Ẹ Má Ṣe Kó Ẹ̀dùn-ọkàn Bá Ẹ̀mí Mímọ́ Jèhófà
“Ẹ má ṣe máa kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, èyí tí a fi fi èdìdì dì yín.”—ÉFÉ. 4:30.
1. Kí ni Jèhófà ti ṣe fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn, ojúṣe wo sì ni ìyẹn gbé lé wọn lọ́wọ́?
JÈHÓFÀ tí ṣe ohun àrà ọ̀tọ̀ kan fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó ń gbé nínú ayé tó kún fún wàhálà yìí. Ó ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti sún mọ́ òun nípasẹ̀ Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, Jésù Kristi. (Jòh. 6:44) Ìwọ náà wà lára wọn bó o bá ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, tó o sì ń mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ rẹ ṣẹ. Torí pé a batisí rẹ ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́, ojúṣe rẹ ni pé kó o má ṣe kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí yẹn.—Mát. 28:19.
2. Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
2 Àwa tí à ń “fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn” ti gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀. (Gál. 6:8; Éfé. 4:17-24) Àmọ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn, ó sì tún kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. (Ka Éfésù 4:25-32.) Ẹ jẹ́ ká wá fara balẹ̀ ṣàgbéyẹ̀wò ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wa yìí. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa kíkó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí Ọlọ́run? Báwo ni ẹnì kan tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà ṣe lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀? Báwo la ṣe lè yẹra fún kíkó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí Jèhófà?
Ohun Tí Pọ́ọ̀lù Ní Lọ́kàn
3. Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ohun tí ọ̀rọ̀ inú Éfésù 4:30 túmọ̀ sí?
3 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ gbé ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Éfésù 4:30 yẹ̀ wò. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, èyí tí a fi fi èdìdì dì yín fún ọjọ́ ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà.” Pọ́ọ̀lù kò fẹ́ kí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe ohun tó máa ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Jèhófà ti lo ẹ̀mí rẹ̀ láti “fi èdìdì dì [wọ́n] fún ọjọ́ ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà.” Nígbà yẹn lọ́hùn-ún àti lóde òní ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ni èdìdì, tàbí “àmì ìdánilójú ohun tí ń bọ̀” fún àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ adúróṣinṣin. (2 Kọ́r. 1:22) Èdìdì yìí jẹ́ àmì pé ohun ìní Ọlọ́run ni wọ́n àti pé wọ́n wà lójú ìlà láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun ní ọ̀run. Iye àwọn tá a fi èdìdì dì ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000].—Ìṣí. 7:2-4.
4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká sá fún kíkó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run?
4 Bí Kristẹni kan bá ń kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́, ìyẹn lè mú kí ẹ̀mí Ọlọ́run kúrò lára rẹ̀, kó má sì darí ìgbésí ayé rẹ̀ mọ́. Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ lẹ́yìn tó dá ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú Bátí-ṣébà jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Nígbà tí Dáfídì ronú pìwà dà, ó bẹ Jèhófà pé: “Má ṣe gbé mi sọnù kúrò níwájú rẹ; ẹ̀mí mímọ́ rẹ ni kí o má sì gbà kúrò lára mi.” (Sm. 51:11) Kìkì àwọn tó “jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú” lára àwọn tí a fẹ̀mí yan ló máa gba “adé” ìyè àìleèkú lókè ọ̀run. (Ìṣí. 2:10; 1 Kọ́r. 15:53) Àwọn Kristẹni tó ní ìrètí ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé náà nílò ẹ̀mí mímọ́, bí wọ́n bá fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, kí wọ́n sì gba ẹ̀bùn ìyè tó ń fi fúnni nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi. (Jòh. 3:36; Róòmù 5:8; 6:23) Torí náà, gbogbo wa gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má ṣe kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà.
Báwo Ni Kristẹni Kan Ṣe Lè Kó Ẹ̀dùn-Ọkàn Bá Ẹ̀mí Mímọ́?
5, 6. Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí Jèhófà?
5 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, a lè yẹra fún kíkó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́. Bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa “rìn nípa ẹ̀mí” ká sì jẹ́ kó máa darí wa, ìyẹn ni kò ní jẹ́ kí ìfẹ́ ti ara borí wa, a kò sì ní máa hu ìwà ti inú Ọlọ́run kò dùn sí. (Gál. 5:16, 25, 26) Àmọ́, ìyẹn lè yí pa dà o. A lè kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí Ọlọ́run dé ìwọ̀n àyè kan tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí sú lọ díẹ̀díẹ̀, tá a sì ń hu àwọn ìwà tí Ọlọ́run dá lẹ́bi nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ onímìísí.
