Ojú Ìwòye Bíbélì
Yẹra fún Sísọ Ọ̀rọ̀ Tó Máa Ń Dunni
“Láti inú ẹnu kan náà ni ìbùkún àti ègún ti ń jáde wá. Kò bẹ́tọ̀ọ́ mu, ẹ̀yin ará mi, kí nǹkan wọ̀nyí máa bá a lọ ní ṣíṣẹlẹ̀ lọ́nà yìí.”—JÁKỌ́BÙ 3:10.
AGBÁRA ọ̀rọ̀ sísọ jẹ́ ohun pàtàkì kan tó mú kí àwa ẹ̀dá èèyàn yàtọ̀ sí àwọn ẹranko. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé àwọn èèyàn kan máa ń ṣi ẹ̀bùn yìí lò. Àwọn ọ̀rọ̀ ìwọ̀sí, èpè ṣíṣẹ́, ọ̀rọ̀kọ́rọ̀, ọ̀rọ̀ òdì, ọ̀rọ̀ rírùn, àtàwọn èdè àlùfààṣá lè dunni wọra, àní, nígbà míì wọ́n máa ń dunni ju ọgbẹ́ ara lọ. Bíbélì sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.”—Òwe 12:18.
Ńṣe làwọn èèyàn tó ń sọ èpè ṣíṣẹ́ dàṣà túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Àwọn ilé ẹ̀kọ́ ń ròyìn pé ńṣe ni sísọ ọ̀rọ̀kọrọ̀ túbọ̀ ń wọ́pọ̀ sí i láàárín àwọn èwe. Àmọ́, àwọn èèyàn kan sọ pé, sísọ àwọn ọ̀rọ̀ tó máa dun ẹlòmíràn wọra ṣàǹfààní tí inú bá ń bí èèyàn kí ara ẹni lè wálẹ̀. Akẹ́kọ̀ọ́ kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ìṣèlú kọ̀wé pé: “Ó yẹ kéèyàn máa lo àwọn èdè àlùfààṣá, nígbà tí ọ̀rọ̀ lásán kò bá lè jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn mọ bí ohun tí wọ́n ṣe ṣe dùnni tó.” Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwọn Kristẹni fi irú ojú yẹpẹrẹ bẹ́ẹ̀ wo àwọn ọ̀rọ̀ tó lè dun àwọn ẹlòmíràn? Irú ojú wo ni Ọlọ́run tiẹ̀ fi ń wò ó?
Kórìíra Àwọn Àwàdà Rírùn
Lílo èdè rírùn kò ṣẹ̀ṣẹ̀ dáyé o. Ǹjẹ́ kò ní yà ọ́ lẹ́nu pé àwọn èèyàn lo èdè rírùn nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì, lóhun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn? Bí àpẹẹrẹ, ó hàn pé àwọn kan nínú ìjọ Kólósè lo àwọn èdè àlùfààṣá nígbà tí àwọn kan múnú bí wọn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí àtifi ìbínú wọn hàn tàbí láti mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó máa dun àwọn tó ṣẹ̀ wọ́n ló mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀, èyí sì lè jẹ́ láti gbẹ̀san. Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń lo àwọn èdè rírùn nígbà tínú bá ń bí wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Kólósè bá àkókò wa mu. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn kúrò lẹ́nu yín.” (Kólósè 3:8) Ní kedere, a gba àwọn Kristẹni níyànjú láti yẹra fún fífi ìbínú hàn àti lílo àwọn èdè àlùfààṣá èyí tó sábà máa ń bá ìbínú rìn.
Lóòótọ́, kì í ṣe pé ọ̀pọ̀ àwọn tó máa ń lo èdè rírùn ní in lọ́kàn láti gbéjà ko àwọn ẹlòmíràn tàbí láti nà wọ́n ní pàṣán ọ̀rọ̀. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ló ti mọ́ wọn lára láti máa lò ó láìbìkítà. Èdè tó ń ríni lára á wá tipa bẹ́ẹ̀ di ohun tí wọn ò lè ṣe kí wọ́n má lò nínú ọ̀rọ̀ wọn ojoojúmọ́. Kò tiẹ̀ rọrùn rárá fún àwọn kan láti sọ̀rọ̀ láìlo èdè àlùfààṣá. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn kan máa ń dìídì sọ ọ̀rọ̀kọrọ̀ káwọn èèyàn bàa lè rẹ́rìn-ín. Àmọ́, ṣé ojú kò-tó-nǹkan ló yẹ ká máa fi wo irú àwọn àwàdàkáwàdà bẹ́ẹ̀, bí ohun téèyàn lè fàyè gbà? Gbé àwọn kókó tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí yẹ̀ wó.
