Jẹ́ Kí Àwọn Àṣà Tó Ti Mọ́ Ọ Lára Ṣe Ọ́ Láǹfààní
ỌKÙNRIN náà ti gbé ní àgbègbè ìlú Áténì fún ọdún méjìlá. Ọ̀nà kan náà ló máa ń gbà lọọlé lójoojúmọ́ tó bá ti kúrò níbi iṣẹ́. Lẹ́yìn náà, ó kó lọ sí àgbègbè mìíràn ní ìlú náà. Bó ṣe parí iṣẹ́ tán lọ́jọ́ kan ló kọrí sílé. Ìgbà tó bá ara rẹ̀ ní àdúgbò tó ń gbé tẹ́lẹ̀ ló ṣẹ̀sẹ̀ mọ̀ pé òun ti ṣìnà ibi tí òun ń lọ. Àṣà tó ti mọ́ ọn lára ti jẹ́ kó forí lé ilé rẹ̀ àtijọ́!
Abájọ tí wọ́n fi ń pe àṣà tó ti mọ́ni lára ní ohun tó ti dara ẹni, ìyẹn ni ìṣe tó ń nípa lórí ẹni lọ́nà tó lágbára. Ní ọ̀nà yìí, a lè fi àṣà wé iná. Iná lè jẹ́ ìmọ́lẹ̀ táa nílò nínú òkùnkùn, a sì lè fi gbọn òtútù nù, a sì lè fi mú oúnjẹ wa gbóná. Ṣùgbọ́n, iná tún lè jẹ́ ọ̀tá rírorò tó lè gbẹ̀mí èèyàn, kó sì jó ohun ìní èèyàn run. Bẹ́ẹ̀ gan-an lọ̀rọ̀ àṣà ṣe rí. Táa bá lò ó lọ́nà tó dáa, ó lè ṣe wá láǹfààní tó ga. Àmọ́ ó tún lè ba nǹkan jẹ́.
Ní ti ọkùnrin táa mẹ́nu kàn níṣàájú yẹn, àṣà tó ti mọ́ ọn lára wulẹ̀ mú kó fi àkókò díẹ̀ ṣòfò nínú sún kẹẹrẹ fà kẹẹrẹ ọkọ lójú pópó ni. Nígbà tọ́ràn bá dórí ohun tó túbọ̀ ṣe pàtàkì, àwọn àṣà tó ti mọ́ra lè jẹ́ ká ṣàṣeyọrí, ó sì lè kó wa sí wàhálà. Gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ lára ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an táa rí nínú Bíbélì yẹ̀ wò, èyí tó fi hàn bí àṣà ṣe lè ranni lọ́wọ́ tàbí bó ṣe lè ṣèdíwọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run àti àjọṣe táa ní pẹ̀lú rẹ̀.
Àwọn Àpẹẹrẹ Àṣà Rere àti Búburú Tó Wà Nínú Bíbélì
Nóà, Jóòbù, àti Dáníẹ́lì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Bíbélì gbóríyìn fún wọn “nítorí òdodo wọn.” (Ìsíkíẹ́lì 14:14) Lọ́nà tó gbàfiyèsí, ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà fi hàn pé wọ́n ti mú àṣà rere dàgbà.
