Láti Ọ̀rọ̀ Dídunni sí Ọ̀rọ̀ Atunilára
“Ikú àti ìyè ń bẹ ní ipá ahọ́n.”—ÒWE 18:21.
ÌPẸ̀GÀN—àṣà mímọ̀ọ́mọ̀ búni láti fìwọ̀sí kanni—ni a dẹ́bi fún ní kedere nínú Bíbélì. Lábẹ́ Òfin Mósè, ẹni tí ó bá pẹ̀gàn àwọn òbí rẹ̀ lè jìyà ikú. (Ẹ́kísódù 21:17) Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀ràn náà. Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì, kò ti èrò náà lẹ́yìn pé ohunkóhun tó bá ṣẹlẹ̀ ‘ní ìkọ̀kọ̀ ilé ẹni’ kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì níwọ̀n bí ẹnì kan bá ti sọ pé òún ń sin Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí lójú ara rẹ̀ bá dà bí olùjọsìn ní irú ọ̀nà ètò kan síbẹ̀ tí kò sì kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ṣùgbọ́n tí ó ń bá a lọ ní títan ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ, irú ọ̀nà ètò ìjọsìn ọkùnrin yìí jẹ́ òtúbáńtẹ́.” (Jákọ́bù 1:26; Orin Dáfídì 15:1, 3) Nítorí náà, bí ọkùnrin kan bá ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ lu aya rẹ̀, gbogbo àwọn iṣẹ́ rẹ̀ míràn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni lè di òtúbáńtẹ́ lójú Ọlọ́run.a—Kọ́ríńtì Kìíní 13:1-3.
Síwájú sí i, a lè lé Kristẹni kan tí ó jẹ́ olùpẹ̀gàn kúrò nínú ìjọ. Ó tilẹ̀ lè pàdánù àwọn ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run. (Kọ́ríńtì Kìíní 5:11; 6:9, 10) Ní kedere, ó yẹ kí ẹnì kan tí ó máa ń sọ ọ̀rọ̀ dídunni ṣe ìyípadà tegbòtigaga. Ṣùgbọ́n báwo ni ó ṣe lè ṣe èyí?
Mímú Ìṣòro Náà Wá Sójútáyé
Lọ́nà tí ó hàn gbangba, ẹlẹ́ṣẹ̀ kan kò ní yí padà àyàfi tí ó bá lóye ní kedere pé òún ní ìṣòro líle koko kan. Gẹ́gẹ́ bí olùgbaninímọ̀ràn kan ṣe ṣàkíyèsí, ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin tí wọ́n máa ń bú èébú “kì í wo ìhùwà wọn gẹ́gẹ́ bí ìloninílòkulò rárá. Sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ bójú mu pátápátá, ó sì jẹ́ ọ̀nà tí ó ‘bá ìwà ẹ̀dá mu’ tí ọkọ àti aya fi ń bá ara wọn lò.” Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn púpọ̀ kì yóò rí ìdí láti yí padà àyàfi tí a bá pe àfiyèsí wọn sí ọ̀ràn náà ní tààràtà.
Lọ́pọ̀ ìgbà, lẹ́yìn tí aya kan bá ti gbé ipò ọ̀ràn rẹ̀ yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà, yóò nímọ̀lára àìgbọdọ̀máṣe láti sọ̀rọ̀ síta—fún ire àlàáfíà tirẹ̀ àti ti àwọn ọmọ rẹ̀ àti láti inú ìbìkítà fún ipò ìdúró ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Lótìítọ́, ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé sísọ̀rọ̀ síta lè mú kí ọ̀ràn burú sí i àti pé ó lè sẹ́ àwọn ohun tí ó bá sọ. Bóyá aya kan lè ṣẹ́pá èyí nípa ríronú tẹ́lẹ̀ tìṣọ́ratìṣọ́ra lórí bí òun yóò ṣe dá ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Bí èso igi wúrà nínú agbọ̀n fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò rẹ̀.” (Òwe 25:11) Ọ̀nà ìsọ̀rọ̀ tí ó ṣe pẹ̀lẹ́ ṣùgbọ́n tí ó kún fún òtítọ́ inú ní àkókò rírọgbọ lè wọ ọkàn rẹ̀.—Òwe 15:1.