Àwàdà rírùn ni ọ̀rọ̀ tó ń kóni nírìíra táwọn kan máa ń sọ láti pa àwọn mìíràn lẹ́rìn-ín. Láyé òde òní, orí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ ni púpọ̀ àwàdà burúkú sábà máa ń dá lé. Ọ̀pọ̀ àwọn tó sì kara wọn sí ọmọlúwàbí èèyàn ló máa ń gbádùn títẹ́tí sí irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. (Róòmù 1:28-32) Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé, àti ìbálòpọ̀ tó bójú mu àtèyí tí kò bójú mu ni ọ̀rọ̀ àwọn òṣèré tó jẹ́ aláwàdà sábà máa ń dá lé. Ọ̀rọ̀ rírùn kì í ṣe kó máà sí nínú ọ̀pọ̀ fíìmù títí kan àwọn ètò orí tẹlifísọ̀n àti rédíò.
Bíbélì kò ṣàì sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Éfésù pé: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà tí ń tini lójú tàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn, àwọn ohun tí kò yẹ.” (Éfésù 5:3, 4) Èyí mú un ṣe kedere pé, Ọlọ́run kórìíra lílo àwọn èdè rírùn, láìka ohunkóhun tó lè mú ẹnì kan sọ ọ́ sí. Kò bójú mu. Ọ̀rọ̀ tó lè dunni wọra ni.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Burúkú Tí Kì Í Dùn Mọ́ Ọlọ́run Nínú
Dájúdájú, ọ̀rọ̀ burúkú kọjá kéèyàn máa lo èdè rírùn nìkan. Àwọn ọ̀rọ̀ ìwọ̀sí, ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn, fífini ṣẹ̀sín àti ṣíṣàríwísí ẹlòmíràn máa ń dunni gan-an. Òótọ́ ni pé gbogbo wa là ń fi ahọ́n wa ṣẹ̀, pàápàá lónìí tí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti sísọ̀rọ̀ ẹlòmíràn lẹ́yìn ti di ohun tó wọ́pọ̀. (Jákọ́bù 3:2) Síbẹ̀, àwọn Kristẹni tòótọ́ kò gbọ́dọ̀ wo lílo èdè èébú bí ohun tí kò jẹ́ nǹkan kan. Bíbélì fi hàn kedere pé Jèhófà Ọlọ́run kórìíra gbogbo ọ̀rọ̀ tó lè dun àwọn ẹlòmíràn wọra.
Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Àwọn Ọba Kejì nínú Bíbélì, a kà nípa àwọn ọmọdékùnrin kan tí wọ́n ń ṣẹ̀ẹ̀kẹ́ èébú sí wòlíì Èlíṣà. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí fi í ṣe yẹ̀yẹ́,” wọ́n sì “ń wí fún un ṣáá pé: ‘Gòkè lọ, apárí! Gòkè lọ, apárí!’” Jèhófà, ẹni tó lè rí ohun tó wà nínú ọkàn àwọn ọmọ kéékèèké wọ̀nyí tó sì mọ èròkerò ọkàn wọn, kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ èébú tí wọ́n ń sọ náà. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé Ọlọ́run pa àwọn ọmọdékùnrin méjìlélógójì nítorí ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ ẹnu wọn ọ̀hún.—2 Àwọn Ọba 2:23, 24.
Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì “ń bá a lọ ní fífi àwọn ońṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sì ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà, títí ìhónú Jèhófà fi jáde wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀, títí kò fi sí ìmúláradá.” (2 Kíróníkà 36:16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbọ̀rìṣà àti àìgbọ́ràn àwọn èèyàn rẹ̀ lolórí ohun tó fa ìbínú Ọlọ́run, síbẹ̀ ó yẹ ká kíyè sí i pé Bíbélì dìídì sọ̀rọ̀ nípa èébú tí wọ́n ń bú àwọn wòlíì Ọlọ́run. Èyí jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ sí irú ìwà bẹ́ẹ̀ rárá.
Lọ́nà kan náà, Bíbélì gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Má ṣe fi àṣìṣe àgbà ọkùnrin hàn lọ́nà mímúná janjan.” (1 Tímótì 5:1) A lè lo ìlànà yìí nínú ọ̀nà tí à ń gbà bá gbogbo èèyàn lò. Bíbélì rọ̀ wá “láti má sọ̀rọ̀ ẹnì kankan lọ́nà ìbàjẹ́, láti má ṣe jẹ́ aríjàgbá, láti jẹ́ afòyebánilò, [ká] máa fi gbogbo ìwà tútù hàn sí ènìyàn gbogbo.”—Títù 3:2.
