“Iṣẹ́-ìsìn Mímọ́-Ọlọ́wọ̀ Pẹ̀lú Agbára Ìmọnúúrò Yín”
“[Ẹ] fi ara yín fún Ọlọrun ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ pẹlu agbára ìmọnúúrò yín.”—ROMU 12:1.
1, 2. Báwo ni kíkọ́ láti máa fi àwọn ìlànà Bibeli sílò ṣe dàbí dídọ̀gá nínú èdè titun?
O HA ti gbìyànjú láti kọ́ èdè titun rí bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò gbà láì ṣiyèméjì pé ó jẹ́ iṣẹ́ tí ó nira. Ó ṣetán, ohun púpọ̀ síi wémọ́ ọn ju wíwulẹ̀ kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ titun. Lílò èdè kan lọ́nà tí ó dánmọ́rán tún ń béèrè pé kí a dọ̀gá nínú gírámà rẹ̀. O gbọ́dọ̀ wòye ìsopọ̀ tí ó wà láàárín àwọn ọ̀rọ̀ kan sí ìkejì àti bí wọ́n ṣe ń parapọ̀ di èrò tí ó pé pérépéré.
2 Ó farajọ gbígbà tí a gba ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sínú. Ohun púpọ̀ síi wémọ́ ọn ju wíwulẹ̀ kọ́ àwọn àṣàyàn ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́. A gbọ́dọ̀ kọ́ gírámà Bibeli pẹ̀lú, kí a sọ ọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ó yẹ kí a lóye bí àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ ṣe ní ìsopọ̀ pẹ̀lú èkínní kejì àti bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a lè fi sílò nínú ìgbésí-ayé ojoojúmọ́. A lè tipa bẹ́ẹ̀ di ẹni tí ó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbaradì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Timoteu 3:17.
3. Nípa iṣẹ́-ìsìn sí Ọlọrun, ìyípadà wo ni ó ṣẹlẹ̀ ní 33 C.E.?
3 Lábẹ́ ìṣètò àkójọ Òfin Mose, a lè fi ìṣòtítọ́ hàn, dé ìwọ̀n àyè gíga, nípa rírọ̀ tímọ́tímọ́ láìgba gbẹ̀rẹ́ mọ́ àwọn ìlànà tí a mú ṣe kedere. Bí ó ti wù kí ó rí, ní 33 C.E., Jehofa pa Òfin náà rẹ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ “kàn án níṣòó mọ́ òpó igi oró” lórí èyí tí a ti pa Ọmọkùnrin rẹ̀. (Kolosse 2:13, 14) Lẹ́yìn náà, a kò fún àwọn ènìyàn Ọlọrun ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ jàn-ànràn jan-anran ti àwọn ẹbọ tí wọ́n níláti máa rú àti ìlànà tí wọ́n níláti máa tẹ̀lé. Kàkà bẹ́ẹ̀, a sọ fún wọn pé: “[Ẹ] fi ara yín fún Ọlọrun ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ pẹlu agbára ìmọnúúrò yín.” (Romu 12:1) Bẹ́ẹ̀ni, àwọn Kristian níláti lo ara wọn tokunra tokunra, pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà, ọkàn, èrò-inú, àti okun nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun. (Marku 12:30; fiwé Orin Dafidi 110:3.) Ṣùgbọ́n kí ni ó túmọ̀ sí láti rúbọ “iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ pẹlu agbára ìmọnúúrò yín”?
4, 5. Kí ni ohun tí ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò wa wémọ́?
4 Àpólà-ọ̀rọ̀ náà “agbára ìmọnúúrò” ni a túmọ̀ láti inú ọ̀rọ̀ Griki náà lo·gi·kosʹ, èyí tí ó túmọ̀ sí “ọgbọ́n ìrònú rere” tàbí “òye.” A késí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun láti lo ẹ̀rí-ọkàn wọn tí a ti fi Bibeli dálẹ́kọ̀ọ́. Dípò gbígbé àwọn ìpinnu wọn karí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ òfin tí a ti gbékalẹ̀ ṣáájú, àwọn Kristian níláti wọn àwọn ìlànà Bibeli wò dáradára. Wọ́n níláti lóye “gírámà” Bibeli, tàbí bí onírúurú ìlànà rẹ̀ ṣe ní ìsopọ̀ pẹ̀lú èkínní kejì. Nípa báyìí, wọ́n lè fi agbára ìmọnúúrò wọn ṣe àwọn ìpinnu tí ó wà déédéé.
