ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 9
Jẹ́ Kí Jèhófà Tù Ẹ́ Lára
“Nígbà tí àníyàn bò mí mọ́lẹ̀, o tù mí nínú, o sì tù mí lára.”—SM. 94:19.
ORIN 44 Àdúrà Ẹni Tó Ní Ẹ̀dùn Ọkàn
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ló máa ń fa àníyàn, kí nìyẹn sì lè mú ká máa rò?
ǸJẸ́ o ti kojú ìṣòro tó mú kó o ṣàníyàn rí?b Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun táwọn kan sọ tàbí ohun tí wọ́n ṣe ló mú kó o máa ṣàníyàn. Nígbà míì sì rèé, ó lè jẹ́ ohun tó o sọ tàbí ohun kan tó o ti ṣe sẹ́yìn ló mú kó o máa ṣàníyàn. Bí àpẹẹrẹ, àṣìṣe tó o ti ṣe sẹ́yìn lè mú kó o máa ronú pé bóyá ni Jèhófà lè dárí jì ẹ́. Ibi tọ́rọ̀ tiẹ̀ tún wá burú sí ni pé o lè máa ronú pé torí pé o ò nígbàgbọ́ lo ṣe ń ṣàníyàn tàbí pé o ò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́ ṣé òótọ́ ni?
2. Àwọn àpẹẹrẹ wo látinú Bíbélì ló jẹ́ ká rí i pé tá a bá tiẹ̀ ní ìdààmú ọkàn, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé a ò nígbàgbọ́?
2 Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn àpẹẹrẹ kan látinú Bíbélì. Obìnrin tó nígbàgbọ́ ni Hánà tó wá di ìyá wòlíì Sámúẹ́lì. Àmọ́, nígbà kan orogún rẹ̀ pẹ̀gàn rẹ̀ débi pé ńṣe ló máa ń sunkún, ìyẹn sì mú kó ní ìdààmú ọkàn. (1 Sám. 1:7) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà, ìgbà kan wà tóun náà ní “àníyàn lórí gbogbo ìjọ.” (2 Kọ́r. 11:28) Ọba Dáfídì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára débi pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. (Ìṣe 13:22) Síbẹ̀ Dáfídì ṣe àwọn àṣìṣe tó mú kí ìdààmú ọkàn bá a. (Sm. 38:4) Jèhófà tu àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí nínú, ó sì tù wọ́n lára. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.
OHUN TÁ A LÈ RÍ KỌ́ LÁTINÚ ÀPẸẸRẸ HÁNÀ
3. Báwo lohun tẹ́nì kan sọ ṣe lè mú ká ní ìdààmú ọkàn?
3 Ìdààmú ọkàn lè bá wa nígbà táwọn míì bá sọ̀rọ̀ tó dùn wá tàbí tí wọ́n bá hùwà àìdáa sí wa. Ó lè dùn wá gan-an tó bá jẹ́ pé ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tàbí ìbátan wa kan ló ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí wa. Ìyẹn sì lè mú ká máa ronú pé àjọṣe àárín wa máa bà jẹ́. Nígbà míì, ó lè jẹ́ pé ṣe ni onítọ̀hún sọ̀rọ̀ láìronú bí ìgbà tí wọ́n fi idà gúnni! (Òwe 12:18) Ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé ṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan nìyẹn. Ó sọ pé: “Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, ẹnì kan tí mo kà sí ọ̀rẹ́ mi bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa mi lórí ìkànnì àjọlò. Ohun tó ṣe yẹn dùn mí gan-an, kódà mi ò lè gbé e kúrò lọ́kàn. Ó yà mí lẹ́nu torí mi ò mọ ìdí tó fi ń bà mí jẹ́ kiri.” Tírú nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Hánà.
4. Àwọn ìṣòro wo ni Hánà kojú?
4 Ọ̀pọ̀ ìṣòro ni Hánà kojú. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún ni kò fi rọ́mọ bí. (1 Sám. 1:2) Bẹ́ẹ̀ sì rèé nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ojú ẹni ègún ni wọ́n fi máa ń wo obìnrin tí kò bá rọ́mọ bí. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kó ẹ̀dùn ọkàn àti ìtìjú bá Hánà. (Jẹ́n. 30:1, 2) Ìṣòro yìí tún légbá kan fún Hánà torí pé ọkọ rẹ̀ ní ìyàwó míì tó ń jẹ́ Pẹ̀nínà, ìyẹn sì láwọn ọmọ. Ńṣe ni Pẹ̀nínà ń jowú Hánà, ó sì máa “ń pẹ̀gàn rẹ̀ ṣáá kó lè múnú bí i.” (1 Sám. 1:6) Níbẹ̀rẹ̀, Hánà ò mọ ohun tó lè ṣe sí ìṣòro yẹn, ó sì ń kó ìdààmú ọkàn bá a. Ọ̀rọ̀ yìí dùn ún débi pé “ńṣe ló máa ń sunkún, tí kò sì ní jẹun.” Bíbélì sọ pé “inú Hánà bà jẹ́ gan-an.” (1 Sám. 1:7, 10) Àmọ́ báwo ni Hánà ṣe rí ìtùnú?
