“Ẹ Máa Gbé Èrò Inú Yín Ka Àwọn Nǹkan Ti Òkè”
“Ẹ máa gbé èrò inú yín ka àwọn nǹkan ti òkè, kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.”—KÓL. 3:2.
1, 2. (a) Kí nìdí tí ìjọ Kólósè fi wà nínú ewu? (b) Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará ní Kólósè kí wọ́n lè dúró láìyẹsẹ̀?
ÀWỌN Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tó wà ní ìjọ Kólósè wà nínú ewu! Àwọn kan nínú ìjọ ń fa ìpínyà, wọ́n sọ pé ó yẹ káwọn èèyàn máa tẹ̀ lé Òfin Mósè. Àwọn kan sọ pé kò yẹ kéèyàn máa gbádùn ara rẹ̀. Láti fi hàn pé èrò wọn kò tọ̀nà, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn ará Kólósè láti fún wọn níṣìírí àti láti kìlọ̀ fún wọn, ó sọ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.”—Kól. 2:8.
2 Táwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn yìí bá gbé èrò inú wọn ka “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé,” ńṣe nìyẹn á fi hàn pé wọn kò mọrírì àǹfààní tí Jèhófà fún wọn láti rí ìgbàlà. (Kól. 2:20-23) Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí wọ́n fi ìṣọ́ ṣọ́ àjọṣe tó ṣeyebíye tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà, torí náà ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ máa gbé èrò inú yín ka àwọn nǹkan ti òkè, kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” (Kól. 3:2) Torí náà, àwọn arákùnrin Kristi yìí gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé àwọn ń retí ogún tí kò lè díbàjẹ́, èyí tí Ọlọ́run “fi pa mọ́ dè [wọ́n] ní ọ̀run.”—Kól. 1:4, 5.
3. (a) Kí ni ohun táwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn ń retí? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Bákan náà lónìí, àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn máa ń gbé èrò inú wọn ka Ìjọba Ọlọ́run lókè ọ̀run àti lórí ohun tí wọ́n ń retí, ìyẹn láti di “àwọn ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi.” (Róòmù 8:14-17) Àmọ́, àwọn tó máa jogún ilẹ̀ ayé ńkọ́? Báwo ni ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ṣe kan àwọn náà? Báwo làwọn “àgùntàn mìíràn” ṣe lè máa gbé èrò wọn ka “àwọn nǹkan ti òkè”? (Jòh. 10:16) Báwo sì ni gbogbo wa ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn olóòótọ́ èèyàn, bí Ábúráhámù àti Mósè, tó jẹ́ pé láìka ìṣòro tí wọ́n ní sí, wọ́n gbé èrò inú wọn ka àwọn nǹkan ti òkè?
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI GBÉ ÈRÒ INÚ WA KA ÀWỌN NǸKAN TI ÒKÈ
4. Báwo ni àwọn àgùntàn mìíràn ṣe lè gbé èrò inú wọn ka àwọn nǹkan ti òkè?
4 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn àgùntàn mìíràn kò lọ sí òkè ọ̀run, àwọn náà lè gbé èrò inú wọn ka àwọn nǹkan ti òkè. Lọ́nà wo? Tí wọ́n bá ń fi Jèhófà Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀ sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn. (Lúùkù 10:25-27) Ìdí nìyẹn tá a fi ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. (1 Pét. 2:21) Bíi tàwọn ará wa ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwa náà wà láàárín àwọn èèyàn tí wọ́n ń gbé èrò èké àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí lásán kiri, tí wọ́n sì ń fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn wá owó àti àwọn ohun ìní tara nínú ètò àwọn nǹkan Sátánì yìí. (Ka 2 Kọ́ríńtì 10:5.) Àmọ́, torí pé à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, a ní láti wà lójúfò ká lè gbéjà ko ohunkóhun tó lè ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.
