Ẹ Máa Yọ̀ Ninu Jehofa!
“Ẹ máa yọ̀ ninu Oluwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí, Ẹ máa yọ̀.”—FILIPPI 4:4.
1. Èéṣe tí a fi lè ṣe kàyéfì nipa ohun tí Paulu ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ pé awọn Kristian níláti máa yọ̀ nígbà gbogbo?
LÓDE ìwòyí, ìdí fún yíyọ̀ lè dàbí èyí tí ó ṣọ̀wọ́n gidigidi. Awọn ẹni erùpẹ̀, àní awọn ojúlówó Kristian pàápàá, ń dojúkọ awọn ipò tí ń fa ìkárísọ—àìníṣẹ́lọ́wọ́, àìlera, ikú olùfẹ́ ẹni, ìṣòro ara-ẹni, tabi ìṣàtakò lati ọ̀dọ̀ awọn mẹ́ḿbà ìdílé tabi awọn ọ̀rẹ́ àtijọ́ tí wọn jẹ́ aláìgbàgbọ́. Nitori naa bawo ni a ṣe lè lóye ìṣílétí Paulu pé, ‘Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo’? Lójú ìwòye awọn àyíká ipò tí kò dùnmọ́ni tí wọ́n sì ń pinnilẹ́mìí tí gbogbo wa gbọ́dọ̀ bá wọ̀jà, èyí ha tilẹ̀ ṣeéṣe bí? Ìjíròrò àyíká ọ̀rọ̀ awọn ọ̀rọ̀ wọnyi yoo ṣèrànwọ́ lati mú ọ̀ràn naa ṣe kedere.
Ẹ Máa Yọ̀—Èéṣe, Bawo Sì Ni?
2, 3. Kí ni ìjẹ́pàtàkì ìdùnnú, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkàwé rẹ̀ ninu ọ̀ràn ti Jesu ati awọn ọmọ Israeli ìgbàanì?
2 “Ẹ máa yọ̀ ninu Oluwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí, Ẹ máa yọ̀.” Èyí lè rán wa létí awọn ọ̀rọ̀ tí a darí sí awọn ọmọ Israeli ní nǹkan bí ọ̀rúndún 24 sẹ́yìn pé: “Ayọ̀ Oluwa oun ni agbára yin,” tabi gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ ti Moffatt: “Lati yọ̀ ninu ẹni Ayérayé ni okun yin.” (Nehemiah 8:10) Ìdùnnú ń pèsè okun ó sì dàbí odi agbára kan ninu èyí tí ẹnìkan lè sá sí fún ìtùnú ati ààbò. Ìdùnnú wúlò ni ṣíṣèrànwọ́ fún ọkùnrin pípé naa Jesu lati forítì í. “Nitori ayọ̀ tí a gbéka iwájú rẹ̀, tí ó farada [òpó igi oró, NW] láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun.” (Heberu 12:2) Ní kedere, lati jẹ́ ẹni tí ó lè máa yọ̀ lójú awọn ipò lílekoko ṣe kókó fún ìgbàlà.
3 Ṣáájú wíwọ Ilẹ̀ Ìlérí, a ti pàṣẹ fún awọn ọmọ Israeli pé: “Kí iwọ kí ó sì máa yọ̀ ninu ohun rere gbogbo, tí OLUWA Ọlọrun rẹ fi fún ọ, ati fún ará ilé rẹ, iwọ, ati ọmọ Lefi, ati àlejò tí ń bẹ láàárín rẹ.” Àbájáde kíkùnà lati fi ayọ̀ ṣiṣẹ́sin Jehofa yoo múná. “Gbogbo ègún wọnyi yoo sì wá sórí rẹ, yoo sì lépa rẹ, yoo sì bá ọ, títí iwọ óò fi run; . . . nitori tí iwọ kò fi ayọ̀ sin OLUWA Ọlọrun rẹ, ati inúdídùn, nitori ọ̀pọ̀ ohun gbogbo.”—Deuteronomi 26:11; 28:45-47.
4. Èéṣe tí a fi lè kùnà lati yọ̀?
