Ẹ Yọ̀ Ninu Ireti Ijọba Naa!
“Ẹ yọ̀ ninu ireti. Ẹ farada labẹ ipọnju.”—ROOMU 12:12, NW.
1. Eeṣe ti a fi lè ri ayọ ninu ibakẹgbẹpọ wa pẹlu Jehofa, ki si ni apọsiteli Pọọlu rọ awọn Kristẹni lati ṣe?
“ỌLỌRUN alayọ.” (1 Timoti 1:11, NW) Ẹ wo bi eyi ti ṣapejuwe Jehofa daradara to! Eeṣe? Nitori pe gbogbo awọn iṣẹ rẹ̀ mú ayọ nla wa fun un. Niwọn bi Jehofa ti jẹ́ Orisun gbogbo ohun rere ti nmunilayọ, gbogbo awọn ẹ̀dá ọlọgbọnloye rẹ̀ lè ri ayọ ninu ibakẹgbẹ wọn pẹlu rẹ̀. Ni ọna ti o ṣe wẹku, apọsiteli Pọọlu rọ awọn Kristẹni lati mọriri anfaani alayọ wọn ti mímọ̀ Jehofa Ọlọrun, lati kun fun ọpẹ fun gbogbo awọn ẹbun agbayanu ti iṣẹda Rẹ̀, ati lati yọ̀ ninu awọn iṣeun-ifẹ ti Ó nfihan si wọn. Pọọlu kọwe pe: “Ẹ maa yọ ninu Oluwa nigba gbogbo: mo sì tun wi, Ẹ maa yọ̀.”—Filipi 4:4; Saamu 104:31.
2. Ireti wo ni o mu ayọ titobi wa, ki si ni a fun awọn Kristẹni niṣiiri lati ṣe nipa ireti yii?
2 Awọn Kristẹni ha nkọbiara si igbaniniyanju ti Pọọlu pese yii bi? Dajudaju wọn ṣe bẹẹ! Awọn arakunrin tẹmi Jesu Kristi ńyọ̀ ninu ireti ologo ti Ọlọrun ṣí silẹ fun wọn. (Roomu 8:19-21; Filipi 3:20, 21) Bẹẹni, wọn mọ pe awọn yoo ṣajọpin ninu mimu ireti nla fun ọjọ-ọla araye ṣẹ, ati alaaye ati oku, nipa ṣiṣiṣẹsin pẹlu Kristi ninu iṣakoso Ijọba rẹ̀ ti ọrun. Finu ro bi wọn yoo ti yọ̀ lọpọlọpọ tó ninu awọn anfaani wọn gẹgẹ bi ajumọjogun, ni ṣiṣiṣẹsin gẹgẹ bi awọn ọba ati alufaa! (Iṣipaya 20:6) Ayọ wo ni yoo jẹ tiwọn bi wọn ti nran araye oluṣotitọ lọwọ lati dé ìjẹ́pípé ti wọn yoo sì ṣeranwọ lati dari imupadabọsipo Paradise si ilẹ-aye wa! Loootọ, gbogbo awọn iranṣẹ Ọlọrun ni “ireti ìyè ainipẹkun, tí Ọlọrun, Ẹni tí ko le ṣeke, ti ṣe ileri ṣaaju ipilẹṣẹ ayé.” (Titu 1:2) Ni oju iwoye ireti titobilọla yii, apọsiteli Pọọlu fun gbogbo awọn Kristẹni niṣiiri pe: “Ẹ maa yọ̀ ninu ireti.”—Roomu 12:12.a
Ayọ Tootọ—Animọ Ti Ọkan-aya
3, 4. (a) Ki ni èdè isọrọ naa “lati yọ̀” tumọsi, niye igba wo si ni awọn Kristẹni gbọdọ maa yọ̀? (b) Ki ni ayọ tootọ, ki ni ó sì sinmi le lori?
3 “Lati yọ̀” tumọsi lati nimọlara ati lati fi ayọ han sode; kò tumọsi lati wà ninu ipo ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀, tabi ìyọ̀ṣìnkìn nigba gbogbo. Awọn ọrọ iṣe ti ó dọgba pẹlu awọn ọrọ Heberu ati Giriiki naa ti a lò ninu Bibeli fun “ayọ,” “ayọ-aṣeyọri,” ati “yíyọ̀” fi imọlara inu lọhun-un ati ifihansode ayọ han. Awọn Kristẹni ni a fun niṣiiri lati “maa baa lọ lati yọ̀,” “maa yọ̀ nigba gbogbo.”—2 Kọrinti 13:11; 1 Tẹsalonika 5:16, NW.
4 Ṣugbọn bawo ni ẹnikan ṣe lè maa yọ̀ nigba gbogbo? Eyi ṣeeṣe nitori pe ayọ tootọ jẹ́ animọ ọkan-aya, animọ jijinlẹ inu lọhun-un, ọ̀kan ti ó jẹ́ ti ẹmi. (Deutaronomi 28:47; Owe 15:13; 17:22) Ó jẹ́ eso ẹmi Ọlọrun, ti Pọọlu tò kété tẹle ifẹ. (Galatia 5:22) Gẹgẹ bi animọ inu lọhun-un kan, kò sinmi lori awọn ohun ẹhin ode, kii tilẹ ṣe lori awọn ará wa paapaa. Ṣugbọn ó sinmi lori ẹmi mímọ́ Ọlọrun. Ó sì nwa lati inu itẹlọrun jijinlẹ inu lọhun-un yẹn ti mímọ̀ pe iwọ ní otitọ, ireti Ijọba naa, ati pe iwọ nṣe ohun ti ó wu Jehofa. Fun idi yẹn, ayọ kii wulẹ ṣe iwa animọ ti a bí mọ wa; ó jẹ́ apakan “akopọ animọ titun,” akojọ awọn animọ ti ó mu ki Jesu Kristi yatọ.—Efesu 4:24, NW; Kolose 3:10.
5. Nigba wo ati bawo ni ifihan sita ayọ ṣe lè wà?
5 Bi o tilẹ jẹ pe ayọ jẹ animọ ọkan-aya kan, sibẹ a lè fihan si gbangba lati ìgbà dé ìgbà. Ki ni awọn ifihan sita ayọ atigbadegba wọnyi? Wọn lè jẹ́ ohunkohun lati ori ìtòrò minniminni oju si fifo soke fun ayọ niti gidi. (1 Ọba 1:40; Luuku 1:44; Iṣe 3:8; 6:15) Nigba naa, eyi ha tumọsi pe awọn eniyan ti wọn kii ṣe ẹnúdùnjuyọ̀ tabi ti wọn kii figba gbogbo rẹrin-in musẹ kò ni ayọ kankan bi? Bẹẹkọ! Ayọ tootọ kò fi araarẹ han ninu ìrégbè, ẹ̀rín kèékèé, ẹ̀rín musẹ, tabi ìfẹhín kẹkẹ igba gbogbo. Awọn ipo maa nfa ki ayọ fi araarẹ han ni oniruuru ọna. Kii ṣe ayọ nikan ni o nmu wa fi iṣọkan kẹgbẹpọ ni Gbọngan Ijọba ṣugbọn, kaka bẹẹ, ifẹni ati ifẹ ará wa.
6. Eeṣe ti awọn Kristẹni fi lè maa yọ̀ nigba gbogbo ani nigba ti wọn bá dojukọ awọn ipo ti kò gbadunmọni paapaa?
6 Apakan ayọ ti kii yipada ni iwapẹtiti rẹ̀ ni inu lọhun-un gẹgẹ bi ẹka akopọ animọ iwa titun Kristẹni tí imọlara rẹ̀ nti inu ọkan-aya wá. Eyi ni ó mu ki ó ṣeeṣe lati maa yọ̀ nigba gbogbo. Nitootọ, nigba miiran ohun kan lè dà wá laamu, tabi a lè dojukọ awọn ipo ti kò gbadun mọni. Ṣugbọn a sì lè ni ayọ ninu ọkan-aya wa. Awọn Kristẹni ijimiji kan jẹ́ ẹrú, tí wọn ní awọn oluwa ti o ṣoro lati tẹlọrun. Iru awọn Kristẹni bẹẹ ha lè maa yọ̀ nigba gbogbo bi? Bẹẹni, nitori ireti Ijọba wọn ati ayọ ninu ọkan-aya wọn.—Johanu 15:11; 16:24; 17:13.