5. Báwo la ṣe lè ṣàyẹ̀wò irú ọwọ́ tí a fi mú owó àti àwọn ohun ìní tara?
5 Ǹjẹ́ a ti ń jẹ́ kí ọwọ́ tí àwọn èèyàn ayé fi mú nǹkan ìní tara máa kó èèràn ràn wá? Àwọn ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí sábà máa ń hàn nínú ìwà wa àti ohun tá à ń rò lọ́kàn. Jésù sọ pé: “Ibi tí ìṣúra rẹ bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn-àyà rẹ yóò wà pẹ̀lú.” (Mát. 6:21) Ká lè mọ ibi tí ọkàn wa ń darí wa sí, ó dára ká máa ṣàyẹ̀wò ara wa ní gbogbo ìgbà. Bi ara rẹ pé: ‘Báwo ni àkókò tí mo fi ń ronú lórí ọ̀rọ̀ owó ṣe pọ̀ tó? Ṣé kì í ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò mi ni mo fi ń ronú lórí bí òwò mi á ṣe gbòòrò sí i, nípa okòwò táá túbọ̀ máa mówó wọlé fún mi tàbí nípa bí mo ṣe lè máa gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ? Ǹjẹ́ mò ń sapá láti máa pọkàn pọ̀ sórí nǹkan tẹ̀mí?’ (Mát. 6:22) Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó bá ń fi “títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ lórí ilẹ̀ ayé” sípò àkọ́kọ́ ń fi àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà sínú ewu.—Mát. 6:19, 20, 24.
6. Kí la lè ṣe ká lè ja àjàṣẹ́gun lórí àwọn ìfẹ́ ti ara?
6 Àwọn nǹkan tí ọkàn wa bá ti fà sí ni ara àìpé wa máa ń fẹ́ ká ṣe. (Ka Róòmù 7:21-25.) Tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run kò bá ṣiṣẹ́ nígbèésí ayé wa, ó ṣeé ṣe ká máa lọ́wọ́ nínú àwọn “iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti òkùnkùn,” irú bí “àwọn àríyá aláriwo àti mímu àmuyíràá, . . . ìbádàpọ̀ tí ó tàpá sófin àti ìwà àìníjàánu.” (Róòmù 13:12, 13) Ká lè ja àjàṣẹ́gun lórí “àwọn nǹkan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé,” ìyẹn àwọn nǹkan tí ọkàn wa máa ń fà sí, a gbọ́dọ̀ gbé èrò inú wa ka àwọn nǹkan ti òkè. Èyí kì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá, ó gba ìsapá, abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Mo ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú.” (1 Kọ́r. 9:27) Ká sòótọ́, tá a bá fẹ́ máa sá eré ìje ìyè náà nìṣó, a kò ní máa tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́, ká wá máa ṣe ohun tó bá ṣáà ti wù wá! Ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun táwọn ọkùnrin olóòótọ́ ìgbàanì méjì ṣe kí wọ́n lè ‘wu Ọlọ́run dáadáa.’—Héb. 11:6.
ÁBÚRÁHÁMÙ “NÍ ÌGBÀGBỌ́ NÍNÚ JÈHÓFÀ”
7, 8. (a) Àwọn ìṣòro wo ló dojú kọ Ábúráhámù àti Sárà? (b) Orí kí ni Ábúráhámù gbé ọkàn rẹ̀ lé?
7 Ábúráhámù gbà láìjanpata nígbà tí Jèhófà sọ fún un pé kí ó kó ìdílé rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Kénáánì. Torí pé Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́, ó sì tún jẹ́ onígbọràn, Jèhófà dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú rẹ̀, ó ní: “Èmi yóò sì mú orílẹ̀-èdè ńlá jáde lára rẹ, èmi yóò sì bù kún ọ.” (Jẹ́n. 12:2) Àmọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà náà, Ábúráhámù àti Sárà ìyàwó rẹ̀ kò tíì bímọ. Ṣé kì í ṣe pé Jèhófà ti gbàgbé ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù? Yàtọ̀ síyẹn, nǹkan ò rọrùn fún wọn nílẹ̀ Kénáánì. Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀ kúrò ní ilé wọn, wọ́n sì fi àwọn ẹbí wọn sílẹ̀ nílùú Úrì tó jẹ́ ìlú tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù nílẹ̀ Mesopotámíà. Wọ́n rìnrìn àjò tí ó lé ní ẹgbẹ̀jọ [1,600] kìlómítà kí wọ́n tó dé Kénáánì. Inú àgọ́ ni wọ́n gbé, wọ́n ní láti fara da ìyàn, wọ́n máa ń wà nínú ewu àwọn onísùnmọ̀mí nígbà míì. (Jẹ́n. 12:5, 10; 13:18; 14:10-16) Síbẹ̀, kò wá sí wọn lọ́kàn láti pa dà sínú ìgbádùn nílùú Úrì!—Ka Hébérù 11:8-12, 15.
