“Ja Ìjà Àtàtà ti Ìgbàgbọ́”
SÓJÀ wo ni inú rẹ̀ kò ní dùn tí wọ́n bá sọ fún un lójú ogun pé: “Padà sílé, kó o lọ máa bá aya rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ ṣeré fúngbà díẹ̀”?
Irú nǹkan tí wọ́n ní kí sójà kan ṣe nìyẹn nígbà ayé Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì. Ọba fúnra rẹ̀ ló pàṣẹ yìí fún Ùráyà ọmọ Hétì, ó sì rọ̀ ọ́ pé kó padà sílé. Àmọ́, Ùráyà kọ̀ láti padà sí ilé rẹ̀. Nígbà tí wọ́n ní kí Ùráyà sọ ìdí tí ò fi fẹ́ padà, ó sọ pé àpótí májẹ̀mú, tó dúró fún wíwà tí Ọlọ́run wà láàárín wọn, àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ísírẹ́lì wà ní pápá ogun. Ó béèrè pé, “èmi—èmi yóò ha sì lọ sínú ilé mi láti jẹ àti láti mu àti láti sùn ti aya mi?” Ùráyà gbà pé èyí kò tọ̀nà ní irú àkókò tí nǹkan le koko bẹ́ẹ̀.—2 Sámúẹ́lì 11:8-11.
Ó yẹ ká ronú gidigidi lórí ohun tí Ùráyà ṣe yẹn, torí pé ojú ogun làwa náà wà. Ogun kan ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ó sì yàtọ̀ sí ogun èyíkéyìí táwọn orílẹ̀-èdè ayé ti jà rí. Ogun àgbáyé méjì tó ti wáyé rí kò jẹ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ogun tá à ń wí yìí, ìwọ náà wà lára àwọn tó ń jagun yìí. Ọ̀pọ̀ ewu ló wà nínú ogun náà, àkòtagìrì sì làwọn ọ̀tá tá a dojú kọ. Nínú ogun yìí, a kì í yìnbọn bẹ́ẹ̀ la kì í ju bọ́ǹbù, síbẹ̀ ohun ìjà wa lágbára gan-an.
Kó o tó di ìhámọ́ra ogun, o gbọ́dọ̀ mọ̀ bóyá ó tọ́ láti jà, kó o sì mọ ohun tó o fẹ́ torí rẹ̀ jà. Ǹjẹ́ èrè tó wà níbẹ̀ tó nǹkan téèyàn lè tìtorí rẹ̀ jà? Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì, ó mú kí ohun tá a torí rẹ̀ ń ja ogun ara ọ̀tọ̀ yìí ṣe kedere, ó ní: “Ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni o, “ìgbàgbọ́” lo gbọ́dọ̀ jà fún nínú ogun yìí kì í ṣe ìlú olódi. “Ìgbàgbọ́” tá a ń sọ yìí ni gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí ìsìn Kristẹni fi ń kọni gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì. Ó ṣe kedere pé o ní láti tẹ́wọ́ gba “ìgbàgbọ́” náà láìsíyèméjì kó o tó lè jà fún un kó o sì ṣẹ́gun.—1 Tímótì 6:12.
Ńṣe ni jagunjagun tó ní làákàyè máa ń sapá láti dá ọ̀tá rẹ̀ mọ̀. Àìmọye ọdún ni ọ̀tá tá à ń bá jà yìí ti wà nínú iṣẹ́ ogun jíjà, ó mọ oríṣiríṣi ọgbọ́n tá a fi ń jagun, ohun ìjà ogun tó ní kò sì lóǹkà. Agbára rẹ̀ ju téèyàn lọ fíìfíì. Àgbà òṣìkà, oníwà ipá àti aládàkàdekè ni ọ̀tá yìí; Sátánì lórúkọ rẹ̀. (1 Pétérù 5:8) Kò sí ohun ìjà tara tàbí ọgbọ́n àyínìke téèyàn lè lò tó máa tu ìyẹ́ kan lára ọ̀tá yìí. (2 Kọ́ríńtì 10:4) Kí lo wá lè lò láti ja ogun yìí?
