Ìgbọràn—Ṣé Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Téèyàn Ń Kọ́ Lọ́mọdé Ni?
“ỌMỌ Tó Lè Dánú Rò Làwọn Òbí Ń Fẹ́, Kì Í Ṣe Ọmọ Onígbọràn Lásán.” Bí àkọlé ìwé ìròyìn kan ṣe kà nìyẹn. Ìròyìn ní ṣókí yìí ni a gbé ka àbájáde ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní New Zealand, tó fi hàn pé kìkì “ìpín méjìlélógún nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló gbà pé ó yẹ ká máa kọ́ àwọn ọmọdé nígbọràn nínú ilé.” Ìwádìí náà tún ṣàwárí pé àwọn òbí lóde òní gbà gbọ́ pé àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ kéèyàn kọ́ àwọn ọmọdé ni nǹkan bíi mímọ̀wàáhù, dídádúró lómìnira, àti ṣíṣe ojúṣe ẹni.
Nínú ayé kóńkó jabele àti ayé onímọtara-ẹni-nìkan yìí, kò yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni kò fojú pàtàkì wo ìgbọràn àti fífi í kọ́ àwọn ọmọ. Àmọ́, ṣé ó dáa kí á kàn ka ọ̀ràn jíjẹ́ ọmọ onígbọràn sí ohun ayé àtijọ́ tí kò bóde mu mọ́? Tàbí kẹ̀, ǹjẹ́ ó wà lára ẹ̀kọ́ pàtàkì tó yẹ káwọn ọmọdé kọ́, kí ó sì ṣe wọ́n láǹfààní? Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ojú wo ni Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó dá ètò ìdílé sílẹ̀, fi ń wo jíjẹ́ onígbọràn sáwọn òbí, kí sì ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tí ń wá látinú irú ìgbọràn bẹ́ẹ̀?—Ìṣe 17:28; Éfésù 3:14, 15.
“Èyí Jẹ́ Òdodo”
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tó wà ní Éfésù, pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa, nítorí èyí jẹ́ òdodo.” (Éfésù 6:1) Nítorí náà, ìdí pàtàkì táa fi gbọ́dọ̀ ṣègbọràn ni pé ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Ọlọ́run lànà pé ó tọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé, “èyí jẹ́ òdodo.”
Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, a rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ìbáwí tí òbí ń fi fúnni tìfẹ́tìfẹ́ jẹ́ ẹwà, àní “ọ̀ṣọ́ òdòdó fífanimọ́ra ni wọ́n jẹ́ fún orí rẹ àti àtàtà ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn fún ọrùn rẹ,” àti ohun tó “dára gidigidi nínú Olúwa.” (Òwe 1:8, 9; Kólósè 3:20) Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èyí, àìgbọràn sí òbí máa ń fa ìbínú Ọlọ́run.—Róòmù 1:30, 32.
“Kí Nǹkan Lè Máa Lọ Dáadáa fún Ọ”
Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí àǹfààní mìíràn tó wà nínú ṣíṣe ìgbọràn nígbà tó kọ̀wé pé: “‘Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ’; èyí tí í ṣe àṣẹ kìíní pẹ̀lú ìlérí: ‘Kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí ìwọ sì lè wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀ ayé.’” (Éfésù 6:2, 3; Ẹ́kísódù 20:12) Báwo ni ṣíṣègbọràn sí òbí ṣe lè jẹ́ kí nǹkan máa lọ dáadáa fúnni?
Ẹ jẹ́ kí á ti ibí yìí bẹ̀rẹ̀, ṣebí òótọ́ ni pé àwọn òbí lọ́jọ́ lórí, tí wọ́n sì nírìírí jù wá lọ? Òótọ́ ni pé wọ́n lè má fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa kọ̀ǹpútà tàbí àwọn ẹ̀kọ́ míì táa ń kọ́ níléèwé, àmọ́ wọ́n mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ìgbésí ayé àti báa ṣe lè kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ọ̀dọ́ kì í lè ro àròjinlẹ̀, nítorí pé wọn ò tíì dàgbà dénú. Ìyẹn ló máa ń jẹ́ kí wọ́n fi ìwàǹwára ṣe ìpinnu, tí wọ́n sì máa ń juwọ́ sílẹ̀ láti ṣe ohun búburú tẹ́gbẹ́ wọn ń ṣe, èyí tó máa ń mú kí wọ́n wọ wàhálà. Bíbélì sọ ojú abẹ níkòó nígbà tó wí pé: “Ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí.” Kí ló lè mú un kúrò? “Ọ̀pá ìbáwí ni yóò mú un jìnnà réré sí i.”—Òwe 22:15.
