Ǹjẹ́ Ò Ń “Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ọgbọ́n Tí Ó Gbéṣẹ́”?
NÍNÚ ìtàn àròsọ kan, wọ́n ní ọmọkùnrin kan ń gbé ní abúlé kan, àwọn òbí rẹ̀ ò sì ní lọ́wọ́. Àwọn ará abúlé yẹn máa ń fi ọmọ náà ṣe yẹ̀yẹ́ torí wọ́n gbà pé ó yọ̀dẹ̀. Táwọn ará abúlé náà bá ní àlejò, wọ́n á pe ọmọ náà pé kó wá, wọ́n á sì máa mú un ṣeré lójú àlejò wọn. Wọ́n á kó ẹyọ owó méjì dání, wọ́n á ní kó múkan. Ọ̀kan lára ẹyọ owó náà fi ìlọ́po méjì ju ìkejì lọ. Tọ́mọ náà bá máa mu, á mú èyí tó kéré níye, á sì sá lọ.
Lọ́jọ́ kan, àlejò kan sọ fún ọmọ náà pé, “Ṣó ò mọ̀ pé èyí tó o mú yẹn kéré sí ìkejì ni?” Ọmọ náà rẹ́rìn-ín, ó wá fèsì pé, “Mo mọ̀.” Àlejò náà wá sọ pé, “Kí ló wá dé tó o fi mú èyí tó kéré, ṣó ò mọ̀ pé tó o bá mú ìkejì, ìlọ́po méjì owó yẹn lo máa ní!” Ọmọ náà sọ pé, “Ó yé mi, àmọ́ tí mo bá mú èyí tó níye lórí yẹn, àwọn èèyàn ò ní fi owó bá mi ṣeré mọ́. Ṣé ẹ mọ iye owó kékeré tí mo ti kó jọ?” Ẹ ò rí i pé ọmọ yìí fi hàn pé òun gbọ́n, ànímọ́ tó dáa táwọn àgbà pàápàá lè kọ́ sì lèyí.
Bíbélì sọ pé: “Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú. Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò máa rìn nínú ààbò ní ọ̀nà rẹ, ẹsẹ̀ rẹ pàápàá kì yóò sì gbún ohunkóhun.” (Òwe 3:21, 23) Torí náà, tá a bá mọ ohun tí “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́” jẹ́ àti bá a ṣe lè lò ó, á dáàbò bò wá. Kò ní jẹ́ ká ṣe ohun tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, àá sì dúró gbọin.
KÍ NI ỌGBỌ́N TÓ GBÉṢẸ́?
Ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ yàtọ̀ sí ìmọ̀ àti òye. Ẹni tó ní ìmọ̀ lẹni tó ń kẹ́kọ̀ọ́, tó sì ní ọ̀pọ̀ ìsọfúnni. Ẹni tó ní òye máa ń mọ bí àwọn ọ̀rọ̀ kan ṣe so kọ́ra. Àmọ́ ẹni tó ní ọgbọ́n máa ń fi òye lo ìmọ̀ tó ní láti ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu.
Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè yára ka ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tán, kó sì lóye ohun tó kà. Ìdáhùn rẹ̀ tiẹ̀ lè sojú abẹ níkòó nígbà tí wọ́n ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé kó sì máa dáhùn dáadáa. Àwọn nǹkan yìí lè mú ká gbà pé ó ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Àmọ́ ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé ó ní ọgbọ́n tó gbẹ́ṣẹ́? Ó lè má jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ó kàn lè jẹ́ ẹni tó máa ń tètè lóye nǹkan. Ṣùgbọ́n tó bá ti ń fi ohun tó ń kọ́ sílò, tó sì ń fi òye ṣe nǹkan, ó ti ń di ọlọ́gbọ́n nìyẹn. Tó bá ń ronú kó tó ṣèpinnu, tí ohun tó ṣe sì bọ́gbọ́n mu, á túbọ̀ ṣe kedere pé ó ní ọgbọ́n tó gbéṣẹ́.
Nínú Mátíù 7:24-27, Jésù sọ àpèjúwe àwọn ọkùnrin méjì tó kọ́ ilé. Jésù pe ọ̀kan nínú wọn ní “olóye.” Ìdí ni pé ọkùnrin yìí ronú ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lẹ́yìnwá ọ̀la, ó sì kọ́lé rẹ̀ sórí àpáta. Ó jẹ́ aláròjinlẹ̀, ó sì hùwà ọgbọ́n. Kò ronú pé ó máa dín ìnáwó kù tóun bá kọ́ ilé òun sórí iyanrìn, òun sì máa tètè kọ́ ọ parí. Torí pé ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, o ronú ohun tó lè tẹ̀yìn ìpinnu rẹ̀ yọ lọ́jọ́ ọ̀la. Nígbà tí ìjì jà, ilé rẹ̀ dúró digbí. Ó wá yẹ ká bi ara wa pé, Báwo làwa náà ṣe lè di ọlọ́gbọ́n, ká sì fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ?