5 Èyí ha túmọ̀ sí pé àwọn Kristian wà láìlófin bí? Rárá kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní kedere ka ìbọ̀rìṣà, ìwà pálapàla takọtabo, ìpànìyàn, irọ́ pípa, ìbẹ́mìílò, àṣìlò ẹ̀jẹ̀, àti onírúurú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn léèwọ̀. (Ìṣe 15:28, 29; 1 Korinti 6:9, 10; Ìṣípayá 21:8) Síbẹ̀, dé ìwọ̀n gíga fíìfíì ju ohun tí a béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israeli lọ, a gbọ́dọ̀ lo agbára ìmọnúúrò wa láti kọ́ àwọn ìlànà Bibeli kí a sì fi wọ́n sílò. Lọ́nà tí ó jọra pẹ̀lú lílóye èdè titun kan, èyí ń gba àkókò àti ìsapá. Báwo ni a ṣe lè mú agbára ìmọnúúrò wa dàgbà?
Mímú Agbára Ìmọnúúrò Rẹ Dàgbà
6. Kí ni kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wémọ́?
6 Lákọ̀ọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ń háragàgà. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí a mí sí “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́nisọ́nà, fún mímú awọn nǹkan tọ́, fún ìbániwí ninu òdodo.” (2 Timoteu 3:16) A kò níláti máa retí nígbà gbogbo pé kí a rí ìdáhùn sí ìṣòro nínú ẹsẹ̀ Bibeli kanṣoṣo. Kàkà bẹ́ẹ̀, a lè níláti ronú lórí àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ mélòókan tí ó tànmọ́lẹ̀ sórí ipò kan ní pàtàkì tàbí ìṣòro kan. A óò níláti ṣe ìwádìí aláápọn fún ìrònú Ọlọrun lórí ọ̀ràn náà. (Owe 2:3-5) A tún nílò òye, nítorí pé “ọkùnrin tí ó ní òye ni ẹni náà tí ó ní ìdarítọ́sọ́nà tí ó kún fún òye-iṣẹ́.” (Owe 1:5, NW) Olóye ènìyàn lè ya àwọn kókó abájọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ọ̀ràn kan sọ́tọ̀ kí ó sì wòye ìsopọ̀ wọn pẹ̀lú èkínní kejì. Gẹ́gẹ́ bí a óò ti ṣe pẹ̀lú ohun kan tí ó rúnilójú, olóyè ènìyàn náà yóò to àwọn ohun rírúnilójú náà pọ̀ kí ó baà lè rí àwòrán wọn lódiidi.
7. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè ronú lórí ìlànà Bibeli nípa ìbáwí?
7 Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn jíjẹ́ òbí yẹ̀wò. Owe 13:24 sọ pé bàbá tí ó nífẹ̀ẹ́ ọmọkùnrin rẹ̀ “a máa tètè nà án.” Bí a bá ronú lórí ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ yìí nìkan, ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ yìí ni a lè ṣìlò láti dá ìfìyàjẹni tí ó le koko, tí a kò sì dáwọ́ rẹ̀ dúró láre. Síbẹ̀, Kolosse 3:21 pèsè ìgbaniníyànjú tí ó wà déédéé pé: “Ẹ̀yin baba, ẹ máṣe máa dá awọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má baà soríkodò.” Àwọn òbí tí wọ́n bá ń lo agbára ìmọnúúrò wọn tí wọ́n sì mú kí àwọn ìlànà wọ̀nyí báramuṣọ̀kan kì yóò fàbọ̀ sórí ìbáwí tí a lè pè ní “oníkà.” Wọn yóò hùwà sí àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú ọ̀yàyà, òye, àti iyì. (Efesu 6:4) Nípa bẹ́ẹ̀, níti ọ̀ràn jíjẹ́ òbí tàbí níti ọ̀ràn mìíràn tí ó wémọ́ àwọn ìlànà Bibeli, a lè mú agbára ìmọnúúrò wa dàgbà nípa wíwọn gbogbo kókó abájọ tí ó so pọ̀ mọ́ ọn wò. Ní ọ̀nà yìí, a lè wòye “gírámà” àwọn ìlànà Bibeli, ohun tí ète Ọlọrun jẹ́ àti bí a ṣe lè ṣàṣeparí ìyẹn.
