Ẹ Máa Ṣiṣẹ́ Ìgbàlà Yín Yọrí!
“Ẹ̀yin olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, . . . ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.”—FÍLÍPÌ 2:12.
1, 2. Èròǹgbà tí ó wọ́pọ̀ wo ni ó ti sún ọ̀pọ̀ ènìyàn láti rò pé wọn kò lè dárí bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn?
“ṢÉ ÀBÍMỌ́ rẹ ni?” Láìpẹ́ yìí, gàdàgbà-gadagba ni ìbéèrè yẹn hàn lẹ́yìn ìwé ìròyìn kan tí a mọ̀ nílé lóko. Nísàlẹ̀ àkọlé yẹn ni a ti rí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Àkópọ̀ ìwà, ànímọ́, àní àwọn ohun tí o yàn láti ṣe nínú ìgbésí ayé pàápàá. Àwọn ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ fi hàn pé ọ̀pọ̀ ju lọ wọn wà nínú apilẹ̀ àbùdá rẹ.” Irú àwọn ọ̀rọ̀ báwọ̀nyí lè mú kí àwọn kan rò pé àwọn kò lè darí bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn.
2 Àwọn mìíràn ń ṣàníyàn pé ọ̀nà tí kò dára tó tí àwọn òbí wọn gbà tọ́ wọn dàgbà tàbí ọ̀nà tí kò dára tó tí olùkọ́ wọn gbà kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ni ó fa ìgbésí ayé àìláyọ̀ tí wọ́n ń gbé. Wọ́n lè gbà pé a ti kádàrá pé kí àwọn ṣe irú àṣìṣe kan náà tí àwọn òbí wọn ṣe, kí àwọn tẹ̀ lé èrò búburú tí ó bá dìde lọ́kàn wọn, kí àwọn di aláìṣòótọ́ sí Jèhófà—ní kúkúrú, kí àwọn yàn láti ṣe búburú. Ṣé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nìyẹn? Òótọ́ ni pé àwọn ẹlẹ́sìn kan wà tí wọ́n rin kinkin mọ́ ọn pé Bíbélì kọ́ni ni ohun tí ó jọ èyí tí a sọ yìí, ẹ̀kọ́ àyànmọ́. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ yìí ti sọ, Ọlọ́run ti pinnu gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbésí ayé rẹ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú.
3. Ìhìn iṣẹ́ tí ń fúnni níṣìírí wo ni Bíbélì ní í sọ nípa agbára tí a ní láti pinnu ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wa ní ọjọ́ ọ̀la?
3 Gbogbo èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọ̀nyí ní èrò abẹ́nú kan náà: Ohun tí o lágbára láti yàn pé o fẹ́ ṣe kò tó nǹkan, agbára tí o sì ní lórí bí ìgbésí ayé rẹ̀ yóò ṣe rí kò tó nǹkan. Ọ̀rọ̀ tí ń múni rẹ̀wẹ̀sì lèyí jẹ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣe ni ìrẹ̀wẹ̀sì sì máa ń dá kún ìṣòro. Òwe 24:10 sọ pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, a rọ̀ wá láti gbà pé a lè ‘ṣiṣẹ́ ìgbàlà wa yọrí.’ (Fílípì 2:12) Báwo ni a ṣe lè mú kí ìgbọ́kànlé tí a ní nínú ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ tí ń gbéni ró yìí lágbára sí i?
Iṣẹ́ ‘Ìkọ́lé’ Tí A Ń Ṣe Nínú Ara Wa
4. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé 1 Kọ́ríńtì 3:10-15 sọ nípa fífi ohun-èlò tí kò lè gbiná kọlé, kí ni èyí kò túmọ̀ sí?