8 Kàkà kí Ábúráhámù gbé ọkàn rẹ̀ sí “àwọn nǹkan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé,” ńṣe ni Ábúráhámù “ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà.” (Jẹ́n. 15:6) Ábúráhámù gbé èrò inú rẹ̀ ka àwọn nǹkan ti òkè ní ti pé ó fọkàn sí àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run Gíga Jù Lọ fi san án lẹ́san torí ìgbàgbọ́ tó ní, Ọlọ́run sọ fún un nígbà tó fara hàn án pé: “‘Jọ̀wọ́, gbé ojú sókè sí ọ̀run, kí o sì ka àwọn ìràwọ̀, bí ó bá lè ṣeé ṣe fún ọ láti kà wọ́n.’ Ó sì ń bá a lọ láti wí fún un pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni irú-ọmọ rẹ yóò dà.’” (Jẹ́n. 15:5) Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe máa fi Ábúráhámù lọ́kàn balẹ̀ tó! Gbogbo ìgbà tí Ábúráhámù bá ti ń gbé ojú sókè tó sì ń rí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ńṣe ni ìlérí tí Jèhófà ṣe fún un pé òun máa sọ àtọmọdọ́mọ rẹ̀ di púpọ̀ á máa wá sọ́kàn rẹ̀. Nígbà tó sì tó àsìkò lójú Ọlọ́run, Ó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, Ábúráhámù bí ọmọ tí ó jẹ́ ajogún rẹ̀.—Jẹ́n. 21:1, 2.
9. Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ábúráhámù, báwo lèyí ṣe máa mú ká máa ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?
9 Bíi ti Ábúráhámù, àwa náà ń retí kí àwọn ìlérí Ọlọ́run ní ìmúṣẹ. (2 Pét. 3:13) Tí a kò bá gbé èrò inú wa ka àwọn nǹkan ti òkè, lójú wa ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í dà bíi pé ìmúṣẹ àwọn ìlérí yẹn ń falẹ̀, èyí sì lè mú kí ìtara tá a fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o yááfì àwọn nǹkan kan nígbà kan sẹ́yìn torí kó o lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tàbí àfikún iṣẹ́ ìsìn míì? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a gbóríyìn fún ẹ. Àmọ́, ní báyìí ńkọ́? Má gbàgbé pé Ábúráhámù fọkàn sí “ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́.” (Héb. 11:10) Ó “ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, a sì kà á sí òdodo fún un.”—Róòmù 4:3.
MÓSÈ RÍ “ẸNI TÍ A KÒ LÈ RÍ”
10. Àwọn àǹfààní wo ni Mósè ní nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́?
10 Ọkùnrin míì tó gbé èrò inú rẹ̀ ka àwọn nǹkan ti òkè ni Mósè. Nígbà tó wà ní ọ̀dọ́, ó gba “ìtọ́ni nínú gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì.” Èyí kì í ṣe ẹ̀kọ́ ìwé kan lásán o. Yàtọ̀ sí pé Íjíbítì ni agbára ayé nígbà yẹn, ilé Fáráò ni wọ́n ti tọ́ Mósè dàgbà. Abájọ tí ẹ̀kọ́ ìwé gíga tí Mósè ní yìí fi mú kó di “alágbára nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀.” (Ìṣe 7:22) Ẹ wo àǹfààní lóríṣiríṣi tó wà níwájú Mósè! Àmọ́, Mósè gbé ọkàn rẹ̀ lé àwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ, ìyẹn ni bó ṣe máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.
