‘Ẹ Wà Lójúfò Kí Ẹ Lè Máa Gbàdúrà’
“Ẹ yè kooro ní èrò inú, kí ẹ sì wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ yín lọ́kàn.”—1 PÉT. 4:7.
1, 2. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká “wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ” wá lọ́kàn? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká fi wádìí ara wa wò tó bá kan ọ̀ràn àdúrà gbígbà?
ỌKÙNRIN kan tó ti ṣiṣẹ́ alẹ́ rí sọ pé: “Béèyàn bá ṣiṣẹ́ lóru, ọwọ́ ìdájí ni ìgbà tó máa ń ṣòro jù láti wà lójúfò.” Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ alẹ́ máa gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Àwọn Kristẹni òde òní dojú kọ ìṣòro kan náà nítorí òru ètò nǹkan búburú Sátánì ti lọ jìnnà, ó ti wà ní ọwọ́ ìdájí báyìí, ìyẹn ìgbà tí nǹkan burú jù lọ láyé. (Róòmù 13: 12) Ó léwu gan-an tá a bá sùn lọ nígbà tí ilẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́ yìí. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká “yè kooro ní èrò inú” ká sì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Ìwé Mímọ́ gbà wá pé ká “wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ” wá lọ́kàn.—1 Pét. 4:7.
2 Nítorí àkókò tá a wà yìí, ó bọ́gbọ́n mu láti bi ara wa pé: ‘Báwo ni mo ṣe wà lójúfò tó tó bá kan ọ̀ràn àdúrà gbígbà? Ǹjẹ́ mo máa ń gba oríṣiríṣi àdúrà, ṣé mo sì máa ń gbàdúrà nígbà gbogbo? Ǹjẹ́ ó ti mọ́ mi lára láti máa gbàdúrà fún àwọn ẹlòmíràn àbí kìkì àwọn ohun tí mo nílò àtèyí tí mo fẹ́ ni àdúrà mi máa ń dá lé? Báwo sì ni ọ̀ràn àdúrà ṣe kan ìgbàlà mi?’
Ẹ MÁA GBA ORÍṢIRÍṢI ÀDÚRÀ
3. Sọ díẹ̀ lára àwọn oríṣi àdúrà tó wà.
3 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Éfésù, ó sọ̀rọ̀ nípa “gbogbo oríṣi àdúrà.” (Éfé. 6:18) Nínú àdúrà wa, a sábà máa ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro wa, kó sì pèsè àwọn ohun tá a nílò. “Olùgbọ́ àdúrà” máa ń fetí sí ẹ̀bẹ̀ wa fún ìrànlọ́wọ́ torí ó nífẹ̀ẹ́ wa. (Sm. 65:2) Àmọ́ a tún ní láti sapá láti máa gba àwọn oríṣi àdúrà míì. Lára wọn ni àdúrà ìyìn, àdúrà ìdúpẹ́ àti ti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa yin Jèhófà nínú àdúrà wa nígbà gbogbo?
4 Ìdí púpọ̀ ló wà tó fi yẹ ká máa sọ̀rọ̀ ìyìn nínú àdúrà wa sí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń fẹ́ láti yìn ín nígbà tá a bá ronú nípa “àwọn iṣẹ́ rẹ̀ alágbára ńlá” àti “ọ̀pọ̀ yanturu títóbi rẹ̀.” (Ka Sáàmù 150:1-6.) Ó jọni lójú pé Sáàmù àádọ́jọ tó ní ẹsẹ mẹ́fà péré gbà wá níyànjú nígbà mẹ́tàlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pé ká máa yin Jèhófà! Onísáàmù mìíràn tún kọrin sí Ọlọ́run pẹ̀lú ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀, ó sọ pé: “Ìgbà méje lóòjọ́ ni mo ń yìn ọ́ nítorí àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ tí ó jẹ́ òdodo.” (Sm. 119:164) Ó dájú pé Jèhófà yẹ fún ìyìn wa. Ǹjẹ́ kò yẹ ká máa yìn ín nínú àdúrà wa ní “ìgbà méje lóòjọ́,” ìyẹn nígbà gbogbo?
5. Báwo ló ṣe jẹ́ ààbò fún wa tá a bá ń fi ẹ̀mí ìmoore hàn nínú àdúrà?
5 Ìdúpẹ́ jẹ́ irú oríṣi àdúrà míì tó ṣe pàtàkì. Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni ní ìlú Fílípì pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.” (Fílí. 4:6) Ààbò ló jẹ́ fún wa tá a bá ń dúpẹ́ oore nínú àdúrà wa sí Jèhófà. Èyí sì ṣe pàtàkì gan-an torí pé àwọn èèyàn ti ya “aláìlọ́pẹ́” ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá a wà yìí. (2 Tím. 3:1, 2) Ẹ̀mí àìmoore ti gbayé kan. Tá ò bá kíyè sára, ẹ̀mí yìí lè ràn wá. Tá a bá ń dúpẹ́ nínú àdúrà wa fún oore tí Ọlọ́run ṣe wá, á mú ká ní ìtẹ́lọ́rùn, kò sì ní jẹ́ ká di ‘oníkùnsínú àti olùráhùn nípa ìpín wa nínú ìgbésí ayé.’ (Júúdà 16) Síwájú sí i, nígbà tí àwọn olórí ìdílé bá ń fi ìdúpẹ́ kún àdúrà tí wọ́n ń gbà pẹ̀lú ìdílé wọn, ńṣe ni wọ́n ń mú kí ìyàwó àtàwọn ọmọ wọn máa ní ẹ̀mí ìmoore tó pọ̀ sí i.
6, 7. Kí ni ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀? Àwọn nǹkan wo la lè rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà nípa wọn?
6 Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ túmọ̀ sí pé kéèyàn fi ìtara gbàdúrà látọkànwá. Àwọn nǹkan wo la lè rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà nípa wọn? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa tàbí tí àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí bá ń bá wa fínra. Ní irú àkókò yẹn, àwọn àdúrà tá a gbà pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ jẹ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀. Ṣùgbọ́n, ṣé àwọn àkókò yìí nìkan la lè rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà?
7 Ronú nípa àdúrà tí Jésù kọ́ wa, kó o sì fiyè sí ohun tó sọ nípa orúkọ Ọlọ́run, Ìjọba Ọlọ́run àti ìfẹ́ Ọlọ́run. (Ka Mátíù 6:9, 10.) Ìwà ibi kún inú ayé yìí, àwọn ìjọba èèyàn sì ń kùnà láti pèsè àwọn ohun tó jẹ́ kòṣeémáàní fún àwọn aráàlú. Dájúdájú, ó yẹ ká máa gbàdúrà pé kí orúkọ Baba wa ọ̀run di mímọ́, kí Ìjọba rẹ̀ sì fòpin sí ìṣàkóso Sátánì lórí ilẹ̀ ayé. Èyí tún jẹ́ àkókò fún wa láti máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kó mú kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká wà lójúfò, ká sì máa gba gbogbo oríṣi àdúrà.
“Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ NÍGBÀ GBOGBO”
8, 9. Kí nìdí tó fi yẹ ká ronú jinlẹ̀ ká tó dá Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòókù lẹ́jọ́ torí pé wọ́n sùn lọ nínú ọgbà Gẹtisémánì?
8 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n “wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ” wọ́n lọ́kàn, ó kéré tán, ìgbà kan wà tí òun alára kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó wà lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó sùn lọ nígbà tí Jésù ń gbàdúrà nínú ọgbà Gẹtisémánì. Kódà, lẹ́yìn tí Jésù sọ fún wọn pé kí wọ́n “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà,” kí wọ́n sì “máa gbàdúrà nígbà gbogbo,” wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀.—Ka Mátíù 26:40-45.