4 Nitori naa, ó jẹ́ kánjúkánjú pé kí àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró ti òde-òní ati “awọn àgùtàn mìíràn” alábàákẹ́gbẹ́ wọn máa yọ̀! (Johannu 10:16) Paulu tẹnumọ́ ìjẹ́pàtàkì yíyọ̀ lórí gbogbo ohun rere tí Jehofa ti ṣe fún wa, nipa títún ìmọ̀ràn rẹ̀ sọ pé, “mo sì tún wí.” Awa ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Àbí a ti ri ara wa bọ ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ ninu ìgbésí-ayé tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí a fi ń gbàgbé awọn ìdí pupọ tí a ní lati máa yọ̀ bí? Awọn ìṣòro ha ń ga pelemọ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn fi ń dí wa lójú lati rí Ìjọba naa ati awọn ìbùkún rẹ̀ bí? A ha ń fàyègba awọn nǹkan mìíràn—ṣíṣàìgbọràn sí òfin Ọlọrun, ṣíṣàìfiyèsí awọn ìlànà àtọ̀runwá, tabi ṣíṣàìnáání awọn ẹrù-iṣẹ́ Kristian—lati já ayọ̀ wa gbà bí?
5. Èéṣe tí ó fi lè ṣòro fún ẹnìkan tí kò ní ìfòyebánilò lati máa yọ̀?
5 “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn. Oluwa ń bẹ nítòsí.” (Filippi 4:5, NW) Ẹnìkan tí kò ní ìfòyebánilò kìí wàdéédéé. Ó lè kùnà lati bójútó ìlera rẹ̀ dáradára, ní jíjọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún pákáǹleke tabi àníyàn tí kò nídìí. Boya kò tíì kọ́ lati mọ ibi tí agbára rẹ̀ mọ kí ó sì máa gbé ní ìbámu bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Ó lè gbé góńgó tí ó ga jù ka iwájú araarẹ̀ kí ó sì máa gbìyànjú lati lé wọn bá láìka iye tí ó lè ná an sí. Tabi kí ó lo ibi tí agbára rẹ̀ mọ gẹ́gẹ́ bí àwáwí fún dídẹ̀rìn tabi dídẹwọ́. Níwọ̀n bí kò ti wàdéédéé tí kò sì ní ìfòyebánilò, ó ṣòro fún un lati yọ̀.
6. (a) Kí ni awọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa níláti rí lára wa, kìkì nígbà wo sì ni èyí lè rí bẹ́ẹ̀? (b) Bawo ni awọn ọ̀rọ̀ Paulu ní 2 Korinti 1:24 ati Romu 14:4 ṣe ṣèrànwọ́ fún wa lati jẹ́ afòyebánilò?
6 Àní bí awọn alátakò bá tilẹ̀ ń wò wá bí agbawèrèmẹ́sìn, ó yẹ kí awọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa lè máa rí ìfòyebánilò wa nígbà gbogbo. Wọn yoo sì ṣe bẹ́ẹ̀ bí a bá wàdéédéé tí a kò sì retí ìjẹ́pípé yálà lati ọ̀dọ̀ araawa tabi lati ọ̀dọ̀ awọn ẹlòmíràn. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a gbọ́dọ̀ fàsẹ́yìn ninu gbígbé ẹrù-ìnira tí ó rékọjá ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun béèrè fún ka awọn ẹlòmíràn lórí. Aposteli Paulu sọ pé: “Kìí ṣe nitori tí awa jẹgàba lórí ìgbàgbọ́ yin, ṣugbọn awa jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ayọ̀ yin.” (2 Korinti 1:24) Gẹ́gẹ́ bí Farisi tẹ́lẹ̀rí, Paulu mọ̀ dáradára pé awọn ìlànà aláìṣeéyípadà tí awọn tí ń bẹ ní ipò ọlá-àṣẹ là sílẹ̀ tí wọn sì gbé kani lórí ń fún ayọ̀ pa, nígbà tí ó jẹ́ pé awọn ìdámọ̀ràn tí ń rannilọ́wọ́ tí awọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni ń fúnni ń mú un pọ̀ sí i. Òtítọ́ naa pé “Oluwa ń bẹ nítòsí” níláti rán ẹni tí ń fòyebánilò létí pé kìí ṣe tiwa lati “dá ọmọ-ọ̀dọ̀ ẹlòmíì lẹ́jọ́? lójú oluwa rẹ̀ ni ó dúró, tabi tí ó ṣubú.”—Romu 14:4.
7, 8. Èéṣe tí awọn Kristian fi lè retí lati ní ìṣòro, síbẹ̀ bawo ni ó ṣe lè ṣeéṣe fún wọn lati máa báa nìṣó ní yíyọ̀?
7 “Ẹ máṣe àníyàn ohunkóhun; ṣugbọn ninu ohun gbogbo, nipa àdúrà ati ẹ̀bẹ̀ pẹlu ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọrun.” (Filippi 4:6) Awa ń nírìírí “awọn àkókò lílekoko tí ó nira lati bálò” èyí tí Paulu kọ̀wé nipa rẹ̀. (2 Timoteu 3:1-5, NW) Nitori naa awọn Kristian gbọ́dọ̀ retí lati dojúkọ ìṣòro. Ọ̀rọ̀ Paulu naa ‘ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo’ kò fagilé ṣíṣeéṣe naa pé Kristian olùṣòtítọ́ kan lè kún fún àìnírètí ati ìrẹ̀wẹ̀sì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ninu ọ̀ràn ti Paulu, ó gbà níti tòótọ́ pé: “A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣugbọn ara kò ni wá: a ń dààmú wa, ṣugbọn a kò sọ ìrètí nù. A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣugbọn a kò kọ̀ wá sílẹ̀; a ń rẹ̀ wá sílẹ̀, ṣugbọn a kò sì pa wá run.” (2 Korinti 4:8, 9) Bí ó ti wù kí ó rí, ìdùnnú Kristian máa ń borí awọn sáà díẹ̀ ti àníyàn ati ìsoríkọ́ tí ó sì máa ń mú wọn fúyẹ́. Ó ń fúnni lókun tí a nílò lati máa tẹ̀síwájú, kí a máṣe gbàgbé awọn ìdí púpọ̀ tí a ní lati yọ̀.
8 Nígbà tí awọn ìṣòro bá dìde, ohun yòówù tí wọn lè jẹ́, Kristian onídùnnú ń fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ bẹ Jehofa fún ìrànwọ́ nípasẹ̀ àdúrà. Oun kìí juwọ́sílẹ̀ fún àníyàn lílékenkà. Lẹ́yìn ṣíṣe ohun tí oun fúnraarẹ̀ lè fòye ṣe lati yanjú ìṣòro naa, ó ń fi ìyọrísí rẹ̀ lé Jehofa lọ́wọ́ ní ìbámu pẹlu ìkésíni naa pé: “Kó ẹrù rẹ lọ sí ara Oluwa, oun ni yoo sì mú ọ dúró.” Ní àkókò yii, Kristian naa ń báa nìṣó lati máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa fún gbogbo oore Rẹ̀.—Orin Dafidi 55:22; tún wo Matteu 6:25-34.
9. Bawo ni ìmọ̀ òtítọ́ ṣe ń mú àlàáfíà èrò-inú wá, ìyọrísí dídára wo sì ni èyí lè ní lórí Kristian kan?
9 “Àlàáfíà Ọlọrun, tí ó ju ìmọ̀ràn gbogbo lọ, yoo ṣọ́ ọkàn ati èrò yín ninu Kristi Jesu.” (Filippi 4:7) Ìmọ̀ nipa òtítọ́ Bibeli ń sọ èrò-inú Kristian naa di òmìnira kúrò ninu èké ó sì ń ṣèrànwọ́ fún un lati mú ọ̀nà ìrònú afúnninílera dàgbà. (2 Timoteu 1:13) Nipa bẹ́ẹ̀ a ń ràn án lọ́wọ́ lati yẹra fún ìwà tí kò lọ́gbọ́n ninu tabi tí ó lòdì èyí tí ó lè jin ipò-ìbátan alálàáfíà wa pẹlu awọn ẹlòmíràn lẹ́sẹ̀. Dípò dídi ẹni tí àìṣèdájọ́-òdodo ati ìwà-ibi mú nímọ̀lára ìmújákulẹ̀, oun fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sínú Jehofa lati yanjú awọn ìṣòro aráyé nípasẹ̀ Ìjọba naa. Irú àlàáfíà èrò-inú bẹ́ẹ̀ ń ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ̀, ó ń mú kí ète ìsúnniṣe rẹ̀ mọ́gaara, ó sì ń pa ìrònú rẹ̀ mọ́ ní ọ̀nà òdodo. Ète ìsúnniṣe mímọ́gaara ati ìrònú títọ̀nà, ní àbárèbábọ̀, ń pèsè awọn ìdí jáǹtìrẹrẹ fún yíyọ̀, láìka awọn ìṣòro ati ìkìmọ́lẹ̀ tí ayé rúdurùdu ti mú wá.
