Ẹ Máa Sìn Ní Ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́
“Èmi yóò fún àwọn ènìyàn ní ìyípadà sí èdè mímọ́ gaara, kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà, kí wọ́n lè máa sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” —SEFANÁYÀ 3:9.
1. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ Sefanáyà 3:9 bàa lè nímùúṣẹ?
NǸKAN bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] èdè làwọn èèyàn ń sọ jákèjádò ayé. Yàtọ̀ sí ìwọ̀nyí, onírúurú èdè àdúgbò ló tún wà. Àmọ́ báwọn èèyàn tiẹ̀ ń sọ àwọn èdè tó jìnnà síra bí èdè Árábíìkì àti Yorùbá ṣe jìnnà síra tó, síbẹ̀ Ọlọ́run ti ṣe ohun kan tó dìídì jẹ́ àrà ọ̀tọ̀. Ó ti mú kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti kọ́ èdè mímọ́ gaara kan ṣoṣo náà kí wọ́n sì máa sọ ọ́ níbi gbogbo. Èyí ń ṣẹlẹ̀ kí ìlérí kan tó tipasẹ̀ wòlíì Sefanáyà ṣe bàa lè nímùúṣẹ, tó sọ pé: “Èmi [Jèhófà Ọlọ́run] yóò fún àwọn ènìyàn ní ìyípadà sí èdè mímọ́ gaara [ní ṣáńgílítí, “ètè mímọ́ tónítóní”], kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà, kí wọ́n lè máa sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.”—Sefanáyà 3:9.
2. Kí ni “èdè mímọ́ gaara” náà, kí ló sì ti mú kó ṣeé ṣe?
2 Òtítọ́ Ọlọ́run tá a rí nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni “èdè mímọ́ gaara” náà. Òun gan-an ni òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run tó máa sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, tó máa dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láre, tó sì máa mú ìbùkún wá fún ìran ènìyàn. (Mátíù 6:9, 10) Gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà ló ń sọ èdè mímọ́ gaara náà nítorí pé òun nìkan ṣoṣo ni ahọ́n tẹ̀mí tó mọ́ tónítóní lórí ilẹ̀ ayé. Ó mú kí wọ́n lè sin Jèhófà “ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” Wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ń sìn ín ní ìṣọ̀kan tàbí wọ́n ń “fi ọkàn kan sìn i.”—Bibeli Mimọ.
Kò Sí Àyè fún Ojúsàájú
3. Kí ló mú ká lè máa fi ìṣọ̀kan sin Jèhófà?
3 Àwa Kristẹni dúpẹ́ púpọ̀ fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àárín wa láìfi ẹgbàágbèje èdè àbínibí wa tó yàtọ̀ síra pè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń wàásù ìhìn rere náà ní ọ̀pọ̀ èdè táwọn èèyàn ń sọ, síbẹ̀ à ń sin Ọlọ́run ní ìṣọ̀kan. (Sáàmù 133:1) Èyí ṣeé ṣe nítorí pé ibikíbi tá a bá wà lórí ilẹ̀ ayé la ti ń sọ èdè mímọ́ gaara kan ṣoṣo náà sí ìyìn Jèhófà.
4. Kí nìdí tí kò fi yẹ kí ojúsàájú wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run?
4 Kò gbọ́dọ̀ sí ojúsàájú láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi èyí hàn kedere nígbà tó wàásù nílé ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kèfèrí nì, Kọ̀nílíù ní ọdún 36 Sànmánì Tiwa. Ohun tó rí sì mú kó sọ pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn, ìjọ Kristẹni kì í ṣe ibi téèyàn ti ń ṣe ojúsàájú, kì í ṣe ibi téèyàn ti ń dá ẹgbẹ́ ìdákọ́ńkọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ibi tá a ti ń fẹ́ràn ẹnì kan jù ẹnì kejì lọ.