7. (a) Ki ni Jesu sọ nipa ayọ labẹ ipọnju? (b) Ki ni ńràn wá lọ́wọ́ lati farada a labẹ ipọnju, ta ni ó sì gbe apẹẹrẹ didarajulọ kalẹ ninu ọ̀ràn yii?
7 Gẹ́lẹ́ lẹhin ti apọsiteli Pọọlu sọ pe: “Ẹ yọ̀ ninu ireti,” ó fikun un pe: “Ẹ farada labẹ ipọnju.” (Roomu 12:12, NW) Jesu tun sọrọ nipa ayọ labẹ ipọnju nigba ti ó sọ ni Matiu 5:11, 12 (NW) pe: “Alayọ ni ẹyin nigba ti awọn eniyan bá nkẹgan yin ti wọn sì nṣenunibini si yin . . . Ẹ yọ̀ kí ẹ sì fosoke fun ayọ, niwọn bi èrè yin ti pọ ninu awọn ọrun.” Yíyọ̀ ati fifosoke fun ayọ nihin-in kò fi dandan jẹ́ ifihan sita niti gidi; ni ipo akọkọ ó jẹ́ itẹlọrun inu lọhun-un yẹn ti ẹnikan ní ninu ṣiṣe ohun ti o dunmọ Jehofa ati Jesu Kristi ninu nigba ti ó nduro gbọnyingbọnyin labẹ adanwo. (Iṣe 5:41) Niti tootọ, ayọ ni ńràn wá lọ́wọ́ lati farada a nigba ti a bá wà labẹ ipọnju. (1 Tẹsalonika 1:6) Ninu eyi, Jesu fi apẹẹrẹ didara julọ lélẹ̀. Iwe mimọ sọ fun wa pe: “Nitori ayọ ti a gbeka iwaju rẹ̀, ó farada igi oró.”—Heberu 12:2, NW.
Yíyọ̀ Ninu Ireti Laika Awọn Iṣoro Si
8. Awọn iṣoro wo ni Kristẹni lè dojukọ, ṣugbọn eeṣe ti awọn iṣoro kò fi gba ayọ Kristẹni lọ?
8 Jíjẹ́ iranṣẹ Jehofa kò dá wa silẹ kuro ninu awọn iṣoro. Awọn iṣoro idile, awọn iṣoro iṣunna owo, àìlera, tabi iku awọn ololufẹ lè wà. Nigba ti iru awọn nǹkan bẹẹ lè fa ìkárísọ, wọn kò mu ipilẹ ti a ni fun yíyọ̀ ninu ireti Ijọba kuro, ayọ inu lọhun-un ti a ni ninu ọkan-aya wa.—1 Tẹsalonika 4:13.
9. Awọn iṣoro wo ni Aburahamu ni, bawo ni a sì ṣe mọ pe oun ní ayọ ninu ọkan-aya rẹ?
9 Fun apẹẹrẹ, gbe Aburahamu yẹwo. Igbesi-aye kò figba gbogbo dùn fun un. Ó ni awọn iṣoro idile. Wáhàrì rẹ̀, Hagari, ati aya rẹ̀, Sera, kò rẹ́. Ọpẹ́-alayé wà. (Jẹnẹsisi 16:4, 5) Iṣimaẹli fi Isaaki ṣeyẹyẹ, ni ṣiṣe inunibini si i. (Jẹnẹsisi 21:8, 9; Galatia 4:29) Nikẹhin, iyawo ọwọn Aburahamu, Sera, kú. (Jẹnẹsisi 23:2) Laika awọn iṣoro wọnyi si, ó yọ̀ lori ireti Iru-ọmọ Ijọba naa, Iru-ọmọ Aburahamu, nipasẹ ẹni ti gbogbo idile ilẹ-aye yoo bukun araawọn. (Jẹnẹsisi 22:15-18) Pẹlu ayọ ninu ọkan-aya rẹ̀, ó farada a ninu iṣẹ-isin Jehofa fun ọgọrun-un ọdun lẹhin ti ó fi Uri ilu ibilẹ rẹ̀ silẹ. Nitori naa a kọ ọ nipa rẹ̀ pe: “Nitori ti o nreti ilu ti ó ni ipilẹ; eyi ti Ọlọrun tẹdo ti ó sì kọ́.” Nitori igbagbọ Aburahamu ninu Ijọba Mesaya ti ńbọ̀ naa, Oluwa Jesu, nigba ti Ọlọrun ti yan an lati jẹ́ Ọba, lè wi pe: “Aburahamu . . . yọ̀ lati rí ọjọ mi: ó sì ri i, ó sì yọ̀.”—Heberu 11:10; Johanu 8:56.
