Ìwọ Lè Rí Ohun Àṣenajú Gbígbámúṣé
BÍBÉLÌ kò dẹ́bi fún fàájì tí a ń gbà nínú ohun àṣenajú, bẹ́ẹ̀ ni kò sì sọ̀rọ̀ nípa ìgbádùn tí a ń rí nínú eré ìtura bí ìfàkókòṣòfò. Ní òdì kejì, Oníwàásù 3:4, NW, sọ pé, “ìgbà rírẹ́rìn-ín” àti “ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri,” wà.a Àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì ìgbàanì gbádùn onírúurú ohun àṣenajú, títí kan orin, ijó, àti àwọn eré àṣedárayá. Jésù fúnra rẹ̀ lọ sí ibi àsè ìgbéyàwó ńlá kan, àti ní àkókò míràn, “àsè ìṣenilálejò gbígbórín.” (Lúùkù 5:29; Jòhánù 2:1, 2) Nítorí náà, Bíbélì kò lòdì sí níní àkókò ìgbádùn.
Bí ó ti wù kí ó rí, níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ lára àwọn ohun àṣenajú lónìí ti ń fògo fún ìwà tí kò mú inú Ọlọ́run dùn, ìbéèrè náà wá ni pé, Kí ni o lè ṣe láti rí i dájú pé àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n rẹ fún yíyan ohun àṣenajú ṣì gbámúṣé?
Máa Ṣàṣàyàn
Ní yíyan ohun àṣenajú wọn, àwọn Kristẹni ní láti jẹ́ kí àwọn ìlànà Bíbélì máa tọ́ wọn sọ́nà. Fún àpẹẹrẹ, onísáàmù náà, Dáfídì, kọ̀wé pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Orin Dáfídì 11:5, NW) Pọ́ọ̀lù sì kọ̀wé sí àwọn ará Kólósè pé: “Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́ ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò . . . Ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn akóni-nírìíra.”—Kólósè 3:5, 8.
Ọ̀pọ̀ ohun àṣenajú tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó lónìí ló ṣe kedere pé wọ́n tẹ ìmọ̀ràn ìwé mímọ́ tí a ṣí payá yìí lójú. Àwọn kan lè jiyàn pé, ‘Àmọ́ n kò jẹ́ dán àwọn ohun tí mo bá rí tí a fi hàn wò.’ Ìyẹn lè rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́, bí ohun àṣenajú rẹ kò bá fi irú ẹni tí ìwọ yóò yà hàn, ó lè fi ohun kan hàn nípa irú ẹni tí o ti jẹ́ ní báyìí. Fún àpẹẹrẹ, ó lè sọ bóyá o wà lára àwọn tí “wọ́n nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá” tàbí tí ‘àgbèrè, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ojúkòkòrò, àti ọ̀rọ̀ rírùn akóni-nírìíra’ gbà lọ́kàn tàbí bóyá o wà lára àwọn tí wọ́n “kórìíra ohun búburú” ní gidi.—Orin Dáfídì 97:10.
Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn ará Fílípì pé: “Ohun yòó wù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòó wù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣepàtàkì, ohun yòó wù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòó wù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòó wù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòó wù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòó wù tí ó bá wà, ohun yòó wù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.”—Fílípì 4:8.
Àmọ́, ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí ha túmọ̀ sí pé gbogbo fíìmù, ìwé, tàbí eré orí tẹlifíṣọ̀n tí apá kan ní í ṣe pẹ̀lú irú ìwà àìṣòdodo kan, bóyá ìwà ọ̀daràn, kò dára lọ́nàkọnà bí? Tàbí ṣé gbogbo eré apanilẹ́rìn-ín ni ó fagi lé nítorí pé wọn kì í ṣe “ti ìdàníyàn ṣíṣepàtàkì”? Rárá, nítorí pé àyíká ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa ohun àṣenajú ni Pọ́ọ̀lù ń jíròrò, àmọ́ nípa ṣíṣàṣàrò nínú ọkàn, tí ó yẹ kí ó dá lórí àwọn ohun tí ó wu Jèhófà. (Orin Dáfídì 19:14) Síbẹ̀síbẹ̀, ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí ó bá di ọ̀ràn yíyan ohun àṣenajú. Ní lílo ìlànà tí a rí nínú Fílípì 4:8, a lè bi ara wa léèrè pé, ‘Irú ohun àṣenajú tí mo yàn ha ń mú kí n máa ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tí kò mọ́ níwà bí?’ Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, nígbà náà, a ní láti ṣàtúnṣe.