6 Tá a bá ń ṣe ohun tó ta ko ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́, a lè máa kó ẹ̀dùn-ọkàn bá òun àti Jèhófà tó jẹ́ Orísun rẹ̀. Ṣíṣe àyẹ̀wò ìwé Éfésù 4:25-32, máa ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bí a ó ṣe máa hùwà, á sì jẹ́ ká máa yẹra fún kíkó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí Ọlọ́run.
Bá A Ṣe Lè Yẹra fún Kíkó Ẹ̀dùn-Ọkàn Bá Ẹ̀mí Mímọ́
7, 8. Ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ ká máa sọ òtítọ́.
7 A gbọ́dọ̀ máa sọ òtítọ́. Nínú Éfésù 4:25, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nísinsìnyí tí ẹ ti fi èké ṣíṣe sílẹ̀, kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara tí ó jẹ́ ti ara wa lẹ́nì kìíní-kejì ni wá.” Níwọ̀n bá a ti so wá pọ̀ ṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀yà ara tí ó jẹ́ ti ara wa lẹ́nì kìíní-kejì,” a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ oníbékebèke tàbí ká máa mọ̀ọ́mọ̀ sọ ohun tó máa ṣi àwọn ará wa lọ́nà, torí pé irọ́ pípa ló jẹ́. Ẹni tí kò bá jáwọ́ nínú irú àṣà yìí kò ní lè ní àjọṣe kankan pẹ̀lú Ọlọ́run.—Ka Òwe 3:32.
8 Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn àti ìwà àgàbàgebè lè ba ìṣọ̀kan ìjọ jẹ́. Torí náà, ó yẹ ká fìwà jọ wòlíì Dáníẹ́lì tó ṣeé fọkàn tán, ẹni tí àwọn míì kò rí ohun ìsọnidìbàjẹ́ kankan lọ́wọ́ rẹ̀. (Dan. 6:4) Ó sì tún yẹ ká máa fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó ní ìrètí ti ọrùn sọ́kàn, pé olúkúlùkù àwọn tó para pọ̀ di “ara Kristi” jẹ́ ara kan ṣoṣo, wọ́n sì ní láti wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù olóòótọ́ yòókù tí a fi ẹ̀mí yàn. (Éfé. 4:11, 12) Tí a bá ní ìrètí ìwàláàyè nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, àwa náà gbọ́dọ̀ máa sọ òtítọ́, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣe àlékún ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé.
9. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe ohun tó wà nínú Éfésù 4:26, 27?
9 A gbọ́dọ̀ kọjú ìjà sí Èṣù, ká má ṣe gbà á láyè láti ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. (Ják. 4:7) Ẹ̀mí mímọ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti kọjú ìjà sí Sátánì. Bí àpẹẹrẹ, a lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ṣíṣọ́ra fún bíbínú sódì. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.” (Éfé. 4:26, 27) Bí ohun kan bá mú inú bí wa, àdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ tá a gbà lójú ẹsẹ̀ lè jẹ́ ká dí ẹni tó “tutù ní ẹ̀mí,” ká kó ara wa ní ìjánu, dípò tí a ó fi kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí Ọlọ́run. (Òwe 17:27) Torí náà, ẹ máa ṣe jẹ́ ká gba ìbínú láyè ká sì tipa bẹ́ẹ̀ fàyè gba Sátánì láti mú wa ṣe ibi. (Sm. 37:8, 9) Ọ̀nà kan tá a lè gbà kọjú ìjà sí Èṣù ni pé ká máa yanjú aáwọ̀ kíákíá, ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Jésù.—Mát. 5:23, 24; 18:15-17.
10, 11. Kí nìdí tí a ò fi gbọ́dọ̀ jalè tàbí ká hùwà àìṣòótọ́ míì?
10 A kò gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀ fún ìdẹwò láti jalè tàbí hùwà àìṣòótọ́. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa olè jíjà pé: “Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ rere, kí ó lè ní nǹkan láti pín fún ẹni tí ó wà nínú àìní.” (Éfé. 4:28) Bí Kristẹni kan tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ bá jalè, ńṣe ló ń “kọjú ìjà sí orúkọ Ọlọ́run” tó sì ń mú ẹ̀gàn bá a. (Òwe 30:7-9) Kódà, pé èèyàn jẹ́ òtòṣì kò ní kó jalè. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò wọn mọ̀ pé kò sí ohun tó yẹ kó mú wọn jalè.—Máàkù 12:28-31.