Èrè ṣíṣe ìgbọràn nasẹ̀ ré kọjá àjọṣe àárín òbí àtọmọ nìkan. Kí nǹkan tó lè máa lọ geerege nínú ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbọ́dọ̀ wà, èyí sì ń béèrè ìgbọràn títí dé àyè kan. Fún àpẹẹrẹ, nínú ìdè ìgbéyàwó, mímúra tán láti juwọ́ sílẹ̀ ló máa ń yọrí sí àlàáfíà, ìfohùnṣọ̀kan, àti ayọ̀, kì í ṣe gbígbójú mọ́ni àti fífojú pa ẹ̀tọ́ àti ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn rẹ́. Níbi iṣẹ́, àwọn òṣìṣẹ́ gbọ́dọ̀ gbọ́ràn sí ọ̀gá lẹ́nu, bí iléeṣẹ́ tàbí iṣẹ́ ajé èyíkéyìí yóò bá kẹ́sẹ járí. Ní ti àwọn òfin tí ìjọba là sílẹ̀, kì í ṣe kìkì pé ìgbọràn kò ní jẹ́ kí wọ́n fìyà jẹ wá nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ń dáàbò bò wá títí dé àyè kan.—Róòmù 13:1-7; Éfésù 5:21-25; 6:5-8.
Àwọn ọ̀dọ́ tó ń ṣàìgbọràn sáwọn aláṣẹ kì í sábàá bẹ́gbẹ́ mu. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èyí, ẹ̀kọ́ táa bá kọ́ nípa ìgbọràn láti kékeré lè ṣe wá láǹfààní jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé wa. Ẹ wo bó ti ṣàǹfààní tó láti kọ́ ẹ̀kọ́ yìí láti kékeré!
Èrè Ńlá Tí Ń Wá Látinú Ṣíṣègbọràn
Kì í ṣe kìkì pé ìgbọràn ń jẹ́ kí àjọṣe dídánmọ́rán wà nínú ìdílé tó sì máa ń yọrí sí àwọn àǹfààní ọlọ́jọ́ pípẹ́ mìíràn nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ń jẹ́ kó ṣeé ṣe láti fìdí àjọṣe tó ṣe pàtàkì jù lọ múlẹ̀—ìyẹn ni àjọṣe láàárín èèyàn àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Jèhófà Ọlọ́run ní ẹ̀tọ́ láti béèrè ìgbọràn kíkún lọ́wọ́ wa, nítorí pé òun ni ‘Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá,’ òun sì ni “orísun ìyè.”—Oníwàásù 12:1; Sáàmù 36:9.
Ọ̀rọ̀ náà “ṣègbọràn” ní onírúurú ọ̀nà táa gbà ń lò ó, fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà nínú Bíbélì. Ní àfikún sí i, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìgbà la tọ́ka sí àwọn òfin, àṣẹ, ìpinnu ìdájọ́, àti ìlànà Ọlọ́run, gbogbo wọn ló sì ń béèrè ìgbọràn. Kò sí àní-àní pé béèyàn yóò bá rí ojú rere Ọlọ́run, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ onígbọràn sí i. Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹni tó bá fẹ́ ní àjọṣe pẹ̀lú Jèhófà gbọ́dọ̀ máa ṣe ìgbọràn. (1 Sámúẹ́lì 15:22) Ó bani nínú jẹ́ pé ìgbọràn kì í yá ènìyàn lára bí àìgbọràn. Bíbélì sọ pé: “Ìtẹ̀sí èrò ọkàn-àyà ènìyàn jẹ́ búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Nítorí náà, kì í ṣe ìgbà ọmọdé nìkan la gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbọràn bí kò ṣe jálẹ̀ ìgbésí ayé. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń mú èrè ńlá wá.
Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ọ́, rántí pé àṣẹ náà pé ká ṣègbọràn sáwọn òbí wé mọ́ ìlérí alápá méjì, èyíinì ni, “kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí ìwọ sì lè wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀ ayé.” Ìwé Òwe 3:1, 2, tún sọ̀rọ̀ nípa ìlérí yìí, pé: “Ọmọ mi, má gbàgbé òfin mi, kí ọkàn-àyà rẹ sì pa àwọn àṣẹ mi mọ́, nítorí ọjọ́ gígùn àti ọ̀pọ̀ ọdún ìwàláàyè àti àlàáfíà ni a ó fi kún un fún ọ.” Èrè ńlá tó wà fún àwọn tó bá ṣègbọràn ni àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà nísinsìnyí àti ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun alálàáfíà.—Ìṣípayá 21:3, 4.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30, 31]
Ìgbọràn máa ń jẹ́ kí a ní àjọṣe dídánmọ́rán nínú ìdílé, níbi iṣẹ́, àti pẹ̀lú Jèhófà