Ẹ Ní Ẹ̀mí Ìrònú Kristi
“Kí Ọlọ́run tí ń pèsè ìfaradà àti ìtùnú yọ̀ǹda fún yín láti ní láàárín ara yín ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní.”—RÓÒMÙ 15:5.
1. Báwo ni ẹ̀mí téèyàn ní ṣe lè nípa lórí ìgbésí ayé ẹni?
IRÚ ẹ̀mí téèyàn ní máa ń kó ipa tí kò kéré nínú ìgbésí ayé. Ẹ̀mí ìdágunlá tàbí ti aápọn, ẹ̀mí rere tàbí búburú, ẹ̀mí aríjàgbá tàbí ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀, ẹ̀mí ìráhùn tàbí ẹ̀mí ìmoore lè nípa tó lágbára lórí bí ẹnì kan ṣe ń kojú àwọn ipò tó bá dìde àti bí àwọn ẹlòmíràn ṣe ń ṣe sí onítọ̀hún. Bí ẹnì kan bá ní ẹ̀mí tó dáa, ó ṣì lè láyọ̀ bí àwọn òkè ìṣòro tiẹ̀ yí i ká pàápàá. Ní ti ẹni tó ní ẹ̀mí burúkú, bó ti wù kí ìgbésí ayé dùn tó, kò sí ohun tó dáa lójú rẹ̀ rí.
2. Báwo ni ẹnì kan ṣe ń kọ́ irú ẹ̀mí tó ní?
2 A lè kọ́ irú ẹ̀mí táa bá fẹ́ ní, ì báà jẹ rere tàbí búburú. Ká sọ tòótọ́, kíkọ́ la máa kọ́ ọ. Nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Collier’s Encyclopedia ń sọ̀rọ̀ nípa ọmọ tí a ṣẹ̀sẹ̀ bí, ó ní: “Irú ẹ̀mí tó bá ní ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ti ní láti jẹ́ èyí tí ó mú dàgbà tàbí tí ó kọ́, gẹ́gẹ́ bó ṣe gbọ́dọ̀ gbọ́ èdè kan tàbí kí ó kọ́ ọ tàbí bó ṣe máa kọ́ ohunkóhun tó bá fẹ́ mọ̀.” Báwo la ṣe ń kọ́ irú ẹ̀mí táa ní? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń fà á, àyíká ẹni àti àwọn téèyàn ń bá kẹ́gbẹ́ máa ń nípa lórí ẹni gan-an. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ táa mẹ́nu kan lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ńṣe là ń kọ́ tàbí gba irú ẹ̀mí tí àwọn èèyàn tó sún mọ́ wá pẹ́kípẹ́kí bá ní bí ewé ṣe máa ń dọṣẹ nígbà tó bá pẹ́ lára ọṣẹ.” Bíbélì sọ ohun kan tó jọ bẹ́ẹ̀ ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, ó ní: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.”—Òwe 13:20; 1 Kọ́ríńtì 15:33.
Àwòṣe Ẹ̀mí Tó Dára
3. Ta ni irú ẹ̀mí tí ó ní jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, báwo la sì ṣe lè fara wé e?
3 Bó ṣe jẹ́ pé Jésù Kristi ló fi àwòṣe tó dára jù lọ lélẹ̀ nínú gbogbo ọ̀ràn yòókù, bẹ́ẹ̀ náà ló fi èyí tó dára jù lọ lélẹ̀ nínú irú ẹ̀mí tó yẹ kéèyàn ní. Ó sọ pé: “Mo fi àwòṣe lélẹ̀ fún yín, pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fún yín, ni kí ẹ máa ṣe pẹ̀lú.” (Jòhánù 13:15) Ká tó lè dà bí Jésù, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀.a Ìdí táa fi ń kọ́ nípa ìgbésí ayé Jésù ni ká lè ṣe ohun tí àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ipa ọ̀nà yìí ni a pè yín sí, nítorí Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Góńgó wa ni pé kí a dà bí Jésù títí dé ibí tó bá ṣeé ṣe dé. Ìyẹn ní í ṣe pẹ̀lú níní irú ẹ̀mí ìrònú tó ní.
4, 5. Apá wo nínú ẹ̀mí ìrònú Jésù la gbé yọ nínú Róòmù orí kẹẹ̀ẹ́dógún, ẹsẹ ìkíní sí ìkẹta, báwo sì làwọn Kristẹni ṣe lè fara wé e?