Olórí ohun ìjà náà ni “idà ẹ̀mí, èyíinì ni, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Éfésù 6:17) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi bó ṣe wúlò tó hàn, ó ní: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Hébérù 4:11, 12) Ó gba ọgbọ́n àti ìṣọ́ra láti lo ohun ìjà tó mú gan-an, tí kì í tàsé, tó sì lè gúnni dé ọkàn àti ìrònú yìí.
Àwọn ọmọ ogun kan lè ní ohun ìjà tó lágbára gan-an àmọ́ bí wọn ò bá mọ bí wọ́n ṣe máa lò ó, ohun ìjà ọ̀hún ò ní wúlò. Ìwọ́ bákan náà nílò ìtọ́ni láti mọ bó o ṣe máa lo idà rẹ dáadáa. Ó dùn mọ́ni pé, ó lè rí ẹ̀kọ́ gbà lọ́dọ̀ àwọn jagunjagun tó ti pẹ́ nínú iṣẹ́ ogun. Jésù pe àwọn jagunjagun tó ti pẹ́ nínú iṣẹ́ ogun yìí ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” àwọn ló gbé iṣẹ́ lé lọ́wọ́ láti máa fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní oúnjẹ tẹ̀mí tàbí ìtọ́ni. (Mátíù 24:45) Wàá mọ ẹgbẹ́ ẹrú yìí tó o bá ń kíyè sí ipa tí ẹrú náà ń sà lójú méjèèjì láti máa kọ́ni àti láti máa ṣe ìkìlọ̀ tó bọ́ sákòókò nípa ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí ọ̀tá náà ń lò. Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn tá a fi ẹ̀mí yàn lára ìjọ Kristẹni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹgbẹ́ ẹrú yìí.—Ìṣípayá 14:1.
Iṣẹ́ tí ẹgbẹ́ ẹrú yìí ń ṣe ju pé kó kàn máa kọ́ni lọ. Ó ń fi irú ẹ̀mí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní hàn, ẹni tó kọ̀wé sí ìjọ Tẹsalóníkà pé: “Àwa di ẹni pẹ̀lẹ́ láàárín yín, bí ìgbà tí abiyamọ ń ṣìkẹ́ àwọn ọmọ tirẹ̀. Nítorí náà, ní níní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún yín, ó dùn mọ́ wa nínú jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ọkàn àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ di olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún wa.” (1 Tẹsalóníkà 2:7, 8) Ó kù sọ́wọ́ olúkúlùkù Kristẹni ajagun láti lo àwọn nǹkan tá a fi ìfẹ́ kọ́ wọn.
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìhámọ́ra Ogun
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun ń bẹ láti dáàbò bò ọ́. Wàá rí orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan ìhámọ́ra ogun yìí nínú Éfésù 6:13-18. Sójà tó bá wà lójúfò kò ní lọ jà bí ìhámọ́ra ogun rẹ̀ nípa tẹ̀mí kò bá pé tàbí tó ń fẹ́ àtúnṣe.
Gbogbo ìhámọ́ra ogun ni Kristẹni nílò, àmọ́ pàtàkì nínú rẹ̀ ni apata ńlá ti ìgbàgbọ́. Ìdí nìyí tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Lékè ohun gbogbo, ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́, èyí tí ẹ ó lè fi paná gbogbo ohun ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú náà.”—Éfésù 6:16.
Apata ńlá, tó lè bo gbogbo ara èèyàn, dúró fún bí ìgbàgbọ́ ẹni ṣe lágbára tó. O ní láti ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú ìtọ́sọ́nà Jèhófà, kó o gba láìsíyèméjì pé gbogbo ìlérí rẹ̀ ni yóò ṣẹ. Lójú rẹ, ńṣe ló yẹ kó dà bíi pé àwọn ìlérí rẹ̀ wọ̀nyẹn ti ṣẹ. Má ṣe ṣiyèméjì rárá pé bóyá ni ètò àwọn nǹkan ti Sátánì yóò pa run láìpẹ́, bóyá ayé yìí máa di Párádísè àti pé bóyá àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run yóò di ẹni pípé.—Aísáyà 33:24; 35:1, 2; Ìṣípayá 19:17-21.
