Ẹ Fi Ìfọkànsin Ọlọ́run Kún Ìfarada Yín
‘Ẹ fi ìfaradà kún ìgbàgbọ́ yín . . . ẹ sì fi ìfọkànsin Ọlọ́run kún ìfaradà yín.’—2 Pétérù 1:5, 6.
1, 2. (a) Irú ìdàgbàsókè wo la retí kí ọmọdé ní? (b) Báwo ni ìdàgbàsókè nípa tẹ̀mí ti ṣe pàtàkì tó?
DÍDÀGBÀSÓKÈ ṣe pàtàkì gan-an fún ọmọdé, àmọ́ ohun tá à ń fẹ́ kọjá wíwulẹ̀ dàgbà sókè lásán. A tún ń retí ìdàgbàsókè nínú èrò orí àti èrò ìmọ̀lára pẹ̀lú. Bí àkókò ti ń lọ, ọmọ náà yóò pa ìṣe ọmọdé tì, yóò sì dàgbà di géńdé ọkùnrin tàbí obìnrin. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí èyí nígbà tó kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo jẹ́ ìkókó, mo máa ń sọ̀rọ̀ bí ìkókó, ronú bí ìkókó, gbèrò bí ìkókó; ṣùgbọ́n nísinsìnyí tí mo ti wá di ọkùnrin, mo ti fi òpin sí àwọn ìwà ìkókó.”—1 Kọ́ríńtì 13:11.
2 Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí kókó pàtàkì kan nípa ìdàgbàsókè tẹ̀mí. Ó pọn dandan kí àwọn Kristẹni tẹ̀ síwájú látorí jíjẹ́ ìkókó nípa tẹ̀mí dórí dídi ẹni tó “dàgbà di géńdé nínú agbára òye.” (1 Kọ́ríńtì 14:20) Wọ́n gbọ́dọ̀ tiraka, kí wọ́n sì gbìyànjú láti “dé orí ìwọ̀n ìdàgbàsókè tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Kristi.” Ìyẹn ni wọn ò fi ní jẹ́ “ìkókó mọ́, tí a ń bì kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun, tí a sì ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ.”—Éfésù 4:13, 14.
3, 4. (a) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ dàgbà di géńdé nípa tẹ̀mí? (b) Àwọn ànímọ́ tínú Ọlọ́run dùn sí wo ló yẹ ká ní, báwo ni wọ́n sì ṣe ṣe pàtàkì tó?
3 Báwo la ṣe lè dàgbà di géńdé nípa tẹ̀mí? Nígbà tó jẹ́ pé ńṣe ni ìdàgbàsókè nípa tara máa ń wáyé fúnra rẹ̀, ìdàgbàsókè nípa tẹ̀mí gba ìsapá. Ó bẹ̀rẹ̀ látorí gbígba ìmọ̀ pípéye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú àti híhùwà níbàámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́. (Hébérù 5:14; 2 Pétérù 1:3) Èyí yóò wá ràn wá lọ́wọ́ láti ní àwọn ànímọ́ tínú Ọlọ́run dùn sí. Gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń rí nínú ọ̀ràn ìdàgbàsókè nípa tara àti gbogbo ohun tó wé mọ́ ọn, ẹ̀ẹ̀kan náà ni dídàgbà nínú onírúurú ànímọ́ tínú Ọlọ́run dùn sí máa ń wáyé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nípa fífi gbogbo ìsapá àfi-taratara-ṣe ṣètìlẹyìn ní ìdáhùnpadà, ẹ pèsè ìwà funfun kún ìgbàgbọ́ yín, ìmọ̀ kún ìwà funfun yín, ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀ yín, ìfaradà kún ìkóra-ẹni-níjàánu yín, ìfọkànsin Ọlọ́run kún ìfaradà yín, ìfẹ́ni ará kún ìfọkànsin Ọlọ́run yín, ìfẹ́ kún ìfẹ́ni ará yín.”—2 Pétérù 1:5-7.