10. Kí ni a lè máa sọ̀rọ̀ tabi ronú lé lórí tí a fi lè nírìírí ìdùnnú tòótọ́?
10 “Ní àkótán, ará, ohunkóhun tíí ṣe òótọ́, ohunkóhun tíí ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tíí ṣe títọ́, ohunkóhun tíí ṣe mímọ́, ohunkóhun tíí ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ní ìròyìn rere; bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọnyi rò.” (Filippi 4:8) Kristian kan kìí rí adùn ninu sísọ̀rọ̀ tabi ríronú nipa ohun búburú. Gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ èyí ń fagilé pupọ lára awọn eré-ìnàjú tí ayé ń pèsè. Kò sí ẹni tí ó lè di ìdùnnú Kristian rẹ̀ mú bí ó bá ń fi irọ́, ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn akóninírìíra, ati awọn ọ̀ràn àìṣòdodo, àìmọ́, tí kò bá ìwàrere mú, tí ó kún fún ìkórìíra, ati ìṣe-họ́ọ̀-sí kún èrò-inú ati ọkàn-àyà rẹ̀. Kí a kúkú sọjú abẹ níkòó, kò sí ẹni tí ó lè rí ìdùnnú tòótọ́ nipa fífi ìwà ẹ̀gbin kún inú èrò-inú ati ọkàn-àyà rẹ̀. Ninu ayé dídíbàjẹ́ tí ó jẹ́ ti Satani, ẹ wo bí ó ti ń gbéniró tó lati mọ̀ pé awọn Kristian ní ọ̀pọ̀ ohun rere lati ronú lé lórí ati lati jíròrò!
Ìdí Jáǹtìrẹrẹ fún Yíyọ̀
11. (a) Kí ni a kò níláti fọwọ́ yẹpẹrẹ mú láé, èésìtiṣe tí kò fi gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀? (b) Ipa wo ni lílọ sí àpéjọpọ̀ àgbáyé kan ní lórí àyànṣaṣojú kan ati aya rẹ̀?
11 Nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nipa awọn ìdí fún yíyọ̀, ẹ máṣe jẹ́ kí á gbàgbé ẹgbẹ́-awọn-ará wa kárí-ayé. (1 Peteru 2:17) Nígbà tí ẹgbẹ́ àwùjọ ti orílẹ̀-èdè ati ti ẹ̀yà ayé ń fi ìkórìíra gbígbóná janjan hàn sí èkínní kejì, awọn ènìyàn Ọlọrun túbọ̀ ń súnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí ninu ìfẹ́. Ní pàtàkì ìṣọ̀kan wọn ni a ń rí ní kedere ní awọn àpéjọpọ̀ àgbáyé. Àyànṣaṣojú kan lati United States kọ̀wé nipa ọ̀kan tí a ṣe ní 1993 ní Kiev, Ukraine, pé: “Omijé ìdùnnú, ojú tí ó kún fún ayọ̀, ìfọwọ́gbánimọ́ra léraléra gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, ati awọn ìkíni tí a ń fi ráńṣẹ́ lati ẹ̀gbẹ́ kan dé ẹ̀gbẹ́ kejì pápá ìṣeré naa nípasẹ̀ awọn agbòòrùn ati aṣọ ìnujú aláràbarà tí àwùjọ naa ń jù yẹbẹyẹbẹ, jẹ́ ẹ̀rí ìṣọ̀kan ìṣàkóso Ọlọrun lọ́nà tí ó ṣe kedere. Ọkàn-àyà wa kún fún ayọ̀ fún ohun tí Jehofa ti ṣe àṣepé rẹ̀ lọ́nà ìyanu ninu ẹgbẹ́-àwọn-ará kárí-ayé. Èyí ti wọ emi ati aya mi lọ́kàn ṣinṣin ó sì ti fi ìtumọ̀ titun kún ìgbàgbọ́ wa.”
