Ẹ Má Ṣe Fàyè Sílẹ̀ Fún Èṣù
“Ẹ má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.”—ÉFÉSÙ 4:27.
1. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń rò pé bóyá ni Èṣù wà?
OJÚ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wo Èṣù tipẹ́tipẹ́ ni pé ó jẹ́ ẹ̀dá kan tó ní ìwo lórí, tó ní pátákò lẹ́sẹ̀, tó ń wọ aṣọ pupa, tó sì ń fi àmúga ńlá sọ àwọn ẹni ibi sínú ọ̀run àpáàdì. Irú èrò bẹ́ẹ̀ ò bá ohun tó wà nínú Bíbélì mu. Àmọ́ láìsí àní-àní, irú èrò òdì bẹ́ẹ̀ ti mú kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn máa rò pé bóyá ni Èṣù wà, tàbí kí wọ́n rò pé ohunkóhun tó bá ṣáà jẹ́ ibi ni Èṣù.
2. Kí làwọn nǹkan tí Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ nípa Èṣù?
2 Bíbélì sọ fún wa pé ẹnì kan wà tó fojú rí Èṣù, ó sì jẹ́ ká rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn dájú pé Èṣù wà lóòótọ́. Jésù Kristi rí i nígbà tí wọ́n jọ wà lókè ọ̀run, wọ́n sì jọ sọ̀rọ̀ nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé. (Jóòbù 1:6; Mátíù 4:4-11) Ìwé Mímọ́ ò sọ orúkọ tí Ọlọ́run pilẹ̀ sọ ẹ̀dá ẹ̀mí yìí ní gbàrà tó dá a, àmọ́ ó pè é ní Èṣù, tó túmọ̀ sí “Afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́” ní èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Irọ́ tó pa láti fi ba Ọlọ́run jẹ́ ló fi gba orúkọ yìí. Bíbélì tún pè é ní Sátánì (tó túmọ̀ sí “Alátakò”), torí pé ó ta ko Jèhófà. Bíbélì sì tún sọ pé Sátánì Èṣù ni “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀,” bóyá torí pé ó lo ejò láti fi tan Éfà jẹ. (Ìṣípayá 12:9; 1 Tímótì 2:14) Òun sì tún ni “ẹni burúkú náà.”—Mátíù 6:13.a
3. Ìbéèrè wo la fẹ́ dáhùn báyìí?
3 Àwa tá a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà kò fẹ́ fìwà jọ Èṣù olórí ọ̀tá Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà lọ́nàkọnà. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá pé: “Ẹ má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.” (Éfésù 4:27) Nígbà náà, kí ni díẹ̀ lára àwọn ìwà Sátánì tá ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó ràn wá?
Má Ṣe Fìwà Jọ Olórí Afọ̀rọ̀-Èké-Banijẹ́ Náà
4. Báwo ni “ẹni burúkú náà” ṣe purọ́ láti fi ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́?
4 Èṣù ló yẹ ká máa pè ní “ẹni burúkú náà” torí pé afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ ni. Ńṣe ni abanijẹ́ èèyàn máa ń mọ̀ọ́mọ̀ parọ́ ohun téèyàn ò ṣe mọ́ni láti lè bani lórúkọ jẹ́. Ọlọ́run pàṣẹ fún Ádámù pé: “Ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Éfà náà gbọ́ bẹ́ẹ̀ o, ṣùgbọ́n Èṣù lọ gbẹnu ejò sọ fún Éfà pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú. Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:4, 5) Irọ́ ńlá ni Èṣù pa yìí o láti fi ba Jèhófà Ọlọ́run lórúkọ jẹ́!
