Ẹ̀KỌ́ 51
Báwo La Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Tá À Ń Sọ Múnú Jèhófà Dùn?
Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa fún wa ní ẹ̀bùn pàtàkì kan, ìyẹn àǹfààní tá a ní láti sọ̀rọ̀. Ṣé a lè lo ẹ̀bùn yìí lọ́nà táá múnú Jèhófà dùn? Bẹ́ẹ̀ ni! (Ka Jémíìsì 1:26.) Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
1. Báwo la ṣe lè lo ẹ̀bùn yìí lọ́nà tó tọ́?
Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa fún ara yín níṣìírí, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró.” (1 Tẹsalóníkà 5:11) Ṣé o mọ ẹnì kan tó o lè fún níṣìírí? Kí lo lè ṣe láti mú kára tu ẹni náà? Sọ ohun táá jẹ́ kó dá a lójú pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. O lè sọ àwọn nǹkan tó o mọyì nípa rẹ̀. Ṣé ẹsẹ Bíbélì kan wà tó o lè kà láti fún un níṣìírí? Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì ló wà tó o lè kà láti fún àwọn èèyàn níṣìírí. Ó tún yẹ kó o fi sọ́kàn pé bí ohun tó o sọ láti fún àwọn èèyàn níṣìírí ṣe ṣe pàtàkì, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀nà tó o gbà sọ ọ́ ṣe pàtàkì. Torí náà, ó yẹ kó o gbìyànjú láti máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà táá mára tù wọ́n.—Òwe 15:1.
2. Irú àwọn ọ̀rọ̀ wo ni kò yẹ ká máa sọ?
Bíbélì sọ pé: “Kí ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ má ṣe ti ẹnu yín jáde.” (Ka Éfésù 4:29.) Ohun téyìí túmọ̀ sí ni pé kò yẹ ká máa bú àwọn èèyàn, kò yẹ ká máa ṣépè, kò sì yẹ ká máa sọ ohun tó máa ti àwọn èèyàn lójú tàbí ohun tó máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn. Bákan náà, kò yẹ ká máa ṣòfófó, kò sì yẹ ká máa bani lórúkọ jẹ́.—Ka Òwe 16:28.
3. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa fún àwọn èèyàn níṣìírí?
Ohun tá à ń sọ sábà máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa àti ohun tá à ń rò lọ́kàn. (Lúùkù 6:45) Torí náà, ó yẹ ká gbìyànjú láti máa ronú lórí àwọn nǹkan tó tọ́, irú bí àwọn nǹkan tó jẹ́ òdodo, tó jẹ́ mímọ́, tó yẹ ní fífẹ́ àtàwọn nǹkan tó yẹ fún ìyìn. (Fílípì 4:8) Ká lè máa ronú lórí àwọn nǹkan yìí, a gbọ́dọ̀ fọgbọ́n yan àwọn tá a máa mú lọ́rẹ̀ẹ́ àti irú eré ìnàjú tá a máa wò. (Òwe 13:20) Yàtọ̀ síyẹn, á dáa ká máa ronú ká tó sọ̀rọ̀. Torí náà, gbìyànjú láti ro bí ohun tó o fẹ́ sọ ṣe máa rí lára àwọn míì. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ téèyàn sọ láìronú dà bí ìgbà tí idà gúnni, àmọ́ ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń woni sàn.”—Òwe 12:18.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká kọ́ bá a ṣe lè máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa múnú Jèhófà dùn àti bá a ṣe lè máa fún àwọn míì níṣìírí.
4. Máa ronú dáadáa kó o tó sọ̀rọ̀
Nígbà míì, èèyàn lè sọ ọ̀rọ̀ kan, kó tún pa dà kábàámọ̀ rẹ̀. (Jémíìsì 3:2) Ka Gálátíà 5:22, 23, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Èwo nínú àwọn ìwà yìí lo lè ní kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní kó o lè máa ṣọ́ bó o ṣe ń sọ̀rọ̀? Báwo ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwà náà ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?
Ka 1 Kọ́ríńtì 15:33, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tó fi yẹ kó o kíyè sára nípa àwọn tó o mú lọ́rẹ̀ẹ́ àti irú eré ìnàjú tó ò ń wò tó o bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu ẹ dáa?
Ka Oníwàásù 3:1, 7, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ tó máa gba pé ká dákẹ́ tàbí ká dúró dìgbà míì láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wa?
5. Máa sọ ohun tó dáa nípa àwọn míì
Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa bú àwọn èèyàn tàbí sọ ohun tó máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Nínú fídíò yẹn, kí nìdí tí arákùnrin yẹn fi ronú pé á dáa kóun ṣàtúnṣe lórí bó ṣe ń bá àwọn míì sọ̀rọ̀?
Àwọn nǹkan wo ló ṣe kí ọ̀rọ̀ ẹ̀ lè máa tu àwọn míì lára?
Ka Oníwàásù 7:16, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tó bá ń ṣe wá bíi pé ká sọ ohun tí ò dáa nípa ẹnì kan?
Ka Oníwàásù 7:21, 22, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o má bàa bínú sódì tẹ́nì kan bá sọ ohun tí ò dáa nípa rẹ?
6. Máa sọ̀rọ̀ lọ́nà táá mú kára tu ìdílé rẹ
Jèhófà fẹ́ ká máa fìfẹ́ bá àwọn tó wà nínú ìdílé wa sọ̀rọ̀, ká sì máa sọ ohun táá mára tù wọ́n. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa mára tu ìdílé rẹ?
Ka Éfésù 4:31, 32, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo lo ṣe lè máa sọ̀rọ̀ lọ́nà táá fi hàn pé o mọyì àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ?
Jèhófà sọ ohun tó fi hàn pé ó mọyì Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀. Ka Mátíù 17:5, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo nìwọ náà ṣe lè fara wé Jèhófà tó o bá ń bá ìdílé rẹ sọ̀rọ̀?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Bọ́rọ̀ bá ṣe rí lára mi ni mo máa ń sọ ọ́. Kò sóhun tó kàn mí tọ́rọ̀ mi ò bá tiẹ̀ bá àwọn míì lára mu.”
Ṣé o gbà pé bó ṣe yẹ kó rí nìyẹn? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
A lè sọ ohun tó máa fún àwọn èèyàn níṣìírí, a sì lè sọ ohun táá kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn nígbà míì. Torí náà, ó yẹ ká máa ronú nípa ohun tá a fẹ́ sọ, ká mọ ìgbà tó yẹ ká sọ̀rọ̀, ká sì máa sọ̀rọ̀ lọ́nà táá mára tuni.
Kí lo rí kọ́?
Báwo lo ṣe lè lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ lọ́nà tó dáa?
Irú àwọn ọ̀rọ̀ wo ni kò yẹ ká máa sọ?
Àwọn nǹkan wo la lè ṣe ká lè máa fún àwọn míì níṣìírí, ká sì máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó tura?
ṢÈWÁDÌÍ
Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa sọ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n?
Tó bá ti mọ́ ẹ lára láti máa ṣépè, ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè mọ bó o ṣe lè jáwọ́.
Wo fídíò yìí kó o lè mọ bó o ṣe lè yẹra fún ṣíṣe òfófó.
Ka ìwé yìí kó o lè mọ̀ nípa ọkùnrin kan tó ti mọ́ lára láti máa ṣépè, kó o sì rí bí Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́ láti jáwọ́.
“Mo Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ronú Gidigidi Nípa Ibi Tí Mo Ń Bọ́rọ̀ Ayé Mi Lọ” (Ilé Ìṣọ́, August 1, 2013)