Ǹjẹ́ Ò ‘Ń Ra Àkókò Tí Ó Rọgbọ Padà’?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù ní ọ̀rúndún kìíní nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.” (Éfésù 5:15, 16) Kí nìdí tí ìmọ̀ràn yìí fi pọn dandan? Ká tó lè dáhùn ìbéèrè yẹn, ó yẹ ká mọ ipò táwọn Kristẹni tó ń gbé ìlú ńlá ìgbàanì yẹn dojú kọ.
Àwọn èèyàn mọ Éfésù sí ìlú tó lọ́rọ̀ rẹpẹtẹ, tó kún fún ìṣekúṣe, tí ìwà ọ̀daràn pọ̀ rẹpẹtẹ nínú rẹ̀, tó sì kún fún onírúurú àṣà ìbẹ́mìílò. Kò tán síbẹ̀ o, àwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀ tún ń bá àwọn ìgbàgbọ́ tó dá lé ìmọ̀ ọgbọ́n orí nípa àkókò wọ̀yá ìjà. Àwọn Gíríìkì tí kì í ṣe Kristẹni ní Éfésù kò gbà gbọ́ pé iwájú nìkan ni àkókò ń lọ. Ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì fi kọ́ wọn pé ńṣe lèèyàn máa ń tún ayé wá léraléra. Ẹni tó bá fi àkókò rẹ̀ tàfàlà ní ayé àkọ́wá lè jèrè gbogbo àkókò yẹn padà nígbà tó bá tún ayé wá. Ó lè jẹ́ irú ìrònú yìí ló mú káwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù máa fojú yẹpẹrẹ wo àkókò tí Jèhófà ti là kalẹ̀ fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan, títí kan àkókò ìdájọ́ Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé kí wọ́n ‘ra àkókò tí ó rọgbọ padà’ fi bá a mu wẹ́kú.
Kì í ṣe ọ̀ràn nípa bí wákàtí ọjọ́ ṣe ń lọ nìkan ni Pọ́ọ̀lù ń sọ. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó lò níhìn-ín tọ́ka sí àkókò kan tá a yàn kalẹ̀, sáà tó wà fún ète kan pàtó. Pọ́ọ̀lù ń gba àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní nímọ̀ràn pé kí wọ́n fọgbọ́n lo àkókò tí ó rọgbọ, tàbí sáà ojú rere tó ṣí sílẹ̀ fún wọn, kó tó dópin, tí ojú àánú Ọlọ́run àti ìpèsè tó ṣe fún ìgbàlà yóò sì wá kásẹ̀ nílẹ̀.—Róòmù 13:11-13; 1 Tẹsalóníkà 5:6-11.
Irú sáà tí ó rọgbọ yẹn là ń gbé báyìí. Dípò táwọn Kristẹni á fi fi sáà ojú rere yìí tàfàlà nípa lílépa fàájì onígbà kúkúrú tí ayé yìí ń fi fúnni, yóò bọ́gbọ́n mu kí wọ́n lo àkókò tí wọ́n ní fún ṣíṣe “àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run,” kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àjọṣe àárín àwọn àti Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wọn túbọ̀ lágbára sí i.—2 Pétérù 3:11; Sáàmù 73:28; Fílípì 1:10.