Àkókò Kò Ṣeé Tọ́jú Pa Mọ́ Lò Ó Dáadáa
ÀKÓKÒ kò dúró de ẹnì kan. Àṣàyàn ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa lọ́rọ̀ yìí. Èyí fi hàn pé o kò lè dá àkókò padà sẹ́yìn. Tó bá ti lọ, ó lọ títí ayé nìyẹn. O kò lè fi pa mọ́ pé wàá lò ó tó bá yá. Bó o bá gbìyànjú láti fi pa mọ́, ò ń tan ara rẹ jẹ ni. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tó o bá fi wákàtí mẹ́jọ sùn tí o kò sì fi àkókò tó kù lọ́jọ́ náà ṣe nǹkan kan? Ní òpin ọjọ́ náà, wàá rí i pé gbogbo àkókò tí o kò fi ṣe nǹkan kan yẹn ti lọ nìyẹn, o ò lè rí i mọ́.
A lè fi àkókò wé odò ńlá kan tó ń ṣàn. Bó ṣe ń ṣàn lọ, o ò lè dá dúró, bẹ́ẹ̀ lo ò sì lè lo èyí tó ti ṣàn kọjá. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àgbá tí omi máa ń yí, wọ́n sì gbé wọn sẹ́gbẹ̀ẹ́ odò. Wọ́n máa ń lo àwọn àgbá náà láti gba agbára látinú omi tó ń ṣàn, wọ́n á sì fi agbára náà mú àwọn ẹ̀rọ wọn ṣiṣẹ́. Ìyẹn àwọn bí ẹ̀rọ ìlọ-nǹkan, ẹ̀rọ ìlagi, pọ́ǹpù omi àti òòlù. Lọ́nà kan náà, o lè lo àkókò láti fi ṣe iṣẹ́ rere, kì í ṣe pé kó o fi pa mọ́. Àmọ́, ká tó lè lo àkókò lọ́nà rere bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ gbógun ti ohun méjì kan tó ń fi àkókò ṣòfò. Àwọn ohun náà ni ìfònídónìí-fọ̀ladọ́la àti kéèyàn máa fi ọ̀pọ̀ nǹkan dí ara rẹ̀ lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ gbé ọ̀ràn ti ìfònídónìí-fọ̀ladọ́la yẹ̀ wò.
Yẹra fún Ìfònídónìí-fọ̀ladọ́la
Àwọn èèyàn máa ń sọ pé, Ṣe ohun tó o fẹ́ ṣe lónìí, ọ̀la lè pẹ́ jù. Àmọ́ àwọn kan ti yí ọ̀rọ̀ náà padà, wọ́n ní, Ṣe ohun tó o fẹ́ ṣe lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, ọ̀la lè yá jù. Nígbà táwọn èèyàn bá ní iṣẹ́ kan tó le láti ṣe, ńṣe ni wọ́n máa ń fòní dónìí fọ̀la dọ́la. Ìfònídónìí-fọ̀ladọ́la ni kéèyàn máa mọ̀ọ́mọ̀ sún ohun tó yẹ kó ṣe lójú ẹsẹ̀ síwájú di ìgbà mìíràn. Ó ti di àṣà ẹni tó ń fòní dónìí fọ̀la dọ́la láti máa sún nǹkan tó yẹ kó ṣe síwájú. Bí àníyàn tó ní nípa iṣẹ́ náà ti ń pọ̀ sí i, á wá ìtura nípa sísún ohun tó fẹ́ ṣe náà síwájú. Yóò wá máa gbádùn àkókò tó rò pé òun ní náà títí dìgbà tí yóò tún wá máa ronú bóun ṣe máa ṣe iṣẹ́ náà.
Nígbà mìíràn, ara wa lè máa gbé kánkán láti ṣe iṣẹ́ kan tàbí gbogbo ohun tá a fẹ́ ṣe, kíyẹn sì mú ká sún iṣẹ́ náà síwájú. Yàtọ̀ síyẹn, kò sẹ́ni tí kò nílò àkókò ìsinmi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àní Ọmọ Ọlọ́run pàápàá ṣe bẹ́ẹ̀. Ọwọ́ Jésù dí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àmọ́ ó wá àkókò ìsinmi fún ara rẹ̀ àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Máàkù 6:31, 32) Irú àkókò ìtura bẹ́ẹ̀ máa ń ṣeni láǹfààní gan-an. Àmọ́ ìfònídónìí-fọ̀ladọ́la yàtọ̀ o, ó máa ń ṣàkóbá fún èèyàn ni. Wo àpẹẹrẹ kan ná.
Ọ̀dọ́bìnrin akẹ́kọ̀ọ́ kan ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti fi múra ìdánwò ìṣirò kan sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ àti ìwé ló gbọ́dọ̀ kà. Ó ronú pé kò lè rọrùn fóun. Ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í fòní dónìí fọ̀la dọ́la. Dípò kó bẹ̀rẹ̀ sí í kàwé rẹ̀, tẹlifíṣọ̀n ló ń wò. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, bẹ́ẹ̀ ló ń sún ohun tó yẹ kó ṣe kó lè yege ìdánwò náà síwájú. Àmọ́ lálẹ́ ọjọ́ tí ìdánwò náà kú ọ̀la, ó wá kanrí mọ́ kíka gbogbo ìwé náà. Ó jókòó sídìí tábìlì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ka gbogbo àkọsílẹ̀ àtàwọn ìwé rẹ̀.