5. Èé ṣe tó fi lòdì láti lọ́wọ́ nínú dídá ẹgbẹ́ ìdákọ́ńkọ́ sílẹ̀ nínú ìjọ?
5 Nígbà tí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga kan ń sọ̀rọ̀ nípa ìbẹ̀wò tó ṣe sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó ní: “Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó bá tinú ẹ̀yà tàbí ìran kan náà wá ló máa ń jókòó tira nínú ṣọ́ọ̀ṣì. . . . Àmọ́ ńṣe làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jókòó pa pọ̀, ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan kì í jókòó lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.” Àmọ́ àwọn kan nínú ìjọ Kọ́ríńtì ìgbàanì ń dá oríṣiríṣi ẹgbẹ́ sílẹ̀. Nípa fífa irú ìyapa bẹ́ẹ̀, wọ́n ń ṣòdì sí ọ̀nà tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà ń ṣiṣẹ́, nítorí pé òun ló ń jẹ́ kí ìṣọ̀kan àti àlàáfíà wà. (Gálátíà 5:22) Bá a bá dá ẹgbẹ́ ìdákọ́ńkọ́ sílẹ̀ nínú ìjọ, ohun tó lòdì sí ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí náà là ń ṣe yẹn. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì sọ́kàn pé: “Mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, nípasẹ̀ orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi pé kí gbogbo yín máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan, àti pé kí ìpínyà má ṣe sí láàárín yín, ṣùgbọ́n kí a lè so yín pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà.” (1 Kọ́ríńtì 1:10) Pọ́ọ̀lù tún tẹnu mọ́ ìṣọ̀kan nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Éfésù.—Éfésù 4:1-6, 16.
6, 7. Ìkìlọ̀ wo ni Jákọ́bù fúnni nípa ṣíṣe ojúsàájú, báwo sì ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe kàn wá?
6 A ti máa ń sọ ọ́ pé àwọn Kristẹni ò gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú. (Róòmù 2:11) Tìtorí pé àwọn kan ń fojú rere hàn sáwọn ọlọ́rọ̀ ní ọ̀rúndún kìíní ni ọmọ ẹ̀yìn nì, Jákọ́bù fi kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ará mi, ẹ kò di ìgbàgbọ́ Olúwa wa Jésù Kristi, ògo wa, mú pẹ̀lú ìṣègbè, àbí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀? Nítorí, bí ọkùnrin kan pẹ̀lú àwọn òrùka wúrà ní àwọn ìka rẹ̀, tí ó sì wọ aṣọ dídángbinrin bá wọlé sínú ìpéjọpọ̀ yín, ṣùgbọ́n tí òtòṣì kan tí ó wọ aṣọ eléèérí pẹ̀lú wọlé, síbẹ̀ tí ẹ fi ojú rere wo ẹni tí ó wọ aṣọ dídángbinrin, tí ẹ sì wí pé: ‘Ìwọ mú ìjókòó yìí tí ó wà níhìn-ín ní ibi tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀,’ tí ẹ sì wí fún òtòṣì náà pé: ‘Ìwọ wà ní ìdúró,’ tàbí: ‘Mú ìjókòó tí ó wà ní ibẹ̀ yẹn lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi,’ ẹ̀yin ní ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ láàárín ara yín, ẹ sì ti di onídàájọ́ tí ń ṣe àwọn ìpinnu burúkú, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?”—Jákọ́bù 2:1-4.
7 Bí àwọn aláìgbàgbọ́ tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ bá kó àwọn òrùka wúrà sọ́wọ́ tí wọ́n sì wọ aṣọ tó ń dán gbinrin wá sípàdé Kristẹni, tí àwọn aláìgbàgbọ́ tó jẹ́ tálákà náà bá wọ aṣọ tó ti fàya wá, wọ́n á ṣìkẹ́ àwọn ọlọ́rọ̀ lọ́nà àkànṣe. Wọ́n á fún wọn ní ìjókòó sí “ibi tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀,” wọ́n á sì sọ fún tálákà pé kó wà ní ìdúró tàbí kó jókòó sílẹ̀ẹ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ ẹnì kan. Àmọ́ àtolówó àti tálákà ni Jèhófà fi àìṣègbè pèsè ẹbọ ìràpadà Jésù fún. (Jóòbù 34:19; 2 Kọ́ríńtì 5:14) Nítorí náà, bá a bá fẹ́ múnú Jèhófà dùn, ká sì sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́, a ò gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú tàbí ‘ká máa kan sáárá sí àwọn ènìyàn jàǹkànjàǹkàn nítorí àǹfààní tara wa.’—Júúdà 4, 16.
Ẹ Sá fún Ìkùnsínú
8. Kí ló ṣẹlẹ̀ nítorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kùn?
8 Tá a bá fẹ́ máa wà níṣọ̀kan ká sì máa rí ojú rere Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sọ́kàn pé: “Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú.” (Fílípì 2:14, 15) Àwọn aláìgbàgbọ́ ọmọ Ísírẹ́lì tá a dá sílẹ̀ kúrò lóko ẹrú Íjíbítì kùn sí Mósè àti Áárónì, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kùn sí Jèhófà Ọlọ́run pàápàá. Nítorí èyí, gbogbo àwọn ọkùnrin láti ogún ọdún sókè ni kò wọ Ilẹ̀ Ìlérí, gbogbo wọn pátá ló kú ní àkókò ìrìn ológójì ọdún nínú aginjù, àyàfi Jóṣúà àti Kálébù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ àtàwọn ọmọ Léfì. (Númérì 14:2, 3, 26-30; 1 Kọ́ríńtì 10:10) Ẹ ò rí i pé ìkùnsínú ò pé wọn rárá!
9. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Míríámù nítorí ìkùnsínú rẹ̀?
9 Èyí fi ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí odindi orílẹ̀-èdè tó bá ń kùn hàn. Ẹnì kọ̀ọ̀kan tó bá jẹ́ oníkùnsínú wá ńkọ́? Tóò, Míríámù, obìnrin tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Mósè àti Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kùn, wọ́n ní: “Ṣé kìkì nípasẹ̀ Mósè nìkan ṣoṣo ni Jèhófà ti gbà sọ̀rọ̀ ni? Kò ha ti sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwa pẹ̀lú bí?” Àkọsílẹ̀ náà fi kún un pé: “Jèhófà sì ń fetí sílẹ̀.” (Númérì 12:1, 2) Kí ni àbájáde rẹ̀? Míríámù tí ẹ̀rí fi hàn pé òun ló mú ipò iwájú nínú ìráhùn yìí ni Ọlọ́run tẹ́ lógo. Lọ́nà wo? Nípa dída ẹ̀tẹ̀ bò ó tí wọ́n sì sọ pé kó lọ máa gbé ní ẹ̀yìn òde ibùdó fún ọjọ́ méje gbáko títí tí ara rẹ̀ fi mọ́.—Númérì 12:9-15.
10, 11. Kí ni ìkùnsínú lè yọrí sí bí a kò bá jáwọ́ ńbẹ̀? Ṣàpèjúwe.
10 Ìkùnsínú kì í ṣe wíwulẹ̀ ṣàwáwí nípa àwọn ìwà àìtọ́ kan. Àwọn tó jẹ́ oníkùnsínú máa ń jọ ara wọn lójú ju bó ti yẹ lọ, wọ́n máa ń pe àfiyèsí si ara wọn dípò Ọlọ́run. Bí wọn ò bá jáwọ́ ńbẹ̀, èyí lè fa ìyapa láàárín àwọn arákùnrin, ó sì lè ṣèdíwọ́ fún ìsapá wọn láti sin Jèhófà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́. Ìdí èyí ni pé àwọn oníkùnsínú máa ń ráhùn pẹ̀lú ìrètí pé àwọn ẹlòmíràn á káàánú wọn.
