Àwọn Èèyàn Ha Ń Gba Ìmọ̀ràn Rẹ Bí?
ÌMỌ̀RÀN rere táa fúnni bó ti tọ́ àti bó ti yẹ sábà máa ń so èso rere. Bẹ́ẹ̀ ni àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Kódà ìmọ̀ràn tó dáa jù lọ, tí àwọn agbaninímọ̀ràn tó dáńgájíá fi fúnni, làwọn èèyàn máa ń pa tì, tàbí kí wọ́n kọ etí ikún sí.—Òwe 29:19.
Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jèhófà fún Kéènì nímọ̀ràn, nítorí pé ó kórìíra Ébẹ́lì, àbúrò rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 4:3-5) Ọlọ́run mọ̀ pé ewu ńlá ló fẹ́ wu Kéènì yìí, ìyẹn ló fi sọ fún un pé: “Èé ṣe tí ìbínú rẹ fi gbóná, èé sì ti ṣe tí ojú rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì? Bí ìwọ bá yíjú sí ṣíṣe rere, ara rẹ kò ha ní yá gágá bí? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá yíjú sí ṣíṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ lúgọ sí ẹnu ọ̀nà, ìfàsí-ọkàn rẹ̀ sì wà fún ọ; ní tìrẹ, ìwọ yóò ha sì kápá rẹ̀ bí?”—Jẹ́nẹ́sísì 4:6, 7.
Jèhófà fi ẹ̀ṣẹ̀ wé ẹranko apanijẹ tó gọ de Kéènì, bó bá ń bá a lọ ní dídi àbúrò rẹ̀ sínú. (Fi wé Jákọ́bù 1:14, 15.) Kò tíì pẹ́ jù fún Kéènì láti yí ìwà rẹ̀ padà, kó “yíjú sí ṣíṣe rere,” kí ó tó ko àgbákò. Ó ṣeni láàánú pé Kéènì kọ̀, kò gbọ́. Ó kọ etí ikún sí ìmọ̀ràn Jèhófà, ojú rẹ̀ sì já a.
Àwọn kan kì í fẹ́ gbọ́ ìmọ̀ràn sétí rárá, kíkọ̀ ni wọ́n máa ń kọ̀ ọ́. (Òwe 1:22-30) Àmọ́ o, kíkọ̀ tí àwọn kan ń kọ ìmọ̀ràn ha lè jẹ́ ẹ̀bi agbaninímọ̀ràn bí? (Jóòbù 38:2) Ìwọ tóo ń fún èèyàn nímọ̀ràn, o ha jẹ́ kó nira láti gbà bí? Èyí lè ṣẹlẹ̀ dáadáa nítorí àìpé ẹ̀dá. Ṣùgbọ́n o lè rí nǹkan ṣe sí i, tí irú rẹ̀ kò fi ní wọ́pọ̀, bóo bá fara balẹ̀ tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. Ẹ jẹ́ ká yẹ díẹ̀ nínú wọn wò.
‘Tọ́ni Sọ́nà Nínú Ẹ̀mí Ìwà Tútù’
“Ẹ̀yin ará, bí ènìyàn kan bá tilẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé kí ó tó mọ̀ nípa rẹ̀, kí ẹ̀yin tí ẹ tóótun nípa tẹ̀mí gbìyànjú láti tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà nínú ẹ̀mí ìwà tútù, bí olúkúlùkù yín ti ń ṣọ́ ara rẹ̀ lójú méjèèjì, kí a má bàa dẹ ìwọ náà wò.” (Gálátíà 6:1) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí i pé kí àwọn tó “tóótun nípa tẹ̀mí” gbìyànjú láti tọ́ Kristẹni tó bá “ṣi ẹsẹ̀ gbé kí ó tó mọ̀” sọ́nà. Nígbà mìíràn, ó jọ pé àwọn tí kò tóótun rárá ló máa ń fẹ́ tètè fúnni nímọ̀ràn. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kó máa yá ẹ jù láti fún àwọn èèyàn nímọ̀ràn. (Òwe 10:19; Jákọ́bù 1:19; 3:1) Ní pàtàkì, àwọn alàgbà ìjọ ló tóótun nípa tẹ̀mí láti ṣe èyí. Ṣùgbọ́n o, Kristẹni èyíkéyìí, tó bá dàgbà dénú gbọ́dọ̀ ṣe kìlọ̀kìlọ̀ bó bá rí arákùnrin kan tó fẹ́ kó sínú ewu.
Bóo bá fẹ́ fúnni nímọ̀ràn tàbí ìbáwí, rí i dájú pé o gbé ohun tóo sọ ka ọgbọ́n àtọ̀runwá, má ṣe gbé e ka àbá àti ọgbọ́n orí ènìyàn. (Kólósè 2:8) Ṣe bíi alásè tó ń ṣàyẹ̀wò gbogbo èròjà rẹ̀ kínníkínní láti rí i dájú pé yóò ṣara lóore, àti pé kò ní nǹkan kan nínú tó lè pani lára. Rí i dájú pé ìmọ̀ràn rẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó má kàn jẹ́ èrò tara ẹni. (2 Tímótì 3:16, 17) Bóo bá ṣe èyí, ó dájú pé ìmọ̀ràn rẹ kì yóò pa ẹnikẹ́ni lára.
Ète ìmọ̀ràn ni láti ‘tọ́ ẹni tó ṣàṣìṣe sọ́nà,’ kì í ṣe láti fipá mú un ṣe ìyípadà tí kò fẹ́ ṣe. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a tú sí “tọ́ sọ́nà padà” tan mọ́ ọ̀rọ̀ kan tí a ń lò tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa títo eegun tó yẹ̀, kí ó má bàa ṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bí W. E. Vine, tí í ṣe onímọ̀ èdè ti wí, ó tún wé mọ́ “ìjẹ́pàtàkì lílo sùúrù àti ìfaradà lẹ́nu iṣẹ́ náà.” Sáà ronú nípa bó ti ṣe pàtàkì tó láti ṣe é lẹ́sọ̀lẹ́sọ̀, lọ́nà tó jáfáfá, kí a má bàa tún lọ dákún ìrora onítọ̀hún. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, agbaninímọ̀ràn ní láti ṣọ́ra gidigidi kó má bàa ṣèpalára fún ẹni tó ń fún nímọ̀ràn. Ó ṣòroó ṣe, kódà bó bá jẹ́ pé onítọ̀hún ló dìídì wá béèrè fún ìmọ̀ràn. Ó tún wá gba òye àti ọgbọ́n tó peléke nígbà táwọn èèyàn kò bá sọ pé kí o wá fáwọn nímọ̀ràn.
Ó dájú pé o kò lè ‘tọ́ ẹnì kan sọ́nà’ bóo bá sọ onítọ̀hún dọ̀tá. Láti yẹra fún èyí, rántí ìjẹ́pàtàkì níní “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra.” (Kólósè 3:12) Bí dókítà kan bá jẹ́ aláìnísùúrù, tó ń jájú mọ́ aláìsàn, aláìsàn náà lè pa ìmọ̀ràn rẹ̀ tì, kó má sì padà wá mọ́ fún ìtọ́jú tó nílò.
Èyí kò wá túmọ̀ sí pé kí ìmọ̀ràn má sọjú abẹ níkòó. Jésù Kristi sọjú abẹ níkòó nígbà tó fún ìjọ méje tó wà ní àgbègbè Éṣíà nímọ̀ràn. (Ìṣípayá 1:4; 3:1-22) Ó fún wọn ní àwọn ìmọ̀ràn kan tó ṣe ṣàkó, tó yẹ wọ́n, tó sì yẹ ní mímú lò. Ṣùgbọ́n o, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù sọjú abẹ níkòó, ó tún máa ń lo àwọn ànímọ́ bí ìyọ́nú àti inú rere, ó tipa báyìí fi ẹ̀mí onífẹ̀ẹ́ bí ti Baba rẹ̀ ọ̀run hàn.—Sáàmù 23:1-6; Jòhánù 10:7-15.
Gbani Nímọ̀ràn Pẹ̀lú Oore Ọ̀fẹ́
“Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.” (Kólósè 4:6) Iyọ̀ lè mú kí oúnjẹ túbọ̀ dùn, kí ó jẹ́ kó túbọ̀ lọ lẹ́nu. Bí ìmọ̀ràn rẹ yóò bá ládùn, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ “pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn.” Àmọ́ o, ká tilẹ̀ sọ pé a ní àwọn èròjà tó dọ́ṣọ̀, a lè se oúnjẹ náà ní ìsèkúsè, tàbí kí a kọ ọ́ yánmayànma sínú abọ́. Irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ kò ní wu èèyàn-án jẹ. Àní, gbígbé òkèlè kan tí a fi sẹ́nu mì lè di ìṣòro.
Nígbà táa bá ń fúnni nímọ̀ràn, ó ṣe pàtàkì láti lo ọ̀rọ̀ yíyẹ. Sólómọ́nì ọlọgbọ́n wí pé: “Bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.” (Òwe 25:11) Ó jọ pé ohun tó ní lọ́kàn ni abọ́ fàdákà táa fi iṣẹ́ ọnà dárà sí lára, táa wá kó àwọn nǹkan oníwúrà táa gbẹ́ rèǹtè-rente bí èso ápù sínú rẹ̀. Yóò mà jojú ní gbèsè o, tún wá wo bí inú rẹ yóò ti dùn tó táa bá fi ta ẹ́ lọ́rẹ! Lọ́nà kan náà, àṣàyàn ọ̀rọ̀, tó jẹ́ olóore ọ̀fẹ́, lè jẹ́ ìwúrí fún ẹni tí o ń gbìyànjú láti ràn lọ́wọ́.—Oníwàásù 12:9, 10.
Ní ìfiwéra, ṣe ni “ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1) Ọ̀rọ̀ kòbákùngbé lè tètè fa ẹ̀dùn ọkàn àti ìbínú, dípò ìdúpẹ́. Lóòótọ́, ọ̀rọ̀ burúkú nìkan kọ́ ló lè mú kí ẹnì kan kọ ìmọ̀ràn tó dáa, ṣùgbọ́n ó tún lè kọ̀ ọ́ báa bá fi ohùn tí kò dáa sọ ọ́. Fífúnni nímọ̀ràn láìfọgbọ́n ṣe é, láìgba tẹni rò, lè dọ́gbẹ́ síni lára bí ẹni pé ohun ìjà ni a lò. Òwe 12:18 sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.” Kí wá làǹfààní sísọ̀rọ̀ láìronú, tó lè mú kó ṣòro fún èèyàn láti gba ìmọ̀ràn?—Òwe 12:15.
Gẹ́gẹ́ bí Sólómọ́nì ti wí, ọ̀rọ̀ tí a fi gbani nímọ̀ràn yẹ kí ó jẹ́ “ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.” Àkókò táa sọ̀rọ̀ mà kúkú ṣe pàtàkì o, bí ìmọ̀ràn wa yóò bá ṣiṣẹ́! Ó ṣe kedere pé ẹni tébi ò pa kì í mọyì oúnjẹ. Bóyá ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹun gidi kan tán ni, tàbí kó jẹ́ pé ara rẹ̀ kò yá. Fífoúnjẹ rọ ẹni tí kò fẹ́ jẹun kò bọ́gbọ́n mu, kò sì bójú mu.
Gbani Nímọ̀ràn Nínú Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
“Ẹ mú ìdùnnú mi kún ní ti pé ẹ . . . [kò ṣe] ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ, kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:2-4) Bóo bá mọ báa ti ń gbani nímọ̀ràn, mímójútó “ire ara ẹni” ti àwọn ẹlòmíràn ni yóò sún ẹ láti fúnni nímọ̀ràn. Ìwọ yóò fi “ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú” bá àwọn ará lò, ìwọ yóò ka ẹlòmíràn sí ẹni tó lọ́lá jù ẹ́ lọ. Kí ni èyí túmọ̀ sí?
Ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú yóò jẹ́ kí o yẹra fún ṣíṣe tàbí sísọ̀rọ̀ bí ẹni tó lọ́lá ju àwọn yòókù lọ. Kò sídìí fún ẹnikẹ́ni wa láti máa ronú pé òun lọ́lá ju àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ òun. Gbogbo wa ló ń ṣàṣìṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Níwọ̀n bí o kò ti mọ ohun tó wà nínú ọkàn-àyà, ó ṣe pàtàkì gan-an láti má ṣe ní èrò òdì nípa ohun tó wà lọ́kàn ẹni tí o ń fún nímọ̀ràn. Ó lè máà ní èrò búburú kankan lọ́kàn, ó sì lè máà mọ̀ nípa ìwà àìtọ́ tàbí ìgbésẹ̀ àìtọ́ èyíkéyìí. Ká tilẹ̀ sọ pé bákan ṣá, ó mọ̀ pé òun ti ṣe ohun tó lòdì sí ohun tí Ọlọ́run béèrè, ó dájú pé yóò rọrùn fún un gan-an láti gba ìmọ̀ràn báa bá fún un nínú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, pẹ̀lú ojúlówó ìfẹ́ nínú ire rẹ̀ nípa tẹ̀mí.
Ronú bí yóò ti rí lára rẹ, ká sọ pé a pè ẹ́ wá jẹun, ṣùgbọ́n tí ẹni tó pè ẹ́ kò yá mọ́ ẹ, tó tún fojú pa ẹ́ rẹ́! Dájúdájú, ìwọ kò ní gbádùn oúnjẹ náà. Àní, “oúnjẹ tí a fi ọ̀gbìn oko sè, níbi tí ìfẹ́ wà, sàn ju akọ màlúù tí a bọ́ yó ní ibùjẹ ẹran tòun ti ìkórìíra.” (Òwe 15:17) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kódà ìmọ̀ràn tó dáa jù lọ pàápàá lè nira láti gbà, bí agbaninímọ̀ràn bá kórìíra ẹni tó ń gbà nímọ̀ràn tàbí tó tẹ́ ẹ, tó sì dójú tì í. Àmọ́ ṣá o, ìfẹ́, ìbọ̀wọ̀ fún tọ̀tún tòsì, àti ìfọkàntánni yóò jẹ́ kí ìmọ̀ràn rọrùn láti fúnni àti láti gbà.—Kólósè 3:14.
Ìmọ̀ràn Tí A Tẹ́wọ́ Gbà
Wòlíì náà, Nátánì, hùwà ìrẹ̀lẹ̀ nígbà tó gba Ọba Dáfídì nímọ̀ràn. Ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ fún Dáfídì hàn nínú ohun tí Nátánì sọ, tó sì ṣe. Nátánì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àpèjúwe kan tó ro ti ohun tó lè mú kí ó nira fún Dáfídì láti gba ìmọ̀ràn. (2 Sámúẹ́lì 12:1-4) Wòlíì náà fa ojú Dáfídì mọ́ra nípa sísọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ tí Dáfídì ní sí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ àti òdodo, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ànímọ́ wọ̀nyí kò fara hàn nínú ohun tó wáyé láàárín òun àti Bátí-ṣébà. (2 Sámúẹ́lì 11:2-27) Nígbà tí wòlíì náà fa kókó inú àpèjúwe náà yọ, ohun tí Dáfídì fi fèsì látọkànwá ni: “Èmi ti ṣẹ̀ sí Jèhófà.” (2 Sámúẹ́lì 12:7-13) Láìdàbí Kéènì, tí kò gbọ́rọ̀ sí Jèhófà lẹ́nu, Dáfídì fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí.
Láìsí àní-àní, Jèhófà ló tọ́ Nátánì sọ́nà, ó ro ti àìpé Dáfídì, ó ro ti pé ó ṣeé ṣe kó fárígá. Nátánì wá ń fọgbọ́n ṣe é nìṣó, ó hàn gbangba pé ó ka Dáfídì sẹ́ni tó lọ́lá ju òun lọ nítorí ipò Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba tí Jèhófà yàn. Bí o bá wà nípò àṣẹ, o lè fúnni ní ìmọ̀ràn yíyẹ, ṣùgbọ́n tó lè ṣòroó gbà bí o kò bá lo ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.
Nátánì tọ́ Dáfídì sọ́nà nínú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Ọ̀rọ̀ wòlíì náà kún fún oore ọ̀fẹ́, ó sì rò ó dáadáa kó tó sọ ọ́, kí Dáfídì lè hùwà padà lọ́nà tí yóò jẹ́ fún ire ara rẹ̀. Nátánì kò retí àtirí nǹkan kan gbà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ bí ẹni pé òun mọ́ ju Dáfídì ní ti ìwà rere tàbí nípa tẹ̀mí. Àbí ẹ ò rí bó ti dáa tó láti máa sọ ọ̀rọ̀ yíyẹ lọ́nà yíyẹ! Bóo bá ń fi irú ẹ̀mí yìí hàn, ó ṣeé ṣe gan-an pé àwọn èèyàn yóò máa gba ìmọ̀ràn rẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ aṣaralóore, ó yẹ kí ìmọ̀ràn rẹ ládùn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
O ha ń mú kí ìmọ̀ràn rẹ fani mọ́ra bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ táa fi fàdákà ṣe?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Wòlíì náà, Nátánì, fi ìrẹ̀lẹ̀ darí àfiyèsí sí ìfẹ́ tí Dáfídì ní sí ìdájọ́ òdodo àti ẹ̀tọ́