12. Bawo ni Isaiah 60:22 ṣe ń ní ìmúṣẹ ní ojú wa kòrókòró?
12 Ẹ wo bí ó ṣe jẹ́ afúngbàgbọ́ lókun tó lónìí fún awọn Kristian lati rí awọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli tí ń ní ìmúṣẹ lójú wọn kòrókòró! Fún àpẹẹrẹ, gbé awọn ọ̀rọ̀ Isaiah 60:22 yẹ̀wò: “Ẹni-kékeré kan ni yoo di ẹgbẹ̀rún, ati kékeré kan di alágbára orílẹ̀-èdè: èmi Oluwa yoo ṣe é kánkán ní àkókò rẹ̀.” Nígbà ìbí Ìjọba naa ní 1914, kìkì 5,100—ẹni-kékeré kan—ní wọ́n ń fi aápọn wàásù. Ṣugbọn ní awọn ọdún márùn-ún tí ó ti kọjá, iye ẹgbẹ́-àwọn-ara kárí-ayé ti ń fi ìpíndọ́gba 5,628 awọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi gbèrú síi lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀! Ní 1993, a dé góńgó 4,709,889 awọn òjíṣẹ́ aláápọn. Ìyẹn mà kọyọyọ o! Èyí túmọ̀sí pé “ẹni-kékeré kan” ní 1914 tí fẹ́rẹ̀ẹ́ di “ẹgbẹ̀rún” níti gidi!
13. (a) Kí ni ó ti ń ṣẹlẹ̀ lati 1914 wá? (b) Bawo ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe ń pa ìlànà tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ Paulu ní 2 Korinti 9:7 mọ́?
13 Lati 1914 Ọba Messia naa ti jáde lọ ní jíjọba láàárín awọn ọ̀tá rẹ̀. Awọn ènìyàn ọlọ́kàn ìmúratán tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn tí wọ́n ti fi àkókò, okun, ati owó ṣètọrẹ lati máa bá iṣẹ́ ìwàásù kárí-ayé naa nìṣó pẹlu ìgbétáásì iṣẹ́ ìkọ́lé káàkiri ayé ti ń ti ìṣàkóso naa lẹ́yìn. (Orin Dafidi 110:2, 3) Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yọ̀ pé wọn ti ṣe ìtọrẹ owo lati mú awọn ìgbòkègbodò wọnyi wá sí ìparí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé agbára káká ni a fi ń mẹ́nukan owó ní awọn ìpàdé wọn.a (Fiwé 1 Kronika 29:9.) A kò níláti gbún awọn Kristian tòótọ́ ní kẹ́ṣẹ́ kí wọn tó ṣètọrẹ; wọn kà á sí àǹfààní kan lati ti Ọba wọn lẹ́yìn títí dé ìwọn tí àyíká ipò wọn bá yọ̀ọ̀da, olúkúlùkù “gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọkàn rẹ̀; kìí ṣe àfèkunṣe, tabi tí aláìgbọdọ̀ má ṣe.”—2 Korinti 9:7.
14. Ipò wo láàárín awọn ènìyàn Ọlọrun ni ó ti farahàn kedere lati 1919 wá, ìdí wo ni ó sì fún wọn lati máa yọ̀?
14 Ìmúpadàbọ̀sípò ìjọsìn tòótọ́ tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láàárín awọn ènìyàn Ọlọrun ti yọrísí dídá paradise tẹ̀mí sílẹ̀. Lati 1919 ó ti mú kí awọn ìpínlẹ̀ rẹ̀ gbòòrò síi lọ́nà tí ń tẹ̀síwájú. (Orin Dafidi 14:7; Isaiah 52:9, 10) Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Awọn Kristian tòótọ́ ń nírìírí “inúdídùn ati ayọ̀.” (Isaiah 51:11) Awọn ìṣùpọ̀-èso dídára tí ó yọrísí jẹ́ ẹ̀rí ohun tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun tóótun lati ṣàṣeparí nípasẹ̀ awọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé. Gbogbo ìyìn ati ọlá lọ sọ́dọ̀ Jehofa, ṣugbọn àǹfààní títóbi jù wo ni a tún lè ní ju dídi alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun? (1 Korinti 3:9) Jehofa lágbára tó lati mú kí awọn òkúta lọgun ìhìn-iṣẹ́ òtítọ́ naa, bí ó bá pọndandan bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, oun ti yàn lati máṣe lo ọ̀nà yẹn ṣugbọn, kàkà bẹ́ẹ̀, lati sún awọn ẹ̀dá erùpẹ̀ tí wọn bá múratán ṣiṣẹ́ lati mú ìfẹ́-inú rẹ̀ ṣẹ.—Luku 19:40.
15. (a) Awọn ìṣẹ̀lẹ̀ òde-òní wo ní a ń fọkàn bálọ? (b) Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni a ń fayọ̀ wọ̀nà fún?