Dípò fífi ẹ̀sùn kanni, aya kan gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti ṣàlàyé ara rẹ̀ nípa bí ọ̀rọ̀ dídunni náà ṣe ní ipa lórí rẹ̀. Gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “èmi” sábà máa ń ṣiṣẹ́ lọ́nà dídára jù lọ. Fún àpẹẹrẹ, ‘Ó dùn mí nítorí pé . . .’ tàbí ‘Mo nímọ̀lára ìnilára kíkorò nígbà tí o sọ̀rọ̀ sí mi pé . . .’ Ó ṣeé ṣe kí irú àwọn gbólóhùn báyìí wọ ọkàn rẹ̀, nítorí pé wọ́n gbógun ti ìṣòro náà dípò ẹni náà.—Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 27:46–28:1.
Ìlóhùnsí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó mẹ̀tọ́mẹ̀yẹ láti ọ̀dọ̀ aya kan lè yọrí sí rere. (Fi wé Orin Dáfídì 141:5.) Ọkùnrin kan tí a óò pè ní Steven rí èyí bẹ́ẹ̀. Ó wí pé: “Aya mi rí ìtẹ̀sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ èébú tí èmi kò ṣàkíyèsí nínú mi, ó sì ní ìgboyà láti sọ fún mi nípa rẹ̀.”
Rírí Ìrànlọ́wọ́ Gbà
Ṣùgbọ́n kí ni aya kan lè ṣe bí ọkọ rẹ̀ bá kọ̀ láti gbà pé òún mọ̀ nípa ìṣòro náà? Níbi tí ọ̀ràn dé yìí, àwọn aya kan máa ń wá ìrànwọ́ níta. Ní àkókò irú wàhálà bẹ́ẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè tọ àwọn alàgbà ìjọ wọn lọ. Bíbélì rọ àwọn ọkùnrin wọ̀nyí láti jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti ẹni jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí wọ́n bá ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí agbo Ọlọ́run tẹ̀mí àti, lákòókò kan náà, láti “fi ìbáwí tọ́ àwọn wọnnì tí ń ṣàtakò” sí ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń fúnni nilera “sọ́nà.” (Títù 1:9; Pétérù Kìíní 5:1-3) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe tiwọn láti yọjúràn sínú àlámọ̀rí ara ẹni àwọn tọkọtaya tí wọ́n ti ṣègbéyàwó, àwọn alàgbà ń ṣàníyàn lọ́nà títọ́ nígbà tí alábàágbéyàwó kan bá ń fi ọ̀rọ̀ rírorò pọ́n ẹnì kejì rẹ̀ lójú. (Òwe 21:13) Ní títẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì tímọ́tímọ́, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kì í wá àwáwí fún èébú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í fojú kékeré wò ó.b
Àwọn alàgbà lè mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ láàárín ọkọ àti aya rẹ̀ túbọ̀ rọrùn. Fún àpẹẹrẹ, obìnrin kan tọ alàgbà kan lọ, ó sì sọ nípa bí ọkọ rẹ̀, tí wọ́n jùmọ̀ jẹ́ olùjọsìn, ti ń fi ọ̀rọ̀ gún un lára fún ọ̀pọ̀ ọdún. Alàgbà náà ṣètò láti pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn méjèèjì. Bí èkíní bá ń sọ̀rọ̀, yóò ní kí èkejì tẹ́tí sílẹ̀ láìjálu ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nígbà tí ó kan aya, ó sọ pé òun kò lè gba ìbínú fùfù ọkọ òun mọ́. Ó ṣàlàyé pé, fún ọ̀pọ̀ ọdún, kò sí ọjọ́ kan kí ẹ̀rù má ma ba òun, tí òun kò ní mọ̀ bóyá ipò ìbínú ni yóò wà nígbà tí ó bá darí sílé. Nígbà tí inú bá ń bí i, yóò máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ń tẹ́ni lógo nípa ìdílé aya rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ aya rẹ̀, àti aya náà fúnra rẹ̀.
