“Ẹ Gbé Gbogbo Ìhámọ́ra Ọlọrun Wọ̀”
AWỌN Kristẹni ń wọ ìhámọ́ra kẹ̀? Eeṣe ti wọn fi nilati gbé iru ohun eelo ologun bẹẹ? Wọn kìí ha ṣe olùfẹ́ alaafia ni bi? (2 Timoti 2:24) Bẹẹni, olùfẹ́ alaafia ni wọn. Sibẹ, gbogbo awọn Kristẹni tootọ ń lọwọ ninu ìjà kan—ninu eyi ti wọn ń làkàkà, kì í ṣe lati pa eniyan, ṣugbọn lati ṣẹgun.
Ìbá ṣe pe Satani kò ti ṣọ̀tẹ̀ ni, iru ìjà kan bẹẹ kì bá tí pọndandan lae. Ṣugbọn ó ṣọ̀tẹ̀, ó sì tan Adamu ati Efa jẹ sinu didarapọ mọ́ ọn ninu ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀. Lati ìgbà naa eto igbekalẹ ayé ti ó ti gbèrú wà ninu agbara “ẹni buburu nì,” Satani Eṣu. (1 Johanu 5:19) Awọn wọnni ti wọn juwọsilẹ fun Ọba-Alaṣẹ titọna naa, Jehofa, gbọdọ dènà agbara idari ti ayé ati oluṣakoso rẹ̀. Wọn gbọdọ jà fun igbesi-aye tẹmi wọn. Fun idi yii, awọn Kristẹni ni a ṣí létí pe: “Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọrun wọ̀, ki ẹyin ki o lè kọ oju ìjà si arekereke Eṣu.”—Efesu 6:11.
Ìhámọ́ra Ogun Naa
Ṣakiyesi pe a nilo “gbogbo ìhámọ́ra Ọlọrun” bi a bá nilati daabobo wá daradara. Nigba naa, ẹ jẹ ki a wo apa kọọkan ìhámọ́ra yii gẹgẹ bi a ti ṣapejuwe rẹ̀ nipasẹ apọsiteli Pọọlu ki a sì ṣe idiyele alailabosi ọkàn nipa araawa lati pinnu yálà a ti mura wa silẹ ni kikun fun ogun jíjà tẹmi.—Efesu 6:14-17.
“Ẹ duro nitori naa lẹhin ti ẹ ti fi àmùrè otitọ di ẹgbẹ́ yin.” (Efesu 6:14a) Ni awọn akoko ti a kọ Bibeli awọn ọmọ-ogun a maa wọ bẹ́líìtì aláwọ ti ó fẹ̀ tó íǹṣì mẹfa. Àmùrè yii a maa ṣeranwọ lati daabobo ìbàdí. Nigba ti ọmọ-ogun kan bá fún àmùrè rẹ̀ le dan-in-dan-in, eyi duro fun imuratan fun ìjà ogun.
Ó ti ba a mu to, nigba naa, pe otitọ atọrunwa ni a fiwe àmùrè ọmọ-ogun kan! Eyi ṣapejuwe daradara pe a gbọdọ pa otitọ Ọrọ Ọlọrun mọ́ pẹkipẹki sọdọ araawa, bi ẹni pe a fi dì wá ní àmùrè. A gbọdọ ronu jinlẹ lori èrò ti Ọrọ Ọlọrun ní ninu. Eyi yoo daabobo wa kuro ninu didi ẹni ti a tanjẹ nipasẹ awọn èké ati itanjẹ. Ju bẹẹ lọ, awọn ọrọ lati ẹnu Jehofa yoo tì wá lẹhin yoo sì fun wa lokun nipa tẹmi yoo sì gbé iwatitọ ró.
“Ti ẹ sì ti di igbaya ododo nì mọra.” (Efesu 6:14b) Igbaya ọmọ-ogun kan daabobo ẹ̀yà ara ìyára ti ó ṣe kókó—ọkan-aya. Ninu ìhámọ́ra tẹmi ti Ọlọrun fi funni, nigba naa, ododo daabobo ọkan-aya wa. Lọna ti ó bá Iwe Mimọ mu, ọkan-aya jẹ́ àmì ti ó bá ohun ti a jẹ́ ninu mu—awọn imọlara, ironu, ati ifẹ-ọkan wa. Niwọn ìgbà ti Bibeli tun sọ pe ọkan-aya ni ó tẹ̀ sí iwa buburu, ó ṣe kókó lati mú ipinnu lati rọ̀ timọtimọ mọ́ ọ̀pá idiwọn ododo ti Jehofa dagba. (Jeremaya 17:9) Igbọran si Ọlọrun kò gbọdọ jẹ́ ṣekárími alagabagebe kan; ó gbọdọ wá lati inu wa lọ́hùn-ún. Eyi beere pe ki a mú ifẹ lilagbara fun ododo ati ikoriira lilagbara bakan naa fun ìwà àìlófin dagba. (Saamu 45:7) Nipa bayii ọkan-aya wa ni a o daabobo.