15 Bí wọ́n ti kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀, awọn ìránṣẹ́ Jehofa ń wo ìṣẹ̀lẹ̀ ayé bayii bí iwọnyi ti tanmọ́ awọn àsọtẹ́lẹ̀ títayọlọ́lá ninu Bibeli. Awọn orílẹ̀-èdè ń sapá gidigidi—ṣugbọn lórí asán—ninu ìgbìyànjú lati mú kí ọwọ́ wọ́n tẹ àlàáfíà fífẹsẹ̀múlẹ̀. Awọn ìṣẹ̀lẹ̀ ń fipá mú wọn lati késí ètò-àjọ Ìparapọ̀ Awọn Orílẹ̀-Èdè lati ṣalàgàta ní awọn ibi tí ìjọ̀ngbọ̀n ti ń ṣẹlẹ̀ lágbàáyé. (Ìfihàn 13:15-17) Ní bayii, awọn ènìyàn Ọlọrun ti ń fi ìháragàgà wọ̀nà fún ọ̀kan lára awọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń mú ìdùnnú wá jùlọ tí ó tíì ṣẹlẹ̀ rí, ọ̀kan tí ń súnmọ́lé síi lójoojúmọ́. “Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi, kí a sì fi ògo fún un: nitori pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùtàn dé, aya rẹ̀ sì ti múratán.”—Ìfihàn 19:7.
Wíwàásù—Ẹrù-Ìnira Tabi Ìdùnnú?
16. Ṣàlàyé bí kíkùnà lati ṣe ohun tí Kristian kan ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣe lè já ìdùnnú rẹ̀ gbà.
16 “Nǹkan wọnnì, tí ẹ̀yin ti kọ́, tí ẹ̀yin sì ti gbà, tí ẹ̀yin sì ti gbọ́, tí ẹyin sì ti rí lọ́wọ́ mi, ẹ máa ṣe wọn: Ọlọrun àlàáfíà yoo sì wà pẹlu yín.” (Filippi 4:9) Nipa ṣíṣe ohun tí wọn ti kọ́, awọn Kristian lè retí lati gba ìbùkún Ọlọrun. Ọ̀kan lára awọn ohun ṣíṣe pàtàkì jùlọ tí wọn ti kọ́ ni bí wíwàásù ìhìnrere naa fún awọn ẹlòmíràn ṣe pọndandan tó. Nítòótọ́, ta ni ó lè gbádùn àlàáfíà èrò-inú tabi kí inú rẹ̀ dùn bí ó bá fawọ́ ìsọfúnni sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ awọn aláìlábòsí-ọkàn tí ìgbésí-ayé wọn gan-an sinmi lé gbígbọ́ ọ?—Esekieli 3:17-21; 1 Korinti 9:16; 1 Timoteu 4:16.
17. Èéṣe tí ìgbòkègbodò ìwàásù wa fi níláti máa jẹ́ orísun ìdùnnú nígbà gbogbo?
17 Ẹ wo bí ó ti dùnmọ́ni tó lati rí awọn ẹni-bí-àgùtàn tí wọn múratán lati kẹ́kọ̀ọ́ nipa Jehofa! Nítòótọ́, awọn wọnnì tí wọn ń ṣiṣẹ́sìn pẹlu ète ìsúnniṣe títọ̀nà yoo máa ri iṣẹ́-ìsìn Ìjọba gẹ́gẹ́ bí orísun ìdùnnú nígbà gbogbo. Èyí jẹ́ nitori pé ìdí pàtàkì fún jíjẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jehofa ni lati yin orúkọ Rẹ̀ ati lati gbé ipò Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olùṣàkóso Ọba-Aláṣẹ ga. (1 Kronika 16:31) Ẹni tí ó bá mọ òtítọ́ yii yoo yọ̀ àní nígbà tí awọn ènìyàn ba fí àìlọ́gbọ́n kọ ìhìnrere naa tí ó múwá pàápàá. Ó mọ̀ pé wíwàásù fún awọn aláìgbàgbọ́ yoo dópin lọ́jọ́ kan; yíyin orúkọ Jehofa yoo sì máa wà nìṣó títí láé.