4 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ànímọ́ tí Pétérù tò lẹ́sẹẹsẹ ló ṣe pàtàkì, kò sì sí èyí tó ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú wọn. Ó fi kún un pé: “Bí nǹkan wọ̀nyí bá wà nínú yín, tí wọ́n sì kún àkúnwọ́sílẹ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ di aláìṣiṣẹ́ tàbí aláìléso ní ti ìmọ̀ pípéye nípa Olúwa wa Jésù Kristi.” (2 Pétérù 1:8) Ẹ jẹ́ ká wá pọkàn pọ̀ sórí ìdí tó fi yẹ ká fi ìfọkànsin Ọlọ́run kún ìfaradà wa.
Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Ní Ìfaradà
5. Kí nìdí tá a fi nílò ìfaradà?
5 Àti Pétérù àti Pọ́ọ̀lù ló so ìfọkànsin Ọlọ́run mọ́ ìfaradà. (1 Tímótì 6:11) Ohun tí ìfaradà túmọ̀ sí kọjá wíwulẹ̀ fara da ìpọ́njú ká má sì juwọ́ sílẹ̀. Ó kan níní sùúrù, ìgboyà, àti ìdúróṣinṣin, ká má sì sọ̀rètí nù nígbà tá a bá dojú kọ ìdánwò, ìdènà, ìdẹwò, tàbí inúnibíni. Níwọ̀n bí a ti ń gbé pẹ̀lú “fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù,” a mọ̀ pé a ó ṣe inúnibíni sí wa. (2 Tímótì 3:12) A gbọ́dọ̀ fara dà á bí a bá fẹ́ fi ẹ̀rí hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí a sì mú àwọn ànímọ́ tá a nílò fún ìgbàlà dàgbà. (Róòmù 5:3-5; 2 Tímótì 4:7, 8; Jákọ́bù 1:3, 4, 12) Tá ò bá ní ìfaradà, a ò lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.—Róòmù 2:6, 7; Hébérù 10:36.
6. Kí ni fífaradà á títí dé òpin túmọ̀ sí?
6 Bó ti wù ká ṣe dáadáa tó níbẹ̀rẹ̀, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé ká ní ìfaradà. Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mátíù 24:13) Bẹ́ẹ̀ ni o, a gbọ́dọ̀ fara dà á dé òpin, yálà dé òpin ìgbésí ayé wa ti ìsinsìnyí tàbí títí dé òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí. Èyí ó wù kó jẹ́, a gbọ́dọ̀ pa ìwà títọ́ wa sí Ọlọ́run mọ́. Àmọ́ ṣá o, láìfi ìfọkànsìn Ọlọ́run kún ìfaradà wa, a ò lè múnú Jèhófà dùn, a ò sì lè rí ẹ̀bùn ìyè ayérayé gba. Ṣùgbọ́n kí ni ìfọkànsìn Ọlọ́run?
Ohun Tí Ìfọkànsìn Ọlọ́run Túmọ̀ Sí
7. Kí ni ìfọkànsìn Ọlọ́run, kí ló sì ń sún wa láti ṣe?
7 Ìfọkànsìn Ọlọ́run ni ọ̀wọ̀, ìjọsìn, àti iṣẹ́ ìsìn tá a ṣe fún Jèhófà Ọlọ́run nìkan nítorí dídúró tí a dúró ṣinṣin ti ipò rẹ̀ gẹ̀gẹ̀ bí ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Láti lè fi hàn pé à ń fọkàn sin Jèhófà, a ní láti ní ìmọ̀ pípéye nípa rẹ̀ àti nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀. Ó yẹ ká fẹ́ láti mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ ní àmọ̀dunjú. Èyí yóò jẹ́ ká ní àjọṣe àtọkànwá pẹ̀lú rẹ̀, èyí tó máa hàn nínú ìṣe wa àti nínú ọ̀nà ìgbésí ayé wa. A gbọ́dọ̀ sa gbogbo agbára wa láti dà bíi Jèhófà—ìyẹn ni pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ọ̀nà rẹ̀, ká sì máa gbé àwọn ànímọ́ àti àkópọ̀ ìwà rẹ̀ yọ. (Éfésù 5:1) Láìsí àní-àní, ìfọkànsìn Ọlọ́run ń sún wa láti fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe.—1 Kọ́ríńtì 10:31.
8. Báwo ni ìfọkànsìn Ọlọ́run àti ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe ṣe so pọ̀ mọ́ra wọn?
8 Bí a bá fẹ́ fi ìfọkànsìn Ọlọ́run ṣèwà hù ní ti tòótọ́, Jèhófà nìkan ṣoṣo la óò máa jọ́sìn, a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun mìíràn gba ipò rẹ̀ nínú ọkàn wa. Nítorí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé ká fún òun ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe. (Diutarónómì 4:24; Aísáyà 42:8) Síbẹ̀, Jèhófà ò fipá mú wa láti jọ́sìn òun. Ìfọkànsìn tá a fínnúfíndọ̀ ṣe ló ń fẹ́. Ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run, èyí tá a gbé ka ìmọ̀ pípéye nípa rẹ̀, ló ń sún wa láti tún ìgbésí ayé wa ṣe, tá a ya ara wa sí mímọ́ pátápátá fún un, tá a sì ń gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó bá ìyàsímímọ́ náà mu.
Ní Àjọṣe Pẹ̀lú Ọlọ́run
9, 10. Báwo la ṣe lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ tí yóò wà pẹ́ títí pẹ̀lú Ọlọ́run?
9 Lẹ́yìn tá a bá ti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wa sí Ọlọ́run hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi, a tún ní láti mú àjọṣe tímọ́tímọ́ dàgbà láàárín àwa àti òun. Fífẹ́ tá a fẹ́ láti ṣe èyí àti láti fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà yóò wá sún wa láti máa bá kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ṣíṣe àṣàrò lé e lórí nìṣó. Bí a bá ṣe ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run nípa lórí èrò inú àti ọkàn wa ni ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà yóò máa jinlẹ̀ sí i. Àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ yóò máa jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wa. A ka Jèhófà sí Ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ jù lọ, a sì fẹ́ máa múnú rẹ̀ dùn ní gbogbo ìgbà. (1 Jòhánù 5:3) Ìdùnnú tá a ní sí àjọṣe alárinrin tó wà láàárín àwa àti Ọlọ́run yóò máa pọ̀ sí i, a sì dúpẹ́ gan-an pé ó ń fi ìfẹ́ tọ́ wa sọ́nà, ó sì ń bá wa wí nígbà tó bá pọn dandan.—Diutarónómì 8:5.
10 Àyàfi tá a bá ń sapá nígbà gbogbo láti fún àjọṣe alárinrin tá a ní pẹ̀lú Jèhófà lókun nìkan ni kò fi ní bà jẹ́. Tó bá sì bà jẹ́, ìyẹn kì í ṣe ẹ̀bi Ọlọ́run, nítorí pé “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà ò jẹ́ kó ṣòro fún wa láti dé ọ̀dọ̀ òun! (1 Jòhánù 5:14, 15) Bó ti wù kó rí, a gbọ́dọ̀ sapá láti má ṣe jẹ́ kí àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín àwa àti Jèhófà bà jẹ́. Àmọ́ ṣá o, ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti sún mọ́ òun nípa fífún wa ní gbogbo ohun tá a nílò láti mú ìfọkànsìn Ọlọ́run dàgbà, ká sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. (Jákọ́bù 4:8) Báwo la ṣe lè lo gbogbo ìpèsè onífẹ̀ẹ́ wọ̀nyí dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́?
Dúró Sán-ún Nípa Tẹ̀mí
11. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a ní ìfọkànsìn Ọlọ́run?
11 Ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tá a ní fún Ọlọ́run yóò sún wa láti fi bí a ṣe ní ìfọkànsìn Ọlọ́run tó hàn, ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé: “Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tímótì 2:15) Ṣíṣe èyí ń béèrè pé ká máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, ká máa lọ sí ìpàdé déédéé, ká sì máa lọ sí òde ẹ̀rí déédéé. A tún lè sún mọ́ Jèhófà nípa ‘gbígbàdúrà láìdabọ̀.’ (1 Tẹsalóníkà 5:17) Àwọn ọ̀nà wọ̀nyí la lè gbà fi hàn pé a ní ìfọkànsìn Ọlọ́run. Ṣíṣàìka èyíkéyìí nínú wọn sí lè sọ wá di aláìsàn nípa tẹ̀mí, ó sì lè jẹ́ ká kó sínú pańpẹ́ Sátánì.—1 Pétérù 5:8.
12. Báwo la ṣe lè borí àwọn àdánwò?
12 Dídúró sán-ún nípa tẹ̀mí àti jíjẹ́ ọ̀jáfáfá tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ọ̀pọ̀ àdánwò tó ń dojú kọ wá. Àdánwò lè wá láti ibi tó ti máa dùn wá gan-an. Ìdágunlá, àtakò, àti inúnibíni lè ṣòro láti fara dà nígbà tó bá wá látọ̀dọ̀ ẹnì kan nínú ìdílé wa, àwọn ẹbí tàbí àwọn aládùúgbò tó sún mọ́ wa pẹ́kípẹ́kí. Àwọn ìṣòro tí ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣọṣẹ́, tó lè mú ká fi ìlànà Kristẹni wa báni dọ́rẹ̀ẹ́ lè wáyé níbi iṣẹ́ tàbí níléèwé. Ìrẹ̀wẹ̀sì, àìsàn àti ìsoríkọ́ lè sọ wá di aláìlera, kó sì wá jẹ́ kó túbọ̀ ṣòro fún wa láti kojú àwọn àdánwò ìgbàgbọ́. Àmọ́ a lè borí gbogbo àdánwò bí a ò bá jáwọ́ “nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.” (2 Pétérù 3:11, 12) A ò sì ní pàdánù ayọ̀ wa tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú ìdánilójú pé a óò rí ìbùkún Ọlọ́run.—Òwe 10:22.
13. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ máa bá a nìṣó ní fífọkànsin Ọlọ́run?
13 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sátánì máa ń dìídì gbógun ti àwọn tó bá ń fọkàn sin Ọlọ́run, síbẹ̀ kò sídìí fún wa láti máa bẹ̀rù. Nítorí kí ni? Nítorí pé “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò.” (2 Pétérù 2:9) Láti lè fara da àwọn àdánwò, ká sì ní irú ìdáǹdè bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ‘kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé, ká sì máa gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.’ (Títù 2:12) Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò kí àìlera èyíkéyìí tó ní í ṣe pẹ̀lú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìgbòkègbodò ti ara má lọ ṣàkóbá fún ẹ̀mí ìfọkànsìn wa, kó sì bà á jẹ́. Ẹ jẹ́ ká wá gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ohun eléwu wọ̀nyí.
Ṣọ́ra fún Àwọn Ohun Tó Lè Ṣàkóbá fún Ìfọkànsìn Ọlọ́run
14. Kí ló yẹ ká rántí bí ìfẹ́ ọ̀rọ̀ àlùmọ́nì bá fẹ́ dẹkùn mú wa?
14 Ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì jẹ́ ìdẹkùn fún ọ̀pọ̀ èèyàn. A lè máa tan ara wa pàápàá jẹ, ká máa “ronú pé fífọkànsin Ọlọ́run jẹ́ ọ̀nà èrè” nípa tara. Ìyẹn sì lè wá ki wá láyà láti tú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ jẹ nítorí pé wọ́n fọkàn tán wa. (1 Tímótì 6:5) A tiẹ̀ lè fi àṣìṣe ronú pé kò sóhun tó burú nínú fífi tipátipá yá owó tá a mọ̀ pé a kò ní lè san lọ́wọ́ Kristẹni kan tó rí towó ṣe. (Sáàmù 37:21) Àmọ́ ṣá o, ìfọkànsìn Ọlọ́run la sọ pé ó “ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀,” kì í ṣe nǹkan ìní ti ara. (1 Tímótì 4:8) Níwọ̀n bí ‘a kò ti mú nǹkan kan wá sínú ayé, tí a kò sì lè mú ohunkóhun jáde,’ ẹ jẹ́ ká túbọ̀ pinnu láti lépa “fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi,” ká sì jẹ́ kí ‘ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ tẹ́ wa lọ́rùn.’—1 Tímótì 6:6-11.
