Ìsọ̀rí 7
Ète Ọlọrun Yoo Ní Imuṣẹ Laipẹ
1, 2. Eeṣe ti a fi le ni idaniloju pe Ọlọrun yoo gbe igbesẹ lati fopin si ìwà-ibi ati ijiya?
1 Bi o tilẹ jẹ pe lati oju-iwoye eniyan Ọlọrun ti yọnda fu àìpé ati ijiya fun akoko pipẹ tobẹẹ, kò ni yọnda fun awọn ipo buburu lati maa baa lọ gbére. Bibeli sọ fun wa pe Ọlọrun ní sáà akoko kan pato fun yiyọnda ki awọn nǹkan wọnyi ṣẹlẹ.
2 “Olukuluku ohun ni akoko wà fun.” (Oniwasu 3:1) Nigba ti akoko ti Ọlọrun yàn fun fifayegba ìwà-ibi ati ijiya bá dé opin rẹ̀, nigba naa oun yoo dásí awọn ọran eniyan. Yoo mu opin débá ìwà-ibi ati ijiya ti yoo si mu ète rẹ̀ ipilẹṣẹ lati mu ki ayé kun fun idile eniyan pipe, ti o jẹ alayọ ti o si ń gbadun alaafia patapata ati ailewu niti ìṣúnná-owó ninu awọn ipo Paradise ṣẹ́.
Awọn Idajọ Ọlọrun
3, 4. Bawo ni ìwé Owe ṣe ṣapejuwe abajade dídá ti Ọlọrun yoo dásí ọran?
3 Ṣakiyesi diẹ lara ọpọlọpọ asọtẹlẹ Bibeli ti o sọ nipa ohun ti dídá ti Ọlọrun yoo dásí ọran, iyẹn ni pe, abajade awọn idajọ rẹ̀, yoo tumọsi fun idile eniyan:
4 “Ẹni iduroṣinṣin ni yoo jokoo ni ilẹ̀ naa, awọn ti o pé yoo si maa wà ninu rẹ̀. Ṣugbọn awọn eniyan buburu ni a o ké kuro ni ilẹ̀-ayé, ati awọn olurekọja ni a o si fàtu kuro ninu rẹ̀.”—Owe 2:21, 22.
5, 6. Bawo ni Orin Dafidi 37 ṣe fi ohun ti yoo ṣẹlẹ han nigba ti Ọlọrun bá dásí ọran?
5 “A o ké awọn oluṣe buburu kuro: ṣugbọn awọn ti o duro de Oluwa ni yoo jogun ayé. Nitori pe nigba diẹ, awọn eniyan buburu ki yoo si . . . Ṣugbọn awọn ọlọkan tutu ni yoo jogun ayé; wọn o si maa ṣe inu didun ninu ọpọlọpọ alaafia.”—Orin Dafidi 37:9-11.
6 “Duro de Oluwa, ki o si maa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́, yoo si gbé ọ leke lati jogun ayé; nigba ti a ba ké awọn eniyan buburu kuro, iwọ o ri i. Maa kiyesi ẹni pípé, ki o si maa wo ẹni diduro ṣinṣin: nitori alaafia ni opin ọkunrin naa. Ṣugbọn awọn alarekọja ni a o parun pọ̀; iran awọn eniyan buburu ni a o ké kuro.”—Orin Dafidi 37:34, 37, 38.
7. Imọran yiyekooro wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fifun wa?
7 Nitori naa, ni oju-iwoye ọjọ-iwaju agbayanu ti yoo débá awọn wọnni ti wọn tẹwọgba ẹ̀tọ́ Ẹlẹdaa Olodumare lati ṣakoso wa, a pàrọwà fun wá pe: “Jẹ ki àyà rẹ ki o pa ofin mi mọ́. Nitori ọjọ gígùn, ati ẹmi gígùn, ati alaafia ni wọn o fi kun un fun ọ.” Nitootọ, iye ayeraye ni a o fi kun un fun awọn wọnni ti wọn yàn lati ṣe ifẹ-inu Ọlọrun! Nipa bẹẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbà wa nimọran pe: “Fi gbogbo àyà rẹ gbẹkẹle Oluwa; má si ṣe tẹ̀ si imọ araarẹ. Mọ̀ ọ́n ni gbogbo ọ̀nà rẹ: oun o si maa tọ́ ipa-ọna rẹ.”—Owe 3:1, 2, 5, 6.