Akẹ́kọ̀ọ́ náà fi ọ̀pọ̀ wákàtí kàwé. Nígbà táwọn ará ilé rẹ̀ ń sùn, ìwé ló fi gbogbo òru náà kà ní tiẹ̀. Ó ń há oríṣiríṣi ìṣirò sórí. Nígbà tó dé ilé ìwé lọ́jọ́ kejì, ọpọlọ rẹ̀ kò jí pépé débi tó fi lè dáhùn àwọn ìbéèrè inú ìdánwò náà. Máàkì tó gbà nínú ìdánwò náà ò dáa rárá, ńṣe ló fìdí rẹmi. Kò sì lè lọ sí kíláàsì tó tẹ̀ lé e. Ó ní láti padà ka àwọn ìwé náà kó sì tún ìdánwò ọ̀hún ṣe.
Sísún tí akẹ́kọ̀ọ́ yìí sún ohun tó yẹ kó ṣe síwájú di ìgbà mìíràn mú ìfàsẹ́yìn ńláǹlà bá a. Àmọ́ ìlànà Bíbélì kan wà tó lè ranni lọ́wọ́ láti yẹra fún irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí akẹ́kọ̀ọ́ yìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.” (Éfésù 5:15, 16) Pọ́ọ̀lù ń gba àwọn Kristẹni níyànjú láti máa lo àkókò wọn lọ́nà rere fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Àmọ́ ìlànà yìí lè ranni lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan pàtàkì mìíràn nígbèésí ayé wa. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà a lè pinnu ìgbà tá a máa ṣe nǹkan kan, tá a bá bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní “àkókò tí ó rọgbọ” tàbí ìgbà tó máa ṣàǹfààní jù lọ, nǹkan náà á dára gan-an, iṣẹ́ náà á sì tètè parí. Èyí fi hàn pé èèyàn jẹ́ “ọlọ́gbọ́n” gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.
Ìgbà wo ni “àkókò tí ó rọgbọ” fún ọ̀dọ́ akẹ́kọ̀ọ́ yẹn láti kàwé fún ìdánwò náà? Tó bá ń lo ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lálaalẹ́, ó lè ka àwọn ìwé náà títí á fi parí wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, kò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa há wọn sórí lálẹ́ ọjọ́ tí ìdánwò ku ọ̀la nígbà tó yẹ kó máa sùn. Èyí á jẹ́ kí ara rẹ̀ balẹ̀ lọ́jọ́ ìdánwò yẹn, nítorí pé ó ti múra sílẹ̀ dáadáa, á sì gba máàkì tó dáa nínú ìdánwò náà.
Nítorí náà, tí wọ́n bá gbé iṣẹ́ kan fún ọ, mọ “àkókò tí ó rọgbọ” láti ṣe iṣẹ́ náà, kó o sì rí i pé o ṣe é. Nípa bẹ́ẹ̀ wàá yẹra fún sísún nǹkan tó yẹ kó o tètè ṣe síwájú, o ò sì ní kó sì wàhálà. Inú rẹ yóò tún dùn pé ó ṣe iṣẹ́ náà dáadáa. Èyí sì ṣe pàtàkì, pàápàá tó bá jẹ́ iṣẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, bí irú ìgbà téèyàn bá níṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni.
Dín Àwọn Ohun Ìdíwọ́ Kù
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, ohun kejì tó lè mú ká lo àkókò wa tó ṣeyebíye lọ́nà rere ni pé ká yẹra fún fífi ọ̀pọ̀ nǹkan dí ara wa lọ́wọ́. Gbogbo wa la mọ̀ pé ó máa ń gba àkókò láti bojú tó àwọn nǹkan, láti tò wọ́n bó ṣe yẹ, láti lò wọ́n, láti jẹ́ kí wọ́n wà ní mímọ́ tónítóní, láti fi wọ́n sáyè wọn, àti láti wá wọn rí. Téèyàn bá ní ohun tó pọ̀, ó máa ń gba àkókò tó pọ̀ láti bójú tó wọn. Téèyàn bá ń ṣiṣẹ́ nínú ilé kan tó ní ọ̀pọ̀ ẹrù, ó máa ń gba àkókò gan-an, ó sì máa ń súni láti ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ju ibì kan tí kò sí ẹrù jánganjàngan. Yàtọ̀ síyẹn, báwọn ẹrù bá ṣe ń pọ̀ sí i ni àkókò tá a máa fi wá ohun tá a nílò rí á ṣe máa pọ̀ sí i.
