Ìṣòro Aráyé Kò Ní Í Pẹ́ Dópin!
“ÌWỌ̀NBA díẹ̀ ni ohun tí ètò ìfẹ́dàáfẹ́re lè ṣe tí kò bá sí lára ìwéwèé gbígbòòrò, tó ní ìtìlẹ́yìn àwọn olóṣèlú, tí wọ́n fẹ́ fi yanjú àwọn ìṣòro tó dìídì ń ṣokùnfà ìforígbárí. Ìrírí ti fi hàn léraléra pé ètò ìfẹ́dàáfẹ́re nìkan kò lè yanjú àwọn ìṣòro tó jẹ́ ti ìṣèlú pọ́ńbélé.”—The State of the World’s Refugees 2000.
Láìka gudugudu méje yààyàà mẹ́fà táwọn afẹ́dàáfẹ́re ń ṣe, síbẹ̀ ńṣe ni ìṣòro ẹ̀dá túbọ̀ ń peléke sí i. Ìrètí wo ló wà pé ojútùú pípẹ́ títí lọ́nà ti ìṣèlú yóò wà? Ká sọ tòótọ́, ó kọjá agbára àwọn olóṣèlú. Àmọ́, ibòmíràn wo la lè yíjú sí? Inú àyọkà kan tó ṣe kókó níbẹ̀rẹ̀ lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù ló ti ṣàlàyé bí Ọlọ́run yóò ṣe fòpin sí gbogbo ìṣòro ọmọ aráyé. Ó tiẹ̀ tọ́ka sí ètò tí Ọlọ́run máa lò láti ṣe èyí—ìyẹn ètò tó máa bojú tó ohun tó dìídì ń fa gbogbo ìṣòro tó ń bá wa fínra lóde òní. Ẹ ò ṣe jẹ́ ká gbé ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yẹ̀ wò? Àyọkà náà wà nínú Éfésù 1:3-10.
“Láti Tún Kó Ohun Gbogbo Jọpọ̀ Nínú Kristi”
Àpọ́sítélì náà sọ pé, ó jẹ́ ètè Ọlọ́run láti ṣe ohun tó pè ní “iṣẹ́ àbójútó kan [tàbí ètò àbójútó kan] ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀.” Kí ni èyí túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ti yan àkókò kan nígbà tí yóò gbégbèésẹ̀ “láti tún kó ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi, àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” (Éfésù 1:10) Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run ti ṣe ètò kan láti mú gbogbo ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ti orí ilẹ̀ ayé padà wà níṣọ̀kan lábẹ́ ìdarí òun fúnra rẹ̀. Ó dùn mọ́ni nínú pé, nígbà tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ nì, J. H. Thayer, ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ tá a pè ní ‘láti tún kó jọpọ̀’ níhìn-ín, ó sọ pé: “Kíkó . . . gbogbo ohun àti gbogbo ẹni (tí ẹ̀ṣẹ̀ ti yà nípa títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí) jọpọ̀ sọ́dọ̀ ara rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, sínú ipò ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi.”
Ìyẹn tọ́ka sí ìdí tó fi yẹ kí Ọlọ́run ṣe èyí nítorí bí ìyapa ṣe wáyé níbẹ̀rẹ̀ pàá. Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, tẹ̀ lé Sátánì Èṣù nínú ọ̀tẹ̀ tó ṣe sí Ọlọ́run. Wọ́n fẹ́ máa ṣe ohun tó wù wọ́n, kí wọ́n lè máa fúnra wọn pinnu rere àti búburú. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Ní ìbámu pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, ó lé wọn kúrò nínú ìdílé Ọlọ́run, wọ́n sì pàdánù àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú rẹ̀. Wọ́n kó ìràn ènìyàn sínú àìpé pẹ̀lú gbogbo ìyọrísí búburú tá à ń bá yí lóde òní.—Róòmù 5:12.