Alàgbà náà ní kí aya náà ṣàlàyé bí àwọn ọ̀rọ̀ ọkọ rẹ̀ ṣe ń mú kí ìmọ̀lára rẹ̀ rí. Ó fèsì pé: “Mo ń nímọ̀lára bíi pé mo jẹ́ ẹni burúkú kan tí kò sí ẹni tí ó lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Mo máa ń béèrè lọ́wọ́ ìyá mi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé, ‘Mọ́mì, ṣé mo ṣòro láti bá gbé ni? Ṣé ẹni tí a kò lè nífẹ̀ẹ́ ni mí ni?’” Bí ó ti ń ṣàpèjúwe bí àwọn ọ̀rọ̀ ọkọ rẹ̀ ṣe ń mú kí ìmọ̀lára rẹ̀ rí, ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Fún ìgbà àkọ́kọ́, ó rí i bí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti ń dun aya rẹ̀ wọra tó.
O Lè Yí Padà
Àwọn Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní ní ìṣòro pẹ̀lú èébú bíbú. Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣí wọn létí láti mú “ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn akóninírìíra” kúrò. (Kólósè 3:8) Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀rọ̀ rírorò jẹ́ ìṣòro inú ọkàn ju kí ó jẹ́ ti ahọ́n lọ. (Lúùkù 6:45) Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣe òun àṣà rẹ̀, ẹ sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ.” (Kólósè 3:9, 10) Nítorí náà, yíyí padà kò kan kìkì sísọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó yàtọ̀ ṣùgbọ́n ríronú lọ́nà tí ó yàtọ̀ pẹ̀lú.
Ọkọ kan tí ó máa ń lo ọ̀rọ̀ tí ń pani lára lè nílò ìrànlọ́wọ́ láti pinnu ohun tí ń sún un hùwà.c Yóò fẹ́ láti ní ẹ̀mí ìrònú tí onísáàmù náà ní pé: “Ọlọ́run, wádìí mi, kí o sì mọ àyà mi: dán mi wò, kí o sì mọ èrò inú mi: Kí o sì wò ó bí ipa ọ̀nà búburú kan bá wà nínú mi.” (Orin Dáfídì 139:23, 24) Fún àpẹẹrẹ: Èé ṣe tí ó fi nímọ̀lára àìní láti máa jọba lé, tàbí máa darí, alábàágbéyàwó rẹ̀? Kí ló máa ń tanná ran ọ̀rọ̀ kíkorò kan? Ńjẹ́ àwọn ìsọ̀kò ọ̀rọ̀ náà jẹ́ àmì ìfìbínúhàn jíjinlẹ̀ bí? (Òwe 15:18) Ó ha máa ń ní ìṣòro ìmọ̀lára àìjámọ́ǹkankan, bóyá tí ó jẹ́ àbáyọrí ọ̀nà tí wọ́n gbà tọ́ ọ, tí ó kún fún àwọn ọ̀rọ̀ líle koko bí? Irú àwọn ìbéèrè báyìí lè ran ọkùnrin kan lọ́wọ́ láti túdìí gbòǹgbò ìwà rẹ̀.
Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣòro láti tu gbòǹgbò èébú, pàápàá jù lọ bí ó bá jẹ́ àwọn òbí tí àwọn fúnra wọ́n jẹ́ ẹni tí ó máa ń ránpọ̀ tàbí àṣà ìbílẹ̀ tí ń gbé ìwà ìjẹgàba lárugẹ ló gbìn ín síni lọ́kàn. Ṣùgbọ́n a lè—pẹ̀lú àkókò àti ìsapá—yọ ohunkóhun tí a bá kọ́ kúrò lọ́kàn. Bíbélì ni ìrànlọ́wọ́ dídára jù lọ lọ́nà yìí. Ó lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti yí ìwà tí ó ti wọra gan-an padà. (Fi wé Kọ́ríńtì Kejì 10:4, 5.) Báwo?
Ojú Ìwòye Títọ́ Nípa Àwọn Iṣẹ́ Tí Ọlọ́run Yàn Fúnni
Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọkùnrin tí wọ́n máa ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu ṣèpalára ní òye tí a gbé gbòdì nípa àwọn iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún ọkọ àti aya. Fún àpẹẹrẹ, òǹkọ̀wé Bíbélì náà, Pọ́ọ̀lù, sọ pé àwọn aya ní láti wà “ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn” àti pé “ọkọ ni orí aya rẹ̀.” (Éfésù 5:22, 23) Ọkọ kan lè ronú pé ipò orí fún òun láyè ìdarí pátápátá láìkù síbì kan. Ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aya rẹ̀ wà ní ìtẹríba, kì í ṣe ẹrú rẹ̀. Ó jẹ́ “olùrànlọ́wọ́” àti “àṣekún” rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Nípa bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, nítorí pé kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ẹran ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n òun a máa bọ́ ọ a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti ń ṣe sí ìjọ.”—Éfésù 5:28, 29.
