Ìgbọràn Oníwà-Bí-Ọlọ́run Nínú Ìdílé Tí Ó Yapa Níti Ìsìn
“Ó MÁA ń dunni ju ẹgba lọ. . . . Mo nímọ̀lára pé a lù mí káàkiri gbogbo ara mi, síbẹ̀ ẹnikẹ́ni kò sì lè rí i.” “Nígbà mìíràn ìgbésí-ayé máa ń sú mi . . . bíi pe kí n jáde kúrò nílé kí n má sì padà wá mọ́.” “Ó máa ń ṣòro láti ronú lọ́nà tí ó tọ́ nígbà mìíràn.”
Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn tí ó kún fún èrò-ìmọ̀lára fi àwọn ìmọ̀lára àìnírètí àti ìdánìkanwà hàn. Wọ́n wá láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n jìyà ìsọ̀rọ̀ èébú síni—ìfẹ̀sùnkanni, ìhalẹ̀mọ́ni, ìpeni-lórúkọ tí ń rẹnisílẹ̀, ìfinipegi—àti pàápàá ìluni láti ọ̀dọ̀ alábàáṣègbéyàwó àti àwọn mẹ́ḿbà ìdílé. Èéṣe tí a fi hùwà sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ́nà tí ó burú tó báyìí? Kìkì nítorí ìgbàgbọ́ ìsìn tí ó yàtọ̀. Lábẹ́ irú àyíká ipò báyìí, gbígbé nínú ìdílé tí ó yapa níti ìsìn máa ń mú kí ìjọsìn Jehofa jẹ́ ìpèníjà gidi kan. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn Kristian tí a ń jẹníyà báyìí máa ń ṣàṣeyọrí nínú fífi ìgbọràn oníwà-bí-Ọlọ́run hàn.
Ọpẹ́ ni pé, kì í ṣe nínú gbogbo ìdílé tí ó yapa níti ìsìn ni a ti máa ń rí irú làásìgbò àti másùnmáwo yìí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó wà dájúdájú. Àpèjúwe yìí ha bá ìdílé rẹ mu bí? Nígbà náà, ó lè ṣòro fún ọ láti ní ọ̀wọ̀ fún alábàáṣègbéyàwó tàbí fún àwọn òbí rẹ. Bí o bá jẹ́ aya nínú irú ipò yẹn tàbí àwọn ọmọ nínú irú àyíká báyìí, báwo ni o ṣe lè ṣàṣeyọrí nínú fífi ìgbọràn oníwà-bí-Ọlọ́run hàn nínú ìdílé tí ó yapa níti ìsìn? Ìtìlẹyìn wo ni àwọn yòókù lè fúnni? Báwo sì ni Ọlọrun ṣe ń wo ọ̀ràn náà?
Èéṣe Tí Ó Fi Ṣòro Gan-an Láti Ṣègbọràn?
Ìfẹ́ ara-ẹni tí ó jẹ́ ti ayé àti àìmoore ń ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú àwọn ìtẹ̀sí aláìpé wọ́n sì ń mú kí ìgbọràn oníwà-bí-Ọlọ́run di ìjàkadì nígbà gbogbo. Satani mọ èyí, ó sì ṣetán láti mú ọ ṣubú. Ó sábà máa ń lo mẹ́ḿbà ìdílé tí kò ní ìmọrírì àti ọ̀wọ̀ kankan fún àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Ọlọrun. Ọ̀pá-ìdiwọ̀n gíga tí o ní fún ohun ti ẹ̀mí àti tí ọ̀nà ìwà híhù sábà máa ń yàtọ̀ pátápátá sí ti àwọn ìdílé rẹ tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́. Èyí túmọ̀ sí ojú-ìwòye tí ó forígbárí níti ìwà híhù àti ìgbòkègbodò. (1 Peteru 4:4) Ìkìmọ́lẹ̀ náà láti yí ọ padà kúrò nínú rírìn ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá-ìdiwọ̀n Kristian lè gbóná janjan, níwọ̀n bí o ti ṣègbọràn sí àṣẹ náà pé: “Ẹ . . . jáwọ́ ninu ṣíṣàjọpín pẹlu wọn ninu awọn iṣẹ́ aláìléso tí ó jẹ́ ti òkùnkùn.” (Efesu 5:11) Ní ojú wọn kò sí ohun tí ó ṣe tí ó tọ̀nà mọ́. Gbogbo èyí jẹ́ nítorí ìsìn rẹ. Ìyá kan, nígbà tí àìsàn ọmọ rẹ̀ kó ìdààmú bá a, béèrè fún ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀ ó sì rí ìdáhùn tí kò báradé gbà pé, “Ìwọ tí o rí ààyè fún ìsìn rẹ; o kò nílò ìrànlọ́wọ́.” Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń dákún ìpèníjà ti ṣíṣe ìgbọràn.