11 Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lè máa ṣe lámèyítọ́ ọ̀nà tí alàgbà kan gbà ń sọ àsọyé nínú ìjọ tàbí ọ̀nà tó gbà ń bójú tó ẹrù iṣẹ́ rẹ̀. Bí a bá ń fetí sí irú alárìíwísí bẹ́ẹ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí ronú bíi tirẹ̀. Kó tó di pé wọ́n gbin èso àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn sínú ọkàn wa, a ò rí ohun tó burú nínú ìgbòkègbodò alàgbà náà o, àmọ́ a ti wá ń rí i báyìí. Tó bá yá, kò sóhun tí alàgbà náà máa ṣe tó máa tẹ́ wa lọ́rùn, àwa náà sì lè wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àríwísí rẹ̀. Irú ìwà bí èyí kò bójú mu rárá nínú ìjọ àwọn èèyàn Jèhófà.
12. Ipa wo ni ìkùnsínú lè ní lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run?
12 Kíkùn sí àwọn èèyàn tí ojúṣe wọ́n jẹ́ láti bójú tó agbo Ọlọ́run lè yọrí sí kíkẹ́gàn. Irú ìkùnsínú bẹ́ẹ̀ tàbí fífi ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ pe ibi wá sórí wọn lè nípa tí kò dára lórí àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà. (Ẹ́kísódù 22:28) Àwọn olùkẹ́gàn tí kò bá ronú pìwà dà kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 5:11; 6:10) Ọmọ ẹ̀yìn náà, Júdà kọ̀wé nípa àwọn oníkùnsínú tí wọ́n “ń ṣàìka ipò olúwa sí, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ àwọn ẹni ògo tèébútèébú,” ìyẹn àwọn tá a fi ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ nínú ìjọ. (Júúdà 8) Irú àwọn oníkùnsínú bẹ́ẹ̀ kò rí ojú rere Ọlọ́run, ó sì yẹ ká sá fún ipa ọ̀nà búburú wọn.
13. Kí nìdí tí kì í fi í ṣe gbogbo àròyé ló burú?
13 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo àròyé ni kì í múnú Ọlọ́run dùn. Kò fetí pa “igbe ìráhùn” nípa Sódómù àti Gòmórà rẹ́, ńṣe ló pa àwọn ìlú búburú wọ̀nyẹn run. (Jẹ́nẹ́sísì 18:20, 21; 19:24, 25) Ní Jerúsálẹ́mù, kété lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, “ìkùnsínú dìde níhà ọ̀dọ̀ àwọn Júù tí ń sọ èdè Gíríìkì lòdì sí àwọn Júù tí ń sọ èdè Hébérù, nítorí pé àwọn opó wọn ni a ń gbójú fò dá nínú ìpín-fúnni ojoojúmọ́.” Torí èyí, “àwọn méjìlá náà” wá ojútùú sí ọ̀ràn yìí nípa yíyan “ọkùnrin méje tí a jẹ́rìí gbè” sípò lórí “iṣẹ́ àmójútó tí ó pọndandan” ti pípín oúnjẹ. (Ìṣe 6:1-6) Àwọn alàgbà òde òní ò gbọ́dọ̀ ‘di etí wọn’ sí àwọn àròyé tó bá lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. (Òwe 21:13) Dípò tí wọ́n á fi máa ṣe lámèyítọ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, ńṣe ló yẹ káwọn alàgbà máa fún wọn níṣìírí kí wọ́n sì máa gbé wọn ró.—1 Kọ́ríńtì 8:1.
14. Ànímọ́ wo la nílò jù lọ tá a bá fẹ́ sá fún ìkùnsínú?