10, 11. (a) Ijakadi wo ni a ní gẹgẹ bi Kristẹni, bawo ni a sì ṣe gbà wá silẹ? (b) Ki ni ó kúnjú ailagbara wa lati wọ̀jà lọna pipe lodisi ẹran-ara wa ti o kun fun ẹṣẹ?
10 Gẹgẹ bi awọn eniyan alaipe, a tun ni ẹran-ara wa ti ó kun fun ẹṣẹ lati bá jà, ijakadi lati ṣe ohun ti ó tọ́ yii sì lè jẹ́ adanilaamu gan-an. Bi o ti wu ki o ri, ija wa lodisi awọn ailera wa kò tumọsi pe a kò ni ireti. Pọọlu ni imọlara idaamu ọkàn lori ìwàyá-ìjà yii, ó sì wi pe: “Ta ni yoo gbà mi lọwọ ara iku yii? Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa.” (Roomu 7:24, 25) Nipasẹ Jesu Kristi ati irapada ti o pese, a gbà wá silẹ.—Roomu 5:19-21.
11 Ẹbọ irapada Kristi kúnjú ailagbara wa lati wọ̀jà naa lọna pípé. A lè yọ̀ ninu irapada yii nitori pe ó mu ki ẹ̀rí-ọkàn ti a sọ di mímọ́ ati idariji awọn ẹṣẹ wa ṣeeṣe. Ni Heberu 9:14 (NW), Pọọlu sọ nipa “ẹ̀jẹ̀ Kristi” ti ó ni agbara lati “wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́ kuro ninu awọn oku iṣẹ.” Nipa bayii, ẹ̀rí-ọkàn awọn Kristẹni ni a kò nilati di ẹrù idalẹbi ati awọn imọlara ẹbi rù. Eyi, papọ pẹlu ireti tí a ní, papọ jẹ́ ipá alagbara kan fun ayọ onidunnu. (Saamu 103:8-14; Roomu 8:1, 2, 32) Bi a ti nronu jinlẹ nipa ireti wa lọkan, gbogbo wa ni a o fun niṣiiri lati wọ ija naa pẹlu aṣeyọri.
Pipa Ireti Wa Mọ́ Pẹkipẹki Sọ́kàn
12. Ireti wo ni awọn Kristẹni ẹni ami ororo nronu jinlẹ le lori?
12 Ó ṣe pataki fun awọn aṣẹku ẹni ami ororo ati awọn agutan miiran lati pa “ireti igbala” wọn mọ́ sọkan, ni gbigbe e wọ gẹgẹ bi àṣíborí aabo. (1 Tẹsalonika 5:8) Awọn Kristẹni ẹni ami ororo lè ronu jinlẹ nipa anfaani agbayanu ti jijere àìlèkú ninu ọrun, nini anfaani atide ọdọ Jehofa Ọlọrun, ati gbigbadun ibakẹgbẹpọ lẹnikọọkan pẹlu Jesu Kristi ti a ti ṣe logo ati awọn apọsiteli ati gbogbo awọn miiran ti 144,000, tí wọn pa iwatitọ wọn mọ́ jalẹ awọn ọrundun. Ọrọ̀ ibakẹgbẹpọ alaiṣeefẹnusọ wo ni eyi!