Nígbà náà àwọn ìgbà mìíràn wà tí ẹ lè ṣàìfohùnṣọ̀kan lórí àwọn ọ̀ràn tí kò tàpá sí Ìwé Mímọ́ ní tààràtà. Síbẹ̀, o mọ̀ pé o jẹ́ apákan ìdílé kan àti pé dé àyè yẹn o ní àwọn ohun àìgbọdọ̀máṣe kan. Connie sọ pé: “Inú máa ń bí mi nígbà tí mo bá ronú nípa ìwà tí bàbá mi ń hù sí wa nítorí mo mọ̀ pé ó nímọ̀lára ìdánìkanwà. Mo níláti máa rán ara mi létí nígbà gbogbo láti máṣe bínú nítorí àtakò bàbá mi. Mo níláti sọ fún ara mi pé ìdí tí ó ṣe gúnmọ́ kan níláti wà tí ó fi hùwàpadà tàbí tí ó fi kọ ìdúró wa. Satani ni alákòóso ètò-ìgbékalẹ̀ nǹkan ìsinsìnyí.” Susan, tí ó fẹ́ aláìgbàgbọ́, sọ pẹ̀lú ìgbọ́kànlé pè: “Ní ìbẹ̀rẹ̀ mo máa ń ní ìmọ̀lára pé kí n kó kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀—ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́. Mo mọ̀ pé Satani ń lò ó láti dán mi wò ni.”
Akitiyan Satani láti mú ọ ní ìmọ̀lára àìjámọ́ nǹkankan lè dàbí ohun tí ń peléke síi. Ọjọ́ púpọ̀ lè kọjá láìsí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú alábàáṣègbéyàwó rẹ. Ìgbésí-ayé lè wá di ti adánìkanwà. Èyí lè mú kí ìgbọ́kànlé àti ọ̀wọ̀ ara-ẹni dínkù kí ó sì dán ìgbàgbọ́ rẹ nínú ìgbọràn oníwà-bí-Ọlọ́run wò. Àwọn ọmọ pàápàá máa ń ní ìmọ̀lára ìfìyàjẹni níti èrò-ìmọ̀lára àti ti ara. Nínú ọ̀ràn kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí wọn kọ̀, àwọn ọ̀dọ́ mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun lọ sí àwọn ìpàdé Kristian pẹ̀lú ìṣòtítọ́. Ọ̀kan lára wọn, tí ó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nísinsìnyí, jẹ́wọ́ pé: “A máa ń nímọ̀lára ìkétìtìrì àti bí ẹni pé okun ti tán nínú wa; a kì í lè sùn; ó máa ń bà wá lọ́kàn jẹ́.”
Kí Ni Ọlọrun Ń Retí Lọ́dọ̀ Rẹ?