“Ti ẹ sì ti fi ìmúra ihinrere alaafia wọ eṣẹ yin ni bàtà.” (Efesu 6:15) Ǹjẹ́ ẹsẹ rẹ̀ ni a wọ̀ ní bàtà ni ọ̀nà yii bi? Wọn ha ń sìn ọ́ lọ sinu iṣẹ-ojiṣẹ pápá deedee lati polongo ihinrere naa bi? Iwọ ha ń làkàkà lati mú ìjójúlówó igbokegbodo iwaasu ati ikọni rẹ sunwọn sii bi? Loootọ, awọn ipinlẹ kan ti gíràn-án ni ifiwera. Awọn ẹnikọọkan lè jẹ́ alaibikita, ẹlẹmii ìdágunlá tabi aṣodisini. Iwaasu wa tilẹ lè mú inunibini wa sori wa. Ṣugbọn nipa fiforiti i, awọn Kristẹni a maa mu ifarada dagba, animọ kan ti ń pese aabo lodisi atako Satani. Bi o tilẹ jẹ pe a ṣe inunibini sí i, Pọọlu jẹ́ oniwaasu onitara, a sì fun wa niṣiiri lati ‘jẹ́ alafarawe rẹ̀, ani gẹgẹ bi oun ti jẹ́ alafarawe Kristi.’—1 Kọrinti 11:1.
Mímú ki ọwọ́ dí ninu igbokegbodo iwaasu Ijọba ń fun igbọkanle wa ninu ihinrere lokun. Siwaju sii, ó ń yọnda ẹmi Jehofa lati ṣiṣẹ nipasẹ wa ninu ṣiṣaṣepari ifẹ-inu rẹ̀. Niti tootọ, iru igbokegbodo bẹẹ sọ wa di alabaaṣiṣẹ pẹlu awọn angẹli—ani pẹlu Jehofa Ọlọrun fúnraarẹ̀ paapaa. (1 Kọrinti 3:9; Iṣipaya 14:6) Níní ‘pupọ lati ṣe ninu iṣẹ Oluwa’ sì ń sọ wa di ‘aduroṣinṣin, alaiyẹsẹ.’ (1 Kọrinti 15:58) Ẹ wo iru agbayanu aabo ti eyi ń pese!
“Ẹ mú apata igbagbọ.” (Efesu 6:16) Pẹlu apata ńlá kan, ọmọ-ogun akoko igbaani kan daabobo araarẹ̀ kuro lọwọ ọ̀kọ̀ ati ẹ̀ṣín. Bi o bá kùnà lati lo apata, oun ni a lè ṣeleṣe yánnayànna tabi ki a tilẹ pa á. Awọn Kristẹni dojukọ awọn ohun ìjà ti wọn tilẹ tubọ ń ṣekupani—“ọfà iná ẹni ibi nì.” Iwọnyi ni ninu gbogbo awọn ohun àmúṣagbára ti Satani ń lò ki ó baa lè sọ igbagbọ wa di alailera ki ó sì pa wa nipa tẹmi. Wọn ní ninu inunibini, èké, awọn ìmọ̀-ọ̀ràn ayé ti ń tannijẹ, òòfà awọn ọrọ̀ àlùmọ́nì, ati idẹwo lati lọwọ ninu iwa palapala. Lati daabobo araawa lodisi gbogbo iwọnyi, a nilo apata ńlá. Kò sí apakan araawa ti a lè ṣí silẹ fun ewu lọna àìséwu.
Aburahamu ati aya rẹ̀, Sera, ni igbagbọ lilagbara. Nigba ti wọn ti kọja ọjọ-ori ọmọ bíbí, wọn ni igbagbọ ninu ileri Ọlọrun pe iru-ọmọ kan ni wọn yoo bí. Lẹhin naa, Aburahamu fi igbagbọ pípẹtẹrí han nigba ti o ṣegbọran si ìpè naa lati fi Isaaki, ọmọkunrin kanṣoṣo rẹ̀ nipasẹ Sera olùfẹ́ ọ̀wọ́n rubọ. Jehofa dá ọwọ́ Aburahamu duro ó sì pese ẹbọ ifidipo kan. Ṣugbọn Aburahamu ṣetan lati ṣegbọran. Eeṣe? Nitori pe ó ní igbagbọ patapata pe Jehofa lè jí ọmọkunrin oun dìde ki ó sì mu awọn ileri ti ó ti ṣe nipa rẹ̀ ṣẹ.—Roomu 4:16-21; Heberu 11:11, 12, 17-19.