Iṣakoso Ọlọrun Latọrunwa
8, 9. Nipasẹ ki ni Ọlọrun yoo fi fọ ilẹ̀-ayé yii mọ́?
8 Ọlọrun yoo ṣe aṣepari fifọ ilẹ̀-ayé mọ yii nipasẹ ijọba ti o dara julọ ti araye tíì ní rí. Ó jẹ ijọba kan ti o ṣagbeyọ ọgbọn atọrunwa nitori ti o ń ṣakoso latọrunwa labẹ idari Ọlọrun. Ijọba ọrun yẹn yoo mu gbogbo oniruuru iṣakoso eniyan kuro lori ilẹ̀-ayé. Awọn eniyan ki yoo tun ni yíyàn miiran mọ́ lae ti gbigbiyanju lati ṣakoso laisi ọwọ́ Ọlọrun nibẹ.
9 Niti eyi asọtẹlẹ Danieli 2:44 sọ pe: “Ni ọjọ awọn ọba wọnyi [awọn ijọba òde-òní] ni Ọlọrun ọrun yoo gbe ijọba kan kalẹ [ni ọrun], eyi ti a kì yoo le parun titilae: a kì yoo si fi ijọba naa le orilẹ-ede miiran lọwọ [a kì yoo tun fayegba ki awọn eniyan ṣakoso araawọn laisi ọwọ́ Ọlọrun nibẹ mọ lae], yoo si fọ tutu, yoo si pa gbogbo ijọba wọnyi [ti wọn wà nisinsinyi] run, ṣugbọn oun o duro titi laelae.”—Tun wo Ìfihàn 19:11-21; 20:4-6 pẹlu.
10. Eeṣe ti a fi le ni idaniloju pe labẹ Ijọba ọrun ti Ọlọrun, ki yoo tun si isọdibajẹ ninu iṣakoso mọ́ lae?
10 Nipa bẹẹ, araye ki yoo tun ni oniruuru ijọba ti a sọdibajẹ mọ lae, nitori nigba ti Ọlọrun bá mu eto-igbekalẹ yii wá si opin rẹ̀, iṣakoso eniyan ní idadurolominira kuro lọdọ rẹ̀ ki yoo tun sí mọ́ lae. Ijọba naa ti ń ṣakoso latọrunwa ni a ki yoo sọdibajẹ, niwọn bi o ti jẹ pe Ọlọrun ni Oludasilẹ ati Oludaabobo rẹ̀. Kàkà bẹẹ, yoo ṣiṣẹ fun ire didara julọ awọn eniyan ọmọ-abẹ rẹ̀. Ifẹ-inu Ọlọrun ni a o wá ṣe jakejado ilẹ̀-ayé bii ti ọrun. Idi niyẹn ti Jesu fi le kọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati gbadura pe: “Ki ijọba rẹ de; Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹẹ ni ni ayé.”—Matteu 6:10.
Bawo Ni A Ti Sunmọ Ọn Tó?