4 Kí ló túmọ̀ sí láti ní ẹ̀mí ìrònú Kristi Jésù? Orí kẹẹ̀ẹ́dógún ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè yẹn. Ní àwọn ẹsẹ díẹ̀ tó ṣáájú nínú orí yìí, Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí ànímọ́ títayọ kan tí Jésù ní nígbà tó sọ pé: “Àmọ́ ṣá o, ó yẹ kí àwa tí a ní okun máa ru àìlera àwọn tí kò lókun, kí a má sì máa ṣe bí ó ti wù wá. Kí olúkúlùkù wa máa ṣe bí ó ti wu aládùúgbò rẹ̀ nínú ohun rere fún gbígbé e ró. Nítorí Kristi pàápàá kò ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀; ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ti ṣubú lù mí.’”—Róòmù 15:1-3.
5 Láti fara wé ẹ̀mí tí Jésù ní yìí, a gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n múra tán láti fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bójú tó àìní àwọn ẹlòmíràn dípò kí wọ́n máa wá ọ̀nà láti tẹ́ ara wọn nìkan lọ́rùn. Ní tòótọ́, irú ìmúratán láti fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ sin àwọn ẹlòmíràn bẹ́ẹ̀ jẹ́ ànímọ́ àwọn ‘tí wọ́n ní okun.’ Jésù, tó ní okun nípa tẹ̀mí ju ẹnikẹ́ni tí ó tíì gbé ayé rí, sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Ọmọ ènìyàn . . wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ó yẹ kí àwa pẹ̀lú máa làkàkà láti sin àwọn ẹlòmíràn, títí kan “àwọn tí kò lókun.”
6. Ọ̀nà wo la lè gbà fara wé ohun tí Jésù ṣe lójú àtakò àti ẹ̀gàn?
6 Ànímọ́ àtàtà mìíràn tí Jésù tún fi hàn ni ọ̀nà ìrònú àti ìgbégbèésẹ̀ tó máa ń gbéni ró ní gbogbo ìgbà. Kò jẹ́ kí ẹ̀mí búburú tí àwọn ẹlòmíràn ní ba ẹ̀mí rere tí òun ní sí sísin Ọlọ́run jẹ́ rí; bẹ́ẹ̀ làwa náà ò gbọ́dọ̀ gba irú rẹ̀ láyè. Nígbà tí wọ́n pẹ̀gàn Jésù, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí i nítorí pé ó ń fi ìṣòtítọ́ jọ́sìn Ọlọ́run, ńṣe ló fi sùúrù fara dà á láìṣàròyé. Ó mọ̀ pé àwọn tí wọ́n ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí yóò mú inú aládùúgbò wọn dùn “nínú ohun rere fún gbígbé e ró” lè máa retí àtakò láti inú ayé aláìgbàgbọ́ àti aláìlóye yìí.
7. Báwo ni Jésù ṣe fi ẹ̀mí sùúrù hàn, èé sì ti ṣe tó fi yẹ ká ṣe bákan náà?
7 Jésù tún fi ẹ̀mí tó dára hàn láwọn ọ̀nà mìíràn. Kò fìgbà kan rí kánjú ju Jèhófà lọ, bí kò ṣe pé ó ń fi sùúrù dúró de ìmúṣẹ àwọn ète Rẹ̀. (Sáàmù 110:1; Mátíù 24:36; Ìṣe 2:32-36; Hébérù 10:12, 13) Láfikún sí i, Jésù mú sùúrù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi”; nítorí pé ó jẹ́ “onínú tútù,” àwọn ìtọ́ni rẹ̀ gbéni ró, wọ́n sì tuni lára. Àti nítorí pé ó jẹ́ “ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà,” kò fìgbà kankan jẹ́ awúfùkẹ̀ tàbí ọ̀yájú. (Mátíù 11:29) Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú láti fara wé àwọn apá wọ̀nyí nínú ẹ̀mí tí Jésù ní nígbà tó sọ pé: “Ẹ pa ẹ̀mí ìrònú yìí mọ́ nínú yín, èyí tí ó wà nínú Kristi Jésù pẹ̀lú, ẹni tí ó jẹ́ pé, bí ó tilẹ̀ wà ní ìrísí Ọlọ́run, kò ronú rárá nípa ìjá-nǹkan-gbà, èyíinì ni, pé kí òun bá Ọlọ́run dọ́gba. Ó tì o, ṣùgbọ́n ó sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀, ó sì wá wà ní ìrí ènìyàn.”—Fílípì 2:5-7.