5. Báwo ni àdúrà ṣe mú kí ọkàn Hánà balẹ̀?
5 Hánà sọ gbogbo ìṣòro tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá a fún Jèhófà. Lẹ́yìn tó gbàdúrà tán, ó sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀ fún Élì àlùfáà àgbà. Élì wá sọ fún un pé: “Máa lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì fún ọ ní ohun tí o béèrè.” Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára obìnrin náà? Bíbélì ròyìn pé Hánà “bá tirẹ̀ lọ, ó jẹun, kò sì kárí sọ mọ́.” (1 Sám. 1:17, 18) Ó ṣe kedere pé àdúrà tí Hánà gbà yẹn mú kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀.
6. Tó bá dọ̀rọ̀ àdúrà, kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Hánà àtohun tó wà nínú Fílípì 4:6, 7?
6 A máa ní ìbàlẹ̀ ọkàn tá a bá tẹra mọ́ àdúrà gbígbà. Ọ̀pọ̀ àkókò ni Hánà fi gbàdúrà sí Jèhófà Baba rẹ̀ ọ̀run. (1 Sám. 1:12) Àwa náà lè ṣe bíi tiẹ̀ tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà ní gbogbo ìgbà nípa ohun tó ń kó ìdààmú ọkàn bá wa, ohun tó ń bà wá lẹ́rù àtàwọn àṣìṣe wa. Kò dìgbà tá a bá sọ àwọn ọ̀rọ̀ dídùn tàbí tá a to ọ̀rọ̀ wa lẹ́sẹẹsẹ kí Jèhófà tó gbọ́ wa. Nígbà míì, a tiẹ̀ lè sunkún sí Jèhófà lọ́rùn bá a ṣe ń sọ ohun tó ń dùn wá, tá ò sì pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ. Bó ti wù kó rí, Jèhófà kò ní sọ pé ọ̀rọ̀ wa sú òun, kò sì ní ṣàì tẹ́tí sí wa. Láfikún sí pé ká sọ àwọn ìṣòro wa fún Jèhófà, ó tún yẹ ká fi ìmọ̀ràn inú Fílípì 4:6, 7 sọ́kàn tá a bá ń gbàdúrà. (Kà á.) Pọ́ọ̀lù dìídì sọ pé ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, ká sì fi ìmọrírì hàn fún ohun tó ṣe fún wa. Ẹ gbọ́ ná, ṣé ìdí wà láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àbí kò sí? Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ ká máa dúpẹ́ fún àwọn nǹkan tó dá, ká dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ pé ó dá wa, ó ń dá ẹ̀mí wa sí, ó ń fìfẹ́ hàn sí wa, ó sì jẹ́ ká nírètí ìyè àìnípẹ̀kun. Kí lohun míì tá a tún lè rí kọ́ lára Hánà?
7. Kí ni Hánà àti ọkọ rẹ̀ máa ń ṣe déédéé?
7 Láìka àwọn ìṣòro tí Hánà ní, òun àti ọkọ rẹ̀ jọ máa ń lọ síbi ìjọsìn Jèhófà tó wà ní Ṣílò déédéé. (1 Sám. 1:1-5) Àgọ́ ìjọsìn yẹn ni Hánà wà nígbà tí Élì àlùfáà àgbà tù ú nínú, tó sì sọ pé kí Jèhófà dáhùn àdúrà rẹ̀.—1 Sám. 1:9, 17.
8. Àǹfààní wo là ń rí bá a ṣe ń lọ sípàdé? Ṣàlàyé.
8 A máa ní ìbàlẹ̀ ọkàn tá a bá ń lọ sípàdé déédéé. Nínú àdúrà tí wọ́n máa ń gbà níbẹ̀rẹ̀ ìpàdé, wọ́n sábà máa ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ wà pẹ̀lú wa. Àlàáfíà sì jẹ́ apá kan èso ti ẹ̀mí. (Gál. 5:22) Ká tiẹ̀ sọ pé a ní ẹ̀dùn ọkàn, tá a bá lọ sípàdé, Jèhófà àtàwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa gbé wa ró, wọ́n á fún wa níṣìírí, ìyẹn á sì jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀. Torí náà, àdúrà àti ìpàdé wà lára àwọn nǹkan pàtàkì tí Jèhófà fi ń tù wá lára. (Héb. 10:24, 25) Ẹ jẹ́ ká tún wo ohun míì tá a lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Hánà.