Ìgbọràn sí Ọlọrun máa ń jẹ́ ohun àkọ́kọ́, ìgbọràn tí ó ní ààlà sí ipò orí ọkọ sì gbọ́dọ̀ jẹ́ bí Jehofa ti darí rẹ̀. (Ìṣe 5:29) Ìyẹn lè ṣòro, síbẹ̀ ó ṣeé ṣe. Máa wo Ọlọrun fún ìrànlọ́wọ́. Ó fẹ́ kí o “jọ́sìn ní ẹ̀mí ati òtítọ́,” kí o tẹ́tísílẹ̀ kí o sì juwọ́sílẹ̀ fún ìdarísọ́nà rẹ̀. (Johannu 4:24) Ìmọ̀ láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, bí ó ti ń kún ọkàn-àyà tí ó tọ́, ń súnni sí ìgbọràn àtọkànwá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àyíká ipò ara-ẹni rẹ lè yípadà, Jehofa tàbí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì í yípadà. (Malaki 3:6; Jakọbu 1:17) Jehofa ti yan ipò orí fún ọkọ. Òtítọ́ ṣì ni èyí yálà ó faramọ́ ipò orí ti Kristi tàbí bẹ́ẹ̀kọ́. (1 Korinti 11:3) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè ṣòro láti fàyàrán bí o bá dojúkọ ìfìyàjẹni àti ìtẹ́nilógo ìgbà gbogbo, ọmọ-ẹ̀yìn náà Jakọbu sọ pé: “Ọgbọ́n tí ó wá lati òkè . . . múra tán lati ṣègbọràn.” (Jakọbu 3:17) Láti mọ ipò orí yìí àti láti faramọ́ ọn láìṣe tàbítàbí béèrè fún ẹ̀mí Ọlọrun, ní pàtàkì èso ti ìfẹ́.—Galatia 5:22, 23.
Nígbà tí o bá nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan, ó rọrùn láti fi ìgbọràn oníwà-bí-Ọlọ́run hàn sí ọlá-àṣẹ tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá. Efesu 5:33 fúnni nímọ̀ràn pé: “Kí olúkúlùkù yín lẹ́nìkọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”
Gbé ọ̀ràn ti Jesu yẹ̀wò. A bú u a sì lù ú, síbẹ̀ òun kò kẹ́gàn ẹnikẹ́ni. Ó pa àkọsílẹ̀ tí kò ní àbàwọ́n mọ́ títí. (1 Peteru 2:22, 23) Kí Jesu tó lè jìyà irú àbùkù tí ó ga báyìí, ó nílò ìgboyà tí ó gadabú àti ìfẹ́ aláìjuwọ́sílẹ̀ fún Bàbá rẹ̀, Jehofa. Ṣùgbọ́n, ìfẹ́ “a máa farada ohun gbogbo.”—1 Korinti 13:4-8.
Paulu rán òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ Timoteu létí, ó sì rán wa létí lónìí pé: “Ọlọrun kò fún wa ní ẹ̀mí ojo, bíkòṣe ti agbára ati ti ìfẹ́ ati ti ìyèkooro èrò-inú.” (2 Timoteu 1:7) Ìfẹ́ tí ó jinlẹ̀ fún Jehofa àti fún Jesu Kristi lè sún ọ láti ṣe ìgbọràn oníwà-bí-Ọlọ́run nígbà tí ipò náà bá dàbí èyí tí kò ṣeé faradà. Èrò-inú tí ó yèkooro yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ojú-ìwòye tí ó wà déédéé àti láti pa àfiyèsí pọ̀ sórí ipò ìbátan rẹ pẹ̀lú Jehofa àti Jesu Kristi.—Fiwé Filippi 3:8-11.
