“Àlàáfíà Ọlọrun Tí ó Ta Gbogbo Ìrònú Yọ”
JÁLẸ̀ ìtàn, àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun ti la àwọn sáà àròdùn ọkàn gbígbóná janjan níti èrò ìmọ̀lára já. Ẹ sì wo bí èyí ṣe jẹ́ òtítọ́ tó lónìí, níwọ̀n bí a ti ń gbé nínú “awọn àkókò lílekoko tí ó nira lati bálò”! (2 Timoteu 3:1, NW) Aposteli Paulu gba àwọn Kristian nímọ̀ràn láti kó àwọn àníyàn wọn lé Jehofa nípasẹ̀ àdúrà. Pẹ̀lú ìyọrísí wo sì ni? “Àlàáfíà Ọlọrun tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yoo sì máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn-àyà yín ati agbára èrò-orí yín nípasẹ̀ Kristi Jesu.”—Filippi 4:7, NW.
Kí ni “àlàáfíà Ọlọrun” yìí? Ó jẹ́ ìparọ́rọ́ kan tí ń wá láti inú níní ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá náà. Irúfẹ́ ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ ń fún wa ní ìgbọ́kànlé pé, láìka àwọn wàhálà wa sí, Jehofa “kì yóò pa àwọn ènìyàn rẹ̀ tì; kì yóò kọ àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ sílẹ̀.”—Orin Dafidi 94:14, Today’s English Version.
Èyí kò túmọ̀ sí pé a ní àjẹsára lòdì sí wàhálà. Onipsalmu náà kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ìpọ́njú olódodo.” (Orin Dafidi 34:19) Ṣùgbọ́n àlàáfíà Ọlọrun lè mú ìtura wá. Báwo?
Àlàáfíà Ọlọrun “ta gbogbo ìrònú yọ,” ni Paulu kọ̀wé—tàbí gẹ́gẹ́ bí a ti túmọ̀ rẹ̀ nínú Concordant Version, ó “ga ju gbogbo ipò èrò-orí lọ.” Àníyàn lè mú kí a ní ìrírí ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírúurú èrò ìmọ̀lára tí ń kó wàhálà báni. (Oniwasu 7:7) Síbẹ̀, àlàáfíà Ọlọrun lè fi ẹsẹ̀ wa múlẹ̀, ní pàtàkì nígbà tí a bá nílò “agbára tí ó rékọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.”—2 Korinti 4:7, NW; 2 Timoteu 1:7.
Síwájú sí i, àlàáfíà Ọlọrun jẹ́ ààbò. Ó lè “ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn-àyà yín ati agbára èrò-orí yín,” gẹ́gẹ́ bí Paulu ti kọ̀wé rẹ̀ sí àwọn ará Filippi. Ọ̀rọ̀ Griki náà tí a túmọ̀ sí “ṣọ́ ẹ̀sọ́” jẹ́ èdè àwọn ológun tí ó ṣeéṣe kí ó múni finú yàwòrán àwọn ológun adènà tí wọ́n ń sọ́ ẹ̀sọ́ ní ọ̀sán àti ní òru. Ní ọ̀nà kan náà, àlàáfíà Ọlọrun lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣọ́ oníwákàtí 24 lórí ọkàn-àyà àti agbára èrò-orí wa.—1 Korinti 10:13; fiwé Efesu 4:26.
Ní ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìpèníjà onípákáǹleke tí a ń dojúkọ lónìí, àlàáfíà Ọlọrun kì í ha ṣe ohun kan tí a níláti ṣọpẹ́ fún bí?—Orin Dafidi 18:2; fiwé Eksodu 40:38.