Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dúró Níwájú Ìtẹ́ Ìdájọ́?
“Nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé ninu ògo rẹ̀, ati gbogbo awọn áńgẹ́lì pẹlu rẹ̀, nígbà naa ni oun yoo jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀.”—MATTEU 25:31.
1-3. Ìdí wo ni a ní fún fífojúsọ́nà fún rere ní ti ìdájọ́?
‘OJẸ̀BI ÀBÓÒ JẸ̀BI?’ Ọ̀pọ̀ ń tọpinpin bí wọ́n ṣe ń gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ìgbẹ́jọ́ kan. Àwọn onídàájọ́ àti àwọn mẹ́ḿbà ìgbìmọ̀ ìdájọ́ lè jẹ́ aláìlábòsí, ṣùgbọ́n òdodo ha máa ń fìgbà gbogbo lékè bí? O kò ha ti gbọ́ nípa àìṣèdájọ́ òdodo àti àìṣẹ̀tọ́ nígbà tí ìgbẹ́jọ́ bá ń lọ lọ́wọ́ bí? Irú àìṣèdájọ́ òdodo bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ohun tuntun, gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú àkàwé Jesu, nínú Luku 18:1-8.
2 Ohun yòówù kí ìrírí rẹ̀ ní ti ìdájọ́ ti ẹ̀dá ènìyàn jẹ́, ṣàkíyèsí ìparí èrò tí Jesu dé: “Ọlọrun kì yoo ha mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún awọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí ń ké jáde sí i tọ̀sán tòru . . . ? Mo sọ fún yín, Oun yoo mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún wọn pẹlu ìyára kánkán. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé, oun yoo ha bá ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀-ayé níti gidi bí?”
3 Bẹ́ẹ̀ ni, Jehofa yóò rí sí i pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ rí ìdájọ́ òdodo gbà nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ó kan Jesu pẹ̀lú, ní pàtàkì nísinsìnyí, nítorí pé, a ń gbé ní “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò ìgbékalẹ̀ búburú ti ìsinsìnyí. Láìpẹ́, Jehofa yóò lo Ọmọkùnrin rẹ̀ alágbára láti mú ìwà búburú kúrò lórí ilẹ̀ ayé. (2 Timoteu 3:1; 2 Tessalonika 1:7, 8; Ìṣípayá 19:11-16) A lóye ipa iṣẹ́ Jesu láti inú ọ̀kan lára àwọn àkàwé tí ó ṣe, tí a sábà máa ń pè ní òwe àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́.
4. Báwo ni a ti ṣe lóye àkókò tí òwe àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ ní ìmúṣẹ sí tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n èé ṣe tí a óò fi fún òwe àkàwé náà ní àfiyèsí nísinsìnyí? (Owe 4:18)
4 Tipẹ́tipẹ́ ni a ti rò pé òwe àkàwé náà ṣàpèjúwe Jesu tí ó jókòó gẹ́gẹ́ bí Ọba ní 1914, tí ó sì ti ń ṣèdájọ́ láti ìgbà náà wá—ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn ènìyàn tí wọ́n fi hàn pé àwọ́n jẹ́ ẹni bí àgùntàn, ikú àkúrun fún àwọn ewúrẹ́. Ṣùgbọ́n títún òwe àkàwé náà gbé yẹ̀wò tọ́ka sí òye kan tí a tún ṣe nípa àkókò tí ó ní ìmúṣẹ àti ohun tí ń ṣàpèjúwe. Àtúnṣe yìí fún ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ ìwàásù wa lókun àti bí ìdáhùnpadà àwọn ènìyàn ti ṣe kókó tó. Láti lè rì ìpìlẹ̀ fún òye jíjinlẹ̀ síi ní ti òwe àkàwé náà, ẹ jẹ́ kí a gbé ohun tí Bibeli fi hàn nípa Jehofa àti Jesu yẹ̀ wò, bí àwọn méjèèjì ṣe jẹ́ Ọba àti Onídàájọ́.
Jehofa Gẹ́gẹ́ Bí Onídàájọ́ Gíga Lọ́lá Jù Lọ
5, 6. Èé ṣe tí ó fi bá a mu wẹ́kú láti wo Jehofa gẹ́gẹ́ bí Ọba àti Onídàájọ́?
5 Jehofa ń fi agbára rẹ̀ ṣàkóso lórí gbogbo ẹ̀dá tí ń bẹ lágbàáyé. Nítorí tí kò ní ìbẹ̀rẹ̀ tí kò sì ní òpin, òun ni “Ọba ayérayé.” (1 Timoteu 1:17; Orin Dafidi 90:2, 4; Ìṣípayá 15:3) Ó ní ọlá àṣẹ láti ṣe àwọn òfin, tàbí láti pa àṣẹ, àti láti rí i pé ó múlẹ̀. Ṣùgbọ́n ọlá àṣẹ rẹ̀ ní jíjẹ́ Onídàájọ́ nínú. Isaiah 33:22 sọ pé: “Oluwa ni onídàájọ́ wa, Oluwa ni olófin wa, Oluwa ni ọba wa; òun óò gbà wá là.”
6 Ó ti pẹ́ tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ti mọ Jehofa gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ àwọn ẹjọ́ àti ọ̀ràn àríyànjiyàn. Fún àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí “Onídàájọ́ gbogbo ayé” ti wọn ẹ̀rí nípa ìwà búburú Sodomu àti Gomorra wò, ó dájọ́ pé àwọn olùgbé náà yẹ fún ìparun, ó sì rí sí i pé ìdájọ́ òdodo náà múlẹ̀. (Genesisi 18:20-33; Jobu 34:10-12) Ẹ wo bí èyí ṣe ní láti fi wá lọ́kàn balẹ̀ tó, láti mọ̀ pé, Jehofa jẹ́ Onídàájọ́ òdodo, tí ó lè mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ nígbà gbogbo!
7. Báwo ni Jehofa ti ṣe ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ ní bíbá Israeli lò?
7 Ní Israeli ìgbàanì, nígbà mìíràn, Jehofa máa ń ṣèdájọ́ ní tààràtà. A kò ha ti ní tù ọ́ nínú nígbà náà lọ́hùn-ún, láti mọ̀ pé Onídàájọ́ pípé kan ni ń pinnu àwọn ọ̀ràn bí? (Lefitiku 24:10-16; Numeri 15:32-36; 27:1-11) Ọlọrun tún pèsè “àwọn òfin” tí ó dára látòkèdélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n fún ṣíṣe ìdájọ́. (Lefitiku 25:18, 19; Nehemiah 9:13; Orin Dafidi 19:9, 10; 119:7, 75, 164; 147:19, 20) Òun ni “Onídàájọ́ gbogbo ayé,” nítorí náà, gbogbo wa ni ó kàn.—Heberu 12:23.
8. Ìran tí ó jẹ mọ́ ọn wo ní Danieli rí?
8 A ni ẹ̀rí “ẹni tí ọ̀ran ṣojú rẹ̀” tí ó jẹ́rìí sí ọ̀ràn yìí. A fi ìran àwọn ẹranko ẹhànnà rírorò tí wọ́n dúró fún àwọn ìjọba tàbí ilẹ̀ ọba han wòlíì Danieli. (Danieli 7:1-8, 17) Ó fi kún un pé: ‘A sọ àwọn ìtẹ́ wọnnì kalẹ̀ títí Ẹni-àgbà ọjọ́ náà fi jókòó, aṣọ ẹni tí ó fún gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.’ (Danieli 7:9) Ṣàkíyèsí pé Danieli rí àwọn ìtẹ́ tí “Ẹni-àgbà ọjọ́ náà [Jehofa] fi jókòó.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ ti wa.) Bí ara rẹ léèrè pé: ‘Danieli níhìn-ín ha ń rí bí Ọlọrun ṣe ń di Ọba bí?’
9. Kí ni ìtumọ̀ kan fún ‘jíjókòó’ lórí ìtẹ́? Fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ.
9 Tóò, nígbà tí a bá kà pé ẹnì kan “jókòó” lórí ìtẹ́, a lè rò pé ó ń di ọba, nítorí pé, nígbà mìíràn, Bibeli máa ń lo irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ: “Nígbà tí [Simri] bẹ̀rẹ̀ sí í jọba, bí ó ti jókòó ní orí ìtẹ́ rẹ̀, ó . . . ” (1 Ọba 16:11; 2 Ọba 10:30; 15:12; Jeremiah 33:17) Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Messia sọ pé: “Yóò sì jókòó yóò sì jọba lórí ìtẹ́ rẹ̀.” (Ìkọ̀wé wínníwinní jẹ́ ti wa.) Nítorí náà, láti ‘jókòó lórí ìtẹ́’ lè túmọ̀ sí dídi ọba. (Sekariah 6:12, 13) A ṣàpèjúwe Jehofa gẹ́gẹ́ bí Ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́. (1 Ọba 22:19; Isaiah 6:1; Ìṣípayá 4:1-3) Òun ni “Ọba ayérayé.” Síbẹ̀, níwọ̀n bí ó ti fi ìtẹnumọ́ kéde apá tuntun kan ní ti ipò ọba aláṣẹ, a lè sọ pé ó ti di Ọba, bí ẹni pé ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ lákọ̀tun.—1 Kronika 16:1, 31; Isaiah 52:7; Ìṣípayá 11:15-17; 15:3; 19:1, 2, 6.
10. Kí ni olórí iṣẹ́ àwọn ọba Israeli? Ṣàpèjúwe.
10 Ṣùgbọ́n kókó pàtàkì kan rèé: Olórí iṣẹ́ àwọn ọba ìgbàanì ni, láti máa gbẹ́jọ́, kí wọ́n sì máa ṣèdájọ́. (Owe 20:8; 29:14) Rántí ìdájọ́ ọlọ́gbọ́n tí Solomoni ṣe nígbà tí àwọn obìnrin méjì ń jà lórí ọmọ kan náà. (1 Ọba 3:16-28; 2 Kronika 9:8) Ọ̀kan lára àwọn ilé ìjọba rẹ̀ ni “ìloro ìtẹ́ níbi ti yóò máa ṣe ìdájọ́,” tí a sì tún ń pè ní “ìloro ìdájọ́.” (1 Ọba 7:7) A ṣàpèjúwe Jerusalemu gẹ́gẹ́ bí ibi tí “a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀” sí. (Orin Dafidi 122:5) Ó ṣe kedere pé, ‘jíjókòó lórí ìtẹ́’ tún lè túmọ̀ sí lílo ọlá àṣẹ ìdájọ́.—Eksodu 18:13; Owe 20:8.
11, 12. (a) Kí ni ìjẹ́pàtàkì jíjókòó tí Jehofa jókòó, tí a mẹ́nu kàn nínú Danieli orí 7? (b) Báwo ni àwọn ẹsẹ mìíràn ṣe jẹ́rìí sí i pé Jehofa jókòó láti ṣèdájọ́?
11 Wàyí o, ẹ jẹ́ kí a padà sí ìran náà, níbi tí Danieli ti rí “Ẹni-àgbà ọjọ́ náà tí ó jókòó.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ ti wa.) Danieli 7:10 fi kún un pé: “Àwọn onídàájọ́ jókòó, a sì ṣí ìwé wọnnì sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, Ẹni-àgbà ọjọ́ náà jókòó láti ṣèdájọ́ nípa ìjẹgàba lórí ayé àti láti ṣèdájọ́ Ọmọkùnrin ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ẹni náà tí ó yẹ kí ó ṣàkóso. (Danieli 7:13, 14) Lẹ́yìn náà, a kà pé “Ẹni-àgbà ọjọ́ nì . . . dé, . . . a sì fi ìdáláre fún àwọn ènìyàn mímọ́,” àwọn tí a ṣèdájọ́ wọn pé, wọ́n yẹ láti ṣàkóso pẹ̀lú Ọmọkùnrin ènìyàn. (Danieli 7:22, ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ ti wa.) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín “àwọn onídàájọ́ jókòó,” wọ́n sì ṣèdájọ́ mímúná lórí agbára ayé tí ó kẹ́yìn.—Danieli 7:26.a
12 Nítorí náà, rírí tí Danieli rí Ọlọrun tí ó ‘jókòó lórí ìtẹ́’ túmọ̀ sí bíbọ̀ Rẹ̀ láti ṣèdájọ́. Dafidi ti kọrin ṣáájú pé: “Ìwọ [Jehofa] ni ó ti mú ìdájọ́ mi àti ìdí ọ̀ràn mi dúró; ìwọ ni ó jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń ṣe ìdájọ́ òdodo.” (Orin Dafidi 9:4, 7) Joeli sì kọ̀wé pé: “Ẹ jí, ẹ sì gòkè wá sí àfonífojì Jehoṣafati ẹ̀yin kèfèrí: nítorí níbẹ̀ ni èmi [Jehofa] óò jókòó láti ṣe ìdájọ́ àwọn kèfèrí yí káàkiri.” (Joeli 3:12; fi wé Isaiah 16:5.) Jesu àti Paulu wà nínú ipò ìdájọ́, nínú èyí tí ẹ̀dá ènìyàn kan tí jókòó láti gbẹ́jọ́, tí ó sì ṣèdájọ́.b—Johannu 19:12-16; Ìṣe 23:3; 25:6.
Ipò Jesu
13, 14. (a) Ìdálójú wo ni àwọn ènìyàn Ọlọrun ní pé Jesu yóò di Ọba? (b) Nígbà wo ni Jesu jókòó lórí ìtẹ́, ní ọ̀nà wo sì ni ó fi ń ṣàkóso láti 33 C.E. wá?
13 Jehofa jẹ́ Ọba àti Onídàájọ́. Jesu ń kọ́? Áńgẹ́lì náà tí ó kéde ìbí rẹ̀ wí pé: “Jehofa Ọlọrun yoo sì fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fún un, . . . kì yoo sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.” (Luku 1:32, 33) Jesu yóò jẹ́ ajogún ipò ọba Dafidi títí láé. (2 Samueli 7:12-16) Òun yóò ṣàkóso láti ọ̀run, nítorí Dafidi wí pé: “Ọ̀rọ̀ àsọjáde Jehofa sí Oluwa mi [Jesu] ni: ‘Jókòó ni ọwọ́ ọ̀tún mi títí tí èmi yóò fi gbé àwọn ọ̀tá rẹ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.’ Ọ̀pá okun rẹ ni Jehofa yóò ràn jáde lọ láti Sioni, ní sísọ pé: ‘Lọ jọba láàárín àwọn ọ̀tá rẹ.’”—Orin Dafidi 110:1-4, NW.
14 Nígbà wo ni ìyẹn yóò jẹ́? Jesu kò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba nígbà tí ó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn. (Johannu 18:33-37) Ní 33 C.E., ó kú, a jí i dìde, ó sì gòkè re ọ̀run. Heberu 10:12 sọ pé: “Ọkùnrin yii rú ẹbọ kanṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ títí lọ kánrin ó sì jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun.” Ọlá àṣẹ wo ni Jesu ní? “[Ọlọrun] mú un jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ní awọn ibi ọ̀run, lókè fíofío rékọjá gbogbo ìjọba-àkóso ati ọlá-àṣẹ ati agbára ati ipò oluwa . . . ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ.” (Efesu 1:20-22) Nítorí pé Jesu ní ọlá àṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọba lórí àwọn Kristian nígbà náà lọ́hùn-ún, Paulu lè kọ̀wé pé, Jehofa “dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ọlá-àṣẹ òkùnkùn ó sì ṣí wa nípò lọ sínú ìjọba Ọmọkùnrin ìfẹ́ rẹ̀.”—Kolosse 1:13; 3:1.
15, 16. (a) Èé ṣe tí a fi sọ pé Jesu kò di Ọba Ìjọba Ọlọrun ní 33 C.E.? (b) Nígbà wo ni Jesu bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso nínú Ìjọba Ọlọrun?
15 Ṣùgbọ́n, ní àkókò yẹn, Jesu kò ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba àti Onídàájọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè. Ó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọrun, ó ń dúró de àkókò náà láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọrun. Paulu kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Èwo ninu awọn áńgẹ́lì ni oun wí nipa rẹ̀ rí pé: ‘Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí emi yoo fi gbé awọn ọ̀tá rẹ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpótí-ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ’?”—Heberu 1:13.
16 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti tẹ ọ̀pọ̀ ẹ̀rí jáde pé sáà dídúró Jesu ti wá sópin ní 1914, nígbà tí ó di alákòóso Ìjọba Ọlọrun nínú àwọn ọ̀run tí a kò lè fojú rí. Ìṣípayá 11:15, 18 sọ pé: “Ìjọba ayé di ìjọba Oluwa wa ati ti Kristi rẹ̀, oun yoo sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí láé ati láéláé.” “Ṣugbọn awọn orílẹ̀-èdè kún fún ìrunú, ìrunú tìrẹ sì dé.” Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn orílẹ̀-èdè fi ìrunú wọn hàn sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì nígbà Ogun Àgbáyé I. (Luku 21:24) Ogun, ìmìtìtì ilẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn, ọ̀wọ́n oúnjẹ, àti irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, tí a ti ń rí láti 1914 jẹ́rìí sí i pé Jesu ń ṣàkóso nísinsìnyí nínú Ìjọba Ọlọrun, òpin ìkẹyìn ayé yìí sì ti sún mọ́lé.—Matteu 24:3-14.