BÁWO NI MO ṢE LÈ DI ỌLỌ́GBỌ́N?
Lákọ̀ọ́kọ́, ìwé Míkà 6:9 sọ pé: “Ẹni tí ó ní ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ yóò sì bẹ̀rù orúkọ [Ọlọ́run].” Ẹni tó bá bẹ̀rù orúkọ Jèhófà á máa bọ̀wọ̀ fún Jèhófà. Èyí gba pé kéèyàn mọ ohun tí orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí, kéèyàn fọwọ́ pàtàkì mú un, kéèyàn sì máa tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà. Tó o bá mọ bẹ́nì kan ṣe ń ronú àti bó ṣe ń hùwà, á rọrùn fún ẹ láti bọ̀wọ̀ fún un. Wàá lè fọkàn tán an, wàá sì lè kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ̀. Tá a bá fẹ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ó yẹ ká máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run ká tó ṣèpinnu, ká sì máa wò ó bóyá ohun tá a fẹ́ ṣe máa múnú Jèhófà dùn tàbí kò ní múnú rẹ̀ dùn.
Ohun kejì lohun tí ìwé Òwe 18:1 sọ pé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.” Tá ò bá ṣọ́ra, a lè ya ara wa sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà, ká sì pa àwọn èèyàn Ọlọ́run tì. Tá ò bá fẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí wa, a gbọ́dọ̀ máa wáyè láti wà pẹ̀lú àwọn tó bẹ̀rù orúkọ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa wà pẹ̀lú àwọn ará ní Gbọ̀ngàn Ìjọba bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Tá a bá wà nípàdé, ó yẹ ká pọkàn pọ̀, ká sì jẹ́ kí ohun tí wọ́n ń sọ wọ̀ wá lọ́kàn.
Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún Jèhófà, a máa túbọ̀ sún mọ́ ọn. (Òwe 3:5, 6) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Jèhófà, tá a sì ń jẹ́ kóhun tá à ń kọ́ wọ̀ wá lọ́kàn, a máa mọ ohun tí ìwà wa máa yọrí sí, àá sì lè tètè ṣe ohun tó tọ́. A tún gbọ́dọ̀ máa gba ìmọ̀ràn táwọn ará tó nírìírí bá fún wa. (Òwe 19:20) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní máa hùwà tí kò bọ́gbọ́n mu, kàkà bẹ́ẹ̀ àá túbọ̀ máa gbọ́n sí i.
BÁWO NI ỌGBỌ́N ṢE LÈ RAN ÌDÍLÉ LỌ́WỌ́?
Ọgbọ́n máa ń jẹ́ kí ìdílé wà ní ìṣọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì gba àwọn aya níyànjú pé kí wọ́n ní “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” fún ọkọ wọn. (Éfé. 5:33) Kí ni ọkọ kan lè ṣe kí ìyàwó rẹ̀ lè máa bọ̀wọ̀ fún un? Tó bá kàn án nípá pé aya òun gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fóun, ọ̀wọ̀ tí aya rẹ̀ máa ní fún un ò ní tọkàn rẹ̀ wá. Kó má bàa dìjà, ìyàwó rẹ̀ lè bọ̀wọ̀ fún un ní ìṣojú rẹ̀, àmọ́ tí kò bá sí níbẹ̀, ṣó ṣì máa bọ̀wọ̀ fún un? Bóyá ni. Ó yẹ kí ọkọ kan ronú lórí ohun táá jẹ́ kí ìyàwó rẹ̀ bọ̀wọ̀ fún un látọkàn wá. Tó bá ń fi èso tẹ̀mí ṣèwàhù, tó nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀, tó sì jẹ́ onínúure, ó dájú pé ìyàwó rẹ̀ máa bọ̀wọ̀ fún un látọkàn wá. Àmọ́, ó yẹ kí ìyàwó kan tó jẹ́ Kristẹni bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ yálà ọkọ rẹ̀ ń hùwà tó dáa tàbí ìwà rẹ̀ ò dáa.—Gál. 5:22, 23.