Gẹ́gẹ́ bí orí ìjọ Kristẹni, Jésù kò na àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní pàṣán ọ̀rọ̀ rí, kí ó sì mú kí wọ́n máa dààmú pẹ̀lú ojora nípa ìgbà tí irú ọ̀rọ̀ ìṣelámèyítọ́ bẹ́ẹ̀ yóò tún bọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ń dáàbò bo iyì wọn. Ó ṣèlérí fún wọn pé: “Èmi yóò . . . tù yín lára. . . . Onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi.” (Mátíù 11:28, 29) Ṣíṣàṣàrò tàdúràtàdúrà lórí bí Jésù ṣe lo ipò orí rẹ̀ lè ran ọkọ kan lọ́wọ́ láti wo ipò orí rẹ̀ pẹ̀lú ojú ìwòye tí ó túbọ̀ wà déédéé.
Nígbà Tí Pákáǹleke Bá Ṣẹlẹ̀
Ìkan ni kí a mọ àwọn ìlànà Bíbélì; fífi wọ́n sílò nígbà tí a bá wà lábẹ́ pákáǹleke ni ó ṣe kókó. Nígbà tí pákáǹleke bá ṣẹlẹ̀, báwo ni ọkọ kan ṣe lè yẹra fún yíyẹ̀ gẹ̀rẹ̀ padà sínú ipa ọ̀nà sísọ̀rọ̀ rírorò?
Kì í ṣe àmì jíjẹ́ ọkùnrin fún ọkọ kan láti máa fi ọ̀rọ̀ gúnni lára nígbà tí inú bá ń bí i. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó lọ́ra àtibínú, ó sàn ju alágbára lọ; ẹni tí ó sì ṣe àkóso ẹ̀mí rẹ̀, ó ju ẹni tí ó ṣẹ́gun ìlú lọ.” (Òwe 16:32) Ọkùnrin gidi máa ń ṣàkóso ẹ̀mí rẹ̀. Ó máa ń fi ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò hàn nípa ríronú pé: ‘Ipa wo ni ọ̀rọ̀ mi ń ní lórí aya mi? Báwo ni ìmọ̀lára mi yóò ṣe rí bí ó bá jẹ́ èmi ni?’—Fi wé Mátíù 7:12.
Bí ó ti wù kí ó rí, Bíbélì gbà pé àwọn ipò kan lè ru ìbínú sókè. Onísáàmù náà kọ̀wé nípa irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀ pé: “Ẹ dúró nínú ẹ̀rù, ẹ má sì ṣe ṣẹ̀; ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀ lórí ẹní yín, kí ẹ sì dúró jẹ́ẹ́.” (Orin Dáfídì 4:4) A tún ti sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “Kò sí ohun tí ó burú nínú bíbínú, ṣùgbọ́n ó burú láti máa sọ̀rọ̀ kíkorò nípa jíjẹ́ ẹni tí ń ránpọ̀, tẹ́ni lógo tàbí rẹni nípò wálẹ̀.”
Bí ọkọ kan bá nímọ̀lára pé òún ń pàdánù àkóso lórí ọ̀rọ̀ òun, ó lè tọrọ gááfárà. Bóyá yóò bọ́gbọ́n mu láti fi iyàrá sílẹ̀, láti nasẹ̀ lọ, tàbí wá ibi ìkọ̀kọ̀ kan láti sinmẹ̀dọ̀. Òwe 17:14 sọ pé: “Fi ìjà sílẹ̀ kí ó tó di ńlá.” Ẹ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò náà padà nígbà tí ọkàn bá ti wálẹ̀.