13. Bawo ni awọn ẹni ami ororo ti wọn ṣì wa lori ilẹ-aye ṣe nimọlara nipa ireti wọn?
13 Bawo ni awọn ẹni ami ororo diẹ ti wọn ṣì wà lori ilẹ-aye ṣe nimọlara nipa ireti Ijọba wọn? Eyi ni a lè kópọ̀ ninu awọn ọrọ ẹnikan ti a bamtisi ni 1913: “Ireti wa jẹ́ ohun didaju kan, yoo sì ni imuṣẹ ni kikun fun olukuluku ẹni ti ó kẹhin lara awọn mẹmba agbo kekere ti wọn jẹ́ 144,000 dé aye ti ó rekọja ohun ti a lè finuwoye paapaa. Awa ti a jẹ́ ara awọn aṣẹku ti nbẹ ni ọdun 1914, nigba ti a reti pe ki gbogbo wa lọ si ọrun, kò tii sọ imọlara ìtóye ireti yẹn ti a ní nù. Ṣugbọn a jẹ́ alagbara fun un bii ti igbakigba ri, a sì tubọ nmọriri rẹ̀ sii bi ó ti ńpẹ́ sii tó ti a nilati duro fun un. Ó jẹ́ ohun kan ti o toye lati duro fun, ani bi o tilẹ beere fun aadọta-ọkẹ ọdun. Mo diyele ireti wa lọna giga sii ju ti igbakigba ri lọ, emi kò sì fẹ́ lati padanu imọriri mi fun un lae. Ireti agbo kekere tun funni ni idaniloju pe ifojusọna awọn ogunlọgọ nla ti agutan miiran yoo ni imuṣẹ, laisi ikuna ṣiṣeeṣe kankan, rekọja ifinuwoye wa ti ó dan yanranyanran julọ. Idi niyẹn ti a fi nduro ṣinṣin titi di wakati yii gan-an, awa yoo sì duro ṣinṣin titi di ìgbà ti Ọlọrun bá fihan pe oun jẹ́ oloootọ si ‘awọn ileri ṣiṣeyebiye rẹ̀ ti wọn sì tobilọla.’”—2 Peteru 1:4; Numeri 23:19; Roomu 5:5.
Yíyọ̀ Nisinsinyi Ninu Ireti Paradise
14. Ireti wo ni awọn ogunlọgọ nla nilati pamọ sọkan?
14 Iru ifihan igbagbọ alayọ aṣeyọri bẹẹ fi awọn idi titobilọla fun yíyọ̀ kún awọn wọnni ti wọn jẹ́ ti ogunlọgọ nla ti awọn agutan miiran. (Iṣipaya 7:15, 16) Iru awọn bẹẹ nilati fi ireti líla Amagẹdọni já sọkan. Bẹẹni, ki wọn wo iwaju si riri ki Ijọba Ọlọrun dá ipo ọba-alaṣẹ agbaye Jehofa Ọlọrun lare ki ó sì sọ orukọ ologo rẹ̀ di mímọ́ nipa mimu ipọnju nla wa eyi ti yoo wẹ ilẹ-aye mọ kuro lọwọ awọn ẹni buburu ti Eṣu ti jẹ́ ọlọrun fun. Ayọ wo ni ó jẹ lati la ipọnju nla naa já!—Daniẹli 2:44; Iṣipaya 7:14.
15. (a) Iṣẹ imularada wo ni Jesu ṣe nigba ti ó wà lori ilẹ-aye, eesitiṣe? (b) Ki ni yoo jẹ aini awọn olula Amagẹdọni já niti ilera, eesitiṣe ti wọn fi yatọ si awọn wọnni ti a ji dide?
15 Nipa awọn ogunlọgọ nla, Iṣipaya 7:17 wi pe: “Nitori Ọdọ-agutan . . . yoo maa ṣe oluṣọ-agutan wọn, ti yoo sì maa ṣe amọna wọn si ibi orisun omi ìyè: Ọlọrun yoo sì nu omije gbogbo nù kuro ni oju wọn.” Bi o tilẹ jẹ pe asọtẹlẹ yii ni imuṣẹ tẹmi nisinsinyi, awọn olula Amagẹdọni já yoo ri ti ó ni imuṣẹ niti gidi. Bawo ni ó ṣe jẹ́ bẹẹ? O dara, ki ni Jesu ṣe nigba ti ó wà lori ilẹ-aye? Ó wo awọn aláàbọ̀ ara sàn, mu awọn arọ rìn, la eti awọn odi ati oju awọn wọnni ti o fọju, ó sì wo awọn ẹlẹ́gbà, amukun-un, ati “àrùn ati gbogbo aisan ni ara awọn eniyan” sàn. (Matiu 9:35; 15:30, 31) Iyẹn kii ha ṣe ohun ti awọn Kristẹni nilo lonii bi? Ogunlọgọ nla yoo gbe awọn aabọ ara ati ailera ara ti ayé ogbologboo kọja sinu ayé titun. Ki ni a reti pe ki Ọdọ agutan ṣe nipa iyẹn? Aini awọn olula Amagẹdọni já yoo yatọ gédégédé si aini awọn wọnni ti a o jí dide. Awọn ti a jí dide ni ó ṣeeṣe ki a túndá pẹlu awọn odidi ara, ti ó da ṣáká, ti ó wà lalaafia, bi o tilẹ jẹ pe kò tii ni ijẹpipe eniyan sibẹ. Nitori iṣẹ iyanu ajinde, o ṣe kedere pe wọn ki yoo nilo atunṣe awọn aabọ ara ti isaaju eyikeyii nipasẹ iṣẹ iyanu ti iwosan lẹhin naa. Ni ọwọ keji ẹ̀wẹ̀, nitori iriri alailẹgbẹ wọn ti líla Amagẹdọni já, atunṣe oniṣẹ iyanu ni ọpọlọpọ awọn ogunlọgọ nla yoo nilo ti wọn yoo sì gba. Lọna ti o han gbangba, ete pataki awọn imularada ti Jesu ṣe ni lati ṣapejuwe ifojusọna alayọ fun iṣiri awọn ogunlọgọ nla pe wọn kii yoo là á já nikan ṣugbọn a o mu wọn larada lẹhin naa.
16. (a) Nigba wo ni imularada oniṣẹ iyanu ti awọn olula Amagẹdọni já yoo ṣẹlẹ, pẹlu iyọrisi wo sì ni? (b) Ninu ireti wo ni wọn yoo maa baa lọ lati yọ̀ laaarin akoko Ẹgbẹrundun?
16 Iru imularada agbayanu bẹẹ lọna ti ó ba ọgbọn mu yoo ṣẹlẹ laaarin awọn olula Amagẹdọni já laipẹ ni ifiwera lẹhin Amagẹdọni ati jinna ṣaaju ki ajinde tó bẹrẹ. (Aisaya 33:24; 35:5, 6; Iṣipaya 21:4; fiwe Maaku 5:25-29.) Nigba naa awọn eniyan yoo da awọn awò-oju, ọ̀pá, ọ̀pá-ìkẹ́sẹ̀, aga kẹ̀kẹ́, ayédèrú erìgì, aranṣe igbọran, ati iru nǹkan bẹẹ nù. Idi fun yíyọ̀ wo ni eyi! Bawo ni iru igbesẹ imupadabọsipo akọkọ nipasẹ Jesu ṣe baramu pẹlu ila iṣẹ awọn olula Amagẹdọni já gẹgẹ bi ipilẹ ayé titun naa! Awọn àrùn ti ndani lọwọkọ ni a o mu kuro loju ọna ki awọn olulaaja wọnyi lè maa tẹsiwaju pẹlu itara onidunnu, ni fifi iharagaga wo igbokegbodo agbayanu ti Ijọba Ẹgbẹrundun ti ó tẹ́rẹrẹ ni iwaju wọn, tí ohun tí aye ogbologboo ti lè fi pọ́n wọn loju kò mu ẹmi wọn rẹwẹsi. Bẹẹni, ani lẹhin Amagẹdọni paapaa, awọn ogunlọgọ nla lè maa baa lọ lati yọ̀ ninu ireti agbayanu ti dídé iwalaaye eniyan pipe ni opin ẹgbẹrun ọdun naa. Gbogbo rẹ̀ jalẹ Ẹgbẹrundun naa, wọn yoo maa yọ̀ ninu ireti ti dide gongo alayọ yẹn.