8. Báwo ni a ṣe lè yẹra fún níní ojú-ìwòye aláìṣeé yípadà, ti tèmi-ni-kí-o-gbà nígbà tí ó bá di ọ̀ràn eré-ìnàjú?
8 Ọ̀nà kejì tí a lè gbà mú agbára ìmọnúúrò wa dàgbà ni láti yẹra fún lílo ojú-ìwòye aláìṣeé yípadà, ti tèmi-ni-kí-o-gbà. Ojú-ìwòye tí kò ṣeé yípadà ń ké ìdàgbàsókè agbára ìmọnúúrò wa nígbèrí. Gbé ọ̀ràn eré-ìnàjú yẹ̀wò. Bibeli sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa.” (1 Johannu 5:19) Èyí ha túmọ̀ sí pé gbogbo ìwé, sinimá, tàbí ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n tí ayé mújáde ni ó jẹ́ oníwà ìbàjẹ́ àti ti Satani bí? Ekukáká ni irú ojú-ìwòye bẹ́ẹ̀ fi lè lọ́gbọ́n nínú. Àmọ́ ṣáá o, àwọn kan lè yàn láti yẹra fún tẹlifíṣọ̀n, sinimá, tàbí àwọn ìwé ayé látòkèdélẹ̀. Ẹ̀tọ́ tiwọn nìyẹn, a kò sì níláti ṣe lámèyítọ́ wọn nítorí rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn náà pẹ̀lú kò níláti gbìyànjú láti lo ipa ìdarí lórí àwọn ẹlòmíràn láti ká ara wọn lọ́wọ́ kò lọ́nà tí ó dàbí tiwọn. Society ti tẹ àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ jáde tí ń gbé àwọn ìlànà Bibeli kalẹ̀ tí ó níláti ràn wá lọ́wọ́ láti lè jẹ́ ẹni tí ń fọgbọ́n yan eré-ìtura tàbí eré-ìnàjú wa. Lílọ rékọjá awọn atọ́nà wọ̀nyí kí a sì jọ̀wọ́ ara wa fún ìrònú oníwà pálapàla, ìwà-ipá bíburú lékenkà, tàbí ìbẹ́mìílò tí ó wà nínú púpọ̀ lára àwọn eré-ìnàjú ti ayé yìí kò bọ́gbọ́nmu rárá. Níti tòótọ́, yíyàn tí ó bọ́gbọ́nmu níti eré-ìnàjú ń béèrè pé kí a lo agbára ìmọnúúrò wa láti fi àwọn ìlànà Bibeli sílò kí a baà lè ní ẹ̀rí-ọkàn mímọ́ gaara níwájú Ọlọrun àti ènìyàn.—1 Korinti 10:31-33.
9. Kí ni “ìfòyemọ̀ kíkún” túmọ̀ sí?
9 Púpọ̀ lára àwọn eré-ìnàjú òde-òní ni ó ṣe kedere pé kò dára fún Kristian.a Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ dá ọkàn-àyà wa lẹ́kọ̀ọ́ láti “kórìíra ibi” kí a má baà dàbí àwọn kan ní ọ̀rúndún kìn-ínní tí wọ́n “rékọjá gbogbo agbára òye ìwàrere.” (Orin Dafidi 97:10; Efesu 4:17-19) Láti ronú lórí irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, a nílò “ìmọ̀ pípéye ati ìfòyemọ̀ kíkún.” (Filippi 1:9) Ọ̀rọ̀ Griki náà tí a túmọ̀ sí “ìfòyemọ̀” dúró fún “agbára ìmòye ìwàrere tí ó ṣeé tètè mọ̀lára.” Ọ̀rọ̀ náà ní ṣangiliti tọ́ka sí agbára ìmòye ti ẹ̀dá ènìyàn, irú bí ìríran. Nígbà tí ó ba kan ọ̀ràn eré-ìnàjú tàbí ọ̀ràn mìíràn tí ó ń béèrè ìpinnu ara-ẹni, a níláti darí agbára ìmòye ìwàrere wa sí ọ̀nà kan kí a baà lè wòye kì í ṣe kìkì àwọn ohun tí a ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀, ní ọ̀nà tí ó ṣe kedere ṣùgbọ́n àwọn wọnnì tí a kò ṣàlàyé délẹ̀délẹ̀. Ní àkókò kan náà, a níláti yẹra fún lílo àwọn ìlànà Bibeli dé àwọn ayé kan tí kò lọ́gbọ́n nínú kí a sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé gbogbo àwọn ará wa níláti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.—Filippi 4:5.