9. Kí ni kò yí pa dà nínú ìṣòro tí Hánà ní, àmọ́ kí ló ṣe?
9 Ohun tó fa ẹ̀dùn ọkàn fún Hánà kò yí pa dà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Lẹ́yìn tó pa dà délé láti Ṣílò, inú ilé tí Pẹ̀nínà orogún rẹ̀ ń gbé náà ló pa dà sí. Bíbélì ò sì sọ pé Pẹ̀nínà ti yíwà pa dà. Èyí túmọ̀ sí pé Hánà á ṣì máa fara da àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí orogún rẹ̀ ń sọ sí i. Síbẹ̀, Hánà kò jẹ́ kóhun tí obìnrin náà ń sọ kó ìbànújẹ́ bá òun mọ́. Ẹ rántí pé lẹ́yìn tó ti sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún Jèhófà, kò banú jẹ́ mọ́. Ó gbára lé Jèhófà, ara sì tù ú. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín Jèhófà dáhùn àdúrà Hánà, òun náà sì láwọn ọmọ tiẹ̀!—1 Sám. 1:19, 20; 2:21.
10. Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Hánà?
10 A ṣì lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn tí ìṣòro wa kò bá tiẹ̀ yanjú. A lè gbàdúrà lemọ́lemọ́ ká sì máa lọ sípàdé déédéé, síbẹ̀ káwọn ìṣòro kan má tíì yanjú. Àpẹẹrẹ Hánà jẹ́ ká rí i pé kò sóhun tó lè ní kí Jèhófà má tù wá lára. Òótọ́ kan ni pé Jèhófà kò ní pa wá tì láé, bópẹ́ bóyá á san wá lẹ́san tá ò bá jẹ́ kó sú wa.—Héb. 11:6.
OHUN TÁ A KỌ́ LÁRA ÀPỌ́SÍTÉLÌ PỌ́Ọ̀LÙ
11. Àwọn nǹkan wo ló mú kí Pọ́ọ̀lù máa ṣàníyàn?
11 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló mú kí Pọ́ọ̀lù máa ṣàníyàn. Bí àpẹẹrẹ, ìfẹ́ tó ní fáwọn ará mú kó ṣàníyàn nígbà tó gbọ́ pé wọ́n níṣòro. (2 Kọ́r. 2:4; 11:28) Bákan náà, bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń wàásù, àwọn ìgbà kan wà tí àwọn alátakò lù ú tí wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìgbà míì tún wà tó bára ẹ̀ “nínú àìní,” ìyẹn sì mú kó ṣàníyàn. (Fílí. 4:12) Tá a bá rántí pé ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú omi tó wọ̀ rì, ìyẹn á jẹ́ ká lóye ìdí tó fi lè máa bẹ̀rù nígbà tó bá ń rìnrìn àjò lójú omi. (2 Kọ́r. 11:23-27) Kí ló ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti borí àníyàn?
12. Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe tó mú kí àníyàn rẹ̀ dín kù?
12 Pọ́ọ̀lù ṣàníyàn nígbà táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ̀ wà nínú ìṣòro, àmọ́ kò gbìyànjú láti dá yanjú àwọn ìṣòro náà. Pọ́ọ̀lù mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, ó mọ̀ pé òun ò lè dá ṣe gbogbo nǹkan. Ìyẹn mú kó yan àwọn arákùnrin míì táá ran àwọn ará lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó yanṣẹ́ fún àwọn arákùnrin tó ṣeé fọkàn tán bíi Tímótì àti Títù. Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ táwọn arákùnrin yẹn ṣe dín àníyàn Pọ́ọ̀lù kù.—Fílí. 2:19, 20; Títù 1:1, 4, 5.
13. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fara wé Pọ́ọ̀lù?
13 Jẹ́ káwọn míì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà ló máa ń ṣàníyàn nígbà táwọn ará bá níṣòro. Àmọ́, ó lójú ohun tí alàgbà kan lè dá ṣe. Ìmọ̀wọ̀n ara ẹni máa jẹ́ kó pín iṣẹ́ náà pẹ̀lú àwọn alàgbà míì, ó sì máa dá àwọn ọ̀dọ́kùnrin lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè kúnjú ìwọ̀n láti ran àwọn ará lọ́wọ́.—2 Tím. 2:2.