8, 9. (a) Èé ṣe tí a fi ní láti sapá kí a tó lè ní ẹ̀mí àìmọtara-ẹni-nìkan? (b) Èé ṣe tí a kò fi ní láti rẹ̀wẹ̀sì bí a ò bá kúnjú ìwọ̀n nínú títẹ̀lé àwòṣe tí Jésù fi lélẹ̀, báwo sì ni Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú èyí?
8 Ó rọrùn láti sọ pé a fẹ́ sin àwọn ẹlòmíràn, a sì fẹ́ fi àìní tiwọn ṣáájú tiwa. Àmọ́ táa bá yẹ ẹ̀mí ìrònú wa wò láìṣàbòsí, a lè rí i pé kì í ṣe gbogbo ọkàn-àyà wa la fẹ́ fi ṣe bẹ́ẹ̀. Èé ṣe? Àkọ́kọ́, nítorí pé a ti jogún ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan láti ọ̀dọ̀ Ádámù àti Éfà; èkejì, nítorí pé a ń gbé nínú ayé kan tó ń gbé ìmọtara-ẹni-nìkan lárugẹ. (Éfésù 4:17, 18) Ohun tí mímú ẹ̀mí àìmọtara-ẹni-nìkan dàgbà sábà máa ń túmọ̀ sí ni pé kí a ní ọ̀nà ìrònú tí ó yàtọ̀ pátápátá sí ti aláìpé tí a bí mọ́ wa. Ìyẹn sì gba ìpinnu àti ìsapá.
9 Àìpé wa tó hàn gbangba, tó sì yàtọ̀ pátápátá sí àwòṣe pípé tí Jésù fi lélẹ̀ fún wa lè máa mú wa rẹ̀wẹ̀sì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. A lè máa ṣiyèméjì pé bóyá ló fi lè ṣeé ṣe fún wa láti ní irú ẹ̀mí ìrònú tí Jésù ní. Àmọ́, kíyè sí ọ̀rọ̀ ìṣírí tí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo mọ̀ pé nínú mi, èyíinì ni, nínú ẹran ara mi, kò sí ohun rere tí ń gbé ibẹ̀; nítorí agbára àti-fẹ́-ṣe wà pẹ̀lú mi, ṣùgbọ́n agbára àtiṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ kò sí. Nítorí rere tí mo fẹ́ ni èmi kò ṣe, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́ ni èmi fi ń ṣe ìwà hù. Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.” (Róòmù 7:18, 19, 22, 23) Lóòótọ́, léraléra ni àìpé Pọ́ọ̀lù dí i lọ́wọ́, tí kò jẹ́ kí ó ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tó bí ó ṣe fẹ́, ṣùgbọ́n ẹ̀mí tí ó ní—ìyẹn ọ̀nà tí ó gbà ń ronú nípa Jèhófà àti òfin Rẹ̀—jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ. Tiwa náà lè ri bẹ́ẹ̀.
Títún Ẹ̀mí Tí Kò Dára Ṣe
10. Irú ẹ̀mí ìrònú wo ni Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Fílípì níyànjú láti ní?
10 Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe pé kí àwọn kan ní ẹ̀mí tí kò dára tó ń fẹ́ àtúnṣe? Bẹ́ẹ̀ ni. Ó jọ pé bí ọ̀ràn àwọn Kristẹni kan ṣe rí ní ọ̀rúndún kìíní nìyẹn. Nínú ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Fílípì, ó sọ̀rọ̀ nípá níní ẹ̀mí tí ó dára. Ó kọ̀wé pé: “Kì í ṣe pé mo ti rí i gbà ná [ìyè tí ọ̀run nípasẹ̀ àjíǹde àkọ́kọ́] tàbí pé a ti sọ mí di pípé ná, ṣùgbọ́n mo ń lépa láti rí i bí èmi pẹ̀lú bá lè gbá èyíinì mú, èyí tí Kristi Jésù pẹ̀lú tìtorí rẹ̀ gbá mi mú. Ẹ̀yin ará, èmi kò tíì ka ara mi sí ẹni tí ó ti gbá a mú nísinsìnyí; ṣùgbọ́n ohun kan wà nípa rẹ̀: Ní gbígbàgbé àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn àti nínàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú, mo ń lépa góńgó náà nìṣó fún ẹ̀bùn eré ìje ti ìpè Ọlọ́run sí òkè nípasẹ̀ Kristi Jésù. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí iye àwa tí a ti dàgbà dénú ní ẹ̀mí ìrònú yìí.”—Fílípì 3:12-15.
11, 12. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń ṣí ẹ̀mí ìrònú tó dára payá fún wa?
11 Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ẹnikẹ́ni tí kò bá rí ìdí tí ó fi yẹ kí òun tẹ̀ síwájú lẹ́yìn tó di Kristẹni tán, kò ní ẹ̀mí tó dáa. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti kùnà láti ní ẹ̀mí ìrònú Kristi. (Hébérù 4:11; 2 Pétérù 1:10; 3:14) Ṣé kò wá sí ìrètí fún irú ẹni tó wà nípò yẹn ni? Rárá o, ó ṣì nírètí. Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti yí irú ẹ̀mí táa ní padà bí a bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù tẹ̀ síwájú ní sísọ pé: “Bí ẹ bá . . . ní èrò orí tí ó tẹ̀ sí ibòmíràn lọ́nà èyíkéyìí, Ọlọ́run yóò ṣí ẹ̀mí ìrònú tí ó wà lókè yìí payá fún yín.”—Fílípì 3:15.
12 Àmọ́ ṣá o, bí a bá fẹ́ kí Jèhófà ṣí ẹ̀mí tó dára payá fún wa, a gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiwa. Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàdúràtàdúrà pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè yóò jẹ́ kí àwọn tó “ní èrò orí tí ó tẹ̀ sí ibòmíràn” ní ẹ̀mí tó dára. (Mátíù 24:45) Inú àwọn alàgbà, tí ẹ̀mí mímọ́ yàn “láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run,” yóò dùn láti ṣe ìrànwọ́. (Ìṣe 20:28) Ẹ wo bí inú wa ṣe dùn tó pé Jèhófà ń gba ti àìpé wa rò, ó sì ń fi ìfẹ́ pèsè ìrànwọ́! Ẹ jẹ́ kí a tẹ́wọ́ gbà á.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Látọ̀dọ̀ Àwọn Ẹlòmíràn
13. Kí la rí kọ́ nípa ẹ̀mí tó dára láti inú àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa Jóòbù?
13 Nínú Róòmù orí kẹẹ̀ẹ́dógún, Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ríronú nípa àpẹẹrẹ àwọn ẹni ìtàn lè ràn wá lọ́wọ́ láti tún ẹ̀mí ìrònú wa ṣe. Ó kọ̀wé pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Ó pọndandan kí àwọn kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà láyé ìgbàanì tún àwọn apá ibì kan nínú ẹ̀mí ìrònú wọn ṣe. Fún àpẹẹrẹ, ní àkópọ̀, Jóòbù ní ẹ̀mí tó dára. Kò fìgbà kan rí ka ohun búburú sí Jèhófà lọ́rùn, kò sì sí ìgbà kan tó jẹ́ kí ìrora yẹ ìgbọ́kànlé òun nínú Ọlọ́run. (Jóòbù 1:8, 21, 22) Síbẹ̀, ó ń fọgbọ́n dá ara rẹ̀ láre. Jèhófà darí Élíhù láti ran Jóòbù lọ́wọ́ láti tún ojú ìwòye rẹ̀ yìí ṣe. Kàkà tí Jóòbù ì bá fi ka èyí sí ìwọ̀sí, ó fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ gbà pé ó pọndandan kí òun tún ẹ̀mí ìrònú náà ṣe, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàtúnṣe kíákíá.—Jóòbù 42:1-6.
14. Báwo la ṣe lè dà bí Jóòbù bí a bá bá wa wí nípa ẹ̀mí táa ní?
14 Ṣé a ó ṣe bí Jóòbù ti ṣe bí Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa kan bá fi inú rere sọ fún wa pé a ti ń ní ẹ̀mí tí kò dára? Gẹ́gẹ́ bíi ti Jóòbù, ǹjẹ́ kí a má ṣe “ka ohunkóhun tí kò bẹ́tọ̀ọ́ mu sí Ọlọ́run lọ́rùn” láé. (Jóòbù 1:22) Bí a bá ń jìyà láìnídìí, ǹjẹ́ kí a má ṣe ráhùn láé tàbí kí a máa sọ pé ọwọ́ Jèhófà ni àwọn ìṣòro wa ti wá. Kí a sì yẹra fún dídá ara wa láre, kí a máa rántí pé bó ti wù kí àwọn àǹfààní tí a ní nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà pọ̀ tó, síbẹ̀ “ẹrú tí kò dára fún ohunkóhun” la ṣì jẹ́.—Lúùkù 17:10.
15. (a) Ẹ̀mí tí kò dára wo làwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù fi hàn? (b) Báwo ni Pétérù ṣe fi ẹ̀mí tó dára hàn?
15 Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn kan tó fetí sí Jésù ní ẹ̀mí tí kò dára. Nígbà kan, Jésù sọ ohun kan tó ṣòro láti lóye. Nítorí ìdí èyí, “ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, wí pé: ‘Ọ̀rọ̀ yìí ń múni gbọ̀n rìrì; ta ní lè fetí sí i?’” Ó hàn gbangba pé ẹ̀mí tí kò dára ni àwọn tó sọ̀rọ̀ lọ́nà yìí ní. Ẹ̀mí tí kò dára yìí sì mú kí wọ́n dẹ́kun fífetí sí Jésù. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ní tìtorí èyí, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sídìí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, wọn kò sì jẹ́ bá a rìn mọ́.” Ǹjẹ́ gbogbo wọn ló ní ẹ̀mí tí kò dára? Ó tì o. Àkọsílẹ̀ náà sọ síwájú sí i pé: “Nítorí náà, Jésù wí fún àwọn méjìlá náà pé: ‘Ẹ̀yin kò fẹ́ lọ pẹ̀lú, àbí?’ Símónì Pétérù dá a lóhùn pé: ‘Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ?’” Lójú ẹsẹ̀, Pétérù dáhùn ìbéèrè ara rẹ̀ pé: “Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 6:60, 66-68) Irú ẹ̀mí yìí mà dára o! Nígbà tí a bá rí àwọn àlàyé tàbí àwọn àtúnṣe nínú òye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó lè kọ́kọ́ ṣòro fún wa láti tẹ́wọ́ gbà, ǹjẹ́ kò ní dára kí a ní irú ẹ̀mí tí Pétérù fi hàn? Ẹ wo bí yóò ṣe jẹ́ ìwà òmùgọ̀ tó láti ṣíwọ́ sísin Jèhófà tàbí kí a máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó yàtọ̀ sí “àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” kìkì nítorí pé àwọn nǹkan kan ṣòro fún wa láti lóye níbẹ̀rẹ̀!—2 Tímótì 1:13.
16. Ẹ̀mí tó múni gbọ̀n rìrì wo ni àwọn aṣáájú ìsìn Júù fi hàn nígbà ayé Jésù?
16 Àwọn aṣáájú ìsìn Júù ọ̀rúndún kìíní kò ní ẹ̀mí tí Jésù ní. Ìpinnu tí wọ́n ti ṣe pé kò sí ohun tó lè mú kí àwọn fetí sí Jésù hàn gbangba nígbà tó jí Lásárù dìde kúrò nínú òkú. Lójú ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀mí tó dára, ńṣe ló yẹ kí iṣẹ́ ìyanu yẹn jẹ́ ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé lóòótọ́ Ọlọ́run ló rán Jésù wá. Àmọ́, ohun táa kà ni pé: “Nítorí náà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí kó Sànhẹ́dírìn jọpọ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: ‘Kí ni kí a ṣe, nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì? Bí a bá jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́ lọ́nà yìí, gbogbo wọn yóò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, àwọn ará Róòmù yóò wá, wọn yóò sì gba àyè wa àti orílẹ̀-èdè wa.’” Kí ni wọ́n wá fẹ́ ṣe? “Láti ọjọ́ yẹn lọ, wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.” Yàtọ̀ sí pé wọ́n gbìmọ̀ láti pa Jésù, wọ́n tún fẹ́ pa ẹ̀rí tó fi hàn gbangba pé oníṣẹ́ ìyanu ni run. “Àwọn olórí àlùfáà gbìmọ̀ pọ̀ nísinsìnyí láti pa Lásárù pẹ̀lú.” (Jòhánù 11:47, 48, 53; 12:9-11) Ẹ wo bí yóò ṣe jẹ́ ohun ìríra tó bí a bá ní irú ẹ̀mí kan náà tí ọkàn wa sì gbọgbẹ́ tàbí ká máa bínú lórí àwọn nǹkan tó yẹ ká máa yọ̀ sí! Ní ti tòótọ́, ó léwu!
Títẹ̀lé Ẹ̀mí Rere Ti Kristi
17. (a) Abẹ́ àwọn ipò wo ni Dáníẹ́lì ti fi ẹ̀mí àìbẹ̀rù hàn? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun nígboyà?
17 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń ní ẹ̀mí rere. Nígbà tí àwọn ọ̀tá Dáníẹ́lì gbìmọ̀ pọ̀ láti gbé òfin kan dìde, èyí tó ka títọrọ nǹkan lọ́wọ́ ọlọ́run èyíkéyìí tàbí ènìyàn èyíkéyìí yàtọ̀ sí ọba léèwọ̀ fún ọgbọ̀n ọjọ́, Dáníẹ́lì mọ̀ pé èyí yóò pa àjọṣe òun pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run lára. Ṣé kò wá ní gbàdúrà sí Ọlọ́run fún odindi ọgbọ̀n ọjọ́ ni? Rárá o, láìbẹ̀rù, ó ń bá a nìṣó láti máa gbàdúrà sí Jèhófà nígbà mẹ́ta lóòjọ́, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀. (Dáníẹ́lì 6:6-17) Bákan náà ni Jésù kò jẹ́ kí àwọn ọ̀tá dẹ́rù ba òun. Ní ọjọ́ Sábáàtì kan, ó rí ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ gbẹ hangogo. Jésù mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó wà níbẹ̀ ni inú wọn kò ní dùn bí òun bá mú ẹnì kan lára dá ní ọjọ́ Sábáàtì. Ó bi wọ́n láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ pé kí wọ́n sọ èrò wọn nípa ọ̀ràn náà. Nígbà tí wọ́n kọ̀ láti sọ̀rọ̀, Jésù mú ọkùnrin náà lára dá. (Máàkù 3:1-6) Jésù kò fìgbà kan rí fà sẹ́yìn ní ṣíṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ̀.
18. Èé ṣe tí àwọn kan fi ń takò wá, àmọ́ ojú wo ló yẹ kí a máa fi wo ẹ̀mí búburú wọn?
18 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní mọ̀ pẹ̀lú pé ìwà búburú èyíkéyìí tí àwọn alátakò lè hù sí wọn kò gbọ́dọ̀ dẹ́rù bà wọ́n. Bí wọ́n bá ń bẹ̀rù, a jẹ́ pé wọn ò ní ẹ̀mí ìrònú Jésù nìyẹn. Ọ̀pọ̀ ló ń tako àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn kan ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọn ò mọ bí ọ̀ràn ṣe jẹ́ gan-an, àwọn mìíràn sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n kórìíra àwọn Ẹlẹ́rìí tàbí iṣẹ́ wọn. Àmọ́, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí àìṣe bí ọ̀rẹ́ tiwọn nípa lórí ẹ̀mí rere tí a ní láé. A ò gbọ́dọ̀ máa jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn sọ ọ̀nà tí a ó gbà jọ́sìn fún wa.
19. Báwo la ṣe lè fi irú ẹ̀mí ìrònú ti Jésù Kristi hàn?
19 Ìgbà gbogbo ni Jésù máa ń fi ẹ̀mí ìrònú tó dára hàn sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ àti sí ètò Ọlọ́run, bó ti wù kí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ṣòro tó. (Mátíù 23:2, 3) A gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Lóòótọ́, aláìpé ni àwọn arákùnrin wa, ṣùgbọ́n aláìpé làwa náà. Ibo la sì ti lè rí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tó dára jù àti àwọn ọ̀rẹ́ gidi tó ṣeé fọkàn tán bí kò ṣe nínú ẹgbẹ́ àwọn ará wa jákèjádò ayé? Jèhófà kò tíì fún wa ní òye tó pé tán lórí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà ní àkọsílẹ̀, àmọ́ ẹ̀sìn wo ló lóye jù wá lọ? Ẹ jẹ́ kí a máa ní ẹ̀mí ìrònú tó dára nígbà gbogbo, irú ẹ̀mí ìrònú tí Jésù Kristi ní. Ara ohun tí ẹ̀mí yẹn wé mọ́ ni mímọ bí a ṣe ń dúró de Jèhófà, bí a ó ṣe jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìtẹ̀jáde náà, Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde jíròrò ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù.
Ṣé O Lè Ṣàlàyé?
• Báwo ni irú ẹ̀mí táa ní ṣe ń nípa lórí ìgbésí ayé wa?
• Ṣàpèjúwe ẹ̀mí ìrònú Jésù Kristi.
• Kí la lè rí kọ́ látinú ẹ̀mí tí Jóòbù ní?
• Ẹ̀mí wo ni ó dáa kí a ní lábẹ́ àtakò?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Kristẹni kan tó ní ẹ̀mí tó dára máa ń làkàkà láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Fífi tàdúràtàdúrà kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí ìrònú Kristi