A sọ fún Nóà pé kí ó kan áàkì, ìyẹn ọkọ̀ kan tó gùn ju pápá tí wọ́n ti ń gbá bọ́ọ̀lù lọ, tó sì ga ju ilé alájà márùn-ún lọ. Irú iṣẹ́ bàǹtàbanta bẹ́ẹ̀ ti ní láti kó jìnnìjìnnì bá ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ kankọ̀kankọ̀ láyé ọjọ́un. Nóà àti àwọn méje tó jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ kan áàkì náà láìní ohun èlò òde òní kankan. Láfikún sí i, Nóà ń bá wíwàásù fún àwọn alájọgbáyé rẹ̀ nìṣó. Ó sì dá wa lójú pé ó tún ń bójú tó àìní ìdílé rẹ̀ nípa tẹ̀mí àti nípa tara. (2 Pétérù 2:5) Kí Nóà tó lè ṣe gbogbo èyí láṣeyọrí, iṣẹ́ àṣekára ti ní láti mọ́ ọn lára. Síwájú sí i, ìtàn Nóà wà nínú Bíbélì pé ó jẹ́ ẹni tó “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn. . . . Nóà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jèhófà ti pa láṣẹ fún un.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:9, 22; 7:5) Níwọ̀n bí a ti pè é ní “aláìní-àléébù” nínú Bíbélì, ó ní láti jẹ́ pé ó ń bá Ọlọ́run rìn nìṣó lẹ́yìn Àkúnya Omi náà àti lẹ́yìn ọ̀tẹ̀ tí wọ́n dì mọ́ Jèhófà ní Bábélì. Ní ti tòótọ́, Nóà ń bá a lọ ní bíbá Ọlọ́run rìn títí di ọjọ́ ikú rẹ̀ ní ẹni àádọ́ta-dín-lẹ́gbẹ̀rún ọdún.—Jẹ́nẹ́sísì 9:29.
Àṣà rere Jóòbù ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ ọkùnrin “aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán.” (Jóòbù 1:1, 8; 2:3) Ó sọ ọ́ di àṣà láti máa ṣe bí àlùfáà fún ìdílé rẹ̀ nípa rírúbọ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn àsè ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, bóyá wọ́n ti “‘dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì ti bú Ọlọ́run nínú ọkàn-àyà wọn.’ Bí Jóòbù ti ń ṣe nìyí nígbà gbogbo.” (Jóòbù 1:5) Kò sí àní-àní pé àwọn àṣà táa gbé ka ìjọsìn Jèhófà ló jẹ ìdílé Jóòbù lógún.
Dáníẹ́lì sin Jèhófà “láìyẹsẹ̀” jálẹ̀ ọjọ́ gígùn tó lò láyé. (Dáníẹ́lì 6:16, 20) Irú àṣà rere nípa tẹ̀mí wo ni Dáníẹ́lì ní? Lákọ̀ọ́kọ́, ó ń gbàdúrà sí Jèhófà déédéé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣòfin kan tó ka àṣà yìí léèwọ̀, “ìgbà mẹ́ta lójúmọ́, [Dáníẹ́lì] ń kúnlẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó ń gbàdúrà, ó sì ń bu ìyìn níwájú Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe déédéé.” (Dáníẹ́lì 6:10) Kò lè ṣíwọ́ àṣà tó ti mọ́ ọn lára láti máa gbàdúrà sí Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà, kódà nígbà tíyẹn fi ìgbésí ayé rẹ̀ sínú ewu pàápàá. Ó dájú pé àṣà yìí fún Dáníẹ́lì lókun nínú ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ tó jẹ́ ti olùpa ìwà títọ́ mọ́ sí Ọlọ́run lọ́nà tí kò láfiwé. Ó jọ pé Dáníẹ́lì tún ní àṣà dáradára ti kíkẹ́kọ̀ọ́ àti ríronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìlérí Ọlọ́run tó ń mọ́kàn yọ̀. (Jeremáyà 25:11, 12; Dáníẹ́lì 9:2) Ó dájú pé àwọn àṣà dáradára wọ̀nyí ràn án lọ́wọ́ láti fara dà á títí dé òpin, tó sì fi ìṣòtítọ́ sá eré ìje ìyè dé ìparí rẹ̀ koko.
Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ìyẹn, nǹkan kò ṣẹnu re fún Dínà rárá nítorí àṣàkaṣà. Ó “sábà máa ń jáde lọ rí àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ náà,” tí wọn kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà. (Jẹ́nẹ́sísì 34:1) Àṣà tó dà bí èyí tí kò burú yìí yọrí sí jàǹbá ńlá. Lákọ̀ọ́kọ́, Ṣékémù bà á jẹ́, ìyẹn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n kà sí ẹni tí “ó ní ọlá jù lọ nínú gbogbo ilé baba rẹ̀.” Lẹ́yìn náà, ìbínú tí méjì nínú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fà yọ sún wọn dórí pípa gbogbo ọkùnrin tó wà ní odindi ìlú ńlá kan. Àbájáde yẹn mà burú jáì o!—Jẹ́nẹ́sísì 34:19, 25-29.
Báwo la ṣe lè ní ìdánilójú pé ohun tó jẹ́ àṣà wa yóò ṣe wá láǹfààní, kò sì ní pa wá lára?
Ṣíṣe Àwọn Ohun Tó Ti Dàṣà
Onímọ̀ ọgbọ́n orí kan kọ ọ́ pé: “Àyànmọ́ ni àṣà.” Àmọ́ kì í ṣọ̀ràn àyànmọ́. Bíbélì fi hàn kedere pé a lè yàn láti yí àwọn àṣà wa tí kò dára padà, ká sì mú èyí tó dára dàgbà.
Táa bá ní àwọn àṣà tó dára, ọ̀nà ìgbésí ayé Kristẹni yóò di ohun tó túbọ̀ gbéṣẹ́ tó sì rọrùn láti máa bá nìṣó. Alex, Kristẹni kan láti ilẹ̀ Gíríìsì, sọ pé: “Àṣà kí n máa tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tí mo fi ń ṣàṣeparí onírúurú iṣẹ́ ti jẹ́ kí n lo àkókò mi lọ́nà tó dára gan-an.” Theophilus, Kristẹni alàgbà kan, tọ́ka sí wíwéwèé gẹ́gẹ́ bí àṣà kan tó ń ràn án lọ́wọ́ láti di ọ̀jáfáfá. Ó sọ pé: “Ó dá mi lójú pé ì bá máà ṣeé ṣe fún mi láti ṣe àwọn ojúṣe mi gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni láṣeyọrí tí kì í bá ṣe pé mo ní àṣà kí n máa wéwèé dáadáa.”
Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a rọ̀ wá pé ká “máa bá a lọ ní rírìn létòletò nínú ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ kan náà yìí.” (Fílípì 3:16) Ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ ni “ọ̀nà . . . kan tó ti mọ́ wa lára láti máa gbà ṣe nǹkan ní gbogbo ìgbà.” Irú àṣà dáradára bẹ́ẹ̀ máa ń ṣe wá láǹfààní nítorí pé a ò wulẹ̀ ní lo àkókò láti ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan mọ́—a ti gbé ọ̀nà kan tó dára kalẹ̀, èyí tó ti mọ́ wa lára láti máa tẹ̀ lé. Àwọn àṣà tó ti jingíri sí wa lára ti di ohun táa ń ṣe láìmọ̀. Gẹ́gẹ́ bí àṣà wíwa ọkọ̀ dáadáa ti lè ran awakọ̀ kan lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó fi máa gbẹ̀mí là ní gbàrà tó bá rí ewu lójú ọ̀nà, àṣà dáradára tún lè ràn àwa náà lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó bójú mu láìjáfara báa ṣe ń rin ipa ọ̀nà Kristẹni wa.
Gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nì, Jeremy Taylor ṣe sọ ọ́: “Ìgbésẹ̀ táa ń gbé ló ń di àṣà.” Bí a bá ní àwọn àṣà tó dára, a lè ṣe àwọn ohun tó dára láìsí ìṣòro. Fún àpẹẹrẹ, báa ṣe jẹ́ Kristẹni òjíṣẹ́, táa bá ní àṣà kíkópa nínú iṣẹ́ wíwàásù déédéé, lílọ sí òde ẹ̀rí yóò túbọ̀ rọrùn fún wa, a ó sì túbọ̀ máa gbádùn rẹ̀. A kà nípa àwọn àpọ́sítélì pé,“ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé ni wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.” (Ìṣe 5:42; 17:2) Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, tó bá jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan là ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, a lè máa bẹ̀rù, kí ó gbà wá lákòókò kí iṣẹ́ náà tó mọ́ wa lára, ìyẹn ni pé ó lè ṣe díẹ̀ kí ọkàn wa tó balẹ̀ nínú ìgbòkègbodò Kristẹni tó ṣe pàtàkì yìí.
Bákan náà ló rí pẹ̀lú àwọn apá mìíràn nínú ìgbòkègbodò Kristẹni wa. Àṣà tó dára lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa ‘ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’ déédéé “ní ọ̀sán àti ní òru.” (Jóṣúà 1:8; Sáàmù 1:2) Kristẹni kan ní àṣà kíka Bíbélì fún ogún ìṣẹ́jú sí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú kó tó sùn lálẹ́. Kódà nígbà tó bá rẹ̀ ẹ́ gan-an, ó máa ń rí i pé bí òun bá lọ sórí bẹ́ẹ̀dì láìka Bíbélì, òun kò ní lè sùn dáadáa. Ó ní láti dìde, kó sì bójú tó àìní tẹ̀mí yẹn. Àṣà dáradára yìí sì ti ràn án lọ́wọ́ láti ka odindi Bíbélì lẹ́ẹ̀kan lọ́dọọdún fún ọdún mélòó kan.
Jésù Kristi, tó jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa, ní àṣà lílọ sí àwọn ìpàdé táa ti ń jíròrò Bíbélì. “Gẹ́gẹ́ bí àṣà rẹ̀ ní ọjọ́ sábáàtì, ó wọ inú sínágọ́gù, ó sì dìde dúró láti kàwé.” (Lúùkù 4:16) Ní ti Joe, alàgbà kan tó ní ìdílé ńlá, tó sì ń ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ wákàtí, àṣà ti ṣèrànwọ́ láti gbin ìjẹ́pàtàkì àti ìfẹ́ láti máa lọ sí àwọn ìpàdé déédéé sí i lọ́kàn. Ó sọ pé: “Àṣà yìí ló ń ràn mí lọ́wọ́, tó ń fún mi ní okun tẹ̀mí tí mo nílò, kí n lè kojú àwọn ìpèníjà àtàwọn ìṣòro pẹ̀lú àṣeyọrí.”—Hébérù 10:24, 25.
Irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú eré ìje ìyè tí Kristẹni ń sá. Ìròyìn tó wá láti orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti ń ṣe inúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Kì í ṣòro fáwọn tí wọ́n ní àṣà tó dára nípa tẹ̀mí, tí wọ́n sì ní ìmọrírì tó jinlẹ̀ fún òtítọ́ láti mú ìdúró wọn nígbà tí àdánwò bá dé, ṣùgbọ́n àwọn tó jẹ́ pé nígbà tí ‘àkókò rọgbọ’ pàápàá, wọ́n máa ń pa ìpàdé jẹ, wọn kì í jáde òde ẹ̀rí déédéé, wọ́n kì í sì í juwọ́ sílẹ̀ nínú àwọn ọ̀ràn kéékèèké, sábà máa ń ṣubú lábẹ́ ìdánwò ‘líle koko.’”—2 Tímótì 4:2.
Yẹra fún Àṣà Tí Kò Dára, Lo Èyí Tó Dára
Àwọn kan máa ń sọ pé ‘kìkì àwọn àṣà téèyàn fẹ́ kó mọ́ òun lára ló yẹ kó mú dàgbà.’ Ọ̀gá tó ń jẹ gàba léni lórí làwọn àṣà búburú. Síbẹ̀, a lè jáwọ́ nínú wọn.
Ìgbà kan wà tí àṣà ká máa wo tẹlifíṣọ̀n ṣáá ti di bárakú fún Stella. Ó jẹ́wọ́ pé: “Mo sábà máa ń ní èrò ‘rere’ kan tó máa ń sún mi dédìí gbogbo àṣà búburú tó di bárakú fún mi.” Ohun tó sún un dédìí àṣà wíwo tẹlifíṣọ̀n láwòjù gan-an nìyẹn. Á máa rò ó nínú ara rẹ̀ pé kí òun kàn wò ó fún “fàájì díẹ̀” tàbí kí òun “fi yíwọ́ padà” ni. Àmọ́, àṣà náà di ohun tí kò ṣeé ṣàkóso mọ́, tó wá sọ ọ́ di ẹni tó ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí nídìí tẹlifíṣọ̀n. Ó sọ pé: “Ó kéré tán, àṣà búburú yìí kò jẹ́ kí n tètè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.” Pẹ̀lú ìsapá àìyẹsẹ̀, ó wá dín àkókò tó ń lò nídìí tẹlifíṣọ̀n kù, ó sì túbọ̀ ń ṣe àṣàyàn ohun tó ń wò. Stella sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń gbìyànjú láti rántí ìdí tí mo fi fẹ́ jáwọ́ nínú àṣà yìí, mo sì gbára lé Jèhófà láti mú ìpinnu mi ṣẹ.”
Kristẹni kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Charalambos tọ́ka sí àṣà búburú kan tí kò jẹ́ kó tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí—àṣà náà ni ká máa fòní dónìí fọ̀la dọ́la. “Nígbà tí mo rí i pé ó léwu kéèyàn máa sọ gbogbo nǹkan dìgbà míì, mo wá bẹ̀rẹ̀ síí yí ìgbésí ayé mi padà. Nígbà tí mo bá ń wéwèé, mo máa ń pinnu ìgbà tí mo fẹ́ ṣe é gan-an àti bí mo ṣe máa bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lé e lórí. Fífi gbogbo ìgbà gbégbèésẹ̀ lórí àwọn ìpinnu mi àti àwọn ohun tí mo wéwèé láti ṣe ni mo fi yanjú ìṣòro náà, ó sì jẹ́ àṣà tó dára títí di ìsinsìnyí.” Láìsí àní-àní, àwọn àṣà tó dáa ló yẹ kéèyàn máa fi dípò àṣà búburú.
Àwọn táa ń bá kẹ́gbẹ́ tún lè jẹ́ ká mú àwọn àṣà kan dàgbà, yálà rere tàbí búburú. Bí àṣà búburú ṣe máa ń ranni náà ni rere máa ń ranni. Kódà bó ṣe jẹ́ pé “ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́,” bẹ́ẹ̀ náà ni ẹgbẹ́ rere máa ń fúnni ní àpẹẹrẹ àwọn ìwà tó dára láti fara wé. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Ní pàtàkì jù lọ, àwọn àṣà wa lè fún àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run lókun, ó sì lè jìn ín lẹ́sẹ̀. Stella sọ pé: “Bí àwọn àṣà wa bá dára, wọ́n ń jẹ́ kí ìlàkàkà wa láti sìn Jèhófà túbọ̀ rọrùn sí i. Bí wọ́n bá jẹ́ èyí tó ń pani lára, wọ́n á máa ṣèdíwọ́ fún ìsapá wa.”
Rọ̀ mọ́ àwọn àṣà tó dára, kí o sì jẹ́ kí wọ́n máa ṣamọ̀nà rẹ. Wọn yóò jẹ́ ipa tó lágbára, tó sì ń ṣeni láǹfààní nínú ìgbésí ayé rẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Bí iná, àṣà lè ṣeni láǹfààní, ó sì lè pani lára
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ó jẹ́ àṣà Jésù láti máa wà nínú sínágọ́gù ní ọjọọjọ́ Sábáàtì, kí ó lè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Àwọn àṣà tó dára nípa tẹ̀mí ń fún àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run lókun