11, 12. Ẹ̀kọ́ wo ni Mósè kà sí ohun iyebíye, báwo la sì ṣe mọ̀?
11 Ó dájú pé nígbà tí Mósè wà ní kékeré, Jókébédì tó jẹ́ ìyá rẹ̀ á ti kọ́ ọ ní ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Ọlọ́run àwọn Hébérù. Mósè ka ìmọ̀ nípa Jèhófà sí ohun ńlá, ó sì gbà pé ó ṣeyebíye ju ọlá èyíkéyìí lọ. Kò jẹ́ kí àwọn àǹfààní tó ṣeé ṣe kó tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ torí pé ilé Fáráò ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ̀. (Ka Hébérù 11:24-27.) Ní ti gidi, ẹ̀kọ́ tí Mósè kọ́ nípa Jèhófà àti ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà ló mú kó lè gbé èrò inú rẹ̀ ka àwọn nǹkan ti òkè.
12 Mósè kọ́ ẹ̀kọ́ ìwé tó dára jù lọ nígbà ayé rẹ̀, àmọ́ ǹjẹ́ ó lo ẹ̀kọ́ náà láti fi wá ipò ńlá kan ní Íjíbítì tàbí láti fi mú kó di olókìkí tàbí kó fi kó ọ̀rọ̀ jọ fún ara rẹ̀? Rárá o. Ká ní ó ṣe bẹ́ẹ̀ ni, kò ní “kọ̀ kí a máa pe òun ní ọmọkùnrin ti ọmọbìnrin Fáráò, ó yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run dípò jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.” Ó ṣe kedere pé Mósè lo ẹ̀kọ́ tó kọ́ nípa Jèhófà láti fi mú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ.
13, 14. (a) Kí ló mú kí Mósè lè ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà máa tó gbé fún un? (b) Bíi ti Mósè, kí ló lè gba pé káwa náà ṣe?
13 Mósè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn Rẹ̀ gan-an. Nígbà tí Mósè wà lẹ́ni ogójì [40] ọdún, ó rò pé òun ti ṣe tán láti kó àwọn èèyàn Ọlọ́run kúrò nígbèkùn Íjíbítì. (Ìṣe 7:23-25) Àmọ́, Mósè ṣì nílò àwọn nǹkan kan kí Jèhófà tó lè gbé iṣẹ́ yẹn fún un. Ó gbọ́dọ̀ láwọn ìwà kan, irú bí ìrẹ̀lẹ̀, sùúrù, ìwà tútù àti ìkóra-ẹni-níjàánu. (Òwe 15:33) Mósè gbọ́dọ̀ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó máa jẹ́ kó lè fara da àdánwò àti ìnira tó ń bọ̀ níwájú. Ogójì [40] ọdún tó fi da àgùntàn mú kó láwọn ìwà tí Ọlọ́run fẹ́ kó ní yìí.
14 Ǹjẹ́ Mósè kọ́ ẹ̀kọ́ nínú iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tó ṣe yìí? Ó kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa! Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé Mósè fi “gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀.” (Núm. 12:3) Ó ti kọ́ ìrẹ̀lẹ̀, èyí sì mú kó lè fi sùúrù bójú tó onírúurú èèyàn àti ìṣòro wọn tó le koko. (Ẹ́kís. 18:26) Ó lè gba pé káwa náà láwọn ìwà tí inú Jèhófà dùn sí tó máa jẹ́ ká lè la “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀ já, ká sì wọ inú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run. (Ìṣí. 7:14) Ṣé a wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn, títí kan àwọn tá a rò pé wọ́n tètè máa ń bínú tàbí àwọn tí wọn kò rí ara gba nǹkan sí? Ẹ jẹ́ ká fiyè sí ohun tí àpọ́sítélì Pétérù sọ nígbà tó rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé: “Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo, ẹ máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.”—1 Pét. 2:17.
BÁ A ṢE LÈ GBÉ ÈRÒ INÚ WA KA ÀWỌN NǸKAN TI ÒKÈ
15, 16. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká gbé èrò inú wa ka àwọn nǹkan ti òkè? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwa Kristẹni máa hùwà rere?
15 “Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò,” là ń gbé yìí. (2 Tím. 3:1) Torí náà, ká lè wà lójúfò nípa tẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ gbé èrò inú wa ka àwọn nǹkan ti òkè. (1 Tẹs. 5:6-9) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ọ̀nà mẹ́ta kan tó kan ìgbésí ayé wa tá a lè gbà ṣe èyí.
16 Ìwà wa: Pétérù mọ̀ pé ìwà rere ṣe pàtàkì. Ó sọ pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè . . . kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà tí wọ́n fojú rí, yin Ọlọ́run lógo.” (1 Pét. 2:12) Yálà, a wà nílé tàbí níbi iṣẹ́, níléèwé, níbi tá a ti ń ṣeré ìnàjú tàbí a wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, a máa ń sa gbogbo ipá wa láti jẹ́ kí ìwà rere wa máa fi ògo fún Jèhófà. Torí pé a jẹ́ ẹ̀dá aláìpé, gbogbo wa la máa ń ṣe àṣìṣe. (Róòmù 3:23) Àmọ́, a kò gbọ́dọ̀ jáwọ́ láti máa “ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́,” a lè borí ẹran ara wa aláìpé tí a bá ń bá a wọ̀yá ìjà.—1 Tím. 6:12.
17. Báwo la ṣe lè nírú ẹ̀mí ìrònú tí Kristi Jésù ní? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
17 Ìrònú wa: Tá a bá fẹ́ máa hùwà tó dáa, ó yẹ ká máa ronú lọ́nà tó tọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ pa ẹ̀mí ìrònú yìí mọ́ nínú yín, èyí tí ó wà nínú Kristi Jésù pẹ̀lú.” (Fílí. 2:5) Irú ẹ̀mí ìrònú wo ni Jésù ní? Ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Ìrẹ̀lẹ̀ ló mú kó lè yááfì gbogbo nǹkan torí kó lè wàásù. Wíwàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn ni nǹkan àkọ́kọ́ lọ́kàn rẹ̀. (Máàkù 1:38; 13:10) Jésù gbà pé ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá sọ la gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé. (Jòh. 7:16; 8:28) Ó fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ dáadáa kó lè fa ọ̀rọ̀ yọ látinú rẹ̀, kó lè gbèjà rẹ̀, kó sì lè ṣàlàyé rẹ̀. Bí a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tí a sì ń lo ìtara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìrònú wa yóò túbọ̀ máa jọ ti Kristi.
18. Ọ̀nà pàtàkì wo la lè gbà ti iṣẹ́ Jèhófà lẹ́yìn?
18 Ìtìlẹ́yìn wa: Ìfẹ́ Jèhófà ni pé “ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba ti àwọn tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” (Fílí. 2:9-11) Kódà ní ipò gíga tí Jésù wà, ó máa ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀, ohun tó yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn. (1 Kọ́r. 15:28) Lọ́nà wo? Ká máa fi gbogbo ọkàn wa ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wa pé ká ṣe, ìyẹn ni pé ká “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 28:19) Bákan náà, a fẹ́ máa “ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn,” ìyẹn ni pé ká máa ṣe dáadáa sáwọn èèyàn tó wà láyìíká wa àtàwọn ará wa.—Gál. 6:10.
19. Kí ló yẹ ká pinnu láti máa ṣe?
19 A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà ń rán wa létí pé ká máa gbé èrò inú wa ka àwọn nǹkan ti òkè! Torí náà, a gbọ́dọ̀ “fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa.” (Héb. 12:1) Bí a ti ń ṣe iṣẹ́ Jèhófà, ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa “fi tọkàntọkàn ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà,” torí a mọ̀ pé Baba wa ọ̀run yóò san wá lẹ́san.—Kól. 3:23, 24.