Fífàyè Gba Ibi Fúngbà Díẹ̀
Àwọn kan lè béèrè pé: ‘Kí nìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? Èé ṣe tí kò wulẹ̀ lo agbára ńlá rẹ̀, kó sì fi tipátipá mú wọn ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kó wá tipa bẹ́ẹ̀ dènà gbogbo ìrora àti ìyà tó ń hàn wá léèmọ̀ báyìí?’ Ó ṣeé ṣe ká ronú lọ́nà yẹn. Àmọ́ kí ni fífi túláàsì mú àwọn èèyàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀ yóò fi hàn? Ǹjẹ́ o lè fojú rere wo ẹnikẹ́ni tó jẹ́ pé ojú ẹsẹ̀ tó bá rí i pé èrò àwọn kan yàtọ̀ sí tòun ló ti máa gbógun dìde láti rẹ́yìn gbogbo wọn nítorí pé ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀? Ó dájú pé o ò ní fojú rere wo onítọ̀hún.
Kì í kúkú ṣe agbára ńlá Ọlọ́run làwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyẹn pè níjà. Ohun tí wọ́n pè níjà ní ti gidi ni ẹ̀tọ́ tó ní láti ṣàkóso àti ọ̀nà tó gbà ń ṣàkóso. Kí àwọn àríyànjiyàn pàtàkì wọ̀nyí lè yanjú pátápátá, Jèhófà fàyè gba àwọn ẹ̀dá rẹ̀ láti ṣàkóso ara wọn fúngbà díẹ̀ láìsí pe òun dá sí wọn. (Oníwàásù 3:1; Lúùkù 21:24) Nígbà tí àkókò yẹn bá dópin, yóò tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso lórí gbogbo ayé pátá. Yóò wá hàn kedere-kèdèrè nígbà náà pé ọ̀nà tó gbà ń ṣàkóso ni ọ̀nà kan ṣoṣo tó lè mú àlàáfíà, ayọ̀ àti aásìkí pípẹ́ títí wá fún àwọn olùgbé ayé. Ìgbà yẹn la óò mú gbogbo àwọn aninilára ayé yìí kúrò títí láé.—Sáàmù 72:12-14; Dáníẹ́lì 2:44.
“Ṣáájú Ìgbà Pípilẹ̀ Ayé”
Ó ti pẹ́ gan-an tí Jèhófà ti pinnu láti ṣe gbogbo èyí. Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan “ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé.” (Éfésù 1:4) Ìyẹn kì í ṣe kí a tó dá ayé tàbí kí a tó dá Ádámù àti Éfà o. Ayé yẹn “dára gan-an ni,” ọ̀tẹ̀ ò sí tíì wáyé nígbà yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) “Ayé” wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá ní lọ́kàn? Ayé àwọn ọmọ tí Ádámù àti Éfà bí ni—ìyẹn ayé ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ti àwọn èèyàn tó ń retí àtidi ẹni tí a rà padà. Kó tó di pé wọ́n bí ọmọ kankan ni Jèhófà ti mọ ọ̀nà tóun máa gbé e gbà láti pèsè ìtura fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù tó ṣeé rà padà.—Róòmù 8:20.
Àmọ́ ṣá o, èyí kò wá túmọ̀ sí pé Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run máa ń bójú tó ọ̀ràn bí ẹ̀dá ènìyàn ṣe ń bójú tó o. Nítorí àwọn èèyàn mọ̀ pé ìṣòro lè yọjú lójijì, wọ́n á wéwèé oríṣiríṣi ọ̀nà àbáyọ sílẹ̀. Rárá o, Ọlọ́run Olódùmarè kàn máa ń gbé ète tirẹ̀ kalẹ̀ ni, á sì mú un ṣẹ. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé bí Jèhófà yóò ṣe mú ìtura pípẹ́ títí wá fún ìràn ènìyàn. Báwo ni yóò ṣe ṣe é?
Ta Ni Yóò Mú Ìtura Wá?
Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tí a fi ẹ̀mí yàn ní ipa pàtàkì tí wọ́n máa kó nínú ṣíṣàtúnṣe ọṣẹ́ tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ti ṣe. Pọ́ọ̀lù sọ pé Jèhófà “yàn wá ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú [Kristi],” láti bá Jésù jọba nínú Ìjọba rẹ̀ ọ̀run. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé èyí síwájú sí i, ó sọ pé Jèhófà “yàn wá ṣáájú sí ìsọdọmọ fún ara rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi.” (Éfésù 1:4, 5) Àmọ́ o, kì í ṣe pé Jèhófà yàn wọ́n, tàbí pé ó ti kádàrá wọn ní ẹnì kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, ó yan ẹgbẹ́ kan tó jẹ́ olóòótọ́ àti olùfọkànsìn tí yóò bá Kristi kópa nínú ṣíṣàtúnṣe ọṣẹ́ tí Sátánì Èṣù pẹ̀lú Ádámù àti Éfà ṣe fún ìdílé aráyé.—Lúùkù 12:32; Hébérù 2:14-18.
Ohun àgbàyanu gbáà lèyí! Nínú ìpèníjà tí Sátánì kọ́kọ́ gbé dìde sí ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run, ohun tó ń sọ ni pé àwọn àléébù kan wà nínú bí Ọlọ́run ṣe ṣẹ̀dá èèyàn—pé tí wọ́n bá dojú kọ ìṣòro tó kọjá agbára wọn tàbí nǹkan kan tó lè ré wọn lọ sínú ẹ̀ṣẹ̀, gbogbo wọn ló máa ṣọ̀tẹ̀ sí ìṣàkóso Ọlọ́run. (Jóòbù 1:7-12; 2:2-5) Nínú ìfihàn pípabanbarì “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ ológo,” bí àkókò ti ń lọ Jèhófà Ọlọ́run fi bí òun ṣe fọkàn tán àwọn èèyàn tí òun dá sórí ilẹ̀ ayé hàn nípa sísọ àwọn kan lára ìdílé Ádámù ẹlẹ́ṣẹ̀ di ọmọ rẹ̀ tẹ̀mí. Àwọn tó wà nínú àwùjọ kékeré yìí ni yóò lọ sìn ní ọ̀run. Fún ète wo?—Éfésù 1:3-6; Jòhánù 14:2, 3; 1 Tẹsalóníkà 4:15-17; 1 Pétérù 1:3, 4.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn tí Ọlọ́run sọ di ọmọ wọ̀nyí yóò di “ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi” nínú Ìjọba rẹ̀ ti ọ̀run. (Róòmù 8:14-17) Gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà, wọ́n á kópa nínú gbígba ìdílé ènìyàn lọ́wọ́ ìrora àti ìyà tó ń bá a fínra báyìí. (Ìṣípayá 5:10) Lóòótọ́, “gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.” Àmọ́, láìpẹ́, àwọn ààyò ọmọ Ọlọ́run yìí yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú Jésù Kristi ní pẹrẹu. Gbogbo èèyàn onígbọràn ni a ‘ó sì dá sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, tí wọn yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run’ lẹ́ẹ̀kan sí i.—Róòmù 8:18-22.
“Ìtúsílẹ̀ Nípa Ìràpadà”
Gbogbo èyí ti ṣeé ṣe nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, tí í ṣe àfihàn pípabanbarì ti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run ní sí ayé ìran èèyàn tó ṣeé rà padà yìí. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀ [Jésù Kristi] àwa ní ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ẹni yẹn, bẹ́ẹ̀ ni, ìdáríjì àwọn àṣemáṣe wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀.”—Éfésù 1:7.
Jésù Kristi ni òléwájú nínú mímú ète Ọlọ́run ṣẹ. (Hébérù 2:10) Ẹbọ ìràpadà rẹ̀ ló mú kí Jèhófà sọ àwọn kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù di ọmọ sínú ìdílé rẹ̀ ọ̀run, kí ó sì gba ìràn ènìyàn kúrò lọ́wọ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù, láìfi àwọn òfin àti ìlànà Rẹ̀ báni dọ́rẹ̀ẹ́. (Mátíù 20:28; 1 Tímótì 2:6) Jèhófà ti ṣe àwọn nǹkan lọ́nà tó gbé òdodo rẹ̀ lárugẹ, tó sì bá ohun tí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ pípé béèrè mu.—Róòmù 3:22-26.