18. Kí ni ń sún Kristian kan lati ṣe ìfẹ́-inú Jehofa?
18 Ìsìn tòótọ́ ń sún awọn wọnnì tí ń ṣe é lati ṣe ohun tí Jehofa béèrè fún, kìí ṣe nitori pé wọn níláti ṣe é, ṣugbọn nitori pé wọn fẹ́ lati ṣe é. (Orin Dafidi 40:8; Johannu 4:34) Ó ṣòro fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ lati lóye èyí. Adélébọ̀ kan ti sọ fún Ẹlẹ́rìí kan tí ó kàn sí i rí pé: “Ṣé o rí i, mo níláti gbóríyìn fún ọ. Ó dájú pé emi kò lè máa lọ lati ilé dé ilé kí n sì máa wàásù nipa ìsìn mi gẹ́gẹ́ bí iwọ ti ń ṣe.” Pẹlu ẹ̀rín músẹ́ Ẹlẹ́rìí naa fèsì pé: “Ìmọ̀lára rẹ yé mi. Ṣáájú kí n tó di ọ̀kan lára awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, o kò lè mú kí n lọ bá awọn ènìyàn mìíràn sọ̀rọ̀ nipa ìsìn. Ṣugbọn nísinsìnyí mo fẹ́ lati ṣe bẹ́ẹ̀.” Adélébọ̀ naa ronú fún ìgbà díẹ̀ ó sì parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Dájúdájú ìsìn rẹ ní ohun kan lati fifúnni tí tèmi kò ní. Bóyá mo níláti ṣe ìwádìí.”
19. Èéṣe tí ó fi jẹ́ ìsinsìnyí ni àkókò naa lati máa yọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ?
19 Ẹṣin-ọ̀rọ̀ ọdún 1994, tí a gbé sí ibi tí ojú ti lè tètè rí i ní awọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, ń rán wa létí déédéé: “Fi gbogbo àyà rẹ gbẹ́kẹ̀lé [Jehofa, NW].” (Owe 3:5) Ìdí pàtàkì mìíràn ha lè wà fún yíyọ̀ ju níní àǹfààní lati fi ìgbẹ́kẹ̀lé wa sínú Jehofa, ibi odi-agbára wa, ẹni tí awa sádi? Orin Dafidi 64:10 ṣàlàyé pé: “Olódodo yoo máa yọ̀ nipa ti Oluwa, yoo sì máa gbẹ́kẹ̀lé e.” Kìí ṣe àkókò nìyí lati mikàn tabi juwọ́sílẹ̀. Oṣù kọ̀ọ̀kan tí ń kọjá túbọ̀ ń mú wa súnmọ́ ìmúṣẹ ohun tí awọn ìránṣẹ́ Jehofa ti ń yánhànhàn lati rí lati ìgbà Abeli wá. Àkókò nìyí lati fi gbogbo ọkàn-àyà wa gbẹ́kẹ̀lé Jehofa, ní mímọ̀ pé kò tíì sí ìgbà kankan rí tí a tíì ní awọn ìdí pupọ tóbẹ́ẹ̀ lati máa yọ̀!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní awọn àpéjọpọ̀ ati ní ẹ̀ẹ̀kan lóṣù ninu ìjọ, a ń ka awọn gbólóhùn ṣókí tí ń fi iye ọrẹ tí a rígbà ati iye ìnáwó tí a ṣe hàn. A máa ń kọ awọn lẹ́tà tí ń sọ nipa bí a ṣe ń lo awọn ọrẹ naa ráńṣẹ́ lati ìgbà dé ìgbà. Olúkúlùkù ni a tipa bayii ránlétí ipò ọ̀ràn ìnáwó iṣẹ́ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kárí-ayé.
Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dáhùn?
◻ Gẹ́gẹ́ bí Nehemiah 8:10 ṣe sọ, èéṣe tí a fi níláti máa yọ̀?
◻ Bawo ni Deuteronomi 26:11 ati 28:45-47 ṣe fi ìjẹ́pàtàkì yíyọ̀ hàn?
◻ Bawo ni Filippi 4:4-9 ṣe ṣèrànwọ́ fún wa lati máa yọ̀ nígbà gbogbo?
◻ Ìdí wo ni ẹṣin-ọ̀rọ̀ ọdún 1994 fún wa lati máa yọ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Awọn Ẹlẹ́rìí ní Russia ati Germany láyọ̀ lati jẹ́ apákan ẹgbẹ́-àwọn-ará káàkiri ayé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ṣíṣàjọpín òtítọ́ naa pẹlu awọn ẹlòmíràn jẹ́ ìdí fún yíyọ̀