5. Kí nìdí tó fi yẹ́ kí Dìótíréfè jẹ́jọ́ ìwà ìbanilórúkọjẹ́ tó hù?
5 Ọ̀kan nínú òfin tí Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ máa lọ káàkiri láàárín àwọn ènìyàn rẹ láti fọ̀rọ̀ èké bani jẹ́.” (Léfítíkù 19:16) Àpọ́sítélì Jòhánù sọ̀rọ̀ ẹnì kan tó jẹ́ abanijẹ́ nígbà ayé rẹ̀ pé: “Mo kọ̀wé ohun kan sí ìjọ, ṣùgbọ́n Dìótíréfè, ẹni tí ń fẹ́ láti gba ipò àkọ́kọ́ láàárín wọn, kò fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ gba ohunkóhun láti ọ̀dọ̀ wa. Ìdí nìyẹn, bí mo bá dé, tí èmi yóò fi rántí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ń bá a lọ ní ṣíṣe, tí ó ń fi àwọn ọ̀rọ̀ burúkú wírèégbè nípa wa.” (3 Jòhánù 9, 10) Dìótíréfè ń sọ̀rọ̀ burúkú nípa Jòhánù láti fi bà á lórúkọ jẹ́, ó sì di dandan kó jẹ́jọ́ ohun tó ṣe. Kò sí Kristẹni tòótọ́ tó máa fẹ́ dà bí Dìótíréfè kó sì wá fìwà jọ Sátánì olórí afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, àbí ó wà?
6, 7. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ rí i pé a ò ba ẹnikẹ́ni lórúkọ jẹ́?
6 Àwọn èèyàn kan máa ń sọ̀rọ̀ tí wọ́n á fi ba àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lórúkọ jẹ́, tàbí kí wọ́n fẹ̀sùn èké kàn wọ́n. Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ: “Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin wà ní ìdúró, wọ́n sì ń fẹ̀sùn [kan Jésù] kíkankíkan.” (Lúùkù 23:10) Ananíà Àlùfáà Àgbà àtàwọn míì náà fẹ̀sùn èké kan Pọ́ọ̀lù. (Ìṣe 24:1-8) Bíbélì sì pe Sátánì ní “olùfisùn àwọn arákùnrin wa . . . , ẹni tí ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tọ̀sán-tòru níwájú Ọlọ́run wa.” (Ìṣípayá 12:10) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí làwọn arákùnrin tí ibí yìí sọ pé Sátánì ń fẹ̀sùn kàn yìí o.
7 Kò yẹ kí Kristẹni bani lórúkọ jẹ́ tàbí kó fẹ̀sùn èké kan ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n ìyẹn lè ṣẹlẹ̀ tá ò bá mọ àtòkèdélẹ̀ ọ̀rọ̀ kan ká tó lọ jẹ́rìí ta ko ẹlòmíràn. Lábẹ́ Òfin Mósè, tẹ́nì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ jẹ́rìí èké, onítọ̀hún lè kú sí i. (Ẹ́kísódù 20:16; Diutarónómì 19:15-19) Síwájú sí i, ara àwọn ohun tí Jèhófà kórìíra ni “ẹlẹ́rìí èké tí ń gbé irọ́ yọ.” (Òwe 6:16-19) Dájúdájú, a gbọ́dọ̀ rí i pé a ò ṣe ohun táa mú wa dà bí olórí afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ àti afẹ̀sùn-èké-kanni náà.
Má Fìwà Jọ Apànìyàn Àkọ́kọ́
8. Ọ̀nà wo ni Èṣù gbà jẹ́ ‘apànìyàn nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀’?
8 Apànìyàn ni Èṣù. Jésù sọ pé: “Apànìyàn ni ẹni yẹn nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀.” (Jòhánù 8:44) Látìgbà tí Sátánì ti yí Ádámù àti Éfà lọ́kàn padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run ló ti di apànìyàn. Òun ló jẹ́ kí tọkọtaya àkọ́kọ́ yìí àti àtọmọdọ́mọ wọn máa kú. (Róòmù 5:12) Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé ẹ̀dá alààyè nìkan ló lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, èrò ibi tí ń bẹ lọ́kàn èèyàn ò lè ṣe é.
9. Kí ni 1 Jòhánù 3:15 sọ pé ó lè sọni di apànìyàn?
9 Ọ̀kan nínú Òfin Mẹ́wàá tí Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì ni pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn.” (Diutarónómì 5:17) Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń kọ̀wé sí àwọn Kristẹni, ó sọ pé: “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má jìyà gẹ́gẹ́ bí òṣìkàpànìyàn.” (1 Pétérù 4:15) Nítorí náà kò sí ìránṣẹ́ Jèhófà tó máa fẹ́ pànìyàn. Ṣùgbọ́n àá jẹ̀bi lọ́dọ̀ Ọlọ́run tá a bá kórìíra Kristẹni bíi tiwa, tá a sì ń rò ó lọ́kàn pé ì bá dára kí ikú pa á dà nù. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apànìyàn, ẹ̀yin sì mọ̀ pé kò sí apànìyàn kankan tí ìyè àìnípẹ̀kun dúró nínú rẹ̀.” (1 Jòhánù 3:15) Àṣẹ tí Ọlọ́run pa fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ nínú ọkàn-àyà rẹ.” (Léfítíkù 19:17) Nítorí náà, á dára ká tètè máa yanjú ìṣòro yòówù kó wà láàárín àwa àti onígbàgbọ́ bíi tiwa, kí Sátánì apànìyàn nì má bàa ba ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa Kristẹni jẹ́.—Lúùkù 17:3, 4.
Má Gba Olórí Òpùrọ́ Náà Láyè
10, 11. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká má bàa gba Sátánì, olórí òpùrọ́ náà láyè?
10 Òpùrọ́ ni Èṣù. Jésù sọ pé: “Nígbà tí ó bá ń pa irọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtẹ̀sí-ọkàn ara rẹ̀, nítorí pé òpùrọ́ ni àti baba irọ́.” (Jòhánù 8:44) Sátánì purọ́ fún Éfà, àmọ́ ńṣe ni Jésù wá sáyé ní tirẹ̀ láti wá jẹ́rìí sí òtítọ́. (Jòhánù 18:37) Tí àwa ọmọlẹ́yìn Kristi ò bá ní gbà fún Èṣù, a ní láti jẹ́ kí irọ́ àti ẹ̀tàn jìnnà sí wa pátápátá. A gbọ́dọ̀ máa “sọ òtítọ́.” (Sekaráyà 8:16; Éfésù 4:25) Àwọn Ẹlẹ́rìí tó bá jẹ́ olóòótọ́ nìkan ni “Jèhófà Ọlọ́run òtítọ́” máa ń bù kún. Àwọn ẹni burúkú ò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣojú fún un rárá.—Sáàmù 31:5; 50:16; Aísáyà 43:10.
11 Tá a bá mọyì bá ò ṣe sí lára àwọn tí Sátánì ń purọ́ tàn jẹ nítorí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a mọ̀, a ò ní yà kúrò nínú ẹ̀kọ́ Kristẹni tí í ṣe “ọ̀nà òtítọ́.” (2 Pétérù 2:2; Jòhánù 8:32) Gbogbo ẹ̀kọ́ Kristẹni látòkèdélẹ̀ ló para pọ̀ jẹ́ “òtítọ́ ìhìn rere.” (Gálátíà 2:5, 14) Ká tó lè rí ìgbàlà, a gbọ́dọ̀ máa “bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́,” ìyẹn ni pé ká má ṣe yẹsẹ̀ nínú rẹ̀, ká má sì gba “baba irọ́” náà láyè rárá.—3 Jòhánù 3, 4, 8.
Má Gbà fún Olórí Apẹ̀yìndà Náà
12, 13. Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sí àwọn apẹ̀yìndà?