17. Ayọ pupọ wo ni yoo wà bi iṣẹ mimu Paradise padabọsipo naa bá ti ntẹsiwaju?
17 Bi iyẹn bá jẹ́ ireti rẹ, tun ronu lori ṣiṣajọpin ninu mimu Paradise padabọsipo lori ilẹ-aye. (Luuku 23:42, 43) Laiṣiyemeji awọn olula Amagẹdọni já yoo ṣeranlọwọ ninu fífọ̀ ilẹ-aye mọ́ ki wọn sì tipa bayii pese awọn ibi gbigbadun mọni ti a o jí awọn oku dide si. Ayẹyẹ isinku ni a lè fi awọn akoko ikini kaabọ fun awọn wọnni ti a mu dide ninu ajinde rọpo, papọ pẹlu awọn ololufẹ tiwa funraawa ti wọn ti sọkalẹ sinu iku. Sì ronu nipa ibakẹgbẹpọ didọṣọ pẹlu awọn ọkunrin ati obinrin oloootọ lati ọpọlọpọ ọrundun ti ó ti kọja. Ta ni iwọ nfẹ lati bá sọrọ ni pataki? Ebẹli, Enọku, Noa, Joobu, Aburahamu, Sera, Isaaki, Jakọbu, Josẹfu, Mose, Joṣua, Rahabu, Debora, Samusini, Dafidi, Elija, Eliṣa, Jeremaya, Esikiẹli, Daniẹli, tabi Johanu Arinibọmi ha ni bi? Ó dara, nigba naa, ifojusọna gbigbadun mọni yii tun jẹ́ apakan ireti rẹ. Iwọ yoo lè bá wọn sọrọpọ, kẹkọọ lati ọdọ wọn, ki o sì ṣiṣẹ papọ pẹlu wọn ni mimu gbogbo ilẹ-aye di Paradise kan.
18. Ayọ pupọ siwaju sii wo ni a lè ronu jinlẹ le lori?
18 Pẹlupẹlu, finuwoye ounjẹ aṣara loore, omi mimọgaara, ati afẹfẹ mimọ tonitoni, pẹlu ilẹ-aye wa ti a mu padabọsipo si iwa deedee ibugbe ohun alaaye pipe rẹ̀ ni ọna ti Jehofa gbà dá a pe ki o jẹ́. Igbesi-aye nigba naa, kii yoo jẹ́ igbadun oréfèé ti ijẹpipe, ṣugbọn ìkópa onitumọ ati alakitiyan. Ronu jinlẹ nipa awujọ awọn eniyan yika ayé ti wọn bọ́ lọwọ iwa ọdaran, igbera-ẹni larugẹ, owú, ija—ẹgbẹ́ ará nibi ti gbogbo eniyan ti mu awọn eso ẹmi dagba ti wọn si fihan. Bawo ni ó ti muni lọkan yọ̀ tó!—Galatia 5:22, 23.
Ireti Ti Nmu Ki Igbesi-aye Toye Fun Gbigbe
19. (a) Nigba wo ni a o niriiri yíyọ̀ ti a mẹnukan ninu Roomu 12:12? (b) Eeṣe ti a fi gbọdọ pinnu lati maṣe jẹ ki ẹrù inira igbesi-aye ti ireti wa sẹgbẹẹkan?
19 Ifojusọna ti ọwọ bá ti tẹ̀ kii ṣe ireti kankan mọ́, nitori naa yíyọ̀ ti Pọọlu funni niṣiiri rẹ̀ ni Roomu 12:12 ni a nilati niriiri rẹ̀ nisinsinyi. (Roomu 8:24) Kiki rironu nipa awọn ibukun ọjọ-ọla ti Ijọba Ọlọrun yoo mu wa jẹ́ idi fun wa lati yọ̀ ninu ireti yẹn nisinsinyi. Nitori naa jẹ́ ẹni ti ó pinnu lati maṣe yọnda awọn ẹrù inira igbesi-aye ninu ayé idibajẹ kan lati ti ireti ologo rẹ sẹgbẹẹkan. Maṣe di ẹni ti ó jagọ ki o sì dawọ iṣẹ duro, ni sisọ iran ireti ti ó wà niwaju nù. (Heberu 12:3) Ṣíṣá ipa-ọna Kristẹni tì ki yoo yanju awọn iṣoro rẹ. Ranti, bi ẹnikan bá kọ ṣiṣiṣẹsin Ọlọrun silẹ nitori gbogbo awọn ẹrù inira igbesi-aye nisinsinyi, oun ṣì dojukọ awọn ẹrù inira wọnni sibẹ, ṣugbọn oun padanu ireti ati nitori naa o padanu ṣiṣeeṣe ti yíyọ̀ ninu awọn ifojusọna agbayanu ti ó wà niwaju.
20. Ipa wo ni ireti Ijọba ní lori awọn wọnni ti wọn tẹwọgba a, eesitiṣe?
20 Awọn eniyan Jehofa ni gbogbo idi lati gbe igbesi-aye alayọ. Ireti didan yanranyanran, arunisoke wọn mu ki igbesi-aye yẹ ni gbígbé. Wọn kò sì pa ireti alayọ yii mọ funraawọn. Bẹẹkọ, wọn ni iharagaga lati ṣajọpin rẹ̀ pẹlu awọn ẹlomiran. (2 Kọrinti 3:12) Bẹẹ ni ó ṣe ri pe awọn wọnni ti wọn tẹwọgba ireti Ijọba naa jẹ́ awọn eniyan onigbọkanle, wọn sì wá ọna lati fun awọn ẹlomiran niṣiiri nipa sisọ ihinrere lati ọdọ Ọlọrun fun wọn. Eyi fi ireti agbayanu ti a tii fifun iran eniyan ni gbogbogboo rí kun igbesi-aye awọn wọnni ti wọn tẹwọgba ihin-iṣẹ naa—ireti Ijọba ti yoo mu Paradise ilẹ-aye padabọsipo. Bi awọn eniyan kò ba tẹwọgba a, awa yoo maa baa lọ sibẹ lati yọ̀ nitori pe awa ni ireti. Awọn ti ó kọ eti ikún sii ni wọn padanu; kii ṣe awa.—2 Kọrinti 4:3, 4.
21. Ki ni ó sunmọ etile, bawo sì ni a ṣe gbọdọ diyele ireti wa?
21 Ileri Ọlọrun ni pe: “Kiyesi i, mo sọ ohun gbogbo di ọtun.” (Iṣipaya 21:5) Ayé titun pẹlu gbogbo awọn ibukun amúniyọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ati alailopin rẹ̀ ti sunmọle. Ireti wa—fun iwalaaye ninu ọrun tabi lori paradise ilẹ-aye—ṣeyebiye; di i mu ṣinṣin. Ni awọn ọjọ ikẹhin lilekoko wọnyi, ju ti igbakigba ri lọ, wo o “bi ìdákọ̀ró ọkàn, ireti ti ó daju ti ó sì duro ṣinṣin.” Pẹlu ireti wa ti a dáró ninu Jehofa, “apata ainipẹkun—Apata ayeraye,” awa dajudaju ni idi amuniloriya gágá gbáà nisinsinyi lati “yọ̀ ninu ireti” ti a gbeka iwaju wa.—Heberu 6:19; Aisaya 26:4, The Amplified Bible (Gẹẹsi).
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Jalẹ 1992, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yika ayé yoo ní gẹgẹ bi ọrọ ẹṣẹ Iwe mimọ ọdun naa: “Ẹ yọ̀ ninu ireti. . . . Ẹ ni iforiti ninu adura.”—Roomu 12:12, NW.
Awọn Ibeere fun Atunyẹwo
◻ Ki ni ireti titobi araye?
◻ Ki ni ayọ tootọ?
◻ Nigba wo ni imularada oniṣẹ iyanu ti awọn olula Amagẹdọni ja ṣeeṣe ki ó waye?
◻ Eeṣe ti a kò fi nilati jẹ́ ki ẹrù inira igbesi-aye ti ireti wa sẹgbẹẹkan?
◻ Ayọ pupọ wo ni iwọ nwọna fun ninu ayé titun?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ki yoo ha fi ayọ̀ kun ọkan-aya rẹ lati jẹrii si iru awọn imularada ti Jesu ṣe?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Awọn wọnni ti wọn nyọ ninu ijọba naa nfun awọn ẹlomiran niṣiiri nipa ṣiṣajọpin ireti wọn