Alábàáṣègbéyàwó Tí Ó Ṣàṣeyọrí Nínú Fífi Ìgbọràn Oníwà-bí-Ọlọ́run Hàn
Nígbà mìíràn o níláti dúró fún ìgbà pípẹ́ láti rí bí Jehofa yóò ṣe yanjú àwọn ìṣòro rẹ. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ kò kúrú rí. Obìnrin kan tí ó ń ṣàṣeyọrí nínú fífi ìgbọràn oníwà-bí-Ọlọ́run hàn fúnni ní ìmọ̀ràn pé: “Máa ṣe ohun tí Jehofa fún ọ ní agbára àti àǹfààní láti ṣe—láti máa jọ́sìn rẹ̀ ní àwọn ìpàdé àti àwọn àpéjọ, láti kẹ́kọ̀ọ́, láti lọ sẹ́nu iṣẹ́-ìsìn, àti láti gbàdúrà.” Ìsapá rẹ ni Jehofa ń bùkún, kì í wulẹ ṣe ohun tí o ṣàṣeparí. Nínú 2 Korinti 4:17, aposteli Paulu sọ pé ‘ìpọ́njú naa jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, ṣùgbọ́n fún awa ó ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ògo kan tí ó jẹ́ àìnípẹ̀kun.’ Ṣàṣàrò lórí èyí. Yóò jẹ́ kókó amúnidúró fún ọ. Aya kan ronú pé: “Ìgbésí-ayé ìdílé mi kò dára síi, nígbà mìíràn mo sì máa ń ṣe kàyéfì bí inú Jehofa bá dùn sí mi. Ṣùgbọ́n ohun kan tí mo gbà gẹ́gẹ́ bí ìbùkún rẹ̀ ni òtítọ́ náà pé mo máa ń borí ipò tí ó lekoko wọ̀nyí ní ọ̀nà tí ó dára ju ti ọkọ mi lọ. Mímọ̀ pé àwọn ìgbésẹ̀ wa dùn mọ́ Jehofa nínú máa ń jẹ́ kí gbogbo ìjàkadì wa jẹ́ ohun yíyẹ.”
Jehofa ṣèlérí pé òun kò ní jẹ́ kí o ní ìrírí àwọn ipò tí ó ju èyí tí o lè faradà lọ. Gbẹ́kẹ̀lé e. Ó mọ̀ jù ọ́ lọ, ó sì mọ̀ ọ́ ju bí o ṣe mọ ara rẹ lọ. (Romu 8:35-39; 11:33; 1 Korinti 10:13) Gbígbàdúrà sí Jehofa ní àwọn àyíká ipò tí ó ṣòro máa ń ṣèrànwọ́. Gbàdúrà fún ẹ̀mí rẹ̀ láti tọ́ ọ sọ́nà, ní pàtàkì nígbà tí o kò bá mọ ọ̀nà tí ìwọ yóò gbà tàbí bí ìwọ yóò ṣe mójútó ipò kan. (Owe 3:5; 1 Peteru 3:12) Rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i nígbà gbogbo fún sùúrù, ìkóra-ẹni-níjàánu, àti ìrẹ̀lẹ̀ láti ṣègbọràn sí ọlá-àṣẹ nínú ìgbésí-ayé rẹ. Onipsalmu náà sọ pé: “Oluwa ni àpáta mi, àti ìlú-olódi mi, àti olùgbàlà mi.” (Orin Dafidi 18:2) Rírántí èyí jẹ́ ìrànlọ́wọ́ tí ń múnilókun fún àwọn tí wọ́n wà nínú agboolé tí ó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ níti ìsìn.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, sa gbogbo ipá láti mú kí ìgbéyàwó rẹ jẹ́ aláyọ̀. Bẹ́ẹ̀ni, Jesu rí i tẹ́lẹ̀ pé ìhìnrere náà yóò mú ìyapa wá. Bí ó ti wù kí ó rí, gbàdúrà pé kí ìyapa kankan máṣe jẹ́ nítorí ìṣesí tàbí ìwà rẹ. (Matteu 10:35, 36) Pẹ̀lú góńgó yìí ní ọkàn, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ń dín ìṣòro ìgbéyàwó kù. Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ nìkan ni o ń fi ìṣesí tí ó tọ́ yìí hàn, ó lè ṣe púpọ̀ láti dènà kí ìṣòro dàgbà di gbúngbùngbún àti èdèkòyedè tí ó rékọjá ààlà. Sùúrù àti ìfẹ́ ṣe pàtàkì púpọ̀. “Jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́” kí o sì “kó ara rẹ ní ìjánu lábẹ́ ibi.”—2 Timoteu 2:24.