12 Ẹ̀dá ẹ̀mí tó di Èṣù ti wà nínú òtítọ́ rí. Àmọ́ Jésù sọ pé: “Kò . . . dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, nítorí pé òtítọ́ kò sí nínú rẹ̀.” (Jòhánù 8:44) Olórí apẹ̀yìndà yìí sọ ara rẹ̀ dẹni tó ń ta ko “Ọlọ́run òtítọ́” nígbà gbogbo. Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn Kristẹni kan kó sí “ìdẹkùn Èṣù.” Bí wọ́n sì ṣe bọ́ sínú ìdẹkùn rẹ̀ ni pé wọ́n jẹ́ kó ṣi àwọn lọ́nà, wọ́n sì yapa kúrò nínú òtítọ́. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi gba Tímótì alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ níyànjú pé kó fi ìwà tútù fún wọn ní ìtọ́ni kí wọ́n lè padà máa ṣe dáadáa nínú ìjọsìn Ọlọ́run kí wọ́n sì bọ́ kúrò nínú ìdẹkùn Sátánì. (2 Tímótì 2:23-26) Àmọ́ ṣá o, ohun tó ti dáa ni pé kéèyàn má tiẹ̀ fìgbà kan kúrò nínú òtítọ́, kó má sì jẹ́ kí èrò àwọn apẹ̀yìndà kó bá òun lọ́nàkọnà.
13 Títẹ́tí tí tọkọtaya àkọ́kọ́ tẹ́tí sí Èṣù, tí wọn ò kọ irọ́ tó pa mú kí wọ́n di apẹ̀yìndà. Nítorí náà, ǹjẹ́ ó yẹ ká tẹ́tí sí àwọn apẹ̀yìndà tàbí ká ka ìwé wọn tàbí ká tiẹ̀ ṣí ibi tí ọ̀rọ̀ wọn máa ń wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Bí a bá fẹ́ràn Ọlọ́run tá a sì fẹ́ràn òtítọ́, a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ rárá. A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn apẹ̀yìndà wọnú ilé wa, a kò sì gbọ́dọ̀ kí wọn rárá nítorí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀ a óò di ‘alájọpín nínú àwọn iṣẹ́ burúkú wọn.’ (2 Jòhánù 9-11) Á dára ká má ṣe jẹ́ kí Èṣù fi ètekéte rẹ̀ mú wa o, ìyẹn ni pé ká rí i dájú pé a ò fi “ọ̀nà òtítọ́” Kristẹni sílẹ̀ láti tẹ̀ lé àwọn olùkọ́ni èké tí wọ́n ń fẹ́ “mú ẹ̀kọ́kẹ́kọ̀ọ́ wọ ààrin” wa, tí wọ́n sì ń fẹ́ ‘fi ọ̀rọ̀ dídùn tàn wá jẹ.’—2 Pétérù 2:1-3, Ìròhìn Ayọ̀.
14, 15. Ìkìlọ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn alàgbà tó wá láti Éfésù àti Tímótì alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀?
14 Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn alàgbà ìjọ tó wá láti Éfésù pé: “Ẹ kíyè sí ara yín àti gbogbo agbo, láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yín ṣe alábòójútó, láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run, èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà. Mo mọ̀ pé lẹ́yìn lílọ mi, àwọn aninilára ìkookò yóò wọlé wá sáàárín yín, wọn kì yóò sì fi ọwọ́ pẹ̀lẹ́tù mú agbo, àti pé láàárín ẹ̀yin fúnra yín ni àwọn ènìyàn yóò ti dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:28-30) Irú àwọn apẹ̀yìndà bẹ́ẹ̀ yọjú lóòótọ́ nígbà tó yá, wọ́n sì “sọ àwọn ohun àyídáyidà.”
15 Ní nǹkan bí ọdún 65 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì pé kó “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” Ó sì sọ pé: “Ṣùgbọ́n máa yẹ àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ sílẹ̀, tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́; nítorí tí wọn yóò tẹ̀ síwájú sí àìṣèfẹ́ Ọlọ́run síwájú àti síwájú, ọ̀rọ̀ wọn yóò sì tàn kálẹ̀ bí egbò kíkẹ̀. Híméníọ́sì àti Fílétọ́sì wà lára wọn. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí pàápàá ti yapa kúrò nínú òtítọ́, wọ́n ń sọ pé àjíǹde ti ṣẹlẹ̀ ná; wọ́n sì ń dojú ìgbàgbọ́ àwọn kan dé.” Bí ìpẹ̀yìndà ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn o! Àmọ́ Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Láìka gbogbo èyíinì sí, ìpìlẹ̀ lílágbára ti Ọlọ́run dúró sẹpẹ́.”—2 Tímótì 2:15-19.