11. Nibo ninu Bibeli ni a ti rí awọn asọtẹlẹ ti yoo ràn wa lọwọ lati pinnu bi a ti sunmọ opin eto-igbekalẹ yii tó?
11 Bawo ni a ti sunmọ opin eto-igbekalẹ alaitẹnilọrun yii ati ibẹrẹ ayé titun Ọlọrun tó? Asọtẹlẹ Bibeli fun wa ni idahun naa ni kedere. Fun apẹẹrẹ, Jesu fúnraarẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ ohun ti a o maa fojusọna fun ki a ba le pinnu ìgbà ti a bá sunmọ, gẹgẹ bi Bibeli ti ṣe sọ ọ, “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan.” (NW) Eyi ni a kọsilẹ ninu Matteu ori 24 ati 25, Marku 13, ati Luku 21. Ati gẹgẹ bi a ṣe kọ ọ silẹ ni 2 Timoteu ori 3, aposteli Paulu sọ tẹ́lẹ̀ pe sáà kan yoo wà ti a pe ni “ikẹhin ọjọ” nigba ti oriṣiriṣi awọn iṣẹlẹ yoo tubọ jẹrii si ibi ti a wà ninu ìṣàn akoko.
12, 13. Ki ni Jesu ati Paulu sọ nipa akoko opin?
12 Jesu sọ pe sáà akoko yii yoo bẹrẹ pẹlu awọn iṣẹlẹ wọnyi: “Orilẹ-ede yoo dide si orilẹ-ede, ati ilẹ̀-ọba si ilẹ̀-ọba: iyan, ati ajakalẹ àrùn, ati isẹlẹ yoo si wà ni ibi pupọ.” (Matteu 24:7) Luku 21:11 fihan pe oun tun mẹnukan an pe ‘ajakalẹ àrùn yoo si wà kaakiri.’ Ó tun kilọ, pẹlu, pe “ẹ̀ṣẹ̀ yoo di pupọ.”—Matteu 24:12.
13 Aposteli Paulu sọ tẹ́lẹ̀ pe: “Ṣugbọn eyi ni ki o mọ̀, pe ni ikẹhin ọjọ ìgbà ewu yoo de. Nitori awọn eniyan yoo jẹ olufẹ ti araawọn, olufẹ owó, afúnnu, agberaga, asọrọbuburu, aṣaigbọran si obi, alailọpẹ, aláìmọ́, alainifẹẹ, alaile-dariji-ni, abanijẹ, alaile-ko-ra-wọn-nijanu, onroro, alainifẹ-ohun-rere, onikupani, alagidi, ọlọkan giga, olufẹ faaji ju olufẹ Ọlọrun lọ; awọn ti wọn ni afarawe iwa-bi Ọlọrun, ṣugbọn ti wọn sẹ́ agbara rẹ̀ . . . Awọn eniyan buburu, ati awọn ẹlẹtan yoo maa gbilẹ siwaju si i, wọn o maa tan-ni-jẹ, a o si maa tan wọn jẹ.”—2 Timoteu 3:1-5, 13.
14, 15. Bawo ni awọn iṣẹlẹ ọ̀rúndún ogun yii ṣe jẹrii sii pe a wà ni ikẹhin ọjọ niti gidi?
14 Awọn nǹkan wọnni ti Jesu ati Paulu sọ tẹ́lẹ̀ ha ti ṣẹlẹ ni akoko tiwa bi? Bẹẹni, wọn ti ṣe bẹẹ dajudaju. Ogun Agbaye Kìn-ín-ní ni o jẹ eyi ti o buru julọ patapata gbáà ninu itan titi di ìgbà yẹn. Oun ni ogun agbaye akọkọ ó sì jẹ ikorita iyipada kan ninu itan ode-oni. Ìyàn, ajakalẹ arun, ati awọn ìjábá miiran ni wọn bá ogun naa rìn. Awọn iṣẹlẹ wọnyẹn lati 1914 siwaju, jẹ gẹgẹ bi Jesu ṣe sọ ọ, “ipilẹṣẹ ipọnju.” (Matteu 24:8) Wọn jẹ ibẹrẹ sáà akoko ti a sọ tẹ́lẹ̀ naa ti a pè ni “ikẹhin ọjọ,” ibẹrẹ iran ikẹhin ti Ọlọrun yoo fayegba ìwà-ibi ati ijiya mọ.