A gbà pé kò sí ẹni tí ó pé. Ọkọ kan tí ó ti ní ìṣòro sísọ̀rọ̀ rírorò lè tún jórẹ̀yìn. Tí èyí bá ṣẹlẹ̀, o gbọ́dọ̀ tọrọ àforíjì. Gbígbé “àkópọ̀-ìwà titun” wọ̀ jẹ́ ọ̀nà ìṣe tí ń bá a lọ, ṣùgbọ́n ó jẹ́ èyí tí ń jèrè ẹ̀san ńlá.—Kólósè 3:10.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Atunilára
Bẹ́ẹ̀ ni, “ikú àti ìyè ń bẹ ní ipá ahọ́n.” (Òwe 18:21) A gbọ́dọ̀ fi àwọn ọ̀rọ̀ tí ń gbé ìgbéyàwó ró, tí ó sì ń fún un lókun, rọ́pò àwọn ọ̀rọ̀ dídunni. Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Ọ̀rọ̀ dídùn dà bí afárá oyin, ó dùn mọ́ ọkàn, ó sì ṣe ìlera fún egungun.”—Òwe 16:24.
Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, a ṣe ìwádìí kan láti mọ àwọn ohun tí ń mú kí àwọn ìdílé tí wọ́n fẹsẹ̀ múlẹ̀ máa bá a lọ lọ́nà gbígbéṣẹ́. Ògbógi nínú ọ̀ràn ìgbéyàwó, David R. Mace, sọ pé: “Ìwádìí náà fi hàn pé àwọn mẹ́ḿbà ìdílé wọ̀nyí fẹ́ràn ara wọn, wọ́n sì máa ń sọ fún ara wọn pé àwọn fẹ́ràn ẹnìkíní kejì. Wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ìtẹ́wọ́gbà nípa ẹnìkíní kejì wọn, wọ́n máa ń jẹ́ kí ẹnìkíní kejì ní ìmọ̀lára jíjẹ́ ẹni tí ó já mọ́ nǹkan, wọ́n sì ń lo gbogbo àkókò àǹfààní bíbọ́gbọ́n mu láti sọ̀rọ̀ pọ̀, kí wọ́n sì fi ìfẹ́ni hàn. Lọ́nà ti ẹ̀dá, ìyọrísí rẹ̀ ni pé wọ́n gbádùn wíwà pa pọ̀, wọ́n sì ń fún ẹnìkínní kejì lókun ní àwọn ọ̀nà tí ń mú kí ipò ìbátan wọ́n tẹ́ wọn lọ́rùn.”
Kò sí ọkọ kan tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run tí ó lè sọ pẹ̀lú òtítọ́ pé òún nífẹ̀ẹ́ aya òun, bí ó bá ń mọ̀ọ́mọ̀ sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ń ṣèpalára fún un. (Kólósè 3:19) Dájúdájú, ọ̀rọ̀ kan náà yóò jẹ́ òtítọ́ nípa ti aya kan tí ó máa ń fi ọ̀rọ̀ gún ọkọ rẹ̀ lára. Ní gidi, iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe tọkọtaya náà ni láti tẹ̀ lé ìṣítí Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Éfésù pé: “Kí àsọjáde jíjẹrà má ṣe ti ẹnu yín jáde, bí kò ṣe àsọjáde yòó wù tí ó dára fún gbígbéni ró bí àìní náà bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.”—Éfésù 4:29.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lo ẹ̀yà ọkùnrin láti tọ́ka sí ẹni tí ń hùwà náà, àwọn ìlànà tí ó wà níhìn-ín kan àwọn obìnrin pẹ̀lú.
b Láti tóótun láti ṣiṣẹ́ sìn tàbí láti máa bá a lọ ní ṣíṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà, ọkùnrin kan kò gbọdọ̀ jẹ́ aluni. Kò lè jẹ́ ẹni tí ń lu àwọn ènìyàn ní ti ara ìyára tàbí tí ń mú wọn láyà pami pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ amọ́kàngbọgbẹ́. Àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní láti ṣàkóso agbo ilé tiwọn lọ́nà rere. Láìka bí ó ṣe lè máa hùwà inú rere níbòmíràn sí, ọkùnrin kan kò tóótun bí ó bá jẹ́ òṣìkà agbonimọ́lẹ̀ ní ilé.—Tímótì Kìíní 3:2-4, 12.
c Ọ̀ran pé Kristẹni kan wá ìtọ́jú nítorí èébú jẹ́ ìpinnu àdáṣe. Bí ó ti wù kí ó rí, ó gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ìtọ́jú èyíkéyìí tí òún bá gbà kò forí gbárí pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Kristẹni alàgbà kan lè ran tọkọtaya kan lọ́wọ́ láti máa jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn ọkọ àti àwọn aya gbọ́dọ̀ sapá gidi láti lóye ara wọn