16. Kí ló ń jẹ́ ká lè dúró ṣinṣin sí Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lójú gbogbo ètekéte olórí apẹ̀yìndà náà?
16 Sátánì sábà máa ń lo àwọn apẹ̀yìndà bóyá á lè rí wọn fi sọ ìjọsìn tòótọ́ dìbàjẹ́, àmọ́ pàbó ló ń já sí. Ní nǹkan bí ọdún 1868, Charles Taze Russell bẹ̀rẹ̀ sí i yẹ àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti fi ń kọ́ni láti ọdúnmọ́dún wò kínníkínní, ó wá rí i pé wọ́n ti gbé ìtumọ̀ Bíbélì gbòdì lọ́pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Bí Russell àtàwọn mélòó kan tí wọ́n ń wá òtítọ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí i kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ déédéé nílùú Pittsburgh, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìyẹn. Láti nǹkan bí ogóje ọdún yẹn wá ni ìfẹ́ tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní sí Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti ń pọ̀ sí i, ìmọ̀ wọn sì ti jinlẹ̀ sí i. Wíwà tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye sì wà lójúfò ló jẹ́ kí wọ́n lè dúró ṣinṣin sí Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lójú gbogbo ètekéte Èṣù olórí apẹ̀yìndà náà.—Mátíù 24:45.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Olùṣàkóso Ayé Máa Darí Rẹ
17-19. Kí ni ayé tó wà lábẹ́ agbára Èṣù, kí sì nìdí tí kò fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ayé náà?
17 Ìdẹkùn míì tí Sátánì máa ń gbìyànjú láti fi mú wa ni pé ó máa ń ṣe ohun tó máa mú ká fẹ́ràn ayé, ìyẹn àwọn èèyàn tó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Jésù pe Èṣù ní “olùṣàkóso ayé,” ó sì sọ pé: “Kò . . . ní ìdìmú kankan lórí mi.” (Jòhánù 14:30) Á dára ká má ṣe jẹ́ kí Sátánì lágbára lórí wa o! A mọ̀ dájú pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Ìyẹn ló jẹ́ kí Èṣù lè fi “gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn” lọ Jésù pé kó ṣáà gbà láti ṣe ìṣe ìjọsìn kan ṣoṣo fún òun, èyí tó máa túmọ̀ sí ìpẹ̀yìndà. Àmọ́ Ọmọ Ọlọ́run kọ̀ jálẹ̀. (Mátíù 4:8-10) Ayé tí Sátánì ń ṣàkóso kórìíra àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi gan-an. (Jòhánù 15:18-21) Abájọ tí àpọ́sítélì Jòhánù fi kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe fẹ́ràn ayé!
18 Jòhánù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, ìfẹ́ fún Baba kò sí nínú rẹ̀; nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé. Síwájú sí i, ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:15-17) A kò gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ayé, nítorí ńṣe làwọn ọ̀nà ayé máa ń mú kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wu ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe, gbogbo ọ̀nà ayé ló sì lòdì pátápátá sáwọn ìlànà Jèhófà Ọlọ́run.
19 Bí ọkàn wa bá wá fẹ́ràn ayé yìí ńkọ́? Ńṣe ni ká gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè mú irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ kúrò nínú ọkàn wa àti gbogbo ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹran ara tó bá rọ̀ mọ́ ọn. (Gálátíà 5:16-21) Ó dájú pé tá a bá ń rántí pé “agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú” ni “àwọn olùṣàkóso ayé” tá ò lè fojú rí tó ń ṣàkóso àwọn èèyàn ayé aláìṣòdodo yìí, a ó pa ara wa mọ́ “láìní èérí kúrò nínú ayé.”—Jákọ́bù 1:27; Éfésù 6:11, 12; 2 Kọ́ríńtì 4:4.
20. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé a “kì í ṣe apá kan ayé”?