9 Àmọ́ ṣá o, dípò tí a ó fi máa dá Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòókù lẹ́jọ́ pé wọn kò wà lójúfò, ó yẹ ká rántí pé wọ́n ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan lọ́jọ́ yẹn, á sì ti rẹ̀ wọ́n gan-an. Ọjọ́ yẹn ni wọ́n múra sílẹ̀ fún àjọyọ̀ Ìrékọjá, wọ́n sì ṣe é ní alẹ́ ọjọ́ náà. Lẹ́yìn náà ni Jésù dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa bí wọ́n á ṣe máa ṣe Ìrántí ikú rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. (1 Kọ́r. 11:23-25) “Lẹ́yìn kíkọrin ìyìn, wọ́n jáde lọ sí Òkè Ńlá Ólífì,” èyí sì gba pé kí wọ́n rìn gba àwọn ọ̀nà tóóró ìlú Jerúsálẹ́mù. (Mát. 26:30, 36) Ó ṣeé ṣe kí aago méjìlá òru ti kọjá dáadáa nígbà yẹn. Ká ní àwa náà wà ní ọgbà Gẹtisémánì lálẹ́ ọjọ́ yẹn ni, ó ṣeé ṣe ká sùn lọ. Jésù ò dá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tó ti rẹ̀ lẹ́bi, kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ tìfẹ́tìfẹ́ pé, “ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.”
10, 11. (a) Kí ni Pétérù kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i ní ọgbà Gẹtisémánì? (b) Kí lo rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù?
10 Pétérù ò gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Gẹtisémánì. Ọ̀ràn náà dùn ún gan-an, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ kí òun máa wà lójúfò. Ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù sọ fún wọn pé: “Gbogbo yín ni a óò mú kọsẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi ní òru yìí.” Kíá ni Pétérù dáhùn pé: “Bí a bá tilẹ̀ mú gbogbo àwọn yòókù kọsẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ, dájúdájú, a kì yóò mú èmi kọsẹ̀ láé!” Jésù dá Pétérù lóhùn pé ó máa sẹ́ òun nígbà mẹ́tà. Pétérù ò gbà, ó fèsì pé: “Àní bí mo bá ní láti kú pẹ̀lú rẹ pàápàá, dájúdájú, èmi kì yóò sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ lọ́nàkọnà.” (Mát. 26:31-35) Síbẹ̀, Pétérù kọsẹ̀, bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Ó dun Pétérù gan-an pé níkẹyìn, òun sẹ́ Jésù, ó sì “sunkún kíkorò.”—Lúùkù 22:60-62.
11 Pétérù kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i yìí, ó sì borí ìṣòro rẹ̀, ìyẹn bó ṣe máa ń dá ara rẹ̀ lójú jù. Ẹ̀rí fi hàn pé àdúrà ló ran Pétérù lọ́wọ́. Kódà, Pétérù ló gbà wá nímọ̀ràn pé ká máa “wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ” wá lọ́kàn. Ṣé à ń ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí yẹn? Ní àfikún sí i, ṣé à ń “gbàdúrà nígbà gbogbo,” tí a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé? (Sm. 85:8) Bákan náà, ẹ jẹ́ ká máa fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ́kàn, pé: “Kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú.”—1 Kọ́r. 10:12.
ỌLỌ́RUN DÁHÙN ÀDÚRÀ NEHEMÁYÀ
12. Kí nìdí tí Nehemáyà fi jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wá?
12 Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa gbígbàdúrà tọkàntọkàn, Nehemáyà jẹ́ àpẹẹrẹ rere. Òun ni agbọ́tí Atasásítà Ọba Páṣíà ní ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ó ti lo ọ̀pọ̀ ọjọ́ “ní gbígbààwẹ̀ àti ní gbígbàdúrà níwájú Ọlọ́run” nítorí ìyọnu tó bá àwọn Júù ní ìlú Jerúsálẹ́mù. (Neh. 1:4) Nígbà tí Atasásítà béèrè ohun tó fà á tí ojú rẹ̀ fi rẹ̀wẹ̀sì, “lójú-ẹsẹ̀, [Nehemáyà] gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run.” (Neh. 2:2-4) Kí ni àbájáde rẹ̀? Jèhófà dáhùn àwọn àdúrà rẹ̀, ó sì darí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó máa ṣe àwọn èèyàn Rẹ̀ láǹfààní. (Neh. 2:5, 6) Ó dájú pé èyí mú kí ìgbàgbọ́ Nehemáyà túbọ̀ lágbára gan-an!