Aposteli Paulu di “ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo.” (1 Korinti 9:22) Bákan náà, bí o kò ti ní fi ẹrù-iṣẹ́ Kristian bánidọ́rẹ̀ẹ́, nígbà mìíràn o lè nílò àti ṣe àwọn àtúnṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ láti lo àkókò púpọ̀ síi pẹ̀lú alábàáṣègbéyàwó àti ìdílé rẹ. Fún ẹni náà tí o yàn láti ṣàjọpín ìgbésí-ayé rẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní àkókò bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Fi ìgbatẹnirò Kristian hàn. Èyí jẹ́ àfihàn ìgbọràn oníwà-bí-Ọlọ́run.
Ó rọrùn fún aya kan tí ó bẹ̀rù Ọlọrun tí ó sì ní ìtẹríba tí ó mọwọ́ọ́padà tí ó sì ní ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn láti fi ìgbọràn oníwà-bí-Ọlọ́run hàn. (Efesu 5:22, 23) Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ní oore-ọ̀fẹ́, “tí a fi iyọ̀ dùn,” máa ń ṣèrànwọ́ láti dín ṣíṣeéṣe náà pé kí ìkonilójú wà lemọ́lemọ́ kù.—Kolosse 4:6; Owe 15:1.
Ọgbọ́n tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá gbaniníyànjú láti yanjú èdèkòyedè kíákíá àti láti dá àlàáfíà padà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí ń gbéniró, dípò lílọ sùn ní “ipò ìtánnísùúrù.” (Efesu 4:26, 29, 31) Èyí ń béèrè ìrẹ̀lẹ̀. Gbáralé Jehofa pátápátá fún okun. Kristian aya kan fìrẹ̀lẹ̀ gbà pé: “Lẹ́yìn àdúrà onígbòóná-ọkàn, mo ti ní ìrírí ẹ̀mí Jehofa tí ó ti fún mi lókun láti fi ìṣesí onífẹ̀ẹ́ hàn sí ọkọ mi.” Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fúnni ní ìmọ̀ràn pé: “Ẹ máṣe fi ibi san ibi fún ẹni kankan. . . . Máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Romu 12:17-21) Èyí jẹ́ ìmọ̀ràn tí ó bọ́gbọ́n mu ó sì jẹ́ ipa-ọ̀nà ìgbọràn oníwà-bí-Ọlọ́run.
Àwọn Ọmọ Tí Wọ́n Fi Ìgbọràn Oníwà-bí-Ọlọ́run Hàn
Ìmọ̀ràn Jehofa fún ẹ̀yin ọmọ tí ó wà nínú ilé tí ó yapa níti ìsìn ni pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí awọn òbí yín ninu ohun gbogbo, nitori èyí wuni gidigidi ninu Oluwa.” (Kolosse 3:20) Ṣàkíyèsí pé Jesu Kristi Oluwa ní a mú wọ inú ọ̀ràn náà. Nítorí ìdí èyí, ìgbọràn sí àwọn òbí kì í ṣe aláìláàlà. Ní ọ̀nà kan ìmọ̀ràn tí ó wà nínú Ìṣe 5:29, pé “ṣègbọràn sí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò awọn ènìyàn,” náà kan àwọn ọ̀dọ́ Kristian. Àwọn ipò yóò dìde nígbà tí ìwọ yóò níláti pinnu ohun tí o níláti ṣe lórí ìpìlẹ̀ ohun tí o mọ̀ pé ó tọ̀nà lójú ìlànà Ìwé Mímọ́. Kíkọ̀ láti lọ́wọ́ nínú àwọn ìṣe ìjọsìn èké lè yọrí sí àwọn ọ̀nà ìjìyà kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfojúsọ́nà tí kò báradé ni èyí, o lè rí ìtùnú o sì lè yọ̀ pàápàá nítorí òtítọ́ náà pé o ń jìyà fún ṣíṣe ohun tí ó tọ́ lójú Ọlọrun.—1 Peteru 2:19, 20.
Níwọ̀n bí àwọn ìlànà Bibeli ti ń tọ́ àwọn ìrònú rẹ sọ́nà, o lè ṣàìfohùn sọ̀kan pẹ̀lú àwọn òbí rẹ nínú àwọn ọ̀ràn kan. Èyí kò sọ wọ́n di ọ̀tá rẹ. Àní bí wọn kò bá tilẹ̀ jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ olùṣèyàsímímọ́ fún Jehofa, ọlá tí ó tọ́ yẹ fún wọn. (Efesu 6:2) Solomoni sọ pé: “Fetísí ti bàbá rẹ tí ó bí ọ, má sì ṣe gan ìyá rẹ.” (Owe 23:22) Gbìyànjú láti lóye bí ó ti ń dùn wọ́n tó nítorí títọpasẹ̀ ìgbàgbọ́ tí ó dàbí ohun tí ó ṣàjèjì sí wọn. Bá wọn sọ̀rọ̀ pọ̀, sì ‘jẹ́ kí ìfòyebánilò rẹ di mímọ̀.’ (Filippi 4:5) Sọ àwọn ìmọ̀lára àti àníyàn rẹ jáde. Dìrọ̀ gbọn-in-gbọn-in mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọrun, síbẹ̀, ‘bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ rẹ ni ó wà, jẹ́ ẹlẹ́mìí-àlàáfíà pẹlu gbogbo ènìyàn.’ (Romu 12:18) Òtítọ́ náà pé o ṣègbọràn sí àṣẹ òbí nísinsìnyí fi hàn Jehofa pé o ń nífẹ̀ẹ́-ọkàn láti máa bá a lọ bí onígbọràn gẹ́gẹ́ bí ọmọ abẹ́ Ìjọba náà.
Ohun Tí Àwọn Mìíràn Lè Ṣe
Àwọn Kristian tí wọ́n ń gbé nínú àwọn ìdílé tí ó yapa níti ìsìn nílò ìṣírí àti ẹ̀mí ìbákẹ́dùn láti ọ̀dọ̀ àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn. Èyí hàn gbangba láti inú àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan sọ pé: “Mo ní ìmọ̀lára àìnírètí àti àìlólùrànlọ́wọ́ pátápátá, níwọ̀n bí kò ti sí ohun tí ẹnikẹ́ni lè ṣe, kò sì sí ohun tí mo lè ṣe láti yí i padà. Mo ń gbẹ́kẹ̀lé Jehofa láti mú ìfẹ́-inú rẹ̀ ṣẹ nínú ìdílé wa, ohunkóhun tí ó wù kí ó jẹ́.”
Ìkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin nípa ti ẹ̀mí nínú àwọn ìpàdé Kristian jẹ́ ààbò kan. Ẹnì kan náà yìí ṣàpèjúwe ìgbésí-ayé rẹ̀ bí èyí tí ó dàbí “oríṣi ayé méjì. Ọ̀kan di dandan fún mi láti wà nínú rẹ̀ ọ̀kan ni mo sì fẹ́ láti wà nínú rẹ̀.” Ìfẹ́ ẹgbẹ́ àwọn ará ni ó mú un ṣeé ṣe fún àwọn wọ̀nyí tí a ń pọ́n lójú láti lo ìfaradà kí wọ́n sì ṣiṣẹ́sìn nínú gbogbo àyíká ipò. Máa rántí wọn nínú àdúrà rẹ. (Efesu 1:16) Ní gbogbo ìgbà, àti déédéé, máa sọ̀rọ̀ tí ń gbéniró, ọ̀rọ̀ rere, tí ó sì ń tuni nínú sí wọn. (1 Tessalonika 5:14) Nígbà tí ó bá ṣeé ṣe tí ó sì bọ́ sí àkókò, fi wọ́n kún àwọn ìgbòkègbodò iṣẹ́-òjíṣẹ́ àti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà rẹ.
Àwọn Ìbùkún àti Àǹfààní ti Ìgbọràn Oníwà-bí-Ọlọ́run
Ṣàṣàrò lójoojúmọ́ lórí àwọn ìbùkún àti àǹfààní tí ó wà nínú ṣíṣàfihàn ìgbọràn oníwà-bí-Ọlọ́run nínú ìdílé tí ó yapa níti ìsìn. Ṣiṣẹ́ síhà jíjẹ́ onígbọràn. ‘Máṣe ṣàárẹ̀.’ (Galatia 6:9) Fífarada àwọn àyíká ipò tí kò báradé àti àìṣèdájọ́-òdodo “nitori ẹ̀rí-ọkàn sí Ọlọrun . . . jẹ́ ohun kan tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà” lọ́dọ̀ Ọlọrun. (1 Peteru 2:19, 20) Jẹ́ onígbọràn dé ìwọ̀n àyè tí o kò ní fi àwọn ìlànà òdodo àti àwọn òfin Jehofa bánidọ́rẹ̀ẹ́. Èyí fi ìdúrósinsin sí ìṣètò Jehofa hàn. Ìwà oníwà-bí-Ọlọ́run rẹ tilẹ̀ lè gba ìwàláàyè alábàáṣègbéyàwó rẹ, àwọn ọmọ rẹ, tàbí àwọn òbí rẹ là.—1 Korinti 7:16; 1 Peteru 3:1.
Bí o ti ń jìjàkadì láti dójú ìwọ̀n àwọn ohun tí a fi dandan béèrè fún àti àwọn ohun àfojúsọ́nà fún ti ìdílé tí ó yapa níti ìsìn, rántí ìjẹ́pàtàkì dídi ìṣòtítọ́ sí Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi mú. O lè juwọ́sílẹ̀ lórí èdèkòyedè tí ó pọ̀, ṣùgbọ́n jíjuwọ́sílẹ̀ níti ìṣòtítọ́ jẹ́ jíjuwọ́sílẹ̀ nínú ohun gbogbo, tí ó ní nínú ìwàláàyè fúnra rẹ̀. Aposteli Paulu sọ pé: “Ọlọrun . . . ti tipasẹ̀ Ọmọkùnrin kan bá wa sọ̀rọ̀ ní òpin awọn ọjọ́ wọnyi, ẹni tí oun yànsípò gẹ́gẹ́ bí ajogún ohun gbogbo, ati nípasẹ̀ ẹni tí oun dá awọn ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan.” Mímọ “ìgbàlà kan tí ó tóbi tó bẹ́ẹ̀” yìí yóò fún ọ lókun láti ṣègbọràn.—Heberu 1:1, 2; 2:3.
Ìṣègbọràn àti ìdúrósinsin rẹ sí àwọn ọ̀nà ìwàrere àti àwọn ìjẹ́pàtàkì tí o kò fi bánidọ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ààbò tí ó lókun fún ọ àti fún alábàáṣègbéyàwó tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́. Ìṣòtítọ́ máa ń mú kí ìdè ìdílé lókun síi. Owe 31:11 sọ nípa aya oníwàrere àti adúróṣinṣin pé: “Àyà ọkọ rẹ̀ gbẹ́kẹ̀lé e láìbẹ̀rù.” Ìwàmímọ́ rẹ àti ọ̀wọ̀ tí ó jinlẹ̀ lè ṣí ojú ọkọ rẹ aláìgbàgbọ́. Ó lè darí rẹ̀ láti tẹ́wọ́gba òtítọ́ Ọlọrun.
Ìgbọràn oníwà-bí-Ọlọ́run ṣe iyebíye ó sì ń gbanilà nítòótọ́. Gbàdúrà fún un nínú ìgbésí-ayé ìdílé rẹ. Yóò yọrí sí àlàáfíà ọkàn yóò sì mú ìyìn wá bá Jehofa.