20 Ohun tí Jésù sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:16) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n jọ ń ṣèjọsìn máa ń sapá gidigidi láti mú kí ìwà wọn àti ìjọsìn wọn wà ní mímọ́, láìní àjọṣe kankan pẹ̀lú ayé yìí. (Jòhánù 15:19; 17:14; Jákọ́bù 4:4) Nítorí pé a ò ní àjọṣe kankan pẹ̀lú ayé aláìṣòdodo yìí, tá a sì tún jẹ́ “oníwàásù òdodo,” ayé yìí kórìíra wa. (2 Pétérù 2:5) Lóòótọ́ o, inú ayé kan náà yìí tí àwọn panṣágà, alọ́nilọ́wọ́gbà, abọ̀rìṣà, olè, òpùrọ́, ọ̀mùtípara àtàwọn tó ń ṣàgbèrè wà là ń gbé. (1 Kọ́ríńtì 5:9-11; 6:9-11; Ìṣípayá 21:8) Ṣùgbọ́n a kì í gba “ẹ̀mí ayé” yìí láyè rárá, nítorí pé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ inú ayé kọ́ ló ń darí ọkàn wa.—1 Kọ́ríńtì 2:12.
Má Ṣe Fàyè Sílẹ̀ fún Èṣù
21, 22. Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Éfésù 4:26, 27?
21 Dípò tí a ó fi jẹ́ kí “ẹ̀mí ayé” máa darí wa, ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń tọ́ wa sọ́nà, èyí sì ń jẹ́ ká lè ní irú àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́ àti ìkóra-ẹni-níjàánu. (Gálátíà 5:22, 23) Ànímọ́ wọ̀nyí ni kì í jẹ́ kí Èṣù lè paná ìgbàgbọ́ wa. Èṣù máa ń fẹ́ ká “gbaná jẹ kìkì láti ṣe ibi,” ṣùgbọ́n ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká “jáwọ́ nínú ìbínú, kí [á] sì fi ìhónú sílẹ̀.” (Sáàmù 37:8) Lóòótọ́, nǹkan tó lè mú wa bínú lè wáyé nígbà míì, àmọ́ ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gbà wá ni pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.”—Éfésù 4:26, 27.
22 Ìbínú wa lè di ẹ̀ṣẹ̀ tá a bá ń fọ̀rọ̀ tó dùn wá sínú. Èṣù lè lò ó láti fi dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ tàbí kó tì wá ṣe ohun tí ò dáa. Ìdí nìyẹn tá a fi gbọ́dọ̀ máa yanjú èdèkòyédè tó bá wà láàárín àwa àti ẹlòmíì kíákíá, ká sì yanjú ẹ̀ lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. (Léfítíkù 19:17, 18; Mátíù 5:23, 24; 18:15, 16) Ńṣe ni ká jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa, ká máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu, ká má sì jẹ́ kí ìbínú wa nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan ṣẹ̀ wá dà aáwọ̀ tàbí ìkórìíra sílẹ̀ tàbí kó mú wa fèèyàn sínú.
23. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ́ tó tẹ̀ lé èyí?
23 A ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn kan lára ìwà Èṣù tá ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó ràn wá. Ṣùgbọ́n àwọn òǹkàwé wa kan lè máa rò ó pé: Ǹjẹ́ ó yẹ ká bẹ̀rù Sátánì? Kí nìdí tó fi ń mú káwọn èèyàn ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni? Kí sì ni ohun tá a lè ṣe kí Èṣù má bàa fi ọgbọ́n àyínìke rẹ̀ borí wa?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí náà “Ǹjẹ́ Èṣù Wà Lóòótọ́?” nínú Ilé Ìṣọ́ November 15, 2005.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí tí a kò fi gbọ́dọ̀ ba ẹnikẹ́ni lórúkọ jẹ́?
• Gẹ́gẹ́ bí 1 Jòhánù 3:15 ṣe wí, kí la lè ṣe ká má báa di apànìyàn?
• Irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn apẹ̀yìndà, kí sì nìdí rẹ̀?
• Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ayé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
A ò ní jẹ́ kí Èṣù ba ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa Kristẹni jẹ́ láé
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Kí nìdí tí Jòhánù fi gbà wá níyànjú pé ká má ṣe nífẹ̀ẹ́ ayé?