13, 14. Kí ló yẹ ká ṣe kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára, ká sì dènà àwọn ohun tí Sátánì ń ṣe láti mú wa rẹ̀wẹ̀sì?
13 Tá a bá ń gbàdúrà nígbà gbogbo bíi ti Nehemáyà, èyí á mú kí ìgbàgbọ́ wa máa lágbára. Sátánì ò láàánú, ó sì sábà máa ń gbéjà kò wá nígbà tó bá ti rẹ̀ wá. Bí àpẹẹrẹ, ká ní à ń ṣàìsàn tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé iye wákàtí tá a fi ń wàásù lóṣooṣù kò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run. Ìrònú àwọn kan lára wa lè máa kó ìdààmú bá wọn, bóyá nítorí àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn kọjá. Sátánì fẹ́ ká gbà gbọ́ pé a kò wúlò rárá. Ó sábà máa ń lo ohun tó ń dùn wá lọ́kàn láti sọ ìgbàgbọ́ wa di ahẹrẹpẹ. Àmọ́, tá a bá ń “wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ” wá lọ́kàn, a lè mú kí ìgbàgbọ́ wa máa lágbára. Láìsí àní-àní, ‘apata ńlá ti ìgbàgbọ́ á jẹ́ ká lè paná gbogbo ohun ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú náà.’—Éfé. 6:16.
14 Tá a bá “wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ” wá lọ́kàn, a ò ní dẹra nù, a ò sì ní juwọ́ sílẹ̀ nígbà tí ìdánwò ìgbàgbọ́ bá dé láìròtẹ́lẹ̀. Nígbà tá a bá dojú kọ àwọn àdánwò àtàwọn ìṣòro, ẹ jẹ́ ká máa rántí àpẹẹrẹ Nehemáyà, ká tètè gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn wá lọ́wọ́. Àfi tí Jèhófà bá ràn wá lọ́wọ́ la lè borí àwọn ìdẹwò ká sì fara da àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ tá a bá dojú kọ.
MÁA GBÀDÚRÀ FÚN ÀWỌN ẸLÒMÍÌ
15. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa tó bá di pé ká gbàdúrà nítorí àwọn ẹlòmíì?
15 Jésù rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí àpọ́sítélì Pétérù, kí ìgbàgbọ́ Pétérù má bàa yẹ̀. (Lúùkù 22:32) Epafírásì tó jẹ́ Kristẹni olùṣòtítọ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fara wé ohun tí Jésù ṣe yìí, ó gbàdúrà nítorí àwọn arákùnrin rẹ̀ tó wà ní ìlú Kólósè. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Kólósè, ó sọ pé: “Nígbà gbogbo ni ó ń gbadura kíkankíkan fún yín, pé kí ẹ lè dúró ní pípé àti pé kí ẹ lè kún fún ohun gbogbo tí í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.” (Kól. 4: 12, Ìròyìn Ayọ̀) Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ mo máa ń gbàdúrà kíkankíkan fún àwọn arákùnrin mi tó wà kárí ayé? Nínú àwọn àdúrà mi, ìgbà mélòó ni mo máa ń rántí àwọn onígbàgbọ́ bíi tèmi tí àjálù dé bá? Ìgbà wo ni mo gbàdúrà kíkankíkan fún àwọn tí iṣẹ́ ńlá já lé léjìká nínú ètò Jèhófà gbẹ̀yìn? Lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, ṣé mo gbàdúrà fún àwọn tí ojú ń pọ́n lára àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ?’
16. Ṣé àwọn àdúrà tá a bá ń gbà nítorí àwọn ẹlòmíì tiẹ̀ wúlò? Ṣàlàyé.