14. Kí ni Pọ́ọ̀lù kò yọ ara rẹ̀ lẹ́nu lé lórí, kí nìyẹn sì kọ́ wa?
14 Gbà pé ìwọ náà nílò ìtùnú. Pọ́ọ̀lù lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ìyẹn mú kó gbà pé òun nílò ìtùnú, ó sì mọyì ẹ̀ nígbà tí wọ́n tù ú nínú. Kò yọ ara ẹ̀ lẹ́nu pé àwọn kan lè máa fojú tẹ́ńbẹ́lú òun torí pé àwọn míì ran òun lọ́wọ́. Nígbà tó kọ̀wé sí Fílémónì, ó sọ pé: “Nígbà tí mo gbọ́ nípa ìfẹ́ rẹ, inú mi dùn gan-an, ara sì tù mí.” (Fílém. 7) Pọ́ọ̀lù tún dárúkọ àwọn míì tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ tí wọ́n sì ràn án lọ́wọ́ gan-an nígbà ìṣòro. (Kól. 4:7-11) Táwa náà bá jẹ́ káwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa mọ̀ pé a nílò ìṣírí, inú wọn á dùn láti gbé wa ró, wọ́n á sì tì wá lẹ́yìn.
15. Kí ló tu Pọ́ọ̀lù nínú lásìkò tí nǹkan nira fún un?
15 Gbára lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé òun lè rí ìtùnú nínú Ìwé Mímọ́. (Róòmù 15:4) Ó sì tún mọ̀ pé á fún òun ní ọgbọ́n tóun lè fi rán ìṣòro yòówù kó dé bá òun. (2 Tím. 3:15, 16) Nígbà tó wà lẹ́wọ̀n lẹ́ẹ̀kejì nílùú Róòmù, ó mọ̀ pé wọ́n máa tó pa òun. Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe lásìkò tí nǹkan nira gan-an yẹn? Ó ní kí Tímótì tètè wá sọ́dọ̀ òun kó sì bá òun mú “àwọn àkájọ ìwé” bọ̀. (2 Tím. 4:6, 7, 9, 13) Kí nìdí? Ìdí ni pé Pọ́ọ̀lù fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àkájọ ìwé náà torí pé wọ́n jẹ́ apá kan lára Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Táwa náà bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé bíi ti Pọ́ọ̀lù, Jèhófà máa fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tù wá nínú, láìka ìṣòro yòówù kó máa bá wa fínra.
OHUN TÁ A KỌ́ LÁRA ỌBA DÁFÍDÌ
16. Ìṣòro wo ni Dáfídì fọwọ́ ara rẹ̀ fà?
16 Dáfídì ṣe ohun kan tó mú kó máa dá ara ẹ̀ lẹ́bi. Ó bá Bátí-ṣébà ìyàwó oníyàwó sùn, ó ṣètò bí wọ́n ṣe pa ọkọ ẹ̀, ó sì tún gbìyànjú láti bo ìwà burúkú náà mọ́lẹ̀. (2 Sám. 12:9) Níbẹ̀rẹ̀, Dáfídì ṣe bíi pé kò sí nǹkan kan tó ṣẹlẹ̀. Ìyẹn ba àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, ọkàn ẹ̀ ò balẹ̀, kódà ó mú kó ṣàìsàn. (Sm. 32:3, 4) Kí ló mú kí Dáfídì borí ìṣòro tó fọwọ́ ara ẹ̀ fà yẹn, kí ló sì lè ran àwa náà lọ́wọ́ tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì?
17. Báwo lọ̀rọ̀ inú Sáàmù 51:1-4 ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Dáfídì ronú pìwà dà tọkàntọkàn?
17 Bẹ Jèhófà pé kó dárí jì ẹ́. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín Dáfídì gbàdúrà sí Jèhófà. Ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ó sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún Jèhófà. (Ka Sáàmù 51:1-4.) Ẹ ò rí i pé ara máa tù ú gan-an lẹ́yìn tó ṣe bẹ́ẹ̀! (Sm. 32:1, 2, 4, 5) Torí náà, tó o bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, má ṣe bò ó mọ́ra. Kàkà bẹ́ẹ̀, yíjú sí Jèhófà kó o sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ náà fún un. Wàá rí i pé ara máa tù ẹ́, ọkàn ẹ á sì fúyẹ́. Àmọ́ o, tó o bá fẹ́ kí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà túbọ̀ dán mọ́rán, ohun míì wà tó o gbọ́dọ̀ ṣe lẹ́yìn tó o bá gbàdúrà.