Mose tun ni iru igbagbọ naa ti a nilo. Ó kọ ọrọ̀ Ijibiti silẹ, ní yíyàn dipo lati jiya ìnilára pẹlu awọn eniyan Ọlọrun. Eeṣe? Nitori pe o ní igbagbọ pe Jehofa wà ati pe yoo mú igbala wá fun awọn ọmọ Isirẹli. Igbagbọ Mose lagbara tobẹẹ gẹẹ debi pe “ó duro ṣinṣin bi ẹni ti o ń rí ẹni airi.”—Heberu 11:6, 24-27.
Awa ha ni igbagbọ ti o ṣee fiwera pẹlu eyi ninu Jehofa bi? Ǹjẹ́ ipo ibatan wa pẹlu Jehofa ha wà timọtimọ tobẹẹ debi pe ń ṣe ni ó fẹrẹẹ dabi pe a ń rí i? Awa ha ń muratan lati ṣe irubọ eyikeyii tabi farada inira eyikeyii lati pa ipo ibatan pẹlu Ọlọrun mọ́ bi? Awa ha ni igbagbọ kikun ninu Jehofa bi? (Heberu 11:1) Bi o bá ri bẹẹ, ọfà iná Satani kì yoo lè fagbara wọ inu apata igbagbọ wa.
“Ẹ sì mú àṣíborí igbala.” (Efesu 6:17a) Àṣíborí ọmọ-ogun kan daabobo ori rẹ̀ ati nipa bayii ọpọlọ rẹ̀—ẹ̀yà ara fun ìmúṣiṣẹ́papọ̀ awọn iṣan imọlara ati ti ironu. Ireti igbala tí Kristẹni ní ní a fiwe àṣíborí kan nitori pe ó ń daabobo ero-inu. Ero-inu Kristẹni kan ni a ti sọ di titun nipasẹ ìmọ̀ pipeye, ṣugbọn ó ṣì jẹ́ ti eniyan alailera ati alaipe kan. (Roomu 7:18; 12:2) Bi a bá yọnda lati fi ironu àìmọ́ ti ń pa igbagbọ run tí ẹmi ayé yii ń mujade bọ́ ero-inu, igbọkanle wa ninu igbala yoo ṣá ó sì lè kú nikẹhin. Ni ọwọ keji ẹ̀wẹ̀, bi a bá ń fi awọn ọrọ afunnilokun ti Ọlọrun bọ́ ero-inu wa lemọlemọ, ireti wa yoo wà ni títàn yòò ati ni kedere titilọ. Iwọ ha wa àṣíborí igbala rẹ mọ́rí pinpin bi?
“Idà ẹmi, ti i ṣe ọrọ Ọlorun.” (Efesu 6:17b) Ọrọ naa pe igi ganganran má gún mi loju okeere ni a ti i wò ó jẹ́ otitọ ninu ogun jíjà Kristẹni. Gẹgẹ bi ẹsẹ wa, ti a ti fi ihinrere alaafia wọ̀ ní bàtà, ti ń gbé wa laaarin awọn alaigbagbọ, a kò wà laini ohun ìjà. Ọrọ Ọlọrun, Bibeli, ṣiṣẹ gẹgẹ bi idà alagbara lati bẹ́ awọn èké ati àṣìlóye tẹmi dànù ati lati ran awọn ẹni ọlọ́kàn-títọ́ lọwọ lati ri ominira tẹmi.—Johanu 8:31, 32.
Jesu fi agbara ohun ìjà yii han nigba ti oun, niti tootọ, bá Satani fà á lori ọ̀ràn ariyanjiyan kan. Nigba ti a dán an wò ninu aginju, Jesu daabobo araarẹ̀ lodisi awọn ikọluni mẹta lati ọdọ satani nipa lilo Ọrọ Ọlọrun lọna gbigbeṣẹ ti ó sì sọ pe: “A kọwe rẹ̀ pe.” (Matiu 4:1-11) Bi a bá kẹkọọ lati lo idà yii pẹlu ìjáfáfá, a lè ran awọn ọlọkantutu lọwọ lati jade kuro labẹ agbara Eṣu. Lẹhin naa, pẹlu, awọn alagba ìjọ ń lo Ọrọ Ọlọrun lati daabobo agbo kuro lọwọ awọn ẹnikọọkan ti ń gbiyanju lati ṣoju igbagbọ awọn alailera dé.—Iṣe 20:28-30.