11 Kì í ṣe ohun tí a kò gbọ́dọ̀ ṣe nìkan ni Pọ́ọ̀lù sọ, ó tún sọ ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe. Tá a bá ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí tá a sì ń rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí, a ó máa ṣiṣẹ́ kára ká lè máa gbọ́ bùkátà ìdílé wa, ká sì tún ní “nǹkan láti pín fún ẹni tí ó wà nínú àìní.” (1 Tím. 5:8) Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ya owó kan sọ́tọ̀ fún àwọn òtòṣì, àmọ́ Júdásì Ísíkáríótù tó jẹ́ ọ̀dàlẹ̀ jí díẹ̀ lára owó náà. (Jòh. 12:4-6) Ó dájú pé kì í ṣe ẹ̀mí mímọ́ ló darí rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwa tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí máa ń “hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Héb. 13:18) A sì ń tipa bẹ́ẹ̀ yàgò fún kíkó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà.
Àwọn Ọ̀nà Míì Tí A Lè Gbà Yẹra fún Kíkó Ẹ̀dùn-Ọkàn Bá Ẹ̀mí Mímọ́
12, 13. (a) Bó ṣe wà nínú Éfésù 4:29, irú ọ̀rọ̀ wo la ò gbọ́dọ̀ máa sọ? (b) Irú ọ̀rọ̀ wo ló yẹ ká máa sọ?
12 A gbọ́dọ̀ ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wa. Pọ́ọ̀lù kéde pé: “Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde, bí kò ṣe àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.” (Éfé. 4:29) Lẹ́ẹ̀kan sí i, a rí i pé kì í ṣe ohun tí a kò gbọ́dọ̀ ṣe nìkan ni Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ó tún sọ ohun tó yẹ ká máa ṣe. Tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí wa, ó máa sún wa láti máa ‘sọ ohun tí ó dára fún gbígbéniró, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.’ Síwájú sí i, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí “àsọjáde jíjẹrà” máa ti ẹnu wa jáde. Wọ́n tún ti lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “jíjẹrà” láti ṣàpèjúwe èso, ẹja tàbí ẹran tó ti bà jẹ́. Bí irú àwọn oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ṣe ń kó wa ní ìríra, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa kórìíra àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ pé ó burú.
13 Ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu wa jáde gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n, onínúure, “tí a fi iyọ̀ dùn.” (Kól. 3:8-10; 4:6) Àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ lè rí i pé a yàtọ̀ nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa ran àwọn míì lọ́wọ́ nípa sísọ àwọn ọ̀rọ̀ “tí ó dára fún gbígbéniró.” Ǹjẹ́ kó máa ṣe àwa náà bó ṣe ṣe onísáàmù tó kọ ọ́ lórin pé: “Kí àwọn àsọjáde ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn-àyà mi dùn mọ́ ọ, ìwọ Jèhófà Àpáta mi àti Olùtúnniràpadà mi.”—Sm. 19:14.
14. Bí Éfésù 4:30, 31 ṣe sọ, kí la gbọ́dọ̀ mú kúrò lọ́dọ̀ wa?
14 A gbọ́dọ̀ mú ìwà kíkorò onínú burúkú, ìbínú, ọ̀rọ̀ èébú àti gbogbo ìwà búburú kúrò lọ́dọ̀ wa. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti kìlọ̀ nípa kíkó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí Ọlọ́run, ó kọ̀wé pé: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú.” (Éfé. 4:30, 31) Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá aláìpé, gbogbo wa la ní láti ṣiṣẹ́ kára ká lè máa ṣàkóso èrò àti ìṣe wa. Tá a bá fàyè gba “ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú,” ńṣe la ó máa kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí Ọlọ́run. Bákan náà lọ̀rọ̀ á ṣe rí tá a bá ń ṣàkọsílẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn èèyàn ṣẹ̀ wá, tí à ń bínú tí a kò sì múra tán láti yanjú aáwọ̀ náà pẹ̀lú ẹni tó ṣẹ̀ wá. Kódà tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí pa ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tì lórí ọ̀ràn yìí, a lè dẹni tó ń hu ìwà tó lè yọrí ṣi ẹ̀ṣẹ̀ lòdì sí ẹ̀mí mímọ́, ìyẹn sì lè ní àbájáde búburú lórí wa.
15. Tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá, kí ló yẹ ká ṣe?
15 A ní láti jẹ́ onínúure, oníyọ̀ọ́nú, ká sì máa dárí jini. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.” (Éfé. 4:32) Kódà tí ohun tí ẹnì kan ṣe fún wa bá dùn wá gan-an, ẹ jẹ́ ká dárí ji onítọ̀hún, bí Ọlọ́run ti ń ṣe. (Lúùkù 11:4) Ká sọ pé ẹnì kan nínú ìjọ sọ ohun tí kò dáa nípa wa. A sì lọ bá ẹni náà, ká lè yanjú ọ̀rọ̀ náà. Ó kábàámọ̀ ohun tó ṣe, ó sì ní ká dárí ji òun. A dárí jì í, àmọ́ ó ṣì ku ohun tó yẹ ká ṣe. Léfítíkù 19:18 sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ gbẹ̀san tàbí kí o di kùnrùngbùn sí ọmọ àwọn ènìyàn rẹ; kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ. Èmi ni Jèhófà.”