17. Àwọn kókó pàtàkì wo ni a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ báyìí?
17 Láti ṣàtúnyẹ̀wò ráńpẹ́: A lè sọ pé Ọlọrun jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba, ṣùgbọ́n lọ́nà mìíràn, ó lè jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ láti ṣèdájọ́. Ní 33 C.E., Jesu jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, òun sì ni Ọba Ìjọba náà nísinsìnyí. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ Jesu tí ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba nísinsìnyí, tún ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ bí? Èé sì ti ṣe tí èyí fi ní láti kàn wá, ní pàtàkì ní àkókò yìí?
18. Ẹ̀rí wo ni ó wà pé Jesu pẹ̀lú yóò jẹ́ Onídàájọ́?
18 Jehofa, ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti yan àwọn onídàájọ́ sípò, yan Jesu gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ tí ó bá ọ̀pá ìdiwọ̀n Rẹ̀ mu. Jesu fi èyí hàn nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa kí ènìyàn wà láàyè nípa tẹ̀mí: “Baba kì í ṣèdájọ́ ẹnikẹ́ni rárá, ṣugbọn ó ti fi gbogbo ìdájọ́ ṣíṣe lé Ọmọkùnrin lọ́wọ́.” (Johannu 5:22) Síbẹ̀, ipa iṣẹ́ Jesu gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ lọ ré kọjá irú ìdájọ́ yẹn, nítorí pé òun jẹ́ onídàájọ́ àwọn alààyè àti àwọn òkú. (Ìṣe 10:42; 2 Timoteu 4:1) Paulu polongo nígbà kan pé: “[Ọlọrun] ti dá ọjọ́ kan ninu èyí tí oun pète lati ṣèdájọ́ ilẹ̀-ayé tí à ń gbé ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan [Jesu] tí oun ti yànsípò, ó sì ti pèsè ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà kan fún gbogbo ènìyàn níti pé ó ti jí i dìde kúrò ninu òkú.”—Ìṣe 17:31; Orin Dafidi 72:2-7.
19. Èé ṣe tí o fi tọ́ láti sọ pé Jesu ń jókòó gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́?
19 Nígbà náà, ó ha tọ́ kí a parí èrò sí pé, Jesu jókòó lórí ìtẹ́ ológo rẹ̀ ní kíkó ipa pàtó gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Jesu sọ fún àwọn aposteli pé: “Ní àtúndá, nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ ti tọ̀ mí lẹ́yìn yoo jókòó fúnra yín pẹlu sórí ìtẹ́ méjìlá, ẹ óò máa ṣèdájọ́ ẹ̀yà Israeli méjìlá.” (Matteu 19:28) Bí Jesu tilẹ̀ ti di Ọba Ìjọba náà nísinsìnyí, ìgbòkègbodò rẹ̀ síwájú sí i tí a mẹ́nu kàn nínú Matteu 19:28 yóò ní jíjókòó lórí ìtẹ́ láti ṣèdájọ́ nígbà Ẹgbẹ̀rúndún nínú. Ní àkókò yẹn, òun yóò ṣèdájọ́ gbogbo aráyé, àwọn olódodo àti aláìṣòdodo. (Ìṣe 24:15) Yóò ṣèrànwọ́ láti fi èyí sọ́kàn bí a ṣe ń darí àfiyèsí wa sí ọ̀kan nínú àwọn òwe àkàwé Jesu tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àkókò wa àti ìwàláàyè wa.
Kí Ni Òwe Àkàwé Náà Sọ?
20, 21. Kí ni àwọn aposteli Jesu béèrè, tí ó jẹ mọ́ àkókò wa, ìbéèrè wo sì ni ó yọrí sí?
20 Kété ṣáájú kí Jesu tó kú, àwọn aposteli rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọnyi yoo ṣẹlẹ̀, kí ni yoo sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ ati ti ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan?” (Matteu 24:3) Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì lórí ilẹ̀ ayé ṣáájú kí ‘òpin tó dé.’ Kété kí òpin náà tó dé, àwọn orílẹ̀-èdè yóò “rí Ọmọkùnrin ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run pẹlu agbára ati ògo ńlá.”—Matteu 24:14, 29, 30.
21 Ṣùgbọ́n, báwo ni nǹkan yóò ti rí fún àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn, nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀? Ẹ jẹ́ kí a ṣèwádìí nínú òwe àkàwé ti àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́, tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ náà: “Nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé ninu ògo rẹ̀, ati gbogbo awọn áńgẹ́lì pẹlu rẹ̀, nígbà naa ni oun yoo jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ni a óò sì kó jọ níwájú rẹ̀.”—Matteu 25:31, 32.
22, 23. Àwọn kókó wo ni ó fi hàn pé òwe àkàwé nípa àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ kò bẹ̀rẹ̀ sí ní ìmúṣẹ ní 1914?
22 Òwe àkàwé yìí ha ní í ṣe pẹ̀lú 1914, nígbà tí Jesu jókòó nínú agbára gẹ́gẹ́ bí Ọba, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe lóye rẹ̀ tẹ́lẹ̀ bí? Tóò, Matteu 25:34 sọ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba, nítorí náà lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, òwe àkàwé náà ní í ṣe pẹ̀lú ìgbà tí Jesu ti di Ọba ní 1914. Ṣùgbọ́n ìdájọ́ wo ni ó ṣe ní kété lẹ́yìn náà? Kì í ṣe ìdájọ́ “gbogbo awọn orílẹ̀-èdè.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn tí wọ́n ń sọ pé àwọn para pọ̀ jẹ́ “ilé Ọlọrun.” (1 Peteru 4:17) Ní ìbámu pẹ̀lú Malaki 3:1-3, Jesu, gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ Jehofa, bẹ àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró tí ó ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ ayé wò láti ṣèdájọ́ wọn. Ó tún jẹ́ àkókò fún ìdájọ́ lórí Kristẹndọmu, tí ó fi èké jẹ́wọ́ pé òún jẹ́ “ilé Ọlọrun.”c (Ìṣípayá 17:1, 2; 18:4-8) Síbẹ̀, kò sí ohunkóhun tí ó fi hàn pé, nígbà náà lọ́hùn-ún, tàbí láti ìgbà náà wá, Jesu ti jókòó láti ṣèdájọ́ àwọn ènìyàn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nígbẹ̀yìngbẹ́yín, gẹ́gẹ́ bí àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́.
23 Bí a bá ṣàyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ ìgbòkègbodò Jesu nínú òwe àkàwé náà, a óò rí i pé, ó ṣèdájọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Òwe àkàwé náà kò fi hàn pé irú ìdájọ́ bẹ́ẹ̀ yóò máa bá a nìṣó fún sáà gígùn ọlọ́dún púpọ̀, bí ẹni pé ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ń kú ní àwọn ẹ̀wádún tí ó ti kọjá wọ̀nyí ni a ti ṣèdájọ́ wọn pé, wọ́n yẹ fún ikú àìnípẹ̀kun tàbí ìyè àìnípẹ̀kun. Ó dà bí ẹni pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ó ti kú ní àwọn ẹ̀wádún lọ́ọ́lọ́ọ́ ti lọ sí isà okú ti gbogbo aráyé. (Ìṣípayá 6:8; 20:13) Ṣùgbọ́n, òwe àkàwé náà ń ṣàpèjúwe àkókò náà nígbà tí Jesu ń ṣèdájọ́ àwọn ènìyàn “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” tí wọ́n wà láàyè nígbà náà, tí wọ́n sì dojú kọ ìmúṣẹ ìdájọ́ rẹ̀.
24. Nígbà wo ni òwe àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ yóò ní ìmúṣẹ?
24 Ní èdè mìíràn, òwe àkàwé náà ń tọ́ka sí ọjọ́ ọ̀la, nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn yóò wá nínú ògo rẹ̀. Òun yóò jókòó láti ṣèdájọ́ àwọn ènìyàn tí ó bá wà láàyè nígbà náà. Yóò gbé ìdájọ́ rẹ̀ karí ohun tí wọ́n ti fi hàn pé àwọn fúnra wọn jẹ́. Ní àkókò yẹn “ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni búburú” yóò ti fìdí múlẹ̀ lọ́nà ṣíṣe kedere. (Malaki 3:18) Kíkéde ìdájọ́ náà ní ti gidi àti ìmúdàájọ́ṣẹ ni a óò ṣe ní àkókò tí ó mọ níwọ̀n. Jesu yóò ṣe àwọn ìpinnu tí ó tọ́, tí a gbé karí ohun tí ó ti hàn gbangba nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan.—Tún wo 2 Korinti 5:10.
25. Kí ni Matteu 25:31 ṣàpèjúwe, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa Ọmọkùnrin ènìyàn, tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ológo?
25 Nítorí náà, èyí túmọ̀ sí pé, ‘jíjókòó tí’ Jesu ‘jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀’ fún ìdájọ́, tí a mẹ́nu kàn nínú Matteu 25:31, ní í ṣe pẹ̀lú àkókò ọjọ́ ọ̀la, nígbà tí Ọba alágbára yìí yóò jókòó láti kéde ìdájọ́, kí ó sì múdàájọ́ ṣẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè. Bẹ́ẹ̀ ni, ìran ìdájọ́ tí ó kan Jesu ní Matteu 25:31-33, 46 ṣeé fi wé ìran inú Danieli orí 7, níbi tí Ọba tí ń ṣàkóso náà, Ẹni-àgbà ọjọ́ nì, ti jókòó láti ṣe ipa tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́.
26. Àlàyé tuntun wo ní ó wá sí ojútáyé nípa òwe àkàwé náà?
26 Lílóye òwe àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ lọ́nà yìí fi hàn pé, ṣíṣèdájọ́ àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ yóò jẹ́ ní ọjọ́ ọ̀la. Yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí “ìpọ́njú ńlá” náà tí a mẹ́nu kàn ní Matteu 24:29, 30 bá bẹ́ sílẹ̀, tí Ọmọkùnrin ènìyàn sì ‘dé nínú ògo rẹ̀.’ (Fi wé Marku 13:24-26.) Nígbà náà, nígbà tí ètò ìgbékalẹ̀ búburú látòkèdélẹ̀ bá ti lọ sí òpin rẹ̀, Jesu yóò pè àpèjọ ìdájọ́, yóò ṣèdájọ́, yóò sì múdàájọ́ ṣẹ.—Johannu 5:30; 2 Tessalonika 1:7-10.
27. Kí ni a ní láti lọ́kàn ìfẹ́ sí láti mọ̀ nípa òwe àkàwé Jesu tí ó kẹ́yìn?
27 Èyí mú òye wa nípa àkókò tí òwe àkàwé Jesu náà ní ìmúṣẹ ṣe kedere, èyí tí ó fi ìgbà tí a óò ṣèdájọ́ àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ hàn. Ṣùgbọ́n báwo ni ó ṣe nípa lórí àwa tí a ń fi pẹ̀lú ìtara wàásù ìhìnrere Ìjọba náà? (Matteu 24:14) Ó ha dín ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ wa kù bí, tàbí ó mú ẹrù iṣẹ́ wíwúwo sí i wá bí? Ẹ jẹ kí a wo bí ó ṣe kàn wá nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ náà tí a pè ní “àwọn onídàájọ́” nínú Danieli 7:10, 26 ni a tún rí nínú Esra 7:26 àti Danieli 4:37; 7:22.
b Ní ti kí àwọn Kristian máa pe ara wọn lẹ́jọ́ lẹ́nì kìíní-kejì, Paulu béèrè pé: “Ó ha jẹ́ awọn ọkùnrin tí a ń fojú-tẹ́ḿbẹ́lú ninu ìjọ ni ẹ̀yin ń fi sípò gẹ́gẹ́ bí awọn onídàájọ́ [ní òwuuru “ni ẹ̀yin ń bá jókòó bí”]?”—1 Korinti 6:4.
c Wo Revelation—Its Grand Climax At Hand!, ojú ìwé 56, 73, 235 sí 245, 260, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Báwo ni Jehofa ṣe ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba àti Onídàájọ́?
◻ Ìtumọ̀ méjì wo ni ‘jíjókòó lórí ìtẹ́’ lè ní?
◻ Kí ni a ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò tí Matteu 25:31 ní ìmúṣẹ, ṣùgbọ́n, ìpìlẹ̀ wo ni ó wà fún ojú ìwòye tí a tún ṣe?
◻ Nígbà wo ni Ọmọkùnrin ènìyàn jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn nínú Matteu 25:31?