15. Kí la lè ṣe bí ìlépa fàájì bá fẹ́ ṣèdíwọ́ fún ìfọkànsìn Ọlọ́run wa?
15 Lílépa fàájì lè ṣèdíwọ́ fún ìfọkànsìn Ọlọ́run. Ó ha lè jẹ́ pé ó yẹ ká ṣe àtúnṣe ojú ẹsẹ̀ lórí ọ̀ràn yìí? Ká sọ tòótọ́, àwọn àǹfààní kan wà nínú ara títọ́ àti eré ìtura. Síbẹ̀, àwọn èrè wọ̀nyẹn ò jámọ́ nǹkan kan tá a bá fi wé ìyè àìnípẹ̀kun. (1 Jòhánù 2:25) Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀,” a sì gbọ́dọ̀ yẹra fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. (2 Tímótì 3:4, 5) Àwọn tó gbájú mọ́ ìfọkànsìn Ọlọ́run ni àwọn tó ń “fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la, kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.”—1 Tímótì 6:19.
16. Àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ wo ni kì í jẹ́ káwọn kan pa àwọn àṣẹ òdodo Ọlọ́run mọ́, báwo la sì ṣe lè borí àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọ̀nyí?
16 Ọtí líle àti ìjoògùnyó, ìwà pálapàla, àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ lè ba ẹ̀mí ìfọkànsìn Ọlọ́run wa jẹ́. Fífàyè gba nǹkan wọ̀nyí lè máà jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti pa àwọn àṣẹ òdodo Ọlọ́run mọ́. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; 2 Kọ́ríńtì 7:1) Kódà Pọ́ọ̀lù alára ní láti fara da ìforígbárí tí ń bá a nìṣó nínú ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀. (Róòmù 7:21-25) A ní láti gbé ìgbésẹ̀ tó lágbára láti mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ kúrò lọ́kàn wa. Lọ́nà kan, a gbọ́dọ̀ pinnu pé a óò máa jẹ́ oníwà rere nìṣó. Pọ́ọ̀lù sọ fún wa pé: “Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.” (Kólósè 3:5) Sísọ àwọn ẹ̀yà ara wa di òkú sí irú àwọn nǹkan ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ béèrè pé ká múra tán láti rẹ́yìn wọn pátápátá. Fífi taratara gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ yóò mú kó ṣeé ṣe fún wa láti yàgò fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ká sì máa lépa òdodo àti ìfọkànsìn Ọlọ́run láàárín ètò àwọn nǹkan búburú yìí.
17. Ojú wo ló yẹ ká fi wo ìbáwí?
17 Ìrẹ̀wẹ̀sì lè sọ wa di ẹni tí kò ní ìfaradà mọ́, kó sì wá ṣàkóbá fún ìfọkànsìn Ọlọ́run wa. Ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà ló ti ní ìrẹ̀wẹ̀sì. (Númérì 11:11-15; Ẹ́sírà 4:4; Jónà 4:3) Ìrẹ̀wẹ̀sì lè ṣàkóbá fún wa gan-an, àgàgà tó bá lọ ní ìkórìíra nínú, nítorí à ń ronú pé wọ́n fojú pa wa rẹ́ tàbí bóyá nítorí pé wọ́n bá wa wí lọ́nà mímúná. Àmọ́ ṣá o, ìbáwí jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ó bìkítà nípa wa. (Hébérù 12:5-7, 10, 11) Kì í ṣe ojú pé a wulẹ̀ ń fìyà jẹ wá ló yẹ ká máa fi wo ìbáwí, bí kò ṣe ká máa wò ó gẹ́gẹ́ bíi títọ́ wa sí ipa ọ̀nà òdodo. Bí a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, a ó mọyì ìbáwí, a ó sì tẹ́wọ́ gbà á, ní mímọ̀ pé “àwọn ìtọ́sọ́nà inú ìbáwí . . . ni ọ̀nà ìyè.” (Òwe 6:23) Èyí lè ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú dáadáa nípa tẹ̀mí nínú lílépa ìfọkànsìn Ọlọ́run.
18. Ẹrù iṣẹ́ wo ló já lé wa léjìká nígbà tí aáwọ̀ bá wà láàárín àwa àti ẹlòmíràn?