Ìjáfáfá ọmọ-ogun kan pẹlu idà kìí wá ní yọ̀bọ́kẹ́. Idalẹkọọ ati idanrawo ti a fi gbogbo ara fun, ni a beere fun lati lò ó lọna jíjáfáfá. Bakan naa, ninu ogun jíjà tẹmi ó gba ọpọ ikẹkọọ ati idanrawo deedee ninu iṣẹ-ojiṣẹ lati di olùlo Ọrọ Ọlọrun lọna jijafafa. Ni gbogbo ọ̀nà, ẹ jẹ ki a lo isapa ti a nilo lati di ọjafafa alodà tẹmi, ti ó tootun lati “mú ọrọ otitọ bi o ti yẹ.”—2 Timoti 2:15, NW.
Ẹ Maa Gbadura, Ẹ Duro Gbọnyingbọnyin
Gbogbo awọn ègé ìhámọ́ra tẹmi wa ṣe kókó fun pipa iwatitọ si Ọlọrun mọ́. Ṣugbọn bawo ni a ṣe lè fi ìhámọ́ra yii silẹ ni wíwọ̀ sọ́rùn? Ikẹkọọ Bibeli deedee, mimura silẹ ṣaaju fun awọn ipade Kristẹni, ati lẹhin naa fifeti silẹ yékéyéké ati kíkópa pẹlu akikanju ninu wọn yoo ràn wa lọwọ lati fi ìhámọ́ra wa silẹ ní wíwọ̀ sọ́rùn. (2 Timoti 3:16; Heberu 10:24, 25) Iṣẹ-ojiṣẹ pápá deedee ati onitara papọ pẹlu ibakẹgbẹ Kristẹni rere yoo tún ràn wa lọwọ lati pa ìhámọ́ra tẹmi ti a ń lò fun idoju ìjà kọni ati ìgbèjà mọ́ si ipo ti o dara.—Owe 13:20; Roomu 15:15, 16; 1 Kọrinti 15:33.
Mímú ẹmi ironu ero-ori titọna dagba tun ṣe pataki pẹlu. A gbọdọ kọ̀ lati fààyè gba awọn ìdẹnilọ ayé yii lati pín wa lọ́kàn. Kaka bẹẹ, ẹ jẹ ki a ní ‘oju tí kò gùn.’ (Matiu 6:19-24) Ni afarawe Jesu Kristi, a tun gbọdọ kẹkọọ lati nifẹẹ ododo ki a sì koriira ìwà àìlófin. (Heberu 1:9) Gbogbo awọn nǹkan wọnyi ń ràn wa lọwọ lati fi ìhámọ́ra tẹmi ti Ọlọrun fi fun wa silẹ ní wíwọ̀ sọ́rùn.
Lẹhin jijiroro ègé ìhámọ́ra tẹmi kọọkan, Pọọlu pari ọrọ nipa sisọ pe: “Pẹlu gbogbo adura ati ẹ̀bẹ̀ . . . ẹ maa gbadura nigba gbogbo ninu ẹmi, ki ẹ sì maa ṣọra sii ninu iduroṣinṣin gbogbo, ati ẹ̀bẹ̀ fun gbogbo eniyan mímọ́.” (Efesu 6:18) Awọn ọmọ-ogun aduroṣinṣin a maa ni ifarakanra pẹlu orile-iṣẹ ẹgbẹ-ogun wọn a sì maa ṣegbọran si awọn aṣẹ. Gẹgẹ bii awọn ọmọ-ogun Kristẹni, a nilati maa ni ifarakanra lemọlẹmọ pẹlu Ọba-Alaṣẹ wa, Jehofa Ọlọrun, nipasẹ “alaṣẹ fun awọn eniyan” rẹ, Jesu Kristi. (Aisaya 55:4) Eyi ni a lè ṣe, kì í ṣe nipasẹ adura olóreféé, ṣugbọn nipasẹ adura ẹ̀bẹ̀ atọkanwa ti ń fi ìwàpẹ́kípẹ́kí wa ati ifọkansin jijinlẹ wa fun Jehofa han. Nipa sisọrọpọ deedee pẹlu Jehofa, a ń gba okun lojoojumọ lati tì wa lẹhin ninu ìjà naa.
Jesu sọ pe: “Mo ti ṣẹgun ayé.” (Johanu 16:33) Jehofa pẹlu fẹ́ ki a jẹ́ aṣẹ́gun. Gẹgẹ bi iku apọsiteli Pọọlu ti sunmọle, oun lè wi pe: “Emi ti ja ìjà rere, emi ti pari iré-ìje mi, emi ti pa igbagbọ mọ́.” (2 Timoti 4:7) Ǹjẹ́ ki awa lè sọ ọrọ ti o rí bakan naa nipa ipa tiwa ninu iforigbari naa. Bi a bá fẹ́ eyi nitootọ, ẹ jẹ ki a “kọ oju ìjà si arekereke Eṣu” nipa fifi gbogbo ìhámọ́ra lati ọdọ Ọlọrun silẹ ni wíwọ̀ sọ́rùn.—Efesu 6:11.