Ìwọ Yóò Ha Fẹ́ Òwú Àtùpà Tí Ń jó Lọ́úlọ́ú Pa Bí?
JESU KRISTI polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọrun fún onírúurú ènìyàn. A ni púpọ̀ nínú wọn lára, a sì mú wọn rẹ̀wẹ̀sì. Ṣùgbọ́n, Jesu fún wọn ní ìhìn iṣẹ́ amọ́kànyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀. Ó ní ìyọ́nú fún àwọn ènìyàn tí ń jìyà.
Akọ̀wé Ìhìn Rere náà, Matteu, tẹnu mọ́ ìyọ́nú Jesu nípa pípe àfiyèsí sí àsọtẹ́lẹ̀ tí Isaiah kọ sílẹ̀. Ní fífa ọ̀rọ̀ tí Kristi mú ṣẹ yọ, Matteu kọ̀wé pé: “Kò sí esùsú kankan tí a ti pa lára tí oun yoo tẹ̀fọ́, kò sì sí òwú àtùpà kankan tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe tí ń jó lọ́úlọ́ú tí oun yoo fẹ́pa, títí oun yoo fi rán ìdájọ́ òdodo jáde pẹlu àṣeyọrí sí rere.” (Matteu 12:20: Isaiah 42:3) Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí, báwo sì ni Jesu ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ?
Àyẹ̀wò Àsọtẹ́lẹ̀ Náà
Esùsú sábà máa ń dàgbà ní agbègbè irà, kì í sì í ṣe nǹkan ọ̀gbìn tí ó lágbára tí ó sì fẹsẹ̀ múlẹ̀. Ní tòótọ́, ‘esùsú tí a ti pa lára’ yóò ti rọ. Nítorí náà, ó dà bíi pé, ó dúró fún àwọn tí a ni lára tàbí tí a ń jẹ níyà, bí ọkùnrin kan tí ó rọ lọ́wọ́ tí Jesu wò sàn ní ọjọ́ Sábáàtì. (Matteu 12:10-14) Ṣùgbọ́n, kí ni nípa ìtọ́kasí alásọtẹ́lẹ̀ tí a ṣe nípa òwú àtùpà kan tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe?
Kólòbó tí ó lẹ́nu gọngọ pẹ̀lú ọwọ́ kọdọrọ ni àtùpà wíwọ́pọ̀ jù lọ nínú ilé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. A sábà máa ń bu òróró ólífì sínú àtùpà náà. Nípasẹ̀ òòfà àtinúwá tí ń bẹ nínú òpó rẹ̀, òwú àtùpà tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe ń fa òróró kí iná rẹ̀ lè máa jó. Àmọ́ ṣáá o, ‘òwú àtùpà tí ń jó lọ́úlọ́ú,’ ni yóò fẹ́ kọ́kọ́ kú.
Jesu pòkìkí ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ tí ń tuni nínú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n dà bí esùsú tí a pa lára, tí a tẹ̀ kòlòbà, tí a sì ń gbá káàkiri. Àwọn wọ̀nyí tún dà bí òwú àtùpà, tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe, tí ń jó lọ́úlọ́ú, nítorí pé, ìwọ̀nba tí ó kù nínú wọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ jó tán. Ní ti gidi, a ni wọ́n lára, a sì mú wọn rẹ̀wẹ̀sì. Bí ó ti wù kí ó rí, Jesu kò tẹ esùsú ìṣàpẹẹrẹ kan tí a ti pa lára fọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò fẹ́ òwú àtùpà ìṣàpẹẹrẹ kan tí ń jó lọ́úlọ́ú pa. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ onífẹ̀ẹ́, oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, àti oníyọ̀ọ́nú kò túbọ̀ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ènìyàn tàbí kí ó mú ìsoríkọ́ bá àwọn ènìyàn tí ń jìyà. Dípò èyí, àwọn ọ̀rọ̀ àti ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú wọn ní ìyọrísí ríruni sókè.—Matteu 11:28-30.
Lónìí pẹ̀lú, ọ̀pọ̀ nílò ìyọ́nú àti ìṣírí nítorí pé, wọ́n dojú kọ àwọn ìṣòro bíbani lọ́kàn jẹ́. Àní àwọn ìránṣẹ́ Jehofa kì í fìgbà gbogbo jẹ́ alágbára nínú ìdààmú. Nígbà mìíràn, àwọn kan jọ òwú àtùpà tí ń jó lọ́úlọ́ú. Nítorí náà, àwọn Kristian ní láti jẹ́ afúnniníṣìírí—ní fífẹ́ iná náà, kí a sọ ọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ—kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fún ara wọn lẹ́nì kíní kejì lókun.—Luku 22:32; Ìṣe 11:23.
Gẹ́gẹ́ bíi Kristian, ó yẹ kí a jẹ́ afúnniníṣìírí. A kò ní láti mọ̀ọ́nmọ̀ gbìyànjú láti káàárẹ̀ bá ẹnikẹ́ni ti ń wá ìrànwọ́ nípa tẹ̀mí. Ní tòótọ́, a óò lọ́kàn ìfẹ́ láti fara wé àpẹẹrẹ Jesu ní fífún àwọn ẹlòmíràn ní ìṣírí. (Heberu 12:1-3; 1 Peteru 2:21) Òtítọ́ náà pé, a lè tẹ ẹnikẹ́ni tí ó gbójú lé wa fún ìṣírí fọ́ láìmọ̀ọ́mọ̀, jẹ́ ìdí rere láti mú wa ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà tí a ń gbà bá àwọn mìíràn lò. Dájúdájú, a kì yóò fẹ́ láti ‘fẹ́ òwú àtùpà kan tí ń jó lọ́úlọ́ú pa.’ Àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ wo ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn yìí?
Àbáyọrí Lámèyítọ́
Bí Kristian kan ‘bá ṣi ẹsẹ̀ gbé, àwọn tí ó tóótun nipa ti ẹ̀mí ní láti gbìyànjú lati tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà ninu ẹ̀mí ìwàtútù.’ (Galatia 6:1) Bí ó ti wù kí ó rí, yóò ha tọ́ láti máa wá àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn, kí a sì lo gbogbo àǹfààní láti tọ́ wọn sọ́nà bí? Tàbí yóò ha tọ́, láti tì wọ́n láti túbọ̀ ṣe dáradára sí i, nípa dídọ́gbọ́n sọ pé, ìsapá wọn lọ́ọ́lọ́ọ́ kò tó, bóyá ní mímú kí wọ́n nímọ̀lára ẹ̀bi bí? Kò sí ẹ̀rí kankan pé, Jesu ṣe ohunkóhun bẹ́ẹ̀. Bí èrò wa tilẹ̀ jẹ́ ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti sunwọ̀n sí i, àwọn tí a ń ṣe lámèyítọ́ wọn lọ́nà tí kò fi inú rere hàn lè di aláìlera, kàkà tí wọn ì bá fi jẹ́ alágbára. Àní lámèyítọ́ tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ pàápàá lè múni rẹ̀wẹ̀sì bí a bá ṣe é láṣejù. Bí ó bá jẹ́ kìkì kò dójú àmì ni a fi ń sọ nípa ìsapá dídára jù lọ tí Kristian ẹlẹ́rìí ọkàn rere kan bá ṣe, ó lè fẹ́rẹ̀ẹ́ juwọ́ sílẹ̀, kí ó sì sọ pé, ‘Èé ṣe ti mo tilẹ̀ fi gbìyànjú rẹ̀ wò?’ Ní tòótọ́, ó lè juwọ́ sílẹ̀ pátápátá.
Nígbà tí ó jẹ́ pé fífúnni ní ìmọ̀ràn tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu ṣe pàtàkì, kò yẹ kí ó jẹ́ àmì ìdánimọ̀ àwọn alàgbà tí a yàn sípò tàbí àwọn mìíràn nínú ìjọ. Kì í ṣe nítorí kí a lè fúnni nímọ̀ràn, kí a sì lè rí ìmọ̀ràn gbà ni ìdí pàtàkì tí a fi ń ṣe ìpàdé Kristian. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ń pàdé pọ̀ déédéé láti gbé ara wa ró, kí a sì fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kíní kejì, kí gbogbogbòò baà lè gbádùn àjọṣepọ̀ wọn àti iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wọn sí Ọlọrun. (Romu 1:11, 12; Heberu 10:24, 25) Ẹ wo bí ó ti ń dára tó nígbà tí a bá fòye mọ ìyàtọ̀ láàárín àṣìṣe wíwúwo àti àìpé, tí ó lọ́gbọ́n nínú, tí ó sì fi ìfẹ́ hàn, láti gbójú fo nǹkan!—Oniwasu 3:1, 7; Kolosse 3:13.
Àwọn ènìyàn máa ń yára hùwà padà sí ìṣírí ju lámèyítọ́ lọ. Ní tòótọ́, nígbà tí àwọn kan bá rò pé a ṣe lámèyítọ́ wọn lọ́nà àìtọ́, wọ́n lè jingíri sínú ìwà tí a ṣe lámèyítọ́ náà! Ṣùgbọ́n, nígbà tí a bá gbóríyìn fún wọn lọ́nà títọ́, orí wọn yóò wú, a óò sì sún wọn láti ṣe púpọ̀ sí i. (Owe 12:18) Nítorí náà, bíi Jesu, ẹ jẹ́ kí a jẹ́ afúnniníṣìírí, kí a má sì ṣe ‘fẹ́ òwú àtùpà tí ń jó lọ́úlọ́ú pa’ láé.
Ṣíṣàfiwéra Ńkọ́?
Gbígbọ́ àwọn ìrírí gbígbámúṣé, ti àwọn Kristian mìíràn lè súnni ṣiṣẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Jesu fúnra rẹ̀ yọ̀, nígbà tí ó gbọ́ nípa àṣeyọrí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ti wíwàásù ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. (Luku 10:17-21) Bákan náà, nígbà tí a bá gbọ́ nípa àṣeyọrí, àpẹẹrẹ rere, tàbí ìwà títọ́ àwọn mìíràn nínú ìgbàgbọ́, ó máa ń fún wa níṣìírí, a sì máa ń fẹ́ láti túbọ̀ dúró ti ìpinnu wa, láti di ìwà Kristian wa mú.
Síbẹ̀, bí a bá gbé ẹ̀sùn kan kalẹ̀ lọ́nà kan tí ó fi hàn pé, ‘O kò dára tó àwọn Kristian wọ̀nyí, ó ṣì yẹ kí o lè máa ṣe púpọ̀ ju bí o ti ń ṣe lọ’ ńkọ́? Ó ha ṣeé ṣe pé, olùgbọ́ náà yóò dáwọ́ lé ètò àfagbáraṣe kan láti lè sunwọ̀n sí i bí? Ó ṣeé ṣe pé, òun yóò rẹ̀wẹ̀sì, bóyá kí ó sì juwọ́ sílẹ̀, ní pàtàkì, bí a bá sábà ń ṣàfiwéra tàbí fi dọ́gbọ́n sọ̀rọ̀. Èyí yóò dà bí òbí kan tí ń bi ọmọ rẹ̀ pé, ‘Èé ṣe tí o kò fi lè dà bí arákùnrin rẹ?’ Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè fa kùnrùngbùn, ó sì lè múni rẹ̀wẹ̀sì, ṣùgbọ́n bóyá ni ó fi lè gbé ìwà tí ó sunwọ̀n sí i lárugẹ. Ṣíṣàfiwéra lè ní irú ìyọrísí jíjọra bẹ́ẹ̀ lórí àwọn àgbàlagbà, àní kí ó tilẹ̀ mú kí wọ́n ní kùnrùngbùn sí àwọn tí a ń fi wọ́n wé.
A kò lè retí pé kí gbogbo ènìyàn ṣe iye kan náà nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọrun. Nínú ọ̀kan lára àwọn àkàwé Jesu, ọ̀gá kan fún àwọn ẹrú rẹ̀ ní yálà tálẹ́ǹtì kan, méjì, tàbí márùn-ún. Ó fún “olúkúlùkù ní ìbámu pẹlu agbára ìlèṣe nǹkan tirẹ̀.” Ó gbóríyìn fún àwọn ẹrú méjì tí wọ́n ṣòwò lọ́nà lílọ́gbọ́n nínú, tí wọ́n sì sọ tálẹ́ǹtì wọn di púpọ̀, nítorí pé, wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, iṣẹ́ wọn mú èrè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ jáde.—Matteu 25:14-30.
Aposteli Paulu kọ̀wé lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ fúnra rẹ̀ jẹ́, nígbà naa ni oun yoo ní ìdí fún ayọ̀ àṣeyọrí níti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹlu ẹlòmíràn.” (Galatia 6:4) Láti lè jẹ́ ẹni tí ń fún àwọn ẹlòmíràn ní ìṣírí ní tòótọ́, nígbà náà, a ní láti gbìyànjú láti yẹra fún síṣàfiwéra lọ́nà òdì.
Àwọn Ọ̀nà Díẹ̀ Láti Gbéni Ró
Kí ni a lè ṣe láti gbé àwọn tí ó rẹ̀wẹ̀sì ró, kí a sì yẹra fún ‘fífẹ́ òwú àtùpà tí ń jó lọ́úlọ́ú pa’? Tóò, pípèsè ìṣírí kì í ṣe ọ̀ràn títẹ̀ lé ọ̀nà ìgbàṣe kan pàtó. Ṣùgbọ́n, ó ṣeé ṣe kí àwọn ọ̀rọ̀ wa gbé àwọn ẹlòmíràn ró, bí a bá fi àwọn ìlànà Bibeli sílò. Kí ni díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí?
Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Ní Filippi 2:3, Paulu gbà wá níyànjú láti ‘má ṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, a ní láti sọ̀rọ̀, kí a sì hùwà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀. ‘Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, a ní láti máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù wá lọ.’ Paulu kò sọ pé, a kò ní láti ronú ohunkóhun nípa ara wa. Síbẹ̀, a ní láti lóye pé, gbogbo ènìyàn lọ́lá jù wá lọ, ní àwọn ọ̀nà kan. Ọ̀rọ̀ Griki náà tí a túmọ̀ sí “lọ́lá jù . . . lọ” níhìn-ín, túmọ̀ sí pé ọkùnrin kan “kò ka àǹfààní tirẹ̀ sí, ó sì ń fi taratara ronú lórí ẹ̀bùn tí ẹlòmíràn fi lọ́lá jù ú lọ.” (New Testament Word Studies, láti ọwọ́ John Albert Bengel, Ìdìpọ̀ 2, ojú ìwé 432) Bí a bá ṣe èyí, tí a sì gbà pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù wá lọ, a óò bá wọn lò tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀.
Fi ọ̀wọ̀ hàn. Nípa ṣíṣàlàyé ara wa tọkàntọkàn, a lè mú kí ó ṣe kedere pé, a ní ìgbọ́kànlé nínú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa, ní kíkà wọ́n sí ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ń fẹ́ láti wu Ọlọrun. Ṣùgbọ́n, ká ní wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí ńkọ́? Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí a pèsè ìtìlẹ́yìn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, tiyìtiyì. Paulu mú ọ̀ràn ṣe kedere lọ́nà yìí: “Ninu bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nìkínní kejì ẹ mú ipò iwájú.”—Romu 12:10.
Jẹ́ olùtẹ́tísílẹ̀ rere. Bẹ́ẹ̀ ni, láti lè fún àwọn tí wọ́n lè dojú kọ àwọn ìṣòro amúnirẹ̀wẹ̀sì ní ìṣírí, ó yẹ kí a jẹ́ olùtẹ́tísílẹ̀ rere, kì í ṣe aláwìíyé. Dípò fífúnni ní àwọn ìmọ̀ràn kánmọ́kánmọ́, tí ó sì jẹ́ oréfèé, ẹ jẹ́ kí a lo àkókò tí ó tó láti pèsè àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tí ó bá àìní lọ́ọ́lọ́ọ́ mu ní ti gidi. Bí a kò bá mọ ohun tí a óò sọ, ìwádìí Bibeli yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìtùnú sọ̀rọ̀, kí a sì gbé àwọn ẹlòmíràn ró.
Jẹ́ onífẹ̀ẹ́. A ní láti nífẹ̀ẹ́ àwọn tí a fẹ́ fún níṣìírí. Nígbà tí a bá lò ó fún àwọn ẹlẹgbẹ́ wa tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Jehofa, ó yẹ kí ìfẹ́ wa lọ ré kọjáa wíwulẹ̀ hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ire wọn dídára jù lọ. Ó ní láti ní ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ nínú. Bí a bá ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ fún gbogbo àwọn ènìyàn Jehofa, àwọn ọ̀rọ̀ wọn yóò jẹ́ ojúlówó ìṣírí fún wọn. Kódà bí ó bá yẹ kí a fúnni ní ìmọ̀ràn fún ìsunwọ̀n sí i, bóyá ni wọn yóò fi ṣi ohun tí a bá sọ lóye tàbí kí ó fa ìpalára, nígbà tí èrò wa kì í bá ṣe láti gbé ojú ìwòye tiwa kalẹ̀, bí kò ṣe láti fúnni ní ìrànwọ́ onífẹ̀ẹ́. Bí Paulu ṣe sọ lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, “ìfẹ́ a máa gbéniró.”—1 Korinti 8:1; Filippi 2:4; 1 Peteru 1:22.
Jẹ́ Agbéniró Nígbà Gbogbo
Ní “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” líle koko wọ̀nyí, àwọn ènìyàn Jehofa ń dojú kọ ọ̀pọ̀ àdánwò. (2 Timoteu 3:1-5) Abájọ tí wọ́n fi máa ń jìyà títí dé ibi tí wọ́n lè fara dà á dé nígbà mìíràn. Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jehofa, dájúdájú, a kì yóò fẹ́ láti sọ tàbí ṣe àwọn ohun tí ó lè mú èyíkéyìí nínú àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa nímọ̀lára bí òwú àtùpà tí ń jó lọ́úlọ́ú tí iná rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú.
Ẹ wo bí ó ti ṣe pàtàkì tó nígbà náà, pé, kí a máa fún ara wa níṣìírí lẹ́nì kíní kejì! Ẹ jẹ́ kí a sa gbogbo ipá wa láti jẹ́ agbéniró nípa jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kí a sì ní ọ̀wọ̀ fún àwọn olùjọ́sìn ẹlẹgbẹ́ wa tí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì. Ǹjẹ́ kí a tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ nígbà tí wọ́n bá finú tán wa, kí a sì máa wá ọ̀nà láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà gbogbo nípa dídarí àfiyèsí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ jẹ́ kí a fi ìfẹ́ hàn, nítorí èso ẹ̀mí mímọ́ Jehofa yìí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fún ara wa lókun lẹ́nì kíní kejì. Ǹjẹ́ kí a má ṣe sọ̀rọ̀ tàbí hùwà lọ́nàkọnà tí ó lè ‘fẹ́ òwú àtùpà tí ń jó lọ́úlọ́ú pa’ láé.