Àwọn tó ń tọ́jú ilé sọ pé ìdajì àkókò táwọn èèyàn ń lò láti fi tọ́jú ilé ni wọ́n máa ń lò dànù sórí “gbígbé nǹkan láti ibì kan sí ibòmíràn, wíwá ibi tí wọ́n máa rìn sí nínú ilé tó kún fún ẹrù, àti kíkó àwọn ohun tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ nílò kúrò nílẹ̀.” Ó lè jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nínú àwọn nǹkan mìíràn tá à ń ṣe nínú ìgbésí ayé wa nìyẹn. Nítorí náà, tó o bá fẹ́ lo àkókò rẹ lọ́nà tó dára gan-an, wo àwọn ohun tó yí ọ ká dáadáa. Ǹjẹ́ àwọn ohun tí ò kò nílò ń gba gbogbo àyè mọ́ ọ lọ́wọ́, tí kò jẹ́ kó o lè rìn nínú ilé, tàbí tó tiẹ̀ ń fi àkókò rẹ ṣòfò pàápàá? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kó àwọn ohun tó ò nílò kúrò nílẹ̀.
Kì í wu àwa èèyàn láti kó àwọn ohun tá ò nílò jáde nínú ilé. Kíkó ohun tèèyàn fẹ́ràn àmọ́ téèyàn ò nílò mọ́ kúrò nínú ilé lè ṣòro gan-an, ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn bá pàdánù ọ̀rẹ́ àtàtà kan. Báwo wá ni èèyàn ṣe lè mọ̀ bóyá kóun mú ohun kan kúrò tàbí kóun fi silẹ̀ nínú ilé? Ìlànà táwọn kan máa ń lò ni pé tí wọn ò bá lo ohun kan títí ọdún kan fi kọjá, wọ́n á mú un kúrò nílẹ̀. Kí ni wàá ṣe tí o kò bá fẹ́ mú un kúrò lẹ́yìn tí ọdún kan ti kọjá? Gbé e síbi ìkó-nǹkan-pa-mọ́-sí fún oṣù mẹ́fà sí i. Nígbà tó o bá rí i pé ọdún kan ààbọ̀ ti kọjá tí o kò lò ó, kò ní ṣòro fún ọ mọ́ láti kó àwọn nǹkan náà jáde nínú ilé. Ohun yòówù kó o ṣe, ìdí tó o fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni kó o lè dín àwọn ohun tí o kò nílò kù, kó o sì lè lo àkókò rẹ lọ́nà rere.
Àmọ́ ṣá o, àwọn ohun téèyàn ò nílò kò mọ sínú ilé tàbí ibi iṣẹ́ nìkan. Jésù sọ nípa “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀” tó lè ‘fún ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa’ kó sì sọni di “aláìléso” nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà. (Mátíù 13:22) Ìgbésí ayé ẹnì kan lè kún fún ọ̀pọ̀ ìgbòkègbodò débi pé á ṣòro fún un láti rí àkókò fún ohun tó ṣe pàtàkì gan-an, ìyẹn àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run. Ohun tó máa yọrí sí ni pé àjọṣe ẹni náà pẹ̀lú Ọlọ́run lè bà jẹ́ kí èyí sì wá mú kó pàdánù wíwọnú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, níbi tí àkókò ti máa wà títí ayé láti ṣe ohun tó ń fúnni ní ìdùnnú àti ìtẹ́lọ́rùn.—Aísáyà 65:17-24; 2 Pétérù 3:13.
Ǹjẹ́ ó máa ń ṣòro fún ọ láti rí àyè ṣe gbogbo ohun tó o rò pé o gbọ́dọ̀ ṣe? Bóyá àwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ rẹ, ilé rẹ, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, eré ìgbà ọwọ́dilẹ̀, ìrìn àjò, eré ìdárayá, àwọn ayẹyẹ tàbí àwọn ohun mìíràn tó o nífẹ̀ẹ́ sí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ pé ó tó àkókò fún ọ láti dín àwọn nǹkan wọ̀nyí kù kó o lè gbájú mọ́ ìjọsìn rẹ sí Ọlọ́run.
Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀, àkókò kò dúró de ẹnì kan. Ká sòótọ́, ńṣe ni àkókò máa ń kọjá lọ bí odò tó ń ṣàn. O kò lè dá a padà, o ò sì lè tọ́jú ẹ pa mọ́; tó bá ti lọ, ó ti lọ títí ayé nìyẹn. Àmọ́ tá a bá ń lo àwọn ìlànà Bíbélì tá a sì ń ṣe àwọn nǹkan tó lè ràn wá lọ́wọ́, àá lè rí àkókò tá a máa fi bójú tó “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” èyí tó máa ṣe wa láǹfààní títí ayé tó sì máa mú ‘ògo àti ìyìn bá Ọlọ́run.’—Fílípì 1:10, 11.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
A lè lo àkókò, tó dà bí odò tó ń ṣàn, fún iṣẹ́ rere
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ìgbà wo ni “àkókò tí ó rọgbọ” fún ọ̀dọ́bìnrin yìí láti múra sílẹ̀ fún ìdánwò rẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Téèyàn bá ń ṣiṣẹ́ níbí tí ẹrù wà jánganjàngan, ó máa ń gba àkókò gan-an, ó sì máa ń mú nǹkan súni