Bí ó ti wù kí ó rí, ní pípinnu irú ohun àṣenajú, àwọn Kristẹni ní láti ‘jẹ́ kí ìfòyebánilò wọn di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.’ (Fílípì 4:5) Ó dájú pé àwọn àṣejù wà nínú irú ohun àṣenajú tí ó ṣe kedere pé wọn kò bójú mu fún àwọn Kristẹni tòótọ́. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan gbé ọ̀ràn yẹ̀ wò tìṣọ́ratìṣọ́ra, kí ó sì ṣe àwọn ìpinnu tí yóò mú kí ó ní ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́ níwájú Ọlọ́run àti ènìyàn. (Kọ́ríńtì Kíní 10:31-33; Pétérù Kíní 3:21) Kò ní bójú mu láti ṣèdájọ́ àwọn ẹlòmíràn lórí àwọn ọ̀ràn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tàbí láti gbé àwọn òfin àtọwọ́dá tí ń pinnu ohun tí àwọn ẹlòmíràn gbọ́dọ̀ ṣe kalẹ̀.b—Róòmù 14:4; Kọ́ríńtì Kíní 4:6.
Ipa Ti Àwọn Òbí
Àwọn òbí ń kó ipa pàtàkì nínú ọ̀ràn ohun àṣenajú. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Dájúdájú bí ẹni kan kò bá pèsè fún àwọn wọnnì tí wọ̀n jẹ́ tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, òun ti sẹ́ níní ìgbàgbọ́ ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (Tímótì Kíní 5:8) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn òbí ní iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe láti pèsè fún àwọn mẹ́ńbà ìdílé wọn nípa ti ara, nípa tẹ̀mí àti ti èrò ìmọ̀lára pẹ̀lú. Èyí yóò ní pípèsè àkókò ìdẹ̀ra gbígbámúṣé fún wọn.—Òwe 24:27.
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a máa ń pa ìhà yí tì nínú ìgbésí ayé ìdílé. Míṣọ́nnárì kan ní Nàìjíríà sọ pé: “Ó dunni pé àwọn òbí kan ka eré ìtura sí ìfàkókòṣòfò. Ní àbájáde rẹ̀, a ti fi àwọn ọmọ kan sílẹ̀ láìsí ìtọ́sọ́nà, wọ́n sì ń rí irú àwọn ọ̀rẹ́ àti fàájì tí kò dára.” Ẹ̀yin òbí, ẹ má ṣe jẹ́ kí èyí ṣẹlẹ̀! Ẹ rí i dájú pé àwọn ọmọ yín ní eré ìtura gbígbámúṣé tí ń tù wọ́n lára ní gidi.
Àmọ́, ìṣọ́ra pọn dandan. Kò yẹ kí àwọn Kristẹni dà bí ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí tí wọ́n jẹ́ “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (Tímótì Kejì 3:1-4) Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kí a fi ohun àṣenajú sí àyè rẹ̀. Ó yẹ kí ó jẹ́ atura—kò yẹ kí ó jọba lé ìwàláàyè ẹni. Nítorí náà, kì í ṣe irú ohun àṣenajú tí ó yẹ nìkan ni àwọn ọmọ àti àwọn àgbàlagbà nílò, wọ́n tún nílò ìwọ̀n tí ó yẹ.—Éfésù 5:15, 16.
Gbádùn Àwọn Ìgbòkègbodò Míràn
Ọ̀pọ̀ àwọn ohun àṣenajú lílókìkí ń kọ́ àwọn ènìyàn láti jókòó gẹlẹtẹ dípò gbígbé nǹkan ṣe. Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò tẹlifíṣọ̀n. Ìwé náà, What to Do After You Turn Off the TV, sọ pé: “Bí [tẹlifíṣọ̀n] ṣe rí gan-an ń kọ́ wa láti jókòó gẹlẹtẹ: Ohun àṣenajú, àti kíkẹ́kọ̀ọ́ pàápàá, ń di ohun tí a ń rí gbà láìsapá, kì í ṣe ohun tí a ṣe.” Dájúdájú, àyè wà fún ohun àṣenajú nígbà tí a jókòó gẹlẹtẹ. Àmọ́ bí ó bá ń gba èyí tí ó pọ̀ jù lára àkókò ẹnì kan, ó ń fi àwọn àǹfààní tí ń ru ìmọ̀lára sókè dù ú.
Òǹkọ̀wé Jerry Mander, tí ó sọ pé òun jẹ́ “mẹ́ńbà ìran tí ó wà ṣáájú kí tẹlifíṣọ̀n tó di ohun tí ó wọ́pọ̀,” ṣàpèjúwe àwọn àkókò kọ̀ọ̀kan tí nǹkan máa ń sú u nígbà tí ó wà lọ́mọdé pé: “Hílàhílo máa ń bá a rìn. Lọ́nà pípeléke, kò gbádùn mọ́ni, kò gbádùn mọ́ni gan-an débi pé n óò pinnu láti gbégbèésẹ̀ níkẹyìn—láti ṣe ohun kan. N óò wulẹ̀ tẹ ọ̀rẹ́ kan láago, n óò jáde nílé. N óò lọ gbá bọ́ọ̀lù. N óò kàwé. N óò ṣe ohun kan. Ní ríronú wẹ̀yìn, mo ń wo àkókò tí nǹkan ń sú mi náà, àkókò ‘tí kò sí ohun tí n óò ṣe,’ bíi kòtò tí àwọn ìgbésẹ̀ ìṣẹ̀dá ti yọ wá.” Lónìí, Mander ṣàkíyèsí pé, àwọn ọmọ ń lo tẹlifíṣọ̀n gẹ́gẹ́ bí ojútùú rírọrùn fún kí nǹkan máa súni. Ó wí pé: “Tẹlifíṣọ̀n ń paná hílàhílo àti agbára ìhùmọ̀ tí ó lè tẹ̀ lé e.”
Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ti ṣàwárí pé àwọn ìgbòkègbodò tí ó nílò ṣíṣe nǹkan dípò wíwulẹ̀ jókòó gẹlẹtẹ lásán lè túbọ̀ mú ìtẹ́lọ́rùn wá ju bí wọ́n ṣe finú wòye lọ. Àwọn kan ti ṣàwárí pé kíkàwé sókè pẹ̀lú àwọn mìíràn jẹ́ orísun ìgbádùn. Àwọn mìíràn ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò àfipawọ́, bíi fífi ohun èlò ìkọrin kan kọrin tàbí kíkun àwòrán kan. Lẹ́yìn náà, àwọn àǹfààní tún wà láti ṣètò fún àpéjọ gbígbámúṣé.c (Lúùkù 14:12-14) Eré ìtura tí a ṣe níta pẹ̀lú ní àwọn àǹfààní. Aṣojúkọ̀ròyìn Jí! kan ní Sweden ròyìn pé: “Àwọn ìdílé kan máa ń lọ pàgọ́ tàbí kí wọ́n lọ pẹja, tàbí rìnrìn àjò ráńpẹ́ lọ sínú igbó, ìrìn àjò nínú ọkọ̀ àjẹ̀, rírìn láàárín àwọn òkè ńlá, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Inú àwọn ọmọdé ń dùn.”
Kò yẹ kí ó yà wá lẹ́nu pé àwọn ohun tí ń sọni dìbàjẹ́ wà nínú ohun àṣenajú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé, àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè “ń rìn nínú àìlérè èrò inú wọn.” (Éfésù 4:17) Nítorí náà, a wulẹ̀ ní láti retí pé púpọ̀ lára àwọn ohun tí wọ́n rí bí èyí tí ń pèsè ìnàjú ni yóò jẹ́ “àwọn iṣẹ́ ti ẹran ara.” (Gálátíà 5:19-21) Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Kristẹni lè kọ́ ara wọn láti ṣe ìpinnu yíyè kooro nípa bí ohun àṣenajú wọn ṣe jẹ́ ojúlówó tó àti bí wọ́n ṣe ń lò wọ́n tó. Wọ́n tún lè mú kí eré ìtura jẹ́ èyí tí ìdílé wéwèé, tí wọ́n sì ṣe pọ̀, wọ́n tilẹ̀ lè gbìyànjú àwọn ìgbòkègbodò tuntun tí yóò tura, tí yóò sì mú kí wọn máa rántí tẹ̀ríntẹ̀rín fún ọ̀pọ̀ ọdún. Bẹ́ẹ̀ ni, o lè rí ohun àṣenajú gbígbámúṣé!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn irú ọ̀rọ̀ Hébérù míràn tí a túmọ̀ sí “láti rẹ́rìn-ín” ni a lè pè ní “láti ṣeré,” “láti dáni lára yá,” “láti ṣayẹyẹ,” tàbí “láti ṣe fàájì.”
b Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo Jí!, ìtẹ̀jáde March 22, 1978 (Gẹ̀ẹ́sì), ojú ìwé 16 sí 21, àti December 8, 1995, ojú ìwé 6 sí 8.
c Fún ìtọ́sọ́nà Ìwé Mímọ́ lórí àwọn ìkórajọ-ṣefàájì, wo Ilé-Ìṣọ́nà, August 15, 1992, ojú ìwé 15 sí 20, àti ti October 1, 1996, ojú ìwé 18 àti 19.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Eré ìtura gbígbámúṣé lè mú ìtẹ́lọ́rùn wá