Nínú ogun àrà ọ̀tọ̀ tó ń lọ lọ́wọ́ yìí, o nílò nǹkan kan tó jùyẹn lọ, ìyẹn ni ọ̀rẹ́. Nígbà ogun, àwọn tí wọ́n jìjọ ń jagun máa ń di ọ̀rẹ́ ara wọn bí wọ́n ṣe ń fún ara wọn níṣìírí tí wọ́n sì jọ ń dáàbò bo ara wọn, bóyá kí wọ́n gba ẹnì kejì wọn lọ́wọ́ ikú nígbà míì pàápàá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dára kó o ní alábàákẹ́gbẹ́, bíbá Jèhófà nìkan dọ́rẹ̀ẹ́ lo ò fi ní ba ogun lọ. Ìdí rèé tí Pọ́ọ̀lù fi sọ níparí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tó ń sọ orúkọ àwọn ohun tó para pọ̀ jẹ́ ìhámọ́ra ogun pé: “Lẹ́sẹ̀ kan náà, pẹ̀lú gbogbo oríṣi àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, kí ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà ní gbogbo ìgbà nínú ẹ̀mí.”—Éfésù 6:18.
Inú wa máa ń dùn láti wà lọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ wa tó jẹ́ kòríkòsùn. A máa ń fẹ́ láti jọ máa ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀. Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà déédéé, ńṣe ló máa dà bíi pé à ń fojú rí i bá a ṣe ń rí ọ̀rẹ́ kan tá a fọkàn tán. Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbà wá níyànjú pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.
Ọgbọ́n Ẹ̀wẹ́ Tí Ọ̀tá Náà Máa Ń Lò
Nígbà mìíràn, kíkojú bí nǹkan ṣe rí nínú ayé yìí lè dà bí ìgbà téèyàn ń fẹsẹ̀ rìn lọ láàárín pápá kan tí wọ́n ri àwọn ohun abúgbàù mọ́lẹ̀ sí. Ibikíbi ni ogun lè gbà yọ sí ọ, tí ọ̀tá náà á sì kọ lù ọ́ lójijì. Àmọ́, kí ó dá ọ lọ́jú pé gbogbo nǹkan tó o lè fi dáàbò bo ara rẹ ni Jèhófà ti pèsè.—1 Kọ́ríńtì 10:13.
Ọ̀tá náà lè fẹ́ ba tìẹ jẹ́ nípa gbígbógun ti àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì tó ṣe pàtàkì fún ìgbàgbọ́ rẹ. Àwọn apẹ̀yìndà lè máa lo ọ̀rọ̀ dídùn, ìpọ́nni ẹ̀tàn àti èrò òdì láti bì ọ́ ṣubú. Ire rẹ kọ́ ló jẹ àwọn apẹ̀yìndà lógún o. Ìwé Òwe 11:9 sọ pé: “Ẹnu ara rẹ̀ ni apẹ̀yìndà fi ń run ọmọnìkejì rẹ̀, ṣùgbọ́n ìmọ̀ ni a fi ń gba olódodo sílẹ̀.”
Àṣìṣe ni yóò jẹ́ tó o bá rò pé ó yẹ kó o máa fetí sóhun táwọn apẹ̀yìndà ń sọ tàbí pé kó o máa kàwé wọn láti lè já wọn nírọ́. Èrò òdì wọn lè ṣàkóbá fún ọ nípa tẹ̀mí, ó sì lè ba ìgbàgbọ́ rẹ jẹ́ bíi egbò tó ń yara kẹ̀. (2 Tímótì 2:16, 17) Ńṣe ló yẹ kó o máa fara wé bí Ọlọ́run ṣe ṣe sáwọn apẹ̀yìndà. Jóòbù sọ nípa Jèhófà pé: “Kò sí apẹ̀yìndà kankan tí yóò wọlé sí iwájú rẹ̀.”—Jóòbù 13:16.
Ọ̀tá náà lè lo ọgbọ́n burúkú míì tó yàtọ̀, èyí tó ti ń ṣiṣẹ́ fún un. Ìwọ rò ó wò ná, tí wọ́n bá lè fẹ̀tàn mú lára ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó ń yan kúrò lórí ìlà láti lọ máa ṣèṣekúṣe, èyí á da ẹgbẹ́ ọmọ ogun náà rú.
Ohun mìíràn tó tún máa ń lò dáadáa ni eré ìnàjú ayé, irú bíi àwọn àwòrán oníwà ìbàjẹ́ orí fídíò àti tẹlifíṣọ̀n àtàwọn orin burúkú. Àwọn kan sọ pé àwọn lè máa wo àwọn àwòrán tàbí ka ìwé oníwà ìbàjẹ́ kó má sì ní ipa búburú kankan lórí àwọn. Ẹni kan tó máa ń wo àwọn àwòrán ìṣekúṣe là á mọ́lẹ̀ pé: “Èèyàn kì í gbàgbé àwọn àwòrán wọ̀nyẹn, bó o ṣe ń ronú tó nípa àwọn àwòrán náà bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe máa ṣe ọ́ bíi pé kó o máa fi àwọn ohun tó o rí ṣèwà hù . . . Àwòrán náà yóò máa mú ọ ronú pé ńṣe lò ń pàdánù àwọn nǹkan kan.” Ṣé ó yẹ kí ẹnì kan lajú ẹ̀ sílẹ̀ káwọn ohun ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́ yìí wá ṣe é léṣe?
Nǹkan mìíràn tí ọ̀tá náà ń lò lára àwọn ohun ìjà rẹ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ ni ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì. Ó máa ń ṣòro láti rí ewu tó wà nínú èyí nítorí pé gbogbo wa pátá la nílò àwọn ohun ìní ti ara. A nílò ilé, oúnjẹ àti aṣọ, kò sì sóhun tó burú nínú kéèyàn ní àwọn nǹkan tó dára. Ibi tí ewu wà ni irú ojú tá a fi ń wò wọ́n. A lè wá ka owó sí pàtàkì ju àwọn nǹkan tẹ̀mí lọ. A lè di olùfẹ́ owó. Nítorí náà, ó yẹ ká máa rántí pé ó níbi tágbára ọrọ̀ mọ. Kì í wà pẹ́ títí, àmọ́ ọrọ̀ tẹ̀mí kì í tán.—Mátíù 6:19, 20.
Bí ara ọmọ ogun kan ò bá yá gágá láti jagun, á nira fún un láti ja àjàṣẹ́gun. “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” (Òwe 24:10) Ìrẹ̀wẹ̀sì jẹ́ ohun kan tí Sátánì máa ń lò dáadáa. Tó o bá ‘gbé ìrètí ìgbàlà wọ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣíborí,’ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣẹ́pá ìrẹ̀wẹ̀sì. (1 Tẹsalóníkà 5:8) Mú kí ìrètí rẹ lágbára bíi ti Ábúráhámù. Nígbà tí Ọlọ́run ní kí Ábúráhámù fi Ísákì, ọmọ kan ṣoṣo tó bí rúbọ, kò lọ́tìkọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó gbà gbọ́ pé Ọlọ́run yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ láti bù kún aráyé nípasẹ̀ àtọmọdọ́mọ òun àti pé Ọlọ́run lè jí Ísákì dìde kúrò nínú ikú láti mú ìlérí náà ṣẹ tí ọ̀ràn náà bá gbà bẹ́ẹ̀.—Hébérù 11:17-19.
Má Ṣe Jáwọ́ Nínú Ìjà Yìí
Àárẹ̀ ti lè máa mú àwọn kan lára àwọn tí wọ́n ti ń fi ìgboyà ja ogun yìí bọ̀ fún ìgbà pípẹ́, nítorí èyí wọ́n lè má máa fi gbogbo ara jà mọ́. Àpẹẹrẹ Ùráyà tá a mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí lè ran gbogbo àwọn tó ń ja ìjà yìí lọ́wọ́ láti máa ní èrò tó dára nípa ogun náà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn Kristẹni tá a jìjọ ń ja ogun yìí ni kò ní àwọn ohun kòṣeémáàní, tó jẹ́ pé inú ewu ni wọ́n wà, tí òtútù àti ebi sì ń pa wọ́n. Bíi ti Ùráyà, ìgbádùn tá a lè ní nísinsìnyí kọ́ la fẹ́ máa ronú nípa rẹ̀ tàbí ká bẹ̀rẹ̀ sí wá bá a ó ṣe gbé ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ. A fẹ́ wà pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà tó wà kárí ayé, àwọn tí wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ jagun, a sì fẹ́ máa ja ogun náà lọ títí dìgbà tí a óò gbádùn àwọn àgbàyanu ìbùkún tá a fi pa mọ́ dè wá.—Hébérù 10:32-34.
