Èé Ṣe Tí Sọ́ọ̀lù Fi Ṣenúnibíni Sáwọn Kristẹni?
‘ÈMI, NÍ TI GIDI RÒ PÉ Ó YẸ KÍ N GBÉ ọ̀pọ̀ ìgbésẹ̀ àtakò lòdì sí orúkọ Jésù ará Násárétì; èyí tí mo ṣe ní Jerúsálẹ́mù ní ti tòótọ́. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹni mímọ́ ni mo tì mọ́ inú ẹ̀wọ̀n, níwọ̀n bí mo ti gba ọlá àṣẹ lọ́wọ́ àwọn olórí àlùfáà. Nígbà tí wọ́n fẹ́ fi ikú pa àwọn ọmọ ẹ̀yìn, mo di ìbò mi lòdì sí wọn. Nípa jíjẹ wọ́n níyà ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní gbogbo sínágọ́gù, mo gbìyànjú láti fi ipá mú wọn láti kó ọ̀rọ̀ wọn jẹ. Níwọ̀n bí orí mi sì ti gbóná sí wọn dé góńgó, mo lọ jìnnà dé ṣíṣe inúnibíni sí wọn, kódà ní àwọn ìlú ńlá tí ń bẹ lẹ́yìn òde.’—Ìṣe 26:9-11.
SỌ́Ọ̀LÙ ará Tásù, táa tún mọ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ló sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí. Àmọ́, nígbà tó fi ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, ó ti di èèyàn ọ̀tọ̀. Kì í tún ṣe alátakò ẹ̀sìn Kristẹni mọ́, ó ti di ọ̀kan lára alágbàwí rẹ̀ tó ní ìtara jù lọ. Ṣùgbọ́n kí ló sún Sọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ tó fi ń ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni? Èé ṣe tó fi rò pé ‘ó yẹ kí òun gbé ọ̀pọ̀ ìgbésẹ̀’ wọ̀nyẹn? Ǹjẹ́ a tilẹ̀ lè rí nǹkan kan kọ́ láti inú ìtàn rẹ̀?
Sísọ̀kúta Pa Sítéfánù
Ìgbà tí Bíbélì kọ́kọ́ mẹ́nu kan orúkọ Sọ́ọ̀lù nìgbà tó ròyìn pé ó bá wọn lọ́wọ́ sí pípa Sítéfánù. “Lẹ́yìn tí wọ́n sì sọ [Sítéfánù] sẹ́yìn òde ìlú ńlá náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ òkúta lù ú. Àwọn ẹlẹ́rìí sì fi ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn lélẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ ọ̀dọ́kùnrin kan tí a ń pè ní Sọ́ọ̀lù.” “Sọ́ọ̀lù, ní tirẹ̀, fọwọ́ sí ṣíṣìkàpa á.” (Ìṣe 7:58; 8:1) Kí ló fa kíkọlu ọkùnrin yẹn? Àwọn Júù, títí kan àwọn kan tó wá láti Sìlíṣíà, bá Sítéfánù ṣe awuyewuye, ṣùgbọ́n ó ta wọ́n yọ. A ò mọ̀ bóyá Sọ́ọ̀lù, tóun náà jẹ́ ará Sìlíṣíà, wà lára wọn. Bó ti wù kó rí, wọ́n bẹ àwọn ẹlẹ́rìí èké lọ́wẹ̀, kí wọ́n lè fẹ̀sùn ìsọ̀rọ̀ òdì kan Sítéfánù, wọ́n sì wọ́ ọ lọ síwájú Sànhẹ́dírìn. (Ìṣe 6:9-14) Àjọ yìí, tí àlùfáà àgbà jẹ́ alága rẹ̀, ni kóòtù gíga àwọn Júù. Gẹ́gẹ́ bí ilé ẹjọ́ gíga jù lọ tí ń rí sọ́ràn ẹ̀sìn, àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ ló tún ń dáàbò bo ohun tí wọ́n kà sí ìjẹ́mímọ́ ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn. Lójú tiwọn, ikú tọ́ sí Sítéfánù. Ó lórí láyà, ó wá ń fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọn kò pa Òfin mọ́, àbí? (Ìṣe 7:53) Kò burú, wọ́n á wá fi hàn án báyìí bí wọ́n ti ń pa á mọ́!
Fífọwọ́sí tí Sọ́ọ̀lù fọwọ́ sí ìpinnu yẹn jẹ́ èrò tó bá ìgbàgbọ́ rẹ̀ mu. Farisí ni. Ẹ̀ya ìsìn lílágbára yìí kan pípa òfin àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ mọ́ títí dóríi bíńtín nípá. Lójú tiwọn, ṣe ni ẹ̀sìn Kristẹni yan irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ lódì, torí pé ó ń fi ọ̀nà tuntun kọ́ni pé nípasẹ̀ Jésù la ti lè rí ìgbàlà. Àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní ń retí pé kí Mèsáyà jẹ́ Ọba ògo tí yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ àjàgà burúkú tí ìṣàkóso Róòmù gbé kọ́ wọn lọ́rùn. Pé ẹni tí Sànhẹ́dírìn Aláṣẹ Ńlá sọ pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn ọ̀rọ̀ òdì, tí wọ́n sì kàn mọ́ òpó igi oró lẹ́yìn náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn tó jẹ́ ẹni ègún, lè wá jẹ́ Mèsáyà, lójú tiwọn èyí ò bá a mu rárá, èrò tí kò ṣeé gbọ́ sétí ni, ó tiẹ̀ kó wọn nírìíra.
Òfin sọ pé “ohun ègún Ọlọ́run” ni ẹni tí a bá gbé kọ́gi. (Diutarónómì 21:22, 23; Gálátíà 3:13) Frederick F. Bruce sọ pé lójú ìwòye Sọ́ọ̀lù, “irú ẹni bí Jésù gan-an lọ̀rọ̀ yìí ń bá wí. Ó kú ikú ègún Ọlọ́run, nípa báyìí, kò tiẹ̀ ṣeé ronú kàn pé òun ni Mèsáyà, tó jẹ́ pé kò lè sí ẹlòmíràn tí Ọlọ́run tún lè bù kún tó o. Torí náà, kéèyàn wá sọ pé Jésù ni Mèsáyà náà jẹ́ ọ̀rọ̀ òdì; ó tọ́ láti fìyà tí wọ́n fi ń jẹ asọ̀rọ̀ òdì jẹ ẹnikẹ́ni tó bá sọ irú ọ̀rọ̀ burúkú bẹ́ẹ̀ jáde lẹ́nu.” Gẹ́gẹ́ bí Sọ́ọ̀lù alára ti jẹ́wọ́ lẹ́yìn náà, èròǹgbà “Kristi tí a kàn mọ́gi, lójú àwọn Júù [jẹ́] okùnfà fún ìkọ̀sẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 1:23.
Ara Sọ́ọ̀lù kọ irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ pátápátá. Kódà kò sóhun tó burú nínú híhùwà òǹrorò, tó bá jẹ́ láti lè tẹ ẹ̀kọ́ yìí rì. Ó dá a lójú pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ nìyí. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù ń ṣàpèjúwe irú ẹ̀mí tí ń bẹ nínú òun, ó sọ pé: “Ní ti ìtara, mo ń ṣe inúnibíni sí ìjọ; ní ti òdodo tí ó jẹ́ nípasẹ̀ òfin, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi.” “Títí dé àyè tí ó pọ̀ lápọ̀jù ni mo ń ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run, tí mo sì ń pa á run, mo sì ń ní ìtẹ̀síwájú púpọ̀ nínú ẹ̀sìn Àwọn Júù ju ọ̀pọ̀ nínú àwọn ojúgbà mi nínú ẹ̀yà mi, níwọ̀n bí mo ti jẹ́ onítara púpọ̀púpọ̀ jù fún àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn baba mi.”—Fílípì 3:6; Gálátíà 1:13, 14.
Ọ̀gá Àwọn Onínúnibíni
Lẹ́yìn ikú Sítéfánù, Sọ́ọ̀lù kò kàn fi mọ sí jíjẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn alátakò, ṣùgbọ́n ó wá di ọ̀gá wọn. Fún ìdí yìí, ó jọ pé òkìkí rẹ̀ wá kàn gan-an, nítorí pé lẹ́yìn tó yí padà pàápàá, tó ń wá bóun ṣe máa dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, “gbogbo wọ́n ń fòyà rẹ̀, nítorí wọn kò gbà gbọ́ pé ọmọ ẹ̀yìn ni.” Nígbà tó ti wá dá àwọn èèyàn lójú pé ó ti di Kristẹni, yíyí tó ti yí padà wá di ohun ayọ̀ àti ìdúpẹ́ láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn, tó gbọ́ pé, kì í kàn-án ṣe pé alátakò kan tẹ́lẹ̀ rí ló yí ọkàn padà, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, pé “ọkùnrin tí ó ṣe inúnibíni sí wa tẹ́lẹ̀ rí ti ń polongo ìhìn rere nísinsìnyí nípa ìgbàgbọ́ náà tí ó pa run tẹ́lẹ̀ rí.”—Ìṣe 9:26; Gálátíà 1:23, 24.