14 Gbogbo wa ló yẹ ká sá fún níní ìkùnsínú, nítorí pé àròyé ṣíṣe ṣáá kì í gbéni ró nípa tẹ̀mí. Irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ lè ba ìṣọ̀kan àárín wa jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa gba ẹ̀mí mímọ́ láyè kó bàa lè mú ká ní ìfẹ́. (Gálátíà 5:22) Ṣíṣègbọràn sí ‘ọba òfin tó jẹ́ ìfẹ́’ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a lọ ní sísin Jèhófà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.—Jákọ́bù 2:8; 1 Kọ́ríńtì 13:4-8; 1 Pétérù 4:8.
Yẹra fún Ìbanilórúkọjẹ́
15. Báwo lo ṣe máa fìyàtọ̀ sáàárín òfófó àti ìbanilórúkọjẹ́?
15 Níwọ̀n bí ìkùnsínú ti lè yọrí sí òfófó tí ń pani lára, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nípa ohun tá a bá ń sọ. Òfófó jẹ́ àhesọ ọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn tàbí ohun tí wọ́n ń ṣe. Àmọ́ irọ́ pípa láti ba ẹlòmíràn jẹ́ ni ìbanilórúkọjẹ́. Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ burú jáì, Ọlọ́run sì kórìíra rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ máa lọ káàkiri láàárín àwọn ènìyàn rẹ láti fọ̀rọ̀ èké bani jẹ́.”—Léfítíkù 19:16.
16. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn kan tó jẹ́ olófòófó, báwo ló ṣì ṣe yẹ kí ìmọ̀ràn rẹ̀ nípa lórí wa?
16 Nítorí pé àwọn àhesọ ọ̀rọ̀ lè yọrí sí ìbanilórúkọjẹ́ ni Pọ́ọ̀lù ṣe bá àwọn olófòófó kan wí. Lẹ́yìn tó mẹ́nu kan àwọn opó tó yẹ kí ìjọ máa ràn lọ́wọ́, ó tọ́ka sí àwọn opó tí wọ́n kọ́ “láti jẹ́ olóòrayè, wọ́n ń rin ìrìn ìranù kiri lọ sí àwọn ilé; bẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe aláìníṣẹ́ nìkan, ṣùgbọ́n olófòófó pẹ̀lú àti alátojúbọ̀ àlámọ̀rí àwọn ẹlòmíràn, wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí kò yẹ kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.” (1 Tímótì 5:11-15) Bí Kristẹni obìnrin kan bá rí i pé òun máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó lè yọrí sí ìbanilórúkọjẹ́, yóò dára kó fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sọ́kàn láti jẹ́ “oníwà àgbà, kì í ṣe afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́.” (1 Tímótì 3:11) Àmọ́ àwọn Kristẹni ọkùnrin náà gbọ́dọ̀ yẹra fún òfófó tí ń pani lára.— Òwe 10:19.
Ẹ Dẹ́kun Dídánilẹ́jọ́!
17, 18. (a) Kí ni Jésù sọ nípa dídá àwọn arákùnrin wa lẹ́jọ́? (b) Báwo la ṣe lè fi ọ̀rọ̀ Jésù nípa ṣíṣe ìdájọ́ sílò?
17 Tá ò bá tiẹ̀ fọ̀rọ̀ èké ba ẹnikẹ́ni jẹ́, a ní láti sá gbogbo ipá wa láti yẹra fún dídá àwọn mìíràn lẹ́jọ́. Jésù dẹ́bi fún irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́; nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ fi ń dáni lẹ́jọ́, ni a ó fi dá yín lẹ́jọ́; àti òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni, ni wọn yóò fi díwọ̀n fún yín. Èé ṣe tí ìwọ fi wá ń wo èérún pòròpórò tí ó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n tí o kò ronú nípa igi ìrólé tí ó wà nínú ojú ìwọ fúnra rẹ? Tàbí báwo ni ìwọ ṣe lè sọ fún arákùnrin rẹ pé, ‘Yọ̀ǹda fún mi láti yọ èérún pòròpórò kúrò nínú ojú rẹ’; nígbà tí, wò ó! igi ìrólé kan ń bẹ nínú ojú ìwọ fúnra rẹ? Alágàbàgebè! Kọ́kọ́ yọ igi ìrólé kúrò nínú ojú tìrẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì ríran kedere ní ti bí o ṣe lè yọ èérún pòròpórò kúrò nínú ojú arákùnrin rẹ.”—Mátíù 7:1-5.
18 A ò gbọ́dọ̀ sọ pé a fẹ́ ran arákùnrin wa lọ́wọ́ láti bá a yọ “èérún pòròpórò” tó wà lójú rẹ̀ kúrò nígbà tí “igi ìrólé” ìṣàpẹẹrẹ tó wà lójú tiwa náà kò jẹ́ ká lè ṣèdájọ́ bó ṣe yẹ. Ní ti tòótọ́, tá a bá mọrírì bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ aláàánú tó, a ò ní máa dá àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí lẹ́jọ́. Báwo la ṣe lè lóye wọn bí Baba wa ọ̀run ṣe lóye wọn? Abájọ tí Jésù fi kìlọ̀ fún wa láti ‘dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá àwa náà lẹ́jọ́’! Yíyẹ àwọn àìpé ti ara wa wò láìṣàbòsí yóò jẹ́ ká yẹra fún ṣíṣe ìdájọ́ tí Ọlọ́run yóò kà sí àìṣòdodo.
Ẹlẹgẹ́ ni Wọ́n Àmọ́ Wọ́n Ní Ọlá
19. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?
19 Bá a bá pinnu láti sin Ọlọ́run ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, kì í ṣe pé a ó wulẹ̀ yẹra fún dídá wọn lẹ́jọ́ nìkan. A ó tún mú ipò iwájú nínú bíbu ọlá fún wọn pẹ̀lú. (Róòmù 12:10) Kódà àǹfààní tiwọn la ó máa wá, dípò àǹfààní ti ara wa, a ó sì máa fi tayọ̀tayọ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ rírẹlẹ̀ nítorí tiwọn. (Jòhánù 13:12-17; 1 Kọ́ríńtì 10:24) Báwo la ṣe lè ni irú ẹ̀mí rere bẹ́ẹ̀? Nípa rírántí pé gbogbo onígbàgbọ́ ló ṣeyebíye lójú Jèhófà àti pé kòṣeémáàní la jẹ́ fún ara wa, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ẹ̀yà ara ènìyàn ṣe ń gbára lé òmíràn.—1 Kọ́ríńtì 12:14-27.
20, 21. Kí ni ohun tí àwọn ọ̀rọ̀ inú 2 Tímótì 2:20, 21 túmọ̀ sí fún wa?
20 Ká sọ tòótọ́, àwọn Kristẹni jẹ́ ohun èlò tá a fi amọ̀ ṣe tá a gbé ìṣúra iyebíye iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà lé lọ́wọ́. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Bí a bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ mímọ́ yìí sí ìyìn Jèhófà, a gbọ́dọ̀ ní ìdúró tó lọ́lá níwájú òun àti Ọmọ rẹ̀. Kìkì jíjẹ́ mímọ́ ní ti ìwà rere àti nípa tẹ̀mí nìkan la fi lè máa bá a lọ ní jíjẹ́ ohun èlò ọlọ́lá tí Ọlọ́run ń lò. Nítorí èyí ni Pọ́ọ̀lù ṣe kọ̀wé pé: “Nínú ilé ńlá, kì í ṣe àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà nìkan ni ó wà ṣùgbọ́n ti igi àti ohun èlò amọ̀ pẹ̀lú, àwọn kan sì wà fún ète ọlọ́lá ṣùgbọ́n àwọn mìíràn fún ète tí kò ní ọlá. Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá yẹra fún àwọn ti ìkẹyìn yìí, òun yóò jẹ́ ohun èlò fún ète ọlọ́lá, tí a sọ di mímọ́, tí ó wúlò fún ẹni tí ó ni ín, tí a múra sílẹ̀ fún gbogbo iṣẹ́ rere.”—2 Tímótì 2:20, 21.