16 Àdúrà tá à ń gbà sí Jèhófà Ọlọ́run nítorí àwọn ẹlòmíì lè ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an. (Ka 2 Kọ́ríńtì 1:11.) Dandan kọ́ ni kí Jèhófà ṣe ohun kan nítorí pé ọ̀pọ̀ àwọn olùjọsìn rẹ̀ ló ń gbàdúrà fún ohun náà lemọ́lemọ́, àmọ́ ó máa ń fiyè sí ohun tí wọ́n fẹ́ lápapọ̀, ó sì máa ń rí ìdàníyàn wọn àtọkànwá. Á dáhùn àdúrà wọn tó bá bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Nítorí náà, ó yẹ ká fi ọwọ́ pàtàkì mú àǹfààní àti ojúṣe tá a ní láti gbàdúrà fún àwọn ẹlòmíì. Bíi ti Epafírásì, ó yẹ ká máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa àti pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún nípa gbígbàdúrà kíkankíkan nítorí wọn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, èyí á mú kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i, torí “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
“ÌGBÀLÀ WA SÚN MỌ́LÉ”
17, 18. Kí lá máa rí gbà tá a bá ń “wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ” wá lọ́kàn?
17 Ṣáájú kí Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Òru ti lọ jìnnà; ojúmọ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́,” ó sọ pé: “Ẹ mọ àsìkò, pé wákàtí ti tó nísinsìnyí fún yín láti jí lójú oorun, nítorí ìgbàlà wa sún mọ́lé nísinsìnyí ju ìgbà tí a di onígbàgbọ́.” (Róòmù 13:11, 12) Ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé, ìgbàlà wa sì ti sún mọ́lé ju bá a ṣe rò lọ. A ò gbọ́dọ̀ sùn lọ nípa tẹ̀mí, a kò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ohun ayé tó lè pín ọkàn wa níyà gba àkókò tá a máa fi gbàdúrà ara ẹni sí Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká “wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ” wá lọ́kàn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ ká lè máa lọ́wọ́ nínú àwọn “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run” bá a ṣe ń dúró de ọjọ́ Jèhófà. (2 Pét. 3:11, 12) Bá a ṣe ń lo ìgbésí ayé wa yóò fi hàn pé à ń wà lójúfò nínú ìjọsìn Ọlọ́run àti pé òótọ́ la gbà gbọ́ pé òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí ti sún mọ́lé. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká “máa gbàdúrà láìdabọ̀.” (1 Tẹs. 5:17) Ẹ tún jẹ́ ká máa fara wé Jésù, ká máa wá ibi tí a lè dá wà láti gbàdúrà sí Jèhófà. Tá a bá ń fara balẹ̀ dá gbàdúrà ara ẹni sí Jèhófà, a ó máa túbọ̀ sún mọ́ ọn. (Ják. 4:7, 8) Ẹ wo bí ìbùkún tá a máa rí gbà á ṣe pọ̀ tó!
18 Bíbélì sọ pé: “Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀ nínú ẹran ara, [Kristi] ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti ìtọrọ pẹ̀lú sí Ẹni tí ó lè gbà á là kúrò nínú ikú, pẹ̀lú igbe ẹkún kíkankíkan àti omijé, a sì gbọ́ ọ pẹ̀lú ojú rere nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Héb. 5:7) Jésù ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti ìtọrọ, ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run títí dé òpin ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà, Jèhófà gba Ọmọ rẹ̀ olùfẹ́ ọ̀wọ́n là lọ́wọ́ ikú, ó sì fi àìleèkú san èrè fún un lókè ọ̀run. Àwa náà lè jẹ́ olóòótọ́ sí Baba wa ọ̀run láìka àwọn ìdẹwò àti àdánwò tá a lè rí lọ́jọ́ iwájú sí. Ká sòótọ́, a lè jèrè iyè àìnípẹ̀kun tá a bá ń “wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ” wá lọ́kàn.