10. Báwo ni a ṣe lè lóye àkópọ̀ ànímọ́ Jehofa bí a ṣe fi í hàn nínú Orin Dafidi 15?
10 Ọ̀nà kẹta láti mú agbára ìmọnúúrò wa dàgbà ni láti mọ agbára ìmòye ti ìrònú Jehofa kí a sì gbìn ín jinlẹ̀ jinlẹ̀ sínú ọkàn-àyà wa. Nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Jehofa ṣí àkópọ̀ ànímọ́ rẹ̀ àti ọ̀pá ìdiwọ̀n rẹ̀ payá. Fún àpẹẹrẹ, ní Orin Dafidi 15, a kà nípa irú ẹni tí Jehofa késí láti jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ̀. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń hùwà òdodo, ń sọ òtítọ́ láti inú ọkàn-àyà rẹ̀, ó ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, kì í sìí rẹ́ àwọn ẹlòmíràn jẹ. Bí o ṣe ń ka psalmu yìí, béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Àwọn ànímọ́ wọ̀nyí ha ṣàpèjúwe mi bí? Jehofa yóò ha késí mi láti jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ̀ bí?’ Agbára ìwòye wa ni a ń fún lókun bí a ṣe ń wà ní ìbáramuṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ọ̀nà àti ìrònú Jehofa.—Owe 3:5, 6; Heberu 5:14.
11. Báwo ni àwọn Farisi ṣe “gbójúfo ìdájọ́-òdodo ati ìfẹ́ fún Ọlọrun”?
11 Apá yìí gan-an ni àwọn Farisi ti kùnà lọ́nà tí ó múnibanújẹ́ gidigidi. Àwọn Farisi mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìlànà kókó ìpìlẹ̀ Òfin ṣùgbọ́n wọn kò róye “gírámà” rẹ̀. Wọ́n lè ka ẹgbàágbèje kúlẹ̀kúlẹ̀ Òfin ní àkàsórí, ṣùgbọ́n wọ́n kùnà láti lóye Àkópọ̀ Ànímọ́ ẹni tí ó wà lẹ́yìn rẹ̀. Jesu sọ fún wọn pé: “Ẹ ń fúnni ní ìdámẹ́wàá efinrin ati ewéko rue ati gbogbo ewébẹ̀ mìíràn, ṣugbọn ẹ̀yin ń gbójúfo ìdájọ́ òdodo ati ìfẹ́ fún Ọlọrun!” (Luku 11:42) Pẹ̀lú èrò-inú wọn tí kò ṣeé yípadà àti ọkàn-àyà wọn tí ó lekoko, àwọn Farisi kùnà láti lo agbára ìmọnúúrò wọn. Ìrònú wọn tí kò ṣe déédéé fara hàn nígbà tí wọ́n ṣe lámèyítọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu fún yíya erín ọkà tí wọ́n sì ń jẹ kóró rẹ̀ ní ọjọ́ Sábáàtì; síbẹ̀, lẹ́yìn àkókò díẹ̀ ní ọjọ́ kan náà, ẹ̀rí-ọkàn wọn kò dá wọn lẹ́bi rárá nígbà tí wọ́n dìmọ̀ pọ̀ láti pa Jesu!—Matteu 12:1, 2, 14.