15 O ṣeeṣe ki o jẹ ojulumọ pẹlu awọn iṣẹlẹ ọ̀rúndún ogun. Iwọ mọ̀ nipa rúgúdù ati iparun ti o ti jẹyọ. Nǹkan bi aadọta ọkẹ lọna ọgọrun-un awọn eniyan ni a ti pa ninu awọn ogun. Araadọta ọkẹ lọna ọgọrọọrun miiran ni wọn ti ku lati inu abajade ebi ati aisan. Awọn isẹlẹ ti gba aimọye iwalaaye. Àìbọ̀wọ̀ fun iwalaaye ati ohun-ìní ń gberu sii. Ibẹru ìwà ọdaran ti di apakan igbesi-aye ojoojumọ. Ilana iwarere ni a ti patì si ẹ̀gbẹ́ kan. Ìbúrẹ́-kẹrẹ̀kẹ iye eniyan ń fa awọn iṣoro eyi ti a kò yanju rẹ̀. Ìbàyíkájẹ́ ń ba ìjójúlówó igbesi-aye jẹ ó si ń fi i sinu ewu. Nitootọ, a ti wà ni ikẹhin ọjọ lati 1914 a sì ń sunmọ òtéńté awọn asọtẹlẹ Bibeli ti o ni akoko wa ninu.
16. Bawo ni sáà akoko tí ikẹhin ọjọ gbà ti gùn tó?
16 Bawo ni sáà akoko ikẹhin ọjọ yii yoo ti gùn to? Jesu sọ nipa sáà ti yoo niriiri “ibẹrẹ ipọnju” lati 1914 siwaju pe: “Iran yii ki yoo rekọja, titi gbogbo nǹkan wọnyi yoo fi ṣẹ.” (Matteu 24:8, 34-36) Nipa bẹẹ, gbogbo oniruuru ẹka iṣẹlẹ pataki ti ikẹhin ọjọ gbọdọ ṣẹlẹ nigba ayé iran kanṣoṣo, iran 1914. Eyi tumọsi pe awọn eniyan kan ti wọn walaaye ni 1914 yoo walaaye sibẹ nigba ti eto-igbekalẹ yii yoo de opin. Iran eniyan wọnyẹn ti di àgbàlagbà lọjọ ori bayii, ti o ń fihan pe akoko kò ni pẹ́ pupọ mọ́ ki Ọlọrun tó mú eto-igbekalẹ awọn nnkan isinsinyi wá sí opin rẹ̀.
17, 18. Asọtẹlẹ wo ni o fi bi a ti sunmọ opin ayé yii tó han?
17 Asọtẹlẹ miiran ti ń fihan pe opin eto-igbekalẹ yii ti sunmọ opin rẹ̀ gírígírí ni aposteli Paulu fi funni, ẹni ti o sọ tẹ́lẹ̀ pe: “Ọjọ Oluwa ń bọ̀wá gẹgẹ bi ole ni òru. Nigba ti wọn bá ń wi pe, alaafia ati ailewu; nigba naa ni iparun òjijì yoo de sori wọn . . . wọn ki yoo si le sálà.”—1 Tessalonika 5:2, 3; tun wo Luku 21:34, 35 pẹlu.
