkéyìí tó bá wá látọ̀dọ̀ rẹ̀ máa ń fi ìdájọ́ pípé rẹ̀ hàn.
“Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.” (Éfésù 4:26, 27) Nígbà mìíràn, ẹnì kan lè rí ohun tó yẹ kó mú un bínú. Bí èyí bá wá ṣẹlẹ̀, kò yẹ kó máa bá a lọ “nínú ipò ìbínú” yẹn. Èé ṣe? Nítorí pé èyí lè sún onítọ̀hún ṣe ohun tó burú, tíyẹn á sì wá jẹ́ kó tipa bẹ́ẹ̀ “fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù,” táá sì wá dẹni tí inú Jèhófà kò dùn sí mọ́.
“Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀; Má ṣe gbaná jẹ kìkì láti ṣe ibi.” (Sáàmù 37:8) Bí a kò bá ṣàkóso èrò wa, ó lè jẹ́ ká hùwà àìníjàánu. Bí ẹnì kan bá fàyè gba ìrunú, onítọ̀hún lè sọ̀rọ̀ tí ò dáa tàbí kó ṣe ohun tí yóò pa àwọn tọ́rọ̀ kàn lára.