18 Èdè àìyedè àti ohun tẹ́nì kan ṣe tó dùn wá lè jẹ́ ìpèníjà fún ìfọkànsìn Ọlọ́run wa. Nǹkan wọ̀nyí lè fa hílàhílo tàbí kí wọ́n tiẹ̀ mú kí àwọn kan gbé ìgbésẹ̀ tí kò bọ́gbọ́n mu, kí wọ́n di ẹni tó ń ta kété sí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn nípa tẹ̀mí. (Òwe 18:1) Àmọ́ ó yẹ ká rántí pé dídi kùnrùngbùn tàbí níní àwọn ẹlòmíràn sínú lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. (Léfítíkù 19:18) Ní tòótọ́, “ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, tí òun rí, kò lè máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí kò rí.” (1 Jòhánù 4:20) Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó láti gbé ìgbésẹ̀ kíá láti yanjú aáwọ̀ àárín ẹnì kan sí ẹnì kejì. Ó sọ fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé: “Bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.” (Mátíù 5:23, 24) Títọrọ àforíjì lè ṣèrànwọ́ láti wo ọgbẹ́ tí ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tàbí ìwà ìka kan ti dá sàn. A lè yanjú gbúngbùngbún tó wà nílẹ̀, kí àjọṣe wa sì máa bá a nìṣó bí a bá tọrọ ìdáríjì, tá a sì gbà pé ọwọ́ tá a fi mú ọ̀ràn náà kù díẹ̀ káàtó. Jésù tún fúnni ní ìmọ̀ràn mìíràn lórí bí a ṣe ń yanjú aáwọ̀. (Mátíù 18:15-17) Ẹ wo bí inú wa ṣe máa ń dùn tó nígbà tí akitiyan tá a ṣe láti yanjú àwọn ìṣòro bá kẹ́sẹ járí!—Róòmù 12:18; Éfésù 4:26, 27.
Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
19. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an láti fara wé àpẹẹrẹ Jésù?
19 Ó dájú pé àdánwò yóò dé bá wa, àmọ́ kò yẹ kí ó mú wa yẹsẹ̀ nínú eré ìje ìyè àìnípẹ̀kun. Rántí pé Jèhófà lè gbà wá lọ́wọ́ àdánwò. Bí a ti ń “mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò,” tá a sì ń “fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa,” ẹ jẹ́ ká “tẹjú mọ́ Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jésù.” (Hébérù 12:1-3) Yíyẹ àpẹẹrẹ Jésù wò kínníkínní àti sísapá láti fara wé e nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mú ìfọkànsìn Ọlọ́run dàgbà ká sì gbé e yọ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
20. Àwọn èrè wo ni ìfaradà àti ìfọkànsìn Ọlọ́run máa ń fúnni?
20 Ńṣe ni ìfaradà àti ìfọkànsìn Ọlọ́run jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láti mú kí ìgbàlà wa dájú. Bí a bá ní àwọn ànímọ́ àtàtà wọ̀nyí, a lè fi ìṣòtítọ́ máa bá iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tí à ń ṣe fún Ọlọ́run nìṣó. Kódà nígbà tí àdánwò bá dé, a óò máa yọ̀ bí a ti ń rí i pé ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti ìbùkún Jèhófà wà lórí wa nítorí pé a ti fara dà á, tá a sì ń bá a nìṣó ní fífọkàn sin Ọlọ́run. (Jákọ́bù 5:11) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jésù fúnra rẹ̀ mú un dá wa lójú pé: “Nípasẹ̀ ìfaradà níhà ọ̀dọ̀ yín ni ẹ ó fi jèrè ọkàn yín.”—Lúùkù 21:19.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí tí ìfaradà fi ṣe pàtàkì?
• Kí ni ìfọkànsìn Ọlọ́run, báwo la sì ṣe ń fi hàn?
• Báwo la ṣe lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́, tó wà pẹ́ títí pẹ̀lú Ọlọ́run?
• Kí ni àwọn nǹkan tó lè ṣàkóbá fún ìfọkànsìn Ọlọ́run wa, báwo la sì ṣe lè yẹra fún wọn?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]
A ń fi ìfọkànsìn Ọlọ́run hàn ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ṣọ́ra fún àwọn ohun tó lè ṣàkóbá fún ìfọkànsìn Ọlọ́run rẹ