18 Lonii, Ogun Tútù ti kọja lọ, ogun laaarin awọn orilẹ-ede le má jẹ ihalẹmọni ti o rinlẹ̀ mọ́. Nitori naa awọn orilẹ-ede le nimọlara pe awọn ti sunmọ ètò ayé titun kan gidigidi. Ṣugbọn nigba ti wọn bá nimọlara pe isapa wọn ń ṣaṣeyọri, yoo tumọsi odikeji ohun ti wọn nilọkan, nitori yoo jẹ àmì ikẹhin pe iparun eto-igbekalẹ yii lati ọwọ́ Ọlọrun ti sunmọle. Ranti, awọn ìṣètò lati yanju ọran lọna ti oṣelu ati adehun alaafia kò fa iyipada gidi kan ninu awọn eniyan. Wọn kò mu ki awọn eniyan nifẹẹ araawọn. Awọn aṣaaju ayé kò si fi opin si ìwà ọdaran, bẹẹ ni wọn kò mu aisan ati iku kuro. Nitori naa maṣe gbẹkẹ rẹ le awọn idagbagberu eyikeyii nipa alaafia ati ailewu eniyan ki o si rò pe ayé yii ti wà loju ọ̀nà lati yanju awọn iṣoro rẹ̀. (Orin Dafidi 146:3) Ohun ti iru igbe bẹẹ yoo tumọsi niti gidi ni pe ayé yii ti sunmọ ìkógbásílé rẹ̀ gírígírí.
Wiwaasu Ihinrere
19, 20. Asọtẹlẹ wo nipa iwaasu ní ikẹhin ọjọ ni a rí ti o ń ní imuṣẹ?
19 Asọtẹlẹ miiran ti ń fihan pe a ti wà ni ikẹhin ọjọ lati 1914 ni ọkan ti Jesu funni pe: “A kò le ṣaima kọ waasu ihinrere ni gbogbo orilẹ-ede.” (Marku 13:10) Tabi bi Matteu 24:14 ti ṣe sọ ọ: “A o si waasu ihinrere ijọba yii ni gbogbo ayé lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo si de.”
20 Lonii, ju ti igbakigba rí lọ ninu itan, ihinrere nipa opin ayé yii ati ìwọlédé Paradise ayé titun labẹ Ijọba Ọlọrun ni a ti ń waasu rẹ̀ ni gbogbo ayé. Lati ọwọ́ awọn wo? Lati ọwọ́ araadọta ọkẹ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Wọn ń waasu ni gbogbo orilẹ-ede lori ilẹ̀-ayé.
21, 22. Ni pataki, ki ni o fi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa han gẹgẹ bi Kristian tootọ?
21 Ni afikun si iwaasu wọn nipa Ijọba Ọlọrun, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń hùwà ni ọ̀nà ti o fi wọn han gẹgẹ bi ọmọlẹhin Kristi tootọ, nitori o polongo pe: “Nipa eyi ni gbogbo eniyan yoo fi mọ̀ pe, ọmọ-ẹhin mi ni ẹyin iṣe, nigba ti ẹyin bá ni ifẹ si ọmọnikeji yin.” Nipa bẹẹ, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a sopọ ṣọkan ninu ẹgbẹ ara kari-aye nipasẹ ìdè ifẹ ti kò ṣee já.—Johannu 13:35; tun wo Isaiah 2:2-4; Kolosse 3:14; Johannu 15:12-14; 1 Johannu 3:10-12; 4:20, 21; Ìfihàn 7:9, 10 pẹlu.
22 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gba ohun ti Bibeli sọ gbọ́ pe: “Ọlọrun kii ṣe ojusaaju eniyan: ṣugbọn ni gbogbo orilẹ-ede, ẹni ti o bá bẹru rẹ̀, ti o si ń ṣiṣẹ òdodo, ẹni itẹwọgba ni lọdọ rẹ̀.” (Iṣe 10:34, 35) Wọn ń wo awọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ wọn ni gbogbo orilẹ-ede gẹgẹ bi arakunrin ati arabinrin wọn nipa tẹmi, laika ẹ̀yà-ìran tabi àwọ̀ sí. (Matteu 23:8) Ati kókó naa pe irufẹ ẹgbẹ ara kari-aye bẹẹ wà loni fikun ẹri naa pe ète Ọlọrun yoo ni imuṣẹ laipẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ijọba ọrun pipe ti Ọlọrun ni yoo jẹ akoso kanṣoṣo fun araye ninu ayé titun naa