21 Àwọn tí kò bá hùwà lọ́nà tó bá ohun tí Ọlọ́run fẹ́ mu ni ‘àwọn ohun èlò tí kò ní ọlá.’ Àmọ́, nípa títẹ̀lé ipa ọ̀nà Ọlọ́run, a óò jẹ́ ‘ohun èlò fún ète ọlọ́lá, tí a sọ di mímọ́, tí a yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tí a sì múra sílẹ̀ fún gbogbo iṣẹ́ rere.’ Nítorí náà, a lè wá bi ara wa pé: ‘Ṣé “ohun èlò ọlọ́lá” ni mi? Ǹjẹ́ mo ní ipa tó dára lórí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ mi? Ṣé ọmọ ìjọ tó ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ olùjọ́sìn ni mi?’
Ẹ Máa Bá A Lọ Láti Sìn ní Ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́
22. Kí la lè fi ìjọ Kristẹni wé?
22 Ìjọ Kristẹni dà bí ètò ìdílé. Ìfẹ́, ìrànwọ́, àti ìgbádùn máa ń wà nínú ìdílé kan tí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé náà bá ń jọ́sìn Jèhófà. Ìwà ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé náà lè yàtọ̀ síra o, àmọ́ olúkúlùkù ló ní ipò ọlá tirẹ̀. Bákan náà ló ṣe rí nínú ìjọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wa ò rí bákan náà—aláìpé sì ni wá—síbẹ̀ Ọlọ́run ń fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nípasẹ̀ Kristi. (Jòhánù 6:44; 14:6) Jèhófà àti Jésù nífẹ̀ẹ́ wa, àwa náà sì gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ hàn sí ara wa gẹ́gẹ́ bí ìdílé tó wà níṣọ̀kan.—1 Jòhánù 4:7-11.
23. Kí ló yẹ ká rántí ká sì pinnu láti ṣe?
23 Ìjọ Kristẹni tó dà bí ìdílé tún jẹ́ ibì kan tá a retí pé kí ìdúróṣinṣin wà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo ní ìfẹ́-ọkàn pé ní ibi gbogbo, kí àwọn ọkùnrin máa bá a lọ ní gbígbàdúrà, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ ìdúróṣinṣin sókè, láìsí ìrunú àti ọ̀rọ̀ fífà.” (1 Tímótì 2:8) Pọ́ọ̀lù wá so ìdúróṣinṣin mọ́ àdúrà níwájú àwùjọ “ní ibi gbogbo” táwọn Kristẹni bá ti pàdé pọ̀. Kìkì àwọn ọkùnrin tó jẹ́ adúróṣinṣin ló gbọ́dọ̀ ṣojú fún ìjọ nínú àdúrà. Láìsí àní-àní, gbogbo wa pátá ni Ọlọ́run retí pé ká jẹ́ adúróṣinṣin sí òun àti sí ara wa. (Oníwàásù 12:13, 14) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu láti ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan, bí àwọn ẹ̀yà ara ènìyàn. Ǹjẹ́ kí àwa náà máa sìn ní ìṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ara ìdílé àwọn olùjọsìn Jèhófà. Lékè gbogbo rẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé kòṣeémáàní la jẹ́ fún ara wa, a ó sì gbádùn ojú rere Ọlọ́run àti ìbùkún rẹ̀ bí a bá ń bá a lọ láti sìn Jèhófà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ló mú kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn Jèhófà láti sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́?
• Èé ṣe táwọn Kristẹni fi ń yẹra fún ojúsàájú?
• Kí lo lè sọ pé ó burú nínú ìkùnsínú?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa bọlá fáwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Pétérù wòye pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Ọlọ́run fi tẹ́ Míríámù lógo?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń fi tayọ̀tayọ̀ sin Jèhófà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́