4 Ronú lórí àkàwé tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe nínú 1 Kọ́ríńtì 3:10-15. Níbẹ̀, ó sọ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé tí Kristẹni kan ń ṣe, ìlànà tí ó sì wà nínú àkàwé rẹ̀ ṣeé lò fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lórí ara wa àti lórí àwọn ẹlòmíràn. Ṣé ohun tí ó ń sọ ni pé yálà ọmọ ẹ̀yìn kan yàn níkẹyìn láti sin Jèhófà, kí ó sì dúró ti ìpinnu rẹ̀ tàbí kò ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹrù iṣẹ́ àwọn tí ó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ bí? Rárá o. Pọ́ọ̀lù ń tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì kí olùkọ́ náà ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé náà lọ́nà tí ó dára jù lọ. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí a ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú àpilẹ̀kọ ìṣáájú, kò sọ pé kò sí ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ náà tàbí ọmọ ẹ̀yìn náà lè ṣe nínú ọ̀ràn yìí. Lóòótọ́, àkàwé Pọ́ọ̀lù darí àfiyèsí sí iṣẹ́ tí a ń ṣe lórí àwọn ẹlòmíràn, kì í ṣe èyí tí a ń ṣe nínú ara wa. Èyí ṣe kedere nítorí tí Pọ́ọ̀lù sọ bí iṣẹ́ ìkọ́lé tí a kò mú ní ọ̀kúnkúndùn ṣe di èyí tí ó run, nígbà tí ó sì jẹ́ pé, a gba kọ́lékọ́lé náà fúnra rẹ̀ là. Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà mìíràn, Bíbélì máa ń lo ọnà èdè kan náà yìí fún iṣẹ́ tí a ń ṣe fún àǹfààní ara wa.
5. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni ó fi hàn pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ‘ìkọ́lé’ kan nínú ara wọn?
5 Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí Júúdà 20, 21, tí ó sọ pé: “Ẹ̀yin, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, nípa gbígbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín mímọ́ jù lọ, àti gbígbàdúrà pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́, ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.” Níhìn-ín, Júúdà lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan náà tí ó túmọ̀ sí “kọ́lé” tí Pọ́ọ̀lù lo nínú 1 Kọ́ríńtì orí 3, ṣùgbọ́n ó jọ pé kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé a ń gbé ara wa ró lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ wa. Nígbà tí Lúùkù ń ṣàkọsílẹ̀ àkàwé Jésù nípa ọkùnrin tí ó fi ìpìlẹ̀ ilé rẹ̀ lélẹ̀ lórí àpáta ràbàtà, ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan náà tí Pọ́ọ̀lù lò fún iṣẹ́ ìkọ́lé ti Kristẹni ni ó lò fún “ìpìlẹ̀.” (Lúùkù 6:48, 49) Síwájú sí i, nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń gba àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú, ó lo èdè àfiwé ti jíjẹ́ ẹni tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lórí “ìpìlẹ̀” kan. Bẹ́ẹ̀ ni, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ wa pé kí a ṣe iṣẹ́ ‘ìkọ́lé’ lórí ara wa.—Éfésù 3:15-19; Kólósè 1:23; 2:7.
6. (a) Ṣàkàwé bí Kristẹni kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn ṣe jẹ́ àbájáde iṣẹ́ ìkọ́lé tí a pawọ́ pọ̀ ṣe? (b) Kí ni olúkúlùkù ọmọ ẹ̀yìn yóò jíhìn?
6 Iṣẹ́ kíkọ́ Kristẹni kan ha jẹ́ ti ẹnì kan ṣoṣo bí? Ó dára, ká ní o fẹ́ kọ́ ilé kan. O wá lọ bá ayàwòrán ilé fún àwọn àwòrán ilé náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ fúnra rẹ ni ó fẹ́ ṣe èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́ náà, o gba kọngílá kan láti bá ọ ṣiṣẹ́, kí ó sì fún ọ nímọ̀ràn lórí ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti gbà ṣe iṣẹ́ ọ̀hún. Bí ó bá fi ìpìlẹ̀ lílágbára lélẹ̀, tí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye àwọn àwòrán ilé náà, tí ó sọ àwọn ohun èlò ìkọ́lé dídára ju lọ tí wà á rà, àní tí ó tilẹ̀ tún kọ́ ọ ní ohun púpọ̀ nípa ilé kíkọ́, dájúdájú, ìwọ yóò gbà pé ó ti ṣe iṣẹ́ tí ó pójú owó. Ṣùgbọ́n bí o kò bá náání ìmọ̀ràn rẹ̀ ńkọ́, tí o lọ ra àwọn ohun èlò olówó pọ́ọ́kú tàbí bàrúùfù, tí o kò tilẹ̀ tẹ̀ lé àwòràn tí a yà fún ọ mọ́? Ó dájú pé o kò ní dá kọngílá náà tàbí ayàwòrán ilé náà lẹ́bi bí ilé ọ̀hún bá wó! Bákan náà, olúkúlùkù Kristẹni tí ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn jẹ́ àbàjáde iṣẹ́ ilé kíkọ́, tí a pawọ́ pọ̀ ṣe. Jèhófà ni ògbóǹtarìgì ayàwòrán ilé náà. Ó ń ṣèrànwọ́ fún Kristẹni olóòótọ́, tí ó jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run,” tí ń kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan lẹ́kọ̀ọ́, tí ó sì ń gbé e ró. (1 Kọ́ríńtì 3:9) Síbẹ̀, ọ̀ràn ọ̀hún kan akẹ́kọ̀ọ́ náà pẹ̀lú. Ní àbárèbábọ̀, òun ni yóò jíhìn bí ó ṣe lo ìgbésí ayé ara rẹ̀. (Róòmù 14:12) Bí ó bá fẹ́ ní àwọn ànímọ́ àtàtà tí ó jẹ́ ti Kristẹni, ó gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára láti ní wọn, ó sì gbọ́dọ̀ sọ wọn di apá kan ara rẹ̀.—2 Pétérù 1:5-8.
7. Àwọn ìpèníjà wo ni àwọn Kristẹni kan dojú kọ, kí ni ó sì lè tù wọ́n nínú?
7 Nígbà náà, èyí ha túmọ̀ sí pé, apilẹ̀ àbùdá, ipò àyíká, àti ànímọ́ àwọn olùkọ́ wa, kò já mọ́ nǹkan kan bí? Rárá o. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kókó wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ohun pàtàkì, tí ó lè nípa lórí ẹni. Ọ̀pọ̀ ìtẹ̀sí ẹ̀ṣẹ̀ àti èrò òdì jẹ́ àbímọ́ni, ó sì lè ṣòro gan-an láti gbéjà kò wọ́n. (Sáàmù 51:5; Róòmù 5:12; 7:21-23) Ẹ̀kọ́ tí òbí kọ́ni àti àyíká ilé lè ní ipa púpọ̀ lórí àwọn ọ̀dọ́—sí rere tàbí sí búburú. (Òwe 22:6; Kólósè 3:21) Jésù dẹ́bi fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù nítorí ipa búburú tí ẹ̀kọ́ wọn ní lórí àwọn ẹlòmíràn. (Mátíù 23:13, 15) Lónìí, irú kókó bẹ́ẹ̀ ń nípa lórí gbogbo wa. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lára àwọn ènìyàn Ọlọ́run ń ní ìṣòro nítorí ìgbà èwe tí kò fara rọ tí wọ́n gbé. Àwọn wọ̀nyí nílò inú rere àti ìgbatẹnirò wa. Wọ́n sì lè rí ìtùnú gbà láti inú ìsọfúnni tí Bíbélì fúnni pé a kò kádàrá àwọn láti ṣe àṣìṣe kan náà tí àwọn òbí wọn ṣe tàbí pé kí wọ́n di aláìṣòótọ́. Ṣàgbéyẹ̀wò bí àwọn ọba kan ní Júdà ìgbàanì ṣe mú kí kókó yìí ṣe kedere.
Àwọn Ọba Júdà—Wọ́n Yan Ohun Tí Ó Wù Wọ́n
8. Àpẹẹrẹ búburú wo ni Jótámù rí lára baba rẹ̀, síbẹ̀ kí ni ó yàn láti ṣe?
8 Ọmọ ọdún 16 péré ni Ùsáyà nígbà tí ó di ọba Júdà, ó sì ṣàkóso fún ọdún 52. Jálẹ̀ èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú àkókò rẹ̀, ó “ń bá a lọ ní ṣíṣe ohun tí ó dúró ṣánṣán ní ojú Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Amasááyà baba rẹ̀ ṣe.” (2 Àwọn Ọba 15:3) Jèhófà mú kí ó ní ọ̀pọ̀ ìṣẹ́gun tí ó bùáyà. Ṣùgbọ́n, ó bani nínú jẹ́ pé, àṣeyọrí kó sí Ùsáyà lórí. Ó di onírera, ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà nípa sísun tùràrí ní ibi pẹpẹ tẹ́ńpìlì, iṣẹ́ tí a yàn fún àwọn àlùfáà. A bá Ùsáyà wí gidigidi, àmọ́ ìbínú ló fi hùwà padà. A wá rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀—a sọ ọ́ di adẹ́tẹ̀, ó sì di dandan fún un láti lo ìyókù ayé rẹ̀ ní àdádó. (2 Kíróníkà 26:16-23) Báwo ni Jótámù, ọmọ rẹ̀, ṣe wá hùwà padà sí gbogbo èyí? Ọ̀dọ́mọkùnrin náà ì bá wulẹ̀ ti jẹ́ kí baba òun nípa lórí òun, kí ó sì kọ etí ọ̀gbọn-in sí ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Àwọn ènìyàn náà lápapọ̀ ti lè jẹ́ agbára ìdarí búburú níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn pẹ̀lú ṣì ń bá ẹ̀sìn wọn tí kò tọ́ lọ. (2 Àwọn Ọba 15:4) Ṣùgbọ́n Jótámù yan ohun tí ó wù ú. “Ó . . . ń bá a nìṣó ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà.”—2 Kíróníkà 27:2.
9. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ohun rere tí ó nípa lórí Áhásì, ṣùgbọ́n báwo ni ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe rí níkẹyìn?
9 Jótámù ṣàkóso fún ọdún 16, ní gbogbo àkókò yìí, ó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Nítorí náà, Áhásì, ọmọ rẹ̀, ní àpẹẹrẹ rere ti baba kan tí ó jẹ́ olóòótọ́. Àwọn ohun rere mìíràn tún wà tí ó lè ní ipa lórí Áhásì. Ó láǹfààní láti gbé ayé ní àkókò tí àwọn wòlíì olóòótọ́ bí Aísáyà, Hóséà, àti Míkà ń fi taápọntaápọn sọ tẹ́lẹ̀ ní ilẹ̀ náà. Síbẹ̀, ó yàn láti ṣe búburú. “Kò . . . ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀.” Ó yá ọ̀pọ̀ ère Báálì, ó sì jọ́sìn wọn, ó tilẹ̀ tún dáná sun àwọn ọmọ tirẹ̀ alára láti fi wọ́n ṣe ìrúbọ sí àwọn òrìṣà. Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ohun rere tí ó lè ní ipa lórí rẹ̀ wọ̀nyí, ó kùnà pátápátá gẹ́gẹ́ bí ọba àti gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà.—2 Kíróníkà 28:1-4.
10. Irú baba wo ni Áhásì jẹ́, ṣùgbọ́n kí ni Hesekáyà, ọmọ rẹ̀, yàn láti ṣe?
10 Bí a bá fojú ìjọsìn mímọ́ gaara wò ó, kò tún sí baba tí ìwà rẹ̀ burú ju ti Áhásì lọ. Ṣùgbọ́n, Hesekáyà, ọmọ rẹ̀, kò kúkú lè yan baba mìíràn fún ara rẹ̀! Ó tilẹ̀ ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé àwọn arákùnrin Hesekáyà ni Áhásì fi rúbọ sí Báálì. Ǹjẹ́ ipò àtilẹ̀wá bíbani nínú jẹ́ yìí sọ Hesekáyà di ẹni tí ó gbọ́dọ̀ gbé ìgbésí ayé aláìṣòótọ́ sí Jèhófà bí? Ní òdìkejì pátápátá, Hesekáyà di ọ̀kan lára àwọn ọba rere díẹ̀ tí ó jẹ ní Júdà—ó jẹ́ olóòótọ́, ọlọ́gbọ́n, àti ẹni ọ̀wọ́n. “Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.” (2 Àwọn Ọba 18:3-7) Àní, ìdánilójú wà pé nígbà tí Hesekáyà ṣì wà lọ́mọdé gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọba ni ó kọ Sáàmù 119 lábẹ́ ìmísí. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kò ṣòro láti mọ ìdí tí ó fi kọ ọ̀rọ̀ náà pé: “Ọkàn mi kò lè sùn nítorí ẹ̀dùn-ọkàn.” (Sáàmù 119:28) Láìfi ìdààmú tí ó kó ẹ̀dùn-ọkàn bá a pè, Hesekáyà jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Jèhófà máa darí ìgbésí ayé òun. Sáàmù 119:105 sọ pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.” Bẹ́ẹ̀ ni, Hesekáyà yan ohun tí ó wù ú—ohun tí ó tọ́.
11. (a) Láìka agbára ìdarí rere tí baba Mánásè ní lórí rẹ̀ sí, báwo ni ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ sí Jèhófà ti burú tó? (b) Kí ni Mánásè yàn láti ṣe ni ìgbẹ̀yìn ìgbésí ayé rẹ̀, kí ni sì a lè rí kọ́ nínú èyí?
11 Ṣùgbọ́n, ní òdìkejì pátápátá, inú ọba tí ó dára jù lọ ní Júdà ni ọba tí ó burú jù lọ ti jáde. Mánásè, ọmọ Hesekáyà, gbé ìbọ̀rìṣà, ìbẹ́mìílò, àti ìwà ipá gígọntíọ lọ́nà tí kò láfiwé lárugẹ. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé “Jèhófà . . . ń bá Mánásè àti àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ṣáá,” ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀. (2 Kíróníkà 33:10) Ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù sọ pé Mánásè fi ayùn rẹ́ Aísáyà nítorí rẹ̀. (Fi wé Hébérù 11:37.) Bóòótọ́ ni, bírọ́ ni, Mánásè kò ṣáà fetí sí ìkìlọ̀ àtọ̀runwá. Àní, ó mú kí a finá sun àwọn kan lára àwọn ọmọ tirẹ̀ alára láàyè gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ, bíńtín ni ti Áhásì, baba rẹ̀ àgbà, jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ tirẹ̀. Síbẹ̀, nígbà tí ọkùnrin burúkú yìí rí àdánwò ní ìgbẹ̀yín ìgbésí ayé rẹ̀, ó ronú pìwà dà, ó sì ṣàtúnṣe. (2 Kíróníkà 33:1-6, 11-20) Àpẹẹrẹ rẹ̀ kọ́ wa pé bí ẹnì kan tilẹ̀ yàn láti ṣe ohun búburú jáì, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé kò lè ṣàtúnṣe. Ó lè yí padà.
12. Àwọn ìpinnu yíyàtọ̀ wo ni Ámónì àti Jòsáyà ọmọ rẹ̀ ṣe ní ti sísin Jèhófà?
12 Ámónì, ọmọ Mánásè, ì bá ti kọ́ ohun púpọ̀ nínú ìrònúpìwàdà baba rẹ̀. Àmọ́ ó yàn láti ṣe ohun tí ó burú. Ámónì ní gidi “mú kí ẹ̀bi pọ̀ sí i” títí di ìgbà tí wọ́n fi pa á lójijì. Jòsáyà, ọmọ rẹ̀, tún wá yàtọ̀ sí i lọ́nà gígadabú. Ó hàn gbangba pé, Jòsáyà yàn láti kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tó ṣẹlẹ̀ sí baba rẹ̀ àgbà. Ọmọ ọdún mẹ́jọ péré ni nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Nígbà tí ó ṣì jẹ́ ọmọ ọdún 16 péré, ó bẹ̀rẹ̀ sí wá Jèhófà, lẹ́yìn náà, ó jẹ́ olóòótọ́ ọba tí àpẹẹrẹ rẹ̀ ṣeé tẹ̀ lé. (2 Kíróníkà 33:20–34:5) Ó yan ohun tí ó wù ú—ohun tí ó tọ́.
13. (a) Ẹ̀kọ́ wo ni a rí kọ́ lára àwọn ọba Jùdíà tí a ti gbé yẹ̀ wò? (b) Báwo ni ẹ̀kọ́ tí ó yẹ kí àwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn ti ṣe pàtàkì tó?
13 Àyẹ̀wò ráńpẹ́ nípa àwọn ọba Júdà méje wọ̀nyí kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ gidi. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn ọba tí ó burú jù lọ ni àwọn ọmọ wọn dára jù lọ, nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn sì rèé, àwọn ọba tí ó dára jù lọ ni àwọn ọmọ wọn burú jù lọ. (Fi wé Oníwàásù 2:18-21.) Èyí kò dín ìjẹ́pàtàkì ẹ̀kọ́ tí ó yẹ kí àwọn òbí kọ́ ọmọ wọn kù. Dájúdájú, àwọn òbí tí ó bá kọ́ ọmọ wọn ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà Jèhófà ti fún àwọn ọmọ wọn ní àǹfààní tí ó dára jù lọ láti di olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. (Diutarónómì 6:6, 7) Síbẹ̀, láìka bí àwọn òbí wọn ti ṣe lè sapá tó, àwọn ọmọ kan yàn láti tọ ipa ọ̀nà búburú. Àwọn ọmọ mìíràn sì rèé, láìka ipa búburú jù lọ tí àwọn òbí wọn ní lórí wọn sí, wọ́n yàn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì sìn ín. Pẹ̀lú ìbùkún rẹ̀, wọ́n ṣàṣeyọrí nínú ìgbésí ayé wọn. Nígbà mìíràn, o ha ń ṣe kàyéfì bí ọ̀ràn tìrẹ yóò ti rí bí? Nígbà náà, ronú nípa díẹ̀ lára àwọn ohun tí Jèhófà fúnra rẹ̀ mú dá wa lójú tí o fi lè yan ohun tí ó tọ́!
Jèhófà Fọkàn Tán Ọ!
14. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jèhófà mọ ibi tí agbára wá mọ?
14 Kò sóhun tó pa mọ́ lójú Jèhófà. Òwe 15:3 sọ pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ ní ibi gbogbo, ó ń ṣọ́ àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.” Dáfídì Ọba sọ nípa Jèhófà pé: “Àní ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi, inú ìwé rẹ sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀, ní ti àwọn ọjọ́ tí a ṣẹ̀dá wọn, tí ìkankan lára wọn kò sì tíì sí.” (Sáàmù 139:16) Nítorí náà, Jèhófà mọ àwọn ìtẹ̀sí òdì tí o ń bá wọ̀jà—yálà o jogún rẹ̀ ni tàbí o ní wọn gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí àwọn agbára ìdarí mìíràn tí ó ju tìrẹ lọ. Ó mọ bí ìwọ̀nyí ṣe ń nípa lórí rẹ gan-an. O mọ ibi tí agbára rẹ mọ, ju bí ìwọ alára ti mọ̀ ọ́n lọ. Ó sì lójú àánú. Kì í retí kí a ṣe ju bí agbára wa ti mọ lọ.—Sáàmù 103:13, 14.
15. (a) Orísun ìtùnú wo ni ó wà fún àwọn tí àwọn ẹlòmíràn mọ̀ọ́mọ̀ hùwà ìkà sí? (b) Ẹrù iṣẹ́ wo ni Jèhófà fún wa, tí ó buyì kún wa?
15 Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jèhófà kò kà wá sí ẹni tí kò sí ohun tí ó lè ṣe rárá nígbà tí ó bá dojú kọ ìdánwò. Ká ní ẹnì kan ti mọ̀ọ́mọ̀ hùwà ìkà sí wa nígbà kan, a lè rí ìtùnú nínú ìdánilójú náà pé Jèhófà kórìíra irú ìwà tí ń dunni bẹ́ẹ̀ tí ẹnì kan mọ̀ọ́mọ̀ ṣe. (Sáàmù 11:5; Róòmù 12:19) Ṣùgbọ́n, òun yóò ha ràdọ̀ bò wá lọ́wọ́ ìyọrísí ìwà búburú wa bí a bá yí padà, tí a sì mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tí kò tọ́? Rárá o. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Gálátíà 6:5) Jèhófà fi ẹrù iṣẹ́ yíyàn láti ṣe ohun tí ó tọ́, kí wọ́n sì sìn ín, jíǹkí àwọn ẹ̀dá rẹ̀ onílàákàyè. Bí Mósè ṣe sọ ọ́ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni ó rí pé: “Èmi ń fi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí yín lónìí, pé èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ìfiré; kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó, ìwọ àti ọmọ rẹ.” (Diutarónómì 30:19) Ó dá Jèhófà lójú pé àwa pẹ̀lú lè yàn láti ṣe ohun tí ó tọ́. Báwo ni a ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
16. Báwo ni a ṣe lè kẹ́sẹ járí nínú ‘ṣíṣiṣẹ́ ìgbàlà wa yọrí’?
16 Kíyè sí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, . . . ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì; nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbéṣẹ́ ṣe nínú yín, nítorí ti ìdùnnú rere rẹ̀, kí ẹ lè fẹ́ láti ṣe, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀.” (Fílípì 2:12, 13) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà tí a pè ní ‘ṣiṣẹ́ yọrí’ níhìn-ín túmọ̀ sí ṣíṣe nǹkan parí. Nítorí náà, kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí a ti pinnu pé yóò kùnà tàbí pé kò ní lè ṣeé dópin. Jèhófà Ọlọ́run ní ìdánilójú pé a lè parí iṣẹ́ tí òun yàn fún wa—iṣẹ́ tí ń yọrí sí ìgbàlà wa—bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kò ní mí sí irú gbólóhùn bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n báwo ni a óò ṣe kẹ́sẹ járí? Kò lè jẹ́ agbára wa. Ká ní a dá ní agbára tí ó tó ni, kò ní yẹ ká ṣe é pẹ̀lú “ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.” Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, Jèhófà ‘ń gbéṣẹ́ ṣe nínú wa,’ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ nínú èrò inú àti ọkàn-àyà wa, ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti “fẹ́ láti ṣe, kí [a] sì gbé ìgbésẹ̀.” Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ yẹn, kí ló wá lè ṣẹlẹ̀ tí a kò fi ní lè ṣe ohun tí ó tọ́ nínú ìgbésí ayé wa, kí a sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀? Kò yẹ kí ó sí!—Lúùkù 11:13.
17. Ìyípadà wo ni a lè ṣe nínú ara wa, báwo sì ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?
17 A óò ní ìdènà tí a gbọ́dọ̀ borí—ó lè jẹ́ ìwà kan tí ó ti mọ́ wa lára àti àwọn agbára ìdarí abèṣe tí ó lè yí ìrònú wa padà sí búburú. Síbẹ̀síbẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Jèhófà, a lè borí wọn! Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tí ó wà ní Kọ́ríńtì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára tó láti sojú “àwọn nǹkan tí a fìdí wọn múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” dé. (2 Kọ́ríńtì 10:4) Ní tòótọ́, Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìyípadà tí ó yẹ nínú ara wa. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń rọ̀ wá láti “bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀,” kí a sì “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfésù 4:22-24) Ẹ̀mí Jèhófà ha lè ràn wá lọ́wọ́ lóòótọ́ láti ṣe irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀ bí? Dájúdájú! Ẹ̀mí Ọlọ́run ń so èso—àwọn ànímọ́ tí ó dára, tí ó ṣeyebíye, tí gbogbo wa fẹ́ mú dàgbà—nínú wa. Àkọ́kọ́ nínú ìwọ̀nyí ni ìfẹ́.—Gálátíà 5:22, 23.
18. Kí ni olúkúlùkù ènìyàn onílàákàyè lágbára láti yàn, kí sì ni èyí lè ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu?
18 Inú èyí ni òtítọ́ àgbàyanu, tí ń sọni dòmìnira, wà. Agbára tí Jèhófà Ọlọ́run ní láti nífẹ̀ẹ́ kò ní ààlà, ó sì dá wá ní àwòrán rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26; 1 Jòhánù 4:8) Nítorí náà, a lè yàn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ìfẹ́ yẹn ní ń pinnu ọjọ́ ọ̀la wa—kì í ṣe irú ìgbésí ayé tí a kọ́kọ́ gbé, kì í ṣe àwọn àṣìṣe tí a ti ṣe, kì í ṣe ìtẹ̀sí tí a jogún láti ṣe búburú. Ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ni ó yẹ kí Ádámù àti Éfà ní kí wọ́n bàa lè dúró ní olùṣòtítọ́ ní Édẹ́nì. Irú ìfẹ́ yẹn ni ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní kí a lè la Amágẹ́dọ́nì já, kí a sì yege ìdánwò ìkẹyìn ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. (Ìṣípayá 7:14; 20:5, 7-10) Láìka àyíká ipò wa sí, olúkúlùkù wa lè mú ìfẹ́ yẹn dàgbà. (Mátíù 22:37; 1 Kọ́ríńtì 13:13) Ẹ jẹ́ kí a pinnu láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí a sì mú kí ìfẹ́ náà máa pọ̀ sí i títí ayérayé.
Kí Ni Èrò Rẹ?
◻ Èròǹgbà tí ó wọ́pọ̀ wo ni ó ta ko ojú ìwòye tí ó dára tí Bíbélì ní nípa jíjíhìn tí olúkúlùkù yóò jíhìn fún ara rẹ̀?
◻ Iṣẹ́ ìkọ́lé wo ni Kristẹni kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ṣe nínú ara rẹ̀?
◻ Báwo ni àpẹẹrẹ àwọn ọba Júdà ṣe fi hàn pé olúkúlùkù ni ó ń yan ohun tí ó bá fẹ́ ṣe?
◻ Báwo ni Jèhófà ṣe mú un dá wa lójú pé a lè yàn láti ṣe ohun tí ó tọ́ nínú ìgbésí ayé wa, láìka agbára ìdarí búburú tí ó lè yí wa ká sí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ṣé apilẹ̀ àbùdá ni ó ń pinnu ọjọ́ ọ̀la rẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Láìfi àpẹẹrẹ búburú ti baba rẹ̀ pè, Jòsáyà Ọba yàn láti sin Ọlọ́run