A Ní Láti Wà Lójúfò
16. Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé ó lè pọn dandan pé ká ṣe àtúnṣe kan ká má bàa máa kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí Jèhófà.
16 Kódà nígbà tá a bá dá wà, a lè dán wa wò láti ṣe ohun tí inú Ọlọ́run kò dùn sí. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan lè ti máa gbọ́ àwọn orin tí kò dáa. Nígbà tó ṣe, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dà á láàmú, torí pé kò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mát. 24:45) Ó lè gbàdúrà nípa ìṣòro náà, kó sì tún rántí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Éfésù 4:30. Níwọ̀n bó ti pinnu pé òun kò ní ṣe ohunkóhun tó máa kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí Ọlọ́run, ó parí èrò sí pé òun kò ní gbọ́ orin tí kò dáa mọ́ láti ìgbà yẹn lọ. Jèhófà á bù kún arákùnrin yìí nítorí ohun tó ṣe yẹn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣọ́ra, ká má bàa kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí Ọlọ́run.
17. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tí a ò bá wà lójúfò, ká sì máa gbàdúrà?
17 Tí a kò bá wà lójúfò, ká sì máa gbàdúrà, a lè juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn àṣà tí kò mọ́, tó sì burú, èyí tó lè yọrí sí kíkó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí Ọlọ́run. Torí pé ẹ̀mí mímọ́ máa ń ṣe àgbéyọ àwọn ànímọ́ Baba wa ọ̀run, a lè kó ẹ̀dùn-ọkàn bá a tàbí ká mú un bínú, ó sì dájú pé a ò ní fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. (Éfé. 4:30) Àwọn akọ̀wé àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní dá ẹ̀ṣẹ̀ torí pé wọ́n ní ẹ̀mí Èṣù ló fún Jésù lágbára tó fi ń ṣe iṣẹ́ ìyanu. (Ka Máàkù 3:22-30.) Àwọn ọ̀tá Kristi yìí “sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́,” wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì. Ǹjẹ́ kí irú èyí má ṣẹlẹ̀ sí wa láé!
18. Báwo la ṣe lè mọ̀ pé a ò tíì dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì?
18 Níwọ̀n bí a kò ti ní fẹ́ láti rìn ní bèbè dídá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì, ó yẹ ká máa rántí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa kíkó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́. Àmọ́ tá a bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ńkọ́? Tá a bá ti ronú pìwà dà tí àwọn alàgbà sì ti ràn wá lọ́wọ́, ìyẹn á mú ká gbà pé Ọlọ́run ti dárí jì wá àti pé a kò tíì dá ẹ̀ṣẹ̀ lòdì sí ẹ̀mí mímọ́. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, a kò tún ní pa dà kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí Ọlọ́run lọ́nàkọnà.
19, 20. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tó yẹ ká yẹra fún? (b) Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?
19 Ọlọ́run ń lo ẹ̀mí rẹ̀ láti mú kí ìfẹ́, ayọ̀ àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ pọ̀ sí i. (Sm. 133:1-3) Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún kíkó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ nípa ṣíṣàì lọ́wọ́ sí òfófó tó ń pani lára tàbí sísọ ohun tí kò ní jẹ́ kí àwọn ará máa bọ̀wọ̀ fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí rẹ̀ yàn. (Ìṣe 20:28; Júúdà 8) Kàkà bẹ́ẹ̀, a ní láti máa ṣe àlékún ìṣọ̀kan ìjọ ká sì máa ṣe ohun táá mú kí àwọn ará túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn. A kò sì gbọ́dọ̀ fa ìyapa nípa dídá ẹgbẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, nípasẹ̀ orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi pé kí gbogbo yín máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan, àti pé kí ìpínyà má ṣe sí láàárín yín, ṣùgbọ́n kí a lè so yín pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà.”—1 Kọ́r. 1:10.
20 Ó wu Jèhófà láti ràn wá lọ́wọ́ ká má bàá máa kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí rẹ̀, ó sì lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó ní bíbéèrè fún ẹ̀mí mímọ́, ká sì pinnu pé a ò ní kó ẹ̀dùn-ọkàn bá a. Ǹjẹ́ kí á máa “fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn,” ká máa fi taratara wá ìtọ́sọ́nà rẹ̀ nísinsìnyí àti títí láé.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ló túmọ̀ sí láti kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí Ọlọ́run?
• Báwo ni ẹnì kan tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà ṣe lè kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́?
• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà yẹra fún kíkó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Ẹ tètè máa yanjú aáwọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Irú èso wo ló ṣàpẹẹrẹ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ jù lọ?