“Àṣírí Ọlọ́wọ̀” ti Ọlọ́run
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ti kọjá kí Ọlọ́run tó sọ bí òun ṣe máa mú ète òun fún ilẹ̀ ayé ṣẹ ní pàtó. Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, “ó sọ àṣírí ọlọ́wọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mímọ̀ fún [àwọn Kristẹni].” (Éfésù 1:9) Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lóye ipa pàtàkì tí Jésù Kristi máa kó nínú mímú ète Ọlọ́run ṣẹ. Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí lóye ipa pàtàkì táwọn náà máa kó gẹ́gẹ́ bí ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba rẹ̀ ọ̀run. (Éfésù 3:5, 6, 8-11) Dájúdájú, ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run ní ọwọ́ Jésù Kristi àtàwọn tí wọ́n máa jùmọ̀ ṣàkóso ni ètò tí Ọlọ́run máa lò láti mú àlàáfíà pípẹ́ títí wá, kì í ṣe ní ọ̀run nìkan àmọ́ lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú. (Mátíù 6:9, 10) Nípasẹ̀ rẹ̀ ni Jèhófà yóò fi mú ayé yìí padà sínú ipò tó fẹ́ kó wà níbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.—Aísáyà 45:18; 65:21-23; Ìṣe 3:21.
Àkókò tó yàn láti gbégbèésẹ̀ tí yóò fi mú gbogbo ìnilára àti ìwà ìrẹ́nijẹ kúrò lórí ilẹ̀ ayé kù sí dẹ̀dẹ̀. Àmọ́, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò náà ní ti gidi ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Lọ́nà wo? Nípa bíbẹ̀rẹ̀ sí kó “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run” jọ nígbà yẹn, ìyẹn àwọn tó máa bá Kristi jọba ní ọ̀run. Àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù wà lára àwọn wọ̀nyí. (Éfésù 2:4-7) Ní báyìí, ní àkókò tiwa, Jèhófà ti ń kó “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé” jọ. (Éfésù 1:10) Iṣẹ́ ìwàásù tí à ń ṣe kárí ayé ló ń lò láti sọ ìhìn rere nípa Ìjọba náà tí ń bẹ ní ìkáwọ́ Jésù Kristi di mímọ̀ fún gbogbo orílẹ̀-èdè. Ó tiẹ̀ ń kó àwọn tó tẹ́wọ́ gbà á jọ sí ibi ààbò àti ìwòsàn tẹ̀mí báyìí. (Jòhánù 10:16) Láìpẹ́ nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé tí a fọ̀ mọ́ tónítóní, wọn yóò rí òmìnira kíkún rẹ́rẹ́ kúrò lọ́wọ́ gbogbo ìwà ìrẹ́nijẹ àti ìjìyà.—2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 11:18.
“Ọ̀pọ̀ ìgbésẹ̀ kíkàmàmà” làwọn elétò ìfẹ́dàáfẹ́re ti gbé láti ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn táyé ń ni lára. (The State of the World’s Children 2000) Àmọ́, ìgbésẹ̀ tó kàmàmà jù lọ ni èyí tó máa wáyé láìpẹ́ nígbà tí Kristi Jésù àtàwọn alájùmọ̀ṣàkóso rẹ̀ nínú Ìjọba ọ̀run bá dá sí ọ̀ràn ayé. Pátápátá ni wọ́n máa fa gbòǹgbò ohun tó ń fa ìforígbárí àtàwọn ìwà ibi mìíràn tó ń hàn wá léèmọ̀ tu. Wọ́n á sì fòpin sí gbogbo ìṣòro ọmọ aráyé.—Ìṣípayá 21:1-4.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ètò ìfẹ́dàáfẹ́re kò tíì yanjú ìṣòro ọmọ aráyé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ẹbọ ìràpadà Kristi ló gba ìran ènìyàn lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ó ṣeé ṣe láti rí ààbò àti ìwòsàn tẹ̀mí lónìí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Láìpẹ́, ìtura kíkún kúrò nínú àwọn ìṣòro yóò dé, nípasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà