ORÍ 16
Máa “Ṣe Ìdájọ́ Òdodo” Bó O Ṣe Ń Bá Ọlọ́run Rìn
1-3. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà? (b) Kí ni Jèhófà fẹ́ ká ṣe ká lè fi hàn pé a mọyì ohun tó ṣe fún wa?
FOJÚ inú wò ó pé o wà nínú ọkọ̀ òkun kan tó ń rì lójú agbami. O ti rò ó pin pé kò sọ́nà àbáyọ kankan fún ẹ mọ́, àmọ́ ṣàdédé ni ẹnì kan dé tó sì fà ẹ́ wọnú ọkọ̀ míì. Ó dájú pé ọkàn ẹ máa balẹ̀ gan-an bí ẹni náà ṣe fà ẹ́ kúrò nínú omi tó sì tún sọ pé: “O ti bọ́ báyìí, kò séwu mọ́”! Báwo ni nǹkan tẹ́ni náà ṣe fún ẹ ṣe máa rí lára ẹ? Ó dájú pé o máa mọyì ẹ̀ gan-an, torí pé ńṣe lẹni náà gba ẹ̀mí ẹ là.
2 Àpèjúwe yìí jẹ́ ká lóye ohun tí Jèhófà ṣe fún wa. Ó sì yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ torí òun ló fún wa ní ìràpadà tó mú ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ó dá wa lójú pé tá a bá ní ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà tó ṣeyebíye yẹn, Jèhófà máa dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, a sì máa wà láàyè títí láé lọ́jọ́ iwájú. (1 Jòhánù 1:7; 4:9) Ní Orí 14 ìwé yìí, a rí i pé ọ̀nà tó ga jù lọ tí Jèhófà gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa àti pé òun jẹ́ onídàájọ́ òdodo ni bó ṣe fún wa ní ìràpadà. Kí la lè ṣe táá jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a mọyì ohun tó ṣe fún wa?
3 Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ ohun tó fẹ́ ká ṣe. Jèhófà lo wòlíì Míkà láti jẹ́ ká mọ ohun tóun fẹ́. Ó sọ pé: “Ó ti sọ ohun tó dára fún ọ, ìwọ ọmọ aráyé. Kí sì ni Jèhófà fẹ́ kí o ṣe? Bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o mọyì jíjẹ́ adúróṣinṣin, kí o sì mọ̀wọ̀n ara rẹ bí o ṣe ń bá Ọlọ́run rẹ rìn!” (Míkà 6:8) Torí náà, ọ̀kan lára ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe ni pé ká “ṣe ìdájọ́ òdodo.” Báwo la ṣe lè ṣe é?
Máa Wá “Òdodo Tòótọ́”
4. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń retí pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo òun?
4 Jèhófà ń retí pé ká máa tẹ̀ lé ìlànà òun nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. A mọ̀ pé àwọn ìlànà Jèhófà jẹ́ òdodo, wọ́n sì bá ìdájọ́ òdodo mu, torí náà tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀ èyí á fi hàn pé àwa náà nífẹ̀ẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo. Àìsáyà 1:17 sọ pé: “Ẹ kọ́ bí ẹ ṣe máa ṣe rere, ẹ wá ìdájọ́ òdodo.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún sọ pé ká “wá òdodo.” (Sefanáyà 2:3) Bákan náà, ó rọ̀ wá pé ká “gbé ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ.” (Éfésù 4:24) Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà, àá máa yẹra fún ìwà ipá, ìwà àìmọ́ àti ìṣekúṣe, torí pé irú àwọn ìwà yìí lòdì sí ìlànà Jèhófà.—Sáàmù 11:5; Éfésù 5:3-5.
5, 6. (a) Kí nìdí tí kò fi nira láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà? (b) Kí ni Bíbélì sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá fẹ́ máa wá òdodo a gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀ láìdáwọ́ dúró?
5 Ṣó nira láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà? Rárá o. Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lẹnì kan nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kò ní ṣòro fún un láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run wa, a sì mọyì àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀, gbogbo ìgbà ló máa ń wù wá pé ká ṣe ohun táá múnú rẹ̀ dùn. (1 Jòhánù 5:3) Rántí pé Jèhófà “nífẹ̀ẹ́ àwọn iṣẹ́ òdodo.” (Sáàmù 11:7) Tá a bá sì fẹ́ fara wé Jèhófà, a ní láti nífẹ̀ẹ́ ohun tó nífẹ̀ẹ́ ká sì kórìíra ohun tó kórìíra.—Sáàmù 97:10.
6 Torí pé a jẹ́ aláìpé, kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn fún wa láti ṣe ohun tó tọ́. Ìdí nìyẹn tá a fi gbọ́dọ̀ bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, ká sì gbé tuntun wọ̀. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà tuntun yìí, ó ní ‘à ń sọ ọ́ di tuntun’ nípasẹ̀ ìmọ̀ tó péye. (Kólósè 3:9, 10) Gbólóhùn náà, ‘à ń sọ ọ́ di tuntun,’ jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá fẹ́ gbé ìwà tuntun wọ̀, kì í ṣe nǹkan tá a máa ṣe lẹ́ẹ̀kan tá a sì máa dáwọ́ dúró. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làá máa ṣe é nìṣó, èyí sì gba ìsapá. Àmọ́ bó ti wù ká sapá tó, a ṣì lè ṣàṣìṣe nínú èrò, ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe wa torí pé aláìpé ni wá.—Róòmù 7:14-20; Jémíìsì 3:2.
7. Bá a ṣe ń gbìyànjú láti ṣe ohun tó tọ́, àwọn nǹkan wo ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ṣàṣìṣe?
7 Bá a ṣe ń gbìyànjú láti ṣe ohun tó tọ́, a máa ń ṣàṣìṣe nígbà míì. Kí ló wá yẹ ká ṣe? Òótọ́ ni pé kò yẹ ká máa wí àwíjàre tá a bá ṣàṣìṣe. Síbẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀, ká wá máa rò pé àwọn àṣìṣe wa ti pọ̀ jù, torí náà a ò yẹ lẹ́ni tó ń sin Jèhófà. Ẹ rántí pé Bàbá wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì ti ṣètò pé káwọn tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn pa dà rí ojú rere òun. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Mò ń kọ àwọn nǹkan yìí sí yín kí ẹ má bàa dẹ́ṣẹ̀.” Àmọ́, ó tún fi kún un pé: “Síbẹ̀, tí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀ [torí àìpé tá a jogún], a ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi.” (1 Jòhánù 2:1) Bẹ́ẹ̀ ni, bá a tiẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹbọ ìràpadà tí Jèhófà pèsè nípasẹ̀ Jésù ti mú ká lè máa jọ́sìn Jèhófà ní fàlàlà. Ṣé ìyẹn ò fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀? Ṣé kò sì mú kó wù ẹ́ pé kó o máa sa gbogbo ipá rẹ kó o lè máa ṣe ohun táá múnú Jèhófà dùn?
Ìhìn Rere Tá À Ń Wàásù Fi Hàn Pé Onídàájọ́ Òdodo ni Ọlọ́run
8, 9. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe fi hàn pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà?
8 Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà máa ṣèdájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà ni pé ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere ṣe fi hàn pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà?
9 Jèhófà ò ní dédé pa ayé burúkú yìí run láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ kìlọ̀ fáwọn èèyàn. Nígbà tí Jésù ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò òpin, ó sọ pé: “A ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Máàkù 13:10; Mátíù 24:3) Bí Jésù ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “kọ́kọ́” jẹ́ ká rí i pé àwọn nǹkan míì máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ìwàásù ìhìn rere náà bá ti kárí ayé. Ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ ni Bíbélì pè ní ìpọ́njú ńlá, ìyẹn ìgbà tí Ọlọ́run máa pa àwọn èèyàn búburú run, táá sì mú kí ayé tuntun dé níbi tí òdodo á máa gbé. (Mátíù 24:14, 21, 22) Ó dájú pé kò ṣẹ́ni tó máa sọ pé ńṣe ni Jèhófà hùwà tí ò dáa sáwọn èèyàn burúkú nígbà yẹn. Jèhófà ń lo iṣẹ́ ìwàásù láti kìlọ̀ fún wọn ní báyìí, torí ó fẹ́ kí wọ́n yí pa dà kí wọ́n lè rí ìgbàlà.—Jónà 3:1-10.
10, 11. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìdájọ́ òdodo Jèhófà?
10 Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe ṣe fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìdájọ́ òdodo Jèhófà? Lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ìgbàlà. Ṣé o rántí àpèjúwe tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí nípa ọkọ̀ òkun tó ń rì, tẹ́nì kan wá fà ẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀? Lẹ́yìn tẹ́ni náà gbé ẹ sínú ọkọ̀ míì, ó dájú pé wàá fẹ́ ran àwọn tó ṣì wà nínú omi yẹn lọ́wọ́. Bọ́rọ̀ àwọn èèyàn tó wà nínú ayé burúkú yìí ṣe rí nìyẹn, ńṣe ni wọ́n dà bí ẹni tó ń rì sínú odò. Ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa pa run. Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Àmọ́, ní báyìí tí Jèhófà ṣì ń mú sùúrù fún wọn, ó yẹ ká sa gbogbo ipá wa láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè “ronú pìwà dà,” torí ìyẹn láá jẹ́ kí wọ́n lè rí ìgbàlà.—2 Pétérù 3:9.
11 Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé à ń fara wé Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run onídàájọ́ òdodo ni pé ká máa wàásù fún gbogbo èèyàn, torí ìyẹn ló máa fi hàn pé a kì í ṣe ojúsàájú. Rántí pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Ìṣe 10:34, 35) Tá a bá fẹ́ jẹ́ onídàájọ́ òdodo bíi ti Ọlọ́run, a ò gbọ́dọ̀ máa ṣe ojúsàájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa wàásù ìhìn rere fún gbogbo èèyàn láìka ibi tí wọ́n ti wá sí, ojú táwọn èèyàn fi ń wò wọ́n, tàbí bóyá olówó ni wọ́n tàbí tálákà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa fún gbogbo èèyàn láǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere náà, kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti rí ìgbàlà.—Róòmù 10:11-13.
Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe Síra Wa
12, 13. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká tètè máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́? (b) Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ká “yéé dáni lẹ́jọ́” àti pé ká “yéé dáni lẹ́bi”? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
12 Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà fi hàn pé à ń ṣèdájọ́ òdodo ni pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn bí Jèhófà ṣe ń ṣe sí wa. A sábà máa ń ríbi táwọn èèyàn kù sí, torí náà ó máa ń yá wa lára láti dá wọn lẹ́jọ́ tàbí ṣàríwísí wọn. Àmọ́, ó dájú pé kò sẹ́ni tó máa fẹ́ kí Jèhófà máa ṣàríwísí òun ní gbogbo ìgbà, tàbí kó máa dá òun lẹ́jọ́. Jèhófà kì í ṣe bẹ́ẹ̀ sí wa rárá. Onísáàmù kan sọ pé: “Jáà, tó bá jẹ́ pé àṣìṣe lò ń wò, Jèhófà, ta ló lè dúró?” (Sáàmù 130:3) A mà dúpẹ́ o pé onídàájọ́ òdodo àti aláàánú ni Ọlọ́run wa, torí ó máa ń gbójú fo àwọn àṣìṣe wa! (Sáàmù 103:8-10) Báwo ló wá yẹ káwa náà máa ṣe sáwọn èèyàn?
13 Tẹ́nì kan bá ṣàṣìṣe, a máa fi hàn pé a jẹ́ aláàánú àti onídàájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà tá a bá gbójú fo ohun tẹ́ni náà ṣe, tá ò sì tètè dá a lẹ́jọ́, ní pàtàkì tí ohun tó ṣẹlẹ̀ náà ò bá kàn wá, tàbí tí ò tó nǹkan. Nínú Ìwàásù Orí Òkè, Jésù kìlọ̀ pé: “Ẹ yéé dáni lẹ́jọ́, kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.” (Mátíù 7:1) Nínú ìwé Ìhìn Rere Lúùkù, Jésù fi kún un pé: “Ẹ yéé dáni lẹ́bi, ó sì dájú pé a ò ní dá yín lẹ́bi.”a (Lúùkù 6:37) Jésù mọ̀ pé àwa èèyàn aláìpé sábà máa ń ṣàríwísí ara wa tàbí dá ara wa lẹ́bi. Torí náà, tí èyíkéyìí lára àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀, ó fẹ́ kí wọ́n jáwọ́.
14. Kí nìdí tó fi yẹ ká tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé ká “yéé dáni lẹ́jọ́”?
14 Kí nìdí tó fi yẹ ká tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé ká “yéé dáni lẹ́jọ́”? Ìdí kan ni pé a ò lẹ́tọ̀ọ́ láti dáni lẹ́jọ́. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jémíìsì sọ pé: “Ẹnì kan ṣoṣo ni Afúnnilófin àti Onídàájọ́ wa,” ìyẹn Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí Jémíìsì fi wá béèrè pé: “Ta ni ọ́ tí o fi ń dá ọmọnìkejì rẹ lẹ́jọ́?” (Jémíìsì 4:12; Róòmù 14:1-4) Yàtọ̀ síyẹn, torí pé a jẹ́ aláìpé, a kì í sábà ṣèdájọ́ lọ́nà tó tọ́. Lára ìwà àti ìṣe tí kì í jẹ́ ká ṣèdájọ́ lọ́nà tó tọ́ ni ẹ̀tanú, ìkanra pé ẹnì kan rí wa fín, owú àti òdodo àṣelékè. Ohun kan tún wà tó yẹ ká fi sọ́kàn tí kò ní jẹ́ ká máa ṣàríwísí àwọn èèyàn, ìyẹn ni pé a ò lè rí ọkàn wọn, a ò sì lè mọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn. Torí náà, ṣó wá yẹ ká gbà pé èrò tí kò tọ́ ló wà lọ́kàn àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà tàbí pé wọn ò ṣe tó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn? Rárá o. Ńṣe ló yẹ ká máa fara wé Jèhófà, ká máa wá ibi táwọn ará wa lọ́kùnrin lóbìnrin dáa sí, dípò ká máa tanná wá àṣìṣe wọn kiri!
15. Irú ìwà àti ìṣe wo la ò gbọ́dọ̀ bá lọ́wọ́ àwọn olùjọsìn Ọlọ́run, kí sì nìdí?
15 Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn ará ilé wa? Inú ìdílé ló yẹ kó jẹ́ ibi tó tura jù, àmọ́ ó bani nínú jẹ́ pé àwọn tó wà nínú ìdílé ló máa ń hùwà ìkà síra wọn jù. A sábà máa ń gbọ́ nípa àwọn ọkọ, aya, tàbí òbí tí wọ́n máa ń bú àwọn ará ilé wọn, tí wọ́n máa ń ṣépè fún wọn, tí wọ́n sì máa ń lù wọ́n. Àmọ́, kò yẹ káwọn olùjọsìn Jèhófà máa sọ̀rọ̀ burúkú síra wọn, tàbí kí wọ́n máa hùwà ìkà síra wọn. (Éfésù 4:29, 31; 5:33; 6:4) Ó yẹ káwọn tó wà nínú ìdílé náà máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù pé ká “yéé dáni lẹ́jọ́” ká sì “yéé dáni lẹ́bi.” Rántí pé lára ọ̀nà tá a lè gbà ṣèdájọ́ òdodo ni pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wa. Ọlọ́run wa kì í hùwà ìkà sí wa, kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń fi “ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó pọ̀ gan-an” hàn sáwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Jémíìsì 5:11) Ó yẹ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àtàtà yìí!
Àwọn Alàgbà Ń Ṣe “Ìdájọ́ Òdodo”
16, 17. (a) Kí ni Jèhófà ń retí pé káwọn alàgbà máa ṣe? (b) Kí ló yẹ káwọn alàgbà ṣe tí ẹnì kan tó hùwà àìtọ́ ò bá ronú pìwà dà, kí sì nìdí?
16 Gbogbo wa ni Jèhófà ń retí pé ká máa ṣe ìdájọ́ òdodo, àmọ́ ní pàtàkì ọ̀rọ̀ náà kan àwọn alàgbà. Kíyè sí ohun tí Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa “àwọn ìjòyè,” tàbí àwọn alàgbà, ó ní: “Wò ó! Ọba kan máa jẹ fún òdodo, àwọn ìjòyè sì máa ṣàkóso fún ìdájọ́ òdodo.” (Àìsáyà 32:1) Èyí fi hàn pé Jèhófà retí pé káwọn alàgbà jẹ́ onídàájọ́ òdodo. Ọ̀nà wo ni wọ́n lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ wọn?
17 Àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí mọ̀ pé táwọn bá fẹ́ jẹ́ onídàájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà, àwọn gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìjọ wà ní mímọ́. Nígbà míì, ó máa ń pọn dandan pé káwọn alàgbà ṣèdájọ́ àwọn tó hùwà àìtọ́ tó burú gan-an. Tí wọ́n bá sì fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń fi sọ́kàn pé Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n fàánú hàn nígbà tó bá yẹ. Torí náà, wọ́n máa ń gbìyànjú láti ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè ronú pìwà dà. Àmọ́, kí ni wọ́n máa ṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá ti sa gbogbo ipá wọn, síbẹ̀ tẹ́ni náà ò ronú pìwà dà? Bíbélì sọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe táá fi hàn pé wọ́n ń ṣèdájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà, ó sọ pé: “Ẹ mú ẹni burúkú náà kúrò láàárín yín.” Ìyẹn túmọ̀ sí pé kí wọ́n yọ ẹni náà kúrò nínú ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 5:11-13; 2 Jòhánù 9-11) Inú àwọn alàgbà kì í dùn tí wọ́n bá fẹ́ yọ ẹnì kan kúrò nínú ìjọ, àmọ́ wọ́n mọ̀ pé ó yẹ káwọn ṣe bẹ́ẹ̀ kí ìwà ẹni náà má bàa kó bá àwọn tó kù nínú ìjọ, kí ìjọ sì lè wà ní mímọ́ tónítóní lójú Jèhófà. Síbẹ̀, wọ́n gbà pé lọ́jọ́ kan, ẹni tó hùwà àìtọ́ náà ṣì máa ronú pìwà dà, á sì pa dà sínú ìjọ.—Lúùkù 15:17, 18.
18. Kí làwọn alàgbà máa ń fi sọ́kàn tí wọ́n bá ń fúnni ní ìmọ̀ràn látinú Bíbélì?
18 Ọ̀nà míì táwọn alàgbà lè gbà fi hàn pé àwọn ń ṣèdájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà ni pé kí wọ́n máa fúnni ní ìmọ̀ràn látinú Bíbélì nígbà tó bá yẹ. Àmọ́ o, kì í ṣe pé àwọn alàgbà ń wá àṣìṣe àwọn èèyàn kiri. Wọn kì í sì í wá bí wọ́n á ṣe máa báni wí ní gbogbo ìgbà. Àmọ́, tẹ́nì kan nínú ìjọ bá “ṣi ẹsẹ̀ gbé kó tó mọ̀,” ńṣe làwọn alàgbà máa “sapá láti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tọ́ ẹni náà sọ́nà,” torí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run kì í le koko mọ́ni tó bá ń ṣèdájọ́. (Gálátíà 6:1) Àwọn alàgbà ò ní bú ẹni tó hùwà àìtọ́ náà tàbí kí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ tí kò dáa sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ẹni náà, tí wọ́n á sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún un nímọ̀ràn kí ara lè tù ú. Kódà, tó bá gba pé káwọn alàgbà fún ẹnì kan nímọ̀ràn tó ṣe tààràtà kẹ́ni náà máa bàa kó sínú ìṣòro, wọ́n ṣì máa ń rántí pé àgùntàn Jèhófà lẹni náà.b (Lúùkù 15:7) Táwọn alàgbà bá ń fìfẹ́ hàn nígbà tí wọ́n bá ń fún ẹnì kan nímọ̀ràn tàbí bá a wí, wọ́n máa lè ran ẹni náà lọ́wọ́.
19. Àwọn ìpinnu wo ló máa ń pọn dandan káwọn alàgbà ṣe, kí ni wọ́n sì máa gbé yẹ̀ wò kí wọ́n tó ṣe àwọn ìpinnu náà?
19 Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn alàgbà ní láti ṣe àwọn ìpinnu tó kan àwọn ará nínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn alàgbà sábà máa ń pàdé pọ̀ láti wò ó bóyá àwọn arákùnrin kan nínú ìjọ ti tóótun láti di alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àwọn alàgbà mọ̀ pé kò yẹ káwọn máa ṣojúsàájú. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé tí wọ́n bá fẹ́ ṣèpinnu nípa àwọn tó tóótun láti di alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ni wọ́n máa gbé yẹ̀ wò, kì í ṣe èrò tiwọn. Ìyẹn láá jẹ́ kí wọ́n ṣèpinnu “láìṣe ẹ̀tanú tàbí ojúsàájú.”—1 Tímótì 5:21.
20, 21. (a) Kí làwọn alàgbà máa ń gbìyànjú láti ṣe fáwọn ará, kí sì nìdí? (b) Kí làwọn alàgbà lè ṣe láti ran “àwọn tó sorí kọ́” lọ́wọ́?
20 Àwọn alàgbà tún máa ń ṣe ìdájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà láwọn ọ̀nà míì. Lẹ́yìn tí Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn alàgbà máa ṣiṣẹ́ “fún ìdájọ́ òdodo,” ó tún sọ pé: “Ẹnì kọ̀ọ̀kan máa dà bí ibi tó ṣeé fara pa mọ́ sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù, ibi ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí omi tó ń ṣàn ní ilẹ̀ tí kò lómi, bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ tó gbẹ táútáú.” (Àìsáyà 32:2) Èyí fi hàn pé àwọn alàgbà máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti tu àwọn ará nínú, kí wọ́n sì mú kára tù wọ́n.
21 Torí pé ìṣòro tó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni pọ̀ nínú ayé, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló nílò ìṣírí. Ẹ̀yin alàgbà kí lẹ lè ṣe láti ran “àwọn tó sorí kọ́” lọ́wọ́? (1 Tẹsalóníkà 5:14) Ẹ fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, kẹ́ ẹ sì fọ̀rọ̀ wọn ro ara yín wò. (Jémíìsì 1:19) Wọ́n lè fẹ́ bá ẹnì kan tí wọ́n fọkàn tán sọ̀rọ̀ nípa àníyàn tó wà lọ́kàn wọn. (Òwe 12:25) Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà àtàwọn ará nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, wọ́n sì mọyì wọn. (1 Pétérù 1:22; 5:6, 7) Bákan náà, ẹ lè gbàdúrà pẹ̀lú wọn, kí ẹ sì tún máa rántí wọn nínú àdúrà yín. Tí alàgbà kan bá gbàdúrà látọkànwá pẹ̀lú ẹnì kan tó rẹ̀wẹ̀sì, ó dájú pé ará máa tu ẹni náà. (Jémíìsì 5:14, 15) Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà, ó ń rí bẹ́ ẹ ṣe ń fìfẹ́ hàn, tẹ́ ẹ sì ń sapá láti ran àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì lọ́wọ́. Ó dájú pé kò ní gbàgbé gbogbo iṣẹ́ rere tẹ́ ẹ̀ ń ṣe.
Táwọn alàgbà bá ń fún àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì níṣìírí, ńṣe ni wọ́n ń gbé ìdájọ́ òdodo Jèhófà yọ
22. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà jẹ́ onídàájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà, kí ló sì máa yọrí sí?
22 Ká sòótọ́, tá a bá ń ṣèdájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà, ńṣe làá túbọ̀ máa sún mọ́ ọn! Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, tá à ń wàásù fáwọn èèyàn kí wọ́n lè rí ìgbàlà, tá a sì ń wo ibi táwọn èèyàn dáa sí dípò ká máa ṣọ́ àṣìṣe wọn, ńṣe là ń gbé ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run yọ. Ẹ̀yin alàgbà, tẹ́ ẹ bá ń ṣe ohun táá jẹ́ kí ìjọ wà ní mímọ́, tẹ́ ẹ̀ ń fúnni ní ìmọ̀ràn tó ń gbéni ró látinú Ìwé Mímọ́, tẹ́ ò ṣe ojúsàájú nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣèpinnu, tẹ́ ẹ sì ń fún àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì níṣìírí, ńṣe lẹ̀ ń fi hàn pé ẹ jẹ́ onídàájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà. Ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn gan-an tó bá bojú wolẹ̀ látọ̀run tó sì rí àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti máa “ṣe ìdájọ́ òdodo” bí wọ́n ṣe ń bá Ọlọ́run wọn rìn!
a Nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan, wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí sí: “Ẹ má ṣe dáni lẹ́jọ́,” àti “ẹ má ṣe dáni lẹ́bi.” Ohun téyìí túmọ̀ sí ni pé ká “má gbìyànjú láti dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ rárá” àti pé ká “má gbìyànjú láti dá àwọn èèyàn lẹ́bi rárá.” Àmọ́, ńṣe ni ọ̀rọ̀ táwọn tó kọ Ìwé Ìhìn Rere lò nínú ẹsẹ yìí ń sọ nípa ohun tẹ́nì kan ti ń ṣe tẹ́lẹ̀, tó sì ń bá a lọ láti máa ṣe. Torí náà, ńṣe ni Jésù ń sọ fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ pé kí wọ́n yéé hu ìwà kan tí wọ́n ti ń hù tẹ́lẹ̀.
b Ní 2 Tímótì 4:2, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé nígbà míì ó lè pọn dandan káwọn alàgbà “báni wí,” kí wọ́n “fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà,” kí wọ́n sì “gbani níyànjú.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “gbani níyànjú” (pa·ra·ka·leʹo) tún lè túmọ̀ sí “láti fúnni ní ìṣírí.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì míì tó jọ ọ́ ni pa·raʹkle·tos, ó sì lè tọ́ka sí agbẹjọ́rò tó máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nílé ẹjọ́. Torí náà, tẹ́nì kan bá tiẹ̀ ṣe ohun tí kò dáa, tó wá gba pé káwọn alàgbà bá a wí, wọ́n máa ń fi sọ́kàn pé ṣe ni wọ́n fẹ́ ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.