18. Kí ni Dáfídì ṣe nígbà tí Jèhófà bá a wí?
18 Jẹ́ kí Jèhófà bá ẹ wí. Nígbà tí Jèhófà rán wòlíì Nátánì sí Dáfídì pé kó sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un, Dáfídì kò wí àwíjàre bẹ́ẹ̀ sì ni kò fojú kéré ẹ̀ṣẹ̀ tó dá. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló gbà pé òun ti ṣẹ ọkọ Bátí-ṣébà, òun sì tún ṣẹ Jèhófà. Dáfídì gbà kí Jèhófà bá òun wí, Jèhófà náà sì dárí jì í. (2 Sám. 12:10-14) Torí náà, tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo tàbí ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, ó yẹ ká sọ fún àwọn tí Jèhófà yàn sípò pé kí wọ́n máa bójú tó wa. (Jém. 5:14, 15) Ká má sì wí àwíjàre tí wọ́n bá ń ràn wá lọ́wọ́. Bó bá ṣe yá wa lára tó láti gba ìbáwí tí wọ́n fún wa, tá a sì ṣe àtúnṣe tó yẹ, bẹ́ẹ̀ lá ṣe rọrùn tó láti pa dà ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn.
19. Ìpinnu wo ló yẹ ká ṣe?
19 Pinnu pé o ò ní tún ẹ̀ṣẹ̀ kan náà dá. Ọba Dáfídì mọ̀ pé tóun ò bá ní dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yẹn mọ́, àfi kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́. (Sm. 51:7, 10, 12) Lẹ́yìn tí Jèhófà ti dárí jì í, Dáfídì pinnu pé òun ò ní fàyè gba èròkerò mọ́. Ìpinnu tó ṣe yẹn sì mú kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀.
20. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ìdáríjì Jèhófà?
20 A lè fi hàn pé a mọyì ìdáríjì Jèhófà tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì wá, tá a gbà pé kó bá wa wí, tá a sì sa gbogbo ipá wa ká má bàa tún ẹ̀ṣẹ̀ náà dá. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ James gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí lẹ́yìn tó dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì tí wọ́n sì bá a wí. Ó sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fáwọn alàgbà, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n gbé ẹrù tó wúwo kan kúrò lọ́rùn mi. Ẹ̀yìn ìyẹn lọkàn mi wá bẹ̀rẹ̀ sí í balẹ̀.” Ẹ wo bó ṣe fini lọ́kàn balẹ̀ tó pé “Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn; ó ń gba àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn là”!—Sm. 34:18.
21. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí Jèhófà tù wá lára?
21 Bí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí ṣe ń parí lọ, ńṣe làwọn ohun tó ń fa àníyàn á máa pọ̀ sí i. Tó o bá ń ṣàníyàn tàbí tó o ní ìdààmú ọkàn, tètè yíjú sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó o sì ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó o kà. Kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí Hánà, Pọ́ọ̀lù àti Dáfídì ṣe nígbà tí wọ́n ní ìdààmú ọkàn. Bẹ Jèhófà Baba rẹ ọ̀run pé kó jẹ́ kó o mọ ohun tó ń kó ẹ lọ́kàn sókè. (Sm. 139:23) Jẹ́ kó bá ẹ gbé ẹrù ìnira rẹ, pàápàá èyí tí agbára rẹ ò ká. Tó o bá ṣe àwọn nǹkan yìí, ìwọ náà á lè sọ bíi ti onísáàmù tó kọrin sí Jèhófà pé: “Nígbà tí àníyàn bò mí mọ́lẹ̀, o tù mí nínú, o sì tù mí lára.”—Sm. 94:19.
ORIN 4 “Jèhófà Ni Olùṣọ́ Àgùntàn Mi”
a Nígbà míì ìṣòro lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mẹ́ta tó kojú àwọn ìṣòro tó mú kí wọ́n ṣàníyàn. A tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe tù wọ́n nínú, tó sì tù wọ́n lára.
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ẹni tó ń ṣàníyàn tàbí tó ní ìdààmú ọkàn sábà máa ń bẹ̀rù tàbí kí àyà ẹ̀ máa já. Àwọn ohun tó lè mú ká ṣàníyàn ni àìlówó lọ́wọ́, àìsàn, ìṣòro ìdílé tàbí àwọn ìṣòro míì. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn tàbí àwọn ìṣòro tá a ronú pé a máa kojú lọ́jọ́ iwájú lè kó wa lọ́kàn sókè.