Ó léwu láti bọ ìhámọ́ra ogun wa sílẹ̀, bóyá ká máa ronú pé ó ṣì máa pẹ́ gan-an kí ogun àjàkẹ́yìn náà tó wáyé. Àpẹẹrẹ Ọba Dáfídì jẹ́ ká mọ ewu tó wà níbẹ̀. Nítorí àwọn ìdí kan, Dáfídì ò sí lọ́dọ̀ àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lójú ogun. Ohun tó wá yọrí sí ni pé, Dáfídì dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kan tó kó ẹ̀dùn ọkàn àti ìrora bá a títí dọjọ́ ikú rẹ̀.—2 Sámúẹ́lì 12:10-14.
Ǹjẹ́ àǹfààní kankan wà nínú jíja ogun yìí, tàbí nínú dídojúkọ ìnira tó la ogun náà lọ? Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣeni láǹfààní láti máa fara da ẹ̀sín tàbí láti yẹra fún fàájì búburú inú ayé yìí? Àwọn tó ń ja àjàṣẹ́gun nínú ogun yìí lè jẹ́rìí sí i pé àwọn nǹkan ayé lè dà bí ohun tó fani mọ́ra, bí ohun kan tó ń dán yinrin-yinrin lókèèrè àmọ́ tá a sún mọ́ ọn tán, tá a wá ri pé nǹkan pàrùpárù ni. (Fílípì 3:8) Ìyẹn nìkan kọ́ o, ìrora ọkàn àti ìjákulẹ̀ ni irú fàájì bẹ́ẹ̀ sábà máa ń fà.
Àwọn Kristẹni tí wọ́n ń ja ogun tẹ̀mí yìí ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́, wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, wọ́n sì ń retí àwọn nǹkan àgbàyanu. Àwọn Kristẹni tá a fi ẹ̀mí yàn ń retí àìleèkú nínú ìwàláàyè ti ọ̀run pẹ̀lú Kristi Jésù. (1 Kọ́ríńtì 15:54) Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn Kristẹni tó ń ja ìjà yìí ló ń retí àtiwà láàyè gẹ́gẹ́ bí ẹni pípé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Dájúdájú àwọn àǹfààní yìí tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ogun yìí yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n ń jà nínú ayé nítorí ó dájú pé a óò ṣẹ́gun nínú ogun náà níwọ̀n tá a bá sáà ti ń bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́. (Hébérù 11:1) Àmọ́ ṣá o, ìparun ni yóò kẹ́yìn ètò àwọn nǹkan tí Sátánì ń ṣàkóso yìí.—2 Pétérù 3:10.
Bó o ṣe ń ja ìjà yìí, máa rántí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Jòhánù 16:33) Jésù ṣẹ́gun nítorí pé ó wà lójúfò ó sì pa ìṣòtítọ́ rẹ̀ mọ́ nígbà ìdánwò. Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]
A kì í yìnbọn bẹ́ẹ̀ la kì í ju bọ́ǹbù, síbẹ̀ ohun ìjà wa lágbára gan-an
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]
Ó dájú pé a óò ṣẹ́gun nínú ogun náà níwọ̀n tá a bá ṣáà ti ń bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àṣíborí ìgbàlà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣẹ́pá ìrẹ̀wẹ̀sì
Fi apata ńlá ti ìgbàgbọ́ paná “ohun ọṣẹ́ oníná” ti Sátánì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
“Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ó yẹ ká ní ìgbàgbọ́ pé àwọn ìlérí Ọlọ́run yóò ṣẹ