-
Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Jẹ́ Aláyọ̀?—Apá KìíníGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
Kò sí ìdílé tí kò níṣòro. Torí náà, tọkọtaya gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí wọ́n lè máa yanjú ìṣòro tí wọ́n bá ní. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Nínú fídíò yẹn, àwọn nǹkan wo ló fi hàn pé ìfẹ́ tó wà láàárín tọkọtaya yìí ti ń tutù?
Àwọn nǹkan wo ni wọ́n ṣe kí ìfẹ́ àárín wọn lè túbọ̀ jinlẹ̀ sí i?
Ka 1 Kọ́ríńtì 10:24 àti Kólósè 3:13. Lẹ́yìn tó o bá ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo ni nǹkan ṣe máa rí nínú ìdílé yín tẹ́ ẹ bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí?
Bíbélì sọ pé ó yẹ ká máa bọlá fún ara wa. Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà máa bọlá fáwọn míì ni pé ká jẹ́ onínúure sí wọn, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Ka Róòmù 12:10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ṣé ó yẹ kẹ́nì kan máa retí pé ó yẹ kí ọkọ tàbí aya òun kọ́kọ́ bọlá fún òun kóun tó lè bọlá fún un? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
-
-
Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Àlàáfíà àti Ìṣọ̀kan Wà Nínú ÌjọGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
3. Kí lo lè ṣe tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín ìwọ àti Kristẹni míì?
Òótọ́ ni pé a wà níṣọ̀kan, síbẹ̀ ó yẹ ká máa rántí pé aláìpé ni gbogbo wa. Nígbà míì, a lè ṣẹ ara wa tàbí ká ṣe ohun tó dun àwọn ẹlòmíì. Torí náà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé “ẹ . . . máa dárí ji ara yín,” ó fi kún un pé: “Bí Jèhófà ṣe dárí jì yín ní fàlàlà, ẹ̀yin náà gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀.” (Ka Kólósè 3:13.) Ọ̀pọ̀ ìgbà la ti ṣẹ Jèhófà tó sì ti dárí jì wá. Torí náà, ó fẹ́ káwa náà máa dárí ji ara wa. Tó o bá rí i pé o ti ṣẹ ẹnì kan, gbìyànjú láti lọ bá ẹni náà kẹ́ ẹ lè yanjú ọ̀rọ̀ náà.—Ka Mátíù 5:23, 24.b
-
-
Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Àlàáfíà àti Ìṣọ̀kan Wà Nínú ÌjọGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
5. Máa dárí jini ní fàlàlà, kó o sì máa wá àlàáfíà
Jèhófà kì í ṣẹ̀ wá, torí náà a ò nílò láti máa dárí jì í, síbẹ̀ ó máa ń dárí jì wá ní fàlàlà. Ka Sáàmù 86:5, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí ni ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ń dárí jini?
Báwo ló ṣe rí lára rẹ láti mọ̀ pé Jèhófà múra tán láti dárí jini?
Àwọn nǹkan wo ló lè mú kó nira fún wa láti máa wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn?
Báwo la ṣe lè máa fara wé Jèhófà kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan lè máa wà láàárín àwa àtàwọn ará? Ka Òwe 19:11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Tí ẹnì kan bá múnú bí ẹ, kí ló yẹ kó o ṣe kó o lè yanjú ọ̀rọ̀ náà?
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a máa ń ṣẹ àwọn míì. Kí ló yẹ ká ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Nínú fídíò yẹn, àwọn nǹkan wo ni arábìnrin yẹn ṣe kó lè wá àlàáfíà?
-