Èyí tí Damásíkù fi jìnnà sí Jerúsálẹ́mù tó nǹkan bí okòó lénígba [220] kìlómítà—ìrìn ọjọ́ méje sí mẹ́jọ. Síbẹ̀, nínú “èémí ìhalẹ̀mọ́ni àti ìṣìkàpànìyàn sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn,” Sọ́ọ̀lù lọ bá àlùfáà àgbà, ó ní kí ó fóun ní lẹ́tà tóun yóò mú lọ sáwọn sínágọ́gù tó wà ní Damásíkù. Èé ṣe? Nítorí kí Sọ́ọ̀lù lè mú ẹnikẹ́ni tó bá rí tó jẹ́ ti “Ọ̀nà Náà” wá sí Jerúsálẹ́mù ní dídè. Pẹ̀lú ìwé àṣẹ tó ti tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́, ó ‘bẹ̀rẹ̀ sí hùwà sí ìjọ lọ́nà bíburú jáì, ó ń gbógun ti ilé kan tẹ̀ lé òmíràn, ó ń wọ́ àti ọkùnrin àti obìnrin jáde, ó ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n.’ Ó ‘ń na àwọn mìíràn lẹ́gba ní sínágọ́gù,’ ó sì ‘di ìbò’ (ní ṣáńgílítí, “òkúta wẹ́wẹ́ tí ó fi dìbò”) pé kí wọ́n pa wọ́n.—Ìṣe 8:3; 9:1, 2, 14; 22:5, 19; 26:10, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, New World Translation of the Holy Scriptures—With References.
Nígbà táwọn ọ̀mọ̀wé kan ronú nípa irú ẹ̀kọ́ tí Gàmálíẹ́lì kọ́ Sọ́ọ̀lù, àti agbára tó ní nísinsìnyí, wọ́n gbà gbọ́ pé kì í wúlẹ̀ ṣe ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Òfin mọ́, ó ti gòkè àgbà báyìí débi pé ó láṣẹ nínú ẹ̀sìn àwọn Júù. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀mọ̀wé kan tilẹ̀ gbà pé Sọ́ọ̀lù lè ti di olùkọ́ nínú sínágọ́gù kan ní Jerúsálẹ́mù. Ṣùgbọ́n o, a ò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú ohun tí ‘dídìbò’ tí Sọ́ọ̀lù sọ pé òun dìbò túmọ̀ sí—bóyá ohun tó túmọ̀ sí ni jíjẹ́ ọmọ ìgbìmọ̀ ilé ẹjọ́ kan tàbí ẹnì kan tó ń ṣètìlẹyìn fún pípa tí wọ́n ń pa àwọn Kristẹni—a ò lè sọ.a
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé láàárọ̀ ọjọ́ ẹ̀sìn Kristẹni, Júù tàbí àwọn aláwọ̀ṣe ni gbogbo àwọn tí ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀hún, ohun tí Sọ́ọ̀lù ka ẹ̀sìn Kristẹni sí ni ẹgbẹ́ apẹ̀yìndà nínú ẹ̀sìn àwọn Júù, ó sì gbà pé ó jẹ́ ojúṣe àwọn aláṣẹ ẹ̀sìn Júù láti tọ́ àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ sọ́nà. Ọ̀mọ̀wé náà, Arland J. Hultgren, sọ pé: “Ó jọ pé Pọ́ọ̀lù onínúnibíni kì bá ta ko ẹ̀sìn Kristẹni ká ní ó rí i gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn kan tí kì í ṣe apá kan ẹ̀sìn àwọn Júù, ẹ̀sìn tó ń bá tiwọn díje. Ó jọ pé ojú tí òun àtàwọn mìíràn fi wo ẹ̀sìn Kristẹni ni pé abẹ́ àṣẹ àwọn Júù ló ṣì wà.” Fún ìdí yìí, ìpinnu rẹ̀ ni láti fagbára mú àwọn Júù tó ti ṣáko lọ láti ṣẹ́rí padà, kí wọ́n sì padà sínú ẹ̀sìn tí gbogbo èèyàn ń ṣe, ó sì fẹ́ gbé e gba gbogbo ọ̀nà tó bá mọ̀ pé òun lè gbà ṣe é. (Ìṣe 26:11) Ọ̀nà kan tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ̀ ni fífi wọ́n sẹ́wọ̀n. Ọ̀nà mìíràn ni nínà wọ́n lọ́rẹ́ nínú sínágọ́gù, ọ̀nà ìfìyàjẹni tó wọ́pọ̀, tí wọ́n lè lò gẹ́gẹ́ bí ìbáwí nítorí àìgbọràn sí ọlá àṣẹ àwọn rábì nínú gbogbo àwọn kóòtù ìbílẹ̀ tó ní adájọ́ mẹ́ta.
Àmọ́ o, fífarahàn tí Jésù fara han Sọ́ọ̀lù lójú ọ̀nà Dámásíkù mú gbogbo ìyẹn wá sópin. Látorí jíjẹ́ ọ̀tá tó ń fi torítọrùn gbógun ti ẹ̀sìn Kristẹni, lójijì Sọ́ọ̀lù di onítara alágbàwí rẹ̀, kò sì pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn làwọn Júù tó wà ní Damásíkù fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀. (Ìṣe 9:1-23) Ó wá jẹ́ ìyàlẹ́nu pé, nígbà tí Sọ́ọ̀lù di Kristẹni, ó fojú winá ọ̀pọ̀ nǹkan tóun alára ṣe nígbà tó ń ṣe inúnibíni, èyí ló fi wá sọ lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà pé: “Ìgbà márùn-ún ni mo gba ẹgba ogójì dín ọ̀kan láti ọwọ́ àwọn Júù.”—2 Kọ́ríńtì 11:24.
Ìtara Lè Gbọ̀nà Òdì
Lẹ́yìn tí a yí Sọ́ọ̀lù, táa wá ń pè ní Pọ́ọ̀lù lọ́kàn padà, ó kọ̀wé pé: “Tẹ́lẹ̀ rí mo jẹ́ asọ̀rọ̀ òdì àti onínúnibíni àti aláfojúdi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a fi àánú hàn sí mi, nítorí tí mo jẹ́ aláìmọ̀kan, tí mo sì gbé ìgbésẹ̀ nínú àìnígbàgbọ́.” (1 Tímótì 1:13) Nítorí náà, jíjẹ́ olóòótọ́ àti aláápọn nínú ẹ̀sìn téèyàn ń ṣe kò túmọ̀ sí pé èèyàn ti rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run. Sọ́ọ̀lù jẹ́ onítara, ó sì ń ṣe ohun tí ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ ní kó ṣe, ṣùgbọ́n ìyẹn ò wá fi hàn pé ohun tó ṣe dáa. Ìtara òdì ni ìtara ajóbíiná tó ní. (Fi wé Róòmù 10:2, 3.) Ó yẹ kí ìyẹn mú wa ronú jinlẹ̀.
Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pẹ̀lú ìdánilójú pé kéèyàn sáà ti máa ṣe dáadáa ni gbogbo ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Ṣùgbọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ni? Ó dáa kí kálukú fetí sílẹ̀ dáadáa sí ọ̀rọ̀ ìyànjú Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú; ẹ di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin.” (1 Tẹsalóníkà 5:21) Èyí túmọ̀ sí lílo àkókò láti fi wá ìmọ̀ pípéye nínú Ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run, kí a sì máa gbé ní ìbámu kíkún pẹ̀lú òtítọ́ náà. Báa bá rí i nígbà táa ń ṣàyẹ̀wò Bíbélì pé ó yẹ ká ṣe àwọn ìyípadà kan, ó yẹ ká tara ṣàṣà ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀. Bóyá la fi lè rí lára wa tó ti jẹ́ asọ̀rọ̀ òdì, onínúnibíni, tàbí aláfojúdi tó ti Sọ́ọ̀lù. Síbẹ̀, àyàfi báa bá gbé ìgbésẹ̀ tó bá ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ pípéye mu nìkan la fi lè jèrè ojú rere Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe.—Jòhánù 17:3, 17.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, The History of the Jewish People in the Age of Jesus Christ (175 B.C.–A.D. 135), látọwọ́ Emil Schürer, ti wí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Mishnah kò sọ nǹkan kan nípa ìlànà tí Sànhẹ́dírìn Aláṣẹ Ńlá, tàbí Sànhẹ́dírìn Ẹlẹ́ni Mọ́kànléláàádọ́rin ń tẹ̀ lé, Mishnah sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìlànà táwọn Sànhẹ́dírìn kéékèèké, àwọn tó ní mẹ́ńbà mẹ́tàlélógún, ń tẹ̀ lé. Àwọn tí ń kẹ́kọ̀ọ́ láti di amòfin lè lọ síbi táwọn Sànhẹ́dírìn kéékèèké ti ń gbọ́ àwọn ẹjọ́ ńláńlá, a sì gbà wọ́n láyè láti rojọ́ gbe ẹni táa fẹ̀sùn kàn, ṣùgbọ́n kì í ṣe láti ṣe rojọ́ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀. Nínú àwọn ẹjọ́ tí kì í bá ṣe ẹjọ́ ńlá, wọ́n lè rojọ́ gbe ẹni táa fẹ̀sùn kàn, wọ́n sì lè rojọ́ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀.