Àwọn Kristẹni Ń jọ́sìn Ní Ẹ̀mí Àti Òtítọ́
“Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí, àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.”—JÒHÁNÙ 4:24.
1. Irú ìjọsìn wo ni inú Ọlọ́run dùn sí?
JÉSU KRISTI, ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Jèhófà, kò fi wá sínú òkùnkùn rárá nípa irú ìjọsìn tínú Baba rẹ̀ ọ̀run dùn sí. Nígbà tí Jésù ń jẹ́rìí tí ń múni lọ́kàn yọ̀ fún obìnrin ará Samáríà kan lẹ́bàá kànga kan nítòsí ìlú Síkárì, ó sọ fún obìnrin náà pé: “Ẹ̀yin ń jọ́sìn ohun tí ẹ kò mọ̀; àwa ń jọ́sìn ohun tí àwa mọ̀, nítorí pé ìgbàlà pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn Júù. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wákàtí náà ń bọ̀, ìsinsìnyí sì ni, nígbà tí àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́, nítorí pé, ní tòótọ́, irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá láti máa jọ́sìn òun. Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí, àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:22-24) Kí làwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn túmọ̀ sí?
2. Orí kí ni àwọn ará Samáríà gbé ìjọsìn wọn kà?
2 Èrò àwọn ará Samáríà nípa ẹ̀sìn kò tọ̀nà. Kìkì ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ ni wọ́n gbà pé ó ní ìmísí—ìyẹn sì jẹ́ kìkì nínú àtúntẹ̀ tiwọn tí a mọ̀ sí Ìwé Márùn-ún Àkọ́kọ́ ti Àwọn Ará Samáríà. Nígbà tó jẹ́ pé àwọn ará Samáríà ò mọ Ọlọ́run ní ti gidi, àwọn Júù ní tiwọn la fi ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ síkàáwọ́ wọn. (Róòmù 3:1, 2) Ó ṣeé ṣe fún àwọn Júù olóòótọ́ àtàwọn mìíràn láti rí ojú rere Jèhófà. Àmọ́ kí ni èyí ń béèrè pé kí wọ́n ṣe?
3. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè jọ́sìn Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́”?
3 Kí ni àwọn Júù, àwọn ará Samáríà, àtàwọn ẹlòmíràn tó wà láyé nígbà yẹn lọ́hùn-ún ní láti ṣe kí wọ́n tó lè múnú Ọlọ́run dùn? Wọ́n ní láti jọ́sìn rẹ̀ “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” Bẹ́ẹ̀ làwa náà gbọ́dọ̀ ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ̀mítẹ̀mí àti tìtaratìtara ló yẹ ká máa fi ṣe iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run, kó sì jẹ́ pé ọkàn tó kún fún ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ ló ń sún wa ṣe é, síbẹ̀ jíjọ́sìn Ọlọ́run ní ẹ̀mí ń béèrè ní pàtàkì pé ká ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ká sì jẹ́ kí ẹ̀mí yẹn máa darí wa. Ẹ̀mí wa tàbí èrò orí wa tún gbọ́dọ̀ bá ti Ọlọ́run mu nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ àti fífi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò. (1 Kọ́ríńtì 2:8-12) Kí Jèhófà lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, a tún gbọ́dọ̀ sìn ín ní òtítọ́. Ìjọsìn wa sì gbọ́dọ̀ bá ohun tí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣí payá nípa rẹ̀ àti nípa àwọn ète rẹ̀ mu.
A Lè Rí Òtítọ́
4. Ojú wo làwọn kan fi ń wo òtítọ́?
4 Àwọn kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ọgbọ́n orí sọ pé kó síbi téèyàn ti lè rí ohun tó ń jẹ́ òtítọ́ pọ́ńbélé. Àní, òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Sweden nì, Alf Ahlberg kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó dá lé ìmọ̀ ọgbọ́n orí ló jẹ́ èyí tí kò ní ìdáhùn kan pàtó.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan sọ pé ààbọ̀ òtítọ́ ló wà, ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí? Ìyẹn yàtọ̀ pátápátá sí èrò Jésù Kristi.
5. Kí nìdí tí Jésù fi wá sí ayé?
5 Ẹ jẹ́ ká fojú inú wò ó pé a wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ tó tẹ̀ lé e yìí: Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 33 Sànmánì Tiwa ni. Jésù dúró níwájú Gómìnà ará Róòmù náà, Pọ́ńtíù Pílátù. Jésù sọ fún Pílátù pé: “Nítorí èyí . . . ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” Pílátù béèrè pé: “Kí ni òtítọ́?” Àmọ́ kò dúró gbọ́ ohun tí Jésù sọ lẹ́yìn ìyẹn.—Jòhánù 18:36-38.
6. (a) Báwo làwọn kan ṣe túmọ̀ “òtítọ́”? (b) Iṣẹ́ wo ni Jésù pa láṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
6 Àwọn kan sọ pé ohun tí “òtítọ́” túmọ̀ sí ni “àpapọ̀ àwọn nǹkan tó jẹ́ gidi, tó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi, tó sì jẹ́ òdodo ọ̀rọ̀.” (Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary) Àmọ́ ṣé òtítọ́ ní gbogbo gbòò ni Jésù jẹ́rìí sí? Rárá o. Ó ní òtítọ́ kan pàtó lọ́kàn. Ó pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n polongo irú òtítọ́ bẹ́ẹ̀, nítorí ó sọ fún wọn pé: “Ẹ . . . máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Ṣáájú òpin ètò àwọn nǹkan yìí, àwọn tó jẹ́ ojúlówó ọmọlẹ́yìn Jésù ní láti polongo “òtítọ́ ìhìn rere” jákèjádò ayé. (Mátíù 24:3; Gálátíà 2:14) Èyí gbọ́dọ̀ di ṣíṣe kí ọ̀rọ̀ Jésù lè nímùúṣẹ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì láti mọ àwọn tó ń fi òtítọ́ kọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè nípa wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà.
Bí A Ṣe Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́
7. Báwo lo ṣe máa fi hàn pé Jèhófà ni Orísun òtítọ́?
7 Jèhófà ni Orísun òtítọ́ tẹ̀mí. Kódà, onísáàmù náà, Dáfídì, pe Jèhófà ní “Ọlọ́run òtítọ́.” (Sáàmù 31:5; 43:3) Jésù sọ pé ọ̀rọ̀ Baba òun jẹ́ òtítọ́, ó sì polongo pé: “A kọ̀wé rẹ̀ nínú àwọn Wòlíì pé, ‘Gbogbo wọn yóò sì jẹ́ àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.’ Gbogbo ẹni tí ó bá ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, tí ó sì ti kẹ́kọ̀ọ́, ń wá sọ́dọ̀ mi.” (Jòhánù 6:45; 17:17; Aísáyà 54:13) Ó wá ṣe kedere pé, àwọn tó ń wá òtítọ́ gbọ́dọ̀ di ẹni tí Jèhófà, Atóbilọ́lá Olùkọ́ni, kọ́. (Aísáyà 30:20, 21) Àwọn olùwá òtítọ́ ní láti gba “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.” (Òwe 2:5) Onírúurú ọ̀nà ni Jèhófà sì ti fìfẹ́ kọ́ni ní òtítọ́.
8. Àwọn ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà kọ́ wa ní òtítọ́ tàbí tí ó gbà fi ránṣẹ́ sí wa?
8 Bí àpẹẹrẹ, ipasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì ni Jèhófà gba fi Òfin ránṣẹ́ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Gálátíà 3:19) Ó ṣèlérí ìbùkún fún àwọn baba ńlá náà, Ábúráhámù àti Jékọ́bù lójú àlá. (Jẹ́nẹ́sísì 15:12-16; 28:10-19) Ọlọ́run tiẹ̀ sọ̀rọ̀ láti ọ̀run pàápàá, bí irú ìgbà tí Jésù ṣe ìrìbọmi, táwọn èèyàn sì gbọ́ ọ̀rọ̀ amúnilọ́kànyọ̀ wọ̀nyí lórí ilẹ̀ ayé pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:17) A tún dúpẹ́ pé Ọlọ́run fi òtítọ́ ránṣẹ́ sí wa nípa mímí sí àwọn tó kọ Bíbélì. (2 Tímótì 3:16, 17) Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe fún wa láti ní ‘ìgbàgbọ́ nínú òtítọ́.’—2 Tẹsalóníkà 2:13.
Òtítọ́ àti Ọmọ Ọlọ́run
9. Báwo ni Ọlọ́run ṣe lo Ọmọ rẹ̀ láti ṣí òtítọ́ payá?
9 Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni bí Ọlọ́run ṣe lo Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, láti ṣí òtítọ́ payá fún aráyé. (Hébérù 1:1-3) Àní, Jésù sọ òtítọ́ ju bí ènìyàn èyíkéyìí ti sọ ọ́ rí lọ. (Jòhánù 7:46) Kódà lẹ́yìn tó gòkè re ọ̀run, ó tún ṣí òtítọ́ tó ti ọ̀dọ̀ Baba rẹ̀ wá payá. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Jòhánù gba “ìṣípayá láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi, èyí tí Ọlọ́run fi fún un, láti fi han àwọn ẹrú rẹ̀, àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́.”—Ìṣípayá 1:1-3.
10, 11. (a) Kí ni òtítọ́ tí Jésù jẹ́rìí sí tan mọ́? (b) Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ kí òtítọ́ hàn gbangba?
10 Jésù sọ fún Pọ́ńtíù Pílátù pé ohun tó gbé Òun wá sí ayé ni láti wá jẹ́rìí sí òtítọ́. Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ó fi hàn pé irú òtítọ́ bẹ́ẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú dídá ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láre nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run tí Kristi jẹ́ Ọba rẹ̀. Àmọ́, jíjẹ́rìí sí òtítọ́ béèrè ju pé kí Jésù kàn máa wàásù, kó sì máa kọ́ni lọ. Jésù mú kí òtítọ́ hàn gbangba nípa mímú un ṣẹ. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan ṣèdájọ́ yín nínú jíjẹ àti mímu tàbí ní ti àjọyọ̀ kan tàbí ní ti ààtò àkíyèsí òṣùpá tuntun tàbí ní ti sábáàtì; nítorí nǹkan wọnnì jẹ́ òjìji àwọn nǹkan tí ń bọ̀, ṣùgbọ́n ohun gidi náà jẹ́ ti Kristi.”—Kólósè 2:16, 17.
11 Ọ̀kan lára ọ̀nà tí òtítọ́ náà fi nímùúṣẹ ni ọ̀rọ̀ lórí àsọtẹ́lẹ̀ ìbí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. (Míkà 5:2; Lúùkù 2:4-11) Òtítọ́ náà tún hàn gbangba nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì nípa dídé Mèsáyà ní òpin ‘ọ̀sẹ̀ àwọn ọdún’ mọ́kàndínláàádọ́rin [69] náà nímùúṣẹ. Èyí wáyé nígbà tí Jésù yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún Ọlọ́run nígbà tó ṣe ìrìbọmi, tá a sì fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án ní àkókò tí a sọ tẹ́lẹ̀ gan-an, ìyẹn ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa. (Dáníẹ́lì 9:25; Lúùkù 3:1, 21, 22) Òtítọ́ náà túbọ̀ ṣe kedere nípasẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ń lani lóye tí Jésù ṣe gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba náà. (Aísáyà 9:1, 2, 6, 7; 61:1, 2; Mátíù 4:13-17; Lúùkù 4:18-21) Ó tún hàn gbangba nípasẹ̀ ikú àti àjíǹde rẹ̀.—Sáàmù 16:8-11; Aísáyà 53:5, 8, 11, 12; Mátíù 20:28; Jòhánù 1:29; Ìṣe 2:25-31.
12. Èé ṣe tí Jésù fi sọ pé, ‘Èmi ni òtítọ́’?
12 Dídá tí òtítọ́ náà dá lórí Jésù Kristi ló fi lè sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Àwọn èèyàn á dòmìnira nípa tẹ̀mí, bí wọ́n bá dúró sí “ìhà ọ̀dọ̀ òtítọ́” nípa títẹ́wọ́ gba ipa tí Jésù kó nínú ète Ọlọ́run. (Jòhánù 8:32-36; 18:37) Nítorí pé àwọn ẹni bí àgùntàn tẹ́wọ́ gba òtítọ́ náà, tí wọ́n sì fi ìgbàgbọ́ tẹ̀ lé Kristi, wọn óò ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 10:24-28.
13. Àwọn kókó mẹ́ta wo la ó fi ṣàyẹ̀wò òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́?
13 Àpapọ̀ òtítọ́ tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tá a mí sí fi kọ́ni ló jẹ́ ìgbàgbọ́ Kristẹni tòótọ́. Ìyẹn la fi lè sọ pé àwọn tó “di onígbọràn sí ìgbàgbọ́ náà” ń ‘rìn nínú òtítọ́.’ (Ìṣe 6:7; 3 Jòhánù 3, 4) Nítorí náà, àwọn wo ló wá ń rìn nínú òtítọ́ lónìí? Àwọn wo ló sì ń fi òtítọ́ kọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè ní ti gidi? Láti dáhùn irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀, a ó darí àfiyèsí sọ́dọ̀ àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, a ó sì ṣàyẹ̀wò òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ nípa (1) ìgbàgbọ́, (2) ọ̀nà ìjọsìn, àti (3) ìwà kálukú.
Òtítọ́ àti Ìgbàgbọ́
14, 15. Kí lo lè sọ nípa irú ọwọ́ tí àwọn Kristẹni ìjímìjí àti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi mú Ìwé Mímọ́?
14 Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fọwọ́ pàtàkì mú Ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà lákọsílẹ̀. (Jòhánù 17:17) Òun ni ọ̀pá ìdiwọ̀n wọn nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣe. Clement ti Alẹkisáńdíríà tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kejì sí ìkẹta sọ pé: “Àwọn tó bá ń sapá láti ní ànímọ́ títayọ kò ní yéé wá òtítọ́ kiri, títí di ìgbà tí wọ́n bá rí ẹ̀rí pé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ bá Ìwé Mímọ́ fúnra rẹ̀ mu.”
15 Bíi tàwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fọwọ́ pàtàkì mú Bíbélì. Wọ́n gbà gbọ́ pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni.” (2 Tímótì 3:16) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára ohun táwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbà gbọ́, a ó sì fi wọ́n wé ohun tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní ti kọ́ nítorí pé Bíbélì ni olórí ìwé tí wọ́n ń lò.
Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ọkàn
16. Kí ni ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa ọkàn?
16 Nítorí pé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gba ohun tí Ìwé Mímọ́ wí gbọ́, ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa ọkàn ni wọ́n fi kọ́ni. Wọ́n mọ̀ pé ‘èèyàn wá di alààyè ọkàn’ nígbà tí Ọlọ́run dá a. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Ní àfikún sí i, wọ́n gbà pé ọkàn èèyàn máa ń kú. (Ìsíkíẹ́lì 18:4; Jákọ́bù 5:20) Wọ́n tún mọ̀ pé ‘àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.’—Oníwàásù 9:5, 10.
17. Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ìrètí tó wà fún àwọn òkú?
17 Síbẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ìjímìjí ní ìrètí tó dájú pé àwọn òkú tó wà ní ìrántí Ọlọ́run yóò ní àjíǹde, tàbí pé a óò mú wọn padà bọ̀ sí ìyè. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ìgbàgbọ́ yẹn ní kedere nígbà tó sọ pé: “Mo sì ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọ́run . . . pé àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Kódà lẹ́yìn ìgbà yẹn, Minucius Felix, tó pera rẹ̀ ní Kristẹni kọ̀wé pé: “Ta ló gọ̀ tàbí tí orí rẹ̀ kú débi tá a fi sọ pé Ọlọ́run tó dá èèyàn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ kò tún ní lè tún un dá ní ọ̀tun?” Bíi ti àwọn Kristẹni ìjímìjí, òtítọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa ọkàn èèyàn, ikú, àti àjíǹde ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì gbà gbọ́. Ẹ jẹ́ ká wá ṣàgbéyẹ̀wò bí Ọlọ́run àti Kristi ṣe jẹ́.
Òtítọ́ àti Mẹ́talọ́kan
18, 19. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Mẹ́talọ́kan kì í ṣe ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́?—Mátíù 28:19.
18 Àwọn Kristẹni ìjímìjí kò ka Ọlọ́run, Kristi, àti ẹ̀mí mímọ́ sí Mẹ́talọ́kan. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ọ̀rọ̀ náà, Mẹ́talọ́kan àti ẹ̀kọ́ ọ̀hún lódindi kò sí nínú Májẹ̀mú Tuntun rárá, bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kò gbìyànjú láti tako Ṣémà [àdúrà Hébérù kan] tó wà nínú Májẹ̀mú Láéláé pé: ‘Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì: Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ Olúwa kan’ (Diu. 6:4).” Àwọn Kristẹni kò jọ́sìn òrìṣà-mẹ́ta-nínú-ọ̀kan ti ilẹ̀ Róòmù tàbí àwọn òrìṣà mìíràn rárá. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, pé Jèhófà nìkan ṣoṣo la gbọ́dọ̀ jọ́sìn, ni wọ́n fara mọ́. (Mátíù 4:10) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún gba ọ̀rọ̀ Kristi gbọ́ pé: “Baba tóbi jù mi lọ.” (Jòhánù 14:28) Ohun kan náà ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ lónìí.
19 Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ìjímìjí fi ìyàtọ̀ tó ṣe kedere sáàárín Ọlọ́run, Kristi, àti ẹ̀mí mímọ́. Kódà, wọ́n batisí àwọn ọmọ ẹ̀yìn (1) ní orúkọ Baba, (2) ní orúkọ Ọmọ, àti (3) ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́, kì í ṣe ní orúkọ Mẹ́talọ́kan. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú ń fi òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ kọ́ni, a sì ń fìyàtọ̀ sáàárín Ọlọ́run, Ọmọ rẹ̀, àti ẹ̀mí mímọ́.
Òtítọ́ àti Ìrìbọmi
20. Ìmọ̀ wo làwọn tó fẹ́ ṣe ìrìbọmi gbọ́dọ̀ ní?
20 Jésù pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa sọni di ọmọ ẹ̀yìn nípa kíkọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́. Káwọn èèyàn tó lè tóótun fún ìrìbọmi, wọ́n ní láti ní ìmọ̀ tó ṣe kókó nípa Ìwé Mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gba ipò àti ọlá àṣẹ Baba àti ti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi. (Jòhánù 3:16) Àwọn tó fẹ́ ṣe ìrìbọmi tún ní láti mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe ẹnì kan bí kò ṣe agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 1:2, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
21, 22. Kí nìdí tó o fi máa sọ pé àwọn onígbàgbọ́ là ń batisí?
21 Kìkì àwọn tó lóye, tí wọ́n ronú pìwà dà, tí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́ pátápátá fún Ọlọ́run láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ni àwọn Kristẹni ìjímìjí ṣe batisí fún. Àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe tí wọ́n kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa ti ní ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ṣáájú àkókò yẹn. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pétérù sọ nípa Jésù tí í ṣe Mèsáyà, nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] èèyàn ló “fi tọkàntọkàn gba ọ̀rọ̀ rẹ̀” tí a sì “batisí.”—Ìṣe 2:41; 3:19–4:4; 10:34-38.
22 Àwọn tó gbà gbọ́ ni à ń batisí gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Àwọn èèyàn ìlú Samáríà tẹ́wọ́ gba òtítọ́, “nígbà tí wọ́n [sì] gba Fílípì gbọ́, ẹni tí ń polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run àti orúkọ Jésù Kristi, a bẹ̀rẹ̀ sí batisí wọn, lọ́kùnrin àti lóbìnrin.” (Ìṣe 8:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwẹ̀fà ará Etiópíà tó jẹ́ olùfọkànsìn aláwọ̀ṣe ti mọ̀ nípa Jèhófà tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ ó kọ́kọ́ gba ọ̀rọ̀ tí Fílípì sọ nípa ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Mèsáyà gbọ́, kó tó di pé ó ṣe ìrìbọmi. (Ìṣe 8:34-36) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Pétérù sọ fún Kọ̀nílíù àtàwọn Kèfèrí mìíràn pé “ẹni tí ó bá bẹ̀rù [Ọlọ́run], tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un” àti pé ẹnikẹ́ni tó bá ló ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi á rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (Ìṣe 10:35, 43; 11:18) Gbogbo èyí ló wà níbàámu pẹ̀lú àṣẹ tí Jésù pa pé ká máa ‘sọni di ọmọ ẹ̀yìn, ká máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tó ti pa láṣẹ fún wa mọ́.’ (Mátíù 28:19, 20; Ìṣe 1:8) Ìlànà kan náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé, kìkì àwọn tó bá ní ìmọ̀ tó ṣe kókó nípa Ìwé Mímọ́, tí wọ́n sì ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run nìkan ni wọ́n máa ń batisí.
23, 24. Báwo ló ṣe yẹ ká batisí Kristẹni?
23 Ríri èèyàn bọnú omi pátápátá ni ìbatisí tó tọ̀nà fáwọn onígbàgbọ́. Lẹ́yìn tá a batisí Jésù nínú Odò Jọ́dánì, ó jáde “sókè kúrò nínú omi.” (Máàkù 1:10) A batisí ìwẹ̀fà ará Etiópíà nínú “ìwọ́jọpọ̀ omi.” Òun àti Fílípì “sọ kalẹ̀ lọ sínú omi náà,” lẹ́yìn náà wọ́n “jáde kúrò nínú” rẹ̀. (Ìṣe 8:36-40) Bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi ìbatisí wé sísin èèyàn tún fi hàn pé ohun tó tọ̀nà ni ríri èèyàn bọnú omi pátápátá.—Róòmù 6:4-6; Kólósè 2:12.
24 Ìwé The Oxford Companion to the Bible sọ pé: “Ṣíṣàpèjúwe àwọn ìbatisí kan nínú Májẹ̀mú Tuntun fi hàn pé ńṣe la gbọ́dọ̀ ri ẹni tí à ń batisí náà bọnú omi pátápátá.” Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé èdè Faransé náà, Larousse du XXe Siècle (Paris, 1928) wí, “àwọn Kristẹni àkọ́kọ́ pàá ṣe batisí wọn nípasẹ̀ ìrìbọmi níbikíbi tí wọ́n bá ti rí omi.” Bákan náà ni ìwé náà, After Jesus—The Triumph of Christianity sọ pé: “Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tí ẹni tó fẹ́ ṣe [batisí] gbọ́dọ̀ ní ni ìgbàgbọ́, lẹ́yìn náà ni rírì í bọnú omi pátápátá ní orúkọ Jésù á wá tẹ̀ lé e.”
25. Kí la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?
25 Àwọn kókó tá a mẹ́nu kàn lókè yìí nípa ìgbàgbọ́ tá a gbé karí Bíbélì àti àṣà àwọn Kristẹni àkọ́kọ́ pàá wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ díẹ̀ ni. A ṣì lè mẹ́nu kan àwọn ọ̀nà mìíràn tí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fi bá ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mu. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a óò jíròrò àwọn ọ̀nà mìíràn tá a fi lè dá àwọn tó ń kọ́ni ní òtítọ́ mọ̀.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Irú ìjọsìn wo ni Ọlọ́run ń fẹ́?
• Báwo ni òtítọ́ ṣe hàn gbangba nípasẹ̀ Jésù Kristi?
• Kí ló jẹ́ òtítọ́ nípa ọkàn àti ikú?
• Báwo la ṣe ń batisí Kristẹni, kí la sì ń retí látọ̀dọ̀ ẹni tó fẹ́ ṣe batisí náà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Jésù sọ fún Pílátù pé: ‘Mo wá láti jẹ́rìí sí òtítọ́’
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ǹjẹ́ o lè ṣàlàyé ìdí tí Jésù fi sọ pé: ‘Èmi ni òtítọ́’?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Kí ló jẹ́ òtítọ́ nípa bó ṣe yẹ kí Kristẹni ṣe batisí?