Bíbélì tún sọ pé kí ọkọ nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀. (Éfé. 5:28, 33) Ìyàwó kan tó fẹ́ kí ọkọ rẹ̀ máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lè ronú pé á dáa kóun ṣe àwọn nǹkan kan tó kù díẹ̀ káàtó láṣìírí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí ọkọ rẹ̀ mọ̀ nípa nǹkan ọ̀hún. Àmọ́ ṣé ìwà ọgbọ́n nìyẹn? Tọ́kọ rẹ̀ bá wá pa dà mọ̀ nípa rẹ̀, kí ló máa ṣẹlẹ̀? Ṣó ṣì máa nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀? Ká sòótọ́, ìyẹn máa ṣòro fún un. Kàkà kí ìyàwó yẹn ṣe bẹ́ẹ̀, á dáa kó wá àsìkò tó wọ̀ táá fi ṣàlàyé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fún ọkọ rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ọkọ rẹ̀ mọyì rẹ̀ pé ó sòótọ́, ìyẹn á sì jẹ́ kó túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí wọn lẹ́nu, káwọn òbí sì máa fi ìlànà Jèhófà tọ́ wọn sọ́nà. (Éfé. 6:1, 4) Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé káwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn ní òfin jàn-ànràn jan-anran? Kì í kàn ṣe pé káwọn ọmọ mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe àti ìyà tí wọ́n máa jẹ tí wọn ò bá ṣe é. Òbí tó gbọ́n máa ń jẹ́ kọ́mọ rẹ̀ mọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n tẹ̀ lé òfin tí wọ́n bá fún un.
Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ọmọ kan sọ̀rọ̀ sí bàbá tàbí ìyá rẹ̀, táwọn òbí náà bá sọ̀rọ̀ burúkú sọ́mọ náà tàbí tí wọ́n fi ìbínú bá a wí, ó lè kó ìtìjú bá ọmọ náà tàbí kó sọ ọmọ náà dẹni tí kì í sọ tinú ẹ̀. Ọmọ náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í dinú, ìyẹn sì lè jẹ́ kó má fi bẹ́ẹ̀ sún mọ́ àwọn òbí rẹ̀ mọ́.
Àwọn òbí tó gbọ́n máa ń ronú nípa bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ọmọ wọn wí àti ipa tó máa ní lórí wọn lọ́jọ́ iwájú. Tí ọmọ kan bá ṣe ohun tí kò tọ́, kò yẹ káwọn òbí yára bá ọmọ náà wí lójú àwọn ẹlòmíì. Tí wọ́n bá ti wà láwọn nìkan, òbí náà lè fi sùúrù ṣàlàyé pé Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn kí wọ́n lè ṣe ara wọn láǹfààní. Èyí á wá mú kọ́mọ náà máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí rẹ̀ torí ó mọ̀ pé Jèhófà lòun ń bọ̀wọ̀ fún. (Éfé. 6:2, 3) Ó dájú pé ohun tí òbí yìí ṣe máa wọ ọmọ rẹ̀ lọ́kàn. Á mọ̀ pé àwọn òbí òun nífẹ̀ẹ́ òun gan-an, á sì túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Èyí á mú kó máa yá ọmọ náà lára láti bá àwọn òbí rẹ̀ sọ̀rọ̀ tí nǹkan kan bá ń jẹ ẹ́ lọ́kàn.
Àwọn òbí kan lè máa rò pé táwọn bá bá ọmọ àwọn wí, ó lè bínú. Torí bẹ́ẹ̀, wọ́n kì í bá wọn wí. Àmọ́, irú ọmọ wo lọmọ náà máa yà tó bá dàgbà? Ṣé irú ọmọ bẹ́ẹ̀ á bẹ̀rù Jèhófà, ṣé á sì máa fi ọgbọ́n Ọlọ́run ṣèwà hù? Ṣó máa fọwọ́ gidi mú ìjọsìn Jèhófà, ṣé á sì máa wù ú láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún Ọlọ́run?—Òwe 13:1; 29:21.
Oníṣẹ́ ọnà kan máa ń fara balẹ̀ ronú lórí ohun tó fẹ́ ṣe, kì í kàn kù gìrì ṣiṣẹ́, kó sì máa retí pé iṣẹ́ ọ̀hún á jọjú. Àwọn òbí tó gbọ́n máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n máa ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò, èyí á sì mú kí wọ́n máa bẹ̀rù orúkọ Jèhófà. Táwọn òbí bá ń fọwọ́ gidi mú ìjọsìn Jèhófà, tí wọ́n sì ń bá àwọn ará kẹ́gbẹ́, wọ́n á ní ọgbọ́n tí wọ́n á fi gbé ilé wọn ró.
Ó yẹ ká máa ronú dáadáa ká tó ṣèpinnu, torí pé àṣesílẹ̀ làbọ̀wábá. Torí náà, dípò téèyàn á fi kù gìrì ṣèpinnu, ǹjẹ́ kò ní dáa kéèyàn fara balẹ̀, kó sì ronú jinlẹ̀? Ronú nípa ohun tó máa gbẹ̀yìn ìpinnu tó o bá ṣe. Máa bẹ Jèhófà pé kó tọ́ ẹ sọ́nà, kó o sì máa fi ọgbọ́n Ọlọ́run ṣèwà hù. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń fi ìṣọ́ ṣọ́ ọgbọ́n tó gbẹ́ṣẹ́, àá sì rí ìyè.—Òwe 3:21, 22.