Ṣíṣàkóso Ètè Wa
Nígbà míì, kì í rọrùn rárá láti ṣàkóso ara wa láti má ṣe sọ̀rọ̀ èébú sí ẹlòmíràn. Nígbà tí wọ́n bá ṣẹ ẹnì kan, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè rò pé kò sóhun tó burú bí òun bá fi ọ̀rọ̀ burúkú jẹ onítọ̀hún níyà, yálà lójú rẹ̀ tàbí lẹ́yìn rẹ̀. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni kò ní fàyè gba irú ìrònú bẹ́ẹ̀. Òwe 10:19 sọ pé: “Nínú ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ kì í ṣàìsí ìrélànàkọjá, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣàkóso ètè rẹ̀ ń hùwà tòyetòye.”
Àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fún wa. Wọn kò ṣàìrí gbogbo nǹkan burúkú tí ọmọ aráyé ń ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn áńgẹ́lì kì í ṣẹgbẹ́ èèyàn tá a bá ń sọ nípa okun àti agbára, síbẹ̀ wọn kì í sọ̀rọ̀ èébú sí àwọn ẹ̀dá èèyàn, “wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ọ̀wọ̀ fún Jèhófà.” (2 Pétérù 2:11) Níwọ̀n bí àwọn áńgẹ́lì ti mọ̀ pé kò sí ìwà burúkú tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ń hù tí Ọlọ́run kò ṣàìrí, àti pé Ó lágbára láti ṣàtúnṣe àwọn ọ̀ràn, wọ́n máa ń ṣàkóso ètè wọn. Máíkẹ́lì, tó jẹ́ olórí gbogbo àwọn áńgẹ́lì, yẹra fún lílo èdè èébú, kódà fún Èṣù pàápàá.—Júúdà 9.
Àwọn Kristẹni ń sapá láti fara wé àwọn áńgẹ́lì. Wọ́n ń tẹ̀ lé ìṣílétí Bíbélì náà pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. Ẹ pèsè àwọn ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọ́pọ̀ lójú gbogbo ènìyàn. Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’”—Róòmù 12:17-19.
Ó yẹ ká kíyè sí i pé, ọ̀nà tí a gbà sọ̀rọ̀ tàbí bí ohùn wa ṣe lọ sókè tàbí lọ sílẹ̀ sí lè mú kí ohun tí à ń sọ dun àwọn ẹlòmíràn. Àwọn tọkọtaya sábà máa ń sọ ohun tó máa dun ẹnì kejì nígbà tí wọ́n bá ń pariwo mọ́ra wọn. Ọ̀pọ̀ òbí sábà máa ń jágbe mọ́ àwọn ọmọ wọn. Àmọ́, kò sídìí tó fi yẹ ká máa lọgun nígbà tá a bá ń sọ ohun tó ń dùn wá. Bíbélì rọ̀ wá pé: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Éfésù 4:31) Bíbélì kan náà tún sọ pé “kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn.”—2 Tímótì 2:24.
Ọ̀rọ̀ Tí Ń Mára Tuni
Nítorí bí ọ̀rọ̀ èébú àti ọ̀rọ̀ rírùn ṣe wọ́pọ̀ lónìí, ó yẹ kí àwọn Kristẹni wá ọ̀nà láti dènà àṣà tó ń ṣèpalára yìí. Bíbélì fi ọ̀nà tó dára tá a lè gbà ṣe é hàn wá, ìyẹn ni pé ká nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa. (Mátíù 7:12; Lúùkù 10:27) Ojúlówó àníyàn àti ìfẹ́ tá a ní fún ọmọnìkejì wa yóò máa sún wa nígbà gbogbo láti máa lo àwọn ọ̀rọ̀ tí ń tuni lára. Bíbélì sọ pé: “Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde, bí kò ṣe àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.”—Éfésù 4:29.
Bákan náà, gbígbin Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú ọkàn wa á ràn wá lọ́wọ́ láti yàgò fún sísọ àwọn ọ̀rọ̀ tó lè dun àwọn ẹlòmíràn. Kíka Ìwé Mímọ́ àti ṣíṣàṣàrò lórí rẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti “mú gbogbo èérí kúrò.” (Jákọ́bù 1:21) Bẹ́ẹ̀ ni, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè wo ọkàn wa sàn.