ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Bó O Ṣe Lè Máa Wàásù Ìhìn Rere Fáwọn Èèyàn
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • 1. Báwo lo ṣe lè sọ ohun tó ò ń kọ́ fún tẹbítọ̀rẹ́?

      Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé: “A ò lè ṣàì sọ ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.” (Ìṣe 4:20) Wọ́n nífẹ̀ẹ́ ohun tí Jésù kọ́ wọn débi pé wọ́n fẹ́ láti sọ ọ́ fún gbogbo èèyàn. Ṣé bó ṣe rí lára tìẹ náà nìyẹn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, wá ọ̀nà tó o lè gbà sọ ohun tó o ti kọ́ fún ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ, kó o sì ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.​—Ka Kólósè 4:6.

      Bó o ṣe lè ṣe é

      • Tó o bá fẹ́ sọ ohun tó o kọ́ nínú Bíbélì fáwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, o lè sọ pé: “Ohun kan wà tí mo kọ́ lọ́sẹ̀ yìí tó wọ̀ mí lọ́kàn gan-an.”

      • Tí ọ̀rẹ́ rẹ kan bá ń ṣàìsàn tàbí tó ní ìdààmú ọkàn, ka ẹsẹ Bíbélì kan fún un tó máa fi í lọ́kàn balẹ̀.

      • Tí ẹni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ bá béèrè pé ‘Báwo ni òpin ọ̀sẹ̀?’ o lè fi àǹfààní yẹn sọ ohun tó o kọ́ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ tàbí ohun tó o kọ́ ní ìpàdé ìjọ fún un.

      • Fi ìkànnì jw.org han àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.

      • Pe àwọn míì láti wá dara pọ̀ mọ́ ẹ tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí kó o jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè béèrè lórí ìkànnì jw.org pé kí ẹnì kan wá máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

  • Bó O Ṣe Lè Máa Wàásù Ìhìn Rere Fáwọn Èèyàn
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • 4. Máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn

      Tó o bá ń wàásù ìhìn rere náà, kì í ṣe ohun tó o fẹ́ sọ nìkan ló yẹ kó o máa rò, ó tún yẹ kó o ronú nípa ọ̀nà tó o máa gbà sọ ọ́. Ka 2 Tímótì 2:24 àti 1 Pétérù 3:15, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí tó o bá fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn?

      • Táwọn ará ilé ẹ kan tàbí àwọn ọ̀rẹ́ ẹ kan ò bá fara mọ́ ohun tó ò ń sọ, kí ló yẹ kó o ṣe, kí sì ni kò yẹ kó o ṣe?

      • Kí nìdí tó fi dáa pé kó o fọgbọ́n béèrè ìbéèrè táá mú káwọn èèyàn ronú jinlẹ̀ dípò kó o fi dandan mú wọn láti gba ohun tó ò ń sọ gbọ́?

      Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ń fi nǹkan han mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ninú Bíbélì.
Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́