12. Báwo ni a ṣe lè túbọ̀ wà ní ìbáramuṣọ̀kan pẹ̀lú Jehofa gẹ́gẹ́ bí Ẹnì Kan?
12 A fẹ́ láti yàtọ̀ sí àwọn Farisi. Ìmọ̀ wa nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbọ́dọ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ wà ní ìbáramuṣọ̀kan pẹ̀lú Jehofa gẹ́gẹ́ bí Ẹnì Kan. Báwo ni a ṣe lè ṣe èyí? Lẹ́yìn kíka apákan nínú Bibeli tàbí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a gbékarí Bibeli, a ti ran àwọn kan lọ́wọ́ nípa sísinmẹ̀dọ̀ ronú lórí àwọn ìbéèrè báwọ̀nyí, ‘Kí ni ìsọfúnni yìí kọ́ mi nípa Jehofa àti àwọn ànímọ́ rẹ̀? Báwo ni mo ṣe lè fi àwọn ànímọ́ Jehofa hàn nínú ìbálò mi pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn?’ Ṣíṣàṣàrò lórí irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ ń mú kí agbára ìmọnúúrò wa dàgbà ó sì ń mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti di “aláfarawé Ọlọrun.”—Efesu 5:1.
Ẹrú Ọlọrun àti Kristi, Kì í Ṣe ti Ènìyàn
13. Báwo ni àwọn Farisi ṣe hùwà gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ bóofẹ́-bóokọ̀ níti ìwàrere?
13 Àwọn alàgbà níláti fàyègba àwọn wọnnì tí wọ́n wà lábẹ́ àbójútó wọn láti lo agbára ìmọnúúrò wọn. Àwọn mẹ́ḿbà ìjọ kì í ṣe ẹrú ènìyàn. Paulu kọ̀wé pé: “Bí emi bá ṣì ń wu awọn ènìyàn, emi kì yoo jẹ́ ẹrú Kristi.” (Galatia 1:10; Kolosse 3:23, 24) Ní ìyàtọ̀ gédégbé, àwọn Farisi fẹ́ kí àwọn ènìyàn gbàgbọ́ pé ó ṣe pàtàkì jù láti jèrè ìtẹ́wọ́gbà ènìyàn ju ti Ọlọrun lọ. (Matteu 23:2-7; Johannu 12:42, 43) Àwọn Farisi yan ara wọn sípò aláṣẹ bóofẹ́-bóokọ̀ níti ìwàrere, wọ́n ń gbé àwọn ìlànà tiwọn kalẹ̀ wọ́n sì ń ṣèdájọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa bí wọn ṣe kúnjú ìwọ̀n tó. Àwọn wọnnì tí ń tẹ̀lé àwọn Farisi ni a sọ di aláìlera níti lílo ẹ̀rí-ọkàn wọn tí a ti fi Bibeli dálẹ́kọ̀ọ́, nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n di ẹrú ènìyàn.
14, 15. (a) Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè fi ara wọn hàn pé àwọn jẹ́ òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ pẹ̀lú agbo? (b) Báwo ni àwọn alàgbà ṣe níláti yanjú àwọn ọ̀ràn ẹ̀rí-ọkàn?
14 Àwọn Kristian alàgbà lónìí mọ̀ pé ní pàtàkì jùlọ agbo náà kì yóò jíhìn fún wọn. Kristian kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ ru ẹrù tirẹ̀. (Romu 14:4; 2 Korinti 1:24; Galatia 6:5) Bí ó ṣe yẹ kí ó rí nìyí. Níti tòótọ́, bí àwọn mẹ́ḿbà agbo náà bá níláti jẹ́ ẹrú ènìyàn, tí wọ́n ń ṣègbọràn kìkì nítorí pé a ń sọ́ wọn lọ́wọ́lẹ́sẹ̀, kí ni wọn yóò ṣe nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn kò bá sí nítòsí? Paulu ní ìdí láti ní ìdùnnú-ayọ̀ nítorí àwọn ará Filippi: “Ní ọ̀nà tí ẹ ń gbà ṣègbọràn nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣugbọn nísinsìnyí pẹlu ìmúratán púpọ̀ sí i nígbà tí emi kò sí lọ́dọ̀ yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà tiyín yọrí pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì.” Nítòótọ́ ẹrú Kristi ni wọ́n, kì í ṣe ti Paulu.—Filippi 2:12.
15 Nítorí náà, níti àwọn ọ̀ràn ẹ̀rí-ọkàn, àwọn alàgbà kì í ṣe ìpinnu fún àwọn wọnni tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó wọn. Wọ́n ń ṣàlàyé àwọn ìlànà Bibeli tí ó wémọ́ ọ̀ràn kan wọn yóò sì yọ̀ọ̀da fún àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn láti lo agbára ìmọnúúrò wọn láti ṣe ìpinnu. Èyí jẹ́ ẹrù-iṣẹ́ bàǹtà-banta kan, síbẹ̀ ó jẹ́ ọ̀kan tí ẹni náà fúnra rẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣe.
16. Ètò-ìgbékalẹ̀ wo ni ó wà ní Israeli fún yíyanjú àwọn ìṣòro?
16 Ronú nípa àkókò náà nígbà tí Jehofa lo àwọn onídàájọ́ láti tọ́ Israeli sọ́nà. Bibeli sọ fún wa pé: “Ní ọjọ́ wọnnì ọba kan kò sí ní Israeli: olúkúlùkù ń ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú ara rẹ̀.” (Onidajọ 21:25) Síbẹ̀ Jehofa pèsè ọ̀nà láti gba ìtọ́sọ́nà fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Ìlú-ńlá kọ̀ọ̀kan ní àwọn àgbà ọkùnrin tí ó lè pèsè ìrànwọ́ tí ó gbámúṣé fún àwọn ìbéèrè àti ìṣòro. Ní àfikún síi, àwọn àlùfáà ọmọ Lefi ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ipá fún rere nípa kíkọ́ àwọn ènìyàn ní òfin Ọlọrun. Nígbà tí àwọn ọ̀ràn tí ó nira ní pàtàkì bá dìde, àlùfáà àgbà lè bá Ọlọrun sọ̀rọ̀ nípa lílò Urimu àti Tummimu. Gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures ṣàlàyé pé: “Ẹni náà tí ó bá yọ̀ọ̀da ara rẹ̀ fún ìpèsè wọ̀nyí, tí ó jèrè ìmọ̀ òfin Ọlọrun tí ó sì fi í sílò, ní atọ́nà yíyèkooro fún ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀. Ṣíṣe ohun tí ‘ó tọ̀nà ní ojú ara rẹ̀’ nínú irú ọràn bẹ́ẹ̀ kì yóò yọrí sí ibi. Jehofa yọ̀ọ̀da fún àwọn ènìyàn náà láti fi ìṣarasíhùwà àti ipa-ọ̀nà onímùúratán tàbí aláìmúratán hàn.”—Ìdìpọ̀ 2, ojú-ìwé 162 sí 163.b
17. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè fi hàn pé àwọn ń fúnni nímọ̀ràn ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọrun dípò tiwọn?
17 Bíi ti àwọn onídàájọ́ Israeli àti àwọn àlùfáà, àwọn alàgbà ìjọ ń pèsè ìrànlọ́wọ́ tí ó gbámúṣé fún àwọn ìṣòro wọ́n sì ń fúnni ní ìmọ̀ràn tí ó níyelórí. Nígbà mìíràn, wọ́n lè “fi ìbáwí tọ́nisọ́nà, bániwí kíkankíkan, gbaniníyànjú, pẹlu gbogbo ìpamọ́ra ati ọgbọ́n-ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.” (2 Timoteu 4:2) Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọrun, kì í ṣe tiwọn. Ẹ wo bí èyí ṣe gbéṣẹ́ tó nígbà tí àwọn alàgbà bá fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ tí wọ́n sì sakun láti dé inú ọkàn-àyà!
18. Èéṣe tí ó fi gbéṣẹ́ ní pàtàkì fún àwọn alàgbà láti dé inú ọkàn-àyà?
18 Ọkàn-àyà ni “ẹ́ńjìnnì” fún ìgbòkègbodò Kristian. Nítorí náà Bibeli sọ pé: “Láti inú rẹ̀ wá ni orísun ìyè.” (Owe 4:23) Àwọn alàgbà tí wọ́n bá ń ru ọkàn-àyà sókè yóò ríi pé a ń sún àwọn wọnnì tí ń bẹ nínú ìjọ ṣiṣẹ́ láti lè ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun. Wọn yóò jẹ́ olùlo ìdánúṣe, tí kì í fìgbà gbogbo nílò kí àwọn ẹlòmíràn gún wọn ní kẹ́ṣẹ́. Jehofa kò fẹ́ ìgbọràn àfipáṣe. Òun ń wá ìgbọràn tí ó wá láti inú ọkàn-àyà tí ó kún fún ìfẹ́. Àwọn alàgbà lè fún irú iṣẹ́-ìsìn tí ọkàn-àyà súnniṣe bẹ́ẹ̀ ní ìṣírí nípa ríran àwọn wọnnì tí ń bẹ nínú agbo lọ́wọ́ láti mú agbára ìmọnúúrò wọn gbèrú.
Mímú “Èrò-Inú ti Kristi” Dàgbà
19, 20. Èéṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti mú èrò-inú ti Kristi dàgbà?
19 Bí a ti ṣàkíyèsí, kò tó láti wulẹ̀ mọ àwọn òfin Ọlọrun. Onipsalmu náà bẹ̀bẹ̀ pé: “Fún mi ní òye, èmi ó sì pa òfin rẹ mọ́; nítòótọ́, èmi óò máa kíyèsí i tinútinú mi gbogbo.” (Orin Dafidi 119:34) Jehofa ti ṣí “èrò-inú ti Kristi” payá nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (1 Korinti 2:16) Gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tí ó ṣiṣẹ́sin Jehofa pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò rẹ̀, Jesu fi àwòkọ́ṣe pípé sílẹ̀ fún wa. Ó lóye àwọn òfin àti ìlànà Ọlọrun, ó sì fi wọ́n sílò láìní àlèébù. Nípa kíkọ́ àpẹẹrẹ rẹ̀, a óò “lè fi èrò-orí mòye ní kíkún ohun tí ìbú ati gígùn ati gíga ati jíjìn naa jẹ́, ati lati mọ ìfẹ́ Kristi tí ó tayọ rékọjá ìmọ̀.” (Efesu 3:17-19) Bẹ́ẹ̀ni, ohun tí a kọ́ láti inú Bibeli nípa Jesu lọ fíìfíì rékọjá ọgbọ́n-orí ti ìmọ̀-ẹ̀kọ́ lásán; ó fún wa ní òye ṣíṣe kedere nípa irú ẹni tí Jehofa fúnra rẹ̀ jẹ́.—Johannu 14:9, 10.
20 Nípa báyìí, bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, a lè fòyemọ ìrònú Jehofa lórí àwọn ọ̀ràn kí a sì dé orí ìpinnu tí ó wà déédéé. Èyí yóò gba ìsapá. A gbọ́dọ̀ di akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ń háragàgà, ní mímú kí a tètè lè lóye àwọn ànímọ́ àti ọ̀pá ìdiwọ̀n Jehofa. Gẹ́gẹ́ bí a ti lè sọ pé ó jẹ́ gírámà titun ni a ń kọ́. Síbẹ̀, àwọn tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ yóò máa tẹ̀lé ìyànjú Paulu láti “fi ara [wọn] fún Ọlọrun ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ pẹlu agbára ìmọnúúrò [wọn].”—Romu 12:1.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Èyí yóò fagilé eré-ìnàjú tí ó níí ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí-èṣù, tí ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè, tàbí oníwà ìkà tí ó burú bàlùmọ̀, bákan náà sì ni èyí tí a ń fẹnu lásán pè ní eré-ìnàjú ti ìdílé tí ń gbé èrò oníṣekúṣe àti onígbọ̀jẹ̀gẹ́ lárugẹ èyí tí àwọn Kristian kò tẹ́wọ́gbà.
b A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Kí Ni O Rí Kọ́?
◻ Ìyípadà wo níti iṣẹ́-ìsìn sí Ọlọrun ni ó ṣẹlẹ̀ ní 33 C.E.?
◻ Báwo ni a ṣe lè mú agbára ìmọnúúrò wa dàgbà?
◻ Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè ran àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú agbo lọ́wọ́ láti jẹ́ ẹrú Ọlọrun àti Kristi?
◻ Èéṣe tí a fi níláti mú “èrò-inú ti Kristi” dàgbà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